Prev  

22. Surah Al-Hajj سورة الحج

  Next  



1st Ayah  1  الأية ١الأولي
بِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
يَا أَيُّهَا النَّاسُ اتَّقُوا رَبَّكُمْ ۚ إِنَّ زَلْزَلَةَ السَّاعَةِ شَيْءٌ عَظِيمٌ
Ya ayyuha annasuittaqoo rabbakum inna zalzalata assaAAati shay-onAAatheem

Yoruba
 
Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ bẹ̀rù Olúwa yín. Dájúdájú ìmì tìtì Àkókò náà, n̄ǹkan ńlá ni.

Ayah  22:2  الأية
يَوْمَ تَرَوْنَهَا تَذْهَلُ كُلُّ مُرْضِعَةٍ عَمَّا أَرْضَعَتْ وَتَضَعُ كُلُّ ذَاتِ حَمْلٍ حَمْلَهَا وَتَرَى النَّاسَ سُكَارَىٰ وَمَا هُم بِسُكَارَىٰ وَلَٰكِنَّ عَذَابَ اللهِ شَدِيدٌ
Yawma tarawnaha tathhalu kullumurdiAAatin AAamma ardaAAat watadaAAukullu thati hamlin hamlaha wataraannasa sukara wama hum bisukarawalakinna AAathaba Allahi shadeed

Yoruba
 
(Àkókò náà ni) ọjọ́ tí ẹ máa rí i tí gbogbo obìnrin tó ń fún ọmọ lọ́mú mu yóò gbàgbé ọmọ tí ó ń fún lọ́mú àti pé gbogbo aboyún yó sì máa bí oyún wọn. Ìwọ yó sì rí àwọn ènìyàn tí ọtí yóò máa pa wọ́n. Ọtí kò sì pa wọ́n, ṣùgbọ́n ìyà Allāhu (tó) le (ló fà á).

Ayah  22:3  الأية
وَمِنَ النَّاسِ مَن يُجَادِلُ فِي اللهِ بِغَيْرِ عِلْمٍ وَيَتَّبِعُ كُلَّ شَيْطَانٍ مَّرِيدٍ
Wamina annasi man yujadilufee Allahi bighayri AAilmin wayattabiAAu kulla shaytaninmareed

Yoruba
 
Ó sì ń bẹ nínú àwọn ènìyàn ẹni tó ń jiyàn nípa (ẹ̀sìn) Allāhu láì ní ìmọ̀. Ó sì ń tẹ̀lé gbogbo èṣù olórí kunkun.

Ayah  22:4  الأية
كُتِبَ عَلَيْهِ أَنَّهُ مَن تَوَلَّاهُ فَأَنَّهُ يُضِلُّهُ وَيَهْدِيهِ إِلَىٰ عَذَابِ السَّعِيرِ
Kutiba AAalayhi annahu man tawallahufaannahu yudilluhu wayahdeehi ila AAathabi assaAAeer

Yoruba
 
Wọ́n kọ ọ́ lé (Èṣù) lórí pé dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé e, ó máa ṣì í lọ́nà. Ó sì máa tọ́ ọ sí ọ̀nà ìyà Iná tó ń jo.

Ayah  22:5  الأية
يَا أَيُّهَا النَّاسُ إِن كُنتُمْ فِي رَيْبٍ مِّنَ الْبَعْثِ فَإِنَّا خَلَقْنَاكُم مِّن تُرَابٍ ثُمَّ مِن نُّطْفَةٍ ثُمَّ مِنْ عَلَقَةٍ ثُمَّ مِن مُّضْغَةٍ مُّخَلَّقَةٍ وَغَيْرِ مُخَلَّقَةٍ لِّنُبَيِّنَ لَكُمْ ۚ وَنُقِرُّ فِي الْأَرْحَامِ مَا نَشَاءُ إِلَىٰ أَجَلٍ مُّسَمًّى ثُمَّ نُخْرِجُكُمْ طِفْلًا ثُمَّ لِتَبْلُغُوا أَشُدَّكُمْ ۖ وَمِنكُم مَّن يُتَوَفَّىٰ وَمِنكُم مَّن يُرَدُّ إِلَىٰ أَرْذَلِ الْعُمُرِ لِكَيْلَا يَعْلَمَ مِن بَعْدِ عِلْمٍ شَيْئًا ۚ وَتَرَى الْأَرْضَ هَامِدَةً فَإِذَا أَنزَلْنَا عَلَيْهَا الْمَاءَ اهْتَزَّتْ وَرَبَتْ وَأَنبَتَتْ مِن كُلِّ زَوْجٍ بَهِيجٍ
Ya ayyuha annasuin kuntum fee raybin mina albaAAthi fa-inna khalaqnakummin turabin thumma min nutfatin thumma minAAalaqatin thumma min mudghatin mukhallaqatin waghayrimukhallaqatin linubayyina lakum wanuqirru fee al-arhami manashao ila ajalin musamman thumma nukhrijukum tiflanthumma litablughoo ashuddakum waminkum man yutawaffawaminkum man yuraddu ila arthali alAAumuri likaylayaAAlama min baAAdi AAilmin shay-an watara al-ardahamidatan fa-itha anzalna AAalayhaalmaa ihtazzat warabat waanbatat min kulli zawjin baheej

Yoruba
 
Ẹ̀yin ènìyàn, tí ẹ bá wà nínú iyèméjì nípa àjíǹde, dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá yín láti inú erùpẹ̀, lẹ́yìn náà láti inú àtọ̀, lẹ́yìn náà láti inú ẹ̀jẹ̀ dídì, lẹ́yìn náà láti inú bááṣí ẹran tí ó pé ní ẹ̀dá àti èyí tí kò pé ní ẹ̀dá nítorí kí A lè ṣàlàyé (agbára Wa) fún yín. A sì ń mú ohun tí A bá fẹ́ dúró sínú àpò ìbímọ títí di gbèdéke àkókò kan. Lẹ́yìn náà, A óò mu yín jáde ní òpóǹló. Lẹ́yìn náà, (ẹ óò máa ṣẹ̀mí lọ) nítorí kí ẹ lè sánn̄gun dópin agbára yín. Ẹni tí wọ́n máa pa (ní kékeré) wà nínú yín. Ó sì wà nínú yín ẹni tí wọ́n máa dá (ìṣẹ̀mí) rẹ̀ sí di àsìkò ogbó kùjọ́kùjọ́ nítorí kí ó má lè mọ́ n̄ǹkan kan mọ́ lẹ́yìn tí ó ti mọ̀ ọ́n. Àti pé o máa rí ilẹ̀ ní gbígbẹ. Nígbà tí A bá sì sọ òjò kalẹ̀ lé e lórí, ó máa yíra padà. Ó máa gbèrú. Ó sì máa mú gbogbo oríṣiríṣi irúgbìn tó dára jáde.

Ayah  22:6  الأية
ذَٰلِكَ بِأَنَّ اللهَ هُوَ الْحَقُّ وَأَنَّهُ يُحْيِي الْمَوْتَىٰ وَأَنَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
Thalika bi-anna Allaha huwa alhaqquwaannahu yuhyee almawta waannahu AAala kullishay-in qadeer

Yoruba
 
Ìyẹn (rí bẹ́ẹ̀) nítorí pé dájúdájú Allāhu, Òun ni Òdodo. Dájúdájú Òun l'Ó ń sọ àwọn òkú di alààyè. Dájúdájú Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.

Ayah  22:7  الأية
وَأَنَّ السَّاعَةَ آتِيَةٌ لَّا رَيْبَ فِيهَا وَأَنَّ اللهَ يَبْعَثُ مَن فِي الْقُبُورِ
Waanna assaAAata atiyatunla rayba feeha waanna Allaha yabAAathu manfee alquboor

Yoruba
 
Àti pé dájúdájú Àkókò náà ń bọ̀. Kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Dájúdájú Allāhu yóò gbé àwọn tó ń bẹ nínú sàréè dìde.

Ayah  22:8  الأية
وَمِنَ النَّاسِ مَن يُجَادِلُ فِي اللهِ بِغَيْرِ عِلْمٍ وَلَا هُدًى وَلَا كِتَابٍ مُّنِيرٍ
Wamina annasi man yujadilufee Allahi bighayri AAilmin wala hudan walakitabin muneer

Yoruba
 
Ó ń bẹ nínú àwọn ènìyàn ẹni tó ń jiyàn nípa (ẹ̀sìn) Allāhu láì ní ìmọ̀ (al-Ƙur'ān) àti ìmọ̀nà (sunnah Ànábì) àti tírà (onímọ̀-ẹ̀sìn) tó ń tan ìmọ́lẹ̀ (sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn).

