Gbagede Yoruba
 



Kike Alkur'an Ati Awon Eko Re: Alaye Ola (Esan) kike AlKur'an Alaponle
 
Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin Lati Ori Minbar Yoruba

Kike Alkur'an Ati Awon Eko Re: Alaye ọla (ẹsan) kike Alkur’an, Wiwa awọn eniyan nisọra nipa kiko airoju nibi kike Alkur’an ati Yiyannana awọn ẹkọ kike Alkur’an

Alukurani je tiira Olohun eleyii ti o sokale lati odo re lati maa je iwe ti yio maa dari gbogbo olugbagbo ododo nibi isemi aye ati esin won, eniti o ba gbe iwe mimo yii siwaju ti o si ntele, iwe yi yio fa iru enibee wo Alijannah Onidera.Nida miran, eniti o ba ju iwe mimo yi seyin ti ko tele, iwe yii yio ti iru eniti bee woo ina, latiara idieyi, eniti o ba nwa oore aye ati orun, ki o ya gba iwe mimo yii mu ki o si maa ka ni oore koore.

- Alaye ọla (ẹsan) kike Alkur’an
- Wiwa awọn eniyan nisọra nipa kiko airoju nibi kike Alkur’an
- Yiyannana awọn ẹkọ kike Alkur’an

Akoko kutuba: Isẹju marundinlogoji

الحمد لله الكريم المنّان الذي أكرمنا بالقرآن , وجعله ربيعا لقلوب أهل البصائر والعرفان , ويسّره للذكر حتى استظهره صغار الولدان وأشهد أن لا إله إلا الله وحده لاشريك له شهدة تنال بها الغفران وأشهد أن محمدا عبده ورسوله حثّ على تعلم القرآن وتعليمه والتفكر فيه وتفهيمه والعمل بأحكامه , والوقوف عند حدوده, صلّى الله عليه وعلى آله وأصحابه وسلم تسليما كثيرا وبعد

Ọpẹ ni fun Ọlọhun to pawa lasẹ ninu tira Rẹ Alapọnle pe: Ẹnyin ti ẹ gbagbọ ni ododo ẹ maa ranti Ọlọhun ni iranti ti o pọ ki ẹ si ma se afọmọ Rẹ ni arọ ati ni irọlẹ”.


"يأيّها الذين آمنوا اذكروا الله كثيرا وسبّحوه بكرة وأصيلا"Suratul Ahsabu : 41 – 42. Mo jẹri pe ko si elomiran ti ijọsin ododo yẹ, ayafi Ọlọhun nikan, O se adehun wiwọ al-jannnah fun ẹniti o ba nranti Rẹ. Bẹẹni mo jẹri pe Anọbi wa Muhammadu ẹrusin Ọlọhun ni, Ojisẹ Rẹ si ni ki ikẹ ati igẹ Ọlọhun maa baa ati awọn ara ile rẹ, awọn sahabe rẹ to fi dori gbogbo musulumi lapapọ.Ẹyin ẹrusin Ọlọhun, ibanisọrọ wa toni yoo da lori tira Ọlọhun, to se pe ibẹ ni orire yin wa, oun si ni ọna abayọ, kuro ninu fitinọti, oun ni o n fun yin ni irohin nipa awọn ẹni isiwaju ati awọn ti yoo tun maa bọ lẹhin yin bẹẹni o tun jẹ iwé idajo laarin ara yin, ọrọ inu rẹ jẹ alaye nipa idajọ Ọlọhun kii se ọrọ awada rara, ẹniti o ba gbee ju silẹ Ọlọhun yoo paarun, bẹẹni ẹniti o ba wa imọna lọ si ibomiran yatọ sii, Ọlọhun yoo sọ ọ nu, oun ni okun Ọlọhun ti o yii, ati iranti ti o gbọnngbọn julọ, anisẹ, oun ni ọna taara ti ko gbun, kikaa rẹ kii su awọn onimimọ tootọ bẹẹni aketunke, akatunka rẹ ki suni, awọn ohun eemọ inu rẹ ko le tan, ẹniti o ba nfi sọrọ yoo sọ ododo, ẹntiti o ba nfi ọrọ inu rẹ sèwàwù yoo gba ẹsan rere lọdọ Ọlọhun, bẹẹni ẹniti o ba npe awọn eniyan lọ sibi tira naa, yoo lekun ni imọna. Tobari bẹẹ, ẹ jẹ lọọ lẹkọ nipa mimọ ọ ke dada, ki a si fi mọ awọn ọmọ wa, ki a tun gbin ifẹ rẹ si ọkan wọn, titi ti yoo fi di bárakú fun wọn, ti yoo si tun ìwà wọn se, anisẹ, ti wọn yoo fi jẹ ọkan ninu awọn to nke Alkur’an, ki wọn o le maa kee lori irun, ati ki híhá rẹ le rọwọn lọrun pẹsẹ lati kekere, sebi ìmọ ni kékeré bii igbati a bá kọ nkann sórí àpáta ni.

