Search

Explore

 
 

Login

 
   

Trend

 
 

Fatwa

Papers

 
          
    

  

 

 

 
Ojule Koko Mewa Awon Akole Titun Fi Itan/Irohin/Ibeere Sowo Wadi Ni Ede Yoruba Agbo-Oro Yoruba Akopo
   
 
Tite Wole

  Create an account

Ojule Nyin Akoko

Tite Jade

 
 
Ifiseje Tire Awon Omo-Egbe Yoruba Se Ayewo Atoka Apoti Ifi Atoka Pamo Atokun Alantakun Awon Eda Ipamo
 
     
 

 

 
 
                  
 

Irohin Nitele-N-Tele

 
 

Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose
[ Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose ]

·Owo Te Wolii Ijo Kerubu To N Feran Eeyan Soogun L'Ogbomoso
·Nitori Ija Gbogbo Igba Pasito, Igbeyawo Odun Meeedogun Fori Sanpon L'Ondo
·Iya Ayo Ku Lojiji N'Ilesa, Won Ni Ale E Lo Fi Ibasun Pa A
·Ismaila Dero Ogba Ewon L'Ekiti, Won Loun Lo Pa Iyawo Re
·Epe niyawo mi maa n se fun mi laraaro to ba n gbadura—Tunde
·Babatunde foruko olopaa otelemuye lu jibiti n'Ilorin, lowo ba te e
·Ezekiel ki omoodo oga re mole, lo ba n wo bii maalu to robe nile-ejo
·L'Akure, ajo to n gbogun ti oogun oloro sawari ile kan to kun fofo fun igbo
·Odaran ponbele ma ni Ige yii o: O fipa ba Tomiwa lo po l'Owo, lo ba tun fi
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
                  
 

Iwadi Ni Yoruba

 
 


 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
                  
 

Random Fatwas Updates

 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
                  
 

Ipase Awon Eto L'owoyi

 
 
Ko Si Oun Kankan Fun Nyin Nibi Yi Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo Mo Wa. Lati Ni Eto Si Awon Ohun Gbogbo Ti Ibiyi, E Gbodo Koko Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi Na Tabi Ki E Darapo Mo Wa.
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
                  
 

Tumo Yoruba Sede Miran

 
 
E Yan Ede Ti E Ba Fe Ni Sise Ipaaro Ede Kan Fun Ekeji:

 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
                  
 

Your Local Time

 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
                  
 

Awon Atoka Ti Atehinwa

 
 
Wednesday, October 14
· Aye Yii Ti Baje O! Omo Odun Meta Ni Hassan Fipa Ba Lo Po N'Ilorin
· Akanse Adura Ati Ijoko Pakati Fun Isehinde Mubasiru, Aburo MKO Abiola, To Ku Yio
· Nwon Ni Oku Orun Gba Tope Loju N'Ifaki-Ekiti, Lo Ba Bere Si i Ka Boroboro
· Lojo Ti Won Sinku Kunle Adepeju, Omo Yunifasiti Ti Won Yinbon Pa N'Ibadan,
· Noosi Abele Bbebi Daran N'Ilorin, Ibi Omo Kate Ni Ko Jade, Lo Ba Gbabe Ku
· O Ma Se O: Won Ba Oku Omo Ghana Legbee Soobu Kan Ni Ago-Oko
· Obafemi Gun Ore Re Pa Ni Yaba, Owo Lo Dija Sile
· Okunrin Kan Ti Bere Si i San Egberun Lona Aadota Naira Fun Agbale To Da Milionu
Thursday, June 18
· Ramdan: Aawe Gbigba Ninu Ramadan Ati Awon Eto Re: Eko ni Nipa Ramadan Ati Ipese
· Ohun tawon ariran eke woli, alufa ati oluwo so pe yoo sele lodun yii ree: Eyi ni
· Kike Alkur'an Ati Awon Eko Re: Alaye Ola (Esan) kike AlKur'an Alaponle
· Leyin ti won ti pa Ironsi losu keje, odun 1966, ibeere ti gbogbo ilu n beere ni
· Asiri pasito to n ba awon iyawo oniyawo sun n'Ibadan tu
· Ileese alajeseku lu awon onisowo ni jibiti owo nla n'Ilorin
· Se won ro pe won yoo wole ni, abi ewo ni ija: Ajimobi, ma ma ba won ja...
· Ijoba soja... Ijoba soja... Ijoba soja...
· Nile Yoruba, ko gbodo sogun, ko gbodo sija o
· Awon adigunjale ma tun sose l'Owo, won gbemi olopaa mefa, bee ni won paayan
· Nitori jenereto, toko-tiyawo na iyawo onile daku
· Epe niyawo mi maa n se fun mi laraaro to ba n gbadura—Tunde
· Gbogbo igba ti mo ba loyun loko mi maa n ba mi ja, o digba ta a ba fee loyun mi-
· Eyi Ni Bi Imaamu Ile Ibadan Se Ku Gan-an: Ki Olohun Gba A Si Ogba Idera Alujana
· Leyin odun meta to ti n womo, iyaale ile bi omo to niwo lori n'Ilesa
· Nitori siga, Alli pa Idowu ni Ikotun
· Asiko ree fun Buruji Kasamu lati de Amerika ki won: Omo egbe PDP gbe Kashamu lo
· Sunday ki iyawo ore re mole n'Ilorin, lo ba fipa ba a lo po
· Won din dundu iya fawon looya l'Ondo
· Awon akekoo ileewe olukoni Oro dero ogba ewon fesun sise egbe okunkun
· Nitori owo ina: Iya Olope fun iya onile e lorun pa ni Mowe
· Mudasiru pa iyawo re ti pelu oyun osu meji, lo ba sa lo siluu oyinbo

Awon Atoka Ti O Ti Pe
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
                  
 

Onka Ni Oju-Agbo

 
 
Ni Wakati Yi, Awon Eniti Nwon Wa Ni Oju Agbo Lowo Yi Pelu Nyin Je 2 Ninu (Awon) Alejo Wa 3 Ninu (Awon) Olulo Wa Ati Omo-Egbe Awqaf, Awon Asiwaju Ninu Egbe Olomokunrin Fatih-ul-Fattah Ati Ninu Egbe Olomobirin Taqiah Sisters. Lati Ri Awon Ti Nwon Ti Fi Oruko Sile Bi Ti Nyin Ti Nwon Wa Ni Oju-Agbo Pelu Nyin Lowo Yi E Te Lati Ri Ni Ibiyi

