Prev  

95. Surah At-Tin سورة التين

  Next  




Ayah  95:1  الأية
    +/- -/+  
بِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ


Ayah  95:3  الأية
    +/- -/+  
وَهَٰذَا الْبَلَدِ الْأَمِينِ
Yoruba
 
Ó tún fi ìlú ìfàyàbalẹ̀ yìí búra.

Ayah  95:4  الأية
    +/- -/+  
لَقَدْ خَلَقْنَا الْإِنسَانَ فِي أَحْسَنِ تَقْوِيمٍ
Yoruba
 
Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn pẹ̀lú ìrísí tó dára jùlọ.

Ayah  95:5  الأية
    +/- -/+  
ثُمَّ رَدَدْنَاهُ أَسْفَلَ سَافِلِينَ
Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, A máa dá a padà sí ìsàlẹ̀ pátápátá (nínú Iná).

Ayah  95:6  الأية
    +/- -/+  
إِلَّا الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ فَلَهُمْ أَجْرٌ غَيْرُ مَمْنُونٍ
Yoruba
 
Àyàfi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Nítorí náà, ẹ̀san tí kò níí pin (tí kò níí pẹ̀dín) ń bẹ fún wọn.

Ayah  95:7  الأية
    +/- -/+  
فَمَا يُكَذِّبُكَ بَعْدُ بِالدِّينِ
Yoruba
 
Ta l'ó tún ń pè ọ́ ní òpùrọ́ nípa Ọjọ́ ẹ̀san lẹ́yìn (ọ̀rọ̀ yìí)?

Ayah  95:8  الأية
    +/- -/+  
أَلَيْسَ اللهُ بِأَحْكَمِ الْحَاكِمِينَ
Yoruba
 
Ṣé Allāhu kọ́ ni Ẹni t'Ó mọ ẹ̀jọ́ dá jùlọ nínú àwọn adájọ́ ni?





© EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us