Prev  

39. Surah Az-Zumar سورة الزمر

  Next  




1st Ayah  1  الأية ١الأولي
بِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
تَنزِيلُ الْكِتَابِ مِنَ اللهِ الْعَزِيزِ الْحَكِيمِ
Tanzeelu alkitabi mina AllahialAAazeezi alhakeem

Yoruba
 
Tírà náà sọ̀kalẹ̀ díẹ̀ díẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Allāhu, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

Ayah  39:2  الأية
إِنَّا أَنزَلْنَا إِلَيْكَ الْكِتَابَ بِالْحَقِّ فَاعْبُدِ اللهَ مُخْلِصًا لَّهُ الدِّينَ
Inna anzalna ilayka alkitababilhaqqi faAAbudi Allaha mukhlisanlahu addeen

Yoruba
 
Dájúdájú Àwa sọ Tírà (al-Ƙur'ān) kalẹ̀ fún ọ pẹ̀lú òdodo. Nítorí náà, jọ́sìn fún Allāhu lẹ́ni tí yóò máa fi àfọ̀mọ́-ọkàn (àníyàn mímọ́) ṣe ẹ̀sìn fún Un.

Ayah  39:3  الأية
أَلَا لِلَّهِ الدِّينُ الْخَالِصُ ۚ وَالَّذِينَ اتَّخَذُوا مِن دُونِهِ أَوْلِيَاءَ مَا نَعْبُدُهُمْ إِلَّا لِيُقَرِّبُونَا إِلَى اللهِ زُلْفَىٰ إِنَّ اللهَ يَحْكُمُ بَيْنَهُمْ فِي مَا هُمْ فِيهِ يَخْتَلِفُونَ ۗ إِنَّ اللهَ لَا يَهْدِي مَنْ هُوَ كَاذِبٌ كَفَّارٌ
Ala lillahi addeenualkhalisu wallatheena ittakhathoomin doonihi awliyaa ma naAAbuduhum illaliyuqarriboona ila Allahi zulfa innaAllaha yahkumu baynahum fee ma hum feehiyakhtalifoona inna Allaha la yahdee man huwa kathibunkaffar

Yoruba
 
Gbọ́! Ti Allāhu ni ẹ̀sìn mímọ́. Àwọn tí wọ́n sì mú àwọn aláfẹ̀yìntì kan yàtọ̀ sí Allāhu, (wọ́n wí pé): "A kò jọ́sìn fún wọn bí kò ṣe pé, nítorí kí wọ́n lè mú wa súnmọ́ Allāhu pẹ́kípẹ́kí ni." Dájúdájú Allāhu l'Ó máa dájọ́ láààrin wọn nípa ohun tí wọ́n ń yapa-ẹnu nípa rẹ̀ (ìyẹn, ẹ̀sìn 'Islām). Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ẹni tí ó jẹ́ òpùrọ́, aláìgbàgbọ́.

Ayah  39:4  الأية
لَّوْ أَرَادَ اللهُ أَن يَتَّخِذَ وَلَدًا لَّاصْطَفَىٰ مِمَّا يَخْلُقُ مَا يَشَاءُ ۚ سُبْحَانَهُ ۖ هُوَ اللهُ الْوَاحِدُ الْقَهَّارُ
Law arada Allahu an yattakhithawaladan lastafa mimma yakhluqu mayashao subhanahu huwa Allahu alwahidualqahhar

Yoruba
 
Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́ fi ẹnì kan ṣe ọmọ ni, ìbá ṣẹ̀ṣà ohun tí Ó bá fẹ́ (fi ṣọmọ) nínú n̄ǹkan tí Ó dá. Mímọ́ ni fún Un (níbi èyí). Òun ni Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí.

Ayah  39:5  الأية
خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ بِالْحَقِّ ۖ يُكَوِّرُ اللَّيْلَ عَلَى النَّهَارِ وَيُكَوِّرُ النَّهَارَ عَلَى اللَّيْلِ ۖ وَسَخَّرَ الشَّمْسَ وَالْقَمَرَ ۖ كُلٌّ يَجْرِي لِأَجَلٍ مُّسَمًّى ۗ أَلَا هُوَ الْعَزِيزُ الْغَفَّارُ
Khalaqa assamawati wal-ardabilhaqqi yukawwiru allayla AAala annahariwayukawwiru annahara AAala allayliwasakhkhara ashshamsa walqamara kullun yajreeli-ajalin musamman ala huwa alAAazeezu alghaffar

Yoruba
 
Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Ó ń ti òru bọnú ọ̀sán. Ó sì ń ti ọ̀sán bọnú òru. Ó sì rọ òòrùn àti òṣùpá; ìkọ̀ọ̀kan wọn máa rìn fún gbèdéke àkókò kan. Gbọ́! Òun ni Alágbára, Aláforíjìn.

Ayah  39:6  الأية
خَلَقَكُم مِّن نَّفْسٍ وَاحِدَةٍ ثُمَّ جَعَلَ مِنْهَا زَوْجَهَا وَأَنزَلَ لَكُم مِّنَ الْأَنْعَامِ ثَمَانِيَةَ أَزْوَاجٍ ۚ يَخْلُقُكُمْ فِي بُطُونِ أُمَّهَاتِكُمْ خَلْقًا مِّن بَعْدِ خَلْقٍ فِي ظُلُمَاتٍ ثَلَاثٍ ۚ ذَٰلِكُمُ اللهُ رَبُّكُمْ لَهُ الْمُلْكُ ۖ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ۖ فَأَنَّىٰ تُصْرَفُونَ
Khalaqakum min nafsin wahidatin thummajaAAala minha zawjaha waanzala lakum mina al-anAAamithamaniyata azwajin yakhluqukum fee butooniommahatikum khalqan min baAAdi khalqin fee thulumatinthalathin thalikumu Allahu rabbukum lahualmulku la ilaha illa huwa faanna tusrafoon

Yoruba
 
Ó ṣẹ̀dá yín láti ara ẹ̀mí ẹyọ kan. Lẹ́yìn náà, Ó dá ìyàwó rẹ̀ láti ara rẹ̀. Ó sì sọ mẹ́jọ kalẹ̀ fún yín nínú ẹran-ọ̀sìn ní takọ- tabo. Ó ń ṣẹ̀dá yín sínú ìyá yín, ẹ̀dá kan lẹ́yìn ẹ̀dá kan nínú àwọn òkùnkùn mẹ́ta. Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín. TiRẹ̀ ni ìjọba. Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ yín lórí kúrò níbi òdodo?

Ayah  39:7  الأية
إِن تَكْفُرُوا فَإِنَّ اللهَ غَنِيٌّ عَنكُمْ ۖ وَلَا يَرْضَىٰ لِعِبَادِهِ الْكُفْرَ ۖ وَإِن تَشْكُرُوا يَرْضَهُ لَكُمْ ۗ وَلَا تَزِرُ وَازِرَةٌ وِزْرَ أُخْرَىٰ ۗ ثُمَّ إِلَىٰ رَبِّكُم مَّرْجِعُكُمْ فَيُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ ۚ إِنَّهُ عَلِيمٌ بِذَاتِ الصُّدُورِ
In takfuroo fa-inna Allaha ghaniyyunAAankum wala yarda liAAibadihi alkufra wa-intashkuroo yardahu lakum wala taziru waziratunwizra okhra thumma ila rabbikum marjiAAukumfayunabbi-okum bima kuntum taAAmaloona innahu AAaleemun bithatiassudoor

Yoruba
 
Tí ẹ bá ṣàì moore, dájúdájú Allāhu rọrọ̀ láì sí ẹ̀yin (kò sì ní bùkátà si yín). Kò sì yọ́nú sí àìmoore fún àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Tí ẹ bá dúpẹ́, Ó máa yọ́nú sí i fún yín. Ẹlẹ́rù-ẹ̀ṣẹ̀ kan kò sì níí ru ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíìràn. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Olúwa yín ni ibùpadàsí yín. Ó sì máa fún yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́. Dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà ẹ̀dá.

