Prev  

36. Surah Yâ­Sîn سورة يس

  Next  




1st Ayah  1  الأية ١الأولي
بِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
يس
Ya-seen

Yoruba
 
Yā sīn (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)

Ayah  36:2  الأية
وَالْقُرْآنِ الْحَكِيمِ
Walqur-ani alhakeem

Yoruba
 
(Allāhu) fi Al-Ƙur'ān tí ó kún fún ọgbọ́n búra.

Ayah  36:3  الأية
إِنَّكَ لَمِنَ الْمُرْسَلِينَ
Innaka lamina almursaleen

Yoruba
 
Dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn Òjíṣẹ́.

Ayah  36:4  الأية
عَلَىٰ صِرَاطٍ مُّسْتَقِيمٍ
AAala siratin mustaqeem

Yoruba
 
(O) wà lórí ọ̀nà tààrà ('Islām).

Ayah  36:5  الأية
تَنزِيلَ الْعَزِيزِ الرَّحِيمِ
Tanzeela alAAazeezi arraheem

Yoruba
 
(Al-Ƙur'ān jẹ́) ìmísí tó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run

Ayah  36:6  الأية
لِتُنذِرَ قَوْمًا مَّا أُنذِرَ آبَاؤُهُمْ فَهُمْ غَافِلُونَ
Litunthira qawman ma onthiraabaohum fahum ghafiloon

Yoruba
 
Nítorí kí o lè ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn kan, (àwọn) tí wọn kò ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn bàbá wọn rí. Nítorí náà, afọ́núfọ́ra sì ni wọ́n (nípa ìmọ̀nà).

Ayah  36:7  الأية
لَقَدْ حَقَّ الْقَوْلُ عَلَىٰ أَكْثَرِهِمْ فَهُمْ لَا يُؤْمِنُونَ
Laqad haqqa alqawlu AAalaaktharihim fahum la yu/minoon

Yoruba
 
Dájúdájú ọ̀rọ̀ náà ti kò lé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn lórí; wọn kò sì níí gbàgbọ́.

Ayah  36:8  الأية
إِنَّا جَعَلْنَا فِي أَعْنَاقِهِمْ أَغْلَالًا فَهِيَ إِلَى الْأَذْقَانِ فَهُم مُّقْمَحُونَ
Inna jaAAalna fee aAAnaqihimaghlalan fahiya ila al-athqani fahummuqmahoon

Yoruba
 
Dájúdájú Àwa ti kó ẹ̀wọ̀n sí wọn lọ́rùn (mọ́ ọwọ́ wọn). Ó sì ga dé àgbọ̀n (wọn). Wọ́n sì gà wọ́n lọ́rùn sókè.

Ayah  36:9  الأية
وَجَعَلْنَا مِن بَيْنِ أَيْدِيهِمْ سَدًّا وَمِنْ خَلْفِهِمْ سَدًّا فَأَغْشَيْنَاهُمْ فَهُمْ لَا يُبْصِرُونَ
WajaAAalna min bayni aydeehim saddanwamin khalfihim saddan faaghshaynahum fahum la yubsiroon

Yoruba
 
Àti pé Àwa fi gàgá kan síwájú wọn, gàgá kan sẹ́yìn wọn; A bò wọ́n lójú, wọn kò sì ríran.

Ayah  36:10  الأية
وَسَوَاءٌ عَلَيْهِمْ أَأَنذَرْتَهُمْ أَمْ لَمْ تُنذِرْهُمْ لَا يُؤْمِنُونَ
Wasawaon AAalayhim aanthartahumam lam tunthirhum la yu/minoon

Yoruba
 
Bákan náà ni fún wọn, yálà o kìlọ̀ fún wọn tàbí o kò kìlọ̀ fún wọn; wọn kò níí gbàgbọ́.

Ayah  36:11  الأية
إِنَّمَا تُنذِرُ مَنِ اتَّبَعَ الذِّكْرَ وَخَشِيَ الرَّحْمَٰنَ بِالْغَيْبِ ۖ فَبَشِّرْهُ بِمَغْفِرَةٍ وَأَجْرٍ كَرِيمٍ
Innama tunthiru mani ittabaAAaaththikra wakhashiya arrahmanabilghaybi fabashshirhu bimaghfiratin waajrin kareem

Yoruba
 
Ẹni tí ìkìlọ̀ rẹ (máa wúlò fún) ni ẹni tí ó tẹ̀lé Ìrántí (al-Ƙur'ān), tí ó sì páyà Àjọkẹ́-ayé ní ìkọ̀kọ̀. Nítorí náà, fún un ní ìró ìdùnnú nípa àforíjìn àti ẹ̀san alápọ̀n-ọ́nlé.

Ayah  36:12  الأية
إِنَّا نَحْنُ نُحْيِي الْمَوْتَىٰ وَنَكْتُبُ مَا قَدَّمُوا وَآثَارَهُمْ ۚ وَكُلَّ شَيْءٍ أَحْصَيْنَاهُ فِي إِمَامٍ مُّبِينٍ
Inna nahnu nuhyeealmawta wanaktubu ma qaddamoo waatharahumwakulla shay-in ahsaynahu fee imamin mubeen

Yoruba
 
Dájúdájú Àwa, Àwa l'À ń sọ àwọn òkú di alàyè. A sì ń ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí wọ́n tì síwájú àti orípa (iṣẹ́ ọwọ́) wọn. Gbogbo n̄ǹkan ni A ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú tírà kan tó yanjú.

