Gbagede Yoruba
 



Moto Pasito Pa Soja Meji N’Ido-Osun
 
Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose
Lati Owo Florence Babasola, Osogbo

Moto Pasito Pa Soja Meji N’Ido-Osun

Pasito eni odun merinlelogoji kan ti foju bale-ejo Majisreeti ilu Osogbo laipe yii, lori esun pe o wa oko niwakuwa, eleyii to yori si iku awon soja meji kan niluu Ido-Osun.

Gege bi agbejoro fun ileese olopaa, Inspekito Fagboyinbo Abiodun, se wi, ori oke-adura kan ni Pasito Ademola Adekunle ti n bo lojo ketala, osu kesan-an, odun yii tisele naa fi sele loju-ona Ede, lagbegbe Aerodrome, niluu Ido-Osun.



Ni nnkan bii aago meje aabo ale ojo naa ni won fesun kan Pasito Ademola pe o wa oko Peugeot Space Wagon to ni nomba LAGOS GQ 378 AAA niwakuwa, eleyii to si mu un kolu awon soja meji ti won je ti Nigerian Army Engineering Construction Regiment tilu Ede.

Loju-ese la gbo pe awon soja naa: Lance Corporal Mohammed Ibrahim, eni odun merinlelogbon ati Corporal Salisu Ibrahim, eni odun mejidinlogbon naa ku leyin ti moto gba won lori masinni ti won wa. Leyin ti won se ayewo iku to pa won ni won sinku won si baraaki awon soja niluu Ede.

Fagboyinbo ni iwa ti Pasito naa hu lodi, o si nijiya nla labe ofin irinna oko tipinle Osun.

Nigba ti won ka esun fifi emi eeyan sofo lona aito naa si etiigbo olujejo, o ni oun ko jebi.

Bakan naa ni agbejoro re, Ogbeni Clement Tanimose ro ile-ejo lati faaye beeli sile fun onibaara oun pelu alaye pe awon soja naa ti muti yo lori masinni ti won wa ni.

Sugbon agbejoro ileese olopaa tako arowa agbejoro olujejo pelu awijare pe gbigba beeli okunrin naa lewu fun emi re, nitori pe ko seni to mo nnkan tawon soja elegbe awon to ku naa le se fun un.

Ninu idajo re, Majisreeti Mohammed Lasisi faaye beeli sile fun olujejo pelu egberun lona ogorun-un naira ati oniduuro meji niye kan naa.

Leyin eyi lo sun igbejo siwaju di ojo kewaa, osu kewaa, odun yii.


 Posted By Ifiranse Eleyi Je Sunday, March 30 @ 05:05:13 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose:
Iru Pasito Radarada Wo Waa Ni Oluso-Aguntan Oyelami Yii Gbogbo Awon Omobinrin Ij


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose



"Moto Pasito Pa Soja Meji N’Ido-Osun" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com