Ayah  22:9  الأية
ثَانِيَ عِطْفِهِ لِيُضِلَّ عَن سَبِيلِ اللهِ ۖ لَهُ فِي الدُّنْيَا خِزْيٌ ۖ وَنُذِيقُهُ يَوْمَ الْقِيَامَةِ عَذَابَ الْحَرِيقِ
Thaniya AAitfihi liyudillaAAan sabeeli Allahi lahu fee addunyakhizyun wanutheequhu yawma alqiyamati AAathabaalhareeq

Yoruba
 
Ó ń ṣègbéraga (sí òdodo, ó ń gbúnrí kúrò níbi òdodo) nítorí kí ó lè kó ìṣìnà bá àwọn ènìyàn lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Àbùkù ń bẹ fún un nílé ayé. Ní Ọjọ́ Àjíǹde, A sì máa fún un ní ìyà Iná jónijóni tọ́ wò.

Ayah  22:10  الأية
ذَٰلِكَ بِمَا قَدَّمَتْ يَدَاكَ وَأَنَّ اللهَ لَيْسَ بِظَلَّامٍ لِّلْعَبِيدِ
Thalika bima qaddamat yadakawaanna Allaha laysa bithallaminlilAAabeed

Yoruba
 
Ìyẹn (rí bẹ́ẹ̀) nítorí ohun tí ọwọ́ rẹ̀ tì síwájú. Dájúdájú Allāhu kò níí ṣàbòsí sí àwọn ẹrúsìn Rẹ̀.

Ayah  22:11  الأية
وَمِنَ النَّاسِ مَن يَعْبُدُ اللهَ عَلَىٰ حَرْفٍ ۖ فَإِنْ أَصَابَهُ خَيْرٌ اطْمَأَنَّ بِهِ ۖ وَإِنْ أَصَابَتْهُ فِتْنَةٌ انقَلَبَ عَلَىٰ وَجْهِهِ خَسِرَ الدُّنْيَا وَالْآخِرَةَ ۚ ذَٰلِكَ هُوَ الْخُسْرَانُ الْمُبِينُ
Wamina annasi man yaAAbuduAllaha AAala harfin fa-in asabahukhayrun itmaanna bihi wa-in asabat-hu fitnatuninqalaba AAala wajhihi khasira addunya wal-akhiratathalika huwa alkhusranu almubeen

Yoruba
 
Ó tún wà nínú àwọn ènìyàn ẹni tó ń jọ́sìn fún Allāhu lórí ahọ́n. Tí rere bá ṣẹlẹ̀ sí i, ó máa fi ọkàn balẹ̀ (sínú ẹ̀sìn). Tí ìfòòró bá sì ṣẹlẹ̀ sí i, ó máa yíjú rẹ̀ padà kúrò nínú ẹ̀sìn. Ó ṣòfò láyé àti lọ́run. Ìyẹn sì ni òfò pọ́nńbélé.

Ayah  22:12  الأية
يَدْعُو مِن دُونِ اللهِ مَا لَا يَضُرُّهُ وَمَا لَا يَنفَعُهُ ۚ ذَٰلِكَ هُوَ الضَّلَالُ الْبَعِيدُ
YadAAoo min dooni Allahi ma layadurruhu wama la yanfaAAuhu thalikahuwa addalalu albaAAeed

Yoruba
 
Ó ń pè lẹ́yìn Allāhu ohun tí kò lè kó ìnira bá a, tí kò sì lè ṣe é ní oore; ìyẹn ni ìṣìnà tó jìnnà (sí ìmọ̀nà).

Ayah  22:13  الأية
يَدْعُو لَمَن ضَرُّهُ أَقْرَبُ مِن نَّفْعِهِ ۚ لَبِئْسَ الْمَوْلَىٰ وَلَبِئْسَ الْعَشِيرُ
YadAAoo laman darruhu aqrabu minnafAAihi labi/sa almawla walabi/sa alAAasheer

Yoruba
 
Ó ń pe ohun tí ìnira rẹ̀ súnmọ́ ju àǹfààní rẹ̀ lọ. Dájúdájú (òrìṣà) burú ní aláfẹ̀yìntì, ó sì burú ní alásùn-únmọ́.

Ayah  22:14  الأية
إِنَّ اللهَ يُدْخِلُ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِن تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ ۚ إِنَّ اللهَ يَفْعَلُ مَا يُرِيدُ
Inna Allaha yudkhilu allatheenaamanoo waAAamiloo assalihati jannatintajree min tahtiha al-anharu inna AllahayafAAalu ma yureed

Yoruba
 
Dájúdájú Allāhu yóò mú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ń ṣe ohun tí Ó bá fẹ́.

Ayah  22:15  الأية
مَن كَانَ يَظُنُّ أَن لَّن يَنصُرَهُ اللهُ فِي الدُّنْيَا وَالْآخِرَةِ فَلْيَمْدُدْ بِسَبَبٍ إِلَى السَّمَاءِ ثُمَّ لْيَقْطَعْ فَلْيَنظُرْ هَلْ يُذْهِبَنَّ كَيْدُهُ مَا يَغِيظُ
Man kana yathunnu anlan yansurahu Allahu fee addunya wal-akhiratifalyamdud bisababin ila assama-i thummaliyaqtaAA falyanthur hal yuthhibannakayduhu ma yagheeth

Yoruba
 
Ẹnikẹ́ni tí ó bá lérò pé Allāhu kò níí ran (Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) lọ́wọ́ láyé àti lọ́run, kí ó na okùn sí sánmọ̀ (àjà ilé rẹ̀) lẹ́yìn náà kí ó gé e (ìyẹn ni pé, kí ó pokùn so). Kí ó wò ó nígbà náà bóyá ète rẹ̀ lè mú (àrànṣe) tó ń bínú sí kúrò (lọ́dọ̀ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -).

Ayah  22:16  الأية
وَكَذَٰلِكَ أَنزَلْنَاهُ آيَاتٍ بَيِّنَاتٍ وَأَنَّ اللهَ يَهْدِي مَن يُرِيدُ
Wakathalika anzalnahu ayatinbayyinatin waanna Allaha yahdee man yureed

Yoruba
 
Báyẹn ni A ṣe sọ̀ ọ́ kalẹ̀ ní àwọn āyah tó yanjú. Dájúdájú Allāhu ń tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sí ọ̀nà.

Ayah  22:17  الأية
إِنَّ الَّذِينَ آمَنُوا وَالَّذِينَ هَادُوا وَالصَّابِئِينَ وَالنَّصَارَىٰ وَالْمَجُوسَ وَالَّذِينَ أَشْرَكُوا إِنَّ اللهَ يَفْصِلُ بَيْنَهُمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ ۚ إِنَّ اللهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ شَهِيدٌ
Inna allatheena amanoo wallatheenahadoo wassabi-eena wannasarawalmajoosa wallatheena ashrakoo inna Allahayafsilu baynahum yawma alqiyamati inna AllahaAAala kulli shay-in shaheed

Yoruba
 
Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo àti àwọn tó di yẹhudi àti àwọn sọ̄bi'ūn àti àwọn nasọ̄rọ̄ àti àwọn mọjūs àti àwọn tó ṣẹbọ, dájúdájú Allāhu yóò ṣèdájọ́ láààrin wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde. Dájúdájú Allāhu ni Arínú-róde gbogbo n̄ǹkan.

Ayah  22:18  الأية
أَلَمْ تَرَ أَنَّ اللهَ يَسْجُدُ لَهُ مَن فِي السَّمَاوَاتِ وَمَن فِي الْأَرْضِ وَالشَّمْسُ وَالْقَمَرُ وَالنُّجُومُ وَالْجِبَالُ وَالشَّجَرُ وَالدَّوَابُّ وَكَثِيرٌ مِّنَ النَّاسِ ۖ وَكَثِيرٌ حَقَّ عَلَيْهِ الْعَذَابُ ۗ وَمَن يُهِنِ اللهُ فَمَا لَهُ مِن مُّكْرِمٍ ۚ إِنَّ اللهَ يَفْعَلُ مَا يَشَاءُ ۩
Alam tara anna Allaha yasjudu lahuman fee assamawati waman fee al-ardiwashshamsu walqamaru wannujoomu waljibaluwashshajaru waddawabbu wakatheerun minaannasi wakatheerun haqqa AAalayhi alAAathabuwaman yuhini Allahu fama lahu min mukrimin inna AllahayafAAalu ma yasha/

Yoruba
 
Ṣé o ò wòye pé dájúdájú Allāhu ni àwọn tó ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti àwọn tó ń bẹ lórí ilẹ̀, àti òòrùn, òṣùpá, àwọn ìràwọ̀, àwọn àpáta, àwọn igi, àwọn n̄ǹkan ẹlẹ́mìí àti ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn ènìyàn ń forí kanlẹ̀ fún? Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ sì ni ìyà ti kò lé lórí. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fi àbùkù kàn, kò sí ẹnì kan tí ó máa ṣe àpọ́nlé rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ń ṣe ohun tí Ó bá fẹ́.

