Prev  

11. Surah Hûd سورة هود

  Next  




1st Ayah  1  الأية ١الأولي
بِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
الر ۚ كِتَابٌ أُحْكِمَتْ آيَاتُهُ ثُمَّ فُصِّلَتْ مِن لَّدُنْ حَكِيمٍ خَبِيرٍ
Alif-lam-ra kitabun ohkimatayatuhu thumma fussilat min ladun hakeeminkhabeer

Yoruba
 
'Alif lām rọ̄. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.) (Èyí ni) Tírà tí wọ́n ti to àwọn āyah inú rẹ̀ ní àtògún régé, lẹ́yìn náà wọ́n ṣàlàyé rẹ̀ yékéyéké láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́gbọ́n, Alámọ̀tán.

Ayah  11:2  الأية
أَلَّا تَعْبُدُوا إِلَّا اللهَ ۚ إِنَّنِي لَكُم مِّنْهُ نَذِيرٌ وَبَشِيرٌ
Alla taAAbudoo illa Allahainnanee lakum minhu natheerun wabasheer

Yoruba
 
(A ti ṣàlàyé rẹ̀) pé ẹ má jọ́sìn fún kiní kan àfi Allāhu. Dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ àti oníròó ìdùnnú fún yín láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

Ayah  11:3  الأية
وَأَنِ اسْتَغْفِرُوا رَبَّكُمْ ثُمَّ تُوبُوا إِلَيْهِ يُمَتِّعْكُم مَّتَاعًا حَسَنًا إِلَىٰ أَجَلٍ مُّسَمًّى وَيُؤْتِ كُلَّ ذِي فَضْلٍ فَضْلَهُ ۖ وَإِن تَوَلَّوْا فَإِنِّي أَخَافُ عَلَيْكُمْ عَذَابَ يَوْمٍ كَبِيرٍ
Waani istaghfiroo rabbakum thumma toobooilayhi yumattiAAkum mataAAan hasanan ilaajalin musamman wayu/ti kulla thee fadlin fadlahuwa-in tawallaw fa-inee akhafu AAalaykum AAathabayawmin kabeer

Yoruba
 
(A ti ṣàlàyé rẹ̀) pé kí ẹ tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Olúwa yín. Lẹ́yìn náà, kí ẹ ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Rẹ̀. Ó máa fún yín ní ìgbádùn dáadáa títí di gbèdéke àkókò kan. Ó máa fún oníṣẹ́-àṣegbọrẹ ní ẹ̀san iṣẹ́ àṣegbọrẹ rẹ̀. Tí ẹ bá sì pẹ̀yìndà, dájúdájú èmi ń páyà ìyà Ọjọ́ ńlá fún yín.

Ayah  11:4  الأية
إِلَى اللهِ مَرْجِعُكُمْ ۖ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
Ila Allahi marjiAAukum wahuwaAAala kulli shay-in qadeer

Yoruba
 
Ọ̀dọ̀ Allāhu ni ibùpadàsí yín. Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.

Ayah  11:5  الأية
أَلَا إِنَّهُمْ يَثْنُونَ صُدُورَهُمْ لِيَسْتَخْفُوا مِنْهُ ۚ أَلَا حِينَ يَسْتَغْشُونَ ثِيَابَهُمْ يَعْلَمُ مَا يُسِرُّونَ وَمَا يُعْلِنُونَ ۚ إِنَّهُ عَلِيمٌ بِذَاتِ الصُّدُورِ
Ala innahum yathnoona sudoorahumliyastakhfoo minhu ala heena yastaghshoona thiyabahumyaAAlamu ma yusirroona wama yuAAlinoona innahuAAaleemun bithati assudoor

Yoruba
 
Gbọ́, dájúdájú àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí ń ká (iyèméjì àti ọ̀tá) sínú igbá-àyà wọn láti lè fara pamọ́ fún Allāhu. Kíyè sí i, nígbà tí wọ́n ń yíṣọ wọn bora, Allāhu mọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi pamọ́ àti n̄ǹkan tí wọ́n ń ṣàfi hàn rẹ̀. Dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa n̄ǹkan tí ń bẹ nínú igbá-àyà ẹ̀dá.

Ayah  11:6  الأية
وَمَا مِن دَابَّةٍ فِي الْأَرْضِ إِلَّا عَلَى اللهِ رِزْقُهَا وَيَعْلَمُ مُسْتَقَرَّهَا وَمُسْتَوْدَعَهَا ۚ كُلٌّ فِي كِتَابٍ مُّبِينٍ
Wama min dabbatin fee al-ardiilla AAala Allahi rizquha wayaAAlamumustaqarraha wamustawdaAAaha kullun fee kitabinmubeen

Yoruba
 
Kò sí ẹ̀dá abẹ̀mí kan tó wà lórí ilẹ̀ àfi kí arísìkí rẹ̀ wà lọ́dọ̀ Allāhu. Ó sì mọ ibùgbé rẹ̀ (nílé ayé) àti ilẹ̀ tí ó máa kú sí. Gbogbo rẹ̀ ti wà nínú àkọsílẹ̀ tó yanjú.

Ayah  11:7  الأية
وَهُوَ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ فِي سِتَّةِ أَيَّامٍ وَكَانَ عَرْشُهُ عَلَى الْمَاءِ لِيَبْلُوَكُمْ أَيُّكُمْ أَحْسَنُ عَمَلًا ۗ وَلَئِن قُلْتَ إِنَّكُم مَّبْعُوثُونَ مِن بَعْدِ الْمَوْتِ لَيَقُولَنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا إِنْ هَٰذَا إِلَّا سِحْرٌ مُّبِينٌ
Wahuwa allathee khalaqa assamawatiwal-arda fee sittati ayyamin wakanaAAarshuhu AAala alma-i liyabluwakum ayyukum ahsanuAAamalan wala-in qulta innakum mabAAoothoona min baAAdi almawtilayaqoolanna allatheena kafaroo in hatha illasihrun mubeen

Yoruba
 
Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà - Ìtẹ́ ọlá Rẹ̀ sì wà lórí omi (ṣíwájú èyí) - nítorí kí Ó lè dan yín wò pé, èwo nínú yín ló dára jùlọ (níbi) iṣẹ́ rere. Tí o bá kúkú sọ pé dájúdájú wọn yóò gbe yín dìde lẹ́yìn ikú, dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ yóò wí pé: "Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe idán pọ́nńbélé."

Ayah  11:8  الأية
وَلَئِنْ أَخَّرْنَا عَنْهُمُ الْعَذَابَ إِلَىٰ أُمَّةٍ مَّعْدُودَةٍ لَّيَقُولُنَّ مَا يَحْبِسُهُ ۗ أَلَا يَوْمَ يَأْتِيهِمْ لَيْسَ مَصْرُوفًا عَنْهُمْ وَحَاقَ بِهِم مَّا كَانُوا بِهِ يَسْتَهْزِئُونَ
Wala-in akhkharna AAanhumu alAAathabaila ommatin maAAdoodatin layaqoolunna ma yahbisuhuala yawma ya/teehim laysa masroofan AAanhum wahaqabihim ma kanoo bihi yastahzi-oon

Yoruba
 
Dájúdájú tí A bá sún ìyà ṣíwájú fún wọn di ìgbà tó ní òǹkà, dájúdájú wọn yóò wí pé: "Kí ló ń dá a dúró ná?" Gbọ́, ní ọjọ́ tí ìyà yóò dé bá wọn, kò níí ṣe é gbé kúrò fún wọn. Àti pé ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì máa dìyà tó máa yí wọn po.

Ayah  11:9  الأية
وَلَئِنْ أَذَقْنَا الْإِنسَانَ مِنَّا رَحْمَةً ثُمَّ نَزَعْنَاهَا مِنْهُ إِنَّهُ لَيَئُوسٌ كَفُورٌ
Wala-in athaqna al-insanaminna rahmatan thumma nazaAAnahaminhu innahu layaoosun kafoor

Yoruba
 
Àti pé dájúdájú tí A bá fi ìkẹ́ kan tọ́ ènìyàn lẹ́nu wò láti ọ̀dọ̀ Wa, lẹ́yìn náà, tí A bá gbà á kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, dájúdájú ó máa di olùsọ̀rètínù, aláìmoore.

Ayah  11:10  الأية
وَلَئِنْ أَذَقْنَاهُ نَعْمَاءَ بَعْدَ ضَرَّاءَ مَسَّتْهُ لَيَقُولَنَّ ذَهَبَ السَّيِّئَاتُ عَنِّي ۚ إِنَّهُ لَفَرِحٌ فَخُورٌ
Wala-in athaqnahu naAAmaabaAAda darraa massat-hu layaqoolanna thahabaassayyi-atu AAannee innahu lafarihunfakhoor

Yoruba
 
Dájúdájú tí A bá sì fún un ní ìdẹ̀ra tọ́wò lẹ́yìn ìnira tó fọwọ́ bà á, dájúdájú ó máa wí pé: "Àwọn aburú ti kúrò lọ́dọ̀ mi." Dájúdájú ó máa di aláyọ̀pọ̀rọ́, onífáàrí.

Ayah  11:11  الأية
إِلَّا الَّذِينَ صَبَرُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ أُولَٰئِكَ لَهُم مَّغْفِرَةٌ وَأَجْرٌ كَبِيرٌ
Illa allatheena sabaroowaAAamiloo assalihati ola-ika lahummaghfiratun waajrun kabeer

Yoruba
 
Àyàfi àwọn tó bá ṣe sùúrù, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Àwọn wọ̀nyẹn, ti wọn ni àforíjìn àti ẹ̀san tó tóbi.

Ayah  11:12  الأية
فَلَعَلَّكَ تَارِكٌ بَعْضَ مَا يُوحَىٰ إِلَيْكَ وَضَائِقٌ بِهِ صَدْرُكَ أَن يَقُولُوا لَوْلَا أُنزِلَ عَلَيْهِ كَنزٌ أَوْ جَاءَ مَعَهُ مَلَكٌ ۚ إِنَّمَا أَنتَ نَذِيرٌ ۚ وَاللهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ وَكِيلٌ
FalaAAallaka tarikun baAAda mayooha ilayka wada-iqun bihi sadruka anyaqooloo lawla onzila AAalayhi kanzun aw jaamaAAahu malakun innama anta natheerun wallahuAAala kulli shay-in wakeel

Yoruba
 
Bóyá o fẹ́ gbé apá kan ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ sílẹ̀, kí ìrẹ̀wẹ̀sì sì bá ọkàn rẹ nípa rẹ̀ (ní ti ìpáyà pé) wọ́n ń wí pé: "Kí ó sì jẹ́ pé àpótí-ọrọ̀ kan sọ̀kalẹ̀ fún un, tàbí kí mọlāika kan bá a wá?" Olùkìlọ̀ ni ìwọ. Allāhu sì ni Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan.

Ayah  11:13  الأية
أَمْ يَقُولُونَ افْتَرَاهُ ۖ قُلْ فَأْتُوا بِعَشْرِ سُوَرٍ مِّثْلِهِ مُفْتَرَيَاتٍ وَادْعُوا مَنِ اسْتَطَعْتُم مِّن دُونِ اللهِ إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ
Am yaqooloona iftarahu qul fa/toobiAAashri suwarin mithlihi muftarayatin wadAAoomani istataAAtum min dooni Allahi in kuntum sadiqeen

Yoruba
 
Tàbí wọ́n ń wí pé: "Ó hun ún ni." Sọ pé: "Ẹ mú sūrah mẹ́wàá àdáhun bí irú rẹ̀ wá, kí ẹ sì ké sí ẹni tí ẹ bá lè ké sí lẹ́yìn Allāhu tí ẹ bá jẹ́ olódodo."

Ayah  11:14  الأية
فَإِلَّمْ يَسْتَجِيبُوا لَكُمْ فَاعْلَمُوا أَنَّمَا أُنزِلَ بِعِلْمِ اللهِ وَأَن لَّا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ۖ فَهَلْ أَنتُم مُّسْلِمُونَ
Fa-illam yastajeeboo lakum faAAlamooannama onzila biAAilmi Allahi waan la ilahailla huwa fahal antum muslimoon

Yoruba
 
Nígbà náà tí wọn kò bá da yín lóhùn, kí ẹ mọ̀ pé dájúdájú wọ́n sọ (al-Ƙur'ān) kalẹ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ Allāhu. Àti pé kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Nítorí náà, ṣé ẹ̀yin yóò di mùsùlùmí?

Ayah  11:15  الأية
مَن كَانَ يُرِيدُ الْحَيَاةَ الدُّنْيَا وَزِينَتَهَا نُوَفِّ إِلَيْهِمْ أَعْمَالَهُمْ فِيهَا وَهُمْ فِيهَا لَا يُبْخَسُونَ
Man kana yureedu alhayataaddunya wazeenataha nuwaffi ilayhim aAAmalahumfeeha wahum feeha la yubkhasoon

Yoruba
 
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń fẹ́ ìṣẹ̀mí ayé àti ọ̀ṣọ́ rẹ̀, A óò san wọ́n ní ẹ̀san iṣẹ́ wọn nílé ayé. A ò sì níí dín kiní kan kù fún wọn nílé ayé.