E Koi Ti Fi Orkuo Sile Lati Wole Si Oju Agbo. Ti E Ba Fe Lati Lo Si Ibiyi E Le Fi Oruko Sile L'ofe Ni Ibiyi
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
                  
 

Ona Igba Wole Si Agbo

 
 
Oruko-Aroso

Oro-Asiri

Se E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi? Ko Buru, E Lee Fi Oruko Sile E Te Ibi Yii Lati Fi Oruko Sile. Lehin Iforukosile, Anfaani Pupo Wa Fun Nyin, Fun Apere E Le Se Atunto Oju Ewe, E Si Lee Tun Fi Ase Sile Nipa Bi Awon Alaiye Yio Ti Han, Ati Wipe E Le Se Ifiranse Awon Alaiye Ti Yio Han Gedegbe Pelu Oruko Nyin Ni Ti Faari.
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
Itan/Irohin/Ibere Nla L'oni

Ko Si Atoka / Itan Kankan Fun Nyin L'owo Yii Nitori Wipe E Koi Ti Fi Oruko Sile Lati Lo Si Ibiyi. Fun Gbogbo awon Anfaani Ti O Wa Fun Apere Awon Atoka / Itan Ti O N Lo L'owo Ati Awon Atoka Titun Ti Oojo, E Gbodo Fi Oruko Sile L'ofe Lati Lo Si Ibiyi Tabi Ki E Darapo L'ati Di Ara Wa.

 

Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin

TITUBA KURO NIBI ESE (AT-TAWBAH MIN AL-MA'ASIY)
(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 25713 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 5)

Lati Ori Minbari Yoruba

TITUBA KURO NIBI ẸSẸ (AT-TAWBAH MIN AL-MA'ASIY)

Awọn erongba khutuba
- Sisẹri pada lọ ọdọ Ọdọ Ọlọhun
- Rire awọn eniyan lori bi wọn yoo se se atunse aarin wọn ati Ọlọhun
- Jijinna si ijakan ninu ikẹ Ọlọhun
Akoko Khutuba mejeeji: Isẹju marundinlogoji

Khutuba Alakọkọ

الحمد لله القائل في كتابه المبين : "وتوبوا إلى الله جميعا أيها المؤمنون لعلكم تفلحون" (النور 31) أحمده إذ فتح لعباده باب التوبة . ودعاهم إليها , ووعدهم أن يتقبلها منهم ويمحو بها سيئاتهم . واشهد أن لا إله إلا الله وحده لا شريك له ولا نعبد إلا إيّاه . وأشهد أن محمدا عبده ورسوله صلّ الله عليه وأصحابه وبعد

Ọpẹ ni fun Ọlọhun to sọ ninu tira Rẹ pe: "Nitorinaa, ẹ ronupiwada lọ si ọdọ Ọlọhun, gbogbo nyin patapata, ẹyin onigbagbọ ododo ki ẹ le baa la. (Suratul Nuru 31). Mo jẹri pe ko si ẹniti isin ododo yẹ, ayafi Ọlọhun nikan ti ko ni orogun, bẹẹni mo si jẹri pe Annọbi wa Muhammadu ẹrusin Ọlọhun ni Ojisẹ Rẹ si ni, ki Ọlọhun bawa kẹ Annọbi, awọn ara ile rẹ, awọn sahabe rẹ ati gbogbo ẹlẹsin isilaamu titi ọjọ ikẹyin.


(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 25713 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 5)
 
   
   
   
   
   
   
   

 

 

Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

Ojo Buruku, Esu Gbomimu L'ojo Ti Won Pariwo "Ole" Le Awolowo Lori
(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 12878 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 5)

Lati Owo Olootu Irohin Yoruba

Ojo Buruku, Esu Gbomimu L'ojo Ti Won Pariwo "Ole" Le Awolowo Lori N'Ibadan, Nitori Ija Oun Ati Akintola Ni

Won ti pari ipade Egbe Olope, Action Group, (AG) niluu Jos, Ladoke Akintola ati Ayo Rosiji pelu awon minisita merin ti won si kuro nipade naa ko pada sibe, bo tile je pe awon agbaagba egbe won parowa fun un lati lo, ki won jo ri Obafemi Awolowo, ki won le yanju ede-aiyede nla to be sile ninu egbe won. Awon eeyan Akintola ni ko je ko lo sipade ohun, won ni anfaani to wa ninu ko ma lo sibe po fun un ju ko lo lo.

Won tile ni ko si anfaani kan fun un bo ba lo sibe, yoo kan tun pada si oko aaro re ni. Oun naa si gbo, ko yaa lo mo. Pelu bi ko se lo nni, awon omo re ko je ki nnkan sinmi niluu Ibadan ati ile Yoruba lapapo, won n rin kaakiri, ipade n lo lorisiirisii, ohun ti won si n wa naa ni bi won yoo ti se fi ese ominira ti Akintola gba lowo Awolowo yii rinle, ti SLA yoo gba agbara kun agbara, ti won ko si ni i so pe Olorun lo mu un.

Awon omo-eyin Awolowo paapaa ko mu nnkan rogbo nibi ipade won ni Jos. Won ti fibinu yo Ayo Rosiji kuro nipo akowe agba egbe ohun, won si ti fi Sam Ikoku si i. Bee ni won ti fun Bola Ige ni oye kan pataki ninu egbe AG, oun ni alukoro pataki bayii, Publicity Secretary' lapapo, gbogbo oro to ba si jade ninu iwe iroyin, tabi to ba jade lori redio, to ba ti je oro egbe won, ki e ti mo pe lati enu Bola Ige lo ti jade.


(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 12878 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 5)
 
   
   
   
   
   
   
   

 

 

Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

WIWA MIMO ATI KI A SI LO IMO TI A BA KO
(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 27186 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)

Lati Ori Minbari Yoruba

WIWA MIMỌ ATI KI A SI LO IMỌ TI A BA KỌ

1- Ipeni si akiyesi lati wa mimọ ti o wulo.
2- Irani leti awọn ẹkọ ti o wa fun wiwa mimọ.
3- Pipe fun sise atunse ilana ẹkọ

Wiwa mimọ jẹ ohun ti Isilaamu kakun babara fun musulumi, ni kika ati kikọ. A o ranti akọkọ ohun ti o sọ kalẹ fun Annabi Muhammad (r) ni ayah ti o sọ Pataki imọ

قوله تعالى:" اقرأ باسم ربك الذي خلق. خلق الإنسان من علق. اقرأ وربك الأكرم. الذي علم بالقلم. علم الإنسان ما لم يعلم".

