Prev  

59. Surah Al-Hashr سورة الحشر

  Next  




Ayah  59:1  الأية
    +/- -/+  
بِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
سَبَّحَ لِلَّهِ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۖ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ
Yoruba
 
Ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ ń ṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

Ayah  59:2  الأية
    +/- -/+  
هُوَ الَّذِي أَخْرَجَ الَّذِينَ كَفَرُوا مِنْ أَهْلِ الْكِتَابِ مِن دِيَارِهِمْ لِأَوَّلِ الْحَشْرِ ۚ مَا ظَنَنتُمْ أَن يَخْرُجُوا ۖ وَظَنُّوا أَنَّهُم مَّانِعَتُهُمْ حُصُونُهُم مِّنَ اللهِ فَأَتَاهُمُ اللهُ مِنْ حَيْثُ لَمْ يَحْتَسِبُوا ۖ وَقَذَفَ فِي قُلُوبِهِمُ الرُّعْبَ ۚ يُخْرِبُونَ بُيُوتَهُم بِأَيْدِيهِمْ وَأَيْدِي الْمُؤْمِنِينَ فَاعْتَبِرُوا يَا أُولِي الْأَبْصَارِ
Yoruba
 
Òun ni Ẹni tí Ó mú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn onítírà jáde kúrò nínú ilé wọn fún àkọ́kọ́ àkójọ (wọ́n sínú ìlú Ṣām). Ẹ̀yin kò lérò pé wọn yóò jáde. Àwọn náà sì lérò pé dájúdájú àwọn odi ilé wọn yóò dáàbò bo àwọn lọ́dọ̀ Allāhu. Ṣùgbọ́n Allāhu wá bá wọn ní ibi tí wọn kò ti lérò; Allāhu sì ju ìbẹ̀rù sínú ọkàn wọn. Wọ́n ń fi ọwọ́ ara wọn àti ọwọ́ àwọn onígbàgbọ́ òdodo wó àwọn ilé wọn. Nítorí náà, ẹ wòye, ẹ̀yin tí ẹ ní ojú ìríran.

Ayah  59:3  الأية
    +/- -/+  
وَلَوْلَا أَن كَتَبَ اللهُ عَلَيْهِمُ الْجَلَاءَ لَعَذَّبَهُمْ فِي الدُّنْيَا ۖ وَلَهُمْ فِي الْآخِرَةِ عَذَابُ النَّارِ
Yoruba
 
Àti pé tí kò bá jẹ́ pé Allāhu ti kọ ìjáde kúrò nínú ìlú Mọdīnah lé àwọn onítírà lórí ni, dájúdájú (Allāhu) ìbá jẹ wọ́n níyà nílé ayé. Ìyà Iná sì tún wà fún wọn ní ọ̀run.

Ayah  59:4  الأية
    +/- -/+  
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ شَاقُّوا اللهَ وَرَسُولَهُ ۖ وَمَن يُشَاقِّ اللهَ فَإِنَّ اللهَ شَدِيدُ الْعِقَابِ
Yoruba
 
Ìyẹn nítorí pé, dájúdájú wọ́n yapa (ọ̀rọ̀) Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì yapa (ọ̀rọ̀) Allāhu, dájúdájú Allāhu le níbi ìyà.

Ayah  59:5  الأية
    +/- -/+  
مَا قَطَعْتُم مِّن لِّينَةٍ أَوْ تَرَكْتُمُوهَا قَائِمَةً عَلَىٰ أُصُولِهَا فَبِإِذْنِ اللهِ وَلِيُخْزِيَ الْفَاسِقِينَ
Yoruba
 
Ẹ̀yin kò níí ge igi dàbínù kan tàbí kí ẹ fi sílẹ̀ kí ó dúró sórí gbòǹgbò rẹ̀, (àfi) pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. (Ó rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí Ó lè dójú ti àwọn òbìlẹ̀jẹ́ ni.