Ayah  36:13  الأية
وَاضْرِبْ لَهُم مَّثَلًا أَصْحَابَ الْقَرْيَةِ إِذْ جَاءَهَا الْمُرْسَلُونَ
Wadrib lahum mathalan as-habaalqaryati ith jaaha almursaloon

Yoruba
 
Fi àpèjúwe kan lélẹ̀ fún wọn nípa àwọn ará ìlú kan nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ wá bá wọn.

Ayah  36:14  الأية
إِذْ أَرْسَلْنَا إِلَيْهِمُ اثْنَيْنِ فَكَذَّبُوهُمَا فَعَزَّزْنَا بِثَالِثٍ فَقَالُوا إِنَّا إِلَيْكُم مُّرْسَلُونَ
Ith arsalna ilayhimu ithnaynifakaththaboohuma faAAazzazna bithalithinfaqaloo inna ilaykum mursaloon

Yoruba
 
(Rántí) nígbà tí A rán Òjíṣẹ́ méjì níṣẹ́ sí wọn. Wọ́n pe àwọn méjèèjì ní òpùrọ́. A sì fi ẹnì kẹta ró àwọn méjèèjì lágbára. Wọ́n sì sọ pé: "Dájúdájú àwa ni Òjíṣẹ́ tí Wọ́n rán níṣẹ́ si yín."

Ayah  36:15  الأية
قَالُوا مَا أَنتُمْ إِلَّا بَشَرٌ مِّثْلُنَا وَمَا أَنزَلَ الرَّحْمَٰنُ مِن شَيْءٍ إِنْ أَنتُمْ إِلَّا تَكْذِبُونَ
Qaloo ma antum illabasharun mithluna wama anzala arrahmanumin shay-in in antum illa takthiboon

Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "Ẹ̀yin kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe abara bí irú tiwa. Àjọkẹ́-ayé kò sì sọ n̄ǹkan kan kalẹ̀. Ẹ̀yin kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe òpùrọ́."

Ayah  36:16  الأية
قَالُوا رَبُّنَا يَعْلَمُ إِنَّا إِلَيْكُمْ لَمُرْسَلُونَ
Qaloo rabbuna yaAAlamu innailaykum lamursaloon

Yoruba
 
Wọ́n sọ pé: "Olúwa wa mọ̀ pé dájúdájú àwa ni Òjíṣẹ́ tí Wọ́n rán níṣẹ́ si yín.

Ayah  36:17  الأية
وَمَا عَلَيْنَا إِلَّا الْبَلَاغُ الْمُبِينُ
Wama AAalayna illaalbalaghu almubeen

Yoruba
 
Kò sì sí ojúṣe kan fún wa bí kò ṣe ìkéde (ẹ̀sìn) tó yanjú."

Ayah  36:18  الأية
قَالُوا إِنَّا تَطَيَّرْنَا بِكُمْ ۖ لَئِن لَّمْ تَنتَهُوا لَنَرْجُمَنَّكُمْ وَلَيَمَسَّنَّكُم مِّنَّا عَذَابٌ أَلِيمٌ
Qaloo inna tatayyarnabikum la-in lam tantahoo lanarjumannakum walayamassannakum minnaAAathabun aleem

Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "Dájúdájú àwa rí àmì aburú lára yín. Tí ẹ kò bá jáwọ́ (níbi ìpèpè yín), dájúdájú a máa sọ yín lókò pa. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro yó sì jẹ yín láti ọ̀dọ̀ wa."

Ayah  36:19  الأية
قَالُوا طَائِرُكُم مَّعَكُمْ ۚ أَئِن ذُكِّرْتُم ۚ بَلْ أَنتُمْ قَوْمٌ مُّسْرِفُونَ
Qaloo ta-irukum maAAakum a-in thukkirtumbal antum qawmun musrifoon

Yoruba
 
Wọ́n sọ pé: "Àmì aburú yín ń bẹ pẹ̀lú yín. Ṣé nítorí pé wọ́n ṣe ìṣítí fún yín (l'ẹ fi rí àmì aburú lára wa)? Kò rí bẹ́ẹ̀! Ìjọ alákọyọ ni yín ni."

Ayah  36:20  الأية
وَجَاءَ مِنْ أَقْصَى الْمَدِينَةِ رَجُلٌ يَسْعَىٰ قَالَ يَا قَوْمِ اتَّبِعُوا الْمُرْسَلِينَ
Wajaa min aqsa almadeenatirajulun yasAAa qala ya qawmi ittabiAAooalmursaleen

Yoruba
 
Ọkùnrin kan sáré dé láti òpin ìlú náà, ó wí pé: "Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ tẹ̀lé àwọn Òjíṣẹ́ náà.

Ayah  36:21  الأية
اتَّبِعُوا مَن لَّا يَسْأَلُكُمْ أَجْرًا وَهُم مُّهْتَدُونَ
IttabiAAoo man la yas-alukum ajranwahum muhtadoon

Yoruba
 
Ẹ tẹ̀lé ẹni tí kò bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín. Olùmọ̀nà sì ni wọ́n.

Ayah  36:22  الأية
وَمَا لِيَ لَا أَعْبُدُ الَّذِي فَطَرَنِي وَإِلَيْهِ تُرْجَعُونَ
Wama liya la aAAbudu allatheefataranee wa-ilayhi turjaAAoon

Yoruba
 
Kí ni ó máa mú mi tí èmi kò fi níí jọ́sìn fún Ẹni tí Ó pilẹ̀ ẹ̀dá mi? Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí.

