Prev  

69. Surah Al-Hâqqah سورة الحاقة

  Next  




Ayah  69:1  الأية
    +/- -/+  
بِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ


Ayah  69:3  الأية
    +/- -/+  
وَمَا أَدْرَاكَ مَا الْحَاقَّةُ
Yoruba
 
Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo náà?

Ayah  69:4  الأية
    +/- -/+  
كَذَّبَتْ ثَمُودُ وَعَادٌ بِالْقَارِعَةِ
Yoruba
 
Àwọn ìjọ Thamūd àti ìjọ ‘Ād pe Àjíǹde (ajámọláya bí àrá) ní irọ́.

Ayah  69:5  الأية
    +/- -/+  
فَأَمَّا ثَمُودُ فَأُهْلِكُوا بِالطَّاغِيَةِ
Yoruba
 
Ní ti ìjọ Thamūd, wọ́n fi igbe tó tayọ ẹnu-ààlà pa wọ́n rẹ́.

Ayah  69:6  الأية
    +/- -/+  
وَأَمَّا عَادٌ فَأُهْلِكُوا بِرِيحٍ صَرْصَرٍ عَاتِيَةٍ
Yoruba
 
Ní ti ìjọ ‘Ād, wọ́n fi atẹ́gùn líle tó tayọ ẹnu-ààlà pa wọ́n rẹ́.

Ayah  69:7  الأية
    +/- -/+  
سَخَّرَهَا عَلَيْهِمْ سَبْعَ لَيَالٍ وَثَمَانِيَةَ أَيَّامٍ حُسُومًا فَتَرَى الْقَوْمَ فِيهَا صَرْعَىٰ كَأَنَّهُمْ أَعْجَازُ نَخْلٍ خَاوِيَةٍ
Yoruba
 
Ó dẹ ẹ́ sí wọn fún òru méje àti ọ̀sán mẹ́jọ láì dáwọ́ dúró. O sì máa rí ìjọ náà tí wọ́n ti kú sínú rẹ̀ bí ẹni pé kùkùté igi dàbínù tó ti luhò nínú ni wọ́n.

Ayah  69:8  الأية
    +/- -/+  
فَهَلْ تَرَىٰ لَهُم مِّن بَاقِيَةٍ
Yoruba
 
Ǹjẹ́ o rí ẹnì kan nínú wọn tó ṣẹ́ kù bí?

Ayah  69:9  الأية
    +/- -/+  
وَجَاءَ فِرْعَوْنُ وَمَن قَبْلَهُ وَالْمُؤْتَفِكَاتُ بِالْخَاطِئَةِ
Yoruba
 
Fir‘aon àti àwọn tó ṣíwájú rẹ̀ àti àwọn ìlú tí wọ́n dojú rẹ̀ bolẹ̀ dé pẹ̀lú àwọn àṣìṣe.

Ayah  69:10  الأية
    +/- -/+  
فَعَصَوْا رَسُولَ رَبِّهِمْ فَأَخَذَهُمْ أَخْذَةً رَّابِيَةً
Yoruba
 
Wọ́n yapa Òjíṣẹ́ Olúwa wọn. Ó sì gbá wọn mú ní ìgbámú tóléken̄kà.

Ayah  69:11  الأية
    +/- -/+  
إِنَّا لَمَّا طَغَى الْمَاءُ حَمَلْنَاكُمْ فِي الْجَارِيَةِ
Yoruba
 
Dájúdájú nígbà tí omi tayọ ẹnu-ààlà. A gbe yín gun ọkọ̀ ojú-omi.

Ayah  69:12  الأية
    +/- -/+  
لِنَجْعَلَهَا لَكُمْ تَذْكِرَةً وَتَعِيَهَا أُذُنٌ وَاعِيَةٌ
Yoruba
 
Nítorí kí Á lè fi ṣe ìrántí fún yín àti nítorí kí etí tó ń ṣọ́ n̄ǹkan lè ṣọ́ ọ.

Ayah  69:13  الأية
    +/- -/+  
فَإِذَا نُفِخَ فِي الصُّورِ نَفْخَةٌ وَاحِدَةٌ
Yoruba
 
Nígbà tí wọ́n bá fọn fèrè oníwo fún ikú ní fífọn ẹyọ kan,

Ayah  69:14  الأية
    +/- -/+  
وَحُمِلَتِ الْأَرْضُ وَالْجِبَالُ فَدُكَّتَا دَكَّةً وَاحِدَةً
Yoruba
 
Tí wọ́n gbé ilẹ̀ àti àpáta sókè, tí wọ́n sì rún méjèèjì wómúwómú ní rírún ẹ̀ẹ̀ kan,

Ayah  69:15  الأية
    +/- -/+  
فَيَوْمَئِذٍ وَقَعَتِ الْوَاقِعَةُ
Yoruba
 
Ní ọjọ́ yẹn ni Ìṣẹ̀lẹ̀ máa ṣẹlẹ̀.

