Iná Jahanamọ wà níwájú wọn. Ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ àti ohun tí wọ́n mú ní alátìlẹ́yìn lẹ́yìn Allāhu kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kan níbi ìyà. Ìyà ńlá sì wà fún wọn.
Ẹníkẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere, fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ni. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ aburú, fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ni. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Olúwa yín ni wọn yóò da yín padà sí.
Dájúdájú A fún àwọn ọmọ 'Isrọ̄'īl ní Tírà àti ìdájọ́ ṣíṣe àti ipò Ànábì. A sì ṣe arísìkí fún wọn nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa. A sì ṣoore àjùlọ fún wọn lórí àwọn ẹ̀dá (àsìkò tiwọn).
Lẹ́yìn náà, A fi ọ́ sí ojú ọ̀nà kan nínú ọ̀rọ̀ náà (ẹ̀sìn 'Islām). Nítorí náà, tẹ̀lé e. Kí o sì má ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú àwọn tí kò nímọ̀.
Tàbí àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ aburú lérò pé A máa ṣe wọ́n gẹ́gẹ́ bí (A ti ṣe) àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, kí ìṣẹ́mí ayé wọn àti ikú wọn rí bákan náà? Ohun tí wọ́n ń dá ní ẹjọ́, ó burú.
Wọ́n wí pé: "Kò sí ìṣẹ̀mí kan mọ́ bí kò ṣe ìṣẹ̀mí ayé wa yìí; à ń kú, a sì ń ṣẹ̀mí. Àti pé kò sí n̄ǹkan tó ń pa wá bí kò ṣe ìgbà." Wọn kò sì ní ìmọ̀ kan nípa ìyẹn; wọn kò ṣe kiní kan bí kò ṣe pé wọ
Àti pé nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa tó yanjú fún wọn, àwíjàre wọn kò jẹ́ kiní kan àyàfi kí wọ́n wí pé: "Ẹ mú àwọn bàbá wa wá tí ẹ bá jẹ́ olódodo."
O sì máa rí gbogbo ìjọ kọ̀ọ̀kan lórí ìkúnlẹ̀. Wọn yó sì máa pe gbogbo ìjọ kọ̀ọ̀kan síbi ìwé iṣẹ́ wọn. Ní òní ni A óò san yín ní ẹ̀san ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Ní ti àwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́, (A óò bi wọ́n léèrè pé:) "Ǹjẹ́ wọn kì í ké àwọn āyah Mi fún yín bí?" Ṣùgbọ́n ẹ ṣègbéraga. Ẹ sì jẹ́ ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀.
Báyẹn ni nítorí pé, ẹ sọ àwọn āyah Allāhu di n̄ǹkan yẹ̀yẹ́. Àti pé ìṣẹ̀mí ayé tàn yín jẹ. Nítorí náà, ní òní wọn kò níí mú wọn jáde kúrò nínú Iná. Wọn kò sì níí fún wọn ní àyè láti ṣe ohun tí wọn yóò fi rí ìyọ́nú Allāhu.