Ayah  11:16  الأية
أُولَٰئِكَ الَّذِينَ لَيْسَ لَهُمْ فِي الْآخِرَةِ إِلَّا النَّارُ ۖ وَحَبِطَ مَا صَنَعُوا فِيهَا وَبَاطِلٌ مَّا كَانُوا يَعْمَلُونَ
Ola-ika allatheena laysa lahumfee al-akhirati illa annaru wahabitama sanaAAoo feeha wabatilun makanoo yaAAmaloon

Yoruba
 
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí kò níí sí kiní kan fún wọn mọ́ ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn àfi Iná. N̄ǹkan tí wọ́n gbélé ayé ṣe sì máa bàjẹ́. Òfò sì ni ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

Ayah  11:17  الأية
أَفَمَن كَانَ عَلَىٰ بَيِّنَةٍ مِّن رَّبِّهِ وَيَتْلُوهُ شَاهِدٌ مِّنْهُ وَمِن قَبْلِهِ كِتَابُ مُوسَىٰ إِمَامًا وَرَحْمَةً ۚ أُولَٰئِكَ يُؤْمِنُونَ بِهِ ۚ وَمَن يَكْفُرْ بِهِ مِنَ الْأَحْزَابِ فَالنَّارُ مَوْعِدُهُ ۚ فَلَا تَكُ فِي مِرْيَةٍ مِّنْهُ ۚ إِنَّهُ الْحَقُّ مِن رَّبِّكَ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يُؤْمِنُونَ
Afaman kana AAala bayyinatinmin rabbihi wayatloohu shahidun minhu wamin qablihi kitabumoosa imaman warahmatan ola-ikayu/minoona bihi waman yakfur bihi mina al-ahzabi fannarumawAAiduhu fala taku fee miryatin minhu innahu alhaqqumin rabbika walakinna akthara annasi layu/minoon

Yoruba
 
Ǹjẹ́ ẹni tó ń bẹ́ lórí ẹ̀rí tó yanjú láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ (ìyẹn, Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -), tí olùjẹ́rìí kan (ìyẹn, mọlāika Jibrīl) sì ń ké al-Ƙur'ān (fún un) láti ọ̀dọ̀ Allāhu, tí tírà (Ànábì) Mūsā sì ti wá ṣíwájú rẹ̀, tí ó jẹ́ tírà tí wọ́n ń tẹ̀lé, tí ó sì jẹ́ ìkẹ́ (fún wọn), (ǹjẹ́ Ànábì yìí - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - jọ olùṣìnà bí?) Àwọn (mùsùlùmí) wọ̀nyí ni wọ́n sì gbà á gbọ́ ní òdodo. Ẹnikẹ́ni tó bá ṣàì gbà á gbọ́ nínú àwọn ìjọ (nasọ̄rọ̄, yẹhudi àti ọ̀ṣẹbọ), nígbà náà Iná ni àdéhùn rẹ̀. Nítorí náà, má ṣe wà nínú iyèméjì nípa al-Ƙur'ān. Dájúdájú òdodo ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn ni kò gbàgbọ́.

Ayah  11:18  الأية
وَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّنِ افْتَرَىٰ عَلَى اللهِ كَذِبًا ۚ أُولَٰئِكَ يُعْرَضُونَ عَلَىٰ رَبِّهِمْ وَيَقُولُ الْأَشْهَادُ هَٰؤُلَاءِ الَّذِينَ كَذَبُوا عَلَىٰ رَبِّهِمْ ۚ أَلَا لَعْنَةُ اللهِ عَلَى الظَّالِمِينَ
Waman athlamu mimmani iftaraAAala Allahi kathiban ola-ika yuAAradoonaAAala rabbihim wayaqoolu al-ashhadu haola-iallatheena kathaboo AAala rabbihim alalaAAnatu Allahi AAala aththalimeen

Yoruba
 
Àti pé ta ni ó ṣàbòsí ju ẹni tó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu? Àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n yóò kó wá síwájú Olúwa wọn. Àwọn ẹlẹ́rìí (ìyẹn, àwọn mọlāika) yó sì máa sọ pé: "Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tó parọ́ mọ́ Olúwa wọn." Gbọ́, ibi dandan Allāhu kí ó máa bá àwọn alábòsí,

Ayah  11:19  الأية
الَّذِينَ يَصُدُّونَ عَن سَبِيلِ اللهِ وَيَبْغُونَهَا عِوَجًا وَهُم بِالْآخِرَةِ هُمْ كَافِرُونَ
Allatheena yasuddoona AAansabeeli Allahi wayabghoonaha AAiwajan wahum bil-akhiratihum kafiroon

Yoruba
 
Àwọn tó ń ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, tí wọ́n sì ń fẹ́ kó wọ́. Àwọn sì ni aláìgbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.

Ayah  11:20  الأية
أُولَٰئِكَ لَمْ يَكُونُوا مُعْجِزِينَ فِي الْأَرْضِ وَمَا كَانَ لَهُم مِّن دُونِ اللهِ مِنْ أَوْلِيَاءَ ۘ يُضَاعَفُ لَهُمُ الْعَذَابُ ۚ مَا كَانُوا يَسْتَطِيعُونَ السَّمْعَ وَمَا كَانُوا يُبْصِرُونَ
Ola-ika lam yakoonoo muAAjizeena feeal-ardi wama kana lahum min dooni Allahimin awliyaa yudaAAafu lahumu alAAathabu makanoo yastateeAAoona assamAAa wama kanooyubsiroon

Yoruba
 
Àwọn wọ̀nyẹn kò lè mórí bọ́ nínú ìyà Allāhu lórí ilẹ̀ àti pé kò sí aláàbò kan fún wọn lẹ́yìn Allāhu. A sì máa ṣe àdìpèlé ìyà fún wọn. Wọn kò lè gbọ́. Àti pé wọn kì í ríran (rí òdodo).

Ayah  11:21  الأية
أُولَٰئِكَ الَّذِينَ خَسِرُوا أَنفُسَهُمْ وَضَلَّ عَنْهُم مَّا كَانُوا يَفْتَرُونَ
Ola-ika allatheena khasirooanfusahum wadalla AAanhum ma kanoo yaftaroon

Yoruba
 
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tó ṣe ẹ̀mí ara wọn lófò. Ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́ sì di òfo mọ́ wọn lọ́wọ́.

Ayah  11:22  الأية
لَا جَرَمَ أَنَّهُمْ فِي الْآخِرَةِ هُمُ الْأَخْسَرُونَ
La jarama annahum fee al-akhiratihumu al-akhsaroon

Yoruba
 
Ní ti òdodo, dájúdájú àwọn gan-an ni ẹni òfò jùlọ ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.

Ayah  11:23  الأية
إِنَّ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ وَأَخْبَتُوا إِلَىٰ رَبِّهِمْ أُولَٰئِكَ أَصْحَابُ الْجَنَّةِ ۖ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ
Inna allatheena amanoowaAAamiloo asalihati waakhbatoo ilarabbihim ola-ika as-habu aljannati hum feehakhalidoon

Yoruba
 
Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe àwọn iṣẹ́ rere, tí wọ́n sì dúnní mọ́ ìronúpìwàdà sọ́dọ̀ Olúwa wọn, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.

Ayah  11:24  الأية
مَثَلُ الْفَرِيقَيْنِ كَالْأَعْمَىٰ وَالْأَصَمِّ وَالْبَصِيرِ وَالسَّمِيعِ ۚ هَلْ يَسْتَوِيَانِ مَثَلًا ۚ أَفَلَا تَذَكَّرُونَ
Mathalu alfareeqayni kalaAAmawal-asammi walbaseeri wassameeAAihal yastawiyani mathalan afala tathakkaroon

Yoruba
 
Àpèjúwe ìjọ méjèèjì dà bí afọ́jú àti adití pẹ̀lú olùríran àti olùgbọ́rọ̀. Ǹjẹ́ àwọn méjèèjì dọ́gba ní àpèjúwe bí? Ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni?

Ayah  11:25  الأية
وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا نُوحًا إِلَىٰ قَوْمِهِ إِنِّي لَكُمْ نَذِيرٌ مُّبِينٌ
Walaqad arsalna noohan ilaqawmihi innee lakum natheerun mubeen

Yoruba
 
A sì kúkú ti rán (Ànábì) Nūh sí ìjọ rẹ̀ (láti sọ pé) dájúdájú olùkìlọ̀ pọ́nńbélé ni mo jẹ́ fún yín.

Ayah  11:26  الأية
أَن لَّا تَعْبُدُوا إِلَّا اللهَ ۖ إِنِّي أَخَافُ عَلَيْكُمْ عَذَابَ يَوْمٍ أَلِيمٍ
An la taAAbudoo illa Allahainnee akhafu AAalaykum AAathaba yawmin aleem

Yoruba
 
(Mò ń kìlọ̀) pé kí ẹ má ṣe jọ́sìn fún ẹnì kan àfi Allāhu. Dájúdájú èmi ń páyà ìyà ọjọ́ ẹlẹ́ta-eléro fún yín.

Ayah  11:27  الأية
فَقَالَ الْمَلَأُ الَّذِينَ كَفَرُوا مِن قَوْمِهِ مَا نَرَاكَ إِلَّا بَشَرًا مِّثْلَنَا وَمَا نَرَاكَ اتَّبَعَكَ إِلَّا الَّذِينَ هُمْ أَرَاذِلُنَا بَادِيَ الرَّأْيِ وَمَا نَرَىٰ لَكُمْ عَلَيْنَا مِن فَضْلٍ بَلْ نَظُنُّكُمْ كَاذِبِينَ
Faqala almalao allatheenakafaroo min qawmihi ma naraka illa basharanmithlana wama naraka ittabaAAaka illaallatheena hum arathiluna badiya arra/yiwama nara lakum AAalayna min fadlinbal nathunnukum kathibeen

Yoruba
 
Àwọn aṣíwájú tó ṣàì gbàgbọ́ nínú ìjọ rẹ̀ sì wí pé: "Àwa kò mọ̀ ọ́ sí ẹnì kan bí kò ṣe abara bí irú wa. Àwa kò sì mọ àwọn tó tẹ̀lé ọ sí ẹnì kan kan bí kò ṣe àwọn ẹni yẹpẹrẹ nínú wa, ọlọ́pọlọ bín-íntín. Àti pé àwa kò ri yín sí ẹni tó fi ọ̀nà kan kan ní àjùlọ lórí wa, ṣùgbọ́n a kà yín kún òpùrọ́."

Ayah  11:28  الأية
قَالَ يَا قَوْمِ أَرَأَيْتُمْ إِن كُنتُ عَلَىٰ بَيِّنَةٍ مِّن رَّبِّي وَآتَانِي رَحْمَةً مِّنْ عِندِهِ فَعُمِّيَتْ عَلَيْكُمْ أَنُلْزِمُكُمُوهَا وَأَنتُمْ لَهَا كَارِهُونَ
Qala ya qawmi araaytum inkuntu AAala bayyinatin min rabbee waataneerahmatan min AAindihi faAAummiyat AAalaykum anulzimukumoohawaantum laha karihoon

Yoruba
 
(Ànábì Nūh) sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ sọ fún mi, tí mo bá wà lórí ẹ̀rí tó yanjú láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi, tí Ó sì fún mi ní ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀, tí wọ́n sì dì yín lójú pa sí i (tí ẹ kò ríran rí òdodo náà), ǹjẹ́ a óò fi dandan mu yín bí, nígbà tí ẹ kórira rẹ̀?

Ayah  11:29  الأية
وَيَا قَوْمِ لَا أَسْأَلُكُمْ عَلَيْهِ مَالًا ۖ إِنْ أَجْرِيَ إِلَّا عَلَى اللهِ ۚ وَمَا أَنَا بِطَارِدِ الَّذِينَ آمَنُوا ۚ إِنَّهُم مُّلَاقُو رَبِّهِمْ وَلَٰكِنِّي أَرَاكُمْ قَوْمًا تَجْهَلُونَ
Waya qawmi la as-alukumAAalayhi malan in ajriya illa AAala Allahiwama ana bitaridi allatheena amanooinnahum mulaqoo rabbihim walakinnee arakumqawman tajhaloon

Yoruba
 
Ẹ̀yin ìjọ mi, èmi kò bi yín léèrè dúkìá kan lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi níbì kan bí kò ṣe lọ́dọ̀ Allāhu. Èmi kò sì níí le àwọn tó gbàgbọ́ lódodo dànù. Dájúdájú wọn yóò pàdé Olúwa wọn, ṣùgbọ́n dájúdájú èmi ń ri yín sí ìjọ aláìmọ̀kan.

Ayah  11:30  الأية
وَيَا قَوْمِ مَن يَنصُرُنِي مِنَ اللهِ إِن طَرَدتُّهُمْ ۚ أَفَلَا تَذَكَّرُونَ
Waya qawmi man yansurunee minaAllahi in taradtuhum afala tathakkaroon

Yoruba
 
Ẹ̀yin ìjọ mi, ta ni ó máa ràn mí lọ́wọ́ níbi (ìyà) Allāhu tí mo bá lé wọn dànù? Ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni?

