Gbagede Yoruba
 



Ile N Jeyan! Igbesi Aye Arisekola Alao Aare Musulumi Ile Yoruba - Igbe Aiye Rere
 
Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere
Lati Olawale Ajao, Ibadan

Ile N Jeyan! Igbesi Aye Arisekola Alao Aare Musulumi Ile Yoruba - Igbe Aiye Rere Ni

Ni aye igba kan nile yii, ero redio ko po pupo, bee ni awon iwe iroyin to wa niluu ati ti oloyinbo ati ti Yoruba ko si to nnkan. Ohun kan naa lawon eeyan fi n mo gbajumo laarin ilu, ti won yoo si tun mo awon olowo tuntun ti won ba sese de saarin ilu kaakiri. Ona kan soso ti awon araalu n gba mo awon eeyan ti owo won ba sese bureke bee ni lati odo awon olorin. Bi olorin nla kan ba ki enikan, ki ile ojo ti awo rekoodu naa ba jade too su, gbogbo ilu pata ni yoo ti mo oruko eni naa, bi awon orin naa ba si se n ta si, bee ni oruko okunrin naa yoo maa ran bii irawo owuro. Ati pelu, bi akorin to korin naa ba je elere nla, kia laye yoo ti mo pe olowo gidi ni eni ti won n ki naa.

Ohun to sele ni odun 1977 si 1978 niyen, nigba ti awon elere nla meta kan ti okiki won n kan lowo, ti irawo won si bu yo korin ki okunrin kan soso sinu awo orin won ti won se leralera, ti okiki okunrin naa si gbile bii irawo nla. Olanrewaju Adepoju, Borokinni Akewi omo Okebadan, lo koko si ode kinni ohun, oun lo koko forin ewi juwe Arisekola Alao fun gbogbo ilu, oun lo je ki Yoruba mo pe eni naa wa to n je Azeez, o pe e ni Arisekola Alao Azeez, oba kekere aarin igboro, Ikolaba Aare Ibadan to ri bii oba ibomi-in.



Ko pe rara ti awo orin re jade ni ti Ebenezer Obey tele e, Obey lo si je ki gbogbo eeyan mo ise ti Arisekola n se gan-an. Oun lo salaye fun gbogbo ilu pe “Bo o ba fee ra Datsun, bo o ba fe 120, tabi 140, bo ba je 200, tabi 240, orisiirisii e lo n be lodo Arisekola. Alao Azeez, Lister Motors, Aye ko otito, Arisekola o, aye ko otito o. Oyinbo oni-Datsun, Arisekola, oyinbo oni-Datsun, Arisekola, oyinbo oni-Datsun.” Leyin ti oun si korin yii naa ni Sunny Ade gba a, oun lo je kawon Yoruba mo pe ore ni Arisekola ati Alaafin, ati pe lojo ti won n gbe ade orin le oun Sunny Ade lori nibere odun 1977, bi Arisekola se jokoo, bee ni Alaafin jokoo, ati Akanni Aluko, pelu Aminatu Abiodun.

Lati igba naa, ni bii odun die din logoji seyin yii, ni oruko Arisekola ti wa lokan gbogbo eeyan ile yii pata, ohun ti awon eeyan si se n ro pe agbalagba nla ni okunrin naa niyi, iyanu lo si je nigba ti pupo ninu won gbo pe o ku die ki Arisekola di omo aadorin odun ni iku mu un lo. Ohun to sele ni pe o ti pe kanrin kese ti won ti n gbo oruko Arisekola Alao, opolopo awon eeyan ti won si ti to omo aadota odun bayii gbonju mo pe eni kan wa to n je Alao Azeez n’Ibadan, ati pe oba kekere aarin igboro ni.

Bi oga soja kan ba ti waa de si Ibadan, awon soja to n gbese jade ni yoo koko so fun Arisekola, oun naa yo si ra ebun to joju, yoo loo mo okunrin naa, oun ni yoo si mu un jade, ti yoo mu un kaakiri awon agbegbe igbadun ati ibi pataki ilu Ibadan, bee ni won yoo si di ore timo-timo.

Bi Arisekola ti lawo yii mu opolopo oriire ba a.

