Ṣé wọn kò wòye pé ó pọ̀ nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn? Àwọn tí A fún ní ipò lórí ilẹ̀, (irú) ipò tí A kò fún ẹ̀yin. A sì rọ omi òjò púpọ̀ fún wọn láti sánmọ̀. A sì ṣe àwọn odò tí ń ṣàn sí ìsàlẹ̀ (ilé) wọn. Lẹ́yìn náà, A pa wọ́n rẹ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. A sì dá àwọn ìran mìíràn lẹ́yìn wọn.
Tí ó bá jẹ́ pé A sọ tírà kan tí A kọ sínú tákàdá kalẹ̀ fún ọ, kí wọ́n sì fi ọwọ́ ara wọn gbá a mú (báyìí), dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ìbá wí pé: "Kí ni èyí bí kò ṣe idán pọ́nńbélé."
Wọ́n sì wí pé: "Nítorí kí ni Wọn kò ṣe sọ mọlāika kan kalẹ̀ fún un?" Tí ó bá jẹ́ pé A sọ mọlāika kan kalẹ̀, ọ̀rọ̀ ìbá ti yanjú. Lẹ́yìn náà, A ò sì níí lọ́ wọn lára mọ́.
Tí ó bá jẹ́ pé A ṣe é ní mọlāika ni, Àwa ìbá ṣe é ní ọkùnrin. Àti pé Àwa ìbá tún fi ohun tí wọ́n ń darú mọ́ra wọn lójú rú wọn lójú.
Wọ́n kúkú ti fi àwọn Òjíṣẹ́ kan ṣe yẹ̀yẹ́ ṣíwájú rẹ! Nítorí náà, ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì dìyà tó yí àwọn tó ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ po.
Àwọn tí A fún ní Tírà, wọ́n mọ̀ ọ́n gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe mọ àwọn ọmọ wọn. Àwọn tó ṣe ẹ̀mí wọn lófò (sínú àìgbàgbọ́), wọn kò sí níí gbàgbọ́.
Lẹ́yìn náà, ìfòòró wọn (lórí ìbéèrè náà) kò jẹ́ kiní kan tayọ pé wọ́n á wí pé: "A fi Allāhu Olúwa wa búra, àwa kì í ṣe ọ̀ṣẹbọ."
Tí ó bá jẹ́ pé o rí (wọn ni) nígbà tí wọ́n bá dá wọn dúró síbi Iná, wọ́n sì máa wí pé: "Yéè! Kí ó sì jẹ́ pé wọ́n dá wa padà (sílé ayé), àwa kò sì níí pe àwọn āyah Olúwa wa nírọ́ (mọ́), a sì máa wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo."
Kò rí bẹ́ẹ̀, ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ láti ẹ̀yìn wá ti hàn sí wọn ni. Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n bá dá wọn padà (sílé ayé), wọn yóò kúkú padà síbi ohun tí A kọ̀ fún wọn. Dájúdájú òpùrọ́ mà ni wọ́n.
Dájúdájú àwọn tó pe pípàdé Allāhu (lọ́run) nírọ́ ti ṣòfò débi pé nígbà tí Àkókò náà bá dé bá wọn lójijì, wọ́n á wí pé: "A ká àbámọ̀ lórí ohun tí a fi jáfira." Wọ́n sì máa ru ẹ̀ṣẹ̀ wọn sẹ́yìn wọn. Kíyè sí i, ohun tí wọn yóò rù lẹ́ṣẹ̀ sì burú.
A kúkú ti mọ̀ pé ohun tí wọ́n ń wí ń bà ọ́ nínú jẹ́. Dájúdájú wọn kò lè pè ọ́ ní òpùrọ́, ṣùgbọ́n àwọn alábòsí ń tako àwọn āyah Allāhu ni.
Wọ́n kúkú ti pe àwọn Òjíṣẹ́ kan lópùrọ́ ṣíwájú rẹ. Wọ́n sì ṣe sùúrù lórí n̄ǹkan tí wọ́n fi pè wọ́n ní òpùrọ́. Wọ́n sì fi ìnira kàn wọ́n títí di ìgbà tí àrànṣe Wa fi dé bá wọn. Kò sì sí aláyìípadà kan fún àwọn ọ̀rọ̀ Allāhu. Dájúdájú ìró àwọn Òjíṣẹ́ ti dé bá ọ.
