Prev  

65. Surah At-Talâq سورة الطلاق

  Next  




Ayah  65:1  الأية
    +/- -/+  
بِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
يَا أَيُّهَا النَّبِيُّ إِذَا طَلَّقْتُمُ النِّسَاءَ فَطَلِّقُوهُنَّ لِعِدَّتِهِنَّ وَأَحْصُوا الْعِدَّةَ ۖ وَاتَّقُوا اللهَ رَبَّكُمْ ۖ لَا تُخْرِجُوهُنَّ مِن بُيُوتِهِنَّ وَلَا يَخْرُجْنَ إِلَّا أَن يَأْتِينَ بِفَاحِشَةٍ مُّبَيِّنَةٍ ۚ وَتِلْكَ حُدُودُ اللهِ ۚ وَمَن يَتَعَدَّ حُدُودَ اللهِ فَقَدْ ظَلَمَ نَفْسَهُ ۚ لَا تَدْرِي لَعَلَّ اللهَ يُحْدِثُ بَعْدَ ذَٰلِكَ أَمْرًا
Yoruba
 
Ìwọ Ànábì, nígbà tí ẹ bá fẹ́ kọ àwọn obìnrin sílẹ̀, ẹ kọ̀ wọ́n sílẹ̀ pẹ̀lú òǹkà ọjọ́ opó ìkọ̀sílẹ̀ tí wọ́n máa ṣe. Kí ẹ sì ṣọ́ òǹkà ọjọ́ opó ìkọ̀sílẹ̀ náà. Kí ẹ bẹ̀rù Allāhu, Olúwa yín. Ẹ má ṣe mú wọn jáde kúrò nínú ilé wọn, àwọn náà kò sì gbọdọ̀ jáde àfi tí wọ́n bá lọ ṣe ìbàjẹ́ tó fojú hàn. Ìwọ̀nyẹn sì ni àwọn ẹnu-ààlà òfin tí Allāhu gbékalẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tayọ àwọn ẹnu-ààlà òfin tí Allāhu gbékalẹ̀, o kúkú ti ṣàbòsí sí ẹ̀mí́ara rẹ̀. Ìwọ kò sì mọ̀ bóyá Allāhu máa mú ọ̀rọ̀ titun kan ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn.

Ayah  65:2  الأية
    +/- -/+  
فَإِذَا بَلَغْنَ أَجَلَهُنَّ فَأَمْسِكُوهُنَّ بِمَعْرُوفٍ أَوْ فَارِقُوهُنَّ بِمَعْرُوفٍ وَأَشْهِدُوا ذَوَيْ عَدْلٍ مِّنكُمْ وَأَقِيمُوا الشَّهَادَةَ لِلَّهِ ۚ ذَٰلِكُمْ يُوعَظُ بِهِ مَن كَانَ يُؤْمِنُ بِاللهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ ۚ وَمَن يَتَّقِ اللهَ يَجْعَل لَّهُ مَخْرَجًا
Yoruba
 
Nígbà tí wọ́n bá fẹ́ parí òǹkà ọjọ́ opó wọn, ẹ mú wọn mọ́ra ní ọ̀nà tó dára tàbí kí ẹ kọ̀ wọ́n sílẹ̀ ní ọ̀nà tó dára. Ẹ fi àwọn onídéédé méjì nínú yín jẹ́rìí sí i. Kí ẹ sì gbé ìjẹ́rìí náà dúró ní tìtorí ti Allāhu. Ìyẹn ni À ń fi ṣe wáàsí fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń bẹ̀rù Allāhu, Ó máa fún un ní ọ̀nà àbáyọ (nínú ìṣòro).

Ayah  65:3  الأية
    +/- -/+  
وَيَرْزُقْهُ مِنْ حَيْثُ لَا يَحْتَسِبُ ۚ وَمَن يَتَوَكَّلْ عَلَى اللهِ فَهُوَ حَسْبُهُ ۚ إِنَّ اللهَ بَالِغُ أَمْرِهِ ۚ قَدْ جَعَلَ اللهُ لِكُلِّ شَيْءٍ قَدْرًا
Yoruba
 
Ó sì máa pèsè fún un ní àyè tí kò ti rokàn. Àti pé ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé Allāhu, Ó máa tó o. Dájúdájú Allāhu yóò mú àṣẹ Rẹ̀ ṣẹ. Dájúdájú Allāhu ti kọ òdíwọ̀n àkókò fún gbogbo n̄ǹkan.