Ayah  36:23  الأية
أَأَتَّخِذُ مِن دُونِهِ آلِهَةً إِن يُرِدْنِ الرَّحْمَٰنُ بِضُرٍّ لَّا تُغْنِ عَنِّي شَفَاعَتُهُمْ شَيْئًا وَلَا يُنقِذُونِ
Aattakhithu min doonihi alihatanin yuridni arrahmanu bidurrin la tughniAAannee shafaAAatuhum shay-an wala yunqithoon

Yoruba
 
Ṣé kí èmi sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu ni? Tí Àjọkẹ́-ayé bá fẹ́ fi ìnira kàn mí, ìṣìpẹ̀ wọn kò lè rọ̀ mí lọ́rọ̀ kiní kan, wọn kò sì lè gbà mí là.

Ayah  36:24  الأية
إِنِّي إِذًا لَّفِي ضَلَالٍ مُّبِينٍ
Innee ithan lafee dalalinmubeen

Yoruba
 
(Bí èmi kò bá jọ́sìn fún Allāhu) nígbà náà dájúdájú mo ti wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.

Ayah  36:25  الأية
إِنِّي آمَنتُ بِرَبِّكُمْ فَاسْمَعُونِ
Innee amantu birabbikum fasmaAAoon

Yoruba
 
Dájúdájú èmi gbàgbọ́ nínú Olúwa Ẹlẹ́dàá yín. Nítorí náà, ẹ gbọ́ mi." (Àwọn aláìgbàgbọ́ sì pa onígbàgbọ́ òdodo yìí.)

Ayah  36:26  الأية
قِيلَ ادْخُلِ الْجَنَّةَ ۖ قَالَ يَا لَيْتَ قَوْمِي يَعْلَمُونَ
Qeela odkhuli aljannata qala yalayta qawmee yaAAlamoon

Yoruba
 
(Àwọn mọlāika) wọ́n sọ pé: "Wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra." Ó sọ pé: "Àwọn ènìyàn mi ìbá ní ìmọ̀

Ayah  36:27  الأية
بِمَا غَفَرَ لِي رَبِّي وَجَعَلَنِي مِنَ الْمُكْرَمِينَ
Bima ghafara lee rabbee wajaAAalaneemina almukrameen

Yoruba
 
Nípa bí Olúwa mi ṣe foríjìn mí àti (bí) Ó ṣe fi mí sí ara àwọn alápọ̀n-ọ́nlé (wọn ìbá ronú pìwàdà)."

Ayah  36:28  الأية
وَمَا أَنزَلْنَا عَلَىٰ قَوْمِهِ مِن بَعْدِهِ مِن جُندٍ مِّنَ السَّمَاءِ وَمَا كُنَّا مُنزِلِينَ
Wama anzalna AAalaqawmihi min baAAdihi min jundin mina assama-i wamakunna munzileen

Yoruba
 
A kò sọ ọmọ ogun kan kalẹ̀ lé àwọn ènìyàn rẹ̀ lórí láti sánmọ̀ lẹ́yìn rẹ̀. A kò sì sọ (mọlāika kan) kalẹ̀ (fún ìparun wọn).

Ayah  36:29  الأية
إِن كَانَتْ إِلَّا صَيْحَةً وَاحِدَةً فَإِذَا هُمْ خَامِدُونَ
In kanat illa sayhatanwahidatan fa-itha hum khamidoon

Yoruba
 
(Ìparun wọn) kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe igbe ẹyọ kan; nígbà náà ni wọ́n di òkú kalẹ̀.

Ayah  36:30  الأية
يَا حَسْرَةً عَلَى الْعِبَادِ ۚ مَا يَأْتِيهِم مِّن رَّسُولٍ إِلَّا كَانُوا بِهِ يَسْتَهْزِئُونَ
Ya hasratan AAalaalAAibadi ma ya/teehim min rasoolin illa kanoobihi yastahzi-oon

Yoruba
 
Àbámọ̀ mà ni fún àwọn ẹrúsìn náà (nígbà tí wọ́n bá fojú ara wọn rí Iná); òjíṣẹ́ kan kò níí wá bá wọn àyàfi kí wọ́n máa fi ṣe yẹ̀yẹ́.

Ayah  36:31  الأية
أَلَمْ يَرَوْا كَمْ أَهْلَكْنَا قَبْلَهُم مِّنَ الْقُرُونِ أَنَّهُمْ إِلَيْهِمْ لَا يَرْجِعُونَ
Alam yaraw kam ahlakna qablahum minaalqurooni annahum ilayhim la yarjiAAoon

Yoruba
 
Ṣé wọn kò wòye pé mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn? (Ṣé wọn kò wòye pé) dájúdájú wọn kò padà sí ọ̀dọ̀ wọn mọ́ (nílé ayé) ni?

Ayah  36:32  الأية
وَإِن كُلٌّ لَّمَّا جَمِيعٌ لَّدَيْنَا مُحْضَرُونَ
Wa-in kullun lamma jameeAAun ladaynamuhdaroon

Yoruba
 
Dájúdájú gbogbo wọn pátápátá sì ni (àwọn mọlāika) máa kó wá sí ọ̀dọ̀ Wa.