Ayah  59:6  الأية
    +/- -/+  
وَمَا أَفَاءَ اللهُ عَلَىٰ رَسُولِهِ مِنْهُمْ فَمَا أَوْجَفْتُمْ عَلَيْهِ مِنْ خَيْلٍ وَلَا رِكَابٍ وَلَٰكِنَّ اللهَ يُسَلِّطُ رُسُلَهُ عَلَىٰ مَن يَشَاءُ ۚ وَاللهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
Yoruba
 
Ohunkóhun tí Allāhu bá dá padà láti ọ̀dọ̀ wọn fún Òjíṣẹ́ Rẹ̀, tí ẹ kò gbé ẹṣin àti ràkúnmí sáré fún (ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ni). Ṣùgbọ́n Allāhu yóò máa fún àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ní agbára lórí ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.

Ayah  59:7  الأية
    +/- -/+  
مَّا أَفَاءَ اللهُ عَلَىٰ رَسُولِهِ مِنْ أَهْلِ الْقُرَىٰ فَلِلَّهِ وَلِلرَّسُولِ وَلِذِي الْقُرْبَىٰ وَالْيَتَامَىٰ وَالْمَسَاكِينِ وَابْنِ السَّبِيلِ كَيْ لَا يَكُونَ دُولَةً بَيْنَ الْأَغْنِيَاءِ مِنكُمْ ۚ وَمَا آتَاكُمُ الرَّسُولُ فَخُذُوهُ وَمَا نَهَاكُمْ عَنْهُ فَانتَهُوا ۚ وَاتَّقُوا اللهَ ۖ إِنَّ اللهَ شَدِيدُ الْعِقَابِ
Yoruba
 
Ohunkóhun tí Allāhu bá dá padà láti ọ̀dọ̀ àwọn ará ìlú fún Òjíṣẹ́ Rẹ̀, (ó jẹ́) ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ àti ti àwọn ìbátan, àwọn ọmọ òrukàn, àwọn tálíkà àti onírìn-àjò (tí agara dá) nítorí kí ó má baá jẹ́ àdápín láààrin àwọn ọlọ́rọ̀ nínú yín. Ohunkóhun tí Òjíṣẹ́ bá fún yín, ẹ gbà á. Ohunkóhun tí ó bá sì kọ̀ fún yín, ẹ jáwọ́ nínú rẹ. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu le níbi ìyà.

Ayah  59:8  الأية
    +/- -/+  
لِلْفُقَرَاءِ الْمُهَاجِرِينَ الَّذِينَ أُخْرِجُوا مِن دِيَارِهِمْ وَأَمْوَالِهِمْ يَبْتَغُونَ فَضْلًا مِّنَ اللهِ وَرِضْوَانًا وَيَنصُرُونَ اللهَ وَرَسُولَهُ ۚ أُولَٰئِكَ هُمُ الصَّادِقُونَ
Yoruba
 
(Ìkógun náà tún wà fún) àwọn aláìní, (ìyẹn,) al-Muhājirūn, àwọn tí wọ́n lé jáde kúrò nínú ilé wọn àti níbi dúkìá wọn, tí wọ́n sì ń wá oore àjùlọ àti ìyọ́nú láti ọ̀dọ̀ Allāhu, tí wọ́n sì ń ṣàrànṣe fún (ẹ̀sìn) Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni olódodo.

Ayah  59:9  الأية
    +/- -/+  
وَالَّذِينَ تَبَوَّءُوا الدَّارَ وَالْإِيمَانَ مِن قَبْلِهِمْ يُحِبُّونَ مَنْ هَاجَرَ إِلَيْهِمْ وَلَا يَجِدُونَ فِي صُدُورِهِمْ حَاجَةً مِّمَّا أُوتُوا وَيُؤْثِرُونَ عَلَىٰ أَنفُسِهِمْ وَلَوْ كَانَ بِهِمْ خَصَاصَةٌ ۚ وَمَن يُوقَ شُحَّ نَفْسِهِ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الْمُفْلِحُونَ
Yoruba
 