Ayah  22:19  الأية
هَٰذَانِ خَصْمَانِ اخْتَصَمُوا فِي رَبِّهِمْ ۖ فَالَّذِينَ كَفَرُوا قُطِّعَتْ لَهُمْ ثِيَابٌ مِّن نَّارٍ يُصَبُّ مِن فَوْقِ رُءُوسِهِمُ الْحَمِيمُ
Hathani khasmani ikhtasamoofee rabbihim fallatheena kafaroo quttiAAatlahum thiyabun min narin yusabbu min fawqiruoosihimu alhameem

Yoruba
 
Àwọn oníjà méjì (kan) nìyí, wọ́n ń takò ara wọn nípa Olúwa wọn. Nítorí náà, àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, wọ́n máa gé aṣọ Iná fún wọn, wọ́n yó sì máa da omi tó gbóná gan-an lé wọn lórí láti òkè orí wọn.

Ayah  22:20  الأية
يُصْهَرُ بِهِ مَا فِي بُطُونِهِمْ وَالْجُلُودُ
Yusharu bihi ma fee butoonihimwaljulood

Yoruba
 
Wọ́n máa fi yọ́ ohun tí ń bẹ nínú ikùn wọn àti awọ ara wọn.

Ayah  22:21  الأية
وَلَهُم مَّقَامِعُ مِنْ حَدِيدٍ
Walahum maqamiAAu min hadeed

Yoruba
 
Àwọn òdùrọ irin (ìyà) sì wà fún wọn pẹ̀lú.

Ayah  22:22  الأية
كُلَّمَا أَرَادُوا أَن يَخْرُجُوا مِنْهَا مِنْ غَمٍّ أُعِيدُوا فِيهَا وَذُوقُوا عَذَابَ الْحَرِيقِ
Kullama aradoo an yakhrujoominha min ghammin oAAeedoo feeha wathooqooAAathaba alhareeq

Yoruba
 
Ìgbàkígbà tí wọ́n bá fẹ́ jáde kúrò nínú rẹ̀ látara ìbànújẹ́, wọ́n á dá wọn padà sínú rẹ̀. (A óò sọ pé): "Ẹ tọ́ ìyà Iná jónijóni wò."

Ayah  22:23  الأية
إِنَّ اللهَ يُدْخِلُ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِن تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ يُحَلَّوْنَ فِيهَا مِنْ أَسَاوِرَ مِن ذَهَبٍ وَلُؤْلُؤًا ۖ وَلِبَاسُهُمْ فِيهَا حَرِيرٌ
Inna Allaha yudkhilu allatheenaamanoo waAAamiloo assalihati jannatintajree min tahtiha al-anharu yuhallawnafeeha min asawira min thahabin walu/lu-anwalibasuhum feeha hareer

Yoruba
 
Dájúdájú Allāhu yóò fi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. A óò ṣe wọ́n ní ọ̀ṣọ́ nínú rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀gbà wúrà àti àlúùlúù. Aṣọ àlàárì sì ni aṣọ wọn nínú rẹ̀.

Ayah  22:24  الأية
وَهُدُوا إِلَى الطَّيِّبِ مِنَ الْقَوْلِ وَهُدُوا إِلَىٰ صِرَاطِ الْحَمِيدِ
Wahudoo ila attayyibimina alqawli wahudoo ila sirati alhameed

Yoruba
 
A fún wọn ní ìmọ̀nà síbi ohun tó dára nínú ọ̀rọ̀. A sì tọ́ wọn sí ọ̀nà Ẹlẹ́yìn.

Ayah  22:25  الأية
إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا وَيَصُدُّونَ عَن سَبِيلِ اللهِ وَالْمَسْجِدِ الْحَرَامِ الَّذِي جَعَلْنَاهُ لِلنَّاسِ سَوَاءً الْعَاكِفُ فِيهِ وَالْبَادِ ۚ وَمَن يُرِدْ فِيهِ بِإِلْحَادٍ بِظُلْمٍ نُّذِقْهُ مِنْ عَذَابٍ أَلِيمٍ
Inna allatheena kafaroo wayasuddoonaAAan sabeeli Allahi walmasjidi alharamiallathee jaAAalnahu linnasi sawaanalAAakifu feehi walbadi waman yurid feehibi-ilhadin bithulmin nuthiqhu min AAathabinaleem

Yoruba
 
Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n ń ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu àti Mọ́sálásí Haram, èyí tí A ṣe ní dọ́gbadọ́gba fún àwọn ènìyàn, olùgbé-inú rẹ̀ àti àlejò (fún ìjọ́sìn ṣíṣe), ẹnikẹ́ni tí ó bá ní èrò láti ṣe ìyípadà kan níbẹ̀ pẹ̀lú àbòsí, A máa mú un tọ́ ìyà ẹlẹ́ta-eléro wò.

Ayah  22:26  الأية
وَإِذْ بَوَّأْنَا لِإِبْرَاهِيمَ مَكَانَ الْبَيْتِ أَن لَّا تُشْرِكْ بِي شَيْئًا وَطَهِّرْ بَيْتِيَ لِلطَّائِفِينَ وَالْقَائِمِينَ وَالرُّكَّعِ السُّجُودِ
Wa-ith bawwa/na li-ibraheemamakana albayti an la tushrik bee shay-an watahhirbaytiya litta-ifeena walqa-imeenawarrukkaAAi assujood

Yoruba
 
(Ẹ rántí) nígbà tí A ṣàfi hàn àyè ilé náà fún (Ànábì) 'Ibrọ̄hīm (A sì pa á láṣẹ) pé o ò gbọdọ̀ sọ kiní kan di akẹgbẹ́ fún Mi. Àti pé kí o ṣe ilé Mi ní mímọ́ fún àwọn olùyípo rẹ̀, olùkírun, olùdáwọ́tẹ-orúnkún àti olùforíkanlẹ̀.

Ayah  22:27  الأية
وَأَذِّن فِي النَّاسِ بِالْحَجِّ يَأْتُوكَ رِجَالًا وَعَلَىٰ كُلِّ ضَامِرٍ يَأْتِينَ مِن كُلِّ فَجٍّ عَمِيقٍ
Waaththin fee annasibilhajji ya/tooka rijalan waAAalakulli damirin ya/teena min kulli fajjin AAameeq

Yoruba
 
Kí o sì pe ìpè fún àwọn ènìyàn fún iṣẹ́ Hajj. Wọn yóò wá bá ọ pẹ̀lú ìrìn ẹsẹ̀ àti lórí gbogbo n̄ǹkan ìgùn, wọn yóò máa wá láti àwọn ọ̀nà jíjìn

Ayah  22:28  الأية
لِّيَشْهَدُوا مَنَافِعَ لَهُمْ وَيَذْكُرُوا اسْمَ اللهِ فِي أَيَّامٍ مَّعْلُومَاتٍ عَلَىٰ مَا رَزَقَهُم مِّن بَهِيمَةِ الْأَنْعَامِ ۖ فَكُلُوا مِنْهَا وَأَطْعِمُوا الْبَائِسَ الْفَقِيرَ
Liyashhadoo manafiAAa lahum wayathkurooisma Allahi fee ayyamin maAAloomatin AAalama razaqahum min baheemati al-anAAami fakuloo minhawaatAAimoo alba-isa alfaqeer

Yoruba
 
Nítorí kí wọ́n lè rí àwọn àǹfààní tó ń bẹ fún wọn àti nítorí kí wọ́n lè ṣèrántí orúkọ Allāhu fún àwọn ọjọ́ tí wọ́n ti mọ̀ lórí n̄ǹkan tí Allāhu pa lésè fún wọn nínú àwọn ẹran-ọ̀sìn. Nítorí náà, ẹ jẹ nínú rẹ̀, kí ẹ sì fi bọ́ aláìlera, tálíkà.

Ayah  22:29  الأية
ثُمَّ لْيَقْضُوا تَفَثَهُمْ وَلْيُوفُوا نُذُورَهُمْ وَلْيَطَّوَّفُوا بِالْبَيْتِ الْعَتِيقِ
Thumma lyaqdoo tafathahum walyoofoonuthoorahum walyattawwafoo bilbaytialAAateeq

Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, kí wọ́n yanjú ìdọ̀tí ara wọn fún ìparí iṣẹ́ Hajj wọn, kí wọ́n mú àwọn ẹ̀jẹ́ wọn ṣẹ, kí wọ́n sì yípo Ilé Láéláé náà.