Ayah  11:31  الأية
وَلَا أَقُولُ لَكُمْ عِندِي خَزَائِنُ اللهِ وَلَا أَعْلَمُ الْغَيْبَ وَلَا أَقُولُ إِنِّي مَلَكٌ وَلَا أَقُولُ لِلَّذِينَ تَزْدَرِي أَعْيُنُكُمْ لَن يُؤْتِيَهُمُ اللهُ خَيْرًا ۖ اللهُ أَعْلَمُ بِمَا فِي أَنفُسِهِمْ ۖ إِنِّي إِذًا لَّمِنَ الظَّالِمِينَ
Wala aqoolu lakum AAindee khaza-inuAllahi wala aAAlamu alghayba wala aqooluinnee malakun wala aqoolu lillatheena tazdareeaAAyunukum lan yu/tiyahumu Allahu khayran AllahuaAAlamu bima fee anfusihim innee ithan lamina aththalimeen

Yoruba
 
Èmi kò sì sọ fún yín pé àwọn ilé-ọrọ̀ Allāhu ń bẹ lọ́dọ̀ mi. Èmi kò sì mọ ìkọ̀kọ̀. Èmi kò sì sọ pé mọlāika ni mí. Èmi kò sì lè sọ fún àwọn tí ẹ̀ ń fojú bín-íntín wò pé, Allāhu kò níí ṣoore fún wọn. Allāhu l'Ó nímọ̀ jùlọ nípa n̄ǹkan tó ń bẹ nínú ẹ̀mí wọn. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ nígbà náà, dájúdájú mo ti wà nínú àwọn alábòsí."

Ayah  11:32  الأية
قَالُوا يَا نُوحُ قَدْ جَادَلْتَنَا فَأَكْثَرْتَ جِدَالَنَا فَأْتِنَا بِمَا تَعِدُنَا إِن كُنتَ مِنَ الصَّادِقِينَ
Qaloo ya noohu qad jadaltanafaaktharta jidalana fa/tina bimataAAiduna in kunta mina assadiqeen

Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "Nūh, o mà kúkú ti jà wá níyàn. O sì ṣe àríyànjiyàn púpọ̀ pẹ̀lú wa. Nítorí náà, mú ohun tí o ṣe ní ìlérí fún wa wá tí o bá wà lára àwọn olódodo."

Ayah  11:33  الأية
قَالَ إِنَّمَا يَأْتِيكُم بِهِ اللهُ إِن شَاءَ وَمَا أَنتُم بِمُعْجِزِينَ
Qala innama ya/teekum bihi Allahuin shaa wama antum bimuAAjizeen

Yoruba
 
(Ànábì Nūh) sọ pé: "Allāhu l'Ó máa mú un wá ba yín tí Ó bá fẹ́. Ẹ̀yin kò sì níí mórí bọ́.

Ayah  11:34  الأية
وَلَا يَنفَعُكُمْ نُصْحِي إِنْ أَرَدتُّ أَنْ أَنصَحَ لَكُمْ إِن كَانَ اللهُ يُرِيدُ أَن يُغْوِيَكُمْ ۚ هُوَ رَبُّكُمْ وَإِلَيْهِ تُرْجَعُونَ
Wala yanfaAAukum nushee inaradtu an ansaha lakum in kana Allahuyureedu an yughwiyakum huwa rabbukum wa-ilayhi turjaAAoon

Yoruba
 
Ìmọ̀ràn mi kò sì lè ṣe yín ní àǹfààní tí mo bá fẹ́ gbà yín nìmọ̀ràn, tí Allāhu bá fẹ́ pa yín run. Òun ni Olúwa yín. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí."

Ayah  11:35  الأية
أَمْ يَقُولُونَ افْتَرَاهُ ۖ قُلْ إِنِ افْتَرَيْتُهُ فَعَلَيَّ إِجْرَامِي وَأَنَا بَرِيءٌ مِّمَّا تُجْرِمُونَ
Am yaqooloona iftarahu qul iniiftaraytuhu faAAalayya ijramee waana baree-on mimmatujrimoon

Yoruba
 
Tàbí wọ́n ń wí pé: "Ó hun ún ni." Sọ pé: "Tí mó bá hun ún, èmi ni mo ni ẹ̀ṣẹ̀ mi. Èmi sì yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń dá lẹ́ṣẹ̀."

Ayah  11:36  الأية
وَأُوحِيَ إِلَىٰ نُوحٍ أَنَّهُ لَن يُؤْمِنَ مِن قَوْمِكَ إِلَّا مَن قَدْ آمَنَ فَلَا تَبْتَئِسْ بِمَا كَانُوا يَفْعَلُونَ
Waoohiya ila noohinannahu lan yu/mina min qawmika illa man qad amanafala tabta-is bima kanoo yafAAaloon

Yoruba
 
A sì fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Nūh pé, dájúdájú kò sí ẹnì kan tí ó máa gbàgbọ́ mọ́ nínú ìjọ rẹ àfi ẹni tó ti gbàgbọ́ tẹ́lẹ̀. Nítorí náà, má ṣe banújẹ́ nípa n̄ǹkan tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

Ayah  11:37  الأية
وَاصْنَعِ الْفُلْكَ بِأَعْيُنِنَا وَوَحْيِنَا وَلَا تُخَاطِبْنِي فِي الَّذِينَ ظَلَمُوا ۚ إِنَّهُم مُّغْرَقُونَ
WasnaAAi alfulka bi-aAAyuninawawahyina wala tukhatibnee fee allatheenathalamoo innahum mughraqoon

Yoruba
 
Kí o sì kan ọkọ̀ ojú-omi náà lójú Wa (báyìí) pẹ̀lú ìmísí Wa. Má sì ṣe bá Mi sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ṣàbòsí. Dájúdájú wọ́n máa tẹ̀ wọ́n rì ni.

Ayah  11:38  الأية
وَيَصْنَعُ الْفُلْكَ وَكُلَّمَا مَرَّ عَلَيْهِ مَلَأٌ مِّن قَوْمِهِ سَخِرُوا مِنْهُ ۚ قَالَ إِن تَسْخَرُوا مِنَّا فَإِنَّا نَسْخَرُ مِنكُمْ كَمَا تَسْخَرُونَ
WayasnaAAu alfulka wakullamamarra AAalayhi malaon min qawmihi sakhiroo minhu qala intaskharoo minna fa-inna naskharu minkum kamataskharoon

Yoruba
 
Ó sì ń kan ọkọ̀ ojú-omi náà lọ. Ìgbàkígbà tí àwọn ọ̀tọ̀kùlú nínú ìjọ rẹ̀ bá kọjá lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n yó sì máa fi ṣe yẹ̀yẹ́. (Ànábì Nūh) sì sọ pé: "Tí ẹ bá fi wá ṣe yẹ̀yẹ́, dájúdájú àwa náà yóò fi yín ṣe yẹ̀yẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ ṣe ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́.

Ayah  11:39  الأية
فَسَوْفَ تَعْلَمُونَ مَن يَأْتِيهِ عَذَابٌ يُخْزِيهِ وَيَحِلُّ عَلَيْهِ عَذَابٌ مُّقِيمٌ
Fasawfa taAAlamoona man ya/teehi AAathabunyukhzeehi wayahillu AAalayhi AAathabun muqeem

Yoruba
 
Nítorí náà, láìpẹ́ ẹ máa mọ ẹni tí ìyà máa dé bá, tí ó máa yẹpẹrẹ rẹ̀, tí ìyà gbere sì máa kò lé lórí."

Ayah  11:40  الأية
حَتَّىٰ إِذَا جَاءَ أَمْرُنَا وَفَارَ التَّنُّورُ قُلْنَا احْمِلْ فِيهَا مِن كُلٍّ زَوْجَيْنِ اثْنَيْنِ وَأَهْلَكَ إِلَّا مَن سَبَقَ عَلَيْهِ الْقَوْلُ وَمَنْ آمَنَ ۚ وَمَا آمَنَ مَعَهُ إِلَّا قَلِيلٌ
Hatta itha jaaamruna wafara attannooru qulna ihmilfeeha min kullin zawjayni ithnayni waahlaka illaman sabaqa AAalayhi alqawlu waman amana wama amanamaAAahu illa qaleel

Yoruba
 
(Báyìí ni ọ̀rọ̀ wà) títí di ìgbà tí àṣẹ Wa dé, omi sì ṣẹ́yọ gbùú láti ojú-àrò (tí wọ́n ti ń ṣe búrẹ́dì). A sọ pé: "Kó gbogbo n̄ǹkan ní takọ-tabo méjìméjì àti ará ilé rẹ sínú ọkọ̀ ojú-omi - àyàfi ẹni tí ọ̀rọ̀ náà ti kò lé lórí (fún ìparun) - àti ẹnikẹ́ni tó gbàgbọ́ ní òdodo. Kò sì sí ẹni tó ní ìgbàgbọ́ òdodo pẹ̀lú rẹ̀ àfi àwọn díẹ̀.

Ayah  11:41  الأية
وَقَالَ ارْكَبُوا فِيهَا بِسْمِ اللهِ مَجْرَاهَا وَمُرْسَاهَا ۚ إِنَّ رَبِّي لَغَفُورٌ رَّحِيمٌ
Waqala irkaboo feeha bismi Allahimajraha wamursaha inna rabbeelaghafoorun raheem

Yoruba
 
(Ànábì Nūh) sọ pé: "Ẹ wọ inú ọkọ̀ ojú-omi náà. Ní orúkọ Allāhu ni ìrìn rẹ̀ àti ìgúnlẹ̀ rẹ̀. Dájúdájú Olúwa mi ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run."

Ayah  11:42  الأية
وَهِيَ تَجْرِي بِهِمْ فِي مَوْجٍ كَالْجِبَالِ وَنَادَىٰ نُوحٌ ابْنَهُ وَكَانَ فِي مَعْزِلٍ يَا بُنَيَّ ارْكَب مَّعَنَا وَلَا تَكُن مَّعَ الْكَافِرِينَ
Wahiya tajree bihim fee mawjin kaljibaliwanada noohunu ibnahu wakana feemaAAzilin ya bunayya irkab maAAana walatakun maAAa alkafireen

Yoruba
 
Ó sì ń gbé wọn lọ nínú ìgbì omi tó dà bí àpáta. (Ànábì Nūh) sì ké sí ọmọkùnrin rẹ̀, tí ó ti yara rẹ̀ sọ́tọ̀: "Ọmọkùnrin mi, gun ọkọ̀ ojú-omi pẹ̀lú wa. Má sì ṣe wà pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́."

Ayah  11:43  الأية
قَالَ سَآوِي إِلَىٰ جَبَلٍ يَعْصِمُنِي مِنَ الْمَاءِ ۚ قَالَ لَا عَاصِمَ الْيَوْمَ مِنْ أَمْرِ اللهِ إِلَّا مَن رَّحِمَ ۚ وَحَالَ بَيْنَهُمَا الْمَوْجُ فَكَانَ مِنَ الْمُغْرَقِينَ
Qala saawee ila jabalinyaAAsimunee mina alma-i qala la AAasimaalyawma min amri Allahi illa man rahima wahalabaynahuma almawju fakana mina almughraqeen

Yoruba
 
Ó wí pé: "Èmi yóò fara pamọ́ síbi àpáta kan tí ó máa gbà mí là níbi omi." (Ànábì Nūh) sọ pé: "Kò sí olùgbàlà kan (kò sí ẹni tí wọ́n máa gbàlà) ní òní níbi àṣẹ Allāhu (ẹ̀kún omi) àfi ẹni tí Allāhu bá ṣàánú." Ìgbì omi sì la àwọn méjèèjì láààrin. Ó sì di ara àwọn olùtẹ̀rì sínú omi.

Ayah  11:44  الأية
وَقِيلَ يَا أَرْضُ ابْلَعِي مَاءَكِ وَيَا سَمَاءُ أَقْلِعِي وَغِيضَ الْمَاءُ وَقُضِيَ الْأَمْرُ وَاسْتَوَتْ عَلَى الْجُودِيِّ ۖ وَقِيلَ بُعْدًا لِّلْقَوْمِ الظَّالِمِينَ
Waqeela ya ardu iblaAAee maakiwaya samao aqliAAee wagheeda almaowaqudiya al-amru wastawat AAala aljoodiyyiwaqeela buAAdan lilqawmi aththalimeen

Yoruba
 
A sọ pé: "Ilẹ̀, fa omi rẹ mu. Sánmọ̀, dáwọ́ (òjò) dúró." Wọ́n sì dín omi kù. Àṣẹ (ìparun wọn) sì wá sí ìmúṣẹ. (Ọkọ̀ ojú-omi) sì gúnlẹ̀ sórí àpáta Jūdī. Wọ́n sì sọ pé: "Kí ìjìnnà sí ìkẹ́ Allāhu máa jẹ́ ti ìjọ alábòsí."