Ayah  39:8  الأية
وَإِذَا مَسَّ الْإِنسَانَ ضُرٌّ دَعَا رَبَّهُ مُنِيبًا إِلَيْهِ ثُمَّ إِذَا خَوَّلَهُ نِعْمَةً مِّنْهُ نَسِيَ مَا كَانَ يَدْعُو إِلَيْهِ مِن قَبْلُ وَجَعَلَ لِلَّهِ أَندَادًا لِّيُضِلَّ عَن سَبِيلِهِ ۚ قُلْ تَمَتَّعْ بِكُفْرِكَ قَلِيلًا ۖ إِنَّكَ مِنْ أَصْحَابِ النَّارِ
Wa-itha massa al-insana durrundaAAa rabbahu muneeban ilayhi thumma ithakhawwalahu niAAmatan minhu nasiya ma kana yadAAooilayhi min qablu wajaAAala lillahi andadan liyudillaAAan sabeelihi qul tamattaAA bikufrika qaleelan innaka min as-habiannar

Yoruba
 
Nígbà tí ìnira kan bá fọwọ́ ba ènìyàn, ó máa pe Olúwa rẹ̀ lẹ́ni tí ó ń ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà tí Ó bá fún un ní ìdẹ̀ra kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀, ó máa gbàgbé ohun tó ṣe ní àdúà sí (Olúwa rẹ) ṣíwájú. Ó sì máa sọ (àwọn ẹ̀dá kan) di akẹgbẹ́ fún Allāhu nítorí kí ó lè kó ìṣìnà bá (ẹlòmíìràn) ní ojú ọ̀nà ẹ̀sìn Rẹ̀ ('Islām). Sọ pé: "Fi àìgbàgbọ́ rẹ jẹ̀gbádùn ayé fún ìgbà díẹ̀. Dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn èrò inú Iná."

Ayah  39:9  الأية
أَمَّنْ هُوَ قَانِتٌ آنَاءَ اللَّيْلِ سَاجِدًا وَقَائِمًا يَحْذَرُ الْآخِرَةَ وَيَرْجُو رَحْمَةَ رَبِّهِ ۗ قُلْ هَلْ يَسْتَوِي الَّذِينَ يَعْلَمُونَ وَالَّذِينَ لَا يَعْلَمُونَ ۗ إِنَّمَا يَتَذَكَّرُ أُولُو الْأَلْبَابِ
Amman huwa qanitun anaaallayli sajidan waqa-iman yahtharu al-akhiratawayarjoo rahmata rabbihi qul hal yastawee allatheenayaAAlamoona wallatheena la yaAAlamoonainnama yatathakkaru oloo al-albab

Yoruba
 
Ǹjẹ́ ẹni tí ó jẹ́ olùtẹ̀lé ti Allāhu (tó jẹ́) olùforíkanlẹ̀ àti olùdìdedúró (lórí ìrun kíkí) ní àwọn àkókò alẹ́, tó ń ṣọ́ra fún ọ̀run, tó sì ń ní àgbẹ́kẹ̀lé nínú àánú Olúwa rẹ̀ (dà bí ẹlẹ́ṣẹ̀ bí?) Sọ pé: "Ǹjẹ́ àwọn tí wọ́n nímọ̀ àti àwọn tí kò nímọ̀ dọ́gba bí? Àwọn onílàákàyè nìkan l'ó ń lo ìrántí.

Ayah  39:10  الأية
قُلْ يَا عِبَادِ الَّذِينَ آمَنُوا اتَّقُوا رَبَّكُمْ ۚ لِلَّذِينَ أَحْسَنُوا فِي هَٰذِهِ الدُّنْيَا حَسَنَةٌ ۗ وَأَرْضُ اللهِ وَاسِعَةٌ ۗ إِنَّمَا يُوَفَّى الصَّابِرُونَ أَجْرَهُم بِغَيْرِ حِسَابٍ
Qul ya AAibadi allatheenaamanoo ittaqoo rabbakum lillatheena ahsanoofee hathihi addunya hasanatun waarduAllahi wasiAAatun innama yuwaffa assabiroonaajrahum bighayri hisab

Yoruba
 
Sọ pé: "Ẹ̀yin ẹrúsìn Mi tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Olúwa yín. Ẹ̀san rere wà fún àwọn tó ṣe rere ní ilé ayé yìí. Ilẹ̀ Allāhu sì gbòòrò. Àwọn onísùúrù ni Wọ́n sì máa fún ní ẹ̀san (rere iṣẹ́) wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ láì níí ní ìṣírò."

Ayah  39:11  الأية
قُلْ إِنِّي أُمِرْتُ أَنْ أَعْبُدَ اللهَ مُخْلِصًا لَّهُ الدِّينَ
Qul innee omirtu an aAAbuda Allahamukhlisan lahu addeen

Yoruba
 
Sọ pé: "Dájúdájú Wọ́n pa mí ní àṣẹ pé kí n̄g jọ́sìn fún Allāhu lẹ́ni tí yóò máa fi àfọ̀mọ́-ọkàn (àníyàn mímọ́) ṣe ẹ̀sìn fún Un.

Ayah  39:12  الأية
وَأُمِرْتُ لِأَنْ أَكُونَ أَوَّلَ الْمُسْلِمِينَ
Waomirtu li-an akoona awwala almuslimeen

Yoruba
 
Wọ́n tún pa mí ní àṣẹ pé kí èmi jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ (nínú) àwọn mùsùlùmí (ní àsìkò tèmi)."

Ayah  39:13  الأية
قُلْ إِنِّي أَخَافُ إِنْ عَصَيْتُ رَبِّي عَذَابَ يَوْمٍ عَظِيمٍ
Qul innee akhafu in AAasayturabbee AAathaba yawmin AAatheem

Yoruba
 
Sọ pé: "Dájúdájú èmi ń páyà ìyà ọjọ́ ńlá, tí mo bá fi lè yapa àṣẹ Olúwa mi."

Ayah  39:14  الأية
قُلِ اللهَ أَعْبُدُ مُخْلِصًا لَّهُ دِينِي
Quli Allaha aAAbudu mukhlisanlahu deenee

Yoruba
 
Sọ pé: "Allāhu ni èmi yóò máa jọ́sìn fún lẹ́ni tí èmi yóò máa fi àfọ̀mọ́-ọkàn (àníyàn mímọ́) ṣe ẹ̀sìn mi fún Un

Ayah  39:15  الأية
فَاعْبُدُوا مَا شِئْتُم مِّن دُونِهِ ۗ قُلْ إِنَّ الْخَاسِرِينَ الَّذِينَ خَسِرُوا أَنفُسَهُمْ وَأَهْلِيهِمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ ۗ أَلَا ذَٰلِكَ هُوَ الْخُسْرَانُ الْمُبِينُ
FaAAbudoo ma shi/tum mindoonihi qul inna alkhasireena allatheena khasirooanfusahum waahleehim yawma alqiyamati ala thalikahuwa alkhusranu almubeen

Yoruba
 
Ẹ̀yin ẹ jọ́sìn fún ohun tí ẹ bá fẹ́ lẹ́yìn Rẹ̀." Sọ pé: "Dájúdájú àwọn ẹni òfò ni àwọn tó ṣe ẹ̀mí ara wọn àti ará ilé wọn ní òfò ní Ọjọ́ Àjíǹde. Gbọ́! Ìyẹn, òhun ni òfò pọ́nńbélé."

Ayah  39:16  الأية
لَهُم مِّن فَوْقِهِمْ ظُلَلٌ مِّنَ النَّارِ وَمِن تَحْتِهِمْ ظُلَلٌ ۚ ذَٰلِكَ يُخَوِّفُ اللهُ بِهِ عِبَادَهُ ۚ يَا عِبَادِ فَاتَّقُونِ
Lahum min fawqihim thulalunmina annari wamin tahtihim thulalunthalika yukhawwifu Allahu bihi AAibadahu yaAAibadi fattaqoon

Yoruba
 
Àwọn àjà Iná máa wà ní òkè wọn. Àwọn àjà yó sì wà ní ìsàlẹ̀ wọn. Ìyẹn ni Allāhu fi ń dẹ́rù ba àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ (báyìí pé:) "Ẹ̀yin ẹrúsìn Mi, ẹ bẹ̀rù Mi."