Ayah  22:30  الأية
ذَٰلِكَ وَمَن يُعَظِّمْ حُرُمَاتِ اللهِ فَهُوَ خَيْرٌ لَّهُ عِندَ رَبِّهِ ۗ وَأُحِلَّتْ لَكُمُ الْأَنْعَامُ إِلَّا مَا يُتْلَىٰ عَلَيْكُمْ ۖ فَاجْتَنِبُوا الرِّجْسَ مِنَ الْأَوْثَانِ وَاجْتَنِبُوا قَوْلَ الزُّورِ
Thalika waman yuAAaththimhurumati Allahi fahuwa khayrun lahu AAindarabbihi waohillat lakumu al-anAAamu illa mayutla AAalaykum fajtaniboo arrijsa minaal-awthani wajtaniboo qawla azzoor

Yoruba
 
Ìyẹn (nìyẹn). Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì pàtàkì àwọn n̄ǹkan tí Allāhu bu ọ̀wọ̀ fún, òhun ló lóore jùlọ fún un lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀. Wọ́n sì ṣe àwọn ẹran-ọ̀sìn ní ẹ̀tọ́ fún yín àyàfi àwọn tí wọ́n ń kà (ní èèwọ̀) fún yín. Nítorí náà, ẹ jìnnà sí ẹ̀gbin òrìṣà. Kí ẹ sì jìnnà sí ọ̀rọ̀ irọ́.

Ayah  22:31  الأية
حُنَفَاءَ لِلَّهِ غَيْرَ مُشْرِكِينَ بِهِ ۚ وَمَن يُشْرِكْ بِاللهِ فَكَأَنَّمَا خَرَّ مِنَ السَّمَاءِ فَتَخْطَفُهُ الطَّيْرُ أَوْ تَهْوِي بِهِ الرِّيحُ فِي مَكَانٍ سَحِيقٍ
Hunafaa lillahi ghayramushrikeena bihi waman yushrik billahi fakaannamakharra mina assama-i fatakhtafuhu attayruaw tahwee bihi arreehu fee makanin saheeq

Yoruba
 
(Ẹ jẹ́) olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn fún Allāhu, ẹ má ṣe jẹ́ ẹni tí yóò máa ṣẹbọ sí I. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣẹbọ sí Allāhu, ó dà bí ẹni tó jábọ́ láti ojú sánmọ̀, tí ẹyẹ sì gbé e lọ tàbí (tí) atẹ́gùn jù ú sínú àyè tó jìnnà.

Ayah  22:32  الأية
ذَٰلِكَ وَمَن يُعَظِّمْ شَعَائِرَ اللهِ فَإِنَّهَا مِن تَقْوَى الْقُلُوبِ
Thalika waman yuAAaththimshaAAa-ira Allahi fa-innaha min taqwaalquloob

Yoruba
 
Ìyẹn (nìyẹn). Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì pàtàkì àwọn n̄ǹkan tí Allāhu fi ṣe àríṣàmì fún ẹ̀sìn 'Islām, dájúdájú ó wà lára níní ìbẹ̀rù Allāhu nínú ọkàn.

Ayah  22:33  الأية
لَكُمْ فِيهَا مَنَافِعُ إِلَىٰ أَجَلٍ مُّسَمًّى ثُمَّ مَحِلُّهَا إِلَى الْبَيْتِ الْعَتِيقِ
Lakum feeha manafiAAu ilaajalin musamman thumma mahilluha ila albaytialAAateeq

Yoruba
 
Àwọn àǹfààní wà fún yín lára àwọn ẹran-ọ̀sìn títí di gbèdéke àkókò kan. Lẹ́yìn náà, Ilé Láéláé náà ni ibùpa àwọn ẹran náà.

Ayah  22:34  الأية
وَلِكُلِّ أُمَّةٍ جَعَلْنَا مَنسَكًا لِّيَذْكُرُوا اسْمَ اللهِ عَلَىٰ مَا رَزَقَهُم مِّن بَهِيمَةِ الْأَنْعَامِ ۗ فَإِلَٰهُكُمْ إِلَٰهٌ وَاحِدٌ فَلَهُ أَسْلِمُوا ۗ وَبَشِّرِ الْمُخْبِتِينَ
Walikulli ommatin jaAAalna mansakanliyathkuroo isma Allahi AAala marazaqahum min baheemati al-anAAami fa-ilahukum ilahunwahidun falahu aslimoo wabashshiri almukhbiteen

Yoruba
 
Ìkọ̀ọ̀kan ìjọ (mùsùlùmí tó ṣíwájú) ni A yan ẹran pípa fún nítorí kí wọ́n lè dárúkọ Allāhu lórí ohun tí Ó pèsè fún wọn nínú àwọn ẹran-ọ̀sìn. Nítorí náà, Ọlọ́hun yín tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Òun ni kí ẹ jẹ́ mùsùlùmí fún. Kí o sì fún àwọn ọlọ́kàn ìrẹ̀lẹ̀, àwọn olùfọkànbalẹ̀ sọ́dọ̀ Allāhu ní ìró ìdùnnú.

Ayah  22:35  الأية
الَّذِينَ إِذَا ذُكِرَ اللهُ وَجِلَتْ قُلُوبُهُمْ وَالصَّابِرِينَ عَلَىٰ مَا أَصَابَهُمْ وَالْمُقِيمِي الصَّلَاةِ وَمِمَّا رَزَقْنَاهُمْ يُنفِقُونَ
Allatheena itha thukiraAllahu wajilat quloobuhum wassabireenaAAala ma asabahum walmuqeemee assalatiwamimma razaqnahum yunfiqoon

Yoruba
 
(Àwọn ni) àwọn tí ó jẹ́ pé tí A bá dárúkọ Allāhu (fún wọn), ọkàn wọn máa gbọ̀n rìrì. (Wọ́n jẹ́) onísùúrù lórí ohun tí ó bá ṣẹlẹ̀ sí wọn. (Wọ́n jẹ́) olùkírun. Wọ́n sì ń ná nínú ohun tí A pa lésè fùn wọn.

Ayah  22:36  الأية
وَالْبُدْنَ جَعَلْنَاهَا لَكُم مِّن شَعَائِرِ اللهِ لَكُمْ فِيهَا خَيْرٌ ۖ فَاذْكُرُوا اسْمَ اللهِ عَلَيْهَا صَوَافَّ ۖ فَإِذَا وَجَبَتْ جُنُوبُهَا فَكُلُوا مِنْهَا وَأَطْعِمُوا الْقَانِعَ وَالْمُعْتَرَّ ۚ كَذَٰلِكَ سَخَّرْنَاهَا لَكُمْ لَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ
Walbudna jaAAalnahalakum min shaAAa-iri Allahi lakum feehakhayrun fathkuroo isma Allahi AAalayhasawaffa fa-itha wajabat junoobuhafakuloo minha waatAAimoo alqaniAAa walmuAAtarrakathalika sakhkharnaha lakum laAAallakumtashkuroon

Yoruba
 
Àwọn ràkúnmí, A ṣe wọ́n nínú àwọn n̄ǹkan àríṣàmì fún ẹ̀sìn Allāhu fún yín. Oore wà lára wọn fún yín. Nítorí náà, ẹ dárúkọ Allāhu lé wọn lórí (kí ẹ sì gún wọn) ní ìdúró. Nígbà tí wọ́n bá fi ẹ̀gbẹ́ lélẹ̀, ẹ jẹ nínú rẹ̀. Ẹ fi bọ́ ẹni tó ní ìtẹ́lọ́rùn àti atọrọjẹ. Báyẹn ni A ṣe rọ̀ wọ́n fún yín nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Un).

Ayah  22:37  الأية
لَن يَنَالَ اللهَ لُحُومُهَا وَلَا دِمَاؤُهَا وَلَٰكِن يَنَالُهُ التَّقْوَىٰ مِنكُمْ ۚ كَذَٰلِكَ سَخَّرَهَا لَكُمْ لِتُكَبِّرُوا اللهَ عَلَىٰ مَا هَدَاكُمْ ۗ وَبَشِّرِ الْمُحْسِنِينَ
Lan yanala Allaha luhoomuhawala dimaoha walakin yanaluhuattaqwa minkum kathalika sakhkharahalakum litukabbiroo Allaha AAala ma hadakumwabashshiri almuhsineen

Yoruba
 
Ẹran (tí ẹ pa) àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ kò níí dé ọ̀dọ̀ Allāhu. Ṣùgbọ́n ìbẹ̀rù Allāhu láti ọ̀dọ̀ yín ló máa dé ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Báyẹn ni (Allāhu) ṣe rọ̀ wọ́n fún yín nítorí kí ẹ lè ṣe ìgbétóbi fún Allāhu nípa bí Ó ṣe fi ọ̀nà mọ̀ yín. Kí o sì fún àwọn olùṣe-rere ní ìró ìdùnnú.

