Gbagede Yoruba
 



Nitori Bi Won Ko Se Rowo Osu Gba, Awon Osise Di Onibaara Nipinle Oyo
 
Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere Lati Owo Olawale Ajao, Ibadan

Nitori Bi Won Ko Se Rowo Osu Gba, Awon Osise Di Onibaara Nipinle Oyo

Lojo Isegun, Tusde, ose to koja, awon osise ofiisi gomina meta kan n dogbon ba iya to n ta nnkan mimu elerindodo soro nibi abe ibooji kan ninu ogba sekiteriati ijoba ipinle Oyo lati ta nnkan mimu tutu fun won lawin. Ko jo pe kinni ohun paapaa lo n wu won i mu, won fee mu un lati saa ri nnkan fi sinu ni. Sugbon gbogbo aroye awon okunrin ohun ni ko wo iya oni miniraasi leti, o ni awin toun ta ti to gee, keni kan ma da oun ni gbese ni toun.

''E saa mo pe ki i sejo tiwa naa. Gbogbo wa la mo bi ilu se ri. A ni lati jo maa wo o se funra wa naa ni. Obinrin ti mo maa n gba ounje (ounje tutu bii iresi, ewa ati bee bee lo) awin lowo e nile ti mo mi, o mo pe ti mo ba ti gbowo ni mo maa setu oun. Oloun n bo asiri ounje ati maa ri owo wo moto wa sofiisi naa nisoro.'' Oro ti okan ninu awon okunrin naa so niyi nibi ti won ti n saroye nipa owo-osu tijoba Seneto Abiola Ajimobi je won. Eyi ni ohun ti ai ri owo-osu gba so awon osise ijoba ipinle yii da. Pupo ninu won lo ti fee di ala;gbe (onibaara) tan nitori won n se fainbara lati rowo woko pada sile lati ibi ise, lati jeun ati lati gbo awon bukaata peepeepe mi-in.

Nibi ti oda owo da awon eeyan yii de, to je pe agbara kaka ni opo fi n ri owo wo moto lo sibi ise, iyokuyo ni won n yo owo oja nitori won n fe fi iwonba owo ti won ba ni lowo ra nnkan to po. Bi elomi-in ninu won ba si fee woko tabi gun okada to ba yo owo irinse bayii, awako tabi olokada yoo si fee le binu gba elomi-in loju.

Gege bi iwadii Iwe Iroyin Yoruba se fidi e mule, osise tijoba je lowo to kere julo ni won je lowoosu meta. Awon ti won wa nipele kin-in-ni si ikefa lenu ise ijoba ni won ti ri owo-osu kokanla, odun to koja gba. Awon wonyi ni won je lowo-osu meta pere, iyen osu kejila, odun to koja pelu osu kin-in-ni ati ikeji, odun yii. Latinu osu kewaa lawon ti won wa ni ipele keje de ipele kejidinlogun ti ri owo gba gbeyin. Sugbon gbogbo awon osise to je ti ileese ijoba nipinle naa bii ileese igbohun-safefe, awon osise ileewosan ijoba, ileese olomi ero ati bee bee lo ko ti i ri owo-osu kokanla gba, bere latori awon onipele kin-in-ni dori awon oga patapata.

Lara awon osise ileese to je tijoba ipinle Oyo ni awon elere idaraya nipinle ohun. Lopin osu keta ta a wa yii ni yoo di owo-osu karun-un tijoba je won. Yato si pe owo ti agbaboolu kookan ninu egbe agbaboolu 3SC n gba je okan ninu awon to n gba owo to kere si ti opolopo awon akegbe won kaakiri orile-ede yii, owo-osu merin tijoba ti je won ko fun won lanfaani lati maa ri ounje gidi je, ati lati maa ri okun to peye se igbaradi lati koju awon akegbe won ninu ifesewonse won gbogbo pelu bo se je pe gaari ati epa lo ku ti opolopo won saaba fi n se ounje lojoojumo bayii.

''E wo o, ki n ma tan yin, gbogbo wa ni nnkan le fun lasiko yii nitori latinu osu kewaa la ti ri owo gba gbeyin. Awon ounje ti ko ye ki n maa je gege bii agbaboolu lemi ti mo n ba yin soro yii n je, kiki awon ounje amunukun bii gaari, eba, amala ati fufu ni mo n je nitori ko sowo lati je ounje gidi to ba wu ni lowo mi. Bo si se n sele si gbogbo wa niyen. Ko si owo, e jowo, Iwe Iroyin Yoruba, e ba wa be ijoba ki won fi wa sokan, ebi n pa wa ku lo≈. Okan ninu awon omo egbe agbaboolu ipinle Oyo lo se bayii soro lasiko ti akoroyin wa n forowero pelu re n'Ibadan.

