1st Ayah 1 الأية ١الأوليبِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
حم
Ha-meem
Yoruba
Hā mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)
|
Ayah 40:2 الأية
تَنزِيلُ الْكِتَابِ مِنَ اللهِ الْعَزِيزِ الْعَلِيمِ
Tanzeelu alkitabi mina AllahialAAazeezi alAAaleem
Yoruba
Tírà náà sọ̀kalẹ̀ díẹ̀ díẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Allāhu, Alágbára, Onímọ̀,
|
Ayah 40:3 الأية
غَافِرِ الذَّنبِ وَقَابِلِ التَّوْبِ شَدِيدِ الْعِقَابِ ذِي الطَّوْلِ ۖ لَا
إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ۖ إِلَيْهِ الْمَصِيرُ
Ghafiri aththanbi waqabiliattawbi shadeedi alAAiqabi thee attawlila ilaha illa
huwa ilayhi almaseer
Yoruba
Aláforíjìn-ẹ̀ṣẹ̀, Olùgba-ìronúpìwàdà, Ẹni líle níbi ìyà, Ọlọ́rẹ, kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni àbọ̀ ẹ̀dá.
|
Ayah 40:4 الأية
مَا يُجَادِلُ فِي آيَاتِ اللهِ إِلَّا الَّذِينَ كَفَرُوا فَلَا يَغْرُرْكَ
تَقَلُّبُهُمْ فِي الْبِلَادِ
Ma yujadilu fee ayatiAllahi illa allatheena kafaroo falayaghrurka taqallubuhum
fee albilad
Yoruba
Kò sí ẹni tí ó máa ṣe àtakò sí àwọn āyah Allāhu àfi àwọn tó ṣàì gbàgbọ́. Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí ìgbòkègbodò wọn nínú ìlú kó ẹ̀tàn bá ọ.
|
Ayah 40:5 الأية
كَذَّبَتْ قَبْلَهُمْ قَوْمُ نُوحٍ وَالْأَحْزَابُ مِن بَعْدِهِمْ ۖ وَهَمَّتْ
كُلُّ أُمَّةٍ بِرَسُولِهِمْ لِيَأْخُذُوهُ ۖ وَجَادَلُوا بِالْبَاطِلِ
لِيُدْحِضُوا بِهِ الْحَقَّ فَأَخَذْتُهُمْ ۖ فَكَيْفَ كَانَ عِقَابِ
Kaththabat qablahum qawmu noohinwal-ahzabu min baAAdihim wahammat kulluommatin
birasoolihim liya/khuthoohu wajadaloo bilbatililiyudhidoo bihi alhaqqa
faakhathtuhumfakayfa kana AAiqab
Yoruba
Ìjọ (Ànábì) Nūh pe òdodo ní irọ́ ṣíwájú wọn. Àwọn ìjọ (mìíràn) lẹ́yìn wọn (náà ṣe bẹ́ẹ̀). Ìjọ kọ̀ọ̀kan ló gbèrò láti ki Òjíṣẹ́ wọn mọ́lẹ̀. Wọ́n fi irọ́ ja òdodo níyàn nítorí kí wọ́n lè fi wó òdodo lulẹ̀. Mo sì gbá wọn mú. Nítorí náà, báwo ni ìyà (tí Mo fi jẹ wọ́n) ti rí (lára wọn ná)!
|
Ayah 40:6 الأية
وَكَذَٰلِكَ حَقَّتْ كَلِمَتُ رَبِّكَ عَلَى الَّذِينَ كَفَرُوا أَنَّهُمْ
أَصْحَابُ النَّارِ
Wakathalika haqqat kalimaturabbika AAala allatheena kafaroo annahum as-habuannar
Yoruba
Àti pé báyẹn ni ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ ṣe kò lórí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ pé: "Dájúdájú àwọn ni èrò inú Iná."
|
Ayah 40:7 الأية
الَّذِينَ يَحْمِلُونَ الْعَرْشَ وَمَنْ حَوْلَهُ يُسَبِّحُونَ بِحَمْدِ رَبِّهِمْ
وَيُؤْمِنُونَ بِهِ وَيَسْتَغْفِرُونَ لِلَّذِينَ آمَنُوا رَبَّنَا وَسِعْتَ كُلَّ
شَيْءٍ رَّحْمَةً وَعِلْمًا فَاغْفِرْ لِلَّذِينَ تَابُوا وَاتَّبَعُوا سَبِيلَكَ
وَقِهِمْ عَذَابَ الْجَحِيمِ
Allatheena yahmiloona alAAarshawaman hawlahu yusabbihoona bihamdi
rabbihimwayu/minoona bihi wayastaghfiroona lillatheena amanoorabbana wasiAAta
kulla shay-in rahmatan waAAilmanfaghfir lillatheena taboo wattabaAAoosabeelaka
waqihim AAathaba aljaheem
Yoruba
Àwọn tó gbé Ìtẹ́-ọlá náà rù àti àwọn tó wà ní àyíká rẹ̀, wọ́n ń ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa wọn. Wọ́n ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu. Wọ́n sì ń tọrọ àforíjìn fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo (báyìí pé): "Olúwa wa, ìkẹ́ àti ìmọ̀ (Rẹ) gbòòrò ju gbogbo n̄ǹkan lọ, nítorí náà, ṣàforíjìn fún àwọn tó ronú pìwàdà, tí wọ́n sì tẹ̀lé ojú-ọ̀nà Rẹ. Kí O sì ṣọ́ wọn nínú ìyà iná Jẹhīm.
|
Ayah 40:8 الأية
رَبَّنَا وَأَدْخِلْهُمْ جَنَّاتِ عَدْنٍ الَّتِي وَعَدتَّهُمْ وَمَن صَلَحَ مِنْ
آبَائِهِمْ وَأَزْوَاجِهِمْ وَذُرِّيَّاتِهِمْ ۚ إِنَّكَ أَنتَ الْعَزِيزُ
الْحَكِيمُ
Rabbana waadkhilhum jannatiAAadnin allatee waAAadtahum waman salaha min
aba-ihimwaazwajihim wathurriyyatihim innaka antaalAAazeezu alhakeem
Yoruba
Olúwa wa, fi wọ́n sínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére èyí tí Ó ṣe ní àdéhùn fún àwọn àti ẹni tó ṣe iṣẹ́ rere nínú àwọn bàbá wọn, àwọn aya wọn àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn. Dájúdájú Ìwọ, Ìwọ ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
|
Ayah 40:9 الأية
وَقِهِمُ السَّيِّئَاتِ ۚ وَمَن تَقِ السَّيِّئَاتِ يَوْمَئِذٍ فَقَدْ رَحِمْتَهُ ۚ
وَذَٰلِكَ هُوَ الْفَوْزُ الْعَظِيمُ
Waqihimu assayyi-ati wamantaqi assayyi-ati yawma-ithin faqad rahimtahuwathalika
huwa alfawzu alAAatheem
Yoruba
Ṣọ́ wọn nínú àwọn aburú. Ẹnikẹ́ni tí O bá ṣọ́ níbi àwọn aburú (ìyà) ní ọjọ́ yẹn, dájúdájú O ti kẹ́ ẹ. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá."
