1st Ayah 1 الأية ١الأوليبِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
الم
Alif-lam-meem
Yoruba
'Alif lām mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)
|
Ayah 31:2 الأية
تِلْكَ آيَاتُ الْكِتَابِ الْحَكِيمِ
Tilka ayatu alkitabi alhakeem
Yoruba
Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà tí ó kún fún ọgbọ́n.
|
Ayah 31:3 الأية
هُدًى وَرَحْمَةً لِّلْمُحْسِنِينَ
Hudan warahmatan lilmuhsineen
Yoruba
(Ó jẹ́) ìmọ̀nà àti ìkẹ́ fún àwọn olùṣe-rere;
|
Ayah 31:4 الأية
الَّذِينَ يُقِيمُونَ الصَّلَاةَ وَيُؤْتُونَ الزَّكَاةَ وَهُم بِالْآخِرَةِ هُمْ
يُوقِنُونَ
Allatheena yuqeemoona assalatawayu/toona azzakata wahum bil-akhiratihum
yooqinoon
Yoruba
Àwọn tó ń kírun, tí wọ́n ń yọ zakāh. Àwọn sì ni wọ́n ní àmọ̀dájú nípa Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.
|
Ayah 31:5 الأية
أُولَٰئِكَ عَلَىٰ هُدًى مِّن رَّبِّهِمْ ۖ وَأُولَٰئِكَ هُمُ الْمُفْلِحُونَ
Ola-ika AAala hudan minrabbihim waola-ika humu almuflihoon
Yoruba
Àwọn wọ̀nyẹn wà lórí ìmọ̀nà láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni olùjèrè.
|
Ayah 31:6 الأية
وَمِنَ النَّاسِ مَن يَشْتَرِي لَهْوَ الْحَدِيثِ لِيُضِلَّ عَن سَبِيلِ اللهِ
بِغَيْرِ عِلْمٍ وَيَتَّخِذَهَا هُزُوًا ۚ أُولَٰئِكَ لَهُمْ عَذَابٌ مُّهِينٌ
Wamina annasi man yashtareelahwa alhadeethi liyudilla AAan sabeeli
Allahibighayri AAilmin wayattakhithaha huzuwan ola-ikalahum AAathabun muheen
Yoruba
Ó wà nínú àwọn ènìyàn, ẹni tó ń ra ọ̀rọ̀ eré láti fi ṣi àwọn ènìyàn lọ́nà kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu pẹ̀lú àìnímọ̀ àti nítorí kí ó lè sọ ẹ̀sìn di yẹ̀yẹ́. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá wà fún.
|
Ayah 31:7 الأية
وَإِذَا تُتْلَىٰ عَلَيْهِ آيَاتُنَا وَلَّىٰ مُسْتَكْبِرًا كَأَن لَّمْ
يَسْمَعْهَا كَأَنَّ فِي أُذُنَيْهِ وَقْرًا ۖ فَبَشِّرْهُ بِعَذَابٍ أَلِيمٍ
Wa-itha tutla AAalayhi ayatunawalla mustakbiran kaan lam yasmaAAha kaanna fee
othunayhiwaqran fabashshirhu biAAathabin aleem
Yoruba
Àti pé nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa fún un, ó máa pẹ̀yìndà ní ti ìgbéraga, àfi bí ẹni pé kò gbọ́ ọ, àfi bí ẹni pé èdídí wà nínú etí rẹ̀ méjèèjì. Nítorí náà, fún un ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
|
Ayah 31:8 الأية
إِنَّ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ لَهُمْ جَنَّاتُ النَّعِيمِ
Inna allatheena amanoowaAAamiloo assalihati lahum jannatuannaAAeem
Yoruba
Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra ń bẹ fún wọn.