Nitorinaa, ẹ jẹki a bẹru Ọlọhun, ki a si se àkólékàn tira Ọlọhun.

"إِنَّ الَّذِينَ يَتْلُونَ كِتَابَ اللَّهِ وَأَقَامُوا الصَّلاةَ وَأَنْفَقُوا مِمَّا رَزَقْنَاهُمْ سِرّاً وَعَلانِيَةً يَرْجُونَ تِجَارَةً لَنْ تَبُورَ(29) لِيُوَفِّيَهُمْ أُجُورَهُمْ وَيَزِيدَهُمْ مِنْ فَضْلِهِ إِنَّهُ غَفُورٌ شَكُورٌ".

Ọlọhun sọ pe:“Dajudaju awọn ẹniti nwọn nke tira Ọlọhun ti wọn si ngbe irun duro ti nwọn si nna ninu ohun ti a pèsè fun wọn ni kọkọ ati ni gbangba, nwọn nse ireti òwò kan ti ko nii parun. Ki o le se asepe ẹsan fun wọn ninu ore ajulọ Rẹ. Dajudaju Oun ni Alaforijin, Oludupẹ lọpọlọpọ” Suratul-Fatir 29 – 30."أَوْ زِدْ عَلَيْهِ وَرَتِّلِ الْقُرْآنَ تَرْتِيلا".O tun sọ ni àyè miran pe:“Ki o si ma ka Al-kur’an létòletò” Suratul Mussammilu: 4.

{لَيْسُوا سَوَآءًا مِّنْ أَهْلِ الْكِتَـابِ أُمَّةٌ قَآئِمَةٌ يَتْلُونَ ءَايَـاتِ اللَّهِ ءَانَآءَ الَّيْلِ وَهُمْ يَسْجُدُونَ}.

O tun sọ pe:“Ijọ kan mbẹ ninu awọn olutẹle tira (isaju) ti o duro deedee, nwọn si nke awọn ọrọ Ọlọhun ni akoko oru nwọn si foribalẹ” Suratul Al-Imran: 113.

"الَّذِينَ يَذْكُرُونَ اللَّهَ قِيَاماً وَقُعُوداً وَعَلَى جُنُوبِهِمْ وَيَتَفَكَّرُونَ فِي خَلْقِ السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضِ رَبَّنَا مَا خَلَقْتَ هَذَا بَاطِلاً سُبْحَانَكَ فَقِنَا عَذَابَ النَّار".

Ọlọhun tun sọ pe:“Awọn ẹniti nranti Ọlọhun ni iduro ati ni ijoko ati ni idubulẹ wọn”, Wo suratul Ali-imran 191.Ojisẹ Ọlọhun sọ ninu adisi ti Buhari gba wa pe: “Ẹniti o loore jùlọ ninu yin: ni ẹniti o wa imọ nipa Al-kur’ani, ti o si nfi mọ ẹlomiran”. Ninu adisi miran ti Buhari ati Musilimuu gbà wá, Ojisẹ Ọlọhun tun sọ pe: “Ẹniti o nke Al-kur’ani ti o si jáfáfá nibi kikee rẹ, yoo maa bẹ pẹlu awọn mọlaika alapọnle ẹni rere, sugbọn ẹniti o ńkálòlò kaa ti kika rẹ soro fun-un, ẹsan meji lo mbẹ fun-un”. Imam Musilimu tun gba adisi miran wa, ti Ojisẹ Ọlọhun sọ pe: Ẹ maa ke Al-kur’an toripe yoo wa ni olusipẹ fun ẹniti o ba nkee lọjọ alukiyamọ”. 

