Gbagede Yoruba
 



O Ma Se O, Sanni Abacha, Agbaboolu Naijiria Tele Ku
 
Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere
Lati Owo Taofik Afolabi ati Soyemi Oluyinka

O Ma Se O, Sanni Abacha, Agbaboolu Naijiria Tele Ku

Olokiki agbaboolu Super Eagles nigba kan, Sanni Abraham Abacha, ti ku, won si ti sin in lose to koja.

Okunrin eni odun marundinlogoji ohun lo daku lale Ojoru, Wesde, to koja, won si sare gbe e lo si ileewosan kan n’Ilorin, sugbon o pada dagbere faye.

Omo ipinle Kogi ohun ni won so pe ko si nnkan kan to n se e ko too di akoko iku re ohun, eyi to je kawon eeyan maa so pe kayeefi ni. Oloogbe Abacha to je pasito ninu ijo Ridiimu ki iku too pa oju re de ni iyawo re to wa ninu oyun, Bisola, omokunrin meji ati obinrin kan gbeyin re.



Leyin to feyinti ninu ise boolu lo da egbe agbaboolu Shinning Stars Football Club sile, o si sakoso re di ojo iku. Ilu Oke Oyi, nipinle Kwara, ni won sin in si l’Ojobo, Tosde, to koja leyin isin ni Soosi Ridiimu to wa ni Sabo Oke, n’Ilorin.


Sola Ameobi yoo kopa ninu ifesewonse Ethiopia Taofik Afolabi ati Soyemi Oluyinka Koosi egbe agbaboolu Super Eagles ile wa, Stephen Keshi, ti so o di mimo pe agbaboolu ile wa to n gba boolu jeun ni Kiloobu Newscastle, Sola Ameobi, yoo kopa ninu kuolifaya ti yoo waye laarin Super Eagles ati Walia Antelopes orile-ede Ethiopia. Ifesewonse ohun yoo waye lojo ketala osu yii.

Saaju asiko yii lomokunrin naa ti farapa, eyi ti ko je ko lanfaani lati gba boolu fun opolopo ose, sugbon bayii ti Koosi Super Eagles ti so pe ko si kinni kan to se agbaboolu naa mo, o ti lanfaani lati kopa ninu ifesewonse naa.

Keshi salaye pe gbogbo enu loun fi so o pe ara Ameobi ti ya daadaa, bee lo wa lara awon agbaboolu toun yoo lo lati gbena woju Ethiopia. O ni Ameobi je eni to feran orile-ede yii, o si maa n wu u lati gba boolu fun Naijiria ni gbogbo igba tawon ba ti pe e; o loun ti ba a soro, o si fi oun lokan bale.

Orile-ede England ni Ameobi n gba boolu fun tele, o si je okan ninu awon to gba boolu wole ju fun egbe agbaboolu won. Sugbon ni 2009, o fife han si orile-ede re, Naijiria, odun 2011 si ni ajo ere boolu agbaye (FIFA) fun un ni ase lati se bee. Odun 2012 lo bere si i gba boolu fun Super Eagles, bee lo ti kopa nigba meta bayii, o si han gbangba pe o sese bere bebe fun orile-ede abinibi re ni.


 Posted By Ifiranse Eleyi Je Sunday, June 08 @ 21:17:04 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· EsinIslam Media Yoruba
· Die sii Nipa Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere:
Oye Okere Tilu Saki, Ile-ejo Ni Mogaji Ko Gbodo Gbe Igbese Kankan Bayii


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere



"O Ma Se O, Sanni Abacha, Agbaboolu Naijiria Tele Ku" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com