Ko si owo ti ko le na, ko si owo ti ko le fi tore, bee ni ko si eni ti ko le saanu fun. Nigba ti yoo fi di odun 1978, okiki Arisekola ti gbile, ko si si ohun ti enikeni fee se nigba naa ti won ko ni i pe e si i, tabi ti ko ni i mo, afi ti ki i baa se Ibadan ni kinni ohun ti fee waye. Nigba ti won gbese kuro lori ofin to de oselu ni 1978, ti awon Awolowo da egbe UPN sile, ti awon Akinloye naa da egbe NPN sile, Arisekola se kinni kan tenikan ko ro pe o le se. O ra moto nla kan, mesidiisi ni moto ohun, o si ni ki won gbe e lo si odo Awolowo foun, o ni ohun ti oun fe ki baba naa fi se ni lati fi rin gbogbo irin-ajo to ba fee rin fun ipolongo. Ki i se pe won ki i gbe iru awon nnkan bee yen kale lasiko ti ibo ba n bo fun awon oloselu, sugbon pe omode ti ko ju omo odun metalelogbon lo se iru eyi je iyanu fun awon Awolowo, bee ni baba naa beere eni ti won n pe bee, Oluwole si so pe Azeez lo n je, ati pe oun mo on daadaa. Bee ni Arisekola di ore won nile Awolowo, to si mo gbogbo awon omo won pata, bo tile je pe ko too di igba naa lo ti n ba won se.

Bee bi Arisekola ti fun awon UPN ni moto, bee lo fun awon NPN lowo, o ni oun ko ni i fi awon omo Ibadan sile, nigba to se pe awon asaaju awon bii Adisa Akinloye, Richard Akinjide atawon mi-in bee ni won wa ninu egbe ohun.

Ohun ti eyi tumo si ni pe ati otun ati osi ni Arisekola n se, ko si si eni to wole ti yoo so pe oun ko mo okunrin onisowo naa. Nigba ti awon omo Ibadan si binu, ti won ni awon yoo gba ijoba ipinle awon kuro lowo Bola Ige, Arisekola naa ni won loo ba, oun lo si gbe moto mesidiisi boginni ti won n pe ni 280 nigba naa fun Omololu Olunloyo, o ni ohun ti oun fe ko se ni ko fi kampeeni, bee lo tun ko owo nla kale fun Olunloyo, nigba ti baba naa si wole, ko si eni meji to ranti ju Arisekola lo. Lati igba naa lo ti je pe ko si gomina kan ti yoo je nipinle Oyo ti yoo so pe oun ko mo Arisekola, tabi ti ko ni i je Arisekola ni yoo mo bi yoo ti debe.

Bo ti n se eleyii, ore to n ba awon soja se ko duro o, nigba ti awon soja si gbajoba ni 1983, ti won yi oga soja to wa nibe pada, ti won gbe okunrin kan ti won pe n Sani Abacha wa, ti won fi i se olori awon soja gbogbo ni ekun Ibadan, owo Arisekola ni Sani Abacha de si, oun lo si n mu okunrin naa kaakiri, bee ni won di ore ti ko se e fowo ra, gbogbo ohun ti Abacha ba si fe nigba to wa n’Ibadan, bo ba ti fi to Arisekola leti, lesekese ni gbogbo re yoo se. Abacha ko si mo, bee ni Arisekola paapaa ko mo pe okunrin naa yoo pada di olori Naijiria lojo iwaju.

Nitori pe Arisekola kewu, ati pe esin Islaamu lo koko mo nigba aye re, ko fi kinni naa sere, ona esin naa lo n tele, ohunkohun ti esin naa ba si la kale ni yoo se. Niwon igba ti okunrin naa si ni owo lowo lati fi se esin, ohun to tete so o di ore awon olori esin yii, ko si si aafaa kan ti ko mo on, tabi pe ode kan ti ki i ba won se daadaa. Lati igba naa lo ti n ran awon eeyan lo si Meka, ti yoo si ko opolopo aafaa lo lodoodun. Bi asiko aawe ba de, lojoojumo lawon aafaa yoo maa wa si ile re ti won yoo si maa gba nnkan fun awon alaini ti won ba wa lodo won. Arisekola paapaa ki i duro, lojoojumo ni yoo ni ki awon aafaa wa maa so kuraani kale ni ile oun, won yoo si ke kuraani naa titi ti aawe yoo fi tan ni, boya o wa nile tabi ko si nile, won yoo maa se bee lojoojumo ni.