Ayah  22:38  الأية
إِنَّ اللهَ يُدَافِعُ عَنِ الَّذِينَ آمَنُوا ۗ إِنَّ اللهَ لَا يُحِبُّ كُلَّ خَوَّانٍ كَفُورٍ
Inna Allaha yudafiAAu AAaniallatheena amanoo inna Allaha la yuhibbukulla khawwanin kafoor

Yoruba
 
Dájúdájú Allāhu ń ti aburú kúrò fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo. Dájúdájú Allāhu kò nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn oníjàǹbá, aláìgbàgbọ́.

Ayah  22:39  الأية
أُذِنَ لِلَّذِينَ يُقَاتَلُونَ بِأَنَّهُمْ ظُلِمُوا ۚ وَإِنَّ اللهَ عَلَىٰ نَصْرِهِمْ لَقَدِيرٌ
Othina lillatheena yuqataloonabi-annahum thulimoo wa-inna Allaha AAalanasrihim laqadeer

Yoruba
 
A yọ̀ǹda (ogun ẹ̀sìn jíjà) fún àwọn (mùsùlùmí) tí (àwọn kèfèrí) ń gbógun tì nítorí pé (àwọn kèfèrí) ti ṣe àbòsí sí wọn. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí àrànṣe wọn.

Ayah  22:40  الأية
الَّذِينَ أُخْرِجُوا مِن دِيَارِهِم بِغَيْرِ حَقٍّ إِلَّا أَن يَقُولُوا رَبُّنَا اللهُ ۗ وَلَوْلَا دَفْعُ اللهِ النَّاسَ بَعْضَهُم بِبَعْضٍ لَّهُدِّمَتْ صَوَامِعُ وَبِيَعٌ وَصَلَوَاتٌ وَمَسَاجِدُ يُذْكَرُ فِيهَا اسْمُ اللهِ كَثِيرًا ۗ وَلَيَنصُرَنَّ اللهُ مَن يَنصُرُهُ ۗ إِنَّ اللهَ لَقَوِيٌّ عَزِيزٌ
Allatheena okhrijoo min diyarihimbighayri haqqin illa an yaqooloo rabbuna Allahuwalawla dafAAu Allahi annasa baAAdahumbibaAAdin lahuddimat sawamiAAu wabiyaAAun wasalawatunwamasajidu yuthkaru feeha ismu Allahikatheeran walayansuranna Allahu man yansuruhuinna Allaha laqawiyyun AAazeez

Yoruba
 
(Àwọn ni) àwọn tí wọ́n lé jáde kúrò nínú ìlú wọn ní ọ̀nà àìtọ́ àfi (nítorí pé) wọ́n ń sọ pé: "Allāhu ni Olúwa wa." Tí kò bá jẹ́ pé Allāhu ń dènà (aburú) fún àwọn ènìyàn ni, tí Ó ń fi apá kan wọn dènà (aburú) fún apá kan, wọn ìbá ti wó ilé ìsìn àwọn fadá, ṣọ́ọ̀ṣì, sínágọ́gù àti àwọn mọ́sálásí tí wọ́n ti ń dárúkọ Allāhu ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀. Dájúdájú Allāhu yóò ṣe àrànṣe fún ẹnikẹ́ni tó ń ran (ẹ̀sìn 'Islām) Rẹ̀ lọ́wọ́. Dájúdájú Allāhu mà ni Alágbára, Olùborí.

Ayah  22:41  الأية
الَّذِينَ إِن مَّكَّنَّاهُمْ فِي الْأَرْضِ أَقَامُوا الصَّلَاةَ وَآتَوُا الزَّكَاةَ وَأَمَرُوا بِالْمَعْرُوفِ وَنَهَوْا عَنِ الْمُنكَرِ ۗ وَلِلَّهِ عَاقِبَةُ الْأُمُورِ
Allatheena in makkannahum feeal-ardi aqamoo assalata waatawooazzakata waamaroo bilmaAAroofi wanahawAAani almunkari walillahi AAaqibatu al-omoor

Yoruba
 
(Àwọn náà ni) àwọn tí ó jẹ́ pé tí A bá fún wọn ní ipò lórí ilẹ̀, wọn yóò kírun, wọn yóò yọ Zakāh, wọn yóò pàṣẹ ohun rere, wọn yó sì kọ ohun burúkú. Ti Allāhu sì ni ìkángun àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá.

Ayah  22:42  الأية
وَإِن يُكَذِّبُوكَ فَقَدْ كَذَّبَتْ قَبْلَهُمْ قَوْمُ نُوحٍ وَعَادٌ وَثَمُودُ
Wa-in yukaththibooka faqad kaththabatqablahum qawmu noohin waAAadun wathamood

Yoruba
 
Tí wọ́n bá pè ọ́ ní òpùrọ́, àwọn ìjọ Nūh, ìjọ ‘Ād àti ìjọ Thamūd kúkú ti pe àwọn Òjíṣẹ́ wọn ní òpùrọ́ ṣíwájú wọn.

Ayah  22:43  الأية
وَقَوْمُ إِبْرَاهِيمَ وَقَوْمُ لُوطٍ
Waqawmu ibraheema waqawmu loot

Yoruba
 
Àti pé ìjọ 'Ibrọhīm àti ìjọ (Ànábì) Lūt,

Ayah  22:44  الأية
وَأَصْحَابُ مَدْيَنَ ۖ وَكُذِّبَ مُوسَىٰ فَأَمْلَيْتُ لِلْكَافِرِينَ ثُمَّ أَخَذْتُهُمْ ۖ فَكَيْفَ كَانَ نَكِيرِ
Waas-habu madyana wakuththibamoosa faamlaytu lilkafireena thumma akhathtuhumfakayfa kana nakeer

Yoruba
 
Àti àwọn ará ìlú Mọdyan (àwọn náà ṣe bẹ́ẹ̀). Wọ́n tún pe (Ànábì) Mūsā ní òpùrọ́. Mo sì lọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ lára. Lẹ́yìn náà, Mo gbá wọn mú. Báwo sì ni bí Mo ṣe (fi ìyà) kọ (aburú fún wọn) ti rí!

Ayah  22:45  الأية
فَكَأَيِّن مِّن قَرْيَةٍ أَهْلَكْنَاهَا وَهِيَ ظَالِمَةٌ فَهِيَ خَاوِيَةٌ عَلَىٰ عُرُوشِهَا وَبِئْرٍ مُّعَطَّلَةٍ وَقَصْرٍ مَّشِيدٍ
Fakaayyin min qaryatin ahlaknahawahiya thalimatun fahiya khawiyatunAAala AAurooshiha wabi/rin muAAattalatinwaqasrin masheed

Yoruba
 
Nítorí náà, mélòó mélòó nínú ìlú tí A ti parẹ́ nígbà tí wọ́n jẹ́ alábòsí; àwọn ilé wọn dàwó lulẹ̀ pẹ̀lú òrùlé rẹ̀. (Mélòó mélòó nínú) kànǹga tí wọ́n ti patì (nípasẹ̀ ìparun) àti ilé pẹ̀tẹ́ẹ̀sì oníbíríkì (tó ti dahoro)!

Ayah  22:46  الأية
أَفَلَمْ يَسِيرُوا فِي الْأَرْضِ فَتَكُونَ لَهُمْ قُلُوبٌ يَعْقِلُونَ بِهَا أَوْ آذَانٌ يَسْمَعُونَ بِهَا ۖ فَإِنَّهَا لَا تَعْمَى الْأَبْصَارُ وَلَٰكِن تَعْمَى الْقُلُوبُ الَّتِي فِي الصُّدُورِ
Afalam yaseeroo fee al-ardi fatakoonalahum quloobun yaAAqiloona biha aw athanunyasmaAAoona biha fa-innaha la taAAmaal-absaru walakin taAAma alquloobu allateefee assudoor

Yoruba
 
Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n sì ní àwọn ọkàn tí wọ́n máa fi ṣe làákàyè tàbí àwọn etí tí wọn máa fi gbọ́rọ̀? Dájúdájú àwọn ojú kò fọ́, ṣùgbọ́n àwọn ọkàn tó wà nínú igbá-àyà ló ń fọ́.