" maa ka pẹlu orukọ Ọlọhun rẹ, ẹni ti o da ẹda, o fi ẹjẹ didi da eniyan. Maa ka atipe Oluwa rẹ ni Alabunkun julọ ẹni ti o fi kọlamu kọ ni lẹkọ. o kọ eniyan ni ohun ti ko mọ tẹlẹ Suratul Alak: 1-5.

Dandan ni ki Musulumi wa mimọ ki o to maa fi se isẹ. Oluwa sọ wipe


(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 27186 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)
 
   
   
   
   
   
   
   

 

 

Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Owo Te Wolii Ijo Kerubu To N Feran Eeyan Soogun L'Ogbomoso
(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 6553 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 3)

Lati Owo Olayinka Adedayo

Owo Te Wolii Ijo Kerubu To N Feran Eeyan Soogun L'Ogbomoso

Nigba ti eni to n pe ara e ni wolii Olorun ba n fi eran eeyan egbe e saajo fawon odo agutan, ki waa ni iba maa fi soogun bo ba se pe ise isegun gan-an lo n se? Eyi ni ibeere ti awon eeyan n bi ara won leere ni olu ileese olopaa ipinle Oyo to wa ni Eleyele, n'Ibadan, nigba tawon agbofinro n safihan okunrin wolii kan, Oluwatosin Odetunde, to n fi eran eeyan soogun fawon eeyan pelu omokunrin re kan, Jacob Odetunde, atawon meji mi-in ti won n je Adewole Elijah ati Adeyanju Adeniyi.

Iwe Irohin Yoruba gbo pe funra okan ninu awon afurasi yii pelu afurasi odaran egbe e kan to ti je Olorun nipe bayii ni won pa okunrin kan labule ti won n pe ni Odo-Oba, nitosi ilu Ogbomoso, nipinle Oyo, laipe yii, ti won si kun oku re bii igba ti awon alapata ba ge eran maalu si bure nla nla.


(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 6553 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 3)
 
   
   
   
   
   
   
   

 

 

Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

Lori Rogbodiyan Yunifasiti Ibadan Ni 1971, Gani Fawehinmi Ba Arabinrin Apampa Fa
(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 11531 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)

Lati Owo Akowe Irohin Yoruba

Lori Rogbodiyan Yunifasiti Ibadan Ni 1971, Gani Fawehinmi Ba Arabinrin Apampa Fa Wahala Gidigidi

Ojo nla kan lojo naa, lojo ti obinrin ti won n pe ni Grace Apampa, alabojuto agba fun ileigbe Azikwe Hall', ninu Yunifasiti Ibadan, duro niwaju igbimo to n gbo ejo awon olopaa ti won yinbon pa Kunle Adepeju, ati ohun to fa sababi isele naa ninu yunifasiti ohun. O duro niwaju won, o si rojo, o salaye titi enu oun paapaa fere bo, bee ni awon looya ko si fi i lorun sile, paapaa Gani Fawehinmi, eni to tako obinrin ohun pe gbogbo ohun to sele nibe, owo e lo ti wa, ati bi ko ba si tire ni, ko le si ija ninu ogba yunifasiti yii debii pe awon olopaa yoo fi wa sibe, tabi ti won yoo waa maa yinbon. Se gbogbo ejo ti awon omo yunifasiti ti ro kale, ori obinrin yii ni won ro ejo naa mo, won ni oun ni ko fun won lounje, oun lo n ta ounje ati oti won fawon araata, bo si se n ta awon ohun to to sawon yii lo n febi pa awon, ohun to faja gan-an niyen.

Awon eeyan ti ro pe obinrin naa ko ni i wa ni, iyen awon looya atawon omoleewe, nitori ohun ti won gbo tele ni pe Apampa ti sa lo. Koda, awon omoleewe kan so kinni ohun di orin, ti won n korin kiri ogba pe, "Ko lee boode, ko lee boode, Apampa tilekun mori, ko le boode!


(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 11531 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)
 
   
   
   
   
   
   
   

 

 

Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara

O Sele L'Egba! Seun Bimo Kan Fokunrin Meji L'Abeokuta
(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 5805 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)

Lati Owo Olootu Irohin Yoruba

O Sele L'Egba! Seun Bimo Kan Fokunrin Meji L'Abeokuta

Opo awon to fee lo sibi isomoloruko kan to waye lojo Aje, Monde, ose to koja, laduugbo kan ti won n pe ni Ita-Balogun, Ago-Oko, niluu Abeokuta, ni won dogbon feyin rin pada nigba ti wahala deede bere lori omo tuntun ti won fee fun loruko lojo naa.

Ohun to fa wahala to mu ki gbogbo aga ati atibababa ti won gba lojo naa bere si i di nnkan tawon kan baje ko seyin bi won se ni okunrin meji ni iya omo naa bimo fun, tawon oko iyawo naa si n ja pe awon lawon lomo.

Seun Ojo ni won pe oruko obinrin ti won ni ko mo eni to le gbomo fun ninu awon mejeeji to n ja ohun.


(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 5805 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)
 
   
   
   
   
   
   
   

 

 

Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

Nnkan De! Oro Awon Minisita Buhari Ti Da Wahala Sile Ninu APC
(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 7563 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)

Lati Owo Olowale Adejare

Nnkan De! Oro Awon Minisita Buhari Ti Da Wahala Sile Ninu APC

Ni gbara ti oruko awon ti Aare Muhammadu Buhari fee fi se minisita re ti jade lawon ti won mo nipa oselu ti mo pe wahala loro naa ba de, sugbon awon asaaju egbe naa gbogbo n pa kinni ohun mora, won ko fee so o sita. Inu awon kan dun pe ibi ti oro ohun yoo yori si ree, sugbon inu awon kan baje patapata.

Oro naa ko le se ko ma ri bee, nitori ninu gbogbo awon ti Buhari mu, ko senikan to lenu ninu awon asaaju APC, Buhari lo yan won funra re, awon to fe lo pe mora, ko si fi tawon olori egbe naa se. Ninu gbogbo awon gomina APC paapaa, Gomina Ibikunle Amosun nikan ni Buhari je ko fa eeyan kale, ko faaye gba gomina mi-in mo rara, eyi si fa ibinu ati ikunsinu repete. Eyi to tile waa mu wahala ati ede-aiyede to si le pada waa bi Ige ko bi Adubi lowo bayii ni pe gbogbo awon ti Buhari yan yii, paapaa awon to yan lati ile Yoruba, awon tawon olori egbe APC lagbegbe naa ko faramo rara ni.


