Gbagede Yoruba
 



WIWA MIMO ATI KI A SI LO IMO TI A BA KO
 
Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun
Lati Ori Minbari Yoruba

WIWA MIMỌ ATI KI A SI LO IMỌ TI A BA KỌ

1- Ipeni si akiyesi lati wa mimọ ti o wulo.
2- Irani leti awọn ẹkọ ti o wa fun wiwa mimọ.
3- Pipe fun sise atunse ilana ẹkọ

Wiwa mimọ jẹ ohun ti Isilaamu kakun babara fun musulumi, ni kika ati kikọ. A o ranti akọkọ ohun ti o sọ kalẹ fun Annabi Muhammad (r) ni ayah ti o sọ Pataki imọ

قوله تعالى:" اقرأ باسم ربك الذي خلق. خلق الإنسان من علق. اقرأ وربك الأكرم. الذي علم بالقلم. علم الإنسان ما لم يعلم".

" maa ka pẹlu orukọ Ọlọhun rẹ, ẹni ti o da ẹda, o fi ẹjẹ didi da eniyan. Maa ka atipe Oluwa rẹ ni Alabunkun julọ ẹni ti o fi kọlamu kọ ni lẹkọ. o kọ eniyan ni ohun ti ko mọ tẹlẹ Suratul Alak: 1-5.

Dandan ni ki Musulumi wa mimọ ki o to maa fi se isẹ. Oluwa sọ wipe



"فاعلم أنه لا إله إلا الله
قال الإمام البخاري: "العلم قبل القول والعمل لقول الله تعالى فبدأ بالعلم وأن العلماء هم ورثة الأنبياء ورثوا العلم من أخذه أخذ بحظ وافر. ومن سلك طريقا يطلب به علما سهل الله له طريقا إلى الجنة". وقال تعالى:"إنما يخشى الله من عباده العلماء". سورة فاطر : 28
وقال:"وما يعقلها إلا العالمون". وقال:"وقالوا لو كنا نسمع أو نعقل ما كنا في أصحاب السعير". وقال:"هل يستوي الذين يعلمون والذين لا يعلمون". وقال النبي:"من يرد الله به خيرا يفقهه في الدين". و قال أبوالدرداء:"إنما العلم بالتعلم".

قال الله تعالى:"يرفع الله الذين آمنوا منكم و الذين آوتوا العلم درجات"

"Lọọ mọ pe ko si ọba kan ayafi Ọlọhun wiwa mimọ ni Ọlọhun fi bẹrẹ, bakannaa o tun jẹ ki a mọ wipe: awọn onimimọ ni wọn yoo jogun Annabi Ọlọhun, wọn jogun lilo imọ, ẹni ti o ba ni imọ ni ọwọ rẹ tẹ ohun Pataki, ẹni ti o ba tọ ọna kan ti o fẹẹ fi wa imọ; Oluwa yoo see ni irọrun fun iru ẹni bẹẹ ọna ti iru ẹni bẹẹ yoo tọ lọ si Al-jannah. Oluwa sọ wipe.  Dajudaju awọn ti wọn npaya Ọlọhun ju laarin awọn ẹru Ọlọhun ni awọn ọni mimọ Suratu Faatir :28.

Oluwa tun sọ wipe: " ẹni ti yo gbọ ọrọ naa ye ni awọn ọni-mimọ� Oluwa sọ wipe: "Njẹ o se dọgbadọgba bi ? ẹni ti o ni mimọ ati ẹni ti ko ni imọ Annabi Muhammad (r) sọ wipe, ẹni ti Ọlọhun ba ro daradara ro yoo jẹ ki o gbọ agbọye ẹsin. Abu Dardaa. sọ wipe: Dajudaju imọ jẹ ohun ti a ma nwa. Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ wipe : "Ọlọhun se agbega fun awọn ti wọn gba Ọlọhun gbọ ninu yin ati awọn ti wọn ni imọ Ọlọhun fun wọn ni ipo.