Àwọn tó ń gbé nínú ìlú Mọdīnah, tí wọ́n sì ní ìgbàgbọ́ òdodo ṣíwájú wọn, wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn tó fi ìlú Mọkkah sílẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ wọn (ní ìlú Mọdīnah). Wọn kò sì ní bùkátà kan nínú igbá-àyà wọn sí n̄ǹkan tí wọ́n bá fún wọn. Wọ́n sì ń gbé àjùlọ fún wọn lórí ẹ̀mí ara wọn, kódà kí ó jẹ́ pé àwọn gan-an ní bùkátà (sí ohun tí wọ́n fún wọn). Ẹnikẹ́ni tí A bá ṣọ́ níbi ahun àti ọ̀kánjúà inú ẹ̀mí rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni olùjèrè.

Ayah  59:10  الأية
    +/- -/+  
وَالَّذِينَ جَاءُوا مِن بَعْدِهِمْ يَقُولُونَ رَبَّنَا اغْفِرْ لَنَا وَلِإِخْوَانِنَا الَّذِينَ سَبَقُونَا بِالْإِيمَانِ وَلَا تَجْعَلْ فِي قُلُوبِنَا غِلًّا لِّلَّذِينَ آمَنُوا رَبَّنَا إِنَّكَ رَءُوفٌ رَّحِيمٌ
Yoruba
 
Àwọn tó dé lẹ́yìn wọn ń sọ pé: "Olúwa wa, foríjin àwa àti àwọn ọmọ ìyá wa tó ṣíwájú wa nínú ìgbàgbọ́ òdodo. Má ṣe jẹ́ kí inúnibíni wà nínú ọkàn wa sí àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo. Olúwa wa, dájúdájú Ìwọ ni Aláàánú, Àṣàkẹ́-ọ̀run."

Ayah  59:11  الأية
    +/- -/+  
أَلَمْ تَرَ إِلَى الَّذِينَ نَافَقُوا يَقُولُونَ لِإِخْوَانِهِمُ الَّذِينَ كَفَرُوا مِنْ أَهْلِ الْكِتَابِ لَئِنْ أُخْرِجْتُمْ لَنَخْرُجَنَّ مَعَكُمْ وَلَا نُطِيعُ فِيكُمْ أَحَدًا أَبَدًا وَإِن قُوتِلْتُمْ لَنَنصُرَنَّكُمْ وَاللهُ يَشْهَدُ إِنَّهُمْ لَكَاذِبُونَ
Yoruba
 
Ṣé o ò rí àwọn tó ṣàgàbà ǹgebè nínú ẹ̀sìn tí wọ́n ń wí fún àwọn ọmọ ìyá wọn, àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn onítírà, pé "Dájúdájú tí wọ́n bá le yín jáde (kúrò nínú ìlú), àwa náà gbọ́dọ̀ jáde pẹ̀lú yín ni. Àwa kò sì níí tẹ̀lé àṣẹ ẹnì kan lórí yín láéláé. Tí wọ́n bá sì gbé ogun dìde si yín, àwa gbọ́dọ̀ ṣe ìrànlọ́wọ́ fún yín ni." Allāhu sì ń jẹ́rìí pé dájúdájú òpùrọ́ ni wọ́n.

Ayah  59:12  الأية
    +/- -/+  
لَئِنْ أُخْرِجُوا لَا يَخْرُجُونَ مَعَهُمْ وَلَئِن قُوتِلُوا لَا يَنصُرُونَهُمْ وَلَئِن نَّصَرُوهُمْ لَيُوَلُّنَّ الْأَدْبَارَ ثُمَّ لَا يُنصَرُونَ
Yoruba
 
Dájúdájú tí wọ́n bá lé wọn jáde, wọn kò níí jáde pẹ̀lú wọn. Dájúdájú tí wọ́n bá sì gbógun tì wọ́n, wọn kò níí ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wọn. Tí wọ́n bá sì wá ìrànlọ́wọ́ wọn, dájúdájú wọn yóò pẹ̀yìndà (láti fẹsẹ̀ fẹ́ẹ). Lẹ́yìn náà, wọn kò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.