(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 7563 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)
 
   
   
   
   
   
   
   

 

 

Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin

Oga Olopaa Wo Segun To Fipa Ba Alaaja Lasepo N'Ibadan Lo Si Kootu
(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 2122 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)

Lati Owo Olootu Irohin Yoruba

Oga Olopaa Wo Segun To Fipa Ba Alaaja Lasepo N'Ibadan Lo Si Kootu

Fun bo se fi tulaasi ba iya kan to n je Alaaja Serifat Isola, lasepo, to si tun ja a lole owo, ero ibanisoro atawon dukia mi-in, oga agba olopaa ipinle Oyo, CP Leye Oyebade, ti pe okunrin eni odun mejidinlogoji kan, Segun Muyiwa lejo si kootu.

Ni nnkan bii aago mejila osan Ojoru, Wesde, ojo ketalelogun, osu kesan-an, odun yii, ni Segun ka Alaaja Serifat eni ti a fi ojulowo oruko e bo lasiiri mo oju-olomo-ko-to-o laduugbo ti won n pe ni Eyin Girama, ni agbegbe Iwo Road, n'Ibadan, to si ja a lole awon dukia re, eyi ti apapo re to egberun mejidinlogorun-un naira (N98,000).


(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 2122 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)
 
   
   
   
   
   
   
   

 

 

Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Alaigboran Niyawo Mi, O Tun N Soogun, Mi O Se Mo - Otedola
(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 2381 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)

Lati Owo Akowe Irohin Yoruba

Alaigboran Niyawo Mi, O Tun N Soogun, Mi O Se Mo - Otedola

Ile-ejo ibile to wa ni Igando, nipinle Eko, ni baale ile kan, Ogbeni Adedola Odetola, gba lo ninu osu kesan-an to pari yii, o ni ki won ba oun fagile igbeyawo odun marun-un to wa laarin oun atiyawo oun, Regina, nitori ko gboran soun lenu. O ni ohun ti iya re ati Anti re ba so fun un lo fi n huwa soun ninu ile, ara oun ko si gba kobinrin ma tele ase oko, kawon si tun jo maa gbe.

Odetola so pe osu mokanla leyin igbeyawo awon ni Regina bere si i se bakan bakan ninu ile, igba naa lo di pe ko maa ko ounje toun ba ra lo sodo mama ati anti re. O ni Regina so pe awon eeyan meji yii lo se pataki ju nigbesi aye oun, ohun ti won ba si so foun loun yoo maa tele, oun ki i se eru oko ti yoo maa sa kubekube labe ase okunrin.


(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 2381 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)
 
   
   
   
   
   
   
   

 

 

Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Nitori Ija Gbogbo Igba Pasito, Igbeyawo Odun Meeedogun Fori Sanpon L'Ondo
(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 1921 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)

Lati Owo Oluseye Iyiade, Akure

Nitori Ija Gbogbo Igba Pasito, Igbeyawo Odun Meeedogun Fori Sanpon L'Ondo

Ile-ejo koko-koko kan to fikale s'Oke-Eda, niluu Akure, ti fopin sigbeyawo olodun meeedogun to wa laarin pasito kan toruko re n je Tunde Adekunle pelu iyawo re, Abileko Agbeke Adekunle, latari esun ija ojoojumo ti eni-owo naa fi kan iyaale ile ohun.

Pasito yii to je oludasile ijo 'Christ Living Church' niluu Owo, nijoba ibile Owo, nipinle Ondo, lo mu esun iyawo re wa pe obinrin naa ki i gboran soun lenu, bee lo lo feran ija ju ka si nnkan lo.

O ni ko sibi tobinrin olomo merin yii ko ti le ja ti kinni ohun ba gun un, koda, o ni Agbeke ti ya aso mo oun lorun ri niwaju gbogbo omo ijo lasiko tawon n se isin lowo.


(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 1921 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)
 
   
   
   
   
   
   
   

 

 

Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

Olorun O, Waa Gba Awa Omo Yoruba Lowo Ogun Ainisokan
(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 8187 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)

Lati Owo Akowe Irohin Yoruba

Olorun O, Waa Gba Awa Omo Yoruba Lowo Ogun Ainisokan

Olorun o, n ko mo ibi ti oju re wa, Oba nla. Sugbon nibikibi ti oju re ba wa, mo gbadura si o ni kutukutu owuro yii, waa gba awa omo Yoruba la, waa ko wa yo lowo ota ile, waa ko wa yo lowo ota awa ara wa. Olorun, gba wa ka le ni isokan laarin ara wa, ki oro ara wa ye ara wa, ki o ma si se so wa di alatako ara wa. Ma je ka fi owo ara wa se ara wa paapaa, ma je ki oro wa ti baje koja atunse ko too ye wa. Amin.

Bi mo ti se fee soro to, n oo tun senupo die. Bi mo ti se fee binu to, n ko ni i binu bee, nitori ki n ma fun awon abuni loro so. Loooto, mo mo pe gbogbo wa ko ni i sun ka kori si ibi kan naa, bee ni ironu wa ko ni i je eyo kan gege bii iran, sugbon awon oro kan wa to ye ko maa dun wa bakan naa, awon ohun kan wa to ye ko maa ye wa bi a ba se n so o, paapaa oro to ba le ko iran Yoruba si iyonu lojo iwaju, ti yoo si maa fa wa seyin ninu ajose orile-ede wa.


(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 8187 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)
 
   
   
   
   
   
   
   

 

 

Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu

Wooli Fe Gbemi Omo Re Omo Odun Meje To Nka L'Akure, Lo Ba Ni Dandan Bi Ki W
(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 2154 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)

Lati Owo Stephen Ajagbe, Ilorin

Wooli Fe Gbemi Omo Re Omo Odun Meje To Nka L'Akure, Lo Ba Ni Dandan Bi Ki Won Foun Lori Ewure

Oro omodebinrin omo odun meje kan, Marvelous, to ka laduugbo Oluwole, lagbegbe Olu Foam, niluu Akure, ti fee di wahala nla sawon araadugbo ohun lorun bayii pelu bi won se ni baba e, Wolii Oluwafemi Ayodele, n leri pe afi dandan koun gbemi e leyin to ti ka pe oun loun wa nidii gbogbo idaamu ti wolii naa n dojuko.

Gege bi ohun ta a fidi e mule nipa isele ohun, Baba Marvelous to je oludasile ijo kan niluu Akure ni won lo loo gbadura lodo wolii kan niluu ohun lori oro aye e to dojuru bii ese telo.