|
Ayah 31:9 الأية
خَالِدِينَ فِيهَا ۖ وَعْدَ اللهِ حَقًّا ۚ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ
Khalideena feeha waAAda Allahihaqqan wahuwa alAAazeezu alhakeem
Yoruba
Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. (Ó jẹ́) àdéhùn Allāhu ní ti òdodo. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
|
Ayah 31:10 الأية
خَلَقَ السَّمَاوَاتِ بِغَيْرِ عَمَدٍ تَرَوْنَهَا ۖ وَأَلْقَىٰ فِي الْأَرْضِ
رَوَاسِيَ أَن تَمِيدَ بِكُمْ وَبَثَّ فِيهَا مِن كُلِّ دَابَّةٍ ۚ وَأَنزَلْنَا
مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَأَنبَتْنَا فِيهَا مِن كُلِّ زَوْجٍ كَرِيمٍ
Khalaqa assamawatibighayri AAamadin tarawnaha waalqa fee al-ardirawasiya an
tameeda bikum wabaththa feeha min kullidabbatin waanzalna mina assama-i
maanfaanbatna feeha min kulli zawjin kareem
Yoruba
Ó dá àwọn sánmọ̀ láì ní òpó tí ẹ lè rí. Ó sì ju àwọn àpáta tó dúró gbagidi sínú ilẹ̀ kí ó má fi lè mì mọ yín lẹ́sẹ̀. Ó fọ́n gbogbo n̄ǹkan abẹ̀mí ká sórí ilẹ̀. A tún sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀, A sì fi mú gbogbo oríṣiríṣi èso dáadáa hù jáde láti inú ilẹ̀.
|
Ayah 31:11 الأية
هَٰذَا خَلْقُ اللهِ فَأَرُونِي مَاذَا خَلَقَ الَّذِينَ مِن دُونِهِ ۚ بَلِ
الظَّالِمُونَ فِي ضَلَالٍ مُّبِينٍ
Hatha khalqu Allahi faarooneematha khalaqa allatheena min doonihi bali
aththalimoonafee dalalin mubeen
Yoruba
Èyí ni ẹ̀dá ti Allāhu. Nítorí náà, ẹ fi ohun tí àwọn mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀ dá hàn mí! Rárá o! Àwọn alábòsí wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé ni.
|
Ayah 31:12 الأية
وَلَقَدْ آتَيْنَا لُقْمَانَ الْحِكْمَةَ أَنِ اشْكُرْ لِلَّهِ ۚ وَمَن يَشْكُرْ
فَإِنَّمَا يَشْكُرُ لِنَفْسِهِ ۖ وَمَن كَفَرَ فَإِنَّ اللهَ غَنِيٌّ حَمِيدٌ
Walaqad atayna luqmanaalhikmata ani oshkur lillahi waman yashkur
fa-innamayashkuru linafsihi waman kafara fa-inna Allaha ghaniyyun hameed
Yoruba
Dájúdájú A ti fún Luƙmọ̄n ní ọgbọ́n, pé: "Dúpẹ́ fún Allāhu." Ẹnikẹ́ni tí ó bá dúpẹ́, ó ń dúpẹ́ fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ni. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàì moore, dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́rọ̀, Ẹlẹ́yìn (tí ẹyìn tọ́ sí).
|
Ayah 31:13 الأية
وَإِذْ قَالَ لُقْمَانُ لِابْنِهِ وَهُوَ يَعِظُهُ يَا بُنَيَّ لَا تُشْرِكْ
بِاللهِ ۖ إِنَّ الشِّرْكَ لَظُلْمٌ عَظِيمٌ
Wa-ith qala luqmanu libnihiwahuwa yaAAithuhu ya bunayya latushrik billahi inna
ashshirka lathulmunAAatheem
Yoruba
(Rántí) nígbà tí Luƙmọ̄n sọ fún ọmọ rẹ̀ nígbà tí ó ń ṣe wáàsí fún un, pé: "Ọmọ mi, má ṣe ṣẹbọ sí Allāhu. Dájúdájú ẹbọ ṣíṣe ni àbòsí ńlá.