Ayah  59:13  الأية
    +/- -/+  
لَأَنتُمْ أَشَدُّ رَهْبَةً فِي صُدُورِهِم مِّنَ اللهِ ۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ قَوْمٌ لَّا يَفْقَهُونَ
Yoruba
 
Dájúdájú ẹ̀yin ni ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ tó lágbára ju Allāhu lọ nínú igbá-àyà wọn. Ìyẹn nítorí pé, dájúdájú àwọn ni ìjọ tí kò gbọ́ àgbọ́yé.

Ayah  59:14  الأية
    +/- -/+  
لَا يُقَاتِلُونَكُمْ جَمِيعًا إِلَّا فِي قُرًى مُّحَصَّنَةٍ أَوْ مِن وَرَاءِ جُدُرٍ ۚ بَأْسُهُم بَيْنَهُمْ شَدِيدٌ ۚ تَحْسَبُهُمْ جَمِيعًا وَقُلُوبُهُمْ شَتَّىٰ ۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ قَوْمٌ لَّا يَعْقِلُونَ
Yoruba
 
Wọn kò lè parapọ̀ dojú ìjà kọ yín àfi (kí wọ́n) wà nínú odi ìlú tàbí (kí wọ́n wà) lẹ́yìn àwọn ògiri. Ogun ààrin ara wọn gan-an le. Ò ń lérò pé wọ́n wà ní ìrẹ́pọ̀ ni, ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sì ni ọkàn wọn wà. Ìyẹn nítorí pé, dájúdájú àwọn ni ìjọ tí kò ní làákàyè.

Ayah  59:15  الأية
    +/- -/+  
كَمَثَلِ الَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ قَرِيبًا ۖ ذَاقُوا وَبَالَ أَمْرِهِمْ وَلَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ
Yoruba
 
Àpẹ̀ẹrẹ wọn dà bí àwọn tó ṣíwájú wọn tí kò tí ì pẹ́ lọ títí. Wọ́n tọ́ aburú ọ̀rọ̀ ara wọn wò. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn.

Ayah  59:16  الأية
    +/- -/+  
كَمَثَلِ الشَّيْطَانِ إِذْ قَالَ لِلْإِنسَانِ اكْفُرْ فَلَمَّا كَفَرَ قَالَ إِنِّي بَرِيءٌ مِّنكَ إِنِّي أَخَافُ اللهَ رَبَّ الْعَالَمِينَ
Yoruba
 
Àpẹ̀ẹrẹ wọn dà bí Èṣù nígbà tí ó bá wí fún ènìyàn pé: "Ṣàì gbàgbọ́." Nígbà tí ó bá ṣàì gbàgbọ́ (tán), ó máa wí pé: "Dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ kúrò nínú ọ̀rọ̀ rẹ. Dájúdájú èmi ń páyà Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá."

Ayah  59:17  الأية
    +/- -/+  
فَكَانَ عَاقِبَتَهُمَا أَنَّهُمَا فِي النَّارِ خَالِدَيْنِ فِيهَا ۚ وَذَٰلِكَ جَزَاءُ الظَّالِمِينَ
Yoruba
 
Nítorí náà, ìkángun àwọn méjèèjì ni pé, dájúdájú àwọn méjèèjì yóò wà nínú Iná. Olùṣegbére ni àwọn méjèèjì nínú rẹ̀. Ìyẹn sì ni ẹ̀san àwọn alábòsí.