Ninu adisi miran ti Musilimu tun gba wa, Ojisẹ Ọlọhun tun sọ pe: “Awọn eniyan kan ko ni pejọ sinu ile kan ninu ile Ọlọhun ti wọn yoo maa ke tira Ọlọhun, ti wọn si maa da ara wọn lẹkọ, ayafi ki ifọkanbalẹ sọ kalẹ si aarin wọn, ti aanu Ọlọhun yoo si muwọn dáádu (bowọn) ti awọn mọlaika yoo si rọkiri yi wọn ka, ti Ọlọhun yoo maa ranti wọn lọdọ awọn ti o nbẹ lọdọ Rẹ.”Ninu adisi miran ẹwẹ, o tun sọ pe: “Alkur’an yoo wa lọjọ alukiyamọ ti yoo si maa sọ fọlọhun pe: irẹ Oluwa mi fi asọ ọsọ sii lọrun, (ẹniti o nke Alkur’an) ni wọn yoo ba de ni ade orí, yoo tun sọ pe: se alekun fun-un, ni wọn yoo ba wọ asọ apọnle fun-un, yoo tun sọ pe yọnu sii, ni Ọlọhun yoo basi yọnu sii, yoo wa sọ bayi pe: maa ke Al-kur’an ki o si maa gun oke lọ, wọn yoo si maa lekun ni dada pẹlu aya kọọkan” (Tirimisiyu lo gba wa). Eleyun un ni awọn ẹsan to mbẹ fun ẹniti o nke alkur’an.

Ojisẹ Ọlọhun wulẹ tisọ ninu àsọsílẹ kan pe: Mo nfi ibẹru Ọlọhun sọ asọsilẹ fun ọ, toripe oun lolórí gbogbo nkan, si dunnimọ ogun jíjà sóju ọna Ọlọhun, toripe oun ni ijọsin pataki ninu ẹsin Isilaamu, ki o si tẹramọ iranti Ọlọhun ati kike Al-kur’ani, toripe oun ni ẹmi rẹ ni sànmọ ati iranti rere nipa rẹ lori ilẹ”. (Afa Alibani sọ pe: adisi naa fẹsẹ mulẹ daada).Iwọnyi ni awọn ẹkọ to dirọ mọ kika Alkur'an:1. Sise afọmọ kika naa fun Ọlọhun lara awọn ti Ọlọhun yoo fi kona lalukiamọ ni ẹniti ko ke Alkurani nitori tọlọhun, ojisẹ Ọlọhun sọ pe ‘’Dajudaju to ba di ọjọ alukiyamọ, Ọlọhun yoo sọkalẹ saarin awọn ẹru rẹ lati se idajọ laarin wọn, gbogbo ijọ pata ni yoo wa ni ìlósòó, akọkọ ẹni ti wọn yoo kọkọ pe ni arakunrin kan ti o ko Alkur’ani jọ (sori) ati arakunrin kan ti o jagun soju ọna Ọlọhun, ati arakunrin kan ti o lowo pupọ. Ni Ọlọhun yoo ba sọ fun oluke Alkur’ani pe se bi mo fi tira mi ti mo sọkalẹ fun ojisẹ mi mọ ọ? Yoo si dahun pe bẹẹni Ọlọhun mi, Ọlọhun yoo wa sọ pe kini o wa fi imọ naa se o? Yoo si dahun pe mo jẹ ẹniti o maa nkaa losan ati loru, Ọlọhun yoo si sọ fun un pe: Irọ lo pa, awọn mọlaika naa yoo sọ pe irọ lo pa, Ọlọhun yoo wa sọfun un pe: o nkaa ki wọn le pe ọ ni oluke-alkur’ani, wọn si ti pe ọ bẹẹ, torinaa, o ti gbẹsan-an rẹ laye lẹhinnaa, wọn yoo waa wọọ lọ sinu ina. Nitori idi eyi ẹ jẹki a kee nitori Ọlọhun nikan.2 Ki o maa kee loni ìmótótó lẹniti o se aluwala.3: Rirun orin, toripe ojisẹ Ọlọhun sọ pe: “Dajudaju awọn ẹnu yin yii awọn ọju ọna Alkurani lo jẹ, nitorinaa, ẹ maa fọ ẹnu pẹlu orin, o tun sọ pe: “dajudaju nigbati eeyan ba dide to nki irun, mọlaika yoo wa sẹhin yin ti yoo maa tẹti gbọ kike Alkuran, yoo si sun mọ ọ, bẹẹni koni yẹ kosi ni gbo lẹniti yoo maa sun mọọ ti yoo si ma tẹti gbọ kike Alkurani titi ti yoo fi gbẹnu rẹ le ọ lẹnu, kọwa ni ka aya kan, ayafi ko jẹ pe ẹnu molaika ni o mbọ si’’ Baehaki lo gbaa wa. O dara pupọ lati maa run orin tori, ki ẹniti o nke Alkurani lori irun ma baa fi suta kan mọlaika.4: Sisadi Ọlọhun pẹlu gbolohun Ahudhu billahi minassaetọnir-rọjimi, toripe Ọlọhun pasẹ wiwi bẹ ni gbogbo igbati a ba fẹẹ ke Alkurani, suratuh Nahali 98