|
Ayah 31:14 الأية
وَوَصَّيْنَا الْإِنسَانَ بِوَالِدَيْهِ حَمَلَتْهُ أُمُّهُ وَهْنًا عَلَىٰ وَهْنٍ
وَفِصَالُهُ فِي عَامَيْنِ أَنِ اشْكُرْ لِي وَلِوَالِدَيْكَ إِلَيَّ الْمَصِيرُ
Wawassayna al-insanabiwalidayhi hamalat-hu ommuhu wahnan AAalawahnin wafisaluhu
fee AAamayni ani oshkur lee waliwalidaykailayya almaseer
Yoruba
Àti pé A pa á ní àṣẹ fún ènìyàn nípa àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì - ìyá rẹ̀ gbé e ká (nínú oyún) pẹ̀lú àìlera lórí àìlera, ó sì gba ọmú lẹ́nu rẹ̀ láààrin ọdún méjì - (A sọ) pé: "Dúpẹ́ fún Èmi àti àwọn òbí rẹ méjèèjì." Ọ̀dọ̀ Mi sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.
|
Ayah 31:15 الأية
وَإِن جَاهَدَاكَ عَلَىٰ أَن تُشْرِكَ بِي مَا لَيْسَ لَكَ بِهِ عِلْمٌ فَلَا
تُطِعْهُمَا ۖ وَصَاحِبْهُمَا فِي الدُّنْيَا مَعْرُوفًا ۖ وَاتَّبِعْ سَبِيلَ مَنْ
أَنَابَ إِلَيَّ ۚ ثُمَّ إِلَيَّ مَرْجِعُكُمْ فَأُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمْ
تَعْمَلُونَ
Wa-in jahadaka AAala antushrika bee ma laysa laka bihi AAilmun fala
tutiAAhumawasahibhuma fee addunya maAAroofanwattabiAA sabeela man anaba ilayya
thumma ilayyamarjiAAukum faonabbi-okum bima kuntum taAAmaloon
Yoruba
Tí àwọn méjèèjì bá sì jà ọ́ lógun pé kí ó fi ohun tí ìwọ kò ní ìmọ̀ nípa rẹ̀ ṣẹbọ sí Mi, má ṣe tẹ̀lé àwọn méjèèjì. Fi dáadáa bá àwọn méjèèjì lòpọ̀ ní ilé ayé. Kí o sì tẹ̀lé ojú ọ̀nà ẹni tí ó bá ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Mi (ní ti ìronúpìwàdà). Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Mi ni ibùpadàsí yín. Nítorí náà, Mo máa fún yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
|
Ayah 31:16 الأية
يَا بُنَيَّ إِنَّهَا إِن تَكُ مِثْقَالَ حَبَّةٍ مِّنْ خَرْدَلٍ فَتَكُن فِي
صَخْرَةٍ أَوْ فِي السَّمَاوَاتِ أَوْ فِي الْأَرْضِ يَأْتِ بِهَا اللهُ ۚ إِنَّ
اللهَ لَطِيفٌ خَبِيرٌ
Ya bunayya innaha in takumithqala habbatin min khardalin fatakun fee sakhratinaw
fee assamawati aw fee al-ardiya/ti biha Allahu inna Allaha lateefunkhabeer
Yoruba
Ọmọ mi, dájúdájú tí ó bá jẹ́ pé òdiwọ̀n èso kardal kan ló wà nínú àpáta, tàbí nínú àwọn sánmọ̀, tàbí nínú ilẹ̀, Allāhu yóò mú un wá. Dájúdájú Allāhu ni Aláàánú, Alámọ̀tán.
|
Ayah 31:17 الأية
يَا بُنَيَّ أَقِمِ الصَّلَاةَ وَأْمُرْ بِالْمَعْرُوفِ وَانْهَ عَنِ الْمُنكَرِ
وَاصْبِرْ عَلَىٰ مَا أَصَابَكَ ۖ إِنَّ ذَٰلِكَ مِنْ عَزْمِ الْأُمُورِ
Ya bunayya aqimi assalatawa/mur bilmaAAroofi wanha AAani almunkari wasbirAAala
ma asabaka inna thalika minAAazmi al-omoor
Yoruba
Ọmọ mi, kírun, p'àṣẹ rere, kọ aburú, kí o sì ṣe sùúrù lórí ohun tí ó bá ṣẹlẹ̀ sí ọ. Dájúdájú ìyẹn wà nínú àwọn ìpinnu ọ̀rọ̀ tó pọn dandan.