Ayah  65:4  الأية
    +/- -/+  
وَاللَّائِي يَئِسْنَ مِنَ الْمَحِيضِ مِن نِّسَائِكُمْ إِنِ ارْتَبْتُمْ فَعِدَّتُهُنَّ ثَلَاثَةُ أَشْهُرٍ وَاللَّائِي لَمْ يَحِضْنَ ۚ وَأُولَاتُ الْأَحْمَالِ أَجَلُهُنَّ أَن يَضَعْنَ حَمْلَهُنَّ ۚ وَمَن يَتَّقِ اللهَ يَجْعَل لَّهُ مِنْ أَمْرِهِ يُسْرًا
Yoruba
 
Àwọn obìnrin tó ti sọ̀rètí nù nípa n̄ǹkan oṣù ṣíṣe nínú àwọn obìnrin yín, tí ẹ bá ṣeyèméjì, òǹkà ọjọ́ ìkọ̀sílẹ̀ wọn ni oṣù mẹ́ta. (Bẹ́ẹ̀ náà ni fún) àwọn tí kò tí ì máa ṣe n̄ǹkan oṣù. Àwọn olóyún, ìparí òǹkà ọjọ́ opó ìkọ̀sílẹ̀ tiwọn ni pé kí wọ́n bí oyún inú wọn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń bẹ̀rù Allāhu, Ó máa ṣe ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ìrọ̀rùn fún un.

Ayah  65:5  الأية
    +/- -/+  
ذَٰلِكَ أَمْرُ اللهِ أَنزَلَهُ إِلَيْكُمْ ۚ وَمَن يَتَّقِ اللهَ يُكَفِّرْ عَنْهُ سَيِّئَاتِهِ وَيُعْظِمْ لَهُ أَجْرًا
Yoruba
 
Ìyẹn ni àṣẹ Allāhu, tí Ó sọ̀kalẹ̀ fún yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń bẹ̀rù Allāhu, Ó máa pa àwọn àṣìṣe rẹ̀ rẹ́. Ó sì máa jẹ́ kí ẹ̀san rẹ̀ tóbi.

Ayah  65:6  الأية
    +/- -/+  
أَسْكِنُوهُنَّ مِنْ حَيْثُ سَكَنتُم مِّن وُجْدِكُمْ وَلَا تُضَارُّوهُنَّ لِتُضَيِّقُوا عَلَيْهِنَّ ۚ وَإِن كُنَّ أُولَاتِ حَمْلٍ فَأَنفِقُوا عَلَيْهِنَّ حَتَّىٰ يَضَعْنَ حَمْلَهُنَّ ۚ فَإِنْ أَرْضَعْنَ لَكُمْ فَآتُوهُنَّ أُجُورَهُنَّ ۖ وَأْتَمِرُوا بَيْنَكُم بِمَعْرُوفٍ ۖ وَإِن تَعَاسَرْتُمْ فَسَتُرْضِعُ لَهُ أُخْرَىٰ
Yoruba
 
Ẹ fún wọn ní ibùgbé nínú ibùgbé yín bí àyè ṣe gbà yín mọ. Ẹ má ṣe ni wọ́n lára láti kó ìfúnpinpin bá wọn. Tí wọ́n bá jẹ́ olóyún, ẹ náwó lé wọn lórí títí wọn yóò fi bí oyún inú wọn. Tí wọ́n bá ń fún ọmọ yín ní ọyàn mu, ẹ fún wọn ní owó-ọ̀yà wọn. Ẹ dámọ̀ràn láààrin ara yín ní ọ̀nà tó dára. Tí ọ̀rọ̀ kò bá sì rọgbọ láààrin ara yín, kí ẹlòmíìràn bá ọkọ (fún ọmọ) ní ọyàn mu.