Ayah  11:45  الأية
وَنَادَىٰ نُوحٌ رَّبَّهُ فَقَالَ رَبِّ إِنَّ ابْنِي مِنْ أَهْلِي وَإِنَّ وَعْدَكَ الْحَقُّ وَأَنتَ أَحْكَمُ الْحَاكِمِينَ
Wanada noohun rabbahufaqala rabbi inna ibnee min ahlee wa-inna waAAdaka alhaqquwaanta ahkamu alhakimeen

Yoruba
 
(Ànábì) Nūh pe Olúwa rẹ̀, ó sì sọ pé: "Olúwa mi, dájúdájú ọmọ mi wà nínú ará ilé mi. Àti pé dájúdájú àdéhùn Rẹ, òdodo ni. Ìwọ l'O sì mọ ẹjọ́ dá jùlọ nínú àwọn adájọ́.

Ayah  11:46  الأية
قَالَ يَا نُوحُ إِنَّهُ لَيْسَ مِنْ أَهْلِكَ ۖ إِنَّهُ عَمَلٌ غَيْرُ صَالِحٍ ۖ فَلَا تَسْأَلْنِ مَا لَيْسَ لَكَ بِهِ عِلْمٌ ۖ إِنِّي أَعِظُكَ أَن تَكُونَ مِنَ الْجَاهِلِينَ
Qala ya noohu innahulaysa min ahlika innahu AAamalun ghayru salihin falatas-alni ma laysa laka bihi AAilmun innee aAAithukaan takoona mina aljahileen

Yoruba
 
Allāhu sọ pé: "Nūh, dájúdájú kò sí nínú ará ilé rẹ (ní ti ẹ̀sìn). Dájúdájú iṣẹ́ tí kò dára ni. Nítorí náà, o ò gbọdọ̀ bi Mí léèrè n̄ǹkan tí o ò ní ìmọ̀ nípa rẹ̀. Dájúdájú Èmi ń kìlọ̀ fún ọ nítorí kí o má baà di ara àwọn aláìmọ̀kan."

Ayah  11:47  الأية
قَالَ رَبِّ إِنِّي أَعُوذُ بِكَ أَنْ أَسْأَلَكَ مَا لَيْسَ لِي بِهِ عِلْمٌ ۖ وَإِلَّا تَغْفِرْ لِي وَتَرْحَمْنِي أَكُن مِّنَ الْخَاسِرِينَ
Qala rabbi innee aAAoothu bikaan as-alaka ma laysa lee bihi AAilmun wa-illataghfir lee watarhamnee akun mina alkhasireen

Yoruba
 
Ó sọ pé: "Olúwa mi, dájúdájú èmi ń sá di Ọ́ níbi kí n̄g bi Ọ́ léèrè n̄ǹkan tí èmi kò ní ìmọ̀ rẹ̀. Tí O ò bá foríjìn mí, kí O sì ṣàánú mi, èmi yóò wà lára àwọn ẹni òfò."

Ayah  11:48  الأية
قِيلَ يَا نُوحُ اهْبِطْ بِسَلَامٍ مِّنَّا وَبَرَكَاتٍ عَلَيْكَ وَعَلَىٰ أُمَمٍ مِّمَّن مَّعَكَ ۚ وَأُمَمٌ سَنُمَتِّعُهُمْ ثُمَّ يَمَسُّهُم مِّنَّا عَذَابٌ أَلِيمٌ
Qeela ya noohu ihbitbisalamin minna wabarakatin AAalayka waAAalaomamin mimman maAAaka waomamun sanumattiAAuhum thumma yamassuhumminna AAathabun aleem

Yoruba
 
A sọ pé: "Nūh, sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Wa. Àti pé kí ìbùkún wà pẹ̀lú rẹ àti àwọn ìjọ nínú àwọn tó ń bẹ pẹ̀lú rẹ. Àwọn ìjọ kan (tún ń bọ̀), tí A óò fún wọn ní ìgbádùn (oore ayé). Lẹ́yìn náà, ìyà ẹlẹ́ta-eléro yó sì fọwọ́ bà wọ́n láti ọ̀dọ̀ Wa."

Ayah  11:49  الأية
تِلْكَ مِنْ أَنبَاءِ الْغَيْبِ نُوحِيهَا إِلَيْكَ ۖ مَا كُنتَ تَعْلَمُهَا أَنتَ وَلَا قَوْمُكَ مِن قَبْلِ هَٰذَا ۖ فَاصْبِرْ ۖ إِنَّ الْعَاقِبَةَ لِلْمُتَّقِينَ
Tilka min anba-i alghaybi nooheehailayka ma kunta taAAlamuha anta wala qawmukamin qabli hatha fasbir inna alAAaqibatalilmuttaqeen

Yoruba
 
Ìwọ̀nyí wà nínú ìró ìkọ̀kọ̀ tí À ń fi (ìmísí rẹ̀) ránṣẹ́ sí ọ. Ìwọ àti ìjọ rẹ kò nímọ̀ rẹ̀ ṣíwájú èyí (tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ). Nítorí náà, ṣe sùúrù. Dájúdájú ìkángun rere wà fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).

Ayah  11:50  الأية
وَإِلَىٰ عَادٍ أَخَاهُمْ هُودًا ۚ قَالَ يَا قَوْمِ اعْبُدُوا اللهَ مَا لَكُم مِّنْ إِلَٰهٍ غَيْرُهُ ۖ إِنْ أَنتُمْ إِلَّا مُفْتَرُونَ
Wa-ila AAadin akhahumhoodan qala ya qawmi oAAbudoo Allaha malakum min ilahin ghayruhu in antum illa muftaroon

Yoruba
 
(Ẹni tí A rán níṣẹ́) sí ìran ‘Ād ni arákùnrin wọn, (Ànábì) Hūd. Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ kò ní ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo lẹ́yìn Rẹ̀. Ẹ̀yin kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe aládàápa irọ́.

Ayah  11:51  الأية
يَا قَوْمِ لَا أَسْأَلُكُمْ عَلَيْهِ أَجْرًا ۖ إِنْ أَجْرِيَ إِلَّا عَلَى الَّذِي فَطَرَنِي ۚ أَفَلَا تَعْقِلُونَ
Ya qawmi la as-alukum AAalayhiajran in ajriya illa AAala allathee fataraneeafala taAAqiloon

Yoruba
 
Ẹ̀yin ìjọ mi, èmi kò bi yín léèrè owó-ọ̀yà kan lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi níbì kan bí kò ṣe lọ́dọ̀ Ẹni tí Ó pilẹ̀ ìṣẹ̀dá mi. Ṣé ẹ ò níí ṣe làákàyè ni?

Ayah  11:52  الأية
وَيَا قَوْمِ اسْتَغْفِرُوا رَبَّكُمْ ثُمَّ تُوبُوا إِلَيْهِ يُرْسِلِ السَّمَاءَ عَلَيْكُم مِّدْرَارًا وَيَزِدْكُمْ قُوَّةً إِلَىٰ قُوَّتِكُمْ وَلَا تَتَوَلَّوْا مُجْرِمِينَ
Waya qawmi istaghfiroo rabbakumthumma tooboo ilayhi yursili assamaa AAalaykummidraran wayazidkum quwwatan ila quwwatikum walatatawallaw mujrimeen

Yoruba
 
Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Olùwa Ẹlẹ́dàá yín, lẹ́yìn náà, kí ẹ ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Rẹ̀ nítorí kí Ó lè rọ̀jò fún yín ní púpọ̀ láti sánmọ̀ àti nítorí kí Ó lè ṣe àlékún agbára kún agbára yín. Ẹ má ṣe pẹ̀yìn dà láti di ẹlẹ́ṣẹ̀ (sínú àìgbàgbọ́)."

Ayah  11:53  الأية
قَالُوا يَا هُودُ مَا جِئْتَنَا بِبَيِّنَةٍ وَمَا نَحْنُ بِتَارِكِي آلِهَتِنَا عَن قَوْلِكَ وَمَا نَحْنُ لَكَ بِمُؤْمِنِينَ
Qaloo ya hoodu maji/tana bibayyinatin wama nahnu bitarikeealihatina AAan qawlika wama nahnulaka bimu/mineen

Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "Hūd, o ò mú ẹ̀rí kan tó yanjú wá fún wa. Àwa kò sì níí gbé àwọn òrìṣà wa jù sílẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ (ẹnu) rẹ. Àti pé àwa kò ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ.

Ayah  11:54  الأية
إِن نَّقُولُ إِلَّا اعْتَرَاكَ بَعْضُ آلِهَتِنَا بِسُوءٍ ۗ قَالَ إِنِّي أُشْهِدُ اللهَ وَاشْهَدُوا أَنِّي بَرِيءٌ مِّمَّا تُشْرِكُونَ
In naqoolu illa iAAtaraka baAAdualihatina bisoo-in qala innee oshhidu Allahawashhadoo annee baree-on mimma tushrikoon

Yoruba
 
A kò níí sọ n̄ǹkan kan (sí ọ) bí kò ṣe pé, àwọn kan nínú àwọn òrìṣà wa ti fi ìnira kàn ọ́ (ló fi ń sọ ìsọkúsọ nípa wọn)." Ó sọ pé: "Dájúdájú èmi ń fi Allāhu ṣe Ẹlẹ́rìí àti pé kí ẹ̀yin náà jẹ́rìí pé dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń fi ṣẹbọ

Ayah  11:55  الأية
مِن دُونِهِ ۖ فَكِيدُونِي جَمِيعًا ثُمَّ لَا تُنظِرُونِ
Min doonihi fakeedoonee jameeAAan thumma latunthiroon

Yoruba
 
Dípò jíjọ́sìn fún Allāhu. Nítorí náà, ẹ parapọ̀ déte sí mi. Lẹ́yìn náà, kí ẹ má ṣe lọ́ mi lára.

Ayah  11:56  الأية
إِنِّي تَوَكَّلْتُ عَلَى اللهِ رَبِّي وَرَبِّكُم ۚ مَّا مِن دَابَّةٍ إِلَّا هُوَ آخِذٌ بِنَاصِيَتِهَا ۚ إِنَّ رَبِّي عَلَىٰ صِرَاطٍ مُّسْتَقِيمٍ
Innee tawakkaltu AAala Allahirabbee warabbikum ma min dabbatin illa huwa akhithunbinasiyatiha inna rabbee AAala siratinmustaqeem

Yoruba
 
Dájúdájú èmi gbáralé Allāhu, Olúwa mi àti Olúwa yín. Kò sí ẹ̀dá abẹ̀mí kan àfi kí (ó jẹ́ pé) Òun l'Ó máa fi àásó orí rẹ̀ mú un. Dájúdájú Olúwa mi wà lórí ọ̀nà tààrà.

Ayah  11:57  الأية
فَإِن تَوَلَّوْا فَقَدْ أَبْلَغْتُكُم مَّا أُرْسِلْتُ بِهِ إِلَيْكُمْ ۚ وَيَسْتَخْلِفُ رَبِّي قَوْمًا غَيْرَكُمْ وَلَا تَضُرُّونَهُ شَيْئًا ۚ إِنَّ رَبِّي عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ حَفِيظٌ
Fa-in tawallaw faqad ablaghtukum maorsiltu bihi ilaykum wayastakhlifu rabbee qawman ghayrakum walatadurroonahu shay-an inna rabbee AAala kullishay-in hafeeth

Yoruba
 
Nítorí náà, tí ẹ bá pẹ̀yìn dà (níbi òdodo), mo kúkú ti fi ohun tí Wọ́n fi rán mi níṣẹ́ jíṣẹ́ fún yín, Olúwa mi yó sì fi ìjọ kan tó máa yàtọ̀ sí ẹ̀yin rọ́pò yín. Ẹ kò sì lè kó ìnira kan kan bá A. Dájúdájú Olúwa mi ni Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan."

Ayah  11:58  الأية
وَلَمَّا جَاءَ أَمْرُنَا نَجَّيْنَا هُودًا وَالَّذِينَ آمَنُوا مَعَهُ بِرَحْمَةٍ مِّنَّا وَنَجَّيْنَاهُم مِّنْ عَذَابٍ غَلِيظٍ
Walamma jaa amrunanajjayna hoodan wallatheena amanoomaAAahu birahmatin minna wanajjaynahum minAAathabin ghaleeth

Yoruba
 
Nígbà tí àṣẹ Wa dé, A gba (Ànábì) Hūd àti àwọn tó gbàgbọ́ pẹ̀lú rẹ̀ là pẹ̀lú ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa; A gbà wọ́n là nínú ìyà tó nípọn.

Ayah  11:59  الأية
وَتِلْكَ عَادٌ ۖ جَحَدُوا بِآيَاتِ رَبِّهِمْ وَعَصَوْا رُسُلَهُ وَاتَّبَعُوا أَمْرَ كُلِّ جَبَّارٍ عَنِيدٍ
Watilka AAadun jahadoo bi-ayatirabbihim waAAasaw rusulahu wattabaAAoo amra kullijabbarin AAaneed

Yoruba
 
Ìran ‘Ād nìyẹn; wọ́n tako àwọn āyah Olúwa wọn. Wọ́n sì yapa àwọn Òjíṣẹ́ wọn. Wọ́n sì tẹ̀lé àṣẹ gbogbo àwọn aláfojúdi alátakò-òdodo.

