Gbagede Yoruba
 



Adajo Ni Ki Won Fi Emmanuel, Ayederu Looya, Sogba Ewon Kirikiri
 
Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun Lati Owo Akoroyin Olootu

Adajo Ni Ki Won Fi Emmanuel, Ayederu Looya, Sogba Ewon Kirikiri

Ogba ewon to wa ni Kirikiri ladajo ni ki won fi ayederu looya kan, Emmanuel Uba, to puro gba milionu mejilelogun naira (N22m) lowo okunrin onisowo kan si titi digba tigbejo mi-in yoo fi waye lori iwa arufin to hu.

Odun 2014 ni won ti koko fesun yiyi iwe ati jibiti kan okunrin naa. Igbejo ohun ni won se ti won fi fun un ni beeli idaji milionu naira (N500,000) ati oniduuro meji. Sugbon ti oro yiwo nigba tawon ibatan Emmanuel meji ti won soniduuro fun un mu esun to awon olopaa lo pe awon ko mo ibi ti afurasi yii sapamo si nitori gbogbo igba tawon ba beere e lowo iyawo atawon omo e ni won ki i le so pato ibi to wa. Eyi lo mu kawon agbofinro topinpin re, ti won si ba a nibi to lugo si labe beedi.

Gege bi a se gbo, okunrin onisowo kan, John Uka, ni Emmanuel puro fun pe okan lara awon osise ajo to n ri seto okoowo ati ileese fun ijoba apapo loun, pelu idaniloju lo si fi so fun John pe oun yoo maa soju re nibi eto okoowo gbogbo.

Iru ise ti ayederu looya naa so pe oun yoo maa se fun John lo tori e gbowo lowo e lodun 2008, to loun yoo loo soju re nibi eto okoowo agbaye kan to waye loju ona Badagry, l'Ojo.

Sugbon lasiko igbejo to waye ni kootu yii l'Ojoru, Wesde, ose to koja lawon oniduuro Emmanuel so o di mimo pe awon ko nifee si sise oniduuro re mo nitori awon iwa aisotito owo re.

Agbenuso ijoba, Inspekito Steven Molo, fi kun un pe afurasi yii tun paro fawon to soniduuro fun un pe ile-ejo ti da oun lare, bee ni won ni ki olupejo ohun sanwo itanran foun lori ejo ti ko lese nile to pe.

Ebe agbejoro afurasi naa, Abileko C. O Mbah, pe ki adajo faaye beeli sile fonibaara oun nitori ara re ko ya ni Adajo B. A. Sonuga fagile. O ni ki won fi okunrin naa satimole ogba ewon titi dojo kerinlelogun, osu kerin, odun yii, tigbejo yoo tesiwaju.

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Sunday, February 26 @ 20:34:09 PST Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun:
Onka Yoruba - Numbers In Yoruba: Figures And Counting, Kika Ni Yoruba Computes


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun



"Adajo Ni Ki Won Fi Emmanuel, Ayederu Looya, Sogba Ewon Kirikiri" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com