Ayah  39:17  الأية
وَالَّذِينَ اجْتَنَبُوا الطَّاغُوتَ أَن يَعْبُدُوهَا وَأَنَابُوا إِلَى اللهِ لَهُمُ الْبُشْرَىٰ ۚ فَبَشِّرْ عِبَادِ
Wallatheena ijtanaboo attaghootaan yaAAbudooha waanaboo ila Allahilahumu albushra fabashshir AAibad

Yoruba
 
Àwọn tí wọ́n takété sí àwọn òrìṣà tí wọn kò jọ́sìn fún un, wọ́n sì ṣẹ́rí padà sí (jíjọ́sìn fún) Allāhu, ìró ìdùnnú ń bẹ fún wọn. Nítorí náà, fún àwọn ẹrúsìn Mi ní ìró ìdùnnú.

Ayah  39:18  الأية
الَّذِينَ يَسْتَمِعُونَ الْقَوْلَ فَيَتَّبِعُونَ أَحْسَنَهُ ۚ أُولَٰئِكَ الَّذِينَ هَدَاهُمُ اللهُ ۖ وَأُولَٰئِكَ هُمْ أُولُو الْأَلْبَابِ
Allatheena yastamiAAoona alqawlafayattabiAAoona ahsanahu ola-ika allatheenahadahumu Allahu waola-ika hum oloo al-albab

Yoruba
 
Àwọn tó ń tẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń tẹ̀lé èyí tó dára jùlọ nínú rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu fi mọ̀nà. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni onílàákàyè.

Ayah  39:19  الأية
أَفَمَنْ حَقَّ عَلَيْهِ كَلِمَةُ الْعَذَابِ أَفَأَنتَ تُنقِذُ مَن فِي النَّارِ
Afaman haqqa AAalayhi kalimatu alAAathabiafaanta tunqithu man fee annar

Yoruba
 
Ṣé ẹni tí ọ̀rọ̀ ìyà Iná ti kòlé lórí (nípa àìgbàgbọ́ rẹ̀, ṣé kò níí wọná ni?) Ṣé ìwọ l'ó máa la ẹni tó wà nínú Iná (nípasẹ̀ àìgbàgbọ́ rẹ̀) ni?

Ayah  39:20  الأية
لَٰكِنِ الَّذِينَ اتَّقَوْا رَبَّهُمْ لَهُمْ غُرَفٌ مِّن فَوْقِهَا غُرَفٌ مَّبْنِيَّةٌ تَجْرِي مِن تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ ۖ وَعْدَ اللهِ ۖ لَا يُخْلِفُ اللهُ الْمِيعَادَ
Lakini allatheena ittaqawrabbahum lahum ghurafun min fawqiha ghurafun mabniyyatuntajree min tahtiha al-anharu waAAda Allahila yukhlifu Allahu almeeAAad

Yoruba
 
Ṣùgbọ́n àwọn tó bẹ̀rù Olúwa wọn, tiwọn ni àwọn ilé gíga, tí àwọn ilé gíga tún wà lókè rẹ̀, àwọn odò yó sì máa ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Àdéhùn Allāhu ni (èyí). Allāhu kò sì níí yẹ àdéhùn náà.

Ayah  39:21  الأية
أَلَمْ تَرَ أَنَّ اللهَ أَنزَلَ مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَسَلَكَهُ يَنَابِيعَ فِي الْأَرْضِ ثُمَّ يُخْرِجُ بِهِ زَرْعًا مُّخْتَلِفًا أَلْوَانُهُ ثُمَّ يَهِيجُ فَتَرَاهُ مُصْفَرًّا ثُمَّ يَجْعَلُهُ حُطَامًا ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَذِكْرَىٰ لِأُولِي الْأَلْبَابِ
Alam tara anna Allaha anzala mina assama-imaan fasalakahu yanabeeAAa fee al-ardithumma yukhriju bihi zarAAan mukhtalifan alwanuhu thummayaheeju fatarahu musfarran thumma yajAAaluhu hutamaninna fee thalika lathikra li-olee al-albab

Yoruba
 
Ṣé o kò wòye pé dájúdájú Allāhu l'Ó sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀, Ó sì mú omi náà wọnú àwọn omi ìṣẹ́lẹ̀rú nínú ilẹ̀, lẹ́yìn náà, Ó ń fi mú irúgbìn tí àwọ̀ wọn yàtọ̀ síra wọn jáde, lẹ́yìn náà, (irúgbìn náà) yóò gbẹ, o sì máa rí i ní pípọ́n, lẹ́yìn náà, Ó máa sọ ọ́ di rírún? Dájúdájú ìrántí wà nínú ìyẹn fún àwọn onílàákàyè.

Ayah  39:22  الأية
أَفَمَن شَرَحَ اللهُ صَدْرَهُ لِلْإِسْلَامِ فَهُوَ عَلَىٰ نُورٍ مِّن رَّبِّهِ ۚ فَوَيْلٌ لِّلْقَاسِيَةِ قُلُوبُهُم مِّن ذِكْرِ اللهِ ۚ أُولَٰئِكَ فِي ضَلَالٍ مُّبِينٍ
Afaman sharaha Allahu sadrahulil-islami fahuwa AAala noorin min rabbihi fawaylunlilqasiyati quloobuhum min thikri Allahi ola-ikafee dalalin mubeen

Yoruba
 
Ǹjẹ́ ẹni tí Allāhu gba ọkàn rẹ̀ láàyè fún ẹ̀sìn 'Islām, tí ó sì wà nínú ìmọ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ (dà bí aláìgbàgbọ́ bí)? Ègbé ni fún àwọn tí ọkàn wọn le sí ìrántí Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.

Ayah  39:23  الأية
اللهُ نَزَّلَ أَحْسَنَ الْحَدِيثِ كِتَابًا مُّتَشَابِهًا مَّثَانِيَ تَقْشَعِرُّ مِنْهُ جُلُودُ الَّذِينَ يَخْشَوْنَ رَبَّهُمْ ثُمَّ تَلِينُ جُلُودُهُمْ وَقُلُوبُهُمْ إِلَىٰ ذِكْرِ اللهِ ۚ ذَٰلِكَ هُدَى اللهِ يَهْدِي بِهِ مَن يَشَاءُ ۚ وَمَن يُضْلِلِ اللهُ فَمَا لَهُ مِنْ هَادٍ
Allahu nazzala ahsana alhadeethikitaban mutashabihan mathaniya taqshaAAirruminhu juloodu allatheena yakhshawna rabbahum thummataleenu julooduhum waquloobuhum ila thikri Allahithalika huda Allahi yahdee bihi man yashaowaman yudlili Allahu fama lahu min had

Yoruba
 
Allāhu l'Ó sọ ọ̀rọ̀ tó dára jùlọ kalẹ̀, (ó jẹ́) Tírà, tí (àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀) jọra wọn ní ọ̀rọ̀ àsọtúnsọ, tí awọ ara àwọn tó ń páyà Olúwa wọn yó sì máa wárìrì nítorí rẹ̀. Lẹ́yìn náà, awọ ara wọn àti ọkàn wọn yóò máa rọ̀ níbi ìrántí Allāhu. Ìyẹn ni ìmọ̀nà Allāhu. Ó sì ń fi ṣe ìmọ̀nà fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ẹni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, kò sí níí sí afinimọ̀nà kan fún un.