Ayah  22:47  الأية
وَيَسْتَعْجِلُونَكَ بِالْعَذَابِ وَلَن يُخْلِفَ اللهُ وَعْدَهُ ۚ وَإِنَّ يَوْمًا عِندَ رَبِّكَ كَأَلْفِ سَنَةٍ مِّمَّا تَعُدُّونَ
WayastaAAjiloonaka bilAAathabiwalan yukhlifa Allahu waAAdahu wa-inna yawman AAindarabbika kaalfi sanatin mimma taAAuddoon

Yoruba
 
Wọ́n sì ń kán ọ lójú fún ìyà náà. Allāhu kò sì níí yapa àdéhùn Rẹ̀. Dájúdájú ọjọ́ kan lọ́dọ̀ Olúwa rẹ dà bí ẹgbẹ̀rún ọdún nínú ohun tí ẹ̀ ń kà (ní òǹkà).

Ayah  22:48  الأية
وَكَأَيِّن مِّن قَرْيَةٍ أَمْلَيْتُ لَهَا وَهِيَ ظَالِمَةٌ ثُمَّ أَخَذْتُهَا وَإِلَيَّ الْمَصِيرُ
Wakaayyin min qaryatin amlaytu lahawahiya thalimatun thumma akhathtuhawa-ilayya almaseer

Yoruba
 
Mélòó mélòó nínú ìlú tí Mo lọ́ lára, tí wọ́n jẹ́ alábòsí. Lẹ́yìn náà, Mo gbá wọn mú. Ọ̀dọ̀ Mi sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.

Ayah  22:49  الأية
قُلْ يَا أَيُّهَا النَّاسُ إِنَّمَا أَنَا لَكُمْ نَذِيرٌ مُّبِينٌ
Qul ya ayyuha annasuinnama ana lakum natheerun mubeen

Yoruba
 
Sọ pé: "Ẹ̀yin ènìyàn, èmi mà ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé fún yín."

Ayah  22:50  الأية
فَالَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ لَهُم مَّغْفِرَةٌ وَرِزْقٌ كَرِيمٌ
Fallatheena amanoowaAAamiloo assalihati lahum maghfiratunwarizqun kareem

Yoruba
 
Nítorí náà, àwọn tó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, àforíjìn àti arísìkí alápọ̀n-ọ́nlé ń bẹ fún wọn.

Ayah  22:51  الأية
وَالَّذِينَ سَعَوْا فِي آيَاتِنَا مُعَاجِزِينَ أُولَٰئِكَ أَصْحَابُ الْجَحِيمِ
Wallatheena saAAaw fee ayatinamuAAajizeena ola-ika as-habu aljaheem

Yoruba
 
Àwọn tó ṣe iṣẹ́ (burúkú) nípa àwọn āyah Wa, tí wọ́n ń dá àwọn ènìyàn ní agara (láti tẹ̀lé àwọn āyah Wa, tí wọ́n sì lérò pé àwọn máa mórí bọ́ lọ́dọ̀ Allāhu); àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú iná Jẹhīm.

Ayah  22:52  الأية
وَمَا أَرْسَلْنَا مِن قَبْلِكَ مِن رَّسُولٍ وَلَا نَبِيٍّ إِلَّا إِذَا تَمَنَّىٰ أَلْقَى الشَّيْطَانُ فِي أُمْنِيَّتِهِ فَيَنسَخُ اللهُ مَا يُلْقِي الشَّيْطَانُ ثُمَّ يُحْكِمُ اللهُ آيَاتِهِ ۗ وَاللهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ
Wama arsalna min qablika minrasoolin wala nabiyyin illa itha tamannaalqa ashshaytanu fee omniyyatihi fayansakhuAllahu ma yulqee ashshaytanu thummayuhkimu Allahu ayatihi wallahuAAaleemun hakeem

Yoruba
 
A kò rán Òjíṣẹ́ kan tàbí Ànábì kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ àfi kí ó jẹ́ pé nígbà tí ó bá sọ̀rọ̀, Èṣù máa ju (n̄ǹkan) sínú ọ̀rọ̀ rẹ̀. Nítorí náà, Allāhu yóò pa ohun tí Èṣù ń jù sínú rẹ̀ rẹ́. Lẹ́yìn náà, Ó máa fi òdodo àwọn āyah Rẹ̀ rinlẹ̀. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.

Ayah  22:53  الأية
لِّيَجْعَلَ مَا يُلْقِي الشَّيْطَانُ فِتْنَةً لِّلَّذِينَ فِي قُلُوبِهِم مَّرَضٌ وَالْقَاسِيَةِ قُلُوبُهُمْ ۗ وَإِنَّ الظَّالِمِينَ لَفِي شِقَاقٍ بَعِيدٍ
LiyajAAala ma yulqee ashshaytanufitnatan lillatheena fee quloobihim maradun walqasiyatiquloobuhum wa-inna aththalimeenalafee shiqaqin baAAeed

Yoruba
 
(Èyí ń ṣẹlẹ̀) nítorí kí (Allāhu) lè fi ohun tí Èṣù ń jù (sínú rẹ̀) ṣe àdánwò fún àwọn tí àìsàn ń bẹ nínú ọkàn wọn àti àwọn tí ọkàn wọn le. Dájúdájú àwọn alábòsí sì wà nínú ìyapa tó jìnnà (sí òdodo).

Ayah  22:54  الأية
وَلِيَعْلَمَ الَّذِينَ أُوتُوا الْعِلْمَ أَنَّهُ الْحَقُّ مِن رَّبِّكَ فَيُؤْمِنُوا بِهِ فَتُخْبِتَ لَهُ قُلُوبُهُمْ ۗ وَإِنَّ اللهَ لَهَادِ الَّذِينَ آمَنُوا إِلَىٰ صِرَاطٍ مُّسْتَقِيمٍ
WaliyaAAlama allatheena ootooalAAilma annahu alhaqqu min rabbika fayu/minoo bihifatukhbita lahu quloobuhum wa-inna Allaha lahadiallatheena amanoo ila siratinmustaqeem

Yoruba
 
(Èyí ń ṣẹlẹ̀) nítorí kí àwọn tí A fún ní ìmọ̀ lè mọ̀ pé dájúdájú al-Ƙur'ān jẹ́ òdodo láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, wọn yó sì gbàgbọ́ nínú rẹ̀, ọkàn wọn yó sì balẹ̀ sí i. Dájúdájú Allāhu l'Ó ń fi ẹsẹ̀ àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo rinlẹ̀ sójú ọ̀nà tààrà ('Islām).

Ayah  22:55  الأية
وَلَا يَزَالُ الَّذِينَ كَفَرُوا فِي مِرْيَةٍ مِّنْهُ حَتَّىٰ تَأْتِيَهُمُ السَّاعَةُ بَغْتَةً أَوْ يَأْتِيَهُمْ عَذَابُ يَوْمٍ عَقِيمٍ
Wala yazalu allatheenakafaroo fee miryatin minhu hatta ta/tiyahumu assaAAatubaghtatan aw ya/tiyahum AAathabu yawmin AAaqeem

Yoruba
 
Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ kò sì níí yé wà nínú iyèméjì nípa rẹ̀ títí Àkókò náà yóò fi dé bá wọn ní òjijì tàbí (títí) ìyà ọjọ́ ìparun yóò fi dé bá wọn.

Ayah  22:56  الأية
الْمُلْكُ يَوْمَئِذٍ لِّلَّهِ يَحْكُمُ بَيْنَهُمْ ۚ فَالَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ فِي جَنَّاتِ النَّعِيمِ
Almulku yawma-ithin lillahi yahkumubaynahum fallatheena amanoo waAAamiloo assalihatifee jannati annaAAeem

Yoruba
 
Gbogbo ìjọba ọjọ́ yẹn ń jẹ́ ti Allāhu tí Ó máa ṣèdájọ́ láààrin wọn. Nítorí náà, àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, (wọn yóò wà) nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra.

Ayah  22:57  الأية
وَالَّذِينَ كَفَرُوا وَكَذَّبُوا بِآيَاتِنَا فَأُولَٰئِكَ لَهُمْ عَذَابٌ مُّهِينٌ
Wallatheena kafaroo wakaththaboobi-ayatina faola-ika lahum AAathabunmuheen

Yoruba
 
Àwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n tún pe àwọn āyah Wa ní irọ́; àwọn wọ̀nyẹn ni ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sì wà fún.

Ayah  22:58  الأية
وَالَّذِينَ هَاجَرُوا فِي سَبِيلِ اللهِ ثُمَّ قُتِلُوا أَوْ مَاتُوا لَيَرْزُقَنَّهُمُ اللهُ رِزْقًا حَسَنًا ۚ وَإِنَّ اللهَ لَهُوَ خَيْرُ الرَّازِقِينَ
Wallatheena hajaroofee sabeeli Allahi thumma qutiloo aw matoolayarzuqannahumu Allahu rizqan hasanan wa-inna Allahalahuwa khayru arraziqeen

Yoruba
 
Àwọn tí wọ́n gbé ìlú wọn jù sílẹ̀ nítorí ẹ̀sìn Allāhu, lẹ́yìn náà, tí wọ́n pa wọ́n tàbí tí wọ́n kú; dájúdájú Allāhu yóò pèsè fún wọn ní ìpèsè tó dára. Dájúdájú Allāhu, Ó mà l'óore jùlọ nínú àwọn olùpèsè.