Gbolohun to daradaju ni “Ahudhu billahis samihil aliimi minassaetọnir rojiimi min hamzihi wanọfuihi wanọfasihi gẹgẹ bi o se fẹsẹ rinlẹ lati ọdọ ojisẹ Ọlọhun (S.A.W)5: Sise bisimilahir rahmonir rọhimi, eyun un ni ibẹrẹ sura, sise bayi ni wọn fi maa nmọ pe ojisẹ Ọlọhun ti pari sura ti o nkéé bọ, ibẹrẹ suratu Taobati nikan ni koti nii wi.6, Kike pẹlu ètò ati ilana kika Alkurani toripe Ọlọhun sọ pe “ki o si maa ke Alkur’ani létòletò’’ Suratul Mussammilu: 4.Umu Salatmọti tilẹ salaye nipa bi anọbi se maa nke Alkurani, o sọ pe o maa nja aya kan kuro lara ekeji, ti yoo si pe arafi inu rẹ lọkọọkan’’ 

Ninu Sọhihu Buhari, Anọsi bun Mọliki sọ pe - ojisẹ Ọlọhun maa nfaa gun dada, lẹhinna ni Anọsi wa ka bismilahi rahmonir rọhim, ti o si fa gbolohun Allọhu gun lodiwọn kika ika meji (mọddu tobihiyyu). Abdullọhi bun Mosud sọ pe ….ẹ mase maa wọ Alkurani mọra wọn bi igbati wọn ba nyarun, torinaa, ẹ kora duro nibi awọn nkan eemọ inu rẹ, ki ẹ si jẹki ọkan yin o mi riri pẹlu rẹ, ẹ ma se jẹki o jẹ pe eré ki ẹ sa parii rẹ ni ẹ o maa sa’’.7 Sise ohun daada, Albarahu bun Asibi sọ pe mo gbọ ti ojisẹ Ọlọhun nka wattiini wassaetuni ninu irun isahi, n o ri ẹniti ohun rẹ dara tabi ti o mọ nkan an ka, bii ti ojisẹ ỌlọhunO tun sọ pe: Ẹ fi ohùn yin kẹwa ba Alkurani, toripe ohun to dara maa njẹ ki Alkurani dara si ni’’. Ninu ẹgbawa ọrọ miran: “didara ohun ọsọ lo jẹ fun Alkurani’’

8 Ki o fi Alkurani kọrin. Ojisẹ Ọlọhun sọ pe: kosi ninu wa ẹniti ko ba maa fi Alkurani kọrin.’’ Laaye miran ẹwẹ ojisẹ Ọlọhun tun sọ pẹ - Ọlọhun ko tẹti si nkan kan ri gẹgẹ bi o ti maa ntẹti si anọbi Ọlọhun tohun rẹ dara, ti o si nfi Alkurani kọrin.9 Sise ohun gẹdẹgbẹ, itumọ rẹ ni pe ki o maa kaa pẹlu ohun obinrin to ba jẹ pe ẹniti o nkaa ba jẹ ọkunrin, bẹni ki obinrin naa ma ka bi igbati ọkunrin ba n ka nkan, sugbọn ki kaluku kaa ni ibamu si adamọ rẹ.10: Diduro nipari aya kọọkan, kódà ki o se pe itumọ rẹ koni tiipe ayafi pẹlu aya to tẹle e toripe ojisẹ Ọlọhun maa nka Alkurani ni aya kọọkan kọọkan, bi Suratul Fatiat yoo sọ pe “Al’amdu lilahi rọbil alamin’’ yoo kora duro, lehinnaa yoo ka aya to tẹ lee.11: Ki o ma gbe ohun rẹ soke bori ohun ẹnikeji rẹ, ki o ma baa fi suta kan ọmọnikeji rẹ ti o mbẹ lẹgbẹ rẹ. 