|
Ayah 40:10 الأية
إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا يُنَادَوْنَ لَمَقْتُ اللهِ أَكْبَرُ مِن مَّقْتِكُمْ
أَنفُسَكُمْ إِذْ تُدْعَوْنَ إِلَى الْإِيمَانِ فَتَكْفُرُونَ
Inna allatheena kafaroo yunadawnalamaqtu Allahi akbaru min maqtikum anfusakum
ithtudAAawna ila al-eemani fatakfuroon
Yoruba
Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, wọn yóò pè wọ́n (láti sọ fún wọn nínú Iná pé): "Dájúdájú ìbínú ti Allāhu tóbi ju ìbínú tí ẹ̀ ń bí síra yín (nínú Iná, ṣebí) nígbà tí wọ́n ń pè yín síbi ìgbàgbọ́ òdodo, ńṣe ni ẹ̀ ń ṣàì gbàgbọ́."
|
Ayah 40:11 الأية
قَالُوا رَبَّنَا أَمَتَّنَا اثْنَتَيْنِ وَأَحْيَيْتَنَا اثْنَتَيْنِ
فَاعْتَرَفْنَا بِذُنُوبِنَا فَهَلْ إِلَىٰ خُرُوجٍ مِّن سَبِيلٍ
Qaloo rabbana amattanaithnatayni waahyaytana ithnatayni faAAtarafnabithunoobina
fahal ila khuroojin min sabeel
Yoruba
Wọ́n wí pé: "Olúwa wa, O pa wá ní ẹ̀ẹ̀ méjì. O sì ji wá ní ẹ̀ẹ̀ méjì. Nítorí náà, a jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. Ǹjẹ́ ọ̀nà kan wà láti jáde (padà sí ilé ayé) bí?"
|
Ayah 40:12 الأية
ذَٰلِكُم بِأَنَّهُ إِذَا دُعِيَ اللهُ وَحْدَهُ كَفَرْتُمْ ۖ وَإِن يُشْرَكْ
بِهِ تُؤْمِنُوا ۚ فَالْحُكْمُ لِلَّهِ الْعَلِيِّ الْكَبِيرِ
Thalikum bi-annahu ithaduAAiya Allahu wahdahu kafartum wa-in yushrak
bihitu/minoo falhukmu lillahi alAAaliyyialkabeer
Yoruba
(Ẹ wà nínú Iná) yẹn nítorí pé dájúdájú nígbà tí wọ́n bá pe Allāhu nìkan ṣoṣo, ẹ̀yin ṣàì gbàgbọ́. Nígbà tí wọ́n bá ṣẹbọ sí I, ẹ sì máa gbàgbọ́ (nínú ẹbọ). Nítorí náà, ìdájọ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Ó ga, Ó tóbi.
|
Ayah 40:13 الأية
هُوَ الَّذِي يُرِيكُمْ آيَاتِهِ وَيُنَزِّلُ لَكُم مِّنَ السَّمَاءِ رِزْقًا ۚ
وَمَا يَتَذَكَّرُ إِلَّا مَن يُنِيبُ
Huwa allathee yureekum ayatihiwayunazzilu lakum mina assama-i rizqan
wamayatathakkaru illa man yuneeb
Yoruba
Òun ni Ẹni tó ń fi àwọn àmì Rẹ̀ hàn yín. Ó sì ń sọ arísìkí kalẹ̀ fún yín láti sánmọ̀. Kò sí ẹni tó ń lo ìrántí àfi ẹni tó ń ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Allāhu (nípasẹ̀ ìronúpìwàdà).
|
Ayah 40:14 الأية
فَادْعُوا اللهَ مُخْلِصِينَ لَهُ الدِّينَ وَلَوْ كَرِهَ الْكَافِرُونَ
FadAAoo Allaha mukhliseenalahu addeena walaw kariha alkafiroon
Yoruba
Nítorí náà, ẹ pe Allāhu lẹ́ni tí yóò máa fi àfọ̀mọ́-ọkàn (àníyàn mímọ́) ṣe ẹ̀sìn fún Un. àwọn aláìgbàgbọ́ ìbáà kórira Rẹ̀.
|
Ayah 40:15 الأية
رَفِيعُ الدَّرَجَاتِ ذُو الْعَرْشِ يُلْقِي الرُّوحَ مِنْ أَمْرِهِ عَلَىٰ مَن
يَشَاءُ مِنْ عِبَادِهِ لِيُنذِرَ يَوْمَ التَّلَاقِ
RafeeAAu addarajati thooalAAarshi yulqee arrooha min amrihi AAalaman yashao min
AAibadihi liyunthira yawma attalaq
Yoruba
(Allāhu) Ẹni tó ni gbogbo ipò àjùlọ, Olúwa Ìtẹ́-ọlá, Ó ń fi ìmísí mímọ́ ránṣẹ́ pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀ sí ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ nítorì kí ó lè fi ṣèkìlọ̀ nípa Ọjọ́ ìpàdé náà.
|
Ayah 40:16 الأية
يَوْمَ هُم بَارِزُونَ ۖ لَا يَخْفَىٰ عَلَى اللهِ مِنْهُمْ شَيْءٌ ۚ لِّمَنِ
الْمُلْكُ الْيَوْمَ ۖ لِلَّهِ الْوَاحِدِ الْقَهَّارِ
Yawma hum barizoona la yakhfaAAala Allahi minhum shay-on limani almulku
alyawmalillahi alwahidi alqahhar
Yoruba
Ní ọjọ́ tí wọn yóò yọ jáde (láti inú sàréè), kiní kan kò sì níí pamọ́ nípa wọn fún Allāhu. (Allāhu yó sì sọ pé): "Ti ta ni ìjọba ní ọjọ́ òní?" Ti Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí ni.
|
Ayah 40:17 الأية
الْيَوْمَ تُجْزَىٰ كُلُّ نَفْسٍ بِمَا كَسَبَتْ ۚ لَا ظُلْمَ الْيَوْمَ ۚ إِنَّ
اللهَ سَرِيعُ الْحِسَابِ
Alyawma tujza kullu nafsin bimakasabat la thulma alyawma inna AllahasareeAAu
alhisab
Yoruba
Ní òní ni A óò san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́. Kò sì sí àbòsí kan ní́òní. Dájúdájú Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́.
|
Ayah 40:18 الأية
وَأَنذِرْهُمْ يَوْمَ الْآزِفَةِ إِذِ الْقُلُوبُ لَدَى الْحَنَاجِرِ كَاظِمِينَ ۚ
مَا لِلظَّالِمِينَ مِنْ حَمِيمٍ وَلَا شَفِيعٍ يُطَاعُ
Waanthirhum yawma al-azifati ithialquloobu lada alhanajiri kathimeenama
liththalimeena min hameeminwala shafeeAAin yutaAA
Yoruba
Àti pé Allāhu l'Ó máa fi òdodo dájọ́. Àwọn tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀, wọn kò lè ṣe ìdájọ́ kan kan. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Olùríran.