Nidii eyi, nigba to di odun 1985, ohun ti ko sele ri sele n’Ibadan, abi ka so pe ni gbogbo ile Yoruba yikayika.

Awon agbaagba elesin Islaamu ile Yoruba ti n fi awon olowo ilu joye, won ti fi Abiola se Baba Adinni, won fi Folawiyo naa se Baba Adinni, nigba naa lo si da bii eni pe ko si oye gidi mo. Ko si eni to mo bi enikan se ronu kan oye Aare Musulumi fun ile Yoruba, bi won si ti ronu oye naa ni won ni Alao Arisekola niluu Ibadan ni oye naa to si, nitori Abiola ti je lati Abeokuta, Folawiyo ti je lati Eko, Ibadan nikan lo ku ti ko ni oloye gidi. Bee ni won fun Arisekola loye naa, won si so pe won yoo we lawani fun un.

Sugbon Arisekola ni ki won duro, o ni lawani ti won yoo we fun oun yoo yato si tawon ti won ti n we tele, o ni olori awon musulumi ni Naijiria pata ni yoo we lawani toun foun. Ni Arisekola ba lo si Sokoto, o si loo ba oba ilu naa, iyen Sultan ti i se olori awon musulumi pata, o ni ko waa we lawani oye foun. Ojo nla lojo naa ti Sultan de sile Yoruba, ojo kan ti ko se e gbagbe ninu ojo ni. Arisekola lo pe e wa, ni gbogbo musulumi ile Yoruba ati awon ti won wa kaakiri ibi gbogbo ba ro wa siluu Ibadan, ko si seni to lo sibi kan lojo ohun, ni gbangba lojaaba ilu Ibadan, won we lawani oye fun Azeez Arisekola, won si so o di Aare Musulumi pata.

Lati ojo naa ni Arisekola ko ti je oye mi-in mo, bo tile je pe ore awon oba nla ile Yoruba ni, Aare musulumi ni gbogbo aye mo on si.

Sugbon leyin ti Arisekola di aare Musulumi, ki lo yi aye re pada? Bawo ni oun ati Abiola se pade, bawo loun ati Abacha se dore to bee, ki lawon eeyan gbogbo si so nipa iku Arisekola. Afi ki e pade Iwe Iroyin Yoruba ose to n bo, nibi ti a oo ti maa so itan igbesi aye Aare Azeez Arisekola Alao lo.

Bi Alaaji Azeez Arisekola Alao se bere yoo ya eni gbogbo lenu, nitori oruko baba re ko si ninu awon olowo Ibadan nigba ti won bi i, ko si seni to gbo oruko won nibi kan ju adugbo won lo. Ojo ayajo awon ololufe ti awon oloyinbo n pe ni Valentine Day ni won bi Azeez, ojo kerinla, osu keji, odun 1945 sinu ebi Alaaji Abdul Raheem Olatubosun Olaniyan Alao ati Alaaja Rabiatu Olatutu Abegbe Alao ti won je omo bibi abule Ajia, nijoba ibile Ona Ara, nipinle Oyo. Azeez iba ti kawe debi to ka a de nigba aye e, omode naa ko nifee si eko iwe rara, oluko kan to n je Ogbeni J.O. Oladejo lo gba a nimoran. Keu nikan lo wu u, omo odun meta pere si ni to ti n lo sile Keu, asiko yii naa ni won si fi Arisekola kun oruko re, ti awon ti won mo on daadaa a si maa pe e ni Aafaa Arisekola. Azeez kekere lo sileewe alakoobere St. Luke’s School, Adigun, Ibadan, o si tesiwaju ni ICC Primary School, Igosun, n’Ibadan. Leyin to pari eko alakoobere lodun 1958 lo se idanwo atiwole sileewe giga Christ School, Ado-Ekiti, ati Lagelu Grammar School, Ibadan. Awon ileewe mejeeji yii si gbajumo daadaa lasiko naa. Oun lo se ipo kin-in-ni ninu awon to se idanwo lati wo ileewe Christ School, Ado-Ekiti, nigba to se ipo keta ninu idanwo atiwole si Lagelu Grammar School. Bo ti waa mowe to nni, ailowo lowo awon obi e ko je ki iwe kika rogbo fun un nitori agbe alaroje lasan lasan ni won.