Ojisẹ Ọlọhun sọ pe gbogbo yin lẹ mba Ọlọhun yin sọrọ, torinaa, ki ẹnikan ma fi suta kan ọmọnikeji rẹ, ki apakan ma fi ohun rẹ bori ẹnikeji nibi kika Alkurani .12: Bi oorun ba de, dawọ Alkurani kika duro Ojisẹ Ọlọhun sọ pe: Bi ẹnikan ninu yin ba dide lati yan nọfila loru, ti Alkur’ani wa nlọ lẹnu rẹ, débi wipe ko mọ ohun ti o nso lẹnu mọ, ki o yara lọ ọ sun”. Ki o ma baa maa wi iwukiwi lori irun, tabi ki o maa ti aya kan bọ si inu omiran, tabi eyiti o yẹ ki o wikẹhin, ni yoo wi siwaju.13. Sise àkólékàn awọn ti kika rẹ lọla julọ, ki o si maa kaa lọpọlọpọ, Ojisẹ Ọlọhun sọ pe: “Njẹ ẹnikan ninu yin yoo wa kágara (ya ọlẹ) ti kò níí le ka ìdáta Alkur’ani ni òru kan, toripe ẹni to ba ka “kuli huwa llọhu Ahadu” (de ipari) ti ka ìdáta Al-kur’ani”. O tun sọ ni aaye miran: Ẹ sa arayin jọ toripe n o ka idata Alkur’an fun yin. Lẹhinnaa o ka "kul huwa llọhu Ahadu”. 

Nitorinaa, ẹ jẹ ka kọ se ojisẹ Ọlọhun ki a si se amojuto awọn aaya tabi awọn suratu ti o lọla pupọ tẹsan rẹ si jẹ àdìpèlé.Ninu awọn sura tóyẹ ka sojúkòkòrò kika rẹ ni: suratus Sajidatu ati suratul-Insan “Al ata alal insaani …” ninu irun asunba loojọ jimọ ati Tabaaraka ki a too sun lálẹ pẹlu kuli ahusu mejeeji to fi dori ayatul kurisiyyi, ki a too sun lalaalẹ, ati lẹhin irun kọọkan”.14. Ki o ma se ka Alkur’ani ni rùkúù tabi ìforíkanlẹ, toripe ojisẹ Ọlọhun sọ pe: Ẹyin eniyan dajudaju ko si ohun ti o sẹku mọ ninu iro idunnu jijẹ anọbi Ọlọhun tayọ àlá rere ti musulumi yoo maa la, tabi ti wọn yoo la fun-un, ẹ tẹti ẹ gbọmi, dajudaju Ọlọhun kọ kike alkur’ani ni rukuu ati iforikanlẹ fun mi, torinaa, ẹ maa gbe Ọlọhun tobi ni rukuu, ki ẹ si mura si adua lọpọlọpọ nibi iforikanlẹ, ki ẹ si ni igbagbọ pe, Ọlọhun yoo tẹwọ gba adua yin. Afa wa ibnu Taemiyat sọ pe: "rukuu ati sujuud ninu aaye iyẹpẹrẹ ara ẹni nilẹ fọlọhun ko si tọna ki a ke alkur’ani ni awọn aye iyẹpẹrẹ …"15. Ki ẹniti kike Alkur’an ti ko rọrun fun to tun nba isoro pade nibi kika rẹ se suuru, ki o si mura si kika rẹ. Ojisẹ Ọlọhun sọ pe: Ẹniti o jáfáfá nibi kike Alkur’ani yoo maa bẹ pẹlu awọn mọlaika ti wọn jẹ alapọnle, ẹnirere sugbọn, ẹniti o nkaa, ti kika naa sòro fun un, ilọpo meji ni laada rẹ yoo maa jẹ”.16. Sísun ẹkun nigbati a ba nkee, Ọlọhun sọ pe: “Atipe wọn yoo wo lulẹ ni idojubolẹ, wọn a si ma sunkun un (Alkur’ani) yoo lekun (fun) wọn ni ìtẹríba”. Suratul Isirai: 109.