Ayah  69:16  الأية
    +/- -/+  
وَانشَقَّتِ السَّمَاءُ فَهِيَ يَوْمَئِذٍ وَاهِيَةٌ
Yoruba
 
Àti pé sánmọ̀ yó fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Ó sì máa fúyẹ́ gẹgẹ ní ọjọ́ yẹn.

Ayah  69:17  الأية
    +/- -/+  
وَالْمَلَكُ عَلَىٰ أَرْجَائِهَا ۚ وَيَحْمِلُ عَرْشَ رَبِّكَ فَوْقَهُمْ يَوْمَئِذٍ ثَمَانِيَةٌ
Yoruba
 
Àwọn mọlāika sì máa wà ní àwọn ẹ̀gbẹ́ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Àti pé ní ọjọ́ yẹn, lókè̀wọn, àwọn (mọlāika) mẹ́jọ ni wọ́n máa ru Ìtẹ́ Olúwa rẹ.

Ayah  69:18  الأية
    +/- -/+  
يَوْمَئِذٍ تُعْرَضُونَ لَا تَخْفَىٰ مِنكُمْ خَافِيَةٌ
Yoruba
 
Ní ọjọ́ yẹn, wọn yóò máa ṣẹ́rí yín wá (fún ìṣírò-iṣẹ́). Kò sì níí sí àṣírí yín kan tó máa pamọ́ (fún Wa).

Ayah  69:19  الأية
    +/- -/+  
فَأَمَّا مَنْ أُوتِيَ كِتَابَهُ بِيَمِينِهِ فَيَقُولُ هَاؤُمُ اقْرَءُوا كِتَابِيَهْ
Yoruba
 
Nítorí náà, ní ti ẹni tí wọ́n bá fún ní tírà rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ó máa sọ pé: "Ẹ gbà, ẹ ka tírà mi wò.

Ayah  69:20  الأية
    +/- -/+  
إِنِّي ظَنَنتُ أَنِّي مُلَاقٍ حِسَابِيَهْ
Yoruba
 
Dájúdájú èmi ti mọ àmọ̀dájú pé dájúdájú èmi yóò bá ìṣírò-iṣẹ́ mi pàdé."

Ayah  69:21  الأية
    +/- -/+  
فَهُوَ فِي عِيشَةٍ رَّاضِيَةٍ
Yoruba
 
Nítorí náà, ó máa wà nínú ìṣẹ̀mí tó máa yọ́nú sí


Ayah  69:23  الأية
    +/- -/+  

Ayah  69:24  الأية
    +/- -/+  
كُلُوا وَاشْرَبُوا هَنِيئًا بِمَا أَسْلَفْتُمْ فِي الْأَيَّامِ الْخَالِيَةِ
Yoruba
 
Ẹ jẹ, kí ẹ sì mu pẹ̀lú ìgbàdún nítorí ohun tí ẹ tì síwájú nínú àwọn ọjọ́ tí ó ti ré kọjá.

Ayah  69:25  الأية
    +/- -/+  
وَأَمَّا مَنْ أُوتِيَ كِتَابَهُ بِشِمَالِهِ فَيَقُولُ يَا لَيْتَنِي لَمْ أُوتَ كِتَابِيَهْ
Yoruba
 
Ní ti ẹni tí wọ́n bá sì fún ní tírà rẹ̀ ní ọwọ́ òsì rẹ̀, ó máa wí pé: "Háà! Kí wọ́n sì má fún mi ni tírà mi!

Ayah  69:26  الأية
    +/- -/+  
وَلَمْ أَدْرِ مَا حِسَابِيَهْ
Yoruba
 
Àti pé kí èmi sì má mọ ohun tí ìṣírò-iṣẹ́ mi jẹ́.

Ayah  69:27  الأية
    +/- -/+  
يَا لَيْتَهَا كَانَتِ الْقَاضِيَةَ
Yoruba
 
Háà! Kí ikú sì jẹ́ òpin (ọ̀rọ̀ ẹ̀dá).

Ayah  69:28  الأية
    +/- -/+  
مَا أَغْنَىٰ عَنِّي مَالِيَهْ ۜ
Yoruba
 
Dúkìá mi kò sì rọ̀ mí lọ́rọ̀.


Ayah  69:30  الأية
    +/- -/+  

Ayah  69:31  الأية
    +/- -/+  
ثُمَّ الْجَحِيمَ صَلُّوهُ
Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, inú iná Jẹhīm ni kí ẹ mú un wọ̀.

Ayah  69:32  الأية
    +/- -/+  
ثُمَّ فِي سِلْسِلَةٍ ذَرْعُهَا سَبْعُونَ ذِرَاعًا فَاسْلُكُوهُ
Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, inú ẹ̀wọ̀n tí gígùn rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin gígùn thar‘u ni kí ẹ kì í sí.