Annabi Muhammad (r) sọ wipe:

عن عبد الله بن مسعود - قال: قال رسول الله:" لا حسد إلا في اثنتين: رجل آتاه الله مالا فسلطه على هلكته في الحق، ورجل آتاه الله حكمةً فهو يقضي بها ويُعلّمها"- أخرجه البخاري.

A kii jowu eniyan ayafi fun nkan meji:

ẹni ti Ọlọhun fun ni owo ti o si nna si ọna ododo ati ẹni ti Ọlọhun fun ni ọgbọn ti o si nloo si ọna ti Ọlọhun, ti o si nkọ ẹlomiran naa. Bukhari lo gbaa wa.

Annabi Muhammad (r) sọ wipe:

عن أبي موسى الأشعري عن النبي قال:"مثل ما بعثني الله به من الهدى والعلم كمثل غيث أصاب أرضًا فكان منها طائفة طيبة، قبلت الماء، فأنبتت الكلأ والعُشب الكثير، وكان منها أجادب أمسكت الماء، فنفع الله بها الناس فشربوا وسقوا وزرعوا، وأصاب طائفة أخرى إنما هي قيعان لا تُمسك ماء ولا تنبت كلأ فذلك مثل من فقُُه في دين الله ونفعهُ ما بعثني الله به، فعلم وعلم، ومثل من لم يرفع بذلك رأسًا ، ولم يقبل هُدى الله الذي أرسلتُ به"_ أخرجه البخاري.

Apejuwe ohun ti Ọlọhun gbe mi dide le lori ni ọnaamọ ati wiwa imọ da gẹgẹ bii ojo ti o rọ si orilẹ, ilẹ miran dara o gba omi duro, o si hu onjẹ ẹran ati koriko ti o pọ, omiran si da si asalẹ o mu omi duro, Ọlọhun si se ni anfani fun awọn eniyan, wọn mun, wọn da si oko, o si hu irugbin, ni igba ti ẹlẹẹkẹta bọ si ilẹ okoo ko gba omi duro, ko si hu koriko. Gbogbo eleyi jẹ apejuwe ẹni ti o gbọ agbọye ẹsin Ọlọhun, ti ohun ti Ọlọhun titori rẹ ran mi nisẹ si se anfani fun un , o kọ ẹkọ o si tun kọ elomiran, bẹẹ naa ni apejuwe eniyan ti ko gbe ori soke lati se anfani ninu rẹ , ti ko si gba imọna Ọlọhun eyi ti o fi ran emi Annabi Bukhari lo gbaa wa.

Annabi tun sọ ninu ọrọ miran wipe:

وقال النبي:"يستغفر لطالب العلم كل شئ حتى الحيتان في البحر". إن الأنبياء لم يورِّثوا دينارًا ولا درهمًا وإنما ورّثوا العلم، فمن أخذه أخذ بحظ وافر"- أخرجه أبو داود.

"Gbogbo nkan ni o maa nwa aforijin fun ẹni ti o nwa imọ, titi ti o fi de ori ẹja ti o wa ninu odo. Dajudaju awọn Annabi Ọlọhun ko fi ogun Dinnari tabi Dirihamu kalẹ, sugbọn wọn fi imọ silẹ bii ogun ẹni ti o imọ ni o ri ohun ti o Pataki mu."

Awọn nkan ti o yẹ ki o pe lara ẹni ti o jẹ oni mimọ ni ki o ni Al-Ikhlaas- sise nkan nitori ti Ọlọhun .Ọlọhun sọ wipe:

قال تعالى:"و ما أمروا إلا ليعبدوا الله مخلصين له الدين".

"Gbogbo ohun ti a payin lasẹ ki ẹ se nitori ki ẹ le se wọn lati fi jọsin fun Ọlọhun ni, ki ẹ si se wọn pẹlu (Ikhlaas) tori ti Ọlọhun ni kan"

Annabi Muhammad (r) sọ wipe :

ويروى عن النبي قال:" رسول الله:"من تعلم علمًا يبتغي به وجه الله - عز وجل - لا يتعلمه إلا ليصيب به عرضًا من الدنيا لم يجد عرف الجنة يوم القيامة".

