Gbagede Yoruba
 



Igbeyawo Pasito Daru N'Ibadan! Iyawo Ni Gbogbo Omo Ijo Ni Pasito Ti Fee Ba
 
Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose
Lati Owo Olawale Ajao, Ibadan

Igbeyawo Pasito Daru N'Ibadan! Iyawo Ni Gbogbo Omo Ijo Ni Pasito Ti Fee Ba Sun Tan

Gbogbo bi okunrin pasito kan, Rotimi Ogunmodede, se maa n ba awon obinrin inu ijo e lasepo, to si se bee fun okan ninu awon alore ijo naa loyun niyawo e, Titilayo Ogunmodede, ti tu fun gbogbo aye bayii.

Titilayo salaye oro naa lasiko to n ro kootu ibile to wa laduugbo Orita Aperin, n'Ibadan, lati fopin si ibasepo olodun mewaa to wa laarin oun atoko e lojo Isegun, Tusde, to koja, iyen ojo ketadinlogun, osu kefa, odun 2014 ta a wa yii.

Iyawo pasito ohun to sapejuwe oko e gege bii onisekuse eeyan to maa n ba awon omo ijo lasepo bo se wu u so niwaju adajo pe latinu osu keta, odun yii, loun ti keru oun jade nile okunrin naa, nitori to fun okan ninu awon alore re to je ore timotimo oun loyun.



"Tawon omo ijo ba pe ogun obinrin, oko mi a mu mokandinlogun bale ninu won. Idi ti mo se ro o papo niyen ti mo fi ko jade. Iya mi lo n lo soosi yen tele, won mu mi lo lati ba mi sadura soko ti mo fee fe ni, bi mo se di iyawo e niyen laimo bo se je, bee o ti niyawo kan tele ri, iyen si ti bimo meji fun un. " Bee niyawo pasito naa so nile-ejo.

Esun ipaniyan lo koko fi kan oko e niwaju adajo, o ni leyin tawon jo lasepo tan lokunrin naa mu oogun kan jade ninu apo to si fee fi kan oun lara. O ni pasito ro pe oun ti sun ni, sugbon boun se soro lojiji pe ki niyen, nise leru ba okunrin naa, to si re subu lule latori ibusun nigba to gbo ohun oun.

Bakan naa niyawo pasito yii fesun kan oko e pe nise lo n lo nnkan-osu oun, ati pe nitori e loun ko se romo bi fun un ni nnkan bii odun mewaa.

Gege bo se so, "Omo ti mo bi gan-an, mo ni idaduro ki n too ri i bi. Oko mi si ti so pe ti mi o ba bimo, nise loun maa pa mi danu. Sugbon Oloun se e, mi o mu osu yen je ti mo fi loyun.

Lati bii odun mewaa yen, mi o bimo le omo kan soso ohun."

Gege b'Iwe Iroyin Yoruba se gbo, iyawo ile to ti bimo merin foko e ni alore ti won ni Pasito Rotimi fun loyun yii, bi iroyin abani-ninu-je ohun si ti de setiigbo e lo ti le iyawo e jade nile.

Nigba to n tako gbogbo ejo tiyawo e ro, Pasito Rotimi so pe oun ko yan alore ijo oun lale debi ti yoo loyun foun, ati pe iyawo oun gan-an lo n yan ale pelu bo se maa n te ara e sile fun eni to je pasito eka ijo toun sese da sile ninu ijo oun, tiyen si maa n ba a lasepo.

"Oun ati pasito yen gan-an ko so pe awon ko pa mi, lojo kan ni mo ba oogun kan bayii to da bii ikoode labe konseeti iyawo mi, mo si mo pe pasito to n yan lale yen lo maa fun un."

Pasito naa tun so pe ara to fu oun siyawo oun lojo naa lo je koun so pe ki awon omo ijo ja konseeti mo on lara, ti won si ba oogun abenu-gongo naa ninu e.

Okunrin olujejo naa royin pe kugu aye tiyawo oun n je lodo pasito to n yan lale yii ti dun mo on lenu to bee ti ko fi gbe ile mo rara, ati pe lojo keta ti won ba awon pari ija oro oogun inu komu niyawo oun so pe koun loo ra yinyin to fi n ta oti elerindodo wa loja laimo pe nise lo dogbon tan oun jade nile, nitori koun too de ni jagunlabi ti pale eru e mo to sa lo.

Aburo olupejo, Busola Anthony, jerii nile-ejo pe loooto ni pasito n yan ore anti oun lale, sugbon awon omo ijo ti yanju e ni soosi, ati pe ko si ibasepo ikoko laarin won mo.

Igbimo awon adajo kootu naa labe akoso Oloye Odunade Adewuyi ti pase pe ki won pe oko alore waa jerii ni kootu lati tan imole sawon oro kan nigba tigbejo naa ba n tesiwaju l'Ojoru, Wesde, ola ode yii.


 Posted By Ifiranse Eleyi Je Thursday, June 26 @ 00:38:58 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose:
Iru Pasito Radarada Wo Waa Ni Oluso-Aguntan Oyelami Yii Gbogbo Awon Omobinrin Ij


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose



"Igbeyawo Pasito Daru N'Ibadan! Iyawo Ni Gbogbo Omo Ijo Ni Pasito Ti Fee Ba " | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com