|
Ayah 40:19 الأية
يَعْلَمُ خَائِنَةَ الْأَعْيُنِ وَمَا تُخْفِي الصُّدُورُ
YaAAlamu kha-inata al-aAAyuni wamatukhfee assudoor
Yoruba
(Allāhu) mọ ojú ìjàǹbá àti ohun tí àwọn ọkàn fi pamọ́.
|
Ayah 40:20 الأية
وَاللهُ يَقْضِي بِالْحَقِّ ۖ وَالَّذِينَ يَدْعُونَ مِن دُونِهِ لَا يَقْضُونَ
بِشَيْءٍ ۗ إِنَّ اللهَ هُوَ السَّمِيعُ الْبَصِيرُ
Wallahu yaqdee bilhaqqiwallatheena yadAAoona min doonihi la yaqdoonabishay-in
inna Allaha huwa assameeAAu albaseer
Yoruba
Àti pé Allāhu l'Ó máa fi òdodo dájọ́. Àwọn tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀, wọn kò lè ṣe ìdájọ́ kan kan. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Olùríran.
|
Ayah 40:21 الأية
أَوَلَمْ يَسِيرُوا فِي الْأَرْضِ فَيَنظُرُوا كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الَّذِينَ
كَانُوا مِن قَبْلِهِمْ ۚ كَانُوا هُمْ أَشَدَّ مِنْهُمْ قُوَّةً وَآثَارًا فِي
الْأَرْضِ فَأَخَذَهُمُ اللهُ بِذُنُوبِهِمْ وَمَا كَانَ لَهُم مِّنَ اللهِ مِن
وَاقٍ
Awa lam yaseeroo fee al-ardi fayanthurookayfa kana AAaqibatu allatheena kanoomin
qablihim kanoo hum ashadda minhum quwwatan waatharanfee al-ardi faakhathahumu
Allahu bithunoobihimwama kana lahum mina Allahi min waq
Yoruba
Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe rí? Wọ́n ní agbára jù wọ́n lọ. Wọ́n sì lo ilẹ̀ (fún oko dídá jù wọ́n lọ). Síbẹ̀síbẹ̀ Allāhu mú wọn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Kò sì sí olùṣọ́ kan fún wọn (níbi ìyà) Allāhu.
|
Ayah 40:22 الأية
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ كَانَت تَّأْتِيهِمْ رُسُلُهُم بِالْبَيِّنَاتِ فَكَفَرُوا
فَأَخَذَهُمُ اللهُ ۚ إِنَّهُ قَوِيٌّ شَدِيدُ الْعِقَابِ
Thalika bi-annahum kanatta/teehim rusuluhum bilbayyinati fakafaroo
faakhathahumuAllahu innahu qawiyyun shadeedu alAAiqab
Yoruba
Ìyẹn nítorí pé, àwọn Òjíṣẹ́ wọn ń wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tó yanjú, ṣùgbọ́n wọ́n ṣàì gbàgbọ́. Nítorí náà, Allāhu mú wọn. Dájúdájú Òun ni Alágbára, Ẹni líle níbi ìyà.
|
Ayah 40:23 الأية
وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا مُوسَىٰ بِآيَاتِنَا وَسُلْطَانٍ مُّبِينٍ
Walaqad arsalna moosa bi-ayatinawasultanin mubeen
Yoruba
Dájúdájú A fi àwọn àmì Wa àti ẹ̀rí tó yanjú rán (Ànábì) Mūsā níṣẹ́
|
Ayah 40:24 الأية
إِلَىٰ فِرْعَوْنَ وَهَامَانَ وَقَارُونَ فَقَالُوا سَاحِرٌ كَذَّابٌ
Ila firAAawna wahamanawaqaroona faqaloo sahirun kaththab
Yoruba
Sí Fir‘aon àti Hāmọ̄n àti Ƙọ̄rūn. Ṣùgbọ́n wọ́n wí pé: "Òpìdán, òpùrọ́ ni (Ànábì Mūsā)."
|
Ayah 40:25 الأية
فَلَمَّا جَاءَهُم بِالْحَقِّ مِنْ عِندِنَا قَالُوا اقْتُلُوا أَبْنَاءَ الَّذِينَ
آمَنُوا مَعَهُ وَاسْتَحْيُوا نِسَاءَهُمْ ۚ وَمَا كَيْدُ الْكَافِرِينَ إِلَّا فِي
ضَلَالٍ
Falamma jaahum bilhaqqimin AAindina qaloo oqtuloo abnaa allatheenaamanoo maAAahu
wastahyoo nisaahumwama kaydu alkafireena illa fee dalal
Yoruba
Nígbà tí ó mú òdodo náà dé ọ̀dọ̀ wọn láti ọ̀dọ̀ Wa, wọ́n wí pé: "Ẹ pa àwọn ọmọkùnrin àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo nínú Allāhu pẹ̀lú rẹ̀, kí ẹ sì fi àwọn ọmọbìnrin wọn sílẹ̀." Ète àwọn aláìgbàgbọ́ kò sí nínú kiní kan bí kò ṣe nínú ìṣìnà.
|
Ayah 40:26 الأية
وَقَالَ فِرْعَوْنُ ذَرُونِي أَقْتُلْ مُوسَىٰ وَلْيَدْعُ رَبَّهُ ۖ إِنِّي أَخَافُ
أَن يُبَدِّلَ دِينَكُمْ أَوْ أَن يُظْهِرَ فِي الْأَرْضِ الْفَسَادَ
Waqala firAAawnu tharooneeaqtul moosa walyadAAu rabbahu innee akhafu anyubaddila
deenakum aw an yuthhira fee al-ardialfasad
Yoruba
Fir‘aon wí pé: "Ẹ fi mí sílẹ̀ kí n̄g pa Mūsā, kí ó sì pe Olúwa rẹ̀ (wò bóyá Ó máa gbà á sílẹ̀). Dájúdájú èmi ń bẹ̀rù pé ó máa yí ẹ̀sìn yín padà tàbí pé ó máa ṣàfi hàn ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀."
|
Ayah 40:27 الأية
وَقَالَ مُوسَىٰ إِنِّي عُذْتُ بِرَبِّي وَرَبِّكُم مِّن كُلِّ مُتَكَبِّرٍ لَّا
يُؤْمِنُ بِيَوْمِ الْحِسَابِ
Waqala moosa innee AAuthtubirabbee warabbikum min kulli mutakabbirin la
yu/minubiyawmi alhisab
Yoruba
(Ànábì) Mūsā sọ pé: "Dájúdájú èmi sá di Olúwa mi àti Olúwa yín kúrò lọ́wọ́ gbogbo onígbèéraga, tí kò ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Ọjọ́ ìṣírò-iṣẹ́.