Akoroyin wa de ibudo asa, nileese ipinle Oyo to n samojuto oro asa ati ise Yoruba ti won n pe ni 'Oyo State Council of Arts and Culture' lede oyinbo, ekun lo ku ti okan ninu awon osise ibe to ba wa soro ko maa sun. O ni atije atimu ti di nnkan foun ati ebi oun bayii, gbogbo awon omo oun to si wa nileese loun ko ri owo ekose won san.

Okunrin naa so siwaju, o ni, ''Iwe Iroyin Yoruba, nnkan ko ti i buru fun mi to bayii ri. Gbogbo nnkan ti mo ba nilo bayii ni mi o rowo ra mo to je awin ni mo n gba ounje atawon nnkan mi in to se pataki si mi. Owo ti mo fi n wo moto wa sibi ise paapaa, yiya ni mo maa n ya a. Se e mo pe eka eto oro-aje gbogbo Naijiria ni aisedeede yii ti de ba pelu bi gbogbo nnkan se gbowo leri nitori bi owo dola ti se won, ti owo naira ti a n na lorile-ede yii ko si niyi mo. Gbogbo aye lo n pariwo pe oja won, sugbon pelu bi oja se won to, ti awon osise ileese aladaani ti won n ri owo gba deede gan-an n pariwo pe ilu ko fararo, eyin e wo bi nnkan se ri fun awa osise ijoba to je pe a ko rowo kankan gba laarin osu merin marun-un.'' Bakan naa lomo sori fawon oluko ileewe girama to je tijoba ipinle Oyo. Oluko ileewe girama ipinle kan to filu Oyo sebugbe salaye pe bo tile je pe gbogbo osise ijoba nipinle naa ni won ni oda owo da, ti atije atimu si dogun doran fun, awon ti aanu oun se ju lawon ti won ni ipenija ilera, to je pe awon dokita ti ko oogun ti won gbodo maa lo loorekoore fun won sugbon ti won ko rowo ra awon oogun ohun mo, leyii to mu ki aisan to n se won maa bureke si i.

Gege bo se so, ''Gbogbo ajo ati alajeseku ti a n da lo ti fori sanpon. Eni to fee gba owo ajo tabi owo alajeseku ko rowo gba, abi bawo lo se fee rowo gba nigba tawon eeyan ko ba ri owo da. Nibo leeyan si ti fee ri owo da nigba ti ko ri owo-osu gba.'' Ni tobinrin kan toun naa je oluko ileewe girama niluu Ibadan, o ni oun ko bi ju omo meji lo, oun nikan loun si n gbo bukaata awon omo naa nitori oko oun ti ku lati nnkan bii odun merin seyin. Sugbon bi awon ko se bimo pupo yii naa, isoro nla ni oro eto-eko omobinrin oun to sese wole si LAUTECH, iyen ileewe fasiti tijoba ipinle Oyo pelu bo se je pe nnkan bii egberin lona aadojo naira (N150) ni omo naa ni lati san nibe, sugbon ti ko sowo lowo oun lati san kobo ninu owo naa pelu bo se je pe osu karun-un ree toun ti ro owo-osu gba gbeyin.

Oro owo bukaata kankan ko tile ba baba kan to n sise ni sekiteriati ijoba ipinle Oyo ni tie, o ni boun yoo se maa ri ounje je nikan lo n ko ipaya ba oun bayii nitori eni toun maa n gbawin ounje bii iresi, gaari, ewa, ororo ati bee bee lo lowo e ko ta awin foun mo.

''Mi o ri oun naa ba wi o, o ni awon to n ra oja lawin lowo oun ti po ju. Akobo Oju-Irin, n'Ibadan, ni mo n gbe. Awa ta a je osise ijoba po laduugbo wa. Ki Olorun ma si je ki ebi se oluware lese ni bayii, afi ki Olorun ba ni se e ki ijoba sanwo ti won je wa.'' Ki i se awon mekunnu ti won je osise nikan ni won n foju wina oda owo ati ai rowo-osu gba yii, ko yo awon ti gomina ipinle Oyo yan sipo gege bii oludamoran sile. Lasiko kan lodun 2015, enikan toro owo lowo okan ninu awon ti Gomina Ajimobi yan gege bii oludamoran, sugbon tokunrin ta a foruko bo lasiiri yii n saroye pe oun ko lowo lowo nitori oun ko ti i gbowo kankan lati nnkan bii osu meta ti gomina ti yan oun sipo.