|
Ayah 31:18 الأية
وَلَا تُصَعِّرْ خَدَّكَ لِلنَّاسِ وَلَا تَمْشِ فِي الْأَرْضِ مَرَحًا ۖ إِنَّ
اللهَ لَا يُحِبُّ كُلَّ مُخْتَالٍ فَخُورٍ
Wala tusaAAAAir khaddaka linnasiwala tamshi fee al-ardi marahan inna Allahala
yuhibbu kulla mukhtalin fakhoor
Yoruba
Má ṣe kọ párìkẹ́ rẹ sí ènìyàn. Má sì ṣe rìn lórí ilẹ̀ pẹ̀lú fáàrí. Dájúdájú Allāhu kò fẹ́ràn gbogbo onígbèéraga, onífáàrí.
|
Ayah 31:19 الأية
وَاقْصِدْ فِي مَشْيِكَ وَاغْضُضْ مِن صَوْتِكَ ۚ إِنَّ أَنكَرَ الْأَصْوَاتِ
لَصَوْتُ الْحَمِيرِ
Waqsid fee mashyika waghdudmin sawtika inna ankara al-aswati lasawtualhameer
Yoruba
Jẹ́ kí ìrìn ẹsẹ̀ rẹ wà ní ìwọ̀ntún-wọ̀nsì, kí o sì rẹ ohùn rẹ nílẹ̀. Dájúdájú ohùn tó burú jùlọ mà ni ohùn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́."
|
Ayah 31:20 الأية
أَلَمْ تَرَوْا أَنَّ اللهَ سَخَّرَ لَكُم مَّا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي
الْأَرْضِ وَأَسْبَغَ عَلَيْكُمْ نِعَمَهُ ظَاهِرَةً وَبَاطِنَةً ۗ وَمِنَ النَّاسِ
مَن يُجَادِلُ فِي اللهِ بِغَيْرِ عِلْمٍ وَلَا هُدًى وَلَا كِتَابٍ مُّنِيرٍ
Alam taraw anna Allaha sakhkharalakum ma fee assamawati wamafee al-ardi
waasbagha AAalaykum niAAamahu thahiratanwabatinatan wamina annasi man
yujadilufee Allahi bighayri AAilmin wala hudan walakitabin muneer
Yoruba
Ṣé ẹ kò wòye pé, dájúdájú Allāhu rọ ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ fún yín, Ó sì pé àwọn ìkẹ́ Rẹ̀ fún yín ní gban̄gba àti ní kọ̀rọ̀? Ó sì wà nínú àwọn ènìyàn ẹni tó ń jiyàn nípa Allāhu láì ní ìmọ̀ (al-Ƙur'ān) àti ìmọ̀nà (nínú sunnah Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) àti tírà (onímọ̀-ẹ̀sìn) tó ń tan ìmọ́lẹ̀ (sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn).
|
Ayah 31:21 الأية
وَإِذَا قِيلَ لَهُمُ اتَّبِعُوا مَا أَنزَلَ اللهُ قَالُوا بَلْ نَتَّبِعُ مَا
وَجَدْنَا عَلَيْهِ آبَاءَنَا ۚ أَوَلَوْ كَانَ الشَّيْطَانُ يَدْعُوهُمْ إِلَىٰ
عَذَابِ السَّعِيرِ
Wa-itha qeela lahumu ittabiAAoo maanzala Allahu qaloo bal nattabiAAu ma
wajadnaAAalayhi abaana awa law kana ashshaytanuyadAAoohum ila AAathabi assaAAeer
Yoruba
Nígbà tí wọ́n bá sì sọ fún wọn pé: "Ẹ tẹ̀lé ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀." Wọ́n á wí pé: "Rárá! A máa tẹ̀lé ohun tí a bá lọ́wọ́ àwọn bàbá wa ni." (Ṣé wọn yóò tẹ̀lé àwọn bàbá wọn) t'òhun ti bí Èṣù ṣe ń pè wọ́n síbi ìyà Iná tó ń jò fòfò?