Ayah  11:60  الأية
وَأُتْبِعُوا فِي هَٰذِهِ الدُّنْيَا لَعْنَةً وَيَوْمَ الْقِيَامَةِ ۗ أَلَا إِنَّ عَادًا كَفَرُوا رَبَّهُمْ ۗ أَلَا بُعْدًا لِّعَادٍ قَوْمِ هُودٍ
WaotbiAAoo fee hathihi addunyalaAAnatan wayawma alqiyamati ala inna AAadankafaroo rabbahum ala buAAdan liAAadin qawmi hood

Yoruba
 
A fi ègún tẹ̀lé wọn nílé ayé yìí àti ní Ọjọ́ Àjíǹde. Gbọ́, dájúdájú ìran ‘Ād ṣàì gbàgbọ́ nínú Olúwa wọn. Kíyè sí i, kí ìjìnnà sí ìkẹ́ máa jẹ́ ti ìran ‘Ād, ìjọ (Ànábì) Hūd.

Ayah  11:61  الأية
وَإِلَىٰ ثَمُودَ أَخَاهُمْ صَالِحًا ۚ قَالَ يَا قَوْمِ اعْبُدُوا اللهَ مَا لَكُم مِّنْ إِلَٰهٍ غَيْرُهُ ۖ هُوَ أَنشَأَكُم مِّنَ الْأَرْضِ وَاسْتَعْمَرَكُمْ فِيهَا فَاسْتَغْفِرُوهُ ثُمَّ تُوبُوا إِلَيْهِ ۚ إِنَّ رَبِّي قَرِيبٌ مُّجِيبٌ
Wa-ila thamooda akhahum salihanqala ya qawmi oAAbudoo Allaha malakum min ilahin ghayruhu huwa anshaakum mina al-ardiwastaAAmarakum feeha fastaghfiroohu thummatooboo ilayhi inna rabbee qareebun mujeeb

Yoruba
 
(Ẹni tí A rán níṣẹ́) sí ìran Thamūd ni arákùnrin wọn, (Ànábì) Sọ̄lih. Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ kò ní ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo lẹ́yìn Rẹ̀. Òun l'Ó pílẹ̀ ìṣẹ̀dá yín láti ara (erùpẹ̀) ilẹ̀. Ó sì fún yín ní ìṣẹ̀mí lò lórí rẹ̀. Nítorí náà, ẹ tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ẹ ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Rẹ̀. Dájúdájú Olúwa mi ni Olùsúnmọ́, Olùjẹ́pè (ẹ̀dá)."

Ayah  11:62  الأية
قَالُوا يَا صَالِحُ قَدْ كُنتَ فِينَا مَرْجُوًّا قَبْلَ هَٰذَا ۖ أَتَنْهَانَا أَن نَّعْبُدَ مَا يَعْبُدُ آبَاؤُنَا وَإِنَّنَا لَفِي شَكٍّ مِّمَّا تَدْعُونَا إِلَيْهِ مُرِيبٍ
Qaloo ya salihuqad kunta feena marjuwwan qabla hatha atanhanaan naAAbuda ma yaAAbudu abaonawa-innana lafee shakkin mimma tadAAoonailayhi mureeb

Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "Sọ̄lih, o ti wà láààrin wa ní ẹni tí a ní ìrètí sí (pé o máa sanjọ́) ṣíwájú (ọ̀rọ̀ tí o sọ) yìí. Ṣé o máa kọ̀ fún wa láti jọ́sìn fún ohun tí àwọn bàbá wa ń jọ́sìn fún ni? Dájúdájú àwa mà wà nínú iyèméjì tó gbópọn nípa n̄ǹkan tí ò ń pè wá sí."

Ayah  11:63  الأية
قَالَ يَا قَوْمِ أَرَأَيْتُمْ إِن كُنتُ عَلَىٰ بَيِّنَةٍ مِّن رَّبِّي وَآتَانِي مِنْهُ رَحْمَةً فَمَن يَنصُرُنِي مِنَ اللهِ إِنْ عَصَيْتُهُ ۖ فَمَا تَزِيدُونَنِي غَيْرَ تَخْسِيرٍ
Qala ya qawmi araaytum inkuntu AAala bayyinatin min rabbee waataneeminhu rahmatan faman yansurunee mina Allahiin AAasaytuhu fama tazeedoonanee ghayra takhseer

Yoruba
 
Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ sọ fún mi, tí ó bá jẹ́ pé èmi wà lórí ẹ̀rí tó yanjú láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi, tí ìkẹ́ kan sì dé bá mi láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀, ta ni ẹni tí ó máa ràn mí lọ́wọ́ nínú (ìyà) Allāhu tí mo bá yapa Rẹ̀? Kò sí kiní kan tí ẹ lè fi ṣe àlékún rẹ̀ fún mi yàtọ̀ sí ìparun.

Ayah  11:64  الأية
وَيَا قَوْمِ هَٰذِهِ نَاقَةُ اللهِ لَكُمْ آيَةً فَذَرُوهَا تَأْكُلْ فِي أَرْضِ اللهِ وَلَا تَمَسُّوهَا بِسُوءٍ فَيَأْخُذَكُمْ عَذَابٌ قَرِيبٌ
Waya qawmi hathihi naqatuAllahi lakum ayatan fatharooha ta/kulfee ardi Allahi wala tamassoohabisoo-in faya/khuthakum AAathabun qareeb

Yoruba
 
Ẹ̀yin ìjọ mi, èyí ni abo ràkúnmí Allāhu. Ó jẹ́ àmì fún yín. Nítorí náà, ẹ fi sílẹ̀, kí ó máa jẹ́ kiri lórí ilẹ̀ Allāhu. Ẹ má ṣe fi ìnira kàn án nítorí kí ìyà tó súnmọ́ má báa jẹ yín."

Ayah  11:65  الأية
فَعَقَرُوهَا فَقَالَ تَمَتَّعُوا فِي دَارِكُمْ ثَلَاثَةَ أَيَّامٍ ۖ ذَٰلِكَ وَعْدٌ غَيْرُ مَكْذُوبٍ
FaAAaqarooha faqalatamattaAAoo fee darikum thalathata ayyamin thalikawaAAdun ghayru makthoob

Yoruba
 
Wọ́n sì gún un pa. Ó sọ pé: "Ẹ jẹ̀gbádùn nínú ilé yín fún ọjọ́ mẹ́ta (kí ìyà yín tó dé). Ìyẹn ni àdéhùn tí kì í ṣe irọ́."

Ayah  11:66  الأية
فَلَمَّا جَاءَ أَمْرُنَا نَجَّيْنَا صَالِحًا وَالَّذِينَ آمَنُوا مَعَهُ بِرَحْمَةٍ مِّنَّا وَمِنْ خِزْيِ يَوْمِئِذٍ ۗ إِنَّ رَبَّكَ هُوَ الْقَوِيُّ الْعَزِيزُ
Falamma jaa amrunanajjayna salihan wallatheena amanoomaAAahu birahmatin minna wamin khizyi yawmi-ithininna rabbaka huwa alqawiyyu alAAazeez

Yoruba
 
Nígbà tí àṣẹ Wa dé, A gba (Ànábì) Sọ̄lih àti àwọn tó gbàgbọ́ pẹ̀lú rẹ̀ là pẹ̀lú ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa. (A tún gbà wọ́n là) nínú àbùkù ọjọ́ yẹn. Dájúdájú Olúwa Rẹ, Òun ni Alágbára, Olùborí (ẹ̀dá).

Ayah  11:67  الأية
وَأَخَذَ الَّذِينَ ظَلَمُوا الصَّيْحَةُ فَأَصْبَحُوا فِي دِيَارِهِمْ جَاثِمِينَ
Waakhatha allatheena thalamooassayhatu faasbahoo fee diyarihimjathimeen

Yoruba
 
Ohùn igbe líle gbá àwọn tó ṣàbòsí mú. Wọ́n sì dà lulẹ̀, tí wọ́n ti dòkú sínú ìlú wọn.

Ayah  11:68  الأية
كَأَن لَّمْ يَغْنَوْا فِيهَا ۗ أَلَا إِنَّ ثَمُودَ كَفَرُوا رَبَّهُمْ ۗ أَلَا بُعْدًا لِّثَمُودَ
Kaan lam yaghnaw feeha alainna thamooda kafaroo rabbahum ala buAAdan lithamood

Yoruba
 
Àfi bí ẹni pé wọn kò gbénú ìlú náà rí. Gbọ́, dájúdájú ìran Thamūd ṣàì gbàgbọ́ nínú Olúwa wọn. Kíyè sí i, kí ìjìnnà sí ìkẹ́ máa jẹ́ ti ìjọ Thamūd.

Ayah  11:69  الأية
وَلَقَدْ جَاءَتْ رُسُلُنَا إِبْرَاهِيمَ بِالْبُشْرَىٰ قَالُوا سَلَامًا ۖ قَالَ سَلَامٌ ۖ فَمَا لَبِثَ أَن جَاءَ بِعِجْلٍ حَنِيذٍ
Walaqad jaat rusuluna ibraheemabilbushra qaloo salaman qalasalamun fama labitha an jaa biAAijlin haneeth

Yoruba
 
Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ Wa ti mú ìró ìdùnnú wá bá (Ànábì) 'Ibrọ̄hīm. Wọ́n sọ pé: "Àlàáfíà (fún ọ)." Ó sọ pé: "Àlàáfíà (fún yín)." Kò sì pẹ́ rárá tó fi gbé ọmọ màálù àyangbẹ wá.

Ayah  11:70  الأية
فَلَمَّا رَأَىٰ أَيْدِيَهُمْ لَا تَصِلُ إِلَيْهِ نَكِرَهُمْ وَأَوْجَسَ مِنْهُمْ خِيفَةً ۚ قَالُوا لَا تَخَفْ إِنَّا أُرْسِلْنَا إِلَىٰ قَوْمِ لُوطٍ
Falamma raa aydiyahum latasilu ilayhi nakirahum waawjasa minhum kheefatan qaloola takhaf inna orsilna ila qawmi loot

Yoruba
 
Nígbà tí ó rí ọwọ́ wọn pé kò kan oúnjẹ náà, ó pajú dà sí wọn (ó f'ojú òdì wo àìjẹun wọn). Ìbẹ̀rù wọn sì mú un. Wọ́n sọ pé: "Má ṣe bẹ̀rù. Dájúdájú àwọn ènìyàn (Ànábì) Lūt ni Wọ́n rán àwa sí."

Ayah  11:71  الأية
وَامْرَأَتُهُ قَائِمَةٌ فَضَحِكَتْ فَبَشَّرْنَاهَا بِإِسْحَاقَ وَمِن وَرَاءِ إِسْحَاقَ يَعْقُوبَ
Wamraatuhu qa-imatun fadahikatfabashsharnaha bi-ishaqa wamin wara-iishaqa yaAAqoob

Yoruba
 
Ìyàwó rẹ̀ wà ní ìdúró, ó rẹ́rìn-ín. A sì fún un ní ìró ìdùnnú (pé ó máa bí) 'Ishāƙ. Àti pé lẹ́yìn 'Ishāƙ ni Ya‘ƙūb (ìyẹn, ọmọọmọ).

Ayah  11:72  الأية
قَالَتْ يَا وَيْلَتَىٰ أَأَلِدُ وَأَنَا عَجُوزٌ وَهَٰذَا بَعْلِي شَيْخًا ۖ إِنَّ هَٰذَا لَشَيْءٌ عَجِيبٌ
Qalat ya waylata aaliduwaana AAajoozun wahatha baAAlee shaykhan inna hathalashay-on AAajeeb

Yoruba
 
Ó sọ pé: "Hẹ̀n-ẹ́n! Ṣé pé mo máa bímọ, arúgbóbìnrin ni mí, baálé mi yìí sì ti dàgbàlágbà! Dájúdájú èyí ni n̄ǹkan ìyanu."

Ayah  11:73  الأية
قَالُوا أَتَعْجَبِينَ مِنْ أَمْرِ اللهِ ۖ رَحْمَتُ اللهِ وَبَرَكَاتُهُ عَلَيْكُمْ أَهْلَ الْبَيْتِ ۚ إِنَّهُ حَمِيدٌ مَّجِيدٌ
Qaloo ataAAjabeena min amri Allahirahmatu Allahi wabarakatuhu AAalaykum ahlaalbayti innahu hameedun majeed

Yoruba
 
Wọ́n sọ pé: "Ṣé o máa ṣèèmọ̀ nípa àṣẹ Allāhu ni? Ìkẹ́ Allāhu àti ìbùkún Rẹ̀ kí ó máa bẹ fún yín, ẹ̀yin ará ilé (yìí). Dájúdájú Allāhu ni Ẹlẹ́yìn, Ológo."

