Gbagede Yoruba
 



Olopaa Ba Ibon Lowo Chioma Atawon Mi-in, Esun Idigunjale Ni Won Fi Kan Won Nile-
 
Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue
Lati Owo Oluyinka Soyemi

Olopaa Ba Ibon Lowo Chioma Atawon Mi-in, Esun Idigunjale Ni Won Fi Kan Won Nile-ejo

Ile-ejo Majisreeti Ikeja, niluu Eko, ti ni ki obinrin kan, Chioma Ezekwesiri, atawon marun-un mi-in si wa lewon lori esun pe won ba ibon lowo won ti won fee fi jale. Awon marun-un to ku ni Raymond Chukwuka, eni odun merinlelogun, Amadi Igwe, eni odun mokanlelogoji; Okechukwu Jerome, eni odun mejidinlogbon, Michael Madu, eni odun mejilelaaadota; ati Ignatius Okeredi, eni odun metadinlogbon.

Esun meta ti won fi kan won ni igbimopo lati sise ibi, idigunjale ati nini ohun ija oloro lona aito.



Nigba ti won ka awon esun ohun si won lese tan, Adajo A. O Komolafe pase pe ki won loo ti awon eeyan naa mo ogba ewon di ojo ti igbejo yoo tun waye.
Gege bi Iwe Iroyin Yoruba se gbo, ileetura Bolatito to wa n'Ijaye, niluu Eko ni awon olopaa ti mu won lasiko ti won fee ja okunrin kan to n se o¯wo¯ ajile lole owo to to milionu mejo. Osise ileetura yii kan lo pe awon olopaa, nigba ti won si de ni won ko awon eeyan naa ni papamora. Ibon meji ati ota mejila ni won ba ninu moto Chioma, eyi lo je ki won ko gbogbo awon afurasi-adigunjale ohun.

Ninu oro tie, Chioma to je obinrin laarin awon eeyan ohun so pe awon ki i se adigunjale, oro ile lo fa wahala tawon fi ya wa si agbegbe naa. O salaye pe Raymond lo seto awon ibon ti won ba lowo awon, sugbon ki i se lati ja enikeni lole. Obinrin ohun so pe odun 1999 loun jade ni Fasiti ipinle Eko, iyen UNILAG, oun si darapo mo egbe awon amofin lodun 2001.

Sugbon ohun ti a gbo ni pe ko si ooto ninu oro naa, ati pe ko si oruko re ninu akosile oruko awon agbejoro to wa lorile-ede yii. Pelu gbogbo nnkan ti obinrin naa ti so ati eyi to se, o da bii eni pe wahala nla lo wa lorun oun atawon to ku re, awon esun ti won si fi kan won le ran won lewon ojo pipe.


 Posted By Ifiranse Eleyi Je Saturday, January 25 @ 02:48:50 PST Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue:
O Ga O! Awon Olopaa Ati Adigunjale Fibon Para Won Loju Ija Niluu Ibadan: Awon Ol


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Ole Jegudujere Olosa Ibaje Olosa Gbajue



"Olopaa Ba Ibon Lowo Chioma Atawon Mi-in, Esun Idigunjale Ni Won Fi Kan Won Nile-" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com