Gbagede Yoruba
 



Buhari Ja Fun Fulani Ri, Lojo Wo Lawon Oloselu Tiwa Fee Ja Fun Wa?
 
Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu Lati Owo Akoroyin Olootu

Buhari Ja Fun Fulani Ri, Lojo Wo Lawon Oloselu Tiwa Fee Ja Fun Wa?

Lori oro awon Fulani ti won ji Olu Falae gbe ni mo si wa, n ko ti i le menu kuro nibe nitori awon ohun to tun n sele si i. E wo o, oro to wa nile yii ki i se oro esin o, n ko si fe ka gba a si oro esin rara. Fulani yato si musulumi, bee ni ki i se gbogbo eni ti won bi si ile Larubawa lo n se Islaamu, oto ni esin, oto ni iran eni. Bakan naa ni oro yii ki i se oro oselu.

O n dun mi gan-an fun awon eeyan ti won n fi oro awon Fulani to fee fi ogun di wa mo inu ile tiwa yii se oro oselu, nitori bi oselu ba fo won loju loni-in, bi wahala oro naa ba sele, won ko ni i wa laye lati se oselu, iru awon ti won ba si n dite mo eya won bayii ni yoo koko ba ogun naa lo. Bi kinni ohun ba sele loooto, ko ni i si oselu kan ti yoo see se nile yii, bee ni enikan ko ni roju raaye se musulumi tabi kristeni paapaa, sebi ibi ti alaafia ba wa ni won ti n fokanbale se esin, awon ti ogun n le ki i raaye duro ko ijo jo.

Awon ohun meji ti awon alagbara aye fi n mu awa mekunnu, ti won si fi n koyin ara wa si ara wa loro oselu ati oro esin, iyen leyin ti won ba ti fi ise ati osi ta wa tan, ti won si ri i pe a ko ri ounje je, a ko rowo fi ra aso tabi to awon omo wa debi to ye. Igba yii ni won yoo fi oro esin si i, e oo ri enikan ti yoo pe ara re ni musulumi, ti yoo ni ija Anobi tabi ija Olorun loun n gbe, ti yoo yo obe, ti yoo maa fi dunbu eda egbe re, bi won ba si dunbu won tan, won yoo ji eru won ko lo. Se esin Olorun kan le mu eeyan se iru iyen ni. Tabi ki won gba ibi oro oselu, eleyii naa buru gidi. Aanu awon odo ati awon omode oni si se mi nidii eyi gan-an.

Won ko ni i je ki o soro ki won too mu o bu, oro ti won ko modi, iro ti won pa fun won, oro ti ko ye won rara ni won yoo tori re bo aso sile, won yoo ni awon yoo se o lese, tabi ki won ni eni ti o n soro si yen, oloore awon ni, nitori eerun owo ti won n fun won, tabi iro ti won ti pa fun won.

Bi e ba ri oro buruku ti awon mi-in ko ranse si mi lori oro Olu yii, enu a ya yin pe se omo Yoruba le ronu bee yen. Awon mi-in ni bawo ni Olu Falae se mo pe awon Fulani lo ji oun gbe, awon mi-in ni Olorun lo mu un, nitori owo to gba lowo Jonathan, awon kan si dide, won ni Olorun lo n fiya je awon baba Afenifere, koda enikan so pe Afenifeya ni won, won ki i se Afenifere. Bi e ba beere lowo awon to n so bayii, pupo ninu won ko mo nnkan kan ju iro ti won n pa fun won lo, ati ariwo buruku ti won n gbo lori redio lenu awon ti won fee ba awon baba yii loruko je loju omo Yoruba gbogbo. Eyi ti awon eeyan tiwa n so, oro omugo ti awon ti won n pe ara won ni asaaju oloselu wa loni-in n gbe kiri, oro yii ni Egbe omo Fulani ile Yoruba gun le, oun ni won se pe gbogbo Yoruba lobo, ti won ni awon ti won ji Olu gbe ko le je Fulani, nitori Fulani kan ko le fi eran re sile ko maa ji eeyan gbe kiri.

A dupe bayii pe awon olopaa ti ri awon ti won ji Olu gbe. Ariwo tawon agbaagba Yoruba tawon oloselu wa ko fee ri pa lo je ki Buhari pase fogaa olopaa pe won gbodo wa awon odaran yii jade. Won ri won mu, won si fi won han aye pelu owo ti won ba lowo won. Lati ojo ti won si ti mu won, egbe awon Fulani ko le soro mo, awon alakooba oponu omo Yoruba ti won n so pe iro ni Olu n pa naa si sa lo, won gbe enu won dake. Idi ni pe nigba ti won ri awon omo ale naa mu, ko si Ogundele, Kumapayi tabi oruko omo Yoruba kan ninu won, Fulani ni won gege bi Olu Falae ti fenu ara re so tele. Omo Fulani ada-maalu ni gbogbo won, won ko si lo sibi ise maalu nijo naa, ise ajinigbe ni won fi ojo ohun se. Bee enu egbe awon Fulani eleran yii ko ni i gba iru oro ti won so yii, ati iro banta banta ti won waa gbe fun gbogbo aye, bi ko ba si ohun to n ti enu awon oloselu ile Yoruba tiwa jade.

Bi awon oloselu tiwa ti i se ree, awon ni won n so pe a ko je kinni kan loju awon eya mi-in, eyi lawon atohunrinwa si se n fee maa se wa sikasika. Awa ti a n soro, ti a n fi gbogbo igba bu awon oloselu ile Yoruba yii, ki i kuku se pe bee naa ni ilara wa po to, tabi pe bee naa la ko feran awon omode eyin wa to. Ohun to n run wa ninu ko ju bi won ti n se oselu tiwon lo:

oselu to n fabuku kan Yoruba, oselu ti won fi fee ta wa si oko eru, oselu ti iya buruku yoo fi je awon omo wa leyin ola lorile-ede Naijiria to ye ko je ile baba won. Ohun to n dun wa ju ree, oro naa ni ko si ye awon omoleyin wa. Ninu awon ti won ko leta si mi lose yii, enikan te atejise kan to dun mo mi pupo, nitori o ba oro ti mo so yii mu. O ni ki la n bu awon Fulani fun, sebi awon oloselu wa lo fa a fun wa, nitori bi awa ti n se oselu wa nile Yoruba ko dara. Ohun ti eni naa n beere gan-an ni pe ki lawon oloselu tiwa n se fun wa gan-an?

O ni lodun 2001 ti a n soro pe Buhari lo sodo Lam Adesina n'Ibadan, sebi Buhari mo pe oun fee se oselu, o si mo pe oun fee di ipo aare, sugbon ko tori iyen ko ma ja fawon eeyan tire, o dide, o lo sodo awon ti won n sejoba Oyo, o si so ohun ti won ni won n se fawon Fulani Oke-Ogun ti ko dara. Bee ni Buhari ko da lo sibe, o mu gomina atijo kan dani, o tun mun tuntun mi-in dani, o di won meru lo. Bee bo ba je awon oloselu tiwa ti n se ni, ti Buhari yii fe ki won dibo foun nile Yoruba tabi ki won fun oun ni ipo gidi kan laye ijoba Obasanjo, ko ni i lo sibe, yoo maa wo awon eeyan re niran ti iya yoo fi maa je won naa ni. Ohun tawon oloselu tiwa n se fun wa niyen. Bi a ba n so pe awon ni won ta wa fun Fulani, ti a si n binu, bi iru oro bayii ba sele, ti Bola saaju, ti Bisi elerin-in-eye tele e, ti won mu gomina kan tabi meji dani, nje iru awa yii yoo lenu lati bu won.

A ko ni i le bu won nitori bi won gba odo Buhari tabi Oba Sokoto lo, ti won ni awon ko ba toro oselu wa, iya to n je awon eeyan awon lawon tori e jade, ki won pe awon omo won ti won n daran nile Yoruba, ki won ti owo omo won bo aso. Se bo je Buhari tabi Sultan, tabi gomina tabi oba kan ni won loo ba ti won so bee fun ni ile Hausa, se tohun yoo so pe oun ko gbo ni. Sugbon oro ibo, oro eni to mo ogbon oselu julo, oro bi awon eeyan won yoo se je gomina, ti won yoo je minista, iyen ni won yoo maa le kiri, ti won yoo maa tori e bu awon agbaagba ile won. Bee ki i se pe gbogbo ipo ti won n gba yii naa, won fi mu anfaani kan ba Yoruba, tara won nikan naa ni. Bi Buhari ba le ja fun awon Fulani nile Yoruba lodun meeedogun seyin, ki lo de ti awon oloselu tiwa ko le ja fun wa? Ki lo de to je gbogbo awon ti won ba fee ja fun wa ni won yoo maa pe loruko buruku, ti won yoo maa de awon omo won si won lati bu won?

Ohun ti mo se so pe oro to wa nile yii ki i se oro oselu tabi ti esin rara niyen, oro to kan Yoruba ni, nitori ohun to le gbe Yoruba mi, tabi ti yoo kuku so won dero eyin ni Naijiria titi aye ni. Awon Fulani ti gbile nile Yoruba bayii, bee la o ri nnkan kan se fun won nitori enu awon Seriki Hausa nile Yoruba tole ninu ijoba Abuja ju awon oba tiwa lo, ko si si awon oloselu odo tiwa nibi to mo eto ti won le se lati gba wa lowo Fulani tabi ti ogun won ba de. Oro to si wa nile yii ko see da nikan se, afi ki awon ti won je gomina wa, awon ti won lagbara nidii oselu, awon ti won n lo si Abuja bo bii Obasanjo da si i. Oto ni igba ti awon Fulani je darandaran lasanlasan, ti eru ba won ti won ko le koju awon onile tabi omo oniluu, ese won ti rinle, won ti gbile, won ti bimo, awon omo won ti dagba, awon ara Oro-Ago, ati agbegbe mi-in ni Ifelodun, ni Kwara, ko le da lo soko mo, bee ni apa awon ilu kan l'Oke-Ogun, bee ni ona esipireesi Ibadan si Eko ati opo awon ilu ni ipinle Ogun, awon Fulani ti ka won mo gidigidi.

Gbogbo wa naa loro yii kan, mo si n ke to o. Bo ba sele, yoo buru ju ba a ti se ro o lo. Kin ni eni kookan wa gege bii omo Yoruba le se? E je ka maa ba oro naa bo lose to n bo.

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Friday, April 29 @ 01:59:57 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu:
Ojo Buruku, Esu Gbomimu L'ojo Ti Won Pariwo "Ole" Le Awolowo Lori


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu



"Buhari Ja Fun Fulani Ri, Lojo Wo Lawon Oloselu Tiwa Fee Ja Fun Wa?" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com