Abdullọhi bun Mosud sọ pe: Ojisẹ Ọlọhun sọ fun mi pe: “Ka Alkur’ani fun mi, (mo si daa lohun pe) n o wa maa ke Alkur’ani fun ọ to se pe irẹ ni Ọlọhun sọ kalẹ fun, ó ní dajudaju mo nifẹ si ki n maa tẹti gbọ lẹnu ẹlomiran, ni mo ba ka suratu Nisai fun un titi ti mo fi debi aya: 41 tọlọhun ti sọ pe: kini ọrọ wọn yoo ti jẹ nigbati a ba mu ẹlẹri jade ninu ijọ kọkan ti Awa si mu iwọ jade ni ẹlẹri lori awọn wọnyi”. Sàdédé ni mo ba ri omije ti o le ròrò loju rẹ, ti o si sọ fun mi pe o tito” Buhari lo gbaa wa.Bẹẹ naa ni Abubakri maa nse ti o ba n ka alkur’ani, iyawa Aisatu sọ pe: “Dajudaju Abubakiri jẹ ọlọkan lilẹ ti ẹkun si maa ngbe ti o ba n ka alkur’ani”. Ninu ẹgbawa miran “ọ je olùkaanu pupọ, debi wipe bi o ba wa ni ibuduro rẹ, kò ní lagbara lati kirun fun awọn eniyan” tori ẹkun rẹ yoo ti pọju... Bẹni Umaru naa, nkirun fun awọn eeyan lọjọ kan ni wọn ba n gbọ ẹkun rẹ, nigbati o ke suratul Yusufu dori ọrọ Ọlọhun to sọ pe: O wipe Ọlọhun nikan ni mo nrojọ ibanujẹ mi ati ironu mi fun”. Suratul Yusuf: 86

Alkọsimu to jẹ ọmọ Abubakiri sọ pe: "mo kọja lẹgbẹẹ Aisat lasiko to nka aya kẹtadinlọgbọn (27) ninu Suratul Turi, ti itumo rẹ lọ bayi pe: "Sugbọn Ọlọhun siju aanu wòwa O si kowa yọ nibi iya ina”.Bẹni Abdullohi bun Abbasi naa sunkun nigbati o ka aya 19 suratul Kọọf: Atipe ipọkaka iku ti de niti otitọ, eyi ni ohun ti o nsa fun”. Bakannaa ni Abdullọhi bun Umaru naa bú gbàmù fẹkun nigbati o ke aya; 284 ninu suratul Bakọrat. “Ti ẹ ba se afihan ohun ti o wa ni ẹmi nyin tabi ẹ fi pamọ, Ọlọhun yoo siro rẹ fun nyin bi ẹ ba se e”.Ẹkun ti wọn ni ki a sun ni ẹkun ipaya Ọlọhun, yatọ si ẹkun munafiki, tabi ẹkun onisekarimi, ojisẹ Ọlọhun sọ pe “Dajudaju ninu awọn ti wọn dara julọ lohun pẹlu kika Alkur’ani ni ẹniti o jẹ pe bi o ba n ka, iwọ gan yoo fura mọ pe o npaya Ọlọhun. 

Ibnu Mojaha lo gbaa wape: "Kosi ohun ti o buru nibi sise bii ẹniti o nsunkun, awọn ẹnirere isiwaju sọ pe “(Bi wọn ba n ka Alkur’ani) ẹ maa sunkun niti ibẹru Ọlọhun bi ẹkun ko ba wa, ẹ se bi ẹniti o nsunkun”. Sugbọn ẹniti o nse bii ẹniti o n sunkun ki awọn eniyan le maa yin-in, munaafiki ni onitọhun o.17. Rironu si ohun ti a nka, Ọlọhun sọ pe:

"كِتَابٌ أَنْزَلْنَاهُ إِلَيْكَ مُبَارَكٌ لِيَدَّبَّرُوا آيَاتِهِ وَلِيَتَذَكَّرَ أُولُو الْأَلْبَاب".“

(Eyi jẹ) tira kan ti a sọkalẹ fun ọ, onibukun, ki nwọn le ronu si awọn ayah Rẹ ati ki awọn ti o ni lakaye le maa ranti )suratu Sọd : 29.