Ayah  11:74  الأية
فَلَمَّا ذَهَبَ عَنْ إِبْرَاهِيمَ الرَّوْعُ وَجَاءَتْهُ الْبُشْرَىٰ يُجَادِلُنَا فِي قَوْمِ لُوطٍ
Falamma thahaba AAan ibraheemaarrawAAu wajaat-hu albushra yujadilunafee qawmi loot

Yoruba
 
Nígbà tí ìbẹ̀rù kúrò lára (Ànábì) 'Ibrọ̄hīm, tí ìró ìdùnnú sì ti dé bá a ló bá ń pàrọwà fún (àwọn Òjíṣẹ́) Wa nípa ìjọ (Ànábì) Lūt.

Ayah  11:75  الأية
إِنَّ إِبْرَاهِيمَ لَحَلِيمٌ أَوَّاهٌ مُّنِيبٌ
Inna ibraheema lahaleemun awwahunmuneeb

Yoruba
 
Dájúdájú (Ànábì) 'Ibrọ̄hīm ni aláfaradà, olùrawọ́rasẹ̀, olùronúpìwàdà.

Ayah  11:76  الأية
يَا إِبْرَاهِيمُ أَعْرِضْ عَنْ هَٰذَا ۖ إِنَّهُ قَدْ جَاءَ أَمْرُ رَبِّكَ ۖ وَإِنَّهُمْ آتِيهِمْ عَذَابٌ غَيْرُ مَرْدُودٍ
Ya ibraheemu aAAridAAan hatha innahu qad jaa amru rabbika wa-innahum ateehimAAathabun ghayru mardood

Yoruba
 
(Ànábì) 'Ibrọ̄hīm, ṣẹ́rí kúrò níbi èyí. Dájúdájú àṣẹ Olúwa rẹ ti dé. Àti pé dájúdájú àwọn (wọ̀nyẹn) ni ìyà tí kò ṣe é dá padà yóò dé bá.

Ayah  11:77  الأية
وَلَمَّا جَاءَتْ رُسُلُنَا لُوطًا سِيءَ بِهِمْ وَضَاقَ بِهِمْ ذَرْعًا وَقَالَ هَٰذَا يَوْمٌ عَصِيبٌ
Walamma jaat rusulunalootan see-a bihim wadaqa bihim tharAAan waqalahatha yawmun AAaseeb

Yoruba
 
Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ Wa dé bá (Ànábì) Lūt, ó banújẹ́ nítorí wọn. Agbára rẹ̀ kò sì ká ọ̀rọ̀ wọn mọ́. Ó sì sọ pé: "Ọjọ́ tó le gan-an ní èyí."

Ayah  11:78  الأية
وَجَاءَهُ قَوْمُهُ يُهْرَعُونَ إِلَيْهِ وَمِن قَبْلُ كَانُوا يَعْمَلُونَ السَّيِّئَاتِ ۚ قَالَ يَا قَوْمِ هَٰؤُلَاءِ بَنَاتِي هُنَّ أَطْهَرُ لَكُمْ ۖ فَاتَّقُوا اللهَ وَلَا تُخْزُونِ فِي ضَيْفِي ۖ أَلَيْسَ مِنكُمْ رَجُلٌ رَّشِيدٌ
Wajaahu qawmuhu yuhraAAoona ilayhiwamin qablu kanoo yaAAmaloona assayyi-ati qalaya qawmi haola-i banatee hunna atharulakum fattaqoo Allaha wala tukhzooni fee dayfeealaysa minkum rajulun rasheed

Yoruba
 
Àwọn ènìyàn rẹ̀ wá bá a, tí wọ́n ń sáré gbọ̀n wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n sì ti ń ṣe iṣẹ́ aburú (bí ìbálòpọ̀ ọkùnrin sí ọkùnrin). Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ènìyàn mi, àwọn wọ̀nyí ni ọmọbìnrin mi, wọ́n mọ́ jùlọ fún yín (láti fi ṣaya dípò ìbálòpọ̀ ọkùnrin sí ọkùnrin). Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì má ṣe dójú tì mí lọ́dọ̀ àlejò mi. Ṣé kò sí ọkùnrin kan tí ó lóye lórí nínú yín ni?"

Ayah  11:79  الأية
قَالُوا لَقَدْ عَلِمْتَ مَا لَنَا فِي بَنَاتِكَ مِنْ حَقٍّ وَإِنَّكَ لَتَعْلَمُ مَا نُرِيدُ
Qaloo laqad AAalimta ma lanafee banatika min haqqin wa-innaka lataAAlamu manureed

Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "Ìwọ kúkú ti mọ̀ pé àwa kò ní bùkátà kan sí àwọn ọmọbìnrin rẹ. O sì ti mọ n̄ǹkan tí à ń fẹ́."

Ayah  11:80  الأية
قَالَ لَوْ أَنَّ لِي بِكُمْ قُوَّةً أَوْ آوِي إِلَىٰ رُكْنٍ شَدِيدٍ
Qala law anna lee bikum quwwatan aw aweeila ruknin shadeed

Yoruba
 
Ó sọ pé: "Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú agbára kan wà fún mi lórí yín ni, tàbí (pé) mo lè darapọ̀ mọ́ ẹbí kan (tàbí ikọ̀ ọmọ-ogun kan) tó lágbára ni, (èmi ìbá di yín lọ́wọ́ níbi aburú yín)."

Ayah  11:81  الأية
قَالُوا يَا لُوطُ إِنَّا رُسُلُ رَبِّكَ لَن يَصِلُوا إِلَيْكَ ۖ فَأَسْرِ بِأَهْلِكَ بِقِطْعٍ مِّنَ اللَّيْلِ وَلَا يَلْتَفِتْ مِنكُمْ أَحَدٌ إِلَّا امْرَأَتَكَ ۖ إِنَّهُ مُصِيبُهَا مَا أَصَابَهُمْ ۚ إِنَّ مَوْعِدَهُمُ الصُّبْحُ ۚ أَلَيْسَ الصُّبْحُ بِقَرِيبٍ
Qaloo ya lootu innarusulu rabbika lan yasiloo ilayka faasri bi-ahlika biqitAAinmina allayli wala yaltafit minkum ahadun illaimraataka innahu museebuha ma asabahuminna mawAAidahumu assubhu alaysa assubhubiqareeb

Yoruba
 
(Àwọn mọlāika) sọ pé: "(Ànábì) Lūt, dájúdájú Òjíṣẹ́ Olúwa rẹ ni àwa. Wọn kò lè (fọwọ́ aburú) kàn ọ́. Nítorí náà, mú àwọn ará ilé rẹ jáde ní abala kan nínú òru. Kí ẹnì kan nínú yín má sì ṣe ṣíjú wẹ̀yìn wò, àfi ìyàwó rẹ, dájúdájú ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn ló máa ṣẹlẹ̀ sí i. Dájúdájú àkókò (àdánwò) wọn ni òwúrọ̀. Ṣé òwúrọ̀ kò súnmọ́ ni?

Ayah  11:82  الأية
فَلَمَّا جَاءَ أَمْرُنَا جَعَلْنَا عَالِيَهَا سَافِلَهَا وَأَمْطَرْنَا عَلَيْهَا حِجَارَةً مِّن سِجِّيلٍ مَّنضُودٍ
Falamma jaa amrunajaAAalna AAaliyaha safilahawaamtarna AAalayha hijaratanmin sijjeelin mandood

Yoruba
 
Nígbà tí àṣẹ Wa dé, A sọ òkè ìlú wọn di ìsàlẹ̀ rẹ̀ (ìlú wọ́n sì dojú bolẹ̀). A tún rọ òjò òkúta amọ̀ sísun lé wọn lórí ní tẹ̀léǹtẹ̀lé.

Ayah  11:83  الأية
مُّسَوَّمَةً عِندَ رَبِّكَ ۖ وَمَا هِيَ مِنَ الظَّالِمِينَ بِبَعِيدٍ
Musawwamatan AAinda rabbika wama hiyamina aththalimeena bibaAAeed

Yoruba
 
(Àwọn òkúta náà) ti ní àmì (orúkọ ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn lára) láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Wọn kò sì jìnnà sí àwọn alábòsí.

Ayah  11:84  الأية
وَإِلَىٰ مَدْيَنَ أَخَاهُمْ شُعَيْبًا ۚ قَالَ يَا قَوْمِ اعْبُدُوا اللهَ مَا لَكُم مِّنْ إِلَٰهٍ غَيْرُهُ ۖ وَلَا تَنقُصُوا الْمِكْيَالَ وَالْمِيزَانَ ۚ إِنِّي أَرَاكُم بِخَيْرٍ وَإِنِّي أَخَافُ عَلَيْكُمْ عَذَابَ يَوْمٍ مُّحِيطٍ
Wa-ila madyana akhahumshuAAayban qala ya qawmi oAAbudoo Allaha malakum min ilahin ghayruhu wala tanqusooalmikyala walmeezana innee arakumbikhayrin wa-innee akhafu AAalaykum AAathaba yawminmuheet

Yoruba
 
(Ẹni tí A rán níṣẹ́) sí ìran Mọdyan ni arákùnrin wọn (Ànábì) Ṣua‘eb. Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ kò ní ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo lẹ́yìn Rẹ̀. Ẹ má ṣe dín kóńgò àti òṣùwọ̀n kù. Mo rí yín pẹ̀lú dáadáa (tí Allāhu ṣe fún yín). Dájúdájú èmi sì ń páyà ìyà ọjọ́ kan tí ó máa yi yín po.

Ayah  11:85  الأية
وَيَا قَوْمِ أَوْفُوا الْمِكْيَالَ وَالْمِيزَانَ بِالْقِسْطِ ۖ وَلَا تَبْخَسُوا النَّاسَ أَشْيَاءَهُمْ وَلَا تَعْثَوْا فِي الْأَرْضِ مُفْسِدِينَ
Waya qawmi awfoo almikyala walmeezanabilqisti wala tabkhasoo annasaashyaahum wala taAAthaw fee al-ardimufsideen

Yoruba
 
Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ wọn kóńgò àti òṣùwọ̀n kún ní dọ́gban̄n̄dọ́gba. Ẹ má ṣe dín n̄ǹkan àwọn ènìyàn kù. Kí ẹ sì má ṣèbàjẹ́ sórí ilẹ̀.

Ayah  11:86  الأية
بَقِيَّتُ اللهِ خَيْرٌ لَّكُمْ إِن كُنتُم مُّؤْمِنِينَ ۚ وَمَا أَنَا عَلَيْكُم بِحَفِيظٍ
Baqiyyatu Allahi khayrun lakum inkuntum mu/mineena wama ana AAalaykum bihafeeth

Yoruba
 
Ohun tí Allāhu bá ṣẹ́kù fún yín (nínú halāl) lóore jùlọ fún yín tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo. Èmi kì í sì ṣe olùṣọ́ lórí yín."

Ayah  11:87  الأية
قَالُوا يَا شُعَيْبُ أَصَلَاتُكَ تَأْمُرُكَ أَن نَّتْرُكَ مَا يَعْبُدُ آبَاؤُنَا أَوْ أَن نَّفْعَلَ فِي أَمْوَالِنَا مَا نَشَاءُ ۖ إِنَّكَ لَأَنتَ الْحَلِيمُ الرَّشِيدُ
Qaloo ya shuAAaybu asalatukata/muruka an natruka ma yaAAbudu abaonaaw an nafAAala fee amwalina ma nashaoinnaka laanta alhaleemu arrasheed

Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "Ṣu‘aeb, ṣé ìrun rẹ ló ń pa ọ́ láṣẹ pé kí á gbé ohun tí àwọn bàbá wa ń jọ́sìn fún jù sílẹ̀, tàbí (ìrun rẹ ló ń kọ̀ fún wa) láti ṣe ohun tí a bá fẹ́ nínú dúkìá wa? Dájúdájú ìwọ mà ni olùfaradà, olóye (lójú ara rẹ nìyẹn)."

Ayah  11:88  الأية
قَالَ يَا قَوْمِ أَرَأَيْتُمْ إِن كُنتُ عَلَىٰ بَيِّنَةٍ مِّن رَّبِّي وَرَزَقَنِي مِنْهُ رِزْقًا حَسَنًا ۚ وَمَا أُرِيدُ أَنْ أُخَالِفَكُمْ إِلَىٰ مَا أَنْهَاكُمْ عَنْهُ ۚ إِنْ أُرِيدُ إِلَّا الْإِصْلَاحَ مَا اسْتَطَعْتُ ۚ وَمَا تَوْفِيقِي إِلَّا بِاللهِ ۚ عَلَيْهِ تَوَكَّلْتُ وَإِلَيْهِ أُنِيبُ
Qala ya qawmi araaytum inkuntu AAala bayyinatin min rabbee warazaqanee minhu rizqanhasanan wama oreedu an okhalifakum ilama anhakum AAanhu in oreedu illa al-islahama istataAAtu wama tawfeeqee illa billahiAAalayhi tawakkaltu wa-ilayhi oneeb

Yoruba
 
Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ sọ fún mi, tí ó bá jẹ́ pé mo wà lórí ẹ̀rí tó yanjú láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi, tí (Olúwa mi) sì fún mi ní arísìkí láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ní arísìkí tó dára (ṣé kí n̄g máa jẹ harāmu pẹ̀lú rẹ̀ ni?). Èmi kò sì fẹ́ yapa yín nípa n̄ǹkan tí mò ń kọ̀ fún yín (ìyẹn ni pé, èmi náà ń lo ohun tí mò ń sọ fún yín). Kò sí ohun tí mo fẹ́ bí kò ṣe àtúnṣe pẹ̀lú bí mo ṣe lágbára mọ. Kò sí kòǹgẹ́ ìmọ̀nà kan fún mi bí kò ṣe pẹ̀lú (ìyọ̀ǹda) Allāhu. Òun ni mo gbáralé. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni mo máa ṣẹ́rí sí (fún ìronúpìwàdà).