Ayah  39:24  الأية
أَفَمَن يَتَّقِي بِوَجْهِهِ سُوءَ الْعَذَابِ يَوْمَ الْقِيَامَةِ ۚ وَقِيلَ لِلظَّالِمِينَ ذُوقُوا مَا كُنتُمْ تَكْسِبُونَ
Afaman yattaqee biwajhihi soo-a alAAathabiyawma alqiyamati waqeela liththalimeenathooqoo ma kuntum taksiboon

Yoruba
 
Ǹjẹ́ ẹni tí ó máa fojú ara rẹ̀ ko aburú ìyà Iná ní Ọjọ́ Àjíǹde (dà bí ẹni tí ó máa wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra wọ́ọ́rọ́wọ́)? Wọn yó sì sọ fún àwọn alábòsí pé: "Ẹ tọ́ ìyà ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ wò."

Ayah  39:25  الأية
كَذَّبَ الَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ فَأَتَاهُمُ الْعَذَابُ مِنْ حَيْثُ لَا يَشْعُرُونَ
Kaththaba allatheena minqablihim faatahumu alAAathabu min haythu layashAAuroon

Yoruba
 
Àwọn tó ṣíwájú wọn pe òdodo ní irọ́. Nítorí náà, ìyà dé bá wọn ní àyè tí wọn kò ti fura.

Ayah  39:26  الأية
فَأَذَاقَهُمُ اللهُ الْخِزْيَ فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا ۖ وَلَعَذَابُ الْآخِرَةِ أَكْبَرُ ۚ لَوْ كَانُوا يَعْلَمُونَ
Faathaqahumu Allahu alkhizyafee alhayati addunya walaAAathabual-akhirati akbaru law kanoo yaAAlamoon

Yoruba
 
Allāhu fún wọn ní àbùkù ìyà tọ́ wò nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí. Ìyà ọ̀run sì tóbi jùlọ tí ó bá jẹ́ pé wọ́n mọ̀.

Ayah  39:27  الأية
وَلَقَدْ ضَرَبْنَا لِلنَّاسِ فِي هَٰذَا الْقُرْآنِ مِن كُلِّ مَثَلٍ لَّعَلَّهُمْ يَتَذَكَّرُونَ
Walaqad darabna linnasifee hatha alqur-ani min kulli mathalin laAAallahumyatathakkaroon

Yoruba
 
A sì ti ṣe gbogbo àkàwé (àpèjúwe àti àpẹ̀ẹrẹ) fún àwọn ènìyàn nínú al-Ƙur'ān yìí nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí

Ayah  39:28  الأية
قُرْآنًا عَرَبِيًّا غَيْرَ ذِي عِوَجٍ لَّعَلَّهُمْ يَتَّقُونَ
Qur-anan AAarabiyyan ghayra theeAAiwajin laAAallahum yattaqoon

Yoruba
 
Al-Ƙur'ān (tí A sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú) èdè Lárúbáwá, èyí tí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ kò dojú rú nítorí kí wọ́n lè bẹ̀rù (Allāhu).

Ayah  39:29  الأية
ضَرَبَ اللهُ مَثَلًا رَّجُلًا فِيهِ شُرَكَاءُ مُتَشَاكِسُونَ وَرَجُلًا سَلَمًا لِّرَجُلٍ هَلْ يَسْتَوِيَانِ مَثَلًا ۚ الْحَمْدُ لِلَّهِ ۚ بَلْ أَكْثَرُهُمْ لَا يَعْلَمُونَ
Daraba Allahu mathalan rajulanfeehi shurakao mutashakisoona warajulan salamanlirajulin hal yastawiyani mathalan alhamdu lillahibal aktharuhum la yaAAlamoon

Yoruba
 
Allāhu fi àkàwé kan lélẹ̀; ẹrúkùnrin kan tó wà lábẹ́ àṣẹ ọ̀gá púpọ̀ tí wọ́n ń ṣe ìfàn̄fà lórí rẹ̀ (kò sì mọ ta ni ó máa dá lóhùn nínú àwọn ọ̀gá rẹ̀) àti (àkàwé) ẹrúkùnrin kan tó dá wà gédégbé lábẹ́ ọ̀gákùnrin kan. Ǹjẹ́ àwọn (ẹrú) méjèèjì dọ́gba ní àkàwé bí? Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.

Ayah  39:30  الأية
إِنَّكَ مَيِّتٌ وَإِنَّهُم مَّيِّتُونَ
Innaka mayyitun wa-innahum mayyitoon

Yoruba
 
Dájúdájú ìwọ máa kú. Dájúdájú àwọn náà máa kú.

Ayah  39:31  الأية
ثُمَّ إِنَّكُمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ عِندَ رَبِّكُمْ تَخْتَصِمُونَ
Thumma innakum yawma alqiyamatiAAinda rabbikum takhtasimoon

Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, ní Ọjọ́ Àjíǹde dájúdájú ẹ̀yin yóò máa bá ara yín ṣe àríyànjiyàn ní ọ̀dọ̀ Olúwa yín.

Ayah  39:32  الأية
فَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّن كَذَبَ عَلَى اللهِ وَكَذَّبَ بِالصِّدْقِ إِذْ جَاءَهُ ۚ أَلَيْسَ فِي جَهَنَّمَ مَثْوًى لِّلْكَافِرِينَ
Faman athlamu mimman kathabaAAala Allahi wakaththaba bissidqiith jaahu alaysa fee jahannama mathwan lilkafireen

Yoruba
 
Nítorí náà, ta l'ó ṣàbòsí ju ẹni tó parọ́ mọ́ Allāhu, tó tún pe òdodo ní irọ́ nígbà tí ó dé bá a? Ṣé kì í ṣe Iná ni ibùgbé fún àwọn aláìgbàgbọ́ ni?

Ayah  39:33  الأية
وَالَّذِي جَاءَ بِالصِّدْقِ وَصَدَّقَ بِهِ ۙ أُولَٰئِكَ هُمُ الْمُتَّقُونَ
Wallathee jaa bissidqiwasaddaqa bihi ola-ika humu almuttaqoon

Yoruba
 
Ẹni tí ó sì mú òdodo wá (ìyẹn, Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) àti (àwọn) ẹni tó jẹ́rìí sí òdodo náà; àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni olùbẹ̀rù (Allāhu).

Ayah  39:34  الأية
لَهُم مَّا يَشَاءُونَ عِندَ رَبِّهِمْ ۚ ذَٰلِكَ جَزَاءُ الْمُحْسِنِينَ
Lahum ma yashaoona AAindarabbihim thalika jazao almuhsineen

Yoruba
 
Ohunkóhun tí wọ́n bá ń fẹ́ wà fún wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Ìyẹn sì ni ẹ̀san àwọn ẹni rere

Ayah  39:35  الأية
لِيُكَفِّرَ اللهُ عَنْهُمْ أَسْوَأَ الَّذِي عَمِلُوا وَيَجْزِيَهُمْ أَجْرَهُم بِأَحْسَنِ الَّذِي كَانُوا يَعْمَلُونَ
Liyukaffira Allahu AAanhum aswaa allatheeAAamiloo wayajziyahum ajrahum bi-ahsani allathee kanooyaAAmaloon

Yoruba
 
Nítorí kí Allāhu lè bá wọn pa aburú tí wọ́n ṣe níṣẹ́ rẹ́ àti (nítorí) kí Ó lè fi èyí tó dára ju ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ san wọ́n ní ẹ̀san wọn.

Ayah  39:36  الأية
أَلَيْسَ اللهُ بِكَافٍ عَبْدَهُ ۖ وَيُخَوِّفُونَكَ بِالَّذِينَ مِن دُونِهِ ۚ وَمَن يُضْلِلِ اللهُ فَمَا لَهُ مِنْ هَادٍ
Alaysa Allahu bikafin AAabdahuwayukhawwifoonaka billatheena min doonihi waman yudliliAllahu fama lahu min had

Yoruba
 
Ṣé Allāhu kò tó fún ẹrúsìn Rẹ̀ ni? Wọ́n sì ń fi àwọn ẹlòmíìràn lẹ́yìn Rẹ̀ dẹ́rù bà ọ́! Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, kò lè sí afinimọ̀nà kan fún un.

