Tírà kan tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ (nìyí). Nítorí náà, wàhálà (iyèméjì) kan kò gbọ́dọ̀ sí nínú ọkàn rẹ lórí rẹ̀ láti fi ṣe ìkìlọ̀ àti ìrántí fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
Nítorí náà, dájúdájú A óò bi àwọn tí A ránṣẹ́ sí léèrè (nípa ìjẹ́pè). Dájúdájú A ó sì bi àwọn Òjíṣẹ́ léèrè (nípa ìjíṣẹ́).
Ọmọ (Ànábì) Ādam, ẹ má ṣe jẹ́ kí Èṣù kó ìfòòró ba yín gẹ́gẹ́ bí ó ṣe yọ àwọn òbí yín méjèèjì jáde kúrò nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ó gba aṣọ kúrò lára àwọn méjèèjì nítorí kí ó lè fi ìhòhò wọn hàn wọ́n. Dájúdájú ó ń ri yín; òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ (ń ri yín) ní àyè tí ẹ̀yin kò ti rí wọn. Dájúdájú Àwa fi Èṣù ṣe ọ̀rẹ́ fún àwọn tí kò gbàgbọ́.
Nígbà tí wọ́n bá ṣe ìbàjẹ́ kan, wọ́n á wí pé: "A bá àwọn bàbá wa lórí rẹ̀ ni. Allāhu l'Ó sì pa á láṣẹ fún wa." Sọ pé: "Dájúdájú Allāhu kì í p'àṣẹ ìbàjẹ́. Ṣé ẹ fẹ́ ṣàfitì ohun tí ẹ ò nímọ̀ nípa rẹ̀ sọ́dọ̀ Allāhu ni?"
Apá kan ni Ó fi mọ̀nà, apa kan sì ni ìṣìnà kò lé lórí. (Nítorí pé) dájúdájú wọ́n mú àwọn èṣù ní aláfẹ̀yìntí lẹ́yìn Allāhu. Wọ́n sì ń lérò pé dájúdájú àwọn ni olùmọ̀nà.
Àkókò kan ti wà fún ìjọ kọ̀ọ̀kan; nígbà tí àkókò wọn bá sì dé, wọn kò níí lè sún un ṣíwájú di àkókò kan, wọn kò sì níí lè fà á sẹ́yìn.
Nítorí náà, ta l'ó ṣàbòsí ju ẹni tó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu tàbí tó pe àwọn āyah Rẹ̀ ní irọ́? Ìpín àwọn wọ̀nyẹn nínú kádàrá yóò máa tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ títí di ìgbà̀tí àwọn Òjíṣẹ́ Wa yóò wá bá wọn, tí wọn yóò gba ẹ̀mí wọn. Wọn yó sì sọ pé: "Níbo ni àwọn n̄ǹkan tí ẹ̀yin ń pè lẹ́yìn Allāhu wà?" Wọn yóò wí pé: "Wọ́n ti di òfò mọ́ wa lọ́wọ́." Wọ́n sì jẹ́rìí léra wọn lórí pé dájúdájú àwọn jẹ́ aláìgbàgbọ́."
Àwọn tó sì gbàgbọ́ lódodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere - A kò làbọ ẹ̀mí kan lọ́rùn àfi ìwọ̀n agbára rẹ̀ - àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.
Àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra yóò pe àwọn èrò inú Iná pé: "A ti rí ohun tí Olúwa wa ṣe àdéhùn rẹ̀ fún wa ní òdodo. Ǹjẹ́ ẹ̀yin náà rí ohun tí Olúwa yín ṣe àdéhùn (rẹ̀ fún yín) ní òdodo?" Wọn yóò wí pé: "Bẹ́ẹ̀ ni." Olùpèpè kan yó sì pèpè láààrin wọn pé: "Kí ibi dandan Allāhu máa bẹ lórí àwọn alábòsí."
Èrò inú Iná yóò pe èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra pé: "Ẹ fún wa nínú omi tàbí nínú ohun tí Allāhu pa lésè fún yín." Wọn yóò sọ pé: "Dájúdájú Allāhu ti ṣe méjèèjì ní èèwọ̀ fún àwọn aláìgbàgbọ́."
Àwọn tó sọ ẹ̀sìn wọn di ìranù àti eré ṣíṣe, tí ìṣẹ̀mí ayé sì kó ẹ̀tàn bá wọn, ní òní ni A óò gbàgbé wọn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe gbàgbé ìpàdé ọjọ́ wọn ti òní yìí àti (bí) wọ́n ṣe ń tako àwọn āyah Wa.
Kí ni wọ́n ń retí bí kò ṣe ẹ̀san Rẹ̀? Lọ́jọ́ tí ẹ̀san Rẹ̀ bá dé, àwọn tó gbàgbé rẹ̀ ṣíwájú yóò wí pé: "Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ Olúwa wa ti mú òdodo wá. Nítorí náà, ǹjẹ́ a lè rí àwọn olùṣìpẹ̀, kí wọ́n wá ṣìpẹ̀ fún wa tàbí kí wọ́n dá wa padà sílé ayé, kí á lè ṣe iṣẹ́ mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí a máa ń ṣe?" Dájúdájú wọ́n ti ṣe ẹ̀mí wọn lófò. Ohun tí wọ́n sì ń dá ní àdápa irọ́ sì di òfo mọ́ wọn lọ́wọ́.
Wọ́n sì pè é lópùrọ́. Nítorí náà, A gba òun àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ là nínú ọkọ̀ ojú-omi. A sì tẹ àwọn tó pe àwọn āyah Wa nírọ́ rì. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ tó fọ́jú (nípa òdodo).
Wọ́n wí pé: "Ṣé o wá bá wa nítorí kí á lè jọ́sìn fún Allāhu nìkan ṣoṣo àti nítorí kí á lè pa ohun tí àwọn bàbá ńlá wa ń jọ́sìn fún tì? Nítorí náà, mú ohun tí o ṣe ní ìlérí fún wa ṣẹ tí o bá wà nínú àwọn olódodo."
Nítorí náà, pẹ̀lú àánú láti ọ̀dọ̀ Wa, A gba òun àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ là. A sì pa àwọn tó pe àwọn āyah Wa nírọ́ run pátápátá; wọn kì í ṣe onígbàgbọ́ òdodo.
Nítorí náà, wọ́n gún abo ràkúnmí náà pa. Wọ́n sì tàpá sí àṣẹ Olúwa wọn. Wọ́n sì wí pé: "Sọ̄lih, mú ohun tí o ṣe ní ìlérí fún wa ṣẹ tí o bá wà nínú àwọn Òjíṣẹ́."