Ayah  69:33  الأية
    +/- -/+  
إِنَّهُ كَانَ لَا يُؤْمِنُ بِاللهِ الْعَظِيمِ
Yoruba
 
Dájúdájú òun kì í gbàgbọ́ nínú Allāhu, Atóbi.

Ayah  69:34  الأية
    +/- -/+  
وَلَا يَحُضُّ عَلَىٰ طَعَامِ الْمِسْكِينِ
Yoruba
 
Kì í sì gba ènìyàn níyànjú láti bọ́ àwọn mẹ̀kúnnù.

Ayah  69:35  الأية
    +/- -/+  
فَلَيْسَ لَهُ الْيَوْمَ هَاهُنَا حَمِيمٌ
Yoruba
 
Nítorí náà, kò níí sí ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ kan fún un níbí yìí ní òní.

Ayah  69:36  الأية
    +/- -/+  
وَلَا طَعَامٌ إِلَّا مِنْ غِسْلِينٍ
Yoruba
 
Kò sì níí sí oúnjẹ kan (fún un) bí kò ṣe (oúnjẹ) àwọnúwẹ̀jẹ̀.

Ayah  69:37  الأية
    +/- -/+  
لَّا يَأْكُلُهُ إِلَّا الْخَاطِئُونَ
Yoruba
 
Kò sí ẹni tí ó máa jẹ ẹ́ bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.

Ayah  69:38  الأية
    +/- -/+  
فَلَا أُقْسِمُ بِمَا تُبْصِرُونَ
Yoruba
 
Nítorí náà, Èmi ń fi ohun tí ẹ̀ ń fojú rí búra


Ayah  69:40  الأية
    +/- -/+  
إِنَّهُ لَقَوْلُ رَسُولٍ كَرِيمٍ
Yoruba
 
Dájúdájú al-Ƙur'ān ni ọ̀rọ̀ (tí A fi rán) Òjíṣẹ́, alápọ̀n-ọ́nlé.

Ayah  69:41  الأية
    +/- -/+  
وَمَا هُوَ بِقَوْلِ شَاعِرٍ ۚ قَلِيلًا مَّا تُؤْمِنُونَ
Yoruba
 
Kì í ṣe ọ̀rọ̀ eléwì. Ohun tí ẹ gbàgbọ́ kéré púpọ̀.

Ayah  69:42  الأية
    +/- -/+  
وَلَا بِقَوْلِ كَاهِنٍ ۚ قَلِيلًا مَّا تَذَكَّرُونَ
Yoruba
 
Kì í sì ṣe ọ̀rọ̀ adábigba. Díẹ̀ lẹ̀ ń lò nínú ìrántí.

Ayah  69:43  الأية
    +/- -/+  
تَنزِيلٌ مِّن رَّبِّ الْعَالَمِينَ
Yoruba
 
Wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

Ayah  69:44  الأية
    +/- -/+  
وَلَوْ تَقَوَّلَ عَلَيْنَا بَعْضَ الْأَقَاوِيلِ
Yoruba
 
Tí ó bá jẹ́ pé (Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ) dá àdápa apá kan ọ̀rọ̀ náà mọ́ Wa ni,

Ayah  69:45  الأية
    +/- -/+  
لَأَخَذْنَا مِنْهُ بِالْيَمِينِ
Yoruba
 
Àwa ìbá gbá a mú lọ́wọ́ ọ̀tún.

Ayah  69:46  الأية
    +/- -/+  
ثُمَّ لَقَطَعْنَا مِنْهُ الْوَتِينَ
Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, Àwa ìbá já isan ọrùn rẹ̀.

Ayah  69:47  الأية
    +/- -/+  
فَمَا مِنكُم مِّنْ أَحَدٍ عَنْهُ حَاجِزِينَ
Yoruba
 
Kò sì sí ẹnì kan nínú yín tí ó máa gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ (Wa).

Ayah  69:48  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّهُ لَتَذْكِرَةٌ لِّلْمُتَّقِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú (al-Ƙur'ān) ni ìrántí fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).

Ayah  69:49  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّا لَنَعْلَمُ أَنَّ مِنكُم مُّكَذِّبِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú Àwa sì mọ̀ pé àwọn tó ń pe al-Ƙur'ān ní irọ́ wà nínú yín.

Ayah  69:50  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّهُ لَحَسْرَةٌ عَلَى الْكَافِرِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú al-Ƙur'ān máa jẹ́ àbámọ̀ ńlá fún àwọn aláìgbàgbọ́.

Ayah  69:51  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّهُ لَحَقُّ الْيَقِينِ
Yoruba
 
Dájúdájú al-Ƙur'ān ni òdodo tó dájú.

Ayah  69:52  الأية
    +/- -/+  
فَسَبِّحْ بِاسْمِ رَبِّكَ الْعَظِيمِ
Yoruba
 
Nítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa Rẹ, Atóbi.





© EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us