Ayah  39:37  الأية
وَمَن يَهْدِ اللهُ فَمَا لَهُ مِن مُّضِلٍّ ۗ أَلَيْسَ اللهُ بِعَزِيزٍ ذِي انتِقَامٍ
Waman yahdi Allahu fama lahumin mudillin alaysa Allahu biAAazeezin theeintiqam

Yoruba
 
Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fi mọ̀nà ('Islām), kò lè sí aṣinilọ́nà fún un. Ṣé Allāhu kọ́ ni Alágbára, Olùgba-ẹ̀san?

Ayah  39:38  الأية
وَلَئِن سَأَلْتَهُم مَّنْ خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ لَيَقُولُنَّ اللهُ ۚ قُلْ أَفَرَأَيْتُم مَّا تَدْعُونَ مِن دُونِ اللهِ إِنْ أَرَادَنِيَ اللهُ بِضُرٍّ هَلْ هُنَّ كَاشِفَاتُ ضُرِّهِ أَوْ أَرَادَنِي بِرَحْمَةٍ هَلْ هُنَّ مُمْسِكَاتُ رَحْمَتِهِ ۚ قُلْ حَسْبِيَ اللهُ ۖ عَلَيْهِ يَتَوَكَّلُ الْمُتَوَكِّلُونَ
Wala-in saaltahum man khalaqa assamawatiwal-arda layaqoolunna Allahu qul afaraaytumma tadAAoona min dooni Allahi in aradaniyaAllahu bidurrin hal hunna kashifatu durrihiaw aradanee birahmatin hal hunna mumsikaturahmatihi qul hasbiya Allahu AAalayhiyatawakkalu almutawakkiloon

Yoruba
 
Dájúdájú tí o bá bi wọ́n léèrè pé: "Ta ni Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀?", dájúdájú wọ́n á wí pé: "Allāhu ni." Sọ pé: "Ẹ sọ fún mi nípa àwọn n̄ǹkan tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu, tí Allāhu bá gbèrò ìnira kan rò mí, ǹjẹ́ wọ́n lè mú ìnira Rẹ̀ kúrò fún mi? Tàbí tí Ó bá gbèrò ìkẹ́ kan sí mi, ǹjẹ́ wọ́n lè dá ìkẹ́ Rẹ̀ dúró bí?" Sọ pé: "Allāhu tó fún mi. Òun sì ni àwọn olùgbáralé ń gbáralé."

Ayah  39:39  الأية
قُلْ يَا قَوْمِ اعْمَلُوا عَلَىٰ مَكَانَتِكُمْ إِنِّي عَامِلٌ ۖ فَسَوْفَ تَعْلَمُونَ
Qul ya qawmi iAAmaloo AAalamakanatikum innee AAamilun fasawfa taAAlamoon

Yoruba
 
Sọ pé: "Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ ṣe tiyín ní àyè yín. Èmi náà ń ṣe tèmi. Nítorí náà, láìpẹ́ ẹ máa mọ

Ayah  39:40  الأية
مَن يَأْتِيهِ عَذَابٌ يُخْزِيهِ وَيَحِلُّ عَلَيْهِ عَذَابٌ مُّقِيمٌ
Man ya/teehi AAathabun yukhzeehi wayahilluAAalayhi AAathabun muqeem

Yoruba
 
ẹni tí ìyà tí ó máa yẹpẹrẹ rẹ̀ máa dé bá, tí ìyà gbere sì máa kò lé lórí."

Ayah  39:41  الأية
إِنَّا أَنزَلْنَا عَلَيْكَ الْكِتَابَ لِلنَّاسِ بِالْحَقِّ ۖ فَمَنِ اهْتَدَىٰ فَلِنَفْسِهِ ۖ وَمَن ضَلَّ فَإِنَّمَا يَضِلُّ عَلَيْهَا ۖ وَمَا أَنتَ عَلَيْهِم بِوَكِيلٍ
Inna anzalna AAalayka alkitabalinnasi bilhaqqi famani ihtadafalinafsihi waman dalla fa-innama yadilluAAalayha wama anta AAalayhim biwakeel

Yoruba
 
Dájúdájú Àwa sọ Tírà kalẹ̀ fún ọ pẹ̀lú òdodo (kí o lè fi ṣe ìrántí) fún àwọn ènìyàn. Nítorí náà, ẹni tí ó bá mọ̀nà, ó mọ̀nà fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹni tí ó bá sì ṣìnà, ó ṣìnà fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ìwọ sì kọ́ ni olùṣọ́ lórí wọn.

Ayah  39:42  الأية
اللهُ يَتَوَفَّى الْأَنفُسَ حِينَ مَوْتِهَا وَالَّتِي لَمْ تَمُتْ فِي مَنَامِهَا ۖ فَيُمْسِكُ الَّتِي قَضَىٰ عَلَيْهَا الْمَوْتَ وَيُرْسِلُ الْأُخْرَىٰ إِلَىٰ أَجَلٍ مُّسَمًّى ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِّقَوْمٍ يَتَفَكَّرُونَ
Allahu yatawaffa al-anfusa heenamawtiha wallatee lam tamut fee manamihafayumsiku allatee qada AAalayha almawta wayursilual-okhra ila ajalin musamman inna fee thalikalaayatin liqawmin yatafakkaroon

Yoruba
 
Allāhu l'Ó ń gba àwọn ẹ̀mí ní àkókò ikú wọn àti (àwọn ẹ̀mí) tí kò kú sójú oorun wọn. Ó ń mú (àwọn ẹ̀mí) tí Ó ti pèbùbù ikú lé lórí mọ́lẹ̀. Ó sì ń fi àwọn yòókù sílẹ̀ títí di gbèdéke àkókò kan. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ní àròjinlẹ̀.

Ayah  39:43  الأية
أَمِ اتَّخَذُوا مِن دُونِ اللهِ شُفَعَاءَ ۚ قُلْ أَوَلَوْ كَانُوا لَا يَمْلِكُونَ شَيْئًا وَلَا يَعْقِلُونَ
Ami ittakhathoo min dooni AllahishufaAAaa qul awa law kanoo la yamlikoonashay-an wala yaAAqiloon

Yoruba
 
Tàbí wọ́n mú àwọn olùṣìpẹ̀ mìíràn lẹ́yìn Allāhu ni? Sọ pé: "(Wọ́n mú wọn ní olùṣìpẹ̀) tó sì jẹ́ pé wọn kò ní agbára kan kan, wọn kò sì níí làákàyè!"

Ayah  39:44  الأية
قُل لِّلَّهِ الشَّفَاعَةُ جَمِيعًا ۖ لَّهُ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ ثُمَّ إِلَيْهِ تُرْجَعُونَ
Qul lillahi ashshafaAAatujameeAAan lahu mulku assamawati wal-ardithumma ilayhi turjaAAoon

Yoruba
 
Sọ pé: "Ti Allāhu ni gbogbo ìṣìpẹ̀ pátápátá. TiRẹ̀ ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò da yín padà sí."

Ayah  39:45  الأية
وَإِذَا ذُكِرَ اللهُ وَحْدَهُ اشْمَأَزَّتْ قُلُوبُ الَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِالْآخِرَةِ ۖ وَإِذَا ذُكِرَ الَّذِينَ مِن دُونِهِ إِذَا هُمْ يَسْتَبْشِرُونَ
Wa-itha thukira Allahuwahdahu ishmaazzat quloobu allatheena layu/minoona bil-akhirati wa-itha thukiraallatheena min doonihi itha hum yastabshiroon

Yoruba
 
Nígbà tí wọ́n bá dárúkọ Allāhu nìkan ṣoṣo, ọkàn àwọn tí kò gbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn máa sá kúrò (níbi mímú Allāhu ní ọ̀kan ṣoṣo). Nígbà tí wọ́n bá sì dárúkọ àwọn mìíràn (tí wọ́n ń jọ́sìn fún) lẹ́yìn Rẹ̀, nígbà náà ni wọn yóò máa dunnú.

