Gbagede Yoruba
 



O Tan! Won Lawon To Ja Oba Sihooho Ni Ado Odo Ti N Ku Nikookan
 
Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
Lati Owo Johnson Akinpelu, Abeokuta

O Tan! Won Lawon To Ja Oba Sihooho Ni Ado Odo Ti N Ku Nikookan

Kayeefi loro to n sele niluu Ado-Odo n je fawon eeyan agbegbe yii nitori bi won se ni awon ti won lowo si bi won se ja Oba ilu naa, Oba Adeniran Akanni Abdul Lateef, sihooho ti won si lu u bii eni maa pa a ti n ku nikookan bayii.

Gege bi Iwe Iroyin Yoruba se gbo, o kere tan, awon meta ni won so pe won ti ku bayii, ti won ko si le so pato iru iku to pa won, eyi ti won lo je keru maa ba awon yooku, ti okan won ko si bale mo pe awon lowo nipa bi won se fiya je ori ade nita gbangba.



Bo tile je pe Oba Adeniran ti won fiya je naa ti so lakooko tijoba gbe iwadii kan dide lori wahala naa pe oun dariji gbogbo awon to huwa naa, sugbon awon eeyan ni awon alale to te ilu naa do si n binu. Ohun ti won ni awon agba ilu ohun so ni pe nnkan aburu lawon odo naa se, ati pe ti iru nnkan to sele si won yii ko ba sele, a je pe awon oba ki i se eni owo. Won ni won ti gbagbe pe eni to ba fowo kan oba, o ti fowo kan oosa, o si ye ki won rija oosa.

Bakan naa la tun gbo pe se lawon araalu naa n binu si Gomina Ibikunle Amosun lori bi won ko se ti i so nnkan kan lori abajade igbimo ti won gbe kale lati sewadii lori wahala to sele ohun, eyi ti ko je ki Oba naa ti i pada sori aleefa e lati bii osu meloo kan seyin ti wahala ohun ti waye.

Titi di akoko yii ni won nijoba ko ti i so pe eeyan bayii ni owo ti te, won ni afi bii eni pe won fee maa gbe leyin enikan lawon ka oro naa si.


 Posted By Ifiranse Eleyi Je Saturday, January 25 @ 03:09:09 PST Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu:
Nitori Oro Ti Ko To Nnkan - Lamidi Fogo Mo Ore E Lori, Lo Ba Ku Patapta: Won Ti


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu



"O Tan! Won Lawon To Ja Oba Sihooho Ni Ado Odo Ti N Ku Nikookan" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com