"ẹni ba wa mimọ eyi ti a ma fi nwa oju rere Ọlọhun, ti ẹni naa si wa nitori lati fi wa ohun aye yii, iru ẹnibẹẹ ko nii gbọ oorun Aljanna ni ọjọ Alkiyamah.

Annabi Muhammad (r) tun sọ wipe:

قال:"القرآن حجة لك أو عليك"- أخرجه مسلم.

" Al-kura'n jẹ ẹri ti yoo gbe ọ, tabi eyi ti yoo se atako fun ọ� Muslim logbaa wa.

Imam Ahmad sọ wipe:

قال الإمام أحمد:"العلم لا يعدله شيء لمن صحت نيته. قالوا: كيف ذلك ؟ قال: ينوي رفع الجهل عن نفسه وعن غيره".

Ko si ohun kan ti o se dọgba imọ fun ẹni ti aniyan (ero ọkan) rẹ ba dara; wọn si beere pe kini o fa ti o fi ri bẹ? o si sọ wipe : tori pe o wa ni ọkan rẹ lati fi gbe aimakan kuro fun ara rẹ ati kuro fun ẹlomiran naa.

gbogbo eleyi njẹ ẹri lori wipe ki a wa mimọ titori Ọlọhun, ki a si mọ wipe Ọlọhun yoo bere lọwọ wa nipa imọ ti a mọ.

Nini imọ jẹ ẹri wipe igbagbọ (Iman) wa ni ọkan iru ẹni bẹẹ; eleyi ni o le mu wa de ipo asiwaju awọn eniyan, yala asiwaju ti ẹsin ni (Iman) tabi asiwaju ti aye. Oluwa sọ wipe:

قول الله تعالى:"فاعلم أنه لا إله إلا الله، و استغفر لذنبك".

"Mọ wipe ko si ọba kan ti o lẹtọ lati jọsin fun ayafi Ọlọhun Allah ki o si wa aforijin fun ẹsẹ rẹ�.

Ki ẹni ti o nwa imọ mọ Pataki ohun ti o nse tori pe Amanah ni, ikilọ ni ati fifọn mimọ ka fun ẹlomiran naa ni pẹlu. Annabi Muhammad (r) sọ wipe:

" من دعا إلى هدى كان له من الأجر مثل أجور من تبعه، إلى يوم القيامة لا ينقص ذلك من أجورهم شيئًا".

"ẹni ti o ba n peni si ọju ọna Isilaamu kan; iru ẹni bẹẹ yoo maa gba laada deede iru lada ẹni ti o ba nlo imọ naa titi di ọjọ Al-kiyamah, lai ni di laada ẹni ti o ba n lo iru imọ bẹẹ ku.


Ẹyin ẹrusin Ọlọhun, Isilaamu fẹ ki a wa imọ ti a o fi gbe aye yii , gẹgẹ bi o se se wiwa imọ ẹsin ni dandan . Eleyi ko tako ẹsin tori pe Annabi Muhammad (r) sọ wipe:

قول النبي في حديث تأبير النخل:"أنتم أعلم بشؤون دنياكم- أخرجه مسلم.

أمثلة من العلماء أمثال ابن الهيثم، و ابن رشد الحفيد و غيرهم ممن طوروا العلوم التجريبية

" ẹyin ni ẹ mọ nipa eto igbesi aye yin julọ Muslim lo gba a wa Annabi sọ eleyi ni asiko ti o sọ ọrọ nipa bi eso dabidun se le hu daradara.

eleyi ni awọn oni mimọ musulumi akọkọ gbọye gẹgẹ bi Ibnu Haisama ati Ibnu Rusdi Al-Hafeed ati awọn miran fi gbe ohun orisirisi se, ti wọn si fakọyọ ni orisirisi agbegbe imọ ti aye fi n se anfani titi di oni yi.