Ayah  39:46  الأية
قُلِ اللهُمَّ فَاطِرَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ عَالِمَ الْغَيْبِ وَالشَّهَادَةِ أَنتَ تَحْكُمُ بَيْنَ عِبَادِكَ فِي مَا كَانُوا فِيهِ يَخْتَلِفُونَ
Quli allahumma fatira assamawatiwal-ardi AAalima alghaybi washshahadatianta tahkumu bayna AAibadika fee ma kanoofeehi yakhtalifoon

Yoruba
 
Sọ pé: "Allāhu, Olúpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba, Ìwọ l'O máa dájọ́ láààrin àwọn ẹrúsìn Rẹ nípa ohun tí wọ́n ń yapa-ẹnu lórí rẹ̀."

Ayah  39:47  الأية
وَلَوْ أَنَّ لِلَّذِينَ ظَلَمُوا مَا فِي الْأَرْضِ جَمِيعًا وَمِثْلَهُ مَعَهُ لَافْتَدَوْا بِهِ مِن سُوءِ الْعَذَابِ يَوْمَ الْقِيَامَةِ ۚ وَبَدَا لَهُم مِّنَ اللهِ مَا لَمْ يَكُونُوا يَحْتَسِبُونَ
Walaw anna lillatheena thalamooma fee al-ardi jameeAAan wamithlahu maAAahu laftadawbihi min soo-i alAAathabi yawma alqiyamati wabadalahum mina Allahi ma lam yakoonoo yahtasiboon

Yoruba
 
Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú gbogbo n̄ǹkan tí ó wà lórí ilẹ̀ jẹ́ ti àwọn alábòsí àti irú rẹ̀ mìíràn pẹ̀lú rẹ̀ (tún jẹ́ tiwọn ni), wọn ìbá fi ṣèràpadà (fún ẹ̀mí ara wọn) níbi aburú ìyà ní Ọjọ́ Àjíǹde. (Nígbà yẹn) ohun tí wọn kò lérò máa hàn sí wọn ní ọ̀dọ̀ Allāhu;

Ayah  39:48  الأية
وَبَدَا لَهُمْ سَيِّئَاتُ مَا كَسَبُوا وَحَاقَ بِهِم مَّا كَانُوا بِهِ يَسْتَهْزِئُونَ
Wabada lahum sayyi-atu makasaboo wahaqa bihim ma kanoo bihiyastahzi-oon

Yoruba
 
Àwọn aburú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ máa hàn sí wọn. Àti pé ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì máa dìyà tó máa yí wọn po.

Ayah  39:49  الأية
فَإِذَا مَسَّ الْإِنسَانَ ضُرٌّ دَعَانَا ثُمَّ إِذَا خَوَّلْنَاهُ نِعْمَةً مِّنَّا قَالَ إِنَّمَا أُوتِيتُهُ عَلَىٰ عِلْمٍ ۚ بَلْ هِيَ فِتْنَةٌ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَهُمْ لَا يَعْلَمُونَ
Fa-itha massa al-insana durrundaAAana thumma itha khawwalnahuniAAmatan minna qala innama ooteetuhu AAalaAAilmin bal hiya fitnatun walakinna aktharahum layaAAlamoon

Yoruba
 
Nígbà tí ìnira kan ba fọwọ́ ba ènìyàn, ó máa pè Wá. Lẹ́yìn náà, nígbà tí A bá fún un ní ìdẹ̀ra kan láti ọ̀dọ̀ Wa, ó máa wí pé: "Wọ́n fún mi pẹ̀lú ìmọ̀ ni." Kò sì rí bẹ́ẹ̀, àdánwò ni, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.

Ayah  39:50  الأية
قَدْ قَالَهَا الَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ فَمَا أَغْنَىٰ عَنْهُم مَّا كَانُوا يَكْسِبُونَ
Qad qalaha allatheenamin qablihim fama aghna AAanhum ma kanooyaksiboon

Yoruba
 
Àwọn tó ṣíwájú wọn kúkú wí (irú) rẹ̀, ṣùgbọ́n ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀.

Ayah  39:51  الأية
فَأَصَابَهُمْ سَيِّئَاتُ مَا كَسَبُوا ۚ وَالَّذِينَ ظَلَمُوا مِنْ هَٰؤُلَاءِ سَيُصِيبُهُمْ سَيِّئَاتُ مَا كَسَبُوا وَمَا هُم بِمُعْجِزِينَ
Faasabahum sayyi-atu makasaboo wallatheena thalamoo min haola-isayuseebuhum sayyi-atu ma kasaboo wamahum bimuAAjizeen

Yoruba
 
Aburú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ sì bá wọn. Àwọn alábòsí nínú àwọn wọ̀nyí náà, aburú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ yóò bá wọn. Wọn kò sì níí mórí bọ́.

Ayah  39:52  الأية
أَوَلَمْ يَعْلَمُوا أَنَّ اللهَ يَبْسُطُ الرِّزْقَ لِمَن يَشَاءُ وَيَقْدِرُ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِّقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ
Awa lam yaAAlamoo anna Allaha yabsutuarrizqa liman yashao wayaqdiru inna fee thalikalaayatin liqawmin yu/minoon

Yoruba
 
Ṣé wọn kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu l'Ó ń tẹ́ arísìkí sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹlòmíìràn). Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo.

Ayah  39:53  الأية
قُلْ يَا عِبَادِيَ الَّذِينَ أَسْرَفُوا عَلَىٰ أَنفُسِهِمْ لَا تَقْنَطُوا مِن رَّحْمَةِ اللهِ ۚ إِنَّ اللهَ يَغْفِرُ الذُّنُوبَ جَمِيعًا ۚ إِنَّهُ هُوَ الْغَفُورُ الرَّحِيمُ
Qul ya AAibadiya allatheenaasrafoo AAala anfusihim la taqnatoo min rahmatiAllahi inna Allaha yaghfiru aththunoobajameeAAan innahu huwa alghafooru arraheem

Yoruba
 
Sọ pé: "Ẹ̀yin ẹrúsìn Mi, tí ẹ ti dẹ́ṣẹ̀ púpọ̀ sí ẹ̀mí ara yín lọ́rùn, ẹ má ṣe sọ̀rètí nù nípa ìkẹ́ Allāhu. Dájúdájú Allāhu l'Ó ń ṣàforíjìn gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ pátápátá. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

Ayah  39:54  الأية
وَأَنِيبُوا إِلَىٰ رَبِّكُمْ وَأَسْلِمُوا لَهُ مِن قَبْلِ أَن يَأْتِيَكُمُ الْعَذَابُ ثُمَّ لَا تُنصَرُونَ
Waaneeboo ila rabbikum waaslimoo lahumin qabli an ya/tiyakumu alAAathabu thumma la tunsaroon

Yoruba
 
Ẹ ṣẹ́rí padà (ní ti ìronúpìwàdà) sí ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Kí ẹ sì juwọ́-jusẹ̀ sílẹ̀ fún Un ṣíwájú kí ìyà náà tó wá ba yín. (Bí bẹ́ẹ̀ kọ́) lẹ́yìn náà, A kò níí ràn yín lọ́wọ́.

Ayah  39:55  الأية
وَاتَّبِعُوا أَحْسَنَ مَا أُنزِلَ إِلَيْكُم مِّن رَّبِّكُم مِّن قَبْلِ أَن يَأْتِيَكُمُ الْعَذَابُ بَغْتَةً وَأَنتُمْ لَا تَشْعُرُونَ
WattabiAAoo ahsana maonzila ilaykum min rabbikum min qabli an ya/tiyakumu alAAathabubaghtatan waantum la tashAAuroon

Yoruba
 
Kí ẹ sì tẹ̀lé ohun tí ó dára jùlọ tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín ṣíwájú kí ìyà náà tó wá ba yín ní òjijì, nígbà tí ẹ̀yin kò níí fura."