Ayah  36:33  الأية
وَآيَةٌ لَّهُمُ الْأَرْضُ الْمَيْتَةُ أَحْيَيْنَاهَا وَأَخْرَجْنَا مِنْهَا حَبًّا فَمِنْهُ يَأْكُلُونَ
Waayatun lahumu al-ardualmaytatu ahyaynaha waakhrajna minhahabban faminhu ya/kuloon

Yoruba
 
Àmì ni òkú ilẹ̀ jẹ́ fún wọn. A sọ ọ́ di ààyè. A sì mú èso jáde láti inú rẹ̀. Wọ́n sì ń jẹ nínú rẹ̀.

Ayah  36:34  الأية
وَجَعَلْنَا فِيهَا جَنَّاتٍ مِّن نَّخِيلٍ وَأَعْنَابٍ وَفَجَّرْنَا فِيهَا مِنَ الْعُيُونِ
WajaAAalna feeha jannatinmin nakheelin waaAAnabin wafajjarna feehamina alAAuyoon

Yoruba
 
A tún ṣe àwọn ọgbà dàbínù àti àjàrà sórí ilẹ̀. A sì mú àwọn odò ìṣẹ́lẹ̀rú ṣàn láti inú rẹ̀

Ayah  36:35  الأية
لِيَأْكُلُوا مِن ثَمَرِهِ وَمَا عَمِلَتْهُ أَيْدِيهِمْ ۖ أَفَلَا يَشْكُرُونَ
Liya/kuloo min thamarihi wamaAAamilat-hu aydeehim afala yashkuroon

Yoruba
 
Nítorí kí wọ́n lè jẹ nínú èso rẹ̀ àti èyí tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe! Ṣé wọn kò níí dúpẹ́ ni?

Ayah  36:36  الأية
سُبْحَانَ الَّذِي خَلَقَ الْأَزْوَاجَ كُلَّهَا مِمَّا تُنبِتُ الْأَرْضُ وَمِنْ أَنفُسِهِمْ وَمِمَّا لَا يَعْلَمُونَ
Subhana allathee khalaqaal-azwaja kullaha mimma tunbitu al-arduwamin anfusihim wamimma la yaAAlamoon

Yoruba
 
Mímọ́ ni fún Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá gbogbo n̄ǹkan ní oríṣiríṣi nínú ohun tí ilẹ̀ ń hù jáde àti nínú ẹ̀mí ara wọn àti nínú ohun tí wọn kò mọ̀.

Ayah  36:37  الأية
وَآيَةٌ لَّهُمُ اللَّيْلُ نَسْلَخُ مِنْهُ النَّهَارَ فَإِذَا هُم مُّظْلِمُونَ
Waayatun lahumu allaylu naslakhuminhu annahara fa-itha hum muthlimoon

Yoruba
 
Àmì kan ni òru jẹ́ fún wọn, tí À ń yọ ọ̀sán jáde láti inú rẹ̀. Nígbà náà (tí A bá yọ ọ́ tán) wọn yóò tún wà nínú òkùnkùn (alẹ́ mìíràn).

Ayah  36:38  الأية
وَالشَّمْسُ تَجْرِي لِمُسْتَقَرٍّ لَّهَا ۚ ذَٰلِكَ تَقْدِيرُ الْعَزِيزِ الْعَلِيمِ
Washshamsu tajree limustaqarrin lahathalika taqdeeru alAAazeezi alAAaleem

Yoruba
 
Àti pé òòrùn yóò máa rìn lọ sí àyè rẹ̀. Ìyẹn ni ètò (ti) Alágbára, Onímọ̀.

Ayah  36:39  الأية
وَالْقَمَرَ قَدَّرْنَاهُ مَنَازِلَ حَتَّىٰ عَادَ كَالْعُرْجُونِ الْقَدِيمِ
Walqamara qaddarnahu manazilahatta AAada kalAAurjooni alqadeem

Yoruba
 
Òṣùpá náà, A ti ṣe òdíwọ̀n àwọn ibùsọ̀ fún un (tí ó ti ma máa tóbi sí i) títí ó máa fi padà dà bíi àran ọ̀pẹ tó ti pẹ́ (gbígbẹ).

Ayah  36:40  الأية
لَا الشَّمْسُ يَنبَغِي لَهَا أَن تُدْرِكَ الْقَمَرَ وَلَا اللَّيْلُ سَابِقُ النَّهَارِ ۚ وَكُلٌّ فِي فَلَكٍ يَسْبَحُونَ
La ashshamsu yanbaghee lahaan tudrika alqamara wala allaylu sabiqu annahariwakullun fee falakin yasbahoon

Yoruba
 
Kò yẹ fún òòrùn láti lo àsìkò òṣùpá. Kò sì yẹ fún alẹ́ láti lo àsìkò ọ̀sán. Ìkọ̀ọ̀kan wà ní òpópónà róbótó tó ń tọ̀.

Ayah  36:41  الأية
وَآيَةٌ لَّهُمْ أَنَّا حَمَلْنَا ذُرِّيَّتَهُمْ فِي الْفُلْكِ الْمَشْحُونِ
Waayatun lahum anna hamalnathurriyyatahum fee alfulki almashhoon

Yoruba
 
Àmì kan tún ni fún wọn pé, dájúdájú Àwa gbé àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn gun ọkọ̀ ojú-omi tó kún kẹ́kẹ́.

Ayah  36:42  الأية
وَخَلَقْنَا لَهُم مِّن مِّثْلِهِ مَا يَرْكَبُونَ
Wakhalaqna lahum min mithlihi mayarkaboon

Yoruba
 
A tún ṣẹ̀dá (òmíràn) fún wọn nínú irú rẹ̀ tí wọn yóò máa gún.