|
Ayah 40:28 الأية
وَقَالَ رَجُلٌ مُّؤْمِنٌ مِّنْ آلِ فِرْعَوْنَ يَكْتُمُ إِيمَانَهُ أَتَقْتُلُونَ
رَجُلًا أَن يَقُولَ رَبِّيَ اللهُ وَقَدْ جَاءَكُم بِالْبَيِّنَاتِ مِن
رَّبِّكُمْ ۖ وَإِن يَكُ كَاذِبًا فَعَلَيْهِ كَذِبُهُ ۖ وَإِن يَكُ صَادِقًا
يُصِبْكُم بَعْضُ الَّذِي يَعِدُكُمْ ۖ إِنَّ اللهَ لَا يَهْدِي مَنْ هُوَ
مُسْرِفٌ كَذَّابٌ
Waqala rajulun mu/minun min alifirAAawna yaktumu eemanahu ataqtuloona rajulan an
yaqoolarabbiyya Allahu waqad jaakum bilbayyinatimin rabbikum wa-in yaku kathiban
faAAalayhi kathibuhuwa-in yaku sadiqan yusibkum baAAdu allatheeyaAAidukum inna
Allaha la yahdee man huwa musrifunkaththab
Yoruba
Ọkùnrin onígbàgbọ́ òdodo kan tó ń fi ìgbàgbọ́ rẹ̀ pamọ́ nínú àwọn ènìyàn Fir‘aon sọ pé: "Ṣé ẹ máa pa ọkùnrin kan nítorí pé ó ń sọ pé, "Allāhu ni Olúwa mi." Ó sì kúkú ti mú àwọn ẹ̀rí tó yanjú wá ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Tí ó bá jẹ́ òpùrọ́, (ìyà) irọ́ rẹ̀ wà lórí rẹ̀. Tí ó bá sì jẹ́ olódodo, apá kan èyí tí ó ṣe ní ìlérí fún yín yó sì kò le yín lórí. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ẹni tí ó jẹ́ aláṣejù, òpùrọ́.
|
Ayah 40:29 الأية
يَا قَوْمِ لَكُمُ الْمُلْكُ الْيَوْمَ ظَاهِرِينَ فِي الْأَرْضِ فَمَن يَنصُرُنَا
مِن بَأْسِ اللهِ إِن جَاءَنَا ۚ قَالَ فِرْعَوْنُ مَا أُرِيكُمْ إِلَّا مَا
أَرَىٰ وَمَا أَهْدِيكُمْ إِلَّا سَبِيلَ الرَّشَادِ
Ya qawmi lakumu almulku alyawma thahireenafee al-ardi faman yansuruna min ba/si
Allahiin jaana qala firAAawnu ma oreekumilla ma ara wama ahdeekum illasabeela
arrashad
Yoruba
Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ̀yin l'ẹ ni ìjọba lónìí, tí ẹ ga jùlọ lórí ilẹ̀ náà (ìyẹn ilẹ̀ Misrọ). Ṣùgbọ́n ta ni ó máa ràn wá lọ́wọ́ tí ìyà Allāhu bá dé bá wa?" Fir‘aon wí pé: "Èmi kò fi n̄ǹkan kan hàn yín bí kò ṣe ohun tí mo rí (nínú òye mi). Èmi kò sì tọ yín sí ọ̀nà kan bí kò ṣe ojú ọ̀nà ìmọ̀nà."
|
Ayah 40:30 الأية
وَقَالَ الَّذِي آمَنَ يَا قَوْمِ إِنِّي أَخَافُ عَلَيْكُم مِّثْلَ يَوْمِ
الْأَحْزَابِ
Waqala allathee amana yaqawmi innee akhafu AAalaykum mithla yawmi al-ahzab
Yoruba
Ẹni tó gbàgbọ́ ní òdodo tún sọ pé: "Ẹ̀yin ènìyàn mi, dájúdájú irú ọjọ́ (ẹ̀san ìyà tó ṣẹlẹ̀ sí) àwọn ọmọ-ogun oníjọ ni èmi ń páyà lórí yín;
|
Ayah 40:31 الأية
مِثْلَ دَأْبِ قَوْمِ نُوحٍ وَعَادٍ وَثَمُودَ وَالَّذِينَ مِن بَعْدِهِمْ ۚ وَمَا
اللهُ يُرِيدُ ظُلْمًا لِّلْعِبَادِ
Mithla da/bi qawmi noohin waAAadinwathamooda wallatheena min baAAdihim
wamaAllahu yureedu thulman lilAAibad
Yoruba
Irú ìṣe (ìparun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn) ènìyàn Nūh, ‘Ād, Thamūd àti àwọn tó tẹ̀lé wọn. Allāhu kò sì gbèrò àbòsí sí àwọn ẹrúsìn náà.
|
Ayah 40:32 الأية
وَيَا قَوْمِ إِنِّي أَخَافُ عَلَيْكُمْ يَوْمَ التَّنَادِ
Waya qawmi innee akhafuAAalaykum yawma attanad
Yoruba
Ẹ̀yin ènìyàn mi, dájúdájú èmi ń páyà Ọjọ́ ìpè fún yín.
|
Ayah 40:33 الأية
يَوْمَ تُوَلُّونَ مُدْبِرِينَ مَا لَكُم مِّنَ اللهِ مِنْ عَاصِمٍ ۗ وَمَن
يُضْلِلِ اللهُ فَمَا لَهُ مِنْ هَادٍ
Yawma tuwalloona mudbireena ma lakummina Allahi min AAasimin waman yudlili
Allahufama lahu min had
Yoruba
Ọjọ́ tí ẹ máa pẹ̀yìndà láti sá lọ; kò sì níí sí aláàbò kan fún yín lọ́dọ̀ Allāhu. Àti pé ẹni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, kò lè sí afinimọ̀nà kan fún un.
|
Ayah 40:34 الأية
وَلَقَدْ جَاءَكُمْ يُوسُفُ مِن قَبْلُ بِالْبَيِّنَاتِ فَمَا زِلْتُمْ فِي شَكٍّ
مِّمَّا جَاءَكُم بِهِ ۖ حَتَّىٰ إِذَا هَلَكَ قُلْتُمْ لَن يَبْعَثَ اللهُ مِن
بَعْدِهِ رَسُولًا ۚ كَذَٰلِكَ يُضِلُّ اللهُ مَنْ هُوَ مُسْرِفٌ مُّرْتَابٌ
Walaqad jaakum yoosufu min qablu bilbayyinatifama ziltum fee shakkin mimma
jaakum bihi hattaitha halaka qultum lan yabAAatha Allahu minbaAAdihi rasoolan
kathalika yudillu Allahuman huwa musrifun murtab
Yoruba
Àti pé dájúdájú (Ànábì) Yūsuf ti tọ̀ yín wá ṣíwájú pẹ̀lú àwọn àlàyé ọ̀rọ̀ tó yanjú, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò yé wà nínú iyèméjì nípa ohun tí ó mú wá ba yín títí di ìgbà tí ó fi kú, tí ẹ fi wí pé: "Allāhu kò níí gbé Òjíṣẹ́ kan dìde mọ́ lẹ́yìn rẹ̀. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń sọ ẹni tí ó jẹ́ aláṣejù, oníyèméjì nù."