Eniti o nka Alkur’ani gbudọ maa ronu si ọrọ Ọlọhun, ki o si fi titobi Ọlọhun si ẹmi, ki o si maa ronu si ọrọ Ọlọhun, yoo maa kaa ni kika ẹniti o fẹẹ gbọ agbọye ohun ti o nka, ti o si fẹẹ maa mulo, sugbọn ki a ke Alkur’ani pẹlu ahọn ti ko si ẹmi nibi ohun ti eniyan nka, eleyi ko le seso kankan fun ẹniti o nkee. Ọlọhun sọ pe:“Awọn ko ronu nipa Alkur’ani ni abi agadagodo wa lori awọn ọkan wọn ni" Suratul Muhammadu: 24Usaefa sọ pe: Mo kirun lẹhin ojisẹ Ọlọhun ni ọjọ kan, loba dẹnu le fatiha, moni: boya yoo ka ọgọrun ayah yoo dakẹ, loba si n kaa lọ, o pari rẹ tan, loba tun dẹnu le suratu Nisai, loba tun kaa tan, bẹni lotun dẹnu le Al’imrani …. Ti o ba ka aya àfọmọ, yoo se afọmọ fọlọhun, to ba debi ayah itọrọ oore lọdọ Ọlọhun yoo tọrọ rẹ, to ba debi ayah iwasọra, yoo wasọra lọ sọdọ Ọlọhun, lehinnaa, o rukuu”. Nasai lo gbaa wa.

Ojisẹ Ọlọhun tun sọ pe ẹniti o ba pari Alkur’ani lalafo ọjọ meta ko le gbagboye ohun ti o nka. Awọn sahabe maa n gba ayah mẹwa ti wọn ko si ni re kọja sinu ayah mẹwa miran titi wọn yoo fi mọ mẹwa alakọkọ dàadaa, ti wọn yoo si fi maa lo, won sọ pe: awa kọ imọ ati lilo rẹ papọ”.18. Kikee laarin gbigbohun soke ati gbigbe silẹ, lori gbigbe ohùn soke, Ojisẹ Ọlọhun sọ pe: “Ọlọhun ko tẹti gbọ nkankan ri, gẹgẹ bi o se maa ntẹti si anọbi Ọlọhun kan, ti ohun rẹ dara, ti o nfi Alkur’ani kọrin, ti o si nkaa soke”. Ninu adiisi miran, o sọ pe “Olugbohunsoke ka Alkur’ani dabi ẹniti o n yọ saka ni gbangba, ẹniti o si nka Alkur’ani jẹjẹ da gẹgẹ bi ẹniti o nse saara ni jẹjẹ”. Imam Nọwawi sọ pe: "kike Alkur’ani ni jẹjẹ loore pupọ ni gbogbo igbati eniyan ba ti npaya sekarimi, tabi fifi suta kan olukirun kan, tabi ti o le fa ki kika rẹ pakasọ mọ ẹniti o nkirun lọwọ, tabi ti o da oorun mọ ẹniti o sun loju, a jẹ pe nigba naa kike jẹjẹ lore julọ, nigbati kikee soke ni oore ni awọn aaye to yatọ si eleyi, atipe kike soke maa n le esu jinna si ni, o si maa ngbe oorun jinna si ẹniti o nka a. Ko buru ki eeyan kọkọ maa kaa soke, titi yoo fi rẹ ẹ, ti yoo maa waa kaa jẹjẹ, lẹhin ti agbara rẹ ba dọtun tan, ki o maa kee soke lọ.19. Ifọrikanlẹ ti kika Alkuraani, wọn fẹẹ fun ẹniti o nka Alkurani lati forikanlẹ ti o ba debi ayah iforikanlẹ, pẹlu gbolohun “Allahu Akbar.’’ 

