Gbagede Yoruba
 



Nje Ija Ooni Ati Alaafin Le Pari Laye Yii Bi?
 
Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu
Lati Owo Adewale Adejare

Nje Ija Ooni Ati Alaafin Le Pari Laye Yii Bi?


Ibeere ti mo beere yii nidii o. O nidii gan-an ni. Opolopo awon eeyan ti won ti n da soro yii, ti won maa n te atejise ranse si mi latigba ti a ti bere oro asaaju Yoruba yii, awon kan wa ti won maa n tenumo on pe bi ija Ooni ati Alaafin ko ba pari, ko sohun kan ti a le se ti Yoruba yoo fi ni ilosiwaju laye yii. Awon mi-in ko ni i so bee yen, won yoo kan so pe ija aarin awon oba Yoruba ni ka koko yanju na, bi a ba ti yanju iyen nile Yoruba yoo toro.

Awon ka n tile la oro naa mole ni tiwon, ohun ti won wi ni pe awon oba merin lo n da ile Yoruba ru, won si daruko awon oba naa: Ooni, Alaafin, Awujale ati Oba Eko. Won nibi ti awon oba yii ba ile Yoruba je de lo wa nitori ija to wa laarin won, bi awon mereerin ko ba si pari ija naa, ko si asaaju kan ti yoo jade fun Yoruba wa yii.

Mo gba oro naa gbo debi kan, n ko gba a gbo tan. Mo gba pe ija wa laarin Ooni ati Alaafin, mo si gba pe ija yii n di ilosiwaju ile Yoruba lowo gidigidi. N ko mo boya awon oba mejeeji yii mo aburu ati oriburuku ti ija won n ko ba ile Yoruba, nitori bo ba se pe won mo pe awon lawon n fi ija yii ko ifaseyin ba wa ni, boya won iba ti mo ohun ti won yoo se si i, afi to ba se pe won ko fe ki Yoruba ni ilosiwaju rara, won kan fe ka maa seru awon eya to ku ni Naijiria ni. Sugbon ninu pe boya Awujale tabi oba Eko n ba Alaafin ja yen, ko soro ninu iyen. Idi ni pe Awujale ko le ba Ooni ja, bee ni ki i se Awujale lo n ba Ooni ja, Sikiru Adetona lo n ba Okunade Sijuwade ja to ni o n gberaga soun, ija yii naa ni won si fi n di ilosiwaju Yoruba lowo, nitori ohun to fa a ti Awujale fi so nigba kan pe awon ki i se Yoruba niyen.



Bi ibi ko ba te, ti ibi ko ba wo, eni ti a ba niwaju to baba fun ni. Bo ba se pe lori oro ti Yoruba yii ni, ibikibi ti Awujale ba wa lo ti gbodo fori bale fun Ooni. Bi won si ti se n se e bo lojo to pe niyen o, afi nigba ti Oba Adetona je. Oba Adetona ko si ba Ooni kankan ja, afigba ti Sijuwade joba. Awon Obafemi Awolowo ni won fi dandan le e pe eni to mowe lawon fe ko je Awujale ni 1959 leyin ti Awujale Gbelegbuwa ku, awon yii naa ni won si ran S.O Sonibare lati loo mu un wa lati ilu oyinbo to wa, ti won si toju re pamo si ile Sonibare yii ni Maryland, Eko, titi ti won fi gbe e lo si Ijebu-Ode lati joba. Ko si tabi-sugbon kankan nibe, niwon igba to ti je owo Awolowo ni gbogbo agbara ijoba Yoruba wa nigba naa, bo ba se pe o koriira Sikiru Adetona tabi ti ko feran re, ko si bi okunrin ara ilu oyinbo naa iba se joba nigba naa.

Sugbon nigba ti ija oselu de, nigba ti ija de repete laarin Awolowo pelu Akintola, nitori pe Adetona je ore omo Akintola, isoro wa fun un lati wa leyin awon Awolowo, oro naa lo si da ija sile laarin won. Ija naa le debii pe nigba ti awon ti won je omoleyin Awolowo pada gbajoba, gbogbo ona ni Bisi Onabanjo gba lati yo Awujale kuro loye re. Nibi ti ija naa ti kan Okunade Sijuwade to sese joba nigba naa niyen. Awujale binu pe ni gbogbo igba ti laasigbo wa fun oun yii, ti won le oun jade kuro laafin oun, ti awon omoleyin Awolowo si n se iwe oun lo, Ooni ko ba oun da si i, koda ko sun mo oun rara, ko si kilo fawon eeyan re pe ki won ma foju Awujale gbole, nigba to si se pe ore lawon lati kekere. Bee ooto ni, ki Omooba Sijuwade too joba, ore nla loun ati Oba Sikiru Adetona, won jo maa n se faaji, won si jo maa n jade ariya gbogbo.