Ayah  36:43  الأية
وَإِن نَّشَأْ نُغْرِقْهُمْ فَلَا صَرِيخَ لَهُمْ وَلَا هُمْ يُنقَذُونَ
Wa-in nasha/ nughriqhum fala sareekhalahum wala hum yunqathoon

Yoruba
 
Tí A bá fẹ́ Àwa ìbá tẹ̀ wọ́n rì sínú omi. Kò níí sí olùrànlọ́wọ́ kan fún wọn. Wọn kò sì níí gbà wọ́n là.

Ayah  36:44  الأية
إِلَّا رَحْمَةً مِّنَّا وَمَتَاعًا إِلَىٰ حِينٍ
Illa rahmatan minnawamataAAan ila heen

Yoruba
 
Àfi (kí Á fi) ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Wa (yọ wọ́n jáde, kí A sì tún fún wọn ní) ìgbádùn ayé títí di ìgbà díẹ̀.

Ayah  36:45  الأية
وَإِذَا قِيلَ لَهُمُ اتَّقُوا مَا بَيْنَ أَيْدِيكُمْ وَمَا خَلْفَكُمْ لَعَلَّكُمْ تُرْحَمُونَ
Wa-itha qeela lahumu ittaqoo mabayna aydeekum wama khalfakum laAAallakum turhamoon

Yoruba
 
(Wọ́n máa gbúnrí) nígbà tí A bá sọ fún wọn pé: "Ẹ ṣọ́ra fún ohun tó wà níwájú yín àti ohun tó wà lẹ́yìn yín nítorí kí A lè kẹ yín."

Ayah  36:46  الأية
وَمَا تَأْتِيهِم مِّنْ آيَةٍ مِّنْ آيَاتِ رَبِّهِمْ إِلَّا كَانُوا عَنْهَا مُعْرِضِينَ
Wama ta/teehim min ayatin min ayatirabbihim illa kanoo AAanha muAArideen

Yoruba
 
Àti pé āyah kan nínú àwọn āyah Olúwa wọn kò níí wá bá wọn àfi kí wọ́n máa gbúnrí kúrò níbẹ̀.

Ayah  36:47  الأية
وَإِذَا قِيلَ لَهُمْ أَنفِقُوا مِمَّا رَزَقَكُمُ اللهُ قَالَ الَّذِينَ كَفَرُوا لِلَّذِينَ آمَنُوا أَنُطْعِمُ مَن لَّوْ يَشَاءُ اللهُ أَطْعَمَهُ إِنْ أَنتُمْ إِلَّا فِي ضَلَالٍ مُّبِينٍ
Wa-itha qeela lahum anfiqoo mimmarazaqakumu Allahu qala allatheena kafaroolillatheena amanoo anutAAimu man law yashaoAllahu atAAamahu in antum illa fee dalalinmubeen

Yoruba
 
Nígbà tí A bá sì sọ fún wọn pé: "Ẹ ná nínú ohun tí Allāhu ṣe ní arísìkí fún yín.", àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ yóò wí fún àwọn tó gbàgbọ́ pé: "Ṣé kí á bọ́ ẹni tí (ó jẹ́ pé) Allāhu ìbá fẹ́ ìbá bọ́ ọ (àmọ́ kò bọ́ ọ. Àwa náà kò sì níí bá A bọ́ ọ)?" Kí ni ẹ̀yin bí kò ṣe pé (ẹ wà) nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.

Ayah  36:48  الأية
وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَٰذَا الْوَعْدُ إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ
Wayaqooloona mata hathaalwaAAdu in kuntum sadiqeen

Yoruba
 
Wọ́n ń wí pé: "Ìgbà wo ni àdéhùn yìí yóò ṣẹ tí ẹ bá jẹ́ olódodo?"

Ayah  36:49  الأية
مَا يَنظُرُونَ إِلَّا صَيْحَةً وَاحِدَةً تَأْخُذُهُمْ وَهُمْ يَخِصِّمُونَ
Ma yanthuroona illasayhatan wahidatan ta/khuthuhum wahumyakhissimoon

Yoruba
 
Wọn kò retí kiní kan bí kò ṣe igbe ẹyọ kan ṣoṣo tí ó máa gbá wọn mú nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àríyànjiyàn lọ́wọ́.

Ayah  36:50  الأية
فَلَا يَسْتَطِيعُونَ تَوْصِيَةً وَلَا إِلَىٰ أَهْلِهِمْ يَرْجِعُونَ
Fala yastateeAAoona tawsiyatanwala ila ahlihim yarjiAAoon

Yoruba
 
Nígbà náà, wọn kò níí lè sọ àsọọ́lẹ̀ kan. Wọn kò sì níí lè padà sí ọ̀dọ̀ ará ilé wọn.

Ayah  36:51  الأية
وَنُفِخَ فِي الصُّورِ فَإِذَا هُم مِّنَ الْأَجْدَاثِ إِلَىٰ رَبِّهِمْ يَنسِلُونَ
Wanufikha fee assoori fa-ithahum mina al-ajdathi ila rabbihim yansiloon

Yoruba
 
Wọ́n á sì fọn fèrè oníwo fún àjíǹde, nígbà náà ni wọn yóò máa sáré jáde láti inú sàréè wá sí ọ̀dọ̀ Olúwa wọn.