Seneto Ajimobi funra e fidi e mule lojo tijoba ipinle Oyo seto akanse adura ibere odun yii legbee ofiisi gomina n'Ibadan, o ni ki i se ife inu ijoba oun ni lati maa je awon osise lowo bi ko se nitori bi eto oro-aje orile-ede yii lapapo ko se fararo, eyi to mu kijoba apapo paapaa je awon ipinle lowo. O ni oro ai rowo-osu gba yii ko mo lori awon osise ijoba nikan, o kan awon toun yan sipo ti won n ba oun sise, ati pe tawon eeyan wonyi paapaa koja tawon osise ijoba nitori pupo ninu won lo kan n sise, sugbon ti won ko ti i rowo gba latigba ti won ti wa nipo toun yan won si.

Nigba to n ba akoroyin wa soro, oludamoran fun ijoba Gomina Ajimobi lori eto iroyin, Ogbeni Akin Oyedele, so pe ki i se ife inu ijoba ni lati je osise kankan lowo nipinle Oyo, bi ko se ipenija to ba eto oro-aje jakejado orile-ede yii atawon ibomi-in kaakiri agbaye.

Gege bo se so, ''Ko si nnkan kan tuntun ta a tun fee so lori oro owo-osu awon osise ju ohun ta a ti n so tele naa lo. Gbogbo wa la jo mo ipo ti eto oro-aje orile-ede yii wa. Oda owo da ijoba apapo paapaa, a si ni igbagbo pe isoro yii ko ni i pee dohun igbagbe, ti awon osise ati gbogbo ara ipinle Oyo yoo si maa jegbadun ijoba nitori eni ti ki i fe kiya je araalu ni Gomina Ajimobi.'' Nigba to n ba akoroyin wa soro, alaga egbe awon osise nipinle Oyo, Ogbeni Waheed Olojede, so pe loooto ipo ti eto oro-aje orile-ede yii wa pelu nnkan to sokunfa bi awon ijoba elekajeka lorile-ede yii se n je awon osise lowo, sugbon iyen ko di egbe awon osise lowo lati beere fun eto won.

Lori akoba to see se ki ai rowo-osu gba deede se fun ilakaka awon osise lati beere fun afikun owo-osu tuntun lowo ijoba, alaga egbe awon osise ipinle Oyo yii so pe, ''Ijoba ipinle Oyo ti tele ilana eto ekunwo ti egbe osise beere fun gbeyin (sisan egberun mejidinlogun naira fun osise to n gbowo to kere julo). Sugbon iyen ko di wa lowo lati beere fun afikun owo-osu nitori latinu osu kerin, odun 2011, nijoba apapo labe akoso Aare Goodluck Jonathan ti buwolu u pe ki gbogbo eka ijoba maa san egberun mejidinlogun naira fun osise ti owo-osu re kere julo.

''Ni bayii, o ye ki afikun ti ba owo yen nitori odun marun-un marun-un lo ye ki afikun maa ba owo osu awon osise. Gbogbo wa la mo pe gbogbo igba ni ayipada n ba eto oro-aje kaakiri agbaye, iyekiye ti won ba si san fawon osise lasiko kan, o ye ki ayipada ba a laarin odun marun-un nitori eto oro-aje ilu yen naa ko le duro soju kan naa laarin odun marun-un yen. Nitori naa, ipenija to ba eto oro-aje kaakiri agbaye ko di wa lowo lati beere fun eto tiwa.

''Owo tijoba je awa osise nipinle Oyo ti n mu opolopo inira ba awon eeyan wa nitori latinu osu kewaa, odun to koja ni elomi-in ti ri owo-osu gba gbeyin, awon mi-in ti ri owo osu kokanla gba, awon kan si ti gba ti osu kejila, sugbon ko ti i si osise to ti i ri owo kankan gba lodun yii, bee, inu osu keta la si wa yii. L'Ojobo, Tosde, ose to koja, lawa egbe osise sepade lori oro owo tijoba je wa yii. Ohun ta a fenuko le lori ni pe a ni lati sepade po pelu ijoba ipinle Oyo ka le jo fikun-lukun lori ona abayo, a si ti fi eyi to ijoba leti ninu leta ta a ko ranse si won. A ko ni i faaye gba ki ijoba yan asoju waa ba wa sepade yen, Gomina Ajimobi gangan la ba loro.

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Sunday, February 26 @ 20:05:53 PST Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· EsinIslam Media Yoruba
· Die sii Nipa Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere:
Oye Okere Tilu Saki, Ile-ejo Ni Mogaji Ko Gbodo Gbe Igbese Kankan Bayii


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere



"Nitori Bi Won Ko Se Rowo Osu Gba, Awon Osise Di Onibaara Nipinle Oyo" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com