(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 2154 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)
 
   
   
   
   
   
   
   

 

 

Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga

Ishola Fipa Ba Omo Odun Mesan-an Lo Po N'Ilorin, O Tun Fi Ankasiifu Nu Oju
(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 1788 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)

Lati Owo Olawale Ajao, Ibadan

Ishola Fipa Ba Omo Odun Mesan-an Lo Po N'Ilorin, O Tun Fi Ankasiifu Nu Oju Ara Re

Owo ajo Sifu Difensi ipinle Kwara ti te arakunrin eni odun metadinlogbon kan, Oyetunde Anjola Ishola, latari pe o huwa to se ni ni kayeefi pelu bo se fipa ba omodebinrin omo odun mesan-an kan ti a foruko bo lasiiri lo po, to si tun fi ankasiifu nu oju ara re.

Gege bi alukoro ajo naa nipinle Kwara, Henry Bilesanmi, se salaye fun akoroyin wa, ojo kejo, osu kesan-an, odun yii, ni Ishola huwa naa ni nnkan bii aago mejo koja iseju marundinlogun. Baba omo yii, Hakeem Mustapha, lo mu esun to ajo naa wa pe Ishola ti fipa ba omo oun obinrin ti ko ju omo odun mesan-an lo lo po.


(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 1788 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)
 
   
   
   
   
   
   
   

 

 

Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

Sugbon Iro Gidi Niyen O: Enu Won Wo Wowo
(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 4316 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)

Lati Owo Oluseye Iyiade

Sugbon Iro Gidi Niyen O: Enu Won Wo Wowo

Enu awon oloselu dun, ko si si ohun ti won ko le se lati ba ara awon je, ati lati ba tara won paapaa je. Won yoo puro, won yoo soro didun, won yoo si maa fi gbogbo awon nnkan wonyi tan araalu je ni. El-Rufai yii naa tun ni o, gomina Kaduna.

Ariwo to pa nijerin ni pe inu oun dun si kinni kan, nje kin ni? O ni owo ti Buhari na ti won fi sayeye ayajo odun ominira to koja yii je milionu lona aadorin pere, iyen seminti milionu.

Sugbon El-Rufai fi kun un pe nigba aye Jonathan, oun ko fi milionu sise re, bilionu ni i fi i sayeye, o ni apapo bilionu to si lo je ogojo bilionu, nitori awon kan n nawo lo ni. Eleyii ki i se bee, oro awon oloselu lasan ni. Ohun ti i ba dara ni ki Rufai ko awon eri ati iwe owo ti won na naa kale, nidii eyi leeyan yoo ti mo pe ododo ni okunrin oloselu to koriira Jonathan naa n so.


(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 4316 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)
 
   
   
   
   
   
   
   

 

 

Ogbon Ati Oye: Imo-Amolo Imo-Ero Ati Ise

Nnkan Omokunrin Oko Mi Ko Le Domo, E Tu Wa Ka - Abike
(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 1637 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)

Lati Owo Bisi Adesoye, Ilesa

Nnkan Omokunrin Oko Mi Ko Le Domo, E Tu Wa Ka�Abike

Nitori to ni nnkan omokunrin oko re ko le domo, Arabinrin Abike, eni ogoji odun ti wo oko re, Ogbeni Odetola, lo sile-ejo ibile kan n'Ilesa pe ki won tu igbeyawo olodun mewaa to wa laarin awon ka.

Ninu awijare Abike niwaju adajo lo ti salaye pe oko oun dara ninu iwa ati isesi, sugbon lati odun mewaa toun ti wa loode e, oun ko loyun aaro dale ri.

Obinrin naa ni gbogbo awon aburo oun ti won segbeyawo leyin oun ni won ti bi omo meji si meta foko won, eyi toun ri bii ipenija nla toun si gbodo wa ona abayo si pelu adura.


(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 1637 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)
 
   
   
   
   
   
   
   

 

 

Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu

Asegbe Kan Ko Si Nile Yii Mo: Oro Buhari Ati Diezani Allison-Madueke
(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 2576 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)

Lati Owo Stephen Ajagbe, Ilorin

Asegbe Kan Ko Si Nile Yii Mo: Oro Buhari Ati Diezani Allison-Madueke

Bi ijoba Buhari ko tile ti i bere ise won loju mejeeji, awon ohun to n sele bayii ti fihan pe nigba ti ise ohun ba bere perewu, nnkan yoo kan nile wa yii naa ni. Okan ninu awon alagbara ana, Diezani Allison-Madueke, lowo awon olopaa ilu oyinbo ti to yen.

O ti farapamo sodo won lohun-un to fee maa gbadun awon owo to ti ri lasiko to fi n ba won sejoba nibi, se bi gbogbo won ti n se tele niyi, nigba ti won ba ko owo mi nibi tan, tabi ti won ba fi ijoba ba aye awon mekunnu ilu je tan, won yoo yaa ta koso seyin odi, won yoo sa lo bamubamu.

Buhari to gbajoba yii ti soro kan, bee ni opo awon alase orile-ede agbaye to mo ohun to n sele ni Naijiria naa ti so bee ri, ohun ti won wi ni pe awon owo ti won n ji ni Naijiria, bi awon ti won n sejoba ba ti le ri ona di awon iho ti won fi n ji owo yii ko, ko le pe ko le jinna ti Naijiria yoo fi di ilu nla ati ilu ti ko ni i see fowo ro seyin nibi kan.


(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 2576 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)
 
   
   
   
   
   
   
   

 

 

Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga

Owo Ajo Sifu Difensi Te Wolii To Fipa Ba Omo Odun Meeedogun Lo Po L'Ondo
(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 6059 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)

Lati Owo Olawale Ajao, Ibadan

Owo Ajo Sifu Difensi Te Wolii To Fipa Ba Omo Odun Meeedogun Lo Po L'Ondo

Lojo Abameta, Satide, ose to koja lohun-un, lowo ajo Sifu Difensi ipinle Ondo te okunrin wolii kan nibi to ti n sere egele pelu omodebinrin kan, Tosin, okan ninu awon omo ijo re to je eni odun meeedogun.

Gege bi ohun t'Iwe Irohin Yoruba fidi e mule nipa isele naa, wolii ohun ti won pe oruko re ni Jacob Olasupo Ojomo to je oludasile ijo Kerubu ati Serafu, to wa ni Apata Iloro, lagbegbe Oke-Ijebu, niluu Akure, ni won fesun kan pe bo se n ba omodebinrin naa lo po, bee lo n gba nnkan mo nnkan fun iya omo yii.