Ayah  22:59  الأية
لَيُدْخِلَنَّهُم مُّدْخَلًا يَرْضَوْنَهُ ۗ وَإِنَّ اللهَ لَعَلِيمٌ حَلِيمٌ
Layudkhilannahum mudkhalan yardawnahuwa-inna Allaha laAAaleemun haleem

Yoruba
 
Dájúdájú (Allāhu) yóò fi wọ́n sínú àyè kan tí wọn yóò yọ́nú sí. Dájúdájú Allāhu mà ni Onímọ̀, Aláfaradà.

Ayah  22:60  الأية
ذَٰلِكَ وَمَنْ عَاقَبَ بِمِثْلِ مَا عُوقِبَ بِهِ ثُمَّ بُغِيَ عَلَيْهِ لَيَنصُرَنَّهُ اللهُ ۗ إِنَّ اللهَ لَعَفُوٌّ غَفُورٌ
Thalika waman AAaqaba bimithlima AAooqiba bihi thumma bughiya AAalayhi layansurannahuAllahu inna Allaha laAAafuwwun ghafoor

Yoruba
 
Ìyẹn (nìyẹn). Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbẹ̀san irú ìyà tí wọ́n fi jẹ ẹ́, lẹ́yìn náà tí wọ́n bá tún ṣàbòsí sí i, dájúdájú Allāhu yóò ṣàrànṣe fún un. Dájúdájú Allāhu mà ni Alámòjúúkúrò, Aláforíjìn.

Ayah  22:61  الأية
ذَٰلِكَ بِأَنَّ اللهَ يُولِجُ اللَّيْلَ فِي النَّهَارِ وَيُولِجُ النَّهَارَ فِي اللَّيْلِ وَأَنَّ اللهَ سَمِيعٌ بَصِيرٌ
Thalika bi-anna Allaha yoolijuallayla fee annahari wayooliju annaharafee allayli waanna Allaha sameeAAun baseer

Yoruba
 
Ìyẹn nítorí pé dájúdájú Allāhu ń fi òru bọ inú ọ̀sán, Ó sì ń fi ọ̀sán bọ inú òru. Allāhu sì ni Olùgbọ́, Olùríran.

Ayah  22:62  الأية
ذَٰلِكَ بِأَنَّ اللهَ هُوَ الْحَقُّ وَأَنَّ مَا يَدْعُونَ مِن دُونِهِ هُوَ الْبَاطِلُ وَأَنَّ اللهَ هُوَ الْعَلِيُّ الْكَبِيرُ
Thalika bi-anna Allaha huwa alhaqquwaanna ma yadAAoona min doonihi huwa albatiluwaanna Allaha huwa alAAaliyyu alkabeer

Yoruba
 
Ìyẹn nítorí pé dájúdájú Allāhu, Òun ni Òdodo. Àti pé dájúdájú ohun tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀ ni irọ́. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Ó ga, Ó tóbi.

Ayah  22:63  الأية
أَلَمْ تَرَ أَنَّ اللهَ أَنزَلَ مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَتُصْبِحُ الْأَرْضُ مُخْضَرَّةً ۗ إِنَّ اللهَ لَطِيفٌ خَبِيرٌ
Alam tara anna Allaha anzala mina assama-imaan fatusbihu al-ardu mukhdarrataninna Allaha lateefun khabeer

Yoruba
 
Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀, ilẹ̀ sì máa lọ́ràá wá? Dájúdájú Allāhu ni Aláàánú, Alámọ̀tán.

Ayah  22:64  الأية
لَّهُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۗ وَإِنَّ اللهَ لَهُوَ الْغَنِيُّ الْحَمِيدُ
Lahu ma fee assamawatiwama fee al-ardi wa-inna Allaha lahuwaalghaniyyu alhameed

Yoruba
 
TiRẹ̀ ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Dájúdájú Allāhu, Òun mà ni Ọlọ́rọ̀, Ẹlẹ́yìn.

Ayah  22:65  الأية
أَلَمْ تَرَ أَنَّ اللهَ سَخَّرَ لَكُم مَّا فِي الْأَرْضِ وَالْفُلْكَ تَجْرِي فِي الْبَحْرِ بِأَمْرِهِ وَيُمْسِكُ السَّمَاءَ أَن تَقَعَ عَلَى الْأَرْضِ إِلَّا بِإِذْنِهِ ۗ إِنَّ اللهَ بِالنَّاسِ لَرَءُوفٌ رَّحِيمٌ
Alam tara anna Allaha sakhkhara lakumma fee al-ardi walfulka tajree fee albahribi-amrihi wayumsiku assamaa an taqaAAa AAalaal-ardi illa bi-ithnihi inna Allahabinnasi laraoofun raheem

Yoruba
 
Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu rọ ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ fún yín, àti ọkọ̀ ojú-omi tó ń rìn nínú agbami odò pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀, Ó ń mú sánmọ̀ dání tí kò fi jábọ́ àyàfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀? Dájúdájú Allāhu mà ni Aláàánú, Oníkẹ̀ẹ́ fún àwọn ènìyàn.

Ayah  22:66  الأية
وَهُوَ الَّذِي أَحْيَاكُمْ ثُمَّ يُمِيتُكُمْ ثُمَّ يُحْيِيكُمْ ۗ إِنَّ الْإِنسَانَ لَكَفُورٌ
Wahuwa allathee ahyakumthumma yumeetukum thumma yuhyeekum inna al-insanalakafoor

Yoruba
 
Òun sì ni Ẹni tó ṣe yín ni alààyè, lẹ́yìn náà Ó ń sọ yín di òkú, lẹ́yìn náà Ó máa sọ yín di alààyè. Dájúdájú ènìyàn mà ni aláìmoore.

Ayah  22:67  الأية
لِّكُلِّ أُمَّةٍ جَعَلْنَا مَنسَكًا هُمْ نَاسِكُوهُ ۖ فَلَا يُنَازِعُنَّكَ فِي الْأَمْرِ ۚ وَادْعُ إِلَىٰ رَبِّكَ ۖ إِنَّكَ لَعَلَىٰ هُدًى مُّسْتَقِيمٍ
Likulli ommatin jaAAalna mansakan humnasikoohu fala yunaziAAunnaka fee al-amri wadAAuila rabbika innaka laAAala hudan mustaqeem

Yoruba
 
Ìjọ kọ̀ọ̀kan l'A fún ní ìlànà tí wọ́n máa lò. Nítorí náà, kí wọ́n má ṣe jà ọ́ níyàn nípa ọ̀rọ̀ náà. Kí o sì pèpè sọ́dọ̀ Olúwa rẹ. Dájúdájú o kúkú wà lójú ọ̀nà tààrà.

Ayah  22:68  الأية
وَإِن جَادَلُوكَ فَقُلِ اللهُ أَعْلَمُ بِمَا تَعْمَلُونَ
Wa-in jadalooka faquli AllahuaAAlamu bima taAAmaloon

Yoruba
 
Tí wọ́n bá sì jà ọ́ níyàn, sọ nígbà náà pé: "Allāhu nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

Ayah  22:69  الأية
اللهُ يَحْكُمُ بَيْنَكُمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ فِيمَا كُنتُمْ فِيهِ تَخْتَلِفُونَ
Allahu yahkumu baynakum yawmaalqiyamati feema kuntum feehi takhtalifoon

Yoruba
 
Allāhu máa ṣèdájọ́ láààrin yín ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí ẹ̀ ń yapa ẹnu sí."

Ayah  22:70  الأية
أَلَمْ تَعْلَمْ أَنَّ اللهَ يَعْلَمُ مَا فِي السَّمَاءِ وَالْأَرْضِ ۗ إِنَّ ذَٰلِكَ فِي كِتَابٍ ۚ إِنَّ ذَٰلِكَ عَلَى اللهِ يَسِيرٌ
Alam taAAlam anna Allaha yaAAlamu mafee assama-i wal-ardi inna thalikafee kitabin inna thalika AAala Allahiyaseer

Yoruba
 
Ṣé o ò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu l'Ó mọ ohun tí ń bẹ nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀? Dájúdájú (àkọsílẹ̀) ìyẹn wà nínú tírà kan. Dájúdájú ìyẹn rọrùn fún Allāhu.