Ayah  36:52  الأية
قَالُوا يَا وَيْلَنَا مَن بَعَثَنَا مِن مَّرْقَدِنَا ۜ ۗ هَٰذَا مَا وَعَدَ الرَّحْمَٰنُ وَصَدَقَ الْمُرْسَلُونَ
Qaloo ya waylana manbaAAathana min marqadina hatha mawaAAada arrahmanu wasadaqaalmursaloon

Yoruba
 
Wọ́n á wí pé: "Ègbé wa ò! Ta ni ó ta wá jí láti ojú oorun wa?" Èyí ni n̄ǹkan tí Àjọkẹ́-ayé ṣe ní àdéhùn. Àwọn Òjíṣẹ́ sì ti sọ òdodo (nípa rẹ̀).

Ayah  36:53  الأية
إِن كَانَتْ إِلَّا صَيْحَةً وَاحِدَةً فَإِذَا هُمْ جَمِيعٌ لَّدَيْنَا مُحْضَرُونَ
In kanat illa sayhatanwahidatan fa-itha hum jameeAAun ladayna muhdaroon

Yoruba
 
Kò jẹ́ kiní kan tayọ igbe ẹyọ kan ṣoṣo. Nígbà náà ni (àwọn mọlāika) yóò kó gbogbo wọn wá sí ọ̀dọ̀ Wa.

Ayah  36:54  الأية
فَالْيَوْمَ لَا تُظْلَمُ نَفْسٌ شَيْئًا وَلَا تُجْزَوْنَ إِلَّا مَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ
Falyawma la tuthlamunafsun shay-an wala tujzawna illa ma kuntumtaAAmaloon

Yoruba
 
Nítorí náà, ní òní wọn kò níí ṣe àbòsí kiní kan fún ẹ̀mí kan. A kò sì níí san yín ní ẹ̀san àfi ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

Ayah  36:55  الأية
إِنَّ أَصْحَابَ الْجَنَّةِ الْيَوْمَ فِي شُغُلٍ فَاكِهُونَ
Inna as-haba aljannati alyawmafee shughulin fakihoon

Yoruba
 
Dájúdájú ní òní, àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra yóò kún fún ìgbádùn.

Ayah  36:56  الأية
هُمْ وَأَزْوَاجُهُمْ فِي ظِلَالٍ عَلَى الْأَرَائِكِ مُتَّكِئُونَ
Hum waazwajuhum fee thilalinAAala al-ara-iki muttaki-oon

Yoruba
 
Àwọn àti àwọn ìyàwó wọn yóò wà lábẹ́ àwọn ibòji, wọn yó sì rọ̀gbọ̀kú sórí àwọn ibùsùn.

Ayah  36:57  الأية
لَهُمْ فِيهَا فَاكِهَةٌ وَلَهُم مَّا يَدَّعُونَ
Lahum feeha fakihatun walahumma yaddaAAoon

Yoruba
 
Èso wà nínú rẹ̀ fún wọn. Ohun tí wọ́n yóò máa bèèrè fún tún wà fún wọn pẹ̀lú.

Ayah  36:58  الأية
سَلَامٌ قَوْلًا مِّن رَّبٍّ رَّحِيمٍ
Salamun qawlan min rabbin raheem

Yoruba
 
Àlàáfíà ni ọ̀rọ̀ tí ó má máa wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

Ayah  36:59  الأية
وَامْتَازُوا الْيَوْمَ أَيُّهَا الْمُجْرِمُونَ
Wamtazoo alyawma ayyuhaalmujrimoon

Yoruba
 
Ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀, ẹ bọ́ sí ọ̀tọ̀ ní òní.

Ayah  36:60  الأية
أَلَمْ أَعْهَدْ إِلَيْكُمْ يَا بَنِي آدَمَ أَن لَّا تَعْبُدُوا الشَّيْطَانَ ۖ إِنَّهُ لَكُمْ عَدُوٌّ مُّبِينٌ
Alam aAAhad ilaykum ya banee adamaan la taAAbudoo ashshaytana innahu lakumAAaduwwun mubeen

Yoruba
 
Ẹ̀yin ọmọ (Ànábì) Ādam, ṣe Èmi kò ti pa yín ní àṣẹ pé, ẹ kò gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún Èṣù? Dájúdájú òun ni ọ̀tá pọ́nńbélé fún yín.

Ayah  36:61  الأية
وَأَنِ اعْبُدُونِي ۚ هَٰذَا صِرَاطٌ مُّسْتَقِيمٌ
Waani oAAbudoonee hatha siratunmustaqeem

Yoruba
 
Àti pé kí ẹ jọ́sìn fún Mi. Èyí ni ọ̀nà tààrà.

Ayah  36:62  الأية
وَلَقَدْ أَضَلَّ مِنكُمْ جِبِلًّا كَثِيرًا ۖ أَفَلَمْ تَكُونُوا تَعْقِلُونَ
Walaqad adalla minkum jibillankatheeran afalam takoonoo taAAqiloon

Yoruba
 
Àti pé (Èṣù) kúkú ti ṣi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ẹ̀dá lọ́nà nínú yín. Ṣé ẹ kò níí ṣe làákàyè ni?

Ayah  36:63  الأية
هَٰذِهِ جَهَنَّمُ الَّتِي كُنتُمْ تُوعَدُونَ
Hathihi jahannamu allatee kuntumtooAAadoon

Yoruba
 
Èyí ni iná Jahanamọ tí À ń ṣe ní àdéhùn fún yín.