|
Ayah 40:35 الأية
الَّذِينَ يُجَادِلُونَ فِي آيَاتِ اللهِ بِغَيْرِ سُلْطَانٍ أَتَاهُمْ ۖ كَبُرَ
مَقْتًا عِندَ اللهِ وَعِندَ الَّذِينَ آمَنُوا ۚ كَذَٰلِكَ يَطْبَعُ اللهُ
عَلَىٰ كُلِّ قَلْبِ مُتَكَبِّرٍ جَبَّارٍ
Allatheena yujadiloona fee ayatiAllahi bighayri sultanin atahum kaburamaqtan
AAinda Allahi waAAinda allatheena amanookathalika yatbaAAu Allahu AAala
kulliqalbi mutakabbirin jabbar
Yoruba
Àwọn tó ń jiyàn nípa àwọn āyah Allāhu láìsí ẹ̀rí kan tí ó dé bá wọn. Ẹ̀ṣẹ̀ ńlá sì ni ní ọ̀dọ̀ Allāhu àti ní ọ̀dọ̀ àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń fi èdídí bo gbogbo ọkàn onígbèéraga, ajẹninípá."
|
Ayah 40:36 الأية
وَقَالَ فِرْعَوْنُ يَا هَامَانُ ابْنِ لِي صَرْحًا لَّعَلِّي أَبْلُغُ
الْأَسْبَابَ
Waqala firAAawnu ya hamanuibni lee sarhan laAAallee ablughu al-asbab
Yoruba
Fir‘aon wí pé: "Hāmọ̄n, mọ ilé gíga fíofío kan fún mi nítorí kí èmi lè dé àwọn ojú ọ̀nà náà.
|
Ayah 40:37 الأية
أَسْبَابَ السَّمَاوَاتِ فَأَطَّلِعَ إِلَىٰ إِلَٰهِ مُوسَىٰ وَإِنِّي لَأَظُنُّهُ
كَاذِبًا ۚ وَكَذَٰلِكَ زُيِّنَ لِفِرْعَوْنَ سُوءُ عَمَلِهِ وَصُدَّ عَنِ
السَّبِيلِ ۚ وَمَا كَيْدُ فِرْعَوْنَ إِلَّا فِي تَبَابٍ
Asbaba assamawatifaattaliAAa ila ilahi moosa wa-inneelaathunnuhu kathiban
wakathalikazuyyina lifirAAawna soo-o AAamalihi wasudda AAani assabeeliwama kaydu
firAAawna illa fee tabab
Yoruba
Àwọn ojú ọ̀nà (inú) sánmọ̀ ni, nítorí kí èmi lè yọjú wo Ọlọ́hun Mūsā nítorí pé, dájúdájú èmi ń rò ó sí òpùrọ́." Báyẹn ni wọ́n ṣe iṣẹ́ aburú (ọwọ́) Fir‘aon ní ọ̀ṣọ́ fún un. Wọ́n sì ṣẹ́rí rẹ̀ kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn Allāhu). Ète Fir‘aon kò sì wà nínú kiní kan bí kò ṣe nínú òfò.
|
Ayah 40:38 الأية
وَقَالَ الَّذِي آمَنَ يَا قَوْمِ اتَّبِعُونِ أَهْدِكُمْ سَبِيلَ الرَّشَادِ
Waqala allathee amana yaqawmi ittabiAAooni ahdikum sabeela arrashad
Yoruba
Ẹni tó gbàgbọ́ ní òdodo tún sọ pé: "Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ tẹ̀lé mi, mo máa júwe yín sí ojú ọ̀nà ìmọ̀nà.
|
Ayah 40:39 الأية
يَا قَوْمِ إِنَّمَا هَٰذِهِ الْحَيَاةُ الدُّنْيَا مَتَاعٌ وَإِنَّ الْآخِرَةَ
هِيَ دَارُ الْقَرَارِ
Ya qawmi innama hathihialhayatu addunya mataAAunwa-inna al-akhirata hiya daru
alqarar
Yoruba
Ẹ̀yin ènìyàn mi, ìgbádùn lásán ni ìṣẹ̀mí ilé ayé yìí. Dájúdájú ọ̀run sì ni ilé gbére.
|
Ayah 40:40 الأية
مَنْ عَمِلَ سَيِّئَةً فَلَا يُجْزَىٰ إِلَّا مِثْلَهَا ۖ وَمَنْ عَمِلَ صَالِحًا
مِّن ذَكَرٍ أَوْ أُنثَىٰ وَهُوَ مُؤْمِنٌ فَأُولَٰئِكَ يَدْخُلُونَ الْجَنَّةَ
يُرْزَقُونَ فِيهَا بِغَيْرِ حِسَابٍ
Man AAamila sayyi-atan fala yujzailla mithlaha waman AAamila salihanmin thakarin
aw ontha wahuwa mu/minun faola-ikayadkhuloona aljannata yurzaqoona feeha
bighayri hisab
Yoruba
Ẹni tí ó bá ṣe aburú kan, Wọn kò níí san án ní ẹ̀san kan àyàfi irú rẹ̀. Ẹni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ rere ní ọkùnrin tàbí ní obìnrin, tí ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n máa wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Wọn yóò máa pèsè ìjẹ-ìmu àti ìgbádùn fún wọn nínú rẹ̀ láì níí ní ìṣírò.
|
Ayah 40:41 الأية
وَيَا قَوْمِ مَا لِي أَدْعُوكُمْ إِلَى النَّجَاةِ وَتَدْعُونَنِي إِلَى النَّارِ
Waya qawmi malee adAAookum ilaannajati watadAAoonanee ila annar
Yoruba
Ẹ̀yin ènìyàn mi, kí ló mú yín tí mò ń pè yín síbi ìgbàlà, tí ẹ̀yin sì ń pè mí síbi Iná?
|
Ayah 40:42 الأية
تَدْعُونَنِي لِأَكْفُرَ بِاللهِ وَأُشْرِكَ بِهِ مَا لَيْسَ لِي بِهِ عِلْمٌ
وَأَنَا أَدْعُوكُمْ إِلَى الْعَزِيزِ الْغَفَّارِ
TadAAoonanee li-akfura billahiwaoshrika bihi ma laysa lee bihi AAilmun
waanaadAAookum ila alAAazeezi alghaffar
Yoruba
Ẹ̀yin ń pè mí pé kí n̄g ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu, kí n̄g sì sọ n̄ǹkan tí èmi kò nímọ̀ nípa rẹ̀ di akẹgbẹ́ fún Un. Èmi sì ń pè yín sí ọ̀dọ̀ Alágbára, Aláforíjìn.