Ayah  39:56  الأية
أَن تَقُولَ نَفْسٌ يَا حَسْرَتَا عَلَىٰ مَا فَرَّطتُ فِي جَنبِ اللهِ وَإِن كُنتُ لَمِنَ السَّاخِرِينَ
An taqoola nafsun ya hasrataAAala ma farrattu fee janbi Allahiwa-in kuntu lamina assakhireen

Yoruba
 
Nítorí kí ẹ̀mí kan má baà wí pé: "Mo ká àbámọ̀ lórí bí mo ṣe jáfara lórí àìtẹ̀lé àṣẹ Allāhu. Àti pé èmi wà nínú àwọn tó ń fi (ọ̀rọ̀ Rẹ̀) ṣe yẹ̀yẹ́."

Ayah  39:57  الأية
أَوْ تَقُولَ لَوْ أَنَّ اللهَ هَدَانِي لَكُنتُ مِنَ الْمُتَّقِينَ
Aw taqoola law anna Allaha hadaneelakuntu mina almuttaqeen

Yoruba
 
Tàbí kí ó má baà wí pé: "Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu fi ọ̀nà mọ̀ mí ni, dájúdájú èmi ìbá wà nínú àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀)."

Ayah  39:58  الأية
أَوْ تَقُولَ حِينَ تَرَى الْعَذَابَ لَوْ أَنَّ لِي كَرَّةً فَأَكُونَ مِنَ الْمُحْسِنِينَ
Aw taqoola heena tara alAAathabalaw anna lee karratan faakoona mina almuhsineen

Yoruba
 
Tàbí nígbà tí ó bá rí Iná kí ó má baà wí pé: "Tí ó bá jẹ́ pé ìpadàsáyé wà fún mi ni, èmi ìbá sì wà nínú àwọn olùṣe-rere."

Ayah  39:59  الأية
بَلَىٰ قَدْ جَاءَتْكَ آيَاتِي فَكَذَّبْتَ بِهَا وَاسْتَكْبَرْتَ وَكُنتَ مِنَ الْكَافِرِينَ
Bala qad jaatka ayateefakaththabta biha wastakbarta wakunta minaalkafireen

Yoruba
 
Bẹ́ẹ̀ ni! Àwọn āyah Mi kúkú ti dé bá ọ. O pè é ní irọ́. O tún ṣègbéraga. O sì wà nínú àwọn aláìgbàgbọ́.

Ayah  39:60  الأية
وَيَوْمَ الْقِيَامَةِ تَرَى الَّذِينَ كَذَبُوا عَلَى اللهِ وُجُوهُهُم مُّسْوَدَّةٌ ۚ أَلَيْسَ فِي جَهَنَّمَ مَثْوًى لِّلْمُتَكَبِّرِينَ
Wayawma alqiyamati tara allatheenakathaboo AAala Allahi wujoohuhum muswaddatunalaysa fee jahannama mathwan lilmutakabbireen

Yoruba
 
Àti pé ní Ọjọ́ Àjíǹde, o máa rí àwọn tó parọ́ mọ́ Allāhu tí ojú wọn máa dúdú. Ṣé inú iná Jahnamọ kọ́ ni ibùgbé fún àwọn onígbèéraga ni?

Ayah  39:61  الأية
وَيُنَجِّي اللهُ الَّذِينَ اتَّقَوْا بِمَفَازَتِهِمْ لَا يَمَسُّهُمُ السُّوءُ وَلَا هُمْ يَحْزَنُونَ
Wayunajjee Allahu allatheenaittaqaw bimafazatihim la yamassuhumu assoo-owala hum yahzanoon

Yoruba
 
Allāhu yóò gba àwọn tó bẹ̀rù (Rẹ̀) là sínú ilé ìgbàlà wọn (ìyẹn, Ọgbà Ìdẹ̀ra). Aburú náà kò níí fọwọ́ bà wọ́n. Wọn kò sì níí banújẹ́.

Ayah  39:62  الأية
اللهُ خَالِقُ كُلِّ شَيْءٍ ۖ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ وَكِيلٌ
Allahu khaliqu kulli shay-inwahuwa AAala kulli shay-in wakeel

Yoruba
 
Allāhu ni Ẹlẹ́dàá gbogbo n̄ǹkan. Òun sì ni Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan.

Ayah  39:63  الأية
لَّهُ مَقَالِيدُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۗ وَالَّذِينَ كَفَرُوا بِآيَاتِ اللهِ أُولَٰئِكَ هُمُ الْخَاسِرُونَ
Lahu maqaleedu assamawatiwal-ardi wallatheena kafaroo bi-ayatiAllahi ola-ika humu alkhasiroon

Yoruba
 
TiRẹ̀ ni àwọn kọ́kọ́rọ́ ilé-ọ̀rọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni ẹni òfò.

Ayah  39:64  الأية
قُلْ أَفَغَيْرَ اللهِ تَأْمُرُونِّي أَعْبُدُ أَيُّهَا الْجَاهِلُونَ
Qul afaghayra Allahi ta/muroonneeaAAbudu ayyuha aljahiloon

Yoruba
 
Sọ pé: "Ṣé n̄ǹkan mìíràn yàtọ̀ sí Allāhu l'ẹ̀ ń pa mí lásẹ pé kí n̄g máa jọ́sìn fún, ẹ̀yin aláìmọ̀kan?"

Ayah  39:65  الأية
وَلَقَدْ أُوحِيَ إِلَيْكَ وَإِلَى الَّذِينَ مِن قَبْلِكَ لَئِنْ أَشْرَكْتَ لَيَحْبَطَنَّ عَمَلُكَ وَلَتَكُونَنَّ مِنَ الْخَاسِرِينَ
Walaqad oohiya ilayka wa-ilaallatheena min qablika la-in ashrakta layahbatannaAAamaluka walatakoonanna mina alkhasireen

Yoruba
 
Dájúdájú A ti fi ìmísí ránṣẹ́ sí ìwọ àti àwọn tó ṣíwájú rẹ (pé) "Dájúdájú tí o bá ṣẹbọ, iṣẹ́ rẹ máa bàjẹ́. Dájúdájú o sì máa wà nínú àwọn ẹni òfò."

Ayah  39:66  الأية
بَلِ اللهَ فَاعْبُدْ وَكُن مِّنَ الشَّاكِرِينَ
Bali Allaha faAAbud wakunmina ashshakireen

Yoruba
 
Rárá (má ṣẹbọ). Allāhu nìkan ni kí o jọ́sìn fún. Kí o sì wà nínú àwọn olùdúpẹ́ (fún Un).

Ayah  39:67  الأية
وَمَا قَدَرُوا اللهَ حَقَّ قَدْرِهِ وَالْأَرْضُ جَمِيعًا قَبْضَتُهُ يَوْمَ الْقِيَامَةِ وَالسَّمَاوَاتُ مَطْوِيَّاتٌ بِيَمِينِهِ ۚ سُبْحَانَهُ وَتَعَالَىٰ عَمَّا يُشْرِكُونَ
Wama qadaroo Allaha haqqaqadrihi wal-ardu jameeAAan qabdatuhu yawmaalqiyamati wassamawatu matwiyyatunbiyameenihi subhanahu wataAAala AAammayushrikoon

Yoruba
 
Wọn kò bu iyì fún Allāhu bí ó ṣe tọ́ láti bu iyì fún Un. Gbogbo ilẹ̀ pátápátá sì ni (Allāhu) máa fọwọ́ ara Rẹ̀ gbámú ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ó sì máa fi ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ ká àwọn sánmọ̀ kóróbójó. Mímọ́ ni fún Un. Ó sì ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.