Ayah  11:89  الأية
وَيَا قَوْمِ لَا يَجْرِمَنَّكُمْ شِقَاقِي أَن يُصِيبَكُم مِّثْلُ مَا أَصَابَ قَوْمَ نُوحٍ أَوْ قَوْمَ هُودٍ أَوْ قَوْمَ صَالِحٍ ۚ وَمَا قَوْمُ لُوطٍ مِّنكُم بِبَعِيدٍ
Waya qawmi la yajrimannakumshiqaqee an yuseebakum mithlu ma asabaqawma noohin aw qawma hoodin aw qawma salihinwama qawmu lootin minkum bibaAAeed

Yoruba
 
Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí (bí) ẹ ṣe ń yapa mi mu yín lùgbàdì irú ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ìjọ (Ànábì) Nūh tàbí ìjọ (Ànábì) Hūd tàbí ìjọ (Ànábì) Sọ̄lih. Ìjọ (Ànábì) Lūt kò sì jìnnà si yín.

Ayah  11:90  الأية
وَاسْتَغْفِرُوا رَبَّكُمْ ثُمَّ تُوبُوا إِلَيْهِ ۚ إِنَّ رَبِّي رَحِيمٌ وَدُودٌ
Wastaghfiroo rabbakum thumma toobooilayhi inna rabbee raheemun wadood

Yoruba
 
Kí ẹ sì tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Olúwa yín. Lẹ́yìn náà, kí ẹ ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Rẹ̀. Dájúdájú Olúwa mi ni Aláàánú, Olólùfẹ́ (ẹ̀dá)."

Ayah  11:91  الأية
قَالُوا يَا شُعَيْبُ مَا نَفْقَهُ كَثِيرًا مِّمَّا تَقُولُ وَإِنَّا لَنَرَاكَ فِينَا ضَعِيفًا ۖ وَلَوْلَا رَهْطُكَ لَرَجَمْنَاكَ ۖ وَمَا أَنتَ عَلَيْنَا بِعَزِيزٍ
Qaloo ya shuAAaybu manafqahu katheeran mimma taqoolu wa-inna lanarakafeena daAAeefan walawla rahtukalarajamnaka wama anta AAalayna biAAazeez

Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "Ṣu‘aeb, a kò gbọ́ àgbọ́yé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú ohun tí ò ń sọ. Dájúdájú àwa sì ń rí ọ ní ọ̀lẹ láààrin wa. Tí kò bá jẹ́ pé nítorí ti ẹbí rẹ ni, àwa ìbá ti kù ọ́ lókò pa; ìwọ kò sì lágbára kan lórí wa."

Ayah  11:92  الأية
قَالَ يَا قَوْمِ أَرَهْطِي أَعَزُّ عَلَيْكُم مِّنَ اللهِ وَاتَّخَذْتُمُوهُ وَرَاءَكُمْ ظِهْرِيًّا ۖ إِنَّ رَبِّي بِمَا تَعْمَلُونَ مُحِيطٌ
Qala ya qawmi arahteeaAAazzu AAalaykum mina Allahi wattakhathtumoohuwaraakum thihriyyan inna rabbee bimataAAmaloona muheet

Yoruba
 
Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ṣé ẹbí mi ló lágbára lójú yin ju Allāhu? Ẹ sì sọ Allāhu di Ẹni tí ẹ kọ̀yìn sí! Dájúdájú Olúwa mi ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

Ayah  11:93  الأية
وَيَا قَوْمِ اعْمَلُوا عَلَىٰ مَكَانَتِكُمْ إِنِّي عَامِلٌ ۖ سَوْفَ تَعْلَمُونَ مَن يَأْتِيهِ عَذَابٌ يُخْزِيهِ وَمَنْ هُوَ كَاذِبٌ ۖ وَارْتَقِبُوا إِنِّي مَعَكُمْ رَقِيبٌ
Waya qawmi iAAmaloo AAala makanatikuminnee AAamilun sawfa taAAlamoona man ya/teehi AAathabunyukhzeehi waman huwa kathibun wartaqiboo innemaAAakum raqeeb

Yoruba
 
Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ máa ṣe bí ẹ ti fẹ́ nínú ẹ̀sìn yín, dájúdájú èmi náà yóò máa bá ẹ̀sìn mi lọ. Láìpẹ́ ẹ̀yin yóò mọ ẹni tí ìyà máa dé bá, tí ó máa yẹpẹrẹ rẹ̀, (ẹ̀yin yó sì mọ) ta ni òpùrọ́. Nítorí náà, ẹ máa retí. Dájúdájú èmi náà wà pẹ̀lú yín tí mò ń retí (ìkángun ọ̀rọ̀ yín)."

Ayah  11:94  الأية
وَلَمَّا جَاءَ أَمْرُنَا نَجَّيْنَا شُعَيْبًا وَالَّذِينَ آمَنُوا مَعَهُ بِرَحْمَةٍ مِّنَّا وَأَخَذَتِ الَّذِينَ ظَلَمُوا الصَّيْحَةُ فَأَصْبَحُوا فِي دِيَارِهِمْ جَاثِمِينَ
Walamma jaa amrunanajjayna shuAAayban wallatheena amanoomaAAahu birahmatin minna waakhathati allatheenathalamoo assayhatu faasbahoofee diyarihim jathimeen

Yoruba
 
Nígbà tí àṣẹ Wa dé, A gba (Ànábì) Ṣu‘aeb àti àwọn tó gbàgbọ́ pẹ̀lú rẹ̀ là pẹ̀lú ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa. Ohùn igbe líle gbá àwọn tó ṣàbòsí mú. Wọ́n sì dà lulẹ̀, tí wọ́n ti dòkú sínú ìlú wọn.

Ayah  11:95  الأية
كَأَن لَّمْ يَغْنَوْا فِيهَا ۗ أَلَا بُعْدًا لِّمَدْيَنَ كَمَا بَعِدَتْ ثَمُودُ
Kaan lam yaghnaw feeha alabuAAdan limadyana kama baAAidat thamood

Yoruba
 
Àfi bí ẹni pé wọn kò gbénú ìlú náà rí.. Gbọ́, kí ìjìnnà sí ìkẹ́ máa jẹ́ ti ìran Mọdyan gẹ́gẹ́ bí ìran Thamūd ṣe jìnnà sí ìkẹ́.

Ayah  11:96  الأية
وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا مُوسَىٰ بِآيَاتِنَا وَسُلْطَانٍ مُّبِينٍ
Walaqad arsalna moosa bi-ayatinawasultanin mubeen

Yoruba
 
Dájúdájú A fi àwọn àmì Wa àti ẹ̀rí pọ́nńbélé rán (Ànábì) Mūsā níṣẹ́

Ayah  11:97  الأية
إِلَىٰ فِرْعَوْنَ وَمَلَئِهِ فَاتَّبَعُوا أَمْرَ فِرْعَوْنَ ۖ وَمَا أَمْرُ فِرْعَوْنَ بِرَشِيدٍ
Ila firAAawna wamala-ihi fattabaAAooamra firAAawna wama amru firAAawna birasheed

Yoruba
 
Sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀. Àwọn ènìyàn sì tẹ̀lé àṣẹ Fir‘aon. Àṣẹ Fir‘aon kò sì jẹ́ ìmọ̀nà.

Ayah  11:98  الأية
يَقْدُمُ قَوْمَهُ يَوْمَ الْقِيَامَةِ فَأَوْرَدَهُمُ النَّارَ ۖ وَبِئْسَ الْوِرْدُ الْمَوْرُودُ
Yaqdumu qawmahu yawma alqiyamatifaawradahumu annara wabi/sa alwirdu almawrood

Yoruba
 
Ó máa ṣíwájú ìjọ rẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ó sì máa kó wọn wọ inú Iná. Wíwọ Iná náà sì burú.

Ayah  11:99  الأية
وَأُتْبِعُوا فِي هَٰذِهِ لَعْنَةً وَيَوْمَ الْقِيَامَةِ ۚ بِئْسَ الرِّفْدُ الْمَرْفُودُ
WaotbiAAoo fee hathihi laAAnatanwayawma alqiyamati bi/sa arrifdu almarfood

Yoruba
 
A fi ègún tẹ̀lé wọn nílé ayé yìí àti ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ẹ̀bùn náà tí wọ́n fún wọn ní tẹ̀léǹtẹ̀lé (ègún àti Iná) sì burú.

Ayah  11:100  الأية
ذَٰلِكَ مِنْ أَنبَاءِ الْقُرَىٰ نَقُصُّهُ عَلَيْكَ ۖ مِنْهَا قَائِمٌ وَحَصِيدٌ
Thalika min anba-i alquranaqussuhu AAalayka minha qa-imun wahaseed

Yoruba
 
Ìyẹn wà nínú àwọn ìró ìlú tí À ń sọ ìtàn rẹ̀ fún ọ. Ó wà nínú àwọn ìlú náà èyí tí ó sì ń jẹ́ ìlú àti èyí tí wọ́n ti parẹ́.

Ayah  11:101  الأية
وَمَا ظَلَمْنَاهُمْ وَلَٰكِن ظَلَمُوا أَنفُسَهُمْ ۖ فَمَا أَغْنَتْ عَنْهُمْ آلِهَتُهُمُ الَّتِي يَدْعُونَ مِن دُونِ اللهِ مِن شَيْءٍ لَّمَّا جَاءَ أَمْرُ رَبِّكَ ۖ وَمَا زَادُوهُمْ غَيْرَ تَتْبِيبٍ
Wama thalamnahumwalakin thalamoo anfusahum famaaghnat AAanhum alihatuhumu allatee yadAAoona min dooni Allahimin shay-in lamma jaa amru rabbika wama zadoohumghayra tatbeeb

Yoruba
 
A kò ṣàbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn. Nítorí náà, àwọn òrìṣà wọn, tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Allāhu, kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nígbà tí àṣẹ Olúwa rẹ dé. Wọn kò ṣe àlékún kan fún wọn bí kò ṣe ìparun.

Ayah  11:102  الأية
وَكَذَٰلِكَ أَخْذُ رَبِّكَ إِذَا أَخَذَ الْقُرَىٰ وَهِيَ ظَالِمَةٌ ۚ إِنَّ أَخْذَهُ أَلِيمٌ شَدِيدٌ
Wakathalika akhthu rabbika ithaakhatha alqura wahiya thalimatuninna akhthahu aleemun shadeed

Yoruba
 
Báyẹn ni ìgbámú Olúwa rẹ. Nígbà tí Ó bá gbá àwọn ìlú alábòsí mú, dájúdájú Ó máa gbá a mú pẹ̀lú ìyà ẹlẹ́ta-eléro tó le.

Ayah  11:103  الأية
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً لِّمَنْ خَافَ عَذَابَ الْآخِرَةِ ۚ ذَٰلِكَ يَوْمٌ مَّجْمُوعٌ لَّهُ النَّاسُ وَذَٰلِكَ يَوْمٌ مَّشْهُودٌ
Inna fee thalika laayatanliman khafa AAathaba al-akhirati thalikayawmun majmooAAun lahu annasu wathalikayawmun mashhoodun

Yoruba
 
Dájúdájú àmì (fèyíkọ́gbọ́n) wà nínú ìyẹn fún ẹnikẹ́ni tó páyà ìyà Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Ìyẹn ni ọjọ́ tí A óò kó àwọn ènìyàn jọ fún. Àti pé ìyẹn ni ọjọ́ tí gbogbo ẹ̀dá yóò fojú rí.

Ayah  11:104  الأية
وَمَا نُؤَخِّرُهُ إِلَّا لِأَجَلٍ مَّعْدُودٍ
Wama nu-akhkhiruhu illali-ajalin maAAdood

Yoruba
 
A kò sì fi falẹ̀ bí kò ṣe títí di àkókò kan tí A ti ṣírò kalẹ̀.

Ayah  11:105  الأية
يَوْمَ يَأْتِ لَا تَكَلَّمُ نَفْسٌ إِلَّا بِإِذْنِهِ ۚ فَمِنْهُمْ شَقِيٌّ وَسَعِيدٌ
Yawma ya/ti la takallamu nafsun illabi-ithnihi faminhum shaqiyyun wasaAAeed

Yoruba
 
Ní ọjọ́ tó bá dé, ẹ̀mí kan kò níí sọ̀rọ̀ àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Olórí burúkú àti olórí ire yó sì wà nínú àwọn ẹ̀dá (ní ọjọ́ náà).