|
Ayah 40:43 الأية
لَا جَرَمَ أَنَّمَا تَدْعُونَنِي إِلَيْهِ لَيْسَ لَهُ دَعْوَةٌ فِي الدُّنْيَا
وَلَا فِي الْآخِرَةِ وَأَنَّ مَرَدَّنَا إِلَى اللهِ وَأَنَّ الْمُسْرِفِينَ
هُمْ أَصْحَابُ النَّارِ
La jarama annama tadAAoonaneeilayhi laysa lahu daAAwatun fee addunya walafee
al-akhirati waanna maraddana ila Allahiwaanna almusrifeena hum as-habu annar
Yoruba
Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n, dájúdájú n̄ǹkan tí ẹ̀ ń pè mí sí, kò ní ẹ̀tọ́ sí ìpè kan ní ayé àti ní ọ̀run. Àti pé dájúdájú ọ̀dọ̀ Allāhu ni àbọ̀ wa. Dájúdájú àwọn olùtayọ-ẹnu-ààlà, àwọn ni èrò inú Iná.
|
Ayah 40:44 الأية
فَسَتَذْكُرُونَ مَا أَقُولُ لَكُمْ ۚ وَأُفَوِّضُ أَمْرِي إِلَى اللهِ ۚ إِنَّ
اللهَ بَصِيرٌ بِالْعِبَادِ
Fasatathkuroona ma aqoolulakum waofawwidu amree ila Allahi inna Allahabaseerun
bilAAibad
Yoruba
Nítorí náà, ẹ máa rántí ohun tí mò ń sọ fún yín. Mo sì ń fi ọ̀rọ̀ mi tì sí ọ̀dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn."
|
Ayah 40:45 الأية
فَوَقَاهُ اللهُ سَيِّئَاتِ مَا مَكَرُوا ۖ وَحَاقَ بِآلِ فِرْعَوْنَ سُوءُ
الْعَذَابِ
Fawaqahu Allahu sayyi-atima makaroo wahaqa bi-ali firAAawna soo-oalAAathab
Yoruba
Allāhu sì ṣọ́ ọ níbi àwọn aburú tí wọ́n dète rẹ̀. Ìyà burúkú sì yí àwọn ènìyàn Fir‘aon po.
|
Ayah 40:46 الأية
النَّارُ يُعْرَضُونَ عَلَيْهَا غُدُوًّا وَعَشِيًّا ۖ وَيَوْمَ تَقُومُ السَّاعَةُ
أَدْخِلُوا آلَ فِرْعَوْنَ أَشَدَّ الْعَذَابِ
Annaru yuAAradoonaAAalayha ghuduwwan waAAashiyyan wayawma taqoomu
assaAAatuadkhiloo ala firAAawna ashadda alAAathab
Yoruba
Iná ni Wọ́n yóò máà ṣẹ́rí wọn sí ní òwúrọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́. Àti pé ní ọjọ́ tí Àkókò náà bá dé (A máa sọ pé): "Ẹ mú àwọn ènìyàn Fir‘aon wọ inú ìyà Iná tó le jùlọ."
|
Ayah 40:47 الأية
وَإِذْ يَتَحَاجُّونَ فِي النَّارِ فَيَقُولُ الضُّعَفَاءُ لِلَّذِينَ
اسْتَكْبَرُوا إِنَّا كُنَّا لَكُمْ تَبَعًا فَهَلْ أَنتُم مُّغْنُونَ عَنَّا
نَصِيبًا مِّنَ النَّارِ
Wa-ith yatahajjoona fee annarifayaqoolu adduAAafao lillatheenaistakbaroo inna
kunna lakum tabaAAan fahal antummughnoona AAanna naseeban mina annar
Yoruba
(Rántí) nígbà tí wọ́n bá ń bá ara wọn ṣe àríyànjiyàn nínú Iná. Àwọn ọ̀lẹ yóò wí fún àwọn tí wọ́n ṣègbéraga pé: "Dájúdájú àwa jẹ́ ọmọlẹ́yìn fún yín, ǹjẹ́ ẹ̀yin lè gbé ìpín kan kúrò fún wa nínú ìyà Iná?"
|
Ayah 40:48 الأية
قَالَ الَّذِينَ اسْتَكْبَرُوا إِنَّا كُلٌّ فِيهَا إِنَّ اللهَ قَدْ حَكَمَ
بَيْنَ الْعِبَادِ
Qala allatheena istakbaroo innakullun feeha inna Allaha qad hakama baynaalAAibad
Yoruba
Àwọn tó ṣègbéraga máa wí pé: "Dájúdájú gbogbo wa l'a wà nínú rẹ̀. Dájúdájú Allāhu kúkú ti dájọ́ láààrin àwọn ẹrú náà."
|
Ayah 40:49 الأية
وَقَالَ الَّذِينَ فِي النَّارِ لِخَزَنَةِ جَهَنَّمَ ادْعُوا رَبَّكُمْ يُخَفِّفْ
عَنَّا يَوْمًا مِّنَ الْعَذَابِ
Waqala allatheena fee annarilikhazanati jahannama odAAoo rabbakum yukhaffif
AAannayawman mina alAAathab
Yoruba
Àwọn tó wà nínú Iná tún máa wí fún àwọn ẹ̀ṣọ́-Iná pé: "Ẹ bá wa pe Olúwa yín, kí Ó ṣe ìyà ní fífúyẹ́ fún wa fún ọjọ́ kan."
|
Ayah 40:50 الأية
قَالُوا أَوَلَمْ تَكُ تَأْتِيكُمْ رُسُلُكُم بِالْبَيِّنَاتِ ۖ قَالُوا بَلَىٰ ۚ
قَالُوا فَادْعُوا ۗ وَمَا دُعَاءُ الْكَافِرِينَ إِلَّا فِي ضَلَالٍ
Qaloo awa lam taku ta/teekumrusulukum bilbayyinati qaloo bala qaloofadAAoo wama
duAAao alkafireena illafee dalal
Yoruba
Wọ́n yóò sọ pé: "Ǹjẹ́ àwọn Òjísẹ́ yín kì í mú àwọn ẹ̀rí tó yanjú wá ba yín bí?" Wọ́n á wí pé: "Bẹ́ẹ̀ ni, (wọ́n mú un wá)." Wọ́n máa sọ pé: "Ẹ ṣàdúà wò." Àdúà (àti ìpè) àwọn aláìgbàgbọ́ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe sínú ìṣìnà.
|
Ayah 40:51 الأية
إِنَّا لَنَنصُرُ رُسُلَنَا وَالَّذِينَ آمَنُوا فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا
وَيَوْمَ يَقُومُ الْأَشْهَادُ
Inna lanansuru rusulanawallatheena amanoo fee alhayatiaddunya wayawma yaqoomu
al-ashhad
Yoruba
Dájúdájú Àwa kúkú máa ṣàrànṣe fún àwọn Òjíṣẹ́ Wa àti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo nínú ìgbésí ayé yìí àti ní ọjọ́ tí àwọn ẹlẹ́rìí yó dìde (ní Ọjọ́ Àjíǹde).
|
Ayah 40:52 الأية
يَوْمَ لَا يَنفَعُ الظَّالِمِينَ مَعْذِرَتُهُمْ ۖ وَلَهُمُ اللَّعْنَةُ وَلَهُمْ
سُوءُ الدَّارِ
Yawma la yanfaAAu aththalimeenamaAAthiratuhum walahumu allaAAnatu walahum soo-o
addar
Yoruba
Ní ọjọ́ tí àwáwí àwọn alábòsí kò níí ṣe wọ́n ní àǹfààní; ègún ń bẹ fún wọn, ilé (ìyà) burúkú sì wà fún wọn.