(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 6059 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)
 
   
   
   
   
   
   
   

 

 

Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere

Nje Oba Ooni Lee Sun Re Bayi Ti Wahala Ti Be Sile Laarin Awon Olomooba Ile-Ife?
(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 6442 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)

Lati Owo Taofeek Surdiq

Nje Oba Ooni Lee Sun Re Bayi Ti Wahala Ti Be Sile Laarin Awon Olomooba Ile-Ife?

Ni bayii to ku ojo merinlelogbon pere ti won yoo kede eni ti yoo je Ooni tuntun ni ilu Ileefe, o da bii eni pe awon idile to letoo soye naa ko ti i fori ikoko soodunrun, bi awon kan se n sekilo fawon afobaje lati te e jeje, lawon kan fori le ile-ejo pe dandan ni kawon fese ofin to oro naa.

Latojo kejidinlogbon, osu keje, odun yii, ti Oba Okunade Sijuwade ti waja lorisiirisii igbese ti bere lori eni ti yoo je Ooni tuntun, niwon igba to si je pe ko seni ti ipo ola ko wu, atawon to letoo si i atawon ti ko letoo si i ni won ti bere si i lo kaakiri lati fa oju awon afobaje mora.

Koda, iwadii fihan pe bawon kan se n ru owo kaakiri, lawon kan n se oniruuru ise idagbasoke sagboole won lati fi jewo pe omo ile oba tooto lawon je.


(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 6442 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)
 
   
   
   
   
   
   
   

 

 

Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin

E Wo O, Odun Kerin Ree Toko Mi Ti Sunmo Mi Gbeyin, E Tu Wa Ka - Serifat
(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 1907 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)

Lati Owo Olootu Irohin Yoruba

E Wo O, Odun Kerin Ree Toko Mi Ti Sunmo Mi Gbeyin, E Tu Wa Ka - Serifat

Awon Yoruba bo, won lowo to ba n dun ni, eeyan ki i fi i sabe aso, bee ni kinni taa n so yii ko se e fi sara ku. Se bo se n sokunrin naa lo n sobinrin, abi ki lo le mu odidi iyaale ile maa rababa niwaju alaga ile-ejo koko-koko pe o to gee, alubata kan ki i darin, to ni ki won ba oun fopin sigbeyawo olodun mefa to wa laarin oun atoko oun, nitori pe o ti le lodun merin bayii tokunrin naa ti beere ohun toun n ta gbeyin.

Lose to koja yii lobinrin ohun to n je Serifat Aralepo mu esun oko re wa sile-ejo koko-koko to wa niluu Ikare-Akoko, nijoba ibile Ariwa Iwo-Oorun Akoko, nipinle Ondo, pe kile-ejo ba oun fopin sigbeyawo to wa laarin oun atoko re ti won pe ni AbdulRasheed Aralepo.


(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 1907 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)
 
   
   
   
   
   
   
   

 

 

Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

Ile-ejo So Pasito Pelu Aafaa Sewon, Awon Agbe Ni Won Lu Ni Jibiti L'Emure-E
(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 1836 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)

Lati Owo Akowe Irohin Yoruba

Ile-ejo So Pasito Pelu Aafaa Sewon, Awon Agbe Ni Won Lu Ni Jibiti L'Emure-Ekiti

Ewon odun kan gbako nile-ejo majisreeti kan to wa niluu Ado-Ekiti pase pe ki won ju pasito ijo 'Deeper Life' kan, Anjorin Adaniki ati aafaa kan, Mallam Maliu Aliu, si nitori iwa jibiti ti won hu.

Anjorin to je eni odun mejilelogoji pelu ojugba re ni kootu so pe won jebi esun jibiti.

Gege bi olopaa to soju ijoba, Sgt. Oriyomi Akinwale se salaye fun ile-ejo, o ni laarin osu karun-un si osu kefa, odun 2013, lawon olujejo naa lu awon eeyan ni jibiti niluu Emure-Ekiti.


(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 1836 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)
 
   
   
   
   
   
   
   

 

 

Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

O Tan! Won Gbe Oku Tajudeen Raji, Oga Awon Omo Egbe Okunkun Wa S'Ogijo Waa
(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 3222 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)

Lati Owo Olowale Adejare

O Tan! Won Gbe Oku Tajudeen Raji, Oga Awon Omo Egbe Okunkun Wa S'Ogijo Waa Sin

Afi bii igba tawon eeyan ilu Ogijo, nijoba ibile Sagamu, nipinle Ogun, ti n reti iru nnkan to sele lose to koja yii, loro naa ri nigba ti won yari pe awon ko ni i je ki won sin oku okan lara oga awon omo egbe okunkun ti won pa to je omo ilu naa sinu ilu yii.

Tajudeen naa ti won lo lenu daadaa ninu awon egbe okunkun to wa nile Yoruba la gbo pe awon eeyan e pa danu lojo Eti, Fraide, ose to koja lohun-un, sugbon iyalenu lo je fawon molebi oloogbe yii nigba ti won gbe oku e wale waa sin, ti awon ara agbegbe ohun si so kinni ohun dorin mo won lowo pe ki won da oku naa pada, won ko si gbodo gbiyanju e wo lati sin in sibe, nitori tawon ti ko o gege bii omo ilu naa.


(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 3222 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)
 
   
   
   
   
   
   
   

 

 

Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Iya Ayo Ku Lojiji N'Ilesa, Won Ni Ale E Lo Fi Ibasun Pa A
(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 1903 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)

Lati Owo Olootu Irohin Yoruba

Iya Ayo Ku Lojiji N'Ilesa, Won Ni Ale E Lo Fi Ibasun Pa A

Tesan olopaa to wa ni Ijamo, n'Ilesa, ni okunrin kan to n sise asegita ti a ko mo oruko re lasiko ti a n ko iroyin yii jo wa lori esun pe o fi tipatipa ba orebinrin re, Iya Ayo, lo po doju iku ni Ojoru, Wesde, ose to koja, lagbegbe Oke-Eso, nijoba ibile Iwo-Oorun Ilesa.

Iwadii Iwe Irohin Yoruba lagbegbe Oke-Eso, nibi ti obinrin oloogbe naa n gbe fidi e mule pe oun ati okunrin naa ti n ba ore won bo latodun meta seyin, ti okunrin to niyawo meji sile yii si maa n wa sodo re waa sun di ojo keji lai si wahala kankan. Bee lawon eeyan si mo awon mejeeji po bii toko-tiyawo ki nnkan to sele laarin won yii too waye.