Sibe naa, baba re mura pe yoo kawe dandan, o si ti fi Azeez lokan bale pe ko si ohun ti yoo se oun ti omo naa ko fi ni i kawe mewaa to fee ka naa jade. Afi lojiji ti iku mu Alaaji Olaniyan Alao lo, baba naa ku nigba ti enikan ko ro pe iku le pa a, bee ni ohun gbogbo daru patapata. Azeez ko le lo sileewe mo, se oro ileewe lo tile dele yii, nigba ti ko ti i si ona lati jeun gan-an alara. Ninu ilakaka yii lo wa ti won fi ronu pe kaka ko duro lai rebikan, ko tete waa loo wa ise kan ko, ki ise naa le je eyi ti yoo se jeun. Odo egbon e kan lo ti ko eko isowo loja Gbagi, n’Ibadan, ohun ti okunrin egbon re yii si n ta ni awon oogun orisiirisii tawon agbe n lo lati fi sise oko, okan pataki ninu awon oogun yii si ni Ganmole 20, oogun to gbajumo gbaa laye atijo ni. Bi won ba ko Ganmole yii de biba, Azeez yoo ko pupo jade ninu re, yoo si gba aarin oja lo. Nitori pe o kere nile, o si yara, ki i pe to fi n ta awon Ganmole naa tan, yoo si tun pada loo ko omiran si i. Lati odun 1958 lo ti wa lodo egbon re agba yii, o si wa nibe titi di odun 1961, nigba ti oun naa da duro.

Ki i se pe Azeez deede da duro bee, ohun to sele ni pe awon ti won ko Ganmole wa ni paali paali fun egbon re n ba a pade nibi to ti n ta loja naa, awon si ro pe o le da kinni naa ta bi awon ba n ko o fun un. Won ni ko mu owo die wa, ki oun naa gba soobu tie sibi kan, awon yoo maa ko oja yii fun un. Bee ni Azeez sare wa owo to gba soobu, n ni won ba ru Ganmole de fun un. Ohun to waa sele ni pe ni gbogbo igba naa, Azeez ko se bii awon onisoobu to ku, ko duro sinu soobu, ita lo n wa, ti yoo si bere si i kiri lati Gbagi kaakiri gbogbo adugbo naa, ti yoo si maa ti inu oja kan de okan, nigba ti yoo si fi di odun 1968, ko si meji eni ti i ta Ganmole bii Arisekola Azeez ni gbogbo agbegbe Ibadan. Bee omo kekere gbaa ni, nitori o sese di omo odun metalelogun ni.

Ni odun 1968 yii, iyen nigba ti Arisekola wa ni omo odun metalelogun yii lo ra moto re akoko, moto Pick-up ti won fi n keru ni, sugbon 404 niSe odun naa je odun nla fun un, nitori paali Ganmole 20 to ta je egbeje, bee lo si gba pon-un kookan gege bii owo oya lori paali kookan, n lo ba gba egbeje pon-un dani. Inu awon oloja naa dun debii pe won ni ko wa owo die wa ko waa gbe moto, bee ni Arisekola di onimoto, moto naa si je eyi to fi n ko oja re kiri. Moto Pick-up yii lo fun un lanfaani lati maa wo inu igbo ati abule lo, nibi to ti n ta kinni naa fun awon agbe, ilopo merin oja naa lo si ta lodun to tele e, n lo ba tun ra moto mi-in, o ni asiko to ki oun gba awon ti won yoo tun maa ba oun ta Ganmole, iyen ni pe bi oun ba gba ona kan, awon omo re yoo gbe moto mi-in gba ona mi-in, n lowo nla ba n wole fun un.