Ayah  11:106  الأية
فَأَمَّا الَّذِينَ شَقُوا فَفِي النَّارِ لَهُمْ فِيهَا زَفِيرٌ وَشَهِيقٌ
Faamma allatheena shaqoofafee annari lahum feeha zafeerun washaheeq

Yoruba
 
Ní ti àwọn tó bá ṣorí burúkú, wọn yóò wà nínú Iná. Wọn yóò máa gbin tòò, wọn yó sì máa ké tòò.

Ayah  11:107  الأية
خَالِدِينَ فِيهَا مَا دَامَتِ السَّمَاوَاتُ وَالْأَرْضُ إِلَّا مَا شَاءَ رَبُّكَ ۚ إِنَّ رَبَّكَ فَعَّالٌ لِّمَا يُرِيدُ
Khalideena feeha ma damatiassamawatu wal-ardu illama shaa rabbuka inna rabbaka faAAAAalun limayureed

Yoruba
 
Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ ní òdiwọ̀n ìgbà tí àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fi ń bẹ, àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́. Dájúdájú Olúwa ni Aṣèyí-ó-wùú.

Ayah  11:108  الأية
وَأَمَّا الَّذِينَ سُعِدُوا فَفِي الْجَنَّةِ خَالِدِينَ فِيهَا مَا دَامَتِ السَّمَاوَاتُ وَالْأَرْضُ إِلَّا مَا شَاءَ رَبُّكَ ۖ عَطَاءً غَيْرَ مَجْذُوذٍ
Waamma allatheena suAAidoofafee aljannati khalideena feeha ma damatiassamawatu wal-ardu illama shaa rabbuka AAataan ghayra majthooth

Yoruba
 
Ní ti àwọn tí A bá ṣe ní olórí-ire, wọ́n máa wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ ní òdíwọ̀n ìgbà tí àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fi ń bẹ, àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́. (Ọgbà Ìdẹ̀ra jẹ́) ọrẹ àìlópin.

Ayah  11:109  الأية
فَلَا تَكُ فِي مِرْيَةٍ مِّمَّا يَعْبُدُ هَٰؤُلَاءِ ۚ مَا يَعْبُدُونَ إِلَّا كَمَا يَعْبُدُ آبَاؤُهُم مِّن قَبْلُ ۚ وَإِنَّا لَمُوَفُّوهُمْ نَصِيبَهُمْ غَيْرَ مَنقُوصٍ
Fala taku fee miryatin mimmayaAAbudu haola-i ma yaAAbudoona illakama yaAAbudu abaohum min qablu wa-innalamuwaffoohum naseebahum ghayra manqoos

Yoruba
 
Nítorí náà, má ṣe wà nínú iyèméjì nípa ohun tí àwọn wọ̀nyí ń jọ́sìn fún. Wọn kò jọ́sìn fún kiní kan bí kò ṣe bí àwọn bàbá wọn náà ṣe ń jọ́sìn (fún àwọn òrìṣà) ní ìṣáájú. Dájúdájú Àwa yóò san wọ́n ní ẹ̀san ìpín (ìyà) wọn láì níí dín in kù.

Ayah  11:110  الأية
وَلَقَدْ آتَيْنَا مُوسَى الْكِتَابَ فَاخْتُلِفَ فِيهِ ۚ وَلَوْلَا كَلِمَةٌ سَبَقَتْ مِن رَّبِّكَ لَقُضِيَ بَيْنَهُمْ ۚ وَإِنَّهُمْ لَفِي شَكٍّ مِّنْهُ مُرِيبٍ
Walaqad atayna moosaalkitaba fakhtulifa feehi walawla kalimatunsabaqat min rabbika laqudiya baynahum wa-innahum lafeeshakkin minhu mureeb

Yoruba
 
A kúkú fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà. Wọ́n sì yapa-ẹnu nípa rẹ̀. Àti pé tí kò bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ kan ti ṣíwájú láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni, Àwa ìbá ti ṣèdájọ́ láààrin wọn. Dájúdájú wọ́n kúkú wà nínú iyèméjì tó gbópọn nípa al-Ƙur'ān.

Ayah  11:111  الأية
وَإِنَّ كُلًّا لَّمَّا لَيُوَفِّيَنَّهُمْ رَبُّكَ أَعْمَالَهُمْ ۚ إِنَّهُ بِمَا يَعْمَلُونَ خَبِيرٌ
Wa-inna kullan lammalayuwaffiyannahum rabbuka aAAmalahum innahu bimayaAAmaloona khabeer

Yoruba
 
Dájúdájú ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ni Olúwa rẹ yóò san ní ẹ̀san iṣẹ́ wọn. Dájúdájú Òun ni Alámọ̀tán nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

Ayah  11:112  الأية
فَاسْتَقِمْ كَمَا أُمِرْتَ وَمَن تَابَ مَعَكَ وَلَا تَطْغَوْا ۚ إِنَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرٌ
Fastaqim kama omirta waman tabamaAAaka wala tatghaw innahu bima taAAmaloonabaseer

Yoruba
 
Dúró ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí A ṣe pa ìwọ àti ẹnikẹ́ni tí ó bá rónú pìwàdà pẹ̀lú rẹ láṣẹ. Ẹ má ṣe tayọ ẹnu-ààlà. Dájúdájú Òun ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

Ayah  11:113  الأية
وَلَا تَرْكَنُوا إِلَى الَّذِينَ ظَلَمُوا فَتَمَسَّكُمُ النَّارُ وَمَا لَكُم مِّن دُونِ اللهِ مِنْ أَوْلِيَاءَ ثُمَّ لَا تُنصَرُونَ
Wala tarkanoo ila allatheenathalamoo fatamassakumu annaru wamalakum min dooni Allahi min awliyaa thumma latunsaroon

Yoruba
 
Ẹ má ṣe tẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn tó ṣàbòsí nítorí kí Iná má baà fọwọ́ bà yín. Kò sì níí sí àwọn aláàbò fún yín lẹ́yìn Allāhu. Lẹ́yìn náà, A ò níí ràn yín lọ́wọ́.

Ayah  11:114  الأية
وَأَقِمِ الصَّلَاةَ طَرَفَيِ النَّهَارِ وَزُلَفًا مِّنَ اللَّيْلِ ۚ إِنَّ الْحَسَنَاتِ يُذْهِبْنَ السَّيِّئَاتِ ۚ ذَٰلِكَ ذِكْرَىٰ لِلذَّاكِرِينَ
Waaqimi assalata tarafayiannahari wazulafan mina allayli inna alhasanatiyuthhibna assayyi-ati thalika thikraliththakireen

Yoruba
 
Kírun ní etí ọ̀sán méjèèjì àti ní abala kan nínú òru. Dájúdájú àwọn iṣẹ́ rere ń pa àwọn iṣẹ́ aburú rẹ́. Ìyẹn ni ìrántí fún àwọn olùrántí (Allāhu).

Ayah  11:115  الأية
وَاصْبِرْ فَإِنَّ اللهَ لَا يُضِيعُ أَجْرَ الْمُحْسِنِينَ
Wasbir fa-inna Allahala yudeeAAu ajra almuhsineen

Yoruba
 
Ṣe sùúrù. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ẹ̀san àwọn olùṣe-rere ráre.

Ayah  11:116  الأية
فَلَوْلَا كَانَ مِنَ الْقُرُونِ مِن قَبْلِكُمْ أُولُو بَقِيَّةٍ يَنْهَوْنَ عَنِ الْفَسَادِ فِي الْأَرْضِ إِلَّا قَلِيلًا مِّمَّنْ أَنجَيْنَا مِنْهُمْ ۗ وَاتَّبَعَ الَّذِينَ ظَلَمُوا مَا أُتْرِفُوا فِيهِ وَكَانُوا مُجْرِمِينَ
Falawla kana mina alquroonimin qablikum oloo baqiyyatin yanhawna AAani alfasadi feeal-ardi illa qaleelan mimman anjayna minhumwattabaAAa allatheena thalamoo maotrifoo feehi wakanoo mujrimeen

Yoruba
 
Kí ó sì jẹ́ pé àwọn onílàákàyè kan wà nínú àwọn ìran tó ṣíwájú yín (nínú àwọn tí A parẹ́) kí wọ́n máa kọ ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀ - àfi ènìyàn díẹ̀ lára àwọn tí A gbàlà nínú wọn. - Àwọn tó ṣàbòsí sì tẹ̀lé n̄ǹkan tí A fi ṣe gbẹdẹmukẹ fún wọn. Wọ́n sì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀.

Ayah  11:117  الأية
وَمَا كَانَ رَبُّكَ لِيُهْلِكَ الْقُرَىٰ بِظُلْمٍ وَأَهْلُهَا مُصْلِحُونَ
Wama kana rabbuka liyuhlikaalqura bithulmin waahluha muslihoon

Yoruba
 
Olúwa rẹ kì í pa àwọn ìlú run lọ́nà àbòsí, nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ bá jẹ́ olùṣàtùn-únṣe.

Ayah  11:118  الأية
وَلَوْ شَاءَ رَبُّكَ لَجَعَلَ النَّاسَ أُمَّةً وَاحِدَةً ۖ وَلَا يَزَالُونَ مُخْتَلِفِينَ
Walaw shaa rabbuka lajaAAala annasaommatan wahidatan wala yazaloonamukhtalifeen

Yoruba
 
Tí ó bá jẹ́ pé Olúwa rẹ bá fẹ́, ìbá ṣe àwọn ènìyàn ní ìjọ ẹlẹ́sìn kan ṣoṣo. (Àmọ́) wọn kò níí yé yapa-ẹnu (lórí 'Islām)

Ayah  11:119  الأية
إِلَّا مَن رَّحِمَ رَبُّكَ ۚ وَلِذَٰلِكَ خَلَقَهُمْ ۗ وَتَمَّتْ كَلِمَةُ رَبِّكَ لَأَمْلَأَنَّ جَهَنَّمَ مِنَ الْجِنَّةِ وَالنَّاسِ أَجْمَعِينَ
Illa man rahima rabbuka walithalikakhalaqahum watammat kalimatu rabbika laamlaanna jahannama minaaljinnati wannasi ajmaAAeen

Yoruba
 
Àfi ẹni tí Olúwa rẹ bá kẹ́. Nítorí ìyẹn l'Ó fi ṣẹ̀dá wọn. Ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ sì ti ṣẹ (báyìí pé): "Dájúdájú Èmi yóò mú nínú àwọn àlùjànnú àti ènìyàn ní àpapọ̀ kúnnú iná Jahanamọ."

Ayah  11:120  الأية
وَكُلًّا نَّقُصُّ عَلَيْكَ مِنْ أَنبَاءِ الرُّسُلِ مَا نُثَبِّتُ بِهِ فُؤَادَكَ ۚ وَجَاءَكَ فِي هَٰذِهِ الْحَقُّ وَمَوْعِظَةٌ وَذِكْرَىٰ لِلْمُؤْمِنِينَ
Wakullan naqussu AAalayka min anba-iarrusuli ma nuthabbitu bihi fu-adaka wajaakafee hathihi alhaqqu wamawAAithatun wathikralilmu/mineen

Yoruba
 
Gbogbo (n̄ǹkan tí) À ń sọ ìtàn rẹ̀ fún ọ nínú àwọn ìró àwọn Òjísẹ́ ni èyí tí A fi ń fi ọ́ lọ́kàn balẹ̀. Òdodo tún dé bá ọ nínú (sūrah) yìí. Wáàsí àti ìrántí tún ni fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

Ayah  11:121  الأية
وَقُل لِّلَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ اعْمَلُوا عَلَىٰ مَكَانَتِكُمْ إِنَّا عَامِلُونَ
Waqul lillatheena layu/minoona iAAmaloo AAala makanatikum innaAAamiloon

Yoruba
 
Kí o sì sọ fún àwọn tí kò gbàgbọ́ pé: "Ẹ máa ṣe bí ẹ ti fẹ́ nínú ẹ̀sìn yín. Dájúdájú àwa náà yóò máa bá ẹ̀sìn wa lọ.

Ayah  11:122  الأية
وَانتَظِرُوا إِنَّا مُنتَظِرُونَ
Wantathiroo innamuntathiroon

Yoruba
 
Ẹ máa retí, dájúdájú Àwa náà ń retí."

Ayah  11:123  الأية
وَلِلَّهِ غَيْبُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَإِلَيْهِ يُرْجَعُ الْأَمْرُ كُلُّهُ فَاعْبُدْهُ وَتَوَكَّلْ عَلَيْهِ ۚ وَمَا رَبُّكَ بِغَافِلٍ عَمَّا تَعْمَلُونَ
Walillahi ghaybu assamawatiwal-ardi wa-ilayhi yurjaAAu al-amru kulluhu faAAbudhuwatawakkal AAalayhi wama rabbuka bighafilin AAammataAAmaloon

Yoruba
 
Ti Allāhu ni ìkọ̀kọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí gbogbo ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí pátápátá. Nítorí náà, jọ́sìn fún Un, kí o sì gbáralé E. Olúwa rẹ kì í sì ṣe onígbàgbéra nípa n̄ǹkan tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.





© EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us