|
Ayah 40:53 الأية
وَلَقَدْ آتَيْنَا مُوسَى الْهُدَىٰ وَأَوْرَثْنَا بَنِي إِسْرَائِيلَ الْكِتَابَ
Walaqad atayna moosaalhuda waawrathna banee isra-eela alkitab
Yoruba
Dájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā ní ìmọ̀nà. A sì jogún Tírà fún àwọn ọmọ 'Isrọ̄'īl.
|
Ayah 40:54 الأية
هُدًى وَذِكْرَىٰ لِأُولِي الْأَلْبَابِ
Hudan wathikra li-olee al-albab
Yoruba
(Ó jẹ́) ìmọ̀nà àti ìrántí fún àwọn onílàákàyè.
|
Ayah 40:55 الأية
فَاصْبِرْ إِنَّ وَعْدَ اللهِ حَقٌّ وَاسْتَغْفِرْ لِذَنبِكَ وَسَبِّحْ بِحَمْدِ
رَبِّكَ بِالْعَشِيِّ وَالْإِبْكَارِ
Fasbir inna waAAda Allahihaqqun wastaghfir lithanbika wasabbihbihamdi rabbika
bilAAashiyyi wal-ibkar
Yoruba
Nítorí náà, ṣe sùúrù. Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Kí o sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ẹyìn fún Olúwa rẹ ní ìrọ̀lẹ́ àti ní òwúrọ̀ kùtùkùtù.
|
Ayah 40:56 الأية
إِنَّ الَّذِينَ يُجَادِلُونَ فِي آيَاتِ اللهِ بِغَيْرِ سُلْطَانٍ أَتَاهُمْ ۙ
إِن فِي صُدُورِهِمْ إِلَّا كِبْرٌ مَّا هُم بِبَالِغِيهِ ۚ فَاسْتَعِذْ بِاللهِ
ۖ إِنَّهُ هُوَ السَّمِيعُ الْبَصِيرُ
Inna allatheena yujadiloonafee ayati Allahi bighayri sultanin atahumin fee
sudoorihim illa kibrun ma hum bibaligheehifastaAAith billahi innahu huwa
assameeAAualbaseer
Yoruba
Dájúdájú àwọn tó ń jiyàn nípa àwọn āyah Allāhu láìní ẹrí kan (lọ́wọ́) tí ó wá bá wọn (láti ọ̀dọ̀ Allāhu), kò sí kiní kan nínú igbá-àyà wọn àyàfi ọkàn-gíga. Wọn kò sì lè dé ibi gíga (pẹ̀lú ọkàn gíga). Nítorí náà, sá di Allāhu. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Olùríran.
|
Ayah 40:57 الأية
لَخَلْقُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ أَكْبَرُ مِنْ خَلْقِ النَّاسِ وَلَٰكِنَّ
أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يَعْلَمُونَ
Lakhalqu assamawati wal-ardiakbaru min khalqi annasi walakinna aktharaannasi la
yaAAlamoon
Yoruba
Dájúdájú ìṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ tóbi ju ìṣẹ̀dá àwọn ènìyàn; ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn ni kò mọ̀.
|
Ayah 40:58 الأية
وَمَا يَسْتَوِي الْأَعْمَىٰ وَالْبَصِيرُ وَالَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا
الصَّالِحَاتِ وَلَا الْمُسِيءُ ۚ قَلِيلًا مَّا تَتَذَكَّرُونَ
Wama yastawee al-aAAma walbaseeruwallatheena amanoo waAAamiloo assalihatiwala
almusee-o qaleelan ma tatathakkaroon
Yoruba
Afọ́jú àti olùríran kò dọ́gba. Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere àti oníṣẹ́-aburú (kò dọ́gba). Díẹ̀ l'ẹ̀ ń lò nínú ìrántí.
|
Ayah 40:59 الأية
إِنَّ السَّاعَةَ لَآتِيَةٌ لَّا رَيْبَ فِيهَا وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا
يُؤْمِنُونَ
Inna assaAAata laatiyatunla rayba feeha walakinna akthara annasila yu/minoon
Yoruba
Dájúdájú Àkókò náà ń bọ̀, kò sì sí iyèméjì nínú rẹ̀. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn ni kò gbàgbọ́.
|
Ayah 40:60 الأية
وَقَالَ رَبُّكُمُ ادْعُونِي أَسْتَجِبْ لَكُمْ ۚ إِنَّ الَّذِينَ يَسْتَكْبِرُونَ
عَنْ عِبَادَتِي سَيَدْخُلُونَ جَهَنَّمَ دَاخِرِينَ
Waqala rabbukumu odAAoonee astajiblakum inna allatheena yastakbiroona AAan
AAibadateesayadkhuloona jahannama dakhireen
Yoruba
Olúwa yín sọ pé: "Ẹ pè Mí, kí N̄g jẹ́pè yín. Dájúdájú àwọn tó ń ṣègbéraga nípa jíjọ́sìn fún Mi, wọn yóò wọ inú iná Jahanamọ ní ẹni yẹpẹrẹ."
|
Ayah 40:61 الأية
اللهُ الَّذِي جَعَلَ لَكُمُ اللَّيْلَ لِتَسْكُنُوا فِيهِ وَالنَّهَارَ
مُبْصِرًا ۚ إِنَّ اللهَ لَذُو فَضْلٍ عَلَى النَّاسِ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَ
النَّاسِ لَا يَشْكُرُونَ
Allahu allathee jaAAala lakumuallayla litaskunoo feehi wannahara mubsiraninna
Allaha lathoo fadlin AAala annasiwalakinna akthara annasi layashkuroon
Yoruba
Allāhu ni Ẹni tí Ó ṣe òru fún yín nítorí kí ẹ lè sinmi nínú rẹ̀. (Ó sì ṣe) ọ̀sán (nítorí kí ẹ lè fi) ríran. Dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́lá-jùlọ lórí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kì í dúpẹ́ (fún Un).
|
Ayah 40:62 الأية
ذَٰلِكُمُ اللهُ رَبُّكُمْ خَالِقُ كُلِّ شَيْءٍ لَّا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ۖ
فَأَنَّىٰ تُؤْفَكُونَ
Thalikumu Allahu rabbukum khaliqukulli shay-in la ilaha illa huwa
faannatu/fakoon
Yoruba
Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín, Ẹlẹ́dàá gbogbo n̄ǹkan. Kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ yín lórí kúrò níbi òdodo?
|
Ayah 40:63 الأية
كَذَٰلِكَ يُؤْفَكُ الَّذِينَ كَانُوا بِآيَاتِ اللهِ يَجْحَدُونَ
Kathalika yu/faku allatheena kanoobi-ayati Allahi yajhadoon
Yoruba
Báyẹn náà ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́ àwọn tó ń tako àwọn āyah Allāhu lórí kúrò níbi òdodo (ṣíwájú tiwọn).