Awọn ilana eto ẹkọ wa loni yii ti bajẹ kọja afẹnusọ ẹkọ ti ko yi ọmọ akẹkọ pada si daradara, o yẹ ni ohun amojuto. Awọn ohun ti a nkọ awọn akẹkọ lọpọlọpọ ko ni nkan se pẹlu wọn loni.

Ninu awọn mimọ ti o yẹ ki ijọba wa se akoleya rẹ ni ki a pa aimọkan rẹ, ki a se akolekan ẹkọ awọn obinrin ni ibamu si ọrọ Annabi Muhammad (r) ti ọ sọ fun sifau bint Abdullah nipa Hafsah:

قول النبي لشفاء بنت عبد الله في شأن حفصة:"الا تعلميها رقية النمل، كما علمتيها الكتابة"- أخرجه أبو داود.

"Ki o kọ ni adua ti yoo ma se gẹgẹ bi o ti se ti kọ ni mimọ kọọ Abu Dawud lo gba Hadiisi yii wa.

Annabi tun sọ wipe:

و قول النبي أيضا:"إذا مات الإنسان انقطع عمله إلا من ثلاث: صدقة جارية أو علم ينتفع به أو ولد صالح يدعو له".

"Ti ọmọ eniyan ba ti ku , ko ni gba lada Kankan mọ ayafi nipa nkan mẹta: sara ọlọjọ pipẹ ti o ba se kalẹ , imọ ti awọn eniyan ba nse anfani ni ibẹ, abi ọmọ daradara ti o nse adua fun obi rẹ, Bakannaa o yẹ ki ijọba se ọrisirisi idani -lẹkọ fun awọn eniyan."

هذا، قال الله تعالى : "إن الله يأمر بالعدل والإحسان وإيتاء ذي القربى وينهى عن الفحشاء والمنكر والبغي يعظكم لعلكم تذكرون "
اللَّهُمَّ لاَ تَدَعْ لَنَا فِي مَقَامِنَا هَذَا ذَنْبًا إِلاَّ غَفَرْتَه، وَلاَ دَيْناً إِلاَّ قَضَيْتَه، وَلاَ مَرِيضاً إِلاَّ شَفَيْتَه، وَلاَ مُسَافِراً إِلاَّ رَجَعْتَه وَلاَ ضَالاًّ إِلاَّ هَدَيْتَه وَلاَ دَاعِيًا فِي سَبِيلِكَ إِلاَّ وَفَقْتَه، وَلاَ حَاجَةً مِنْ حَوَائِجِ الدُّنْيَا وَالآخِرَةِ هِيَ لَكَ فِيهَا رِضَا وَلَنَا فِيهَا صَلاَح إِلاَّ قَضَيْتَهَا وَيَسَّرْتَهَا لَنَا يَا رَبَّ الْعَالَمِين.

رَبَّنَا هَبْ لَنَا مِنْ لَدُنْكَ رَحْمَةً وَهَيِّئْ لَنَا مِنْ أَمْرِنَا رَشَدا. رَبَّنَا هَبْ لَنَا مِنْ أَزْوَاجِنَا وَذُرِيَاِتنَا قُرَةً أَعْيُنٍ وَاجْعَلْنَا لِلَمُتَقِينَ إِمَامًا.

رَبَّنَا آتِنَا فِي الدُّنْيَا حَسَنَةً وَفِي الأَخِرَةِ حَسَنَةً وَقِنَا عَذَابَ النَّارِ


 Posted By Ifiranse Eleyi Je Wednesday, October 14 @ 17:30:02 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun:
Onka Yoruba - Numbers In Yoruba: Figures And Counting, Kika Ni Yoruba Computes


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun



"WIWA MIMO ATI KI A SI LO IMO TI A BA KO" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com