Ayah  22:71  الأية
وَيَعْبُدُونَ مِن دُونِ اللهِ مَا لَمْ يُنَزِّلْ بِهِ سُلْطَانًا وَمَا لَيْسَ لَهُم بِهِ عِلْمٌ ۗ وَمَا لِلظَّالِمِينَ مِن نَّصِيرٍ
WayaAAbudoona min dooni Allahi malam yunazzil bihi sultanan wama laysa lahum bihiAAilmun wama liththalimeenamin naseer

Yoruba
 
Lẹ́yìn Allāhu, wọ́n sì ń jọ́sìn fún ohun tí (Allāhu) kò sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fún àti ohun tí kò sí ìmọ̀ kan fún wọn lórí rẹ̀. Kò sì níí sí alárànṣe kan fún àwọn alábòsí.

Ayah  22:72  الأية
وَإِذَا تُتْلَىٰ عَلَيْهِمْ آيَاتُنَا بَيِّنَاتٍ تَعْرِفُ فِي وُجُوهِ الَّذِينَ كَفَرُوا الْمُنكَرَ ۖ يَكَادُونَ يَسْطُونَ بِالَّذِينَ يَتْلُونَ عَلَيْهِمْ آيَاتِنَا ۗ قُلْ أَفَأُنَبِّئُكُم بِشَرٍّ مِّن ذَٰلِكُمُ ۗ النَّارُ وَعَدَهَا اللهُ الَّذِينَ كَفَرُوا ۖ وَبِئْسَ الْمَصِيرُ
Wa-itha tutla AAalayhim ayatunabayyinatin taAArifu fee wujoohi allatheena kafarooalmunkara yakadoona yastoona billatheenayatloona AAalayhim ayatina qulafaonabbi-okum bisharrin min thalikum annaruwaAAadaha Allahu allatheena kafaroo wabi/saalmaseer

Yoruba
 
Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa tó yanjú fún wọn, o máa rí ohun tí ẹ̀mí kọ̀ (ìkorò-ojú) nínú ojú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́; wọn sì fẹ́ẹ̀ fọwọ́ ìnira kan àwọn tí ń ké àwọn āyah Wa fún wọn. Sọ pé: "Ṣé kí n̄g fún yín ní ìró ohun tó burú ju ìyẹn? Iná tí Allāhu ṣèlérí rẹ̀ fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ni. Ìkángun náà sì burú."

Ayah  22:73  الأية
يَا أَيُّهَا النَّاسُ ضُرِبَ مَثَلٌ فَاسْتَمِعُوا لَهُ ۚ إِنَّ الَّذِينَ تَدْعُونَ مِن دُونِ اللهِ لَن يَخْلُقُوا ذُبَابًا وَلَوِ اجْتَمَعُوا لَهُ ۖ وَإِن يَسْلُبْهُمُ الذُّبَابُ شَيْئًا لَّا يَسْتَنقِذُوهُ مِنْهُ ۚ ضَعُفَ الطَّالِبُ وَالْمَطْلُوبُ
Ya ayyuha annasuduriba mathalun fastamiAAoo lahu inna allatheenatadAAoona min dooni Allahi lan yakhluqoo thubabanwalawi ijtamaAAoo lahu wa-in yaslubuhumu aththubabushay-an la yastanqithoohu minhu daAAufa attalibuwalmatloob

Yoruba
 
Ẹ̀yin ènìyàn, Wọ́n fi àkàwé kan lélẹ̀. Nítorí náà, ẹ tẹ́tí sí i. Dájúdájú àwọn tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu, wọn kò lè dá eṣinṣin kan, wọn ìbàá para pọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Tí eṣinṣin náà bá sì gba kiní kan mọ́ wọn lọ́wọ́, wọn kò lè gbà á padà lọ́wọ́ rẹ̀. Ọ̀lẹ ni ẹni tí ń wá n̄ǹkan (lọ́dọ̀ òrìṣà) àti (òrìṣà) tí wọ́n ń wá n̄ǹkan lọ́dọ̀ rẹ̀.

Ayah  22:74  الأية
مَا قَدَرُوا اللهَ حَقَّ قَدْرِهِ ۗ إِنَّ اللهَ لَقَوِيٌّ عَزِيزٌ
Ma qadaroo Allaha haqqaqadrihi inna Allaha laqawiyyun AAazeez

Yoruba
 
Wọn kò bu ọ̀wọ̀ fún Allāhu ní ọ̀wọ̀ tí ó tọ́ sí I. Dájúdájú Allāhu mà ni Alágbára, Olùborí.

Ayah  22:75  الأية
اللهُ يَصْطَفِي مِنَ الْمَلَائِكَةِ رُسُلًا وَمِنَ النَّاسِ ۚ إِنَّ اللهَ سَمِيعٌ بَصِيرٌ
Allahu yastafee mina almala-ikatirusulan wamina annasi inna Allaha sameeAAunbaseer

Yoruba
 
Allāhu l'Ó ń ṣa àwọn kan lẹ́ṣà (láti jẹ́) Òjíṣẹ́ nínú àwọn mọlāika àti nínú àwọn ènìyàn. Dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Olùríran.

Ayah  22:76  الأية
يَعْلَمُ مَا بَيْنَ أَيْدِيهِمْ وَمَا خَلْفَهُمْ ۗ وَإِلَى اللهِ تُرْجَعُ الْأُمُورُ
YaAAlamu ma bayna aydeehim wamakhalfahum wa-ila Allahi turjaAAu al-omoor

Yoruba
 
Ó mọ ohun tí ń bẹ níwájú wọn àti ní ẹ̀yìn wọn. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí.

Ayah  22:77  الأية
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا ارْكَعُوا وَاسْجُدُوا وَاعْبُدُوا رَبَّكُمْ وَافْعَلُوا الْخَيْرَ لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ ۩
Ya ayyuha allatheena amanooirkaAAoo wasjudoo waAAbudoo rabbakum wafAAalooalkhayra laAAallakum tuflihoon

Yoruba
 
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ dáwọ́tẹ orúnkún (lórí ìrun), ẹ forí kanlẹ̀, ẹ jọ́sìn fún Olúwa yín, kí ẹ sì ṣe rere nítorí kí ẹ lè jèrè.

Ayah  22:78  الأية
وَجَاهِدُوا فِي اللهِ حَقَّ جِهَادِهِ ۚ هُوَ اجْتَبَاكُمْ وَمَا جَعَلَ عَلَيْكُمْ فِي الدِّينِ مِنْ حَرَجٍ ۚ مِّلَّةَ أَبِيكُمْ إِبْرَاهِيمَ ۚ هُوَ سَمَّاكُمُ الْمُسْلِمِينَ مِن قَبْلُ وَفِي هَٰذَا لِيَكُونَ الرَّسُولُ شَهِيدًا عَلَيْكُمْ وَتَكُونُوا شُهَدَاءَ عَلَى النَّاسِ ۚ فَأَقِيمُوا الصَّلَاةَ وَآتُوا الزَّكَاةَ وَاعْتَصِمُوا بِاللهِ هُوَ مَوْلَاكُمْ ۖ فَنِعْمَ الْمَوْلَىٰ وَنِعْمَ النَّصِيرُ
Wajahidoo fee Allahi haqqajihadihi huwa ijtabakum wama jaAAalaAAalaykum fee addeeni min harajin millata abeekumibraheema huwa sammakumu almuslimeena min qabluwafee hatha liyakoona arrasoolu shaheedanAAalaykum watakoonoo shuhadaa AAala annasifaaqeemoo assalata waatoo azzakatawaAAtasimoo billahi huwa mawlakumfaniAAma almawla waniAAma annaseer

Yoruba
 
Ẹ jagun fún ẹ̀sìn Allāhu ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ tí ẹ lè gbà jagun fún Un. Òun l'Ó ṣà yín lẹ́ṣà, kò sì kó ìdààmú kan kan ba yín nínú ẹ̀sìn. (Ẹ tẹ̀lé) ẹ̀sìn bàbá yín (Ànábì) 'Ibrọ̄hīm. (Allāhu) l'Ó sọ yín ní mùsùlùmí ṣíwájú (àsìkò yìí) àti nínú (al-Ƙur'ān) yìí nítorí kí Òjíṣẹ́ lè jẹ́ ẹlẹ́rìí fún yín àti nítorí kí ẹ̀yin náà lè jẹ́ ẹlẹ́rìí fún àwọn ènìyàn. Nítorí náà, ẹ kírun, ẹ yọ Zakāh, kí ẹ sì bá Allāhu dúró. Òun ni Aláàbò yín. Ó dára ni Aláàbò. Ó sì dára ní Alárànṣe.




© EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us