Ayah  36:64  الأية
اصْلَوْهَا الْيَوْمَ بِمَا كُنتُمْ تَكْفُرُونَ
Islawha alyawma bimakuntum takfuroon

Yoruba
 
Ẹ wọ inú rẹ̀ ní òní nítorí pé, ẹ̀yin jẹ́ aláìgbàgbọ́.

Ayah  36:65  الأية
الْيَوْمَ نَخْتِمُ عَلَىٰ أَفْوَاهِهِمْ وَتُكَلِّمُنَا أَيْدِيهِمْ وَتَشْهَدُ أَرْجُلُهُم بِمَا كَانُوا يَكْسِبُونَ
Alyawma nakhtimu AAala afwahihimwatukallimuna aydeehim watashhadu arjuluhum bima kanooyaksiboon

Yoruba
 
Ní òní, A máa di ẹnu wọn pa. Àwọn ọwọ́ wọn yó sì máa bá Wa sọ̀rọ̀. Àwọn ẹsẹ̀ wọn yó sì máa jẹ́rìí sí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

Ayah  36:66  الأية
وَلَوْ نَشَاءُ لَطَمَسْنَا عَلَىٰ أَعْيُنِهِمْ فَاسْتَبَقُوا الصِّرَاطَ فَأَنَّىٰ يُبْصِرُونَ
Walaw nashao latamasnaAAala aAAyunihim fastabaqoo assiratafaanna yubsiroon

Yoruba
 
Tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́, Àwa ìbá fọ́ wọn lójú, wọn ìbá sì yára wá si ojú ọ̀nà, báwo ni wọ́n ṣe máa ríran ná?

Ayah  36:67  الأية
وَلَوْ نَشَاءُ لَمَسَخْنَاهُمْ عَلَىٰ مَكَانَتِهِمْ فَمَا اسْتَطَاعُوا مُضِيًّا وَلَا يَرْجِعُونَ
Walaw nashao lamasakhnahumAAala makanatihim fama istataAAoo mudiyyanwala yarjiAAoon

Yoruba
 
Tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́, Àwa ìbá yí wọn padà sí ẹ̀dá mìíràn nínú ibùgbé wọn. Wọn kò sì níí lágbára láti lọ síwájú. Wọn kò sì níí padà sẹ́yìn.

Ayah  36:68  الأية
وَمَن نُّعَمِّرْهُ نُنَكِّسْهُ فِي الْخَلْقِ ۖ أَفَلَا يَعْقِلُونَ
Waman nuAAammirhu nunakkis-hu fee alkhalqiafala yaAAqiloon

Yoruba
 
Ẹnikẹ́ni tí A bá fún ní ẹ̀mí gígùn lò, A óò sọ ẹ̀dá rẹ̀ di ọ̀lẹ, ṣé wọn kò níí ṣe làákàyè ni!

Ayah  36:69  الأية
وَمَا عَلَّمْنَاهُ الشِّعْرَ وَمَا يَنبَغِي لَهُ ۚ إِنْ هُوَ إِلَّا ذِكْرٌ وَقُرْآنٌ مُّبِينٌ
Wama AAallamnahu ashshiAArawama yanbaghee lahu in huwa illa thikrunwaqur-anun mubeen

Yoruba
 
A kò kọ́ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ní ewì. Kò yẹ ẹ́ (kò sì rọ̀ ọ́ lọ́rùn láti kéwì). Kí ni ohun (tí A fi ránṣẹ́ sí i) bí kò ṣe ìrántí àti al-Ƙur'ān pọ́nńbélé

Ayah  36:70  الأية
لِّيُنذِرَ مَن كَانَ حَيًّا وَيَحِقَّ الْقَوْلُ عَلَى الْكَافِرِينَ
Liyunthira man kana hayyanwayahiqqa alqawlu AAala alkafireen

Yoruba
 
Nítorí kí ó lè ṣèkìlọ̀ fún ẹni tí ó jẹ́ alààyè àti nítorí kí ọ̀rọ̀ náà lè kò lórí àwọn aláìgbàgbọ́.

Ayah  36:71  الأية
أَوَلَمْ يَرَوْا أَنَّا خَلَقْنَا لَهُم مِّمَّا عَمِلَتْ أَيْدِينَا أَنْعَامًا فَهُمْ لَهَا مَالِكُونَ
Awa lam yaraw anna khalaqnalahum mimma AAamilat aydeena anAAaman fahumlaha malikoon

Yoruba
 
Ṣé wọn kò wòye pé dájúdájú Àwa l'A ṣẹ̀dá nínú ohun tí A fi ọwọ́ Wa ṣe (tí ó jẹ́) àwọn ẹran-ọ̀sìn fún wọn? Wọ́n sì ní ìkápá lórí wọn.

Ayah  36:72  الأية
وَذَلَّلْنَاهَا لَهُمْ فَمِنْهَا رَكُوبُهُمْ وَمِنْهَا يَأْكُلُونَ
Wathallalnaha lahumfaminha rakoobuhum waminha ya/kuloon

Yoruba
 
A tẹ̀ wọ́n lórí ba fún wọn; wọ́n ń gùn nínú wọn, wọ́n sì ń jẹ nínú wọn.

Ayah  36:73  الأية
وَلَهُمْ فِيهَا مَنَافِعُ وَمَشَارِبُ ۖ أَفَلَا يَشْكُرُونَ
Walahum feeha manafiAAu wamasharibuafala yashkuroon

Yoruba
 
Àwọn àǹfààní àti ohun mímu tún wà fún wọn nínú rẹ̀. Ṣé wọn kò níí dúpẹ́ ni?