Ayah  59:18  الأية
    +/- -/+  
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا اتَّقُوا اللهَ وَلْتَنظُرْ نَفْسٌ مَّا قَدَّمَتْ لِغَدٍ ۖ وَاتَّقُوا اللهَ ۚ إِنَّ اللهَ خَبِيرٌ بِمَا تَعْمَلُونَ
Yoruba
 
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ̀mí kan sì wòye sí ohun tí ó tì ṣíwájú fún ọ̀la (àlùkìyáámọ̀). Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

Ayah  59:19  الأية
    +/- -/+  
وَلَا تَكُونُوا كَالَّذِينَ نَسُوا اللهَ فَأَنسَاهُمْ أَنفُسَهُمْ ۚ أُولَٰئِكَ هُمُ الْفَاسِقُونَ
Yoruba
 
Kí ẹ sì má ṣe dà bí àwọn tó gbàgbé Allāhu. (Allāhu) sì mú wọn gbàgbé ẹ̀mí ara wọn. Àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni arúfin.

Ayah  59:20  الأية
    +/- -/+  
لَا يَسْتَوِي أَصْحَابُ النَّارِ وَأَصْحَابُ الْجَنَّةِ ۚ أَصْحَابُ الْجَنَّةِ هُمُ الْفَائِزُونَ
Yoruba
 
Àwọn èrò inú Iná àti àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra kò dọ́gba. Àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, àwọn ni olùjèrè.

Ayah  59:21  الأية
    +/- -/+  
لَوْ أَنزَلْنَا هَٰذَا الْقُرْآنَ عَلَىٰ جَبَلٍ لَّرَأَيْتَهُ خَاشِعًا مُّتَصَدِّعًا مِّنْ خَشْيَةِ اللهِ ۚ وَتِلْكَ الْأَمْثَالُ نَضْرِبُهَا لِلنَّاسِ لَعَلَّهُمْ يَتَفَكَّرُونَ
Yoruba
 
Tí ó bá jẹ́ pé A sọ al-Ƙur'ān yìí kalẹ̀ sórí àpáta ni, dájúdájú o máa rí i tí ó máa wálẹ̀, tí ó máa fọ́ pẹ́tẹpẹ̀tẹ fún ìpáyà Allāhu. Ìwọ̀nyí ni àwọn àkàwé tí À ń fi lélẹ̀ fún àwọn ènìyàn nítorí kí wọ́n lè ronú jinlẹ̀.

Ayah  59:22  الأية
    +/- -/+  
هُوَ اللهُ الَّذِي لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ۖ عَالِمُ الْغَيْبِ وَالشَّهَادَةِ ۖ هُوَ الرَّحْمَٰنُ الرَّحِيمُ
Yoruba
 
Òun ni Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun, Onímọ̀ ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba. Òun ni Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

Ayah  59:23  الأية
    +/- -/+  
هُوَ اللهُ الَّذِي لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ الْمَلِكُ الْقُدُّوسُ السَّلَامُ الْمُؤْمِنُ الْمُهَيْمِنُ الْعَزِيزُ الْجَبَّارُ الْمُتَكَبِّرُ ۚ سُبْحَانَ اللهِ عَمَّا يُشْرِكُونَ
Yoruba
 
Òun ni Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Ọba (ẹ̀dá), Ẹni-mímọ́ jùlọ, Aláìlábùkù, Olùjẹ́rìí-Òjíṣẹ́-Rẹ̀, Olùjẹ́rìí-ẹ̀dá, Alágbára, Olùjẹni-nípá, Atóbi. Mímọ́ ni fún Allāhu tayọ ohun tí wọ́n fi ń ṣẹbọ sí I.

Ayah  59:24  الأية
    +/- -/+  
هُوَ اللهُ الْخَالِقُ الْبَارِئُ الْمُصَوِّرُ ۖ لَهُ الْأَسْمَاءُ الْحُسْنَىٰ ۚ يُسَبِّحُ لَهُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ
Yoruba
 
Òun ni Allāhu, Ẹlẹ́dàá, Olùpilẹ̀-ẹ̀dá, Olùyàwòrán-ẹ̀dá. TiRẹ̀ ni àwọn orúkọ tó dára jùlọ. Ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ń ṣàfọ̀mọ́ fún Un. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.





© EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us