Ayah  39:68  الأية
وَنُفِخَ فِي الصُّورِ فَصَعِقَ مَن فِي السَّمَاوَاتِ وَمَن فِي الْأَرْضِ إِلَّا مَن شَاءَ اللهُ ۖ ثُمَّ نُفِخَ فِيهِ أُخْرَىٰ فَإِذَا هُمْ قِيَامٌ يَنظُرُونَ
Wanufikha fee assoori fasaAAiqaman fee assamawati waman fee al-ardiilla man shaa Allahu thumma nufikha feehiokhra fa-itha hum qiyamun yanthuroon

Yoruba
 
Wọ́n á fọn fèrè oníwo (fún ikú). Àwọn tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ sì máa kú àfi ẹni tí Allāhu bá fẹ́. Lẹ́yìn náà, wọ́n máa fọn ọ́n ní ẹ̀ẹ̀ kejì, nígbà náà wọ́n máa wà ní ìdìde. Wọn yó sì máa wò sùn.

Ayah  39:69  الأية
وَأَشْرَقَتِ الْأَرْضُ بِنُورِ رَبِّهَا وَوُضِعَ الْكِتَابُ وَجِيءَ بِالنَّبِيِّينَ وَالشُّهَدَاءِ وَقُضِيَ بَيْنَهُم بِالْحَقِّ وَهُمْ لَا يُظْلَمُونَ
Waashraqati al-ardu binoori rabbihawawudiAAa alkitabu wajee-a binnabiyyeenawashshuhada-i waqudiya baynahum bilhaqqiwahum la yuthlamoon

Yoruba
 
Àti pé ilẹ̀ náà yóò máa tàn yànrànyànràn pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ Olúwa rẹ̀. Wọ́n máa gbé ìwé iṣẹ́ ẹ̀dá lélẹ̀. Wọ́n sì máa mú àwọn Ànábì àti àwọn ẹlẹ́rìí wá. A máa fi òdodo ṣèdájọ́ láààrin wọn. A kò sì níí ṣàbòsí sí wọn.

Ayah  39:70  الأية
وَوُفِّيَتْ كُلُّ نَفْسٍ مَّا عَمِلَتْ وَهُوَ أَعْلَمُ بِمَا يَفْعَلُونَ
Wawuffiyat kullu nafsin ma AAamilatwahuwa aAAlamu bima yafAAaloon

Yoruba
 
Àti pé Wọ́n máa san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́. Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

Ayah  39:71  الأية
وَسِيقَ الَّذِينَ كَفَرُوا إِلَىٰ جَهَنَّمَ زُمَرًا ۖ حَتَّىٰ إِذَا جَاءُوهَا فُتِحَتْ أَبْوَابُهَا وَقَالَ لَهُمْ خَزَنَتُهَا أَلَمْ يَأْتِكُمْ رُسُلٌ مِّنكُمْ يَتْلُونَ عَلَيْكُمْ آيَاتِ رَبِّكُمْ وَيُنذِرُونَكُمْ لِقَاءَ يَوْمِكُمْ هَٰذَا ۚ قَالُوا بَلَىٰ وَلَٰكِنْ حَقَّتْ كَلِمَةُ الْعَذَابِ عَلَى الْكَافِرِينَ
Waseeqa allatheena kafaroo ilajahannama zumaran hatta itha jaoohafutihat abwabuha waqala lahumkhazanatuha alam ya/tikum rusulun minkum yatloonaAAalaykum ayati rabbikum wayunthiroonakumliqaa yawmikum hatha qaloo bala walakinhaqqat kalimatu alAAathabi AAala alkafireen

Yoruba
 
Wọn yó sì da àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ lọ sínú iná Jahanamọ níjọníjọ, títí di ìgbà tí wọ́n bá dé ibẹ̀, wọ́n máa ṣí àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ sílẹ̀ (fún wọn). Àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ yó sì sọ fún wọn pé: "Ǹjẹ́ àwọn Òjíṣẹ́ kan kò wá ba yín láti ààrin ara yín, tí wọ́n ń ké àwọn āyah Olúwa yín fún yín, tí wọ́n sì ń kìlọ̀ ìpàdé ọjọ́ yín òní yìí fún yín?" Wọ́n wí pé: "Bẹ́ẹ̀ ni (wọ́n wá bá wa)." Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ìyà kò lé àwọn aláìgbàgbọ́ lórí ni.

Ayah  39:72  الأية
قِيلَ ادْخُلُوا أَبْوَابَ جَهَنَّمَ خَالِدِينَ فِيهَا ۖ فَبِئْسَ مَثْوَى الْمُتَكَبِّرِينَ
Qeela odkhuloo abwaba jahannama khalideenafeeha fabi/sa mathwa almutakabbireen

Yoruba
 
A óò sọ pé: "Ẹ wọ àwọn ẹnu ọ̀nà iná Jahanamọ. Olùṣegbére (ni yín) nínú rẹ̀. Ibùgbé àwọn onígbèéraga sì burú.

Ayah  39:73  الأية
وَسِيقَ الَّذِينَ اتَّقَوْا رَبَّهُمْ إِلَى الْجَنَّةِ زُمَرًا ۖ حَتَّىٰ إِذَا جَاءُوهَا وَفُتِحَتْ أَبْوَابُهَا وَقَالَ لَهُمْ خَزَنَتُهَا سَلَامٌ عَلَيْكُمْ طِبْتُمْ فَادْخُلُوهَا خَالِدِينَ
Waseeqa allatheena ittaqaw rabbahumila aljannati zumaran hatta itha jaoohawafutihat abwabuha waqala lahumkhazanatuha salamun AAalaykum tibtum fadkhuloohakhalideen

Yoruba
 
Àti pé A óò kó àwọn tó bẹ̀rù Olúwa wọn lọ sínú Ọgbà Ìdẹ̀ra níjọníjọ, títí di ìgbà tí wọ́n bá dé ibẹ̀, wọ́n máa ṣí àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ sílẹ̀ (fún wọn). Àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ yó sì sọ fún wọn pé: "Kí àlàáfíà máa ba yín. Ẹ̀yin dára (nítorí iṣẹ́ yín tó dára). Nítorí náà, ẹ wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, (kí ẹ di) olùṣegbére(nínú rẹ̀)."

Ayah  39:74  الأية
وَقَالُوا الْحَمْدُ لِلَّهِ الَّذِي صَدَقَنَا وَعْدَهُ وَأَوْرَثَنَا الْأَرْضَ نَتَبَوَّأُ مِنَ الْجَنَّةِ حَيْثُ نَشَاءُ ۖ فَنِعْمَ أَجْرُ الْعَامِلِينَ
Waqaloo alhamdu lillahiallathee sadaqana waAAdahu waawrathanaal-arda natabawwao mina aljannati haythu nashaofaniAAma ajru alAAamileen

Yoruba
 
Wọ́n á sọ pé: "Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó mú àdéhùn Rẹ̀ ṣẹ fún wa. Ó tún jogún ilẹ̀ náà fún wa, tí à ń gbé níbikíbi tí a bá fẹ́ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra." Ẹ̀san àwọn olùṣe-rere mà sì dára.

Ayah  39:75  الأية
وَتَرَى الْمَلَائِكَةَ حَافِّينَ مِنْ حَوْلِ الْعَرْشِ يُسَبِّحُونَ بِحَمْدِ رَبِّهِمْ ۖ وَقُضِيَ بَيْنَهُم بِالْحَقِّ وَقِيلَ الْحَمْدُ لِلَّهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ
Watara almala-ikata haffeenamin hawli alAAarshi yusabbihoona bihamdirabbihim waqudiya baynahum bilhaqqi waqeelaalhamdu lillahi rabbi alAAalameen

Yoruba
 
O sì máa rí àwọn Mọlāika tí wọ́n ń rọkiriká ní àyíká Ìtẹ́-ọlá. Wọ́n ń ṣe àfọ̀mọ́ àti ìdúpẹ́ fún Olúwa wọn. A máa fi òdodo ṣèdájọ́ láààrin àwọn ẹ̀dá. Wọ́n sì máa sọ pé: "Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá."





© EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us