Ayah  36:74  الأية
وَاتَّخَذُوا مِن دُونِ اللهِ آلِهَةً لَّعَلَّهُمْ يُنصَرُونَ
Wattakhathoo min dooni Allahialihatan laAAallahum yunsaroon

Yoruba
 
Wọ́n sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu nítorí kí wọ́n lè ṣàrànṣe fún wọn!

Ayah  36:75  الأية
لَا يَسْتَطِيعُونَ نَصْرَهُمْ وَهُمْ لَهُمْ جُندٌ مُّحْضَرُونَ
La yastateeAAoona nasrahumwahum lahum jundun muhdaroon

Yoruba
 
Wọn kò sì lè ṣe àrànṣe fún wọn; ṣebí àwọn òrìṣà ni ọmọ ogun tí (àwọn mọlāika) máa kó wá sínú Iná fún àwọn abọ̀rìṣà (láti fi jẹ wọ́n níyà).

Ayah  36:76  الأية
فَلَا يَحْزُنكَ قَوْلُهُمْ ۘ إِنَّا نَعْلَمُ مَا يُسِرُّونَ وَمَا يُعْلِنُونَ
Fala yahzunka qawluhum innanaAAlamu ma yusirroona wama yuAAlinoon

Yoruba
 
Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọn bà ọ́ nínú jẹ́. Dájúdájú Àwa mọ ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ àti ohun tí wọ́n ń ṣàfi hàn rẹ̀.

Ayah  36:77  الأية
أَوَلَمْ يَرَ الْإِنسَانُ أَنَّا خَلَقْنَاهُ مِن نُّطْفَةٍ فَإِذَا هُوَ خَصِيمٌ مُّبِينٌ
Awa lam yara al-insanu annakhalaqnahu min nutfatin fa-itha huwa khaseemunmubeen

Yoruba
 
Ṣé ènìyàn kò wòye pé dájúdájú Àwa l'A ṣẹ̀dá rẹ̀ láti inú àtọ̀? (Ṣebí lẹ́yìn) ìgbà náà l'ó di alátakò pọ́nńbélé.

Ayah  36:78  الأية
وَضَرَبَ لَنَا مَثَلًا وَنَسِيَ خَلْقَهُ ۖ قَالَ مَن يُحْيِي الْعِظَامَ وَهِيَ رَمِيمٌ
Wadaraba lana mathalanwanasiya khalqahu qala man yuhyee alAAithamawahiya rameem

Yoruba
 
Àti pé ó fi àkàwé lélẹ̀ nípa Wa. Ó sì gbàgbé ìṣẹ̀dá rẹ̀. Ó wí pé: "Ta ni Ó máa sọ egungun di alààyè nígbà tí ó ti kẹfun?"

Ayah  36:79  الأية
قُلْ يُحْيِيهَا الَّذِي أَنشَأَهَا أَوَّلَ مَرَّةٍ ۖ وَهُوَ بِكُلِّ خَلْقٍ عَلِيمٌ
Qul yuhyeeha allatheeanshaaha awwala marratin wahuwa bikulli khalqin AAaleem

Yoruba
 
Sọ pé: "Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá rẹ̀ nígbà àkọ́kọ́ l'Ó máa sọ ọ́ di alààyè. Òun sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo ẹ̀dá.

Ayah  36:80  الأية
الَّذِي جَعَلَ لَكُم مِّنَ الشَّجَرِ الْأَخْضَرِ نَارًا فَإِذَا أَنتُم مِّنْهُ تُوقِدُونَ
Allathee jaAAala lakum mina ashshajarial-akhdari naran fa-itha antum minhutooqidoon

Yoruba
 
(Òun ni) Ẹni tí Ó mú iná jáde fún yín láti ara igi tútù. Ẹ sì ń fi dáná.

Ayah  36:81  الأية
أَوَلَيْسَ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ بِقَادِرٍ عَلَىٰ أَن يَخْلُقَ مِثْلَهُم ۚ بَلَىٰ وَهُوَ الْخَلَّاقُ الْعَلِيمُ
Awa laysa allathee khalaqa assamawatiwal-arda biqadirin AAala an yakhluqamithlahum bala wahuwa alkhallaqu alAAaleem

Yoruba
 
Ǹjẹ́ Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ kò ní agbára láti dá irú wọn (mìíràn) bí? Bẹ́ẹ̀ ni (Ó ní agbára). Òun sì ni Ẹlẹ́dàá, Onímọ̀.

Ayah  36:82  الأية
إِنَّمَا أَمْرُهُ إِذَا أَرَادَ شَيْئًا أَن يَقُولَ لَهُ كُن فَيَكُونُ
Innama amruhu itha aradashay-an an yaqoola lahu kun fayakoon

Yoruba
 
Àṣẹ Rẹ̀ nígbà tí Ó bá gbèrò kiní kan ni pé, Ó máa sọ fún un pé "Jẹ́ bẹ́ẹ̀." Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀.

Ayah  36:83  الأية
فَسُبْحَانَ الَّذِي بِيَدِهِ مَلَكُوتُ كُلِّ شَيْءٍ وَإِلَيْهِ تُرْجَعُونَ
Fasubhana allathee biyadihimalakootu kulli shay-in wa-ilayhi turjaAAoon

Yoruba
 
Sabõda haka, tsarki yã tabbata ga Wanda mallakar kõwane abu take ga HannãyenSa, kuma zuwa gare Shi ake mayar da ku. 





© EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us