Nígbà tí A bá sì kó àwọn ènìyàn jọ (fún Àjíǹde), àwọn òrìṣà yóò di ọ̀tá fún àwọn abọ̀rìṣà. Wọ́n sì máa tako ìjọ́sìn tí wọ́n ṣe fún wọn.
Sọ pé: "Èmi kì í ṣe àkọ́kọ́ nínú àwọn Òjíṣẹ́. Èmi kò sì mọ n̄ǹkan tí wọ́n máa ṣe fún èmi àti ẹ̀yin. Èmi kò tẹ̀lé kiní kan àyàfi ohun tí Wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi ní ìmísí. Èmi kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe olùkìlọ̀ pọ́nńbélé."
A pa á ní àsẹ fún ènìyàn pé kí ó máa ṣe dáadáa sí àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì. Ìyá rẹ̀ ní oyún rẹ̀ pẹ̀lú wàhálà. Ó sì bí i pẹ̀lú wàhálà. Oyún rẹ̀ àti gbígba ọmú lẹ́nu rẹ̀ jẹ́ ọgbọ̀n oṣù. (Ó sì ń tọ́ ọ) títí ó fi dàgbà dáadáa, tí ó fi di ọmọ ogójì ọdún, ó sì sọ pé: "Olúwa mi, fi mọ̀ mí kí n̄g máa dúpẹ́ ìdẹ̀ra Rẹ, èyí tí Ó fi ṣe ìdẹ̀ra fún mi àti fún àwọn òbí mi méjèèjì, kí n̄g sì máa ṣe iṣẹ́ rere, èyí tí O yọ́nú sí. Kí O sì ṣe rere fún mi lórí àwọn àrọ́mọdọ́mọ mi. Dájúdájú èmi ti ronú pìwàdà sí ọ̀dọ̀ Rẹ. Dájúdájú èmi sì wà nínú àwọn mùsùlùmí."
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí A máa gba iṣẹ́ rere tí wọ́n ṣe níṣẹ́, A sì máa ṣe àmójúkúrò níbi àwọn aburú iṣẹ́ wọn; wọ́n máa wà nínú àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. (Ó jẹ́) àdéhùn òdodo tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn.
Àwọn (aláìgbàgbọ́) wọ̀nyẹn ni àwọn tí ọ̀rọ̀ náà ti kò lé lórí nínú àwọn ìjọ kan tí ó ti ré kọjá ṣíwájú wọn nínú àwọn àlùjànnú àti ènìyàn. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ẹni òfò.
Wọ́n wí pé: "Ṣé ìwọ wá bá wa láti ṣẹ́ wa lórí kúrò níbi àwọn òrìṣà wa ni? Mú ohun tí ò ń ṣe ìlérí rẹ̀ fún wa wá tí ìwọ bá wà nínú àwọn olódodo."
Ó ń pa gbogbo n̄ǹkan rẹ́ (ìyẹn nínú ìlú wọn) pẹ̀lú àṣẹ Olúwa rẹ̀. Nígbà náà, wọ́n di ẹni tí wọn kò rí mọ́ àfi àwọn ibùgbé wọn. Báyẹn ni A ṣe ń san ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ẹ̀san.
A kúkú ṣe àyè ìrọ̀rùn (nílé ayé) fún wọn nínú èyí tí A kò ṣe àyè ìrọ̀rùn (irú rẹ̀) fún ẹ̀yin nínú rẹ̀. A sì fún wọn ní ìgbọ́rọ̀, àwọn ìríran àti àwọn ọkàn. Àmọ́ ìgbọ́rọ̀ wọn àti àwọn ìríran wọn pẹ̀lú àwọn ọkàn wọn kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kan kan níbi ìyà nítorí pé, wọ́n ń ṣe àtakò sí àwọn āyah Allāhu. Àti pé ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì dìyà tó yí wọn po.
Àwọn ọlọ́hun tí wọ́n sọ di ohun tí ó máa mú wọn súnmọ́ (ìgbàlà) lẹ́yìn Allāhu kò ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ mọ́? Rárá (kò lè sí àrànṣe fún wọn)! Wọ́n ti di ofò mọ́ wọn lọ́wọ́. Ìyẹn sì ni (ọlọ́hun) irọ́ wọn àti ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́.
Nítorí náà, ṣe sùúrù gẹ́gẹ́ bí àwọn onípinnu ọkàn nínú àwọn Òjíṣẹ́ ti ṣe sùúrù. Má ṣe bá wọn wá ìyà pẹ̀lú ìkánjú. Ní ọjọ́ tí wọ́n bá rí ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn, wọn yóò dà bí ẹni pé wọn kò gbé ilé ayé (yìí) tayọ àkókò kan nínú ọ̀sán. Ìkéde (ẹ̀sìn nìyí fún wọn). Ta ni ó sì máa parun bí kò ṣe ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.