Ki enikeni too maa so ohun ti ko mo, oro ti mo so yii see wadii nibi gbogbo, o wa ninu awon iwe itan, awon mi-in ti won si dagba paapaa le so nipa re. Ooni ti soro yii loju mi ri pe ko sija kan laarin awon ju bee lo, Awujale ti soro naa loju mi ri, Obasanjo ti so o loju mi ri, bee ni Ayo Adebanjo. Ohun ti mo se so pe ko sija gidi kan laarin Ooni ati Awujale niyen, ija to wa nibe see pari daadaa, awon eeyan si ti gbiyanju re. Igba kan wa ti awon Ayo Adebanjo, Olanihun Ajayi - awon meji pere yii naa ni - ti won mu Awujale de aafin Ooni, ni bii odun 2009, ti Ooni gba Oba naa lalejo, ti awon mejeeji si jo da soro laarin ara won. Sugbon ohun to tun maa n ru ija yii sile ni ore ti Awujale ba Alaafin se, bi kinni kan ba ti sele laarin Ooni ati Alaafin, Awujale ni Alaafin yoo pe, yoo fi oro naa to o leti, ija naa yoo si maa feju si i.

Eleyii fi han pe ki i se Ooni ni Awujale n ba ja, ija awon ore meji lasan ni. Tabi ka pe e ni ota ore mi, ota emi naa ni, ore ore mi, ore emi naa ni. Iyen ni pe bi Ooni ati Alaafin ba n ja, nigba to se pe ore Awujale ni Alaafin, Awujale le da sija naa, yoo si so pe Ooni n ba ore oun ja. Ohun to n sele laarin awon wonyi niyen, o si daju pe bi ko ba sija laarin Ooni ati Alaafin mo, ko sija kan bayii ti yoo wa laarin Awujale ati Ooni.

Sugbon awon ija yii ti maa n ba nnkan to dara je ju ni, nitori nigba ti ija naa le ni Awujale so o ni gbangba, ti awon iwe iroyin gbogbo si gbe e pe awon Ijebu ki i se Yoruba ni tawon o, to si daruko ilu naa pe Wadai lawon ti wa. Bi awon agbalagba ba mo pe ija lo de ti Oba Adetona fi so bee, awon omo kekere ti won yoo ka iwe itan lojo iwaju nko, tabi awon omo Ijebu ti won ka oro to ba jade lenu oba won si oro lati odo Olorun won.

Bi ija Awujale ti ri yii naa ni ija Oba Eko ati Ooni ri. Ninu asa ati isedale Yoruba, ko si kinni kan to le fa ija laarin won rara, lati ibo sibo! Sugbon nigba ti Alaaji Riliwan Akiolu yoo di Oba Eko, ede-aiyede sele, nitori Kunle Ojora naa fee du ipo naa, oun naa fee di oba Eko. Kunle Ojora yii, ore timo-timo Ooni Sijuwade ni.

Bi won ba fee ka awon ore to sunmo Oba yii ju, boya ni won yoo ka eni merin ko too kan Kunle. Lati ile ni won ti jo n bo, won ko si n se ohunkohun leyin ara won. Dajudaju, bi iru Kunle ba fee joba, eeyan ko le so pe ki Sijuwade ma ran an lowo nibi to ba ti see se. Iranlowo yii lo bi Akiolu ninu, pe bawo ni Sijuwade yoo se gbe seyin enikan ninu idije ipo oba awon. Bo si tile je pe leyin ti Akiolu di oba tan, ti Ooni loo ki i to si ko ero leyin, to si mu ebun lo fun un, oro naa ko tan ninu Oba tuntun naa. Nitori pe Ooni pe Oba naa ni okan ninu awon omo oun, nigba ti Akiolu yoo pada fesi oro yii ni gbangba, ohun to so ni pe awon ki i se Yoruba, Binni lawon ti wa. Bi eeyan ba fee maa tu tifun-tedo oro ti Oba yii so, oluware yoo kan tun maa da nnkan ru si i ni, nitori itan ti won yoo pa fun un, oun naa ko ni i le gbe e sara.

Oro to so yii le mu ki ijoba ti ko ba feran re gba agbara olori ipinle Eko kuro lowo re, nitori awon oba bii Olofin Iseri, Oloto, Osolo, ati awon oba ti won ti Ife wa ni won ni ile won, ile Yoruba si ni gbogbo ibe, ibi ti won ti n da oko won lo di Eko. Nitori pe awon eru ti Oba Ibinni ran nise si fi agbara mu awon ti won n sise ninu oko yii lati di olori won ko so pe Yoruba ko ni won, tabi pe ile Ibinni ni Eko. Lara ohun buruku ti itan adorikodo ti awon oba wa maa n pa nitori ija maa n mu wa niyen, idi si niyen ti Jakande se le fi Osolo Farombi se alaga awon oba Eko ni 1980.

Sugbon eyin naa yoo ri i pe ija Awujale ati Ooni, tabi ti Oba Eko pelu Ooni, ati oju ati imu ni, ko si eyi to too gbe sare nibe. Nibi ti ija wa gan-an ni ti Ooni ati Alaafin. Nibi ti ise ti mo ni a oo se ti fee bere niyen.

Sugbon a gbodo koko mo idi ija yii, ka too le mo ohun ti a oo se si i, nitori emi naa gbagbo pe bi Ooni ati Alaafin ko ba ja, ile Yoruba yoo dara.


 Posted By Ifiranse Eleyi Je Sunday, March 30 @ 05:35:16 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu:
Ojo Buruku, Esu Gbomimu L'ojo Ti Won Pariwo "Ole" Le Awolowo Lori


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 5
Awon Ibo Ni Oniyi: 1


Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Iroyin Oselu Ati Ojelu: Iwa Awon Oloselu



"Nje Ija Ooni Ati Alaafin Le Pari Laye Yii Bi?" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com