Eniyan le ka Alkurani ni ijoko, inaro, lori irin ati idubulẹ, gbogbo rẹ lo lẹtọ. Ọlọhun sọ pe:Awọn ẹniti nranti Ọlọhun ni iduro ati ni ijoko ati idubulẹ wọn, ti nwọn nronu nipa seda ọrun ati ilẹ “suratu Alimran 191.Eyiti o dara julọ ni ki o joko pẹlu Ọlọhun lẹniti yoo doju kọ kibula.20. Ki o ma ke e tan laarin ọjọ ti ko pe mẹta tori adisi ti ojisẹ Ọlọhun fi kọ sise bẹẹ.

Too, ẹyin ẹrusin Ọlọhun, o jẹ ohun to se ni laanu pe ọpọ ẹda lo ti kairoju nipa kike Alkurani, awọn agba kairoju pẹlu aye, nigbati ile iwe kosi jẹki awọn ọmọde raye fun ọrọ Ọlọhun ọpọ ile iwe ti wọn nkekọ Alkurani ni o jẹ pe akoko perete ni wọn fi silẹ fun un, ko si amojuto to muna doko fun ọrọ Ọlọhun, dipo eleyi ọrọ bọọlu ni ọpọ ọmọ ati obi to fi dori alagbatọ n mojuto. Eleyi gan ni gbajare ti Ojisẹ Ọlọhun ke lọ si ọdọ Ọlọhun rẹ. Wo Suratul Furkonu: 30.O di dandan, lati yan afa Kan pato ti yoo kọni lẹkọ kika Alkurani, kii se pe o kan maa ka Alkurani lalaini afa kan pato, to mọ tifun tẹdọ ofin ati ilana kika Alkurani. 

Ojuse ẹniti o fẹẹ mọ Alkurani ka ni ki o sẹsa onimimọ ti o mọ Alkurani ka daada fun ara rẹ tabi fun awọn ọmọ rẹ ki wọn le mọọ ka daada. Botilẹ jẹpe a ri awọn ajọ to nse taafisi, sugbọn ti awọn olukọ wọn kódàngajia to. Kódà ọpọ awọn ọmọ naa ni wọn koni alamojuto, Bẹni ọpọ obi nfi ọmọ sile keu lalaini ra tira tabi se koriya fun afa to nkọ wọn tofa ki ọpọ ọmọ keu maa gbe igbá báárà kaa kiri, to nfa ki elomiran ma fẹ fi ọmọ rẹ sile keu. Gbogbo iwa wonyii lo n fa ki awon ọta Isilaamu maa wẹnu si musulumi lara. 

Toba ri bẹẹ, o se pataki ki awọn alasẹ ji giri si ọrọ yii.

Nipari, ẹyin ẹrusin Ọlọhun, ẹ jẹka mojuto tira Ọlọhun ni kikọ ati ni kika, ki a si maa ronu si ọrọ inu rẹ, pẹlu ipaya Ọlọhun, Ojisẹ Ọlọhun sọ pe: "ẹniti o ba ke arafi kan ninu tira Ọlọhun (Alkuranu) yoo ni laada pe o se daada kan. Daada kan lọdo Ọlọhun yoo maa wa nipo mẹwa. N o sọ pe (Alif lam mim) aya kan ni, sugbọn (alif) arafi kan ni, (lami) arafi kan ni (mim) arafi kan ni, a jẹ pe ẹni ba sọ (Alifu lam mimu) ọgbọn laada ni onitọhun ti fi sefajẹ torinaa, ẹ maa ke Alkurani.

فاتقوا الله- عباد الله – واهتموا بكناب الله تلاوة وتدبّرا وعملا أعوذ بالله من الشيطان الرجيم : إن الذين يتلون كتاب الله وأقاموا الصلّواة وأنفقوا مما رزقناهم " (فاطر 29) الآيات ..... إلى قوله " إنه غفور شكور" ( فاطر 30 ).

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Thursday, June 18 @ 07:25:00 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin:
Oorun didun igi ododo ti orewa nipa ajulo awon iya awon olugbagbo ododo


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Alaiye Esin - Ibere Ati Idahun Imo Esin



"Kike Alkur'an Ati Awon Eko Re: Alaye Ola (Esan) kike AlKur'an Alaponle" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com