Ayah  65:7  الأية
    +/- -/+  
لِيُنفِقْ ذُو سَعَةٍ مِّن سَعَتِهِ ۖ وَمَن قُدِرَ عَلَيْهِ رِزْقُهُ فَلْيُنفِقْ مِمَّا آتَاهُ اللهُ ۚ لَا يُكَلِّفُ اللهُ نَفْسًا إِلَّا مَا آتَاهَا ۚ سَيَجْعَلُ اللهُ بَعْدَ عُسْرٍ يُسْرًا
Yoruba
 
Kí ọlọ́rọ̀ ná nínú ọrọ̀ rẹ̀. Ẹni tí A sì díwọ̀n arísìkí rẹ̀ fún (níwọ̀nba), kí ó ná nínú ohun tí Allāhu fún un. Allāhu kò làbọ ẹ̀mí kan lọ́rùn àyàfi n̄ǹkan tí Ó fún un. Allāhu yó sì mú ìrọ̀rùn wá lẹ́yìn ìnira.

Ayah  65:8  الأية
    +/- -/+  
وَكَأَيِّن مِّن قَرْيَةٍ عَتَتْ عَنْ أَمْرِ رَبِّهَا وَرُسُلِهِ فَحَاسَبْنَاهَا حِسَابًا شَدِيدًا وَعَذَّبْنَاهَا عَذَابًا نُّكْرًا
Yoruba
 
Mélòó mélòó nínú àwọn ìlú tí wọ́n yapa àṣẹ Olúwa Rẹ̀ àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. A sì máa ṣírò iṣẹ́ wọn ní ìṣírò líle. Àti pé A máa jẹ wọ́n níyà tó burú gan-an.

Ayah  65:9  الأية
    +/- -/+  
فَذَاقَتْ وَبَالَ أَمْرِهَا وَكَانَ عَاقِبَةُ أَمْرِهَا خُسْرًا
Yoruba
 
Nítorí náà, wọn máa tọ́ ìyà ọ̀ràn wọn wò. Ìkángun ọ̀rọ̀ wọn sì jẹ́ òfò.

Ayah  65:10  الأية
    +/- -/+  
أَعَدَّ اللهُ لَهُمْ عَذَابًا شَدِيدًا ۖ فَاتَّقُوا اللهَ يَا أُولِي الْأَلْبَابِ الَّذِينَ آمَنُوا ۚ قَدْ أَنزَلَ اللهُ إِلَيْكُمْ ذِكْرًا
Yoruba
 
Allāhu ti pèsè ìyà líle sílẹ̀ dè wọ́n. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, ẹ̀yin onílàákàyè tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo. Allāhu kúkú ti sọ tírà ìrántí kalẹ̀ fún yín.

Ayah  65:11  الأية
    +/- -/+  
رَّسُولًا يَتْلُو عَلَيْكُمْ آيَاتِ اللهِ مُبَيِّنَاتٍ لِّيُخْرِجَ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ مِنَ الظُّلُمَاتِ إِلَى النُّورِ ۚ وَمَن يُؤْمِن بِاللهِ وَيَعْمَلْ صَالِحًا يُدْخِلْهُ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِن تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا أَبَدًا ۖ قَدْ أَحْسَنَ اللهُ لَهُ رِزْقًا
Yoruba
 
Òjíṣẹ́ kan tí ó máa ké àwọn āyah Allāhu tó yanjú fún yín nítorí kí ó lè mú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n tún ṣe àwọn iṣẹ́ rere, kúrò nínú àwọn òkùnkùn lọ sínú ìmọ́lẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàgbọ́ nínú Allāhu ní òdodo, tí ó sì ń ṣe iṣẹ́ rere, Ó máa mú un wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé. Dájúdájú Allāhu ti ṣe arísìkí rẹ̀ (ìjẹ-ìmu àti ìgbádùn rẹ̀) ní dáadáa fún un.

Ayah  65:12  الأية
    +/- -/+  
اللهُ الَّذِي خَلَقَ سَبْعَ سَمَاوَاتٍ وَمِنَ الْأَرْضِ مِثْلَهُنَّ يَتَنَزَّلُ الْأَمْرُ بَيْنَهُنَّ لِتَعْلَمُوا أَنَّ اللهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ وَأَنَّ اللهَ قَدْ أَحَاطَ بِكُلِّ شَيْءٍ عِلْمًا
Yoruba
 
Allāhu ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ méje àti ilẹ̀ ní (òǹkà) irú rẹ̀. Àṣẹ ń sọ̀kalẹ̀ láààrin wọn nítorí kí ẹ lè mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan. Àti pé dájúdájú Allāhu fi ìmọ̀ rọ̀gbà yí gbogbo n̄ǹkan ká.





© EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us