Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ ń jẹ́ tiRẹ̀. Àti pé tiRẹ̀ ni gbogbo ẹyìn ní ọ̀run. Òun sì ni Ọlọ́gbọ́n, Alámọ̀tán.
Ṣé wọn kò rí ohun tó ń bẹ níwájú wọn àti ohun tó ń bẹ lẹ́yìn wọn ní sánmọ̀ àti ilẹ̀? Tí A bá fẹ́, Àwa ìbá jẹ́ kí ilẹ̀ ri mọ́ wọn lẹ́sẹ̀, tàbí kí Á já apá kan nínú sánmọ̀ lulẹ̀ lé wọn lórí mọ́lẹ̀. Dájúdájú àmì kan wà nínú ìyẹn fún gbogbo ẹrúsìn, olùronúpìwàdà.
Dájúdájú A ti fún (Ànábì) Dāwūd ní oore àjùlọ láti ọ̀dọ̀ Wa; Ẹ̀yin àpáta, ẹ ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú rẹ̀. (A pe) àwọn ẹyẹ náà (pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.) A sì rọ irin fún un.
(A sọ fún un) pé, ṣe àwọn ẹ̀wù irin tó máa bo ara dáadáa, ṣe òrùka fún ẹ̀wù irin náà níwọ̀n-níwọ̀n. Kí ẹ sì ṣe rere. Dájúdájú Èmi ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Wọ́n gbúnrí (níbi ẹ̀sìn). Nítorí náà, A rán adágún odò tí wọ́n mọ odi yíká sí wọn. A sì pààrọ̀ oko wọn méjèèjì fún wọn pẹ̀lú oko èso méjì mìíràn tí ó jẹ́ oko èso tó korò, oko igi àti kiní kan nínú igi sidir díẹ̀.
(Àwọn ará ìlú Saba') wí pé: "Olúwa wa, mú àwọn ìrìn-àjò wa láti ìlú kan sí ìlú mìíràn jìnnà síra wọn." Wọ́n ṣe àbòsí sí ẹ̀mí ara wọn. A sì sọ wọ́n di ìtàn. A tú wọn ká pátápátá (ìlú wọn di ahoro). Dájúdájú àwọn àmì kan wà nínú ìyẹn fún gbogbo onísùúrù, olùdúpẹ́.
Àti pé A kò rán olùkìlọ̀ kan sí ìlú kan àyàfi kí àwọn onígbẹdẹmukẹ ìlú náà wí pé: "Dájúdájú àwa ṣàì gbàgbọ́ nínú ohun tí Wọ́n fi ran yín níṣẹ́."
Wọ́n á sọ pé: "Mímọ́ ni fún Ọ! Ìwọ ni Aláàbò wa, kì í ṣe àwọn. Rárá (wọn kò jọ́sìn fún wa). Àwọn àlùjànnú ni wọ́n ń jọ́sìn fún; ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni wọ́n gbàgbọ́ nínú àwọn àlùjànnú.
Àwọn tó ṣíwájú wọn náà pe òdodo ní irọ́. (Ọwọ́ àwọn wọ̀nyí) kò sì tí ì tẹ ìdá kan ìdá mẹ́wàá nínú ohun tí A fún (àwọn tó ṣíwájú). Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n pe àwọn Òjíṣẹ́ Mi ní òpùrọ́. Báwo sì ni bí Mo ṣe (fi ìyà) kọ (aburú fún wọn) ti rí!
Sọ pé: "Tí mo bá ṣìnà, mo ṣìnà fún ẹ̀mí ara mi ni. Tí mo bá sì mọ̀nà, nípa ohun tí Olúwa mi fi ránṣẹ́ sì mi ní ìmísí ni. Dájúdájú Òun ni Olùgbọ́, Alásùn-únmọ́ ẹ̀dá."
Tí ó bá jẹ́ pé o lè rí (ẹ̀sín wọn ni) nígbà tí ẹ̀rù bá dé bá wọn (ní Ọjọ́ Àjíǹde, o máa rí i pé), kò níí sí ìmóríbọ́ kan (fún wọn). A sì máa gbá wọn mú láti àyè tó súnmọ́.
A sì fi gàgá sí ààrin àwọn àti ohun tí wọ́n ń ṣojú kòkòrò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí A ti ṣe fún àwọn ẹgbẹ́ wọn ní ìṣáájú. Dájúdájú wọ́n wà nínú iyèméjì tó gbópọn (nípa Ọjọ́ Àjíǹde).