(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 1903 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)
 
   
   
   
   
   
   
   

 

 

Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue

Ise Ode Ni Won Gba Sunday Fun, Lo Ba N Sagbodegba Fole
(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 2369 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)

Lati Owo Stephen Ajagbe, Ilorin

Ise Ode Ni Won Gba Sunday Fun, Lo Ba N Sagbodegba Fole

Owo awon olopaa ilu Abeokuta ti te okunrin eni odun mejidinlogoji kan, Sunday Uche, to n sise ode atawon merin mi-in lori esun pe won ji moto gbe, bee ni won tun fee fipa ba obinrin to ni moto naa lo po.

Awon yooku towo te pelu Sunday ni Mohammed Aliu, Odeh Benedict, Akinniyi Ademola ati Sikirulai Ojulari. Agbo pe awon adigunjale naa wa lara awon to n yo awon eeyan agbegbe Ijaba, Iyesi Ota, Itele ati gbogbo Ado-Odo lapapo lenu.


(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 2369 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)
 
   
   
   
   
   
   
   

 

 

Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin

Nitori Obinrin, Awon Fulani Sara Won Pa Lojo Odun Ileya Ni Saki
(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 3416 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)

Lati Owo Olawale Ajao, Ibadan

Nitori Obinrin, Awon Fulani Sara Won Pa Lojo Odun Ileya Ni Saki

Gbogboeeyan to n koja ninu oja Sango, niluu Saki, nipinle Oyo, lo n diwo mori, ti won si tun n pariwo ikunle abiyamo nigba ti omodekunrin Fulani daran-daran kan subu sinu agbara eje latari bi elegbe re kan se sa a ladaa ni gbogbo ara, to si gbabe dero orun.

Isele buruku naa waye lojo Abameta, Satide, ojo kerindinlogbon, osu kesan-an, odun yii, nigba tawon odomokunrin Fulani daran-daran kora won jo ninu oja naa lati sajoyo odun Ileya to sese kogba wole. Gege bi ise won lodoodun, awon odo Fulani naa maa n lo anfaani popo-sinsin odun yii lati wa oko tabi iyawo, won a si tun maa lo anfaani naa lati se faaji lorisiirisii.


(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 3416 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)
 
   
   
   
   
   
   
   

 

 

Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue

Nibi Ti Oni Atawon Egbe E Ti Fee Ta Eru Ti Won Ji Lowo Ti Te Won N'Ibadan
(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 5768 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)

Lati Owo Taofeek Surdiq

Nibi Ti Oni Atawon Egbe E Ti Fee Ta Eru Ti Won Ji Lowo Ti Te Won N'Ibadan

Olawale Ajao, Ibadan Adanu ti iba se obinrin ontaja kan loja Sango, n'Ibadan, ti pada sori awon obayeje eeyan to fee ba a laye je pelu bi awon odomokunrin merin kan ti won ti so ole jija di ise se ja ilekun soobu re wole, ti won si ko gbogbo oja to wa nibe pata, sugbon towo awon olopaa pada te won, ti won si da gbogbo dukia obinrin onisowo naa pada fun un.

Laaaro ojo Aiku (Sannde), ojo ketadinlogbon, osu kesan-an, odun yii, nigba ti onikaluku awon ontaja ti gbe ilekun soobu won ti pa fun ijosin ojo naa tabi isinmi opin ose ni okunrin eni odun merindinlogbon kan, Godbless Oni, ko awon emewa e meta ti won n je Alaka Babatunde (eni odun metalelogun), Jamiu Alabi (eni odun mejidinlogbon) ati Benjamin Segun, eni ti ko ju omo odun mejidinlogun pere lo, ti won si loo ja ilekun awon soobu ti won ti n ta awon ohun eso ara, ni won ba ko gbogbo oja ti won ba nibe lo pata.


(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 5768 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)
 
   
   
   
   
   
   
   

 

 

Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara

Babalawo Fewon Jura Lori Esun Aini Salanga L'Ondo
(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 2000 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)

Lati Owo Oluseye Iyiade, Ondo

Babalawo Fewon Jura Lori Esun Aini Salanga L'Ondo

Boroboro bii igba ti aje iba maa ka ni onisegun ibile kan, Ogbeni Sowosoye Rufai n ka nigba tawon wolewole ijoba ibile Iwo-Oorun Ondo wo o wa sile-ejo alagbeeka kan to wa ni sekiteriati ijoba ibile naa pelu esun merin otooto ti won fi kan an.

Nigba to n ka awon esun naa si olujejo yii leti, oga awon wolewole ohun, Arabinrin Elizabeth Akinfemisoye so pe Rufai ko lati pese salanga miiran sile re nigba to han si i pe eyi ti won n lo tele ti kun, eyi to lo see se ko fa ajakale arun fawon to n gbe nile yii ati agbegbe re.


(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 2000 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)
 
   
   
   
   
   
   
   

 

 

Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga

Olode Ile-eko Alakoobere Fipa Ba Omoleewe Lo Po N'Ilorin
(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 2275 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)

Lati Owo Olayinka Adedayo

Olode Ile-eko Alakoobere Fipa Ba Omoleewe Lo Po N'Ilorin

Ogbeni olode kan, Appolos Isaiah, ti fipa ba odomodebinrin omo odun mesan-an kan lo po ni ile eko to ti n sise ode laduugbo Taiwo-Isale, niluu Ilorin, bayii.

Gege bi akoroyin wa se gbo, ojo kejidinlogun, osu to koja, nisele naa waye. Isaiah ni iwadii akoroyin wa fihan pe o n sise pelu ileese eleto aabo Ogboye-s Security Company ti won si fi i si ile eko alakoobere Methodist Nursery and Primary School' to wa ni adugbo TaiwoIsale.

Akoroyin wa ri i gbo pe nise ni Isaiah fogbon pe omodebinrin naa ti a foruko bo lasiiri yii, to si tan an wo ile ode to wa ninu ogba ileewe naa, nibe lo si ti fipa ba a lo po.