Ọ̀wọ́ ẹni tó ń jẹ́pè ni àwọn tó ń gbọ́rọ̀. (Ní ti) àwọn òkú, Allāhu yó gbé wọn dìde. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò dá wọn padà sí.
Wọ́n tún wí pé: "Nítorí kí ni wọn kò ṣe sọ àmì kan kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀?" Sọ pé: "Dájúdájú Allāhu lágbára láti sọ àmì kan kalẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀."
Kò sí ohun abẹ̀mí kan (tó ń rìn) lórí ilẹ̀, tàbí ẹyẹ kan tó ń fò pẹ̀lú apá rẹ̀ méjèèjì bí kò ṣe àwọn ẹ̀dá kan (bí) irú yín. A kò fi kiní kan sílẹ̀ (láì ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀) sínú Tírà (ìyẹn, ummul-kitāb). Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Olúwa wọn ni wọn yóò kó wọn jọ sí.
Dájúdájú A ti ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ kan ṣíwájú rẹ. A sì fi àwọn ìpọ́njú àti àwọn àìlera gbá wọn mú nítorí kí wọ́n lè rawọ́ rasẹ̀ (sí Allāhu).
Wọn kò ṣe rawọ́ rasẹ̀ (sí Wa) nígbà tí ìyà Wa dé bá wọn! Ṣùgbọ́n ọkàn wọn le koko. Èṣù sì ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ ní ọ̀ṣọ́ fún wọn.
Nítorí náà, nígbà tí wọ́n gbàgbé ohun tí A fi ṣe ìrántí fún wọn, A ṣí àwọn ọ̀nà gbogbo n̄ǹkan sílẹ̀ fún wọn, títí di ìgbà tí wọ́n yọ àyọ̀pọ̀rọ́ sí ohun tí A fún wọn (nínú oore ayé.), A sì mú wọn lójijì. Wọ́n sì di olùsọ̀rètínù.
Má ṣe lé àwọn tó ń pe Olúwa wọn ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́ dànù; wọ́n ń fẹ́ Ojú rere Rẹ̀ ni. Ìṣirò-iṣẹ́ wọn kò sí ní ọrùn rẹ ní ọ̀nà kan kan. Kò sì sí ìṣirò-iṣẹ́ tìrẹ náà ní ọrùn wọn ní ọ̀nà kan kan. Tí o bá lé wọn dànù, o sì máa wà nínú àwọn alábòsí.
Báyẹn ni A ṣe fi apá kan wọn ṣe àdánwò fún apá kan nítorí kí (àwọn aláìgbàgbọ́) lè wí pé: "Ṣé àwọn (mùsùlùmí aláìní) wọ̀nyí náà ni Allāhu ṣe ìdẹ̀ra (ìmọ̀nà) fún láààrin wa!?" Ṣé Allāhu kọ́ l'Ó nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùdúpẹ́ ni?
Pa àwọn tó sọ ẹ̀sìn wọn di eré ṣíṣe àti ìranù tì. Ìṣẹ̀mí ayé sì tàn wọ́n jẹ. Fi al-Ƙur'ān ṣe ìṣítí nítorí kí wọ́n má baà fa ẹ̀mí kalẹ̀ sínú ìparun nípasẹ̀ ohun tí ó ṣe níṣẹ́ (aburú). Kò sì sí aláàbò tàbí olùṣìpẹ̀ kan fún un lẹ́yìn Allāhu. Tí ó bá sì fi gbogbo ààrọ̀ ṣèràpadà, A ò níí gbà á lọ́wọ́ rẹ̀. Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí wọ́n fà kalẹ̀ fún ìparun nípasẹ̀ ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Ohun mímu tó gbóná parí àti ìyà ẹlẹ́ta eléro ń bẹ fún wọn nítorí pé wọ́n máa ń ṣàì gbàgbọ́.
Báyẹn ni wọ́n ṣe fi (àwọn àmì) ìjọba Allahu tí ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ han (Ànábì) 'Ibrọ̄hīm nítorí kí ó lè wà nínú àwọn alámọ̀dájú.