Prev  

81. Surah At-Takwîr سورة التكوير

  Next  




Ayah  81:1  الأية
    +/- -/+  
بِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
إِذَا الشَّمْسُ كُوِّرَتْ
Yoruba
 
Nígbà tí wọ́n bá ká òòrùn kóróbójó dànù,

Ayah  81:2  الأية
    +/- -/+  
وَإِذَا النُّجُومُ انكَدَرَتْ
Yoruba
 
Àti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá já bọ́ káàkiri,

Ayah  81:3  الأية
    +/- -/+  
وَإِذَا الْجِبَالُ سُيِّرَتْ
Yoruba
 
Àti nígbà tí wọ́n bá mú àwọn àpáta rìn (kúrò ní àyè wọn, tí wọ́n kù wọ́n dànù),

Ayah  81:4  الأية
    +/- -/+  
وَإِذَا الْعِشَارُ عُطِّلَتْ
Yoruba
 
Àti nígbà tí wọ́n bá pa àwọn ràkúnmí aboyún tì,

Ayah  81:5  الأية
    +/- -/+  
وَإِذَا الْوُحُوشُ حُشِرَتْ
Yoruba
 
Àti nígbà tí wọ́n bá ko àwọn ẹranko jọ,

Ayah  81:6  الأية
    +/- -/+  
وَإِذَا الْبِحَارُ سُجِّرَتْ
Yoruba
 
Àti nígbà tí wọ́n bá mú àwọn agbami odò gbiná,

Ayah  81:7  الأية
    +/- -/+  
وَإِذَا النُّفُوسُ زُوِّجَتْ
Yoruba
 
Àti nígbà tí wọ́n bá so àwọn ẹ̀mí pọ̀ mọ́ra wọn, (ẹni rere pẹ̀lú ẹni rere, ẹni ibi pẹ̀lú ẹni ibi)

Ayah  81:8  الأية
    +/- -/+  
وَإِذَا الْمَوْءُودَةُ سُئِلَتْ
Yoruba
 
Àti nígbà tí ọmọbìnrin tí wọ́n bò mọ́lẹ̀ láàyè bá bèèrè pé

Ayah  81:9  الأية
    +/- -/+  

Ayah  81:10  الأية
    +/- -/+  
وَإِذَا الصُّحُفُ نُشِرَتْ
Yoruba
 
Àti nígbà tí wọ́n bá ṣí àwọn tákàdá (iṣẹ́ ẹ̀dá) sílẹ̀,

Ayah  81:11  الأية
    +/- -/+  
وَإِذَا السَّمَاءُ كُشِطَتْ
Yoruba
 
Àti nígbà tí wọ́n bá ká sánmọ̀ kúrò lókè,

Ayah  81:12  الأية
    +/- -/+  
وَإِذَا الْجَحِيمُ سُعِّرَتْ
Yoruba
 
Àti nígbà tí wọ́n bá mú iná Jẹhīm jò fòfò,

Ayah  81:13  الأية
    +/- -/+  
وَإِذَا الْجَنَّةُ أُزْلِفَتْ
Yoruba
 
Àti nígbà tí wọ́n bá sún Ọgbà Ìdẹ̀ra mọ́ (àwọn onígbàgbọ́ òdodo),

Ayah  81:14  الأية
    +/- -/+  
عَلِمَتْ نَفْسٌ مَّا أَحْضَرَتْ
Yoruba
 
(nígbà náà ni) ẹ̀mí (kọ̀ọ̀kan) yóò mọ ohun tí ó mú wá (nínú iṣẹ́ ire àti iṣẹ́ ibi).

Ayah  81:15  الأية
    +/- -/+  
فَلَا أُقْسِمُ بِالْخُنَّسِ
Yoruba
 
Nítorí náà, Èmi (Allāhu) ń fi àwọn ìràwọ̀ tó ń yọ ní alẹ́, tó ń wọ̀ọ̀kùn ní ọ̀sán búra,

Ayah  81:16  الأية
    +/- -/+  
الْجَوَارِ الْكُنَّسِ
Yoruba
 
(ìyẹn) àwọn ìràwọ̀ tó ń rìn lọ rìn bọ̀, tó ń wọ̀ọ̀kùn sí ibùwọ̀ wọn.

Ayah  81:17  الأية
    +/- -/+  
وَاللَّيْلِ إِذَا عَسْعَسَ
Yoruba
 
Mo tún fi alẹ́ nígbà tí ó bá lọ búra.

Ayah  81:18  الأية
    +/- -/+  
وَالصُّبْحِ إِذَا تَنَفَّسَ
Yoruba
 
Mo tún fi òwúrọ̀ nígbà tí ó bá mọ́lẹ̀ búra.

Ayah  81:19  الأية
    +/- -/+  
إِنَّهُ لَقَوْلُ رَسُولٍ كَرِيمٍ
Yoruba
 
Dájúdájú (al-Ƙur'ān) ni ọ̀rọ̀ (tí A fi rán Jibrīl) Òjíṣẹ́, alápọ̀n-ọ́nlé,

Ayah  81:20  الأية
    +/- -/+  
ذِي قُوَّةٍ عِندَ ذِي الْعَرْشِ مَكِينٍ
Yoruba
 
Alágbára, ẹni pàtàkì ní ọ̀dọ̀ Ẹni t'Ó ni Ìtẹ́-ọlá,

Ayah  81:21  الأية
    +/- -/+  
مُّطَاعٍ ثَمَّ أَمِينٍ
Yoruba
 
ẹni tí wọ́n ń tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀ níbẹ̀ yẹn (nínú sánmọ̀), olùfọkàntán.

Ayah  81:22  الأية
    +/- -/+  
وَمَا صَاحِبُكُم بِمَجْنُونٍ
Yoruba
 
Àti pé ẹni yín (Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) kì í ṣe wèrè.

Ayah  81:23  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدْ رَآهُ بِالْأُفُقِ الْمُبِينِ
Yoruba
 
Ó kúkú rí i nínú òfurufú kedere.

Ayah  81:24  الأية
    +/- -/+  
وَمَا هُوَ عَلَى الْغَيْبِ بِضَنِينٍ
Yoruba
 
Àti pé kì í ṣe ahun (tàbí ẹni-afurasí) lórí ìró ìkọ̀kọ̀ (tí A fi ránṣẹ́ sí i).

Ayah  81:25  الأية
    +/- -/+  
وَمَا هُوَ بِقَوْلِ شَيْطَانٍ رَّجِيمٍ
Yoruba
 
Al-Ƙur'ān kì í sì ṣe ọ̀rọ̀ (tí A fi rán) Èṣù, ẹni ẹ̀kọ̀.


Ayah  81:27  الأية
    +/- -/+  
إِنْ هُوَ إِلَّا ذِكْرٌ لِّلْعَالَمِينَ
Yoruba
 
Kí sì ni al-Ƙur'ān bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá.

Ayah  81:28  الأية
    +/- -/+  
لِمَن شَاءَ مِنكُمْ أَن يَسْتَقِيمَ
Yoruba
 
(Ó wà) fún ẹni tí ó bá fẹ́ nínú yín láti dúró déédé.

Ayah  81:29  الأية
    +/- -/+  
وَمَا تَشَاءُونَ إِلَّا أَن يَشَاءَ اللهُ رَبُّ الْعَالَمِينَ
Yoruba
 
Ẹ̀yin kò sì níí fẹ́ (láti dúró déédé) àyàfi tí Allāhu bá fẹ́, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.





© EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us