|
Ayah 40:64 الأية
اللهُ الَّذِي جَعَلَ لَكُمُ الْأَرْضَ قَرَارًا وَالسَّمَاءَ بِنَاءً
وَصَوَّرَكُمْ فَأَحْسَنَ صُوَرَكُمْ وَرَزَقَكُم مِّنَ الطَّيِّبَاتِ ۚ ذَٰلِكُمُ
اللهُ رَبُّكُمْ ۖ فَتَبَارَكَ اللهُ رَبُّ الْعَالَمِينَ
Allahu allathee jaAAala lakumual-arda qararan wassamaa binaanwasawwarakum
faahsana suwarakum warazaqakummina attayyibati thalikumu Allahurabbukum
fatabaraka Allahu rabbu alAAalameen
Yoruba
Allāhu ni Ẹni tí Ó ṣe ilẹ̀ fún yín ní ibùgbé. Ó sì ṣe sánmọ̀ ní àjà (le yín lórí). Ó ya àwòrán yín. Ó sì ya àwòrán yín dáradára. Ó pèsè arísìkí fún yín nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa. Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín. Nítorí náà, mímọ́ ni fún Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
|
Ayah 40:65 الأية
هُوَ الْحَيُّ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ فَادْعُوهُ مُخْلِصِينَ لَهُ الدِّينَ ۗ
الْحَمْدُ لِلَّهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ
Huwa alhayyu la ilahailla huwa fadAAoohu mukhliseena lahu addeenaalhamdu lillahi
rabbi alAAalameen
Yoruba
Òun ni Alààyè. Kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Nítorí náà, ẹ pè É lẹ́ni tí yóò máa fi àfọ̀mọ́-ọkàn (àníyàn mímọ́) ṣe ẹ̀sìn fún Un. Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
|
Ayah 40:66 الأية
قُلْ إِنِّي نُهِيتُ أَنْ أَعْبُدَ الَّذِينَ تَدْعُونَ مِن دُونِ اللهِ لَمَّا
جَاءَنِيَ الْبَيِّنَاتُ مِن رَّبِّي وَأُمِرْتُ أَنْ أُسْلِمَ لِرَبِّ
الْعَالَمِينَ
Qul innee nuheetu an aAAbuda allatheenatadAAoona min dooni Allahi lamma
jaaniyaalbayyinatu min rabbee waomirtu an oslima lirabbi alAAalameen
Yoruba
Sọ pé: "Dájúdájú Wọ́n kọ̀ fún mi pé kí n̄g jọ́sìn fún àwọn tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu, nígbà tí àwọn ẹ̀rí tó yanjú ti dé bá mi láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi, tí wọ́n sì pa mí ní àṣẹ pé kí n̄g juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ (kí n̄g jẹ́ mùsùlùmí) fún Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
|
Ayah 40:67 الأية
هُوَ الَّذِي خَلَقَكُم مِّن تُرَابٍ ثُمَّ مِن نُّطْفَةٍ ثُمَّ مِنْ عَلَقَةٍ
ثُمَّ يُخْرِجُكُمْ طِفْلًا ثُمَّ لِتَبْلُغُوا أَشُدَّكُمْ ثُمَّ لِتَكُونُوا
شُيُوخًا ۚ وَمِنكُم مَّن يُتَوَفَّىٰ مِن قَبْلُ ۖ وَلِتَبْلُغُوا أَجَلًا
مُّسَمًّى وَلَعَلَّكُمْ تَعْقِلُونَ
Huwa allathee khalaqakum min turabinthumma min nutfatin thumma min AAalaqatin
thummayukhrijukum tiflan thumma litablughoo ashuddakum thummalitakoonoo
shuyookhan waminkum man yutawaffa min qabluwalitablughoo ajalan musamman
walaAAallakum taAAqiloon
Yoruba
Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín láti inú erùpẹ̀, lẹ́yìn náà láti inú àtọ̀, lẹ́yìn náà láti inú ẹ̀jẹ̀ dídì, lẹ́yìn náà Ó mu yín jáde ní òpóǹló. Lẹ́yìn náà, (Ó da yín sí) nítorí kí ẹ lè sánn̄gun dópin agbára yín. Lẹ́yìn náà (Ó tún da yín sí) nítorí kí ẹ lè di àgbàlágbà. Ó wà nínú yín ẹni tí A óò ti gba ẹ̀mí rẹ̀ ṣíwájú (ipò àgbà). Àti pé (Ó da yín sí) nítorí kí ẹ lè dàgbà dé gbèdéke àkókò kan àti nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè.
|
Ayah 40:68 الأية
هُوَ الَّذِي يُحْيِي وَيُمِيتُ ۖ فَإِذَا قَضَىٰ أَمْرًا فَإِنَّمَا يَقُولُ لَهُ
كُن فَيَكُونُ
Huwa allathee yuhyee wayumeetufa-itha qada amran fa-innama yaqoolu lahukun
fayakoon
Yoruba
Òun ni Ẹni tí ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Nígbà tí Ó bá sì pèbùbù kiní kan, Ó kàn máa sọ fún un pé: "Jẹ́ bẹ́ẹ̀." Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀.
|
Ayah 40:69 الأية
أَلَمْ تَرَ إِلَى الَّذِينَ يُجَادِلُونَ فِي آيَاتِ اللهِ أَنَّىٰ يُصْرَفُونَ
Alam tara ila allatheena yujadiloonafee ayati Allahi anna yusrafoon
Yoruba
Ṣé o kò wòye sí àwọn tí ń ṣàríyànjiyàn nípa àwọn āyah Allāhu bí wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo!
|
Ayah 40:70 الأية
الَّذِينَ كَذَّبُوا بِالْكِتَابِ وَبِمَا أَرْسَلْنَا بِهِ رُسُلَنَا ۖ فَسَوْفَ
يَعْلَمُونَ
Allatheena kaththaboo bilkitabiwabima arsalna bihi rusulana fasawfayaAAlamoon
Yoruba
Àwọn tó pe Tírà náà àti ohun tí A fi rán àwọn Òjíṣẹ́ Wa níṣẹ́ ní irọ́, láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀.
|
Ayah 40:71 الأية
إِذِ الْأَغْلَالُ فِي أَعْنَاقِهِمْ وَالسَّلَاسِلُ يُسْحَبُونَ
Ithi al-aghlalu fee aAAnaqihimwassalasilu yushaboon
Yoruba
Nígbà tí àwọn sẹ́kẹ́sẹkẹ̀ àti ẹ̀wọ̀n bá wà ní ọrùn wọn, tí wọn yóò fi máa wọ́ wọn
|
Ayah 40:72 الأية
فِي الْحَمِيمِ ثُمَّ فِي النَّارِ يُسْجَرُونَ
Fee alhameemi thumma fee annariyusjaroon
Yoruba
Sínú omi tó gbóná parí. Lẹ́yìn náà, wọn yóò fi wọ́n ko Iná.
|
Ayah 40:73 الأية
ثُمَّ قِيلