Gbagede Yoruba
 



Afi Ki Buhari Gba Wa Lowo Awon Onise-ina Yii o
 
Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo Lati Owo Akoroyin Olootu

Afi Ki Buhari Gba Wa Lowo Awon Onise-ina Yii o

Nigba ti Buhari de, ti awon eeyan yii bere si i fun wa ni ina ijoba, ti ina n tan yaa yoo, gbogbo ilu lo n kan saara si won o, nise ni won n so pe won ti gbe eje Buhari wonu ara won, ise won ti yato, ki kaluku maa lo ina lo lo ku. N lawon eeyan ba n gbalu ti won n jo, afi bo si se di enu ojo meta yii ti nnkan yipada, to tun pada si tatijo, to si tile tun fee buru ju ti atijo lo lawon ibomi-in. 

Bi ko ba waa si ina mo, bi awon onise monamona ba tun masinni won se tabi ti won n wa ohun to ba je lati tunse, sebi gbogbo ilu naa ni yoo fi ara mo on ti a oo si maa reti igba ti ina ohun ba de. 

Ewo waa ni eyi ti awon araabi yii tun gbe de yii o, ko ma si ina, ki gbogbo ilu wa ninu ookun, ko waa je asiko naa ni awon onina yii yoo ni ki gbogbo araalu maa waa san owo ina ti won ko lo, ti won yoo si ni awon fi owo kun owo ina sisan.


Nijo wo ni Naijiria yoo bo ninu nnkan bayii, nijo wo ni awon alagbara ilu yii yoo sinmi a n ni mekunnu lara. Nigba ti ki i se oran, sebi bi e ko ba fun araalu ni ina lo, won ko kuku le pe yin lejo tabi ki won mu yin si i, ewo waa ni ki eyin tun maa gba alekun owo, owo oran lowo awon ti won ko lo ina, owo tipatipa lowo awon araalu ti won ko ni enikan, afi Olorun Oba.

Ohun to se ye ki ijoba yii gba wa ree o, ki Buhari gba wa lowo awon onise-ina yii, bi won ba fee fi owo kun owo ina, ki won koko fun araalu ni ina daadaa na, bi awon eeyan ba lo ina daadaa, ko ni i nira fun won lati sanwo ina ti won ba lo. Sugbon ki eeyan maa sanwo oja ti ko ra, ko maa sanwo ohun ti ko lo, haa, ireje nla ma ni, Olorun ko fe e o. Oodua paapaa ko feru e, afaimo kawon irunmole to nile yii ma doju ija ko awon onimonamona. Olorun paapaa yoo mu gbogbo arenije o jare.

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Friday, April 29 @ 04:31:55 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo:
Yoruba Greetings, (Middle) Names In Yoruba Language With Titles Of Obas (Kings)


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo



"Afi Ki Buhari Gba Wa Lowo Awon Onise-ina Yii o" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com