(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 2275 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)
 
   
   
   
   
   
   
   

 

 

Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

Losu Mefa Pere, Eedegbeta Olopaa Ti Padanu Emi Won - Arase
(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 1918 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)

Lati Owo Olowale Adejare

Losu Mefa Pere, Eedegbeta Olopaa Ti Padanu Emi Won - Arase

O kere tan, awon olopaa bii eedegbeta ni won ti padanu emi won loniruuru ona laarin osu mefa seyin ninu odun yii nikan. Oga agba awon olopaa, Ogbeni Solomon Arase, lo soro yii lasiko to n kopa ninu eto kan tawon igbimo to n ri si ibasepo laarin olopaa atawon araalu nipinle Osun gbe kale. Arase ni nnkan ibanuje ni iku awon eeyan naa je foun, sugbon eleyii tun safihan ife ti won ni si orile-ede yii.

O ni gbogbo ipa loun gege bii oga won yoo sa lati ri i pe iku awon agbofinro naa ko ja sofo. Bakan naa lo ro awon olopaa to wa lenu ise lati mo pe ifara-eni-jin fun ise nikan lo le mu eeyan goke agba. Oga olopaa naa fi kun oro re pe ijoba to wa lode bayii ti ni opolopo nnkan iyanu nipamo to fee fun awon olopaa lati le mu igbe aye rorun fun won. Lara re ni sisan owo osu won deede ati igbega lati le je koriya fun won.


(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 1918 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)
 
   
   
   
   
   
   
   

 

 

Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun

Nitori Ikolu Tawon Olokada Festac Town Se Sawon Olopaa, Awon Asofin Eko Gbe Igbi
(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 2616 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)

Lati Owo Taofeek Surdiq

Nitori Ikolu Tawon Olokada Festac Town Se Sawon Olopaa, Awon Asofin Eko Gbe Igbimo Kale

Ni bayii tile igbimo asofin Eko ti gbe igbimo eleni marun-un kale lati ri si leta ifehonu han tawon olugbe agbegbe Festac Town, nijoba ibile Amuwo Odofin, ko si won pe ki won jowo, fofin de awon olokada agbegbe yii lati yee sise nibe mo lori iwa a-lo-ni-lowo-gba ti won fi kan won ni ko ti i seni to mo ohun ti yoo tidi e yo fawon olokada naa.

Ninu leta ohun ti aare egbe awon olugbe agbegbe yii, Ogbeni Sola Fakorede, ko sile yii lo ti so pe inu-fuu-aya-fuu lawon n gbe bayii, pelu bawon olokada se n fise naa boju sise laabi, ti won n da awon eeyan lona gba nnkan-ini won.


(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 2616 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)
 
   
   
   
   
   
   
   

 

 

Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose

Ismaila Dero Ogba Ewon L'Ekiti, Won Loun Lo Pa Iyawo Re
(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 2694 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)

Lati Owo Olootu Irohin Yoruba

Ismaila Dero Ogba Ewon L'Ekiti, Won Loun Lo Pa Iyawo Re

Baale ile eni odun mokandinlogbon kan, Azeez Ismaila, ti wo gau nipinle Ekiti, Olorun nikan ni yoo si ko o yo. Idi ni pe ile-ejo majisreeti kan to kale siluu Ado-Ekiti ti pase pe ki won loo ju u sahaamo ogba ewon lori esun ti won fi kan an pe oun lo pa iyawo re, Odunayo Ismaila.

Gege bi olopaa to soju ijoba nile-ejo, Sajenti Bankole Olasunkanmi, se salaye, ojo keeedogbon, osu kesan-an, odun yii, ni afurasi ohun lowo ninu esun ipaniyan ti won fi kan an lagbegbe Odo-Ado, niluu Ado Ekiti.

Esun tile-ejo fi kan olujejo ni Olasunkanmi so pe o tako abala kan ninu ofin to n gbogun ti iwa odaran nipinle Ekiti, todun 2012.


(Abala Lati Ka Eyi Siwaju... | 2694 Oode-Ipese Atoka Yii | Nje E Ni Alaiye Lori Eyi? | Iwon: 0)
 
   
   
   
   
   
   
   

 

 

 
EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Newspapers Magazines, Halal Custom Search Results For Islam, Shariah, Fatwa Rulings, News Headlines On Middle East, African American Muslims, European Muslims, Africa And Asia In Arabic, English, Yoruba, Hausa, Indonesian Bahasa, Swahili, French, Urdu, Somali, Persian, Turkish, Arab Forums Of National International Islamic Scholars Writers - Schools, Universities, Colleges, Mosques, Muslim Businesses - Arabic English Koran Translations Transliteration Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And Muxlima.Com

 
 

Ojule :|: Koko Mewa :|: Akole Titun :|: Fi Itan/Irohin/Ibeere Sowo :|: Wadi Ni Ede Yoruba :|: Agbo-Oro Yoruba :|: Egbe Yoruba :|: Se Ayewo :|: Ifiseje Tire :|: Idiwon :|: Atoka :|: Apoti Ifi Atoka Pamo :|: Akopo :|: Atokun Alantakun :|: Eda Ipamo :|: Ibeere Ti O Wopo :|: So Nipa Wa F'Aiye :|: Akopo Iwe
 
 Custom Search EsinIslam
بحث مخصص

 

· About Us    · Explorer   · Writers   ·Reciters   · Rulings   · Contact Us

·· Sign In

·· Sign Up

Read More About Us Choice · Forums · Papers · Writers

·· Donations

·· Fatwa

Brought To You By The Awqaf London - The Society Of Students Of Sheikh Dr. Abu-Abdullah Adelabu

We Are EsinIslam Media Of The Awqaf Students Of Sheikh Abu-Abdullah Adelabu

 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 

Director Umm-Abdullah Adelabu Head Office admin@esinislam.com Amir (President) Sheikh Abu-Abdullah Adelabu (Ph D Damas) sheikh@esinislam.com

 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 
 

© EsinIslam.Com And Muxlima.Com Designed And Produced By Awqaf London Copyright All Rights Reserved. Media contact publicrelations@esinislam.com

No copyright permission required for users whose works, activities and intentions are for purpose of Da'wah, Islamic studies and services to the Muslims. However The Awqaf's Majlis (Council) does review 'Given Permissions' and 'Media Engagements' as necessary

P. O. Box 46044, Maida Vale, London W9 3WN The United Kingdom Tel: +44 (0) 207 266 2207 Fax: +44 (0) 207 266 1289 / 266 3496

Please Pray For Us And For Our Sheikh - May Salawat Allah And Salaam Allah Be Upon Our Beloved Prophet Muhammad s.a.w

 

:|: Home :|: Donations :|: About Us :|: Contact :|: Fatwa Request :|: Our Sheikh :|:

 

© EsinIslam.Com - Muxlima.Com from The Awqaf London

 

الله أكبر :: Allah Is Great