Nigba ti owo yii po debi kan, Arisekola bere owo-moto, o n ra moto akero ati akeru, o si n fi won haaya fawon eeyan kiri. Eyi ni pe nigba ti yoo fi di bii odun 1970 si 1975, Arisekola ti ni moto to to bii ogoji to wa nita, awon to fi n keru, awon to fi n kero, ati awon to bere si i gbe fun awon eeyan pe ki won maa san owo e die-die. Ohun to maa n se ni pe yoo kuku ra moto tuntun lowo awon Leyland, oun yoo san owo moto naa tan fun won, yoo waa gbe e fawon eeyan, yoo si fi iye to ba fe le e lori. Ohun to n se niyi ti awon oni-Datsun fi n wa eni ti yoo je bii asoju nla fun won ni gbogbo agbegbe West, n ni won ba mu ileese Arisekola to pe ni Lister Motors, ni won ba bere si i ro oko Datsun orisiirisii fun un, to si je ni gbogbo ibile Yoruba, ko si elomiran to tun n ta Datsun bii Alao Arisekola.

Ohun ti eeyan ba n se ko mura si i daadaa, asiko ti Arisekola bere si i sowo moto lo mo awon soja ti won je oga n’Ibadan, won a maa lo awon moto re, bee lo si maa n ta oja fun won ti won ba fe ohun kan. Onibaranda ati alajapa okunrin gbaa ni, ko si ohun ti awon soja fee lo ti ko ni i ko o lo fun won, yoo si gba owo re nigba ti won ba san an. Bo ba waa gba owo, opolopo ere to ba ri lori e, bee ni yoo tun ha a fun pupo ninu awon ti won gbe ise naa jade fun un, bee lo di pe awon soja ko le fi i sere, nitori won mo pe ise yoowu ti awon ba gbe fun un, bo ba ti n jere lori e, bee ni yoo je ko maa kan awon naa.
Ise rere Aare po to be gee, ti o fi gbajumo laarin awon larubaya ati awon India Musulumi ninu ati awon ti ko i se Musulumi. Nile yi ko si oninure ti o to Arisekol.  Nipa ki eniyan o nawo si Esin asinla Isla, ko si afiwe baba yi.  Igbati Olohun yio wa da okunrin Olu-omo ti Oke Ibadan yi lare, opolopo ninu awon omo re ni nwon n se esin. Koda a ri ninu awon omo Aare ti Aare papap mo loju aiye re wipe tiwa-tesin ni nwon ti iru nwon sowon laarin awon egbe nwon yala ni Naijiriya ni tabi loke okun.
Se gbogbo ohun ti eda ba n se naa lolere.  Ere esan po pupo ti Olohun ti san fun Alaaji Azeez lati oju aye re.  A fi asiko yi be Olohun: "Ki Olohun Ma Fi Esan Dun Aare Musulumi Arisekola Alao Ni Orun."
Adura wa si Olohun ni wipe ki Olohun se idarijin gbogbo ese-kese ti Alaaji Azeez Arisekola iba se laiye yi nitori wipe elese ni gbogbo awa eda. Ki Olohun ka a kun ara awon eni rere Re ati awon Agbesinga tooto lorile. Ki Olohun dele fun enirere wa yii.  Ki Olohun si tan imole Ihinrere Re si awon molebi oloogbe yii lati re nwo lekun nitori ise rere re ati igbe aiye rere ti o gbe. Ki Olohun si tu awon ebi re loju. Ki Olohun se ike ati ige fun Alao, Ki Olohun si fi si Ogba Ike, Ogba-Ige, Ogba Idera ti Alujana Firidaosi.

Orun re re o, Alaaji Arisekola Alao Aare Musulumi Ile Yoruba, Olu-Omo Oke Ibadan, Agbesinga Agba. O digba o! Ki Olohun Fi Ipade Wa Si Ogba Idera Alujana Firidaosi - Amin ati Amin.


 Posted By Ifiranse Eleyi Je Thursday, June 26 @ 01:21:29 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· EsinIslam Media Yoruba
· Die sii Nipa Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere:
Oye Okere Tilu Saki, Ile-ejo Ni Mogaji Ko Gbodo Gbe Igbese Kankan Bayii


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere



"Ile N Jeyan! Igbesi Aye Arisekola Alao Aare Musulumi Ile Yoruba - Igbe Aiye Rere" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com