|
Ayah 31:22 الأية
وَمَن يُسْلِمْ وَجْهَهُ إِلَى اللهِ وَهُوَ مُحْسِنٌ فَقَدِ اسْتَمْسَكَ
بِالْعُرْوَةِ الْوُثْقَىٰ ۗ وَإِلَى اللهِ عَاقِبَةُ الْأُمُورِ
Waman yuslim wajhahu ila Allahiwahuwa muhsinun faqadi istamsaka
bilAAurwatialwuthqa wa-ila Allahi AAaqibatual-omoor
Yoruba
Ẹnikẹ́ni tí ó bá jura rẹ̀ sílẹ̀ fún Allāhu, tí ó jẹ́ olùṣe-rere, dájúdájú onítọ̀un ti dìrọ̀ mọ́ okùn tó fọkàn balẹ̀ jùlọ. Àti pé ọ̀dọ̀ Allāhu ni ìkángun àwọn ọ̀rọ̀ (ẹ̀dá) wà.
|
Ayah 31:23 الأية
وَمَن كَفَرَ فَلَا يَحْزُنكَ كُفْرُهُ ۚ إِلَيْنَا مَرْجِعُهُمْ فَنُنَبِّئُهُم
بِمَا عَمِلُوا ۚ إِنَّ اللهَ عَلِيمٌ بِذَاتِ الصُّدُورِ
Waman kafara fala yahzunkakufruhu ilayna marjiAAuhum fanunabbi-ohum bimaAAamiloo
inna Allaha AAaleemun bithati assudoor
Yoruba
Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàì gbàgbọ́, má ṣe jẹ́ kí àìgbàgbọ́ rẹ̀ kó ìbànújẹ́ bá ọ. Ọ̀dọ̀ Wa ni ibùpadàsí wọn. Nígbà náà, A máa fún wọn ní ìró ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà ẹ̀dá.
|
Ayah 31:24 الأية
نُمَتِّعُهُمْ قَلِيلًا ثُمَّ نَضْطَرُّهُمْ إِلَىٰ عَذَابٍ غَلِيظٍ
NumattiAAuhum qaleelan thumma nadtarruhumila AAathabin ghaleeth
Yoruba
A máa fún wọn ní ìgbádùn díẹ̀. Lẹ́yìn náà, A máa taari wọn sínú ìyà tó nípọn.
|
Ayah 31:25 الأية
وَلَئِن سَأَلْتَهُم مَّنْ خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ لَيَقُولُنَّ اللهُ
ۚ قُلِ الْحَمْدُ لِلَّهِ ۚ بَلْ أَكْثَرُهُمْ لَا يَعْلَمُونَ
Wala-in saaltahum man khalaqa assamawatiwal-arda layaqoolunna Allahu quli
alhamdulillahi bal aktharuhum la yaAAlamoon
Yoruba
Dájúdájú tí o bá bi wọ́n léèrè pé: "Ta ni Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀?", dájúdájú wọ́n á wí pé: "Allāhu ni." Sọ pé: "Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò mọ̀.
|
Ayah 31:26 الأية
لِلَّهِ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ إِنَّ اللهَ هُوَ الْغَنِيُّ
الْحَمِيدُ
Lillahi ma fee assamawatiwal-ardi inna Allaha huwa alghaniyyu alhameed
Yoruba
Ti Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Ọlọ́rọ̀, Ẹlẹ́yìn.
|
Ayah 31:27 الأية
وَلَوْ أَنَّمَا فِي الْأَرْضِ مِن شَجَرَةٍ أَقْلَامٌ وَالْبَحْرُ يَمُدُّهُ مِن
بَعْدِهِ سَبْعَةُ أَبْحُرٍ مَّا نَفِدَتْ كَلِمَاتُ اللهِ ۗ إِنَّ اللهَ
عَزِيزٌ حَكِيمٌ
Walaw annama fee al-ardi minshajaratin aqlamun walbahru yamudduhu minbaAAdihi
sabAAatu abhurin ma nafidat kalimatuAllahi inna Allaha AAazeezun hakeem
Yoruba
Tí ó bá jẹ́ pé kìkìdá ohun tó ń bẹ lórí ilẹ̀ ní igi ni gègé ìkọ̀wé, kí agbami odò jẹ́ tàdáà rẹ̀, agbami odò méje (tún wà) lẹ́yìn rẹ̀ (tó máa kún un), àwọn ọ̀rọ̀ Allāhu kò níí tán (lẹ́yìn tí àwọn n̄ǹkan ìkọ̀wé wọ̀nyí bá tán nílẹ̀). Dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
|
Ayah 31:28 الأية
مَّا خَلْقُكُمْ وَلَا بَعْثُكُمْ إِلَّا كَنَفْسٍ وَاحِدَةٍ ۗ إِنَّ اللهَ
سَمِيعٌ بَصِيرٌ
Ma khalqukum wala baAAthukumilla kanafsin wahidatin inna AllahasameeAAun baseer
Yoruba
Ìṣẹ̀dá yín àti àjíǹde yín kò tayọ bí (ìṣẹ̀dá àti àjíǹde) ẹ̀mí ẹyọ kan. Dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Olùríran.
|
Ayah 31:29 الأية
أَلَمْ تَرَ أَنَّ اللهَ يُولِجُ اللَّيْلَ فِي النَّهَارِ وَيُولِجُ النَّهَارَ
فِي اللَّيْلِ وَسَخَّرَ الشَّمْسَ وَالْقَمَرَ كُلٌّ يَجْرِي إِلَىٰ أَجَلٍ
مُّسَمًّى وَأَنَّ اللهَ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرٌ
Alam tara anna Allaha yooliju allaylafee annahari wayooliju annahara feeallayli
wasakhkhara ashshamsa walqamara kullunyajree ila ajalin musamman waanna Allaha
bimataAAmaloona khabeer
Yoruba
Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu l'Ó ń ti òru bọ inú ọ̀sán, Ó ń ti ọ̀sán bọ inú òru, Ó sì rọ òòrùn àti òṣùpá? Ìkọ̀ọ̀kan wọn máa rìn títí di gbèdéke àkókò kan. Àti pé (ṣé o ò rí i pé) dájúdájú Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́?
|
Ayah 31:30 الأية
ذَٰلِكَ بِأَنَّ اللهَ هُوَ الْحَقُّ وَأَنَّ مَا يَدْعُونَ مِن دُونِهِ
الْبَاطِلُ وَأَنَّ اللهَ هُوَ الْعَلِيُّ الْكَبِيرُ
Thalika bi-anna Allaha huwa alhaqquwaanna ma yadAAoona min doonihi albatilu
waanna Allahahuwa alAAaliyyu alkabeer
Yoruba
Ìyẹn nítorí pé, dájúdájú Allāhu, Òun ni Òdodo. Àti pé dájúdájú ohun tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀ ni irọ́. Dájúdájú Allāhu, Ó ga, Ó tóbi.
|
Ayah 31:31 الأية
أَلَمْ تَرَ أَنَّ الْفُلْكَ تَجْرِي فِي الْبَحْرِ بِنِعْمَتِ اللهِ لِيُرِيَكُم
مِّنْ آيَاتِهِ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِّكُلِّ صَبَّارٍ شَكُورٍ
Alam tara anna alfulka tajree fee albahribiniAAmati Allahi liyuriyakum min
ayatihiinna fee thalika laayatin likulli sabbarinshakoor
Yoruba
Ṣé o ò rí i pé dájúdájú ọkọ̀ ojú-omi ń rìn ní ojú omi pẹ̀lú ìdẹ̀ra Rẹ̀, (ṣebí) nítorí kí (Allāhu) lè fi hàn yín nínú àwọn àmì Rẹ̀ ni? Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún gbogbo onísùúrù, olùdúpẹ́.
|
Ayah 31:32 الأية
وَإِذَا غَشِيَهُم مَّوْجٌ كَالظُّلَلِ دَعَوُا اللهَ مُخْلِصِينَ لَهُ الدِّينَ
فَلَمَّا نَجَّاهُمْ إِلَى الْبَرِّ فَمِنْهُم مُّقْتَصِدٌ ۚ وَمَا يَجْحَدُ
بِآيَاتِنَا إِلَّا كُلُّ خَتَّارٍ كَفُورٍ
Wa-itha ghashiyahum mawjun kaththulalidaAAawoo Allaha mukhliseena lahu
addeenafalamma najjahum ila albarri faminhum muqtasidunwama yajhadu bi-ayatina
illakullu khattarin kafoor
Yoruba
Nígbà tí ìgbì omi bá bò wọ́n mọ́lẹ̀ dáru bí ẹ̀ṣújò, wọ́n máa pe Allāhu lẹ́ni tí yóò máa fi àfọ̀mọ́-ọkàn (àníyàn mímọ́) ṣe ẹ̀sìn fún Un. Nígbà tí Ó bá sì gbà wọ́n là sórí ilẹ̀, onídéédé sì máa wà nínú wọn. Kò sì sí ẹni tó máa tako àwọn āyah Wa àfi gbogbo ọ̀dàlẹ̀, aláìmoore.
|
Ayah 31:33 الأية
يَا أَيُّهَا النَّاسُ اتَّقُوا رَبَّكُمْ وَاخْشَوْا يَوْمًا لَّا يَجْزِي وَالِدٌ
عَن وَلَدِهِ وَلَا مَوْلُودٌ هُوَ جَازٍ عَن وَالِدِهِ شَيْئًا ۚ إِنَّ وَعْدَ
اللهِ حَقٌّ ۖ فَلَا تَغُرَّنَّكُمُ الْحَيَاةُ الدُّنْيَا وَلَا يَغُرَّنَّكُم
بِاللهِ الْغَرُورُ
Ya ayyuha annasuittaqoo rabbakum wakhshaw yawman la yajzee walidunAAan waladihi
wala mawloodun huwa jazin AAan walidihishay-an inna waAAda Allahi haqqun
falataghurrannakumu alhayatu addunya walayaghurrannakum billahi algharoor
Yoruba
Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ bẹ̀rù Olúwa yín. Kí ẹ sì páyà ọjọ́ kan tí òbí kan kò níí ṣàǹfààní fún ọmọ rẹ̀; àti pé ọmọ kan, òun náà kò níí ṣàǹfààní kiní kan fún òbí rẹ̀. Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Nítorí náà, ìṣẹ̀mí ayé yìí kò gbọdọ̀ tàn yín jẹ. (Èṣù) ẹlẹ́tàn kò sì gbọdọ̀ tàn yín jẹ nípa Allāhu.
|
Ayah 31:34 الأية
إِنَّ اللهَ عِندَهُ عِلْمُ السَّاعَةِ وَيُنَزِّلُ الْغَيْثَ وَيَعْلَمُ مَا فِي
الْأَرْحَامِ ۖ وَمَا تَدْرِي نَفْسٌ مَّاذَا تَكْسِبُ غَدًا ۖ وَمَا تَدْرِي
نَفْسٌ بِأَيِّ أَرْضٍ تَمُوتُ ۚ إِنَّ اللهَ عَلِيمٌ خَبِيرٌ
Inna Allaha AAindahu AAilmu assaAAatiwayunazzilu alghaytha wayaAAlamu ma fee
al-arhamiwama tadree nafsun matha taksibu ghadan wamatadree nafsun bi-ayyi ardin
tamootu inna AllahaAAaleemun khabeer
Yoruba
Dájúdájú Allāhu, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni ìmọ̀ Àkókò náà wà. Ó ń sọ òjò kalẹ̀. Ó mọ ohun tó wà nínú àpòlùkẹ́. Ẹ̀mí kan kò sì mọ ohun tí ó máa ṣe níṣẹ́ ní ọ̀la. Ẹ̀mí kan kò sì mọ ilẹ̀ wo l'ó máa kú sí. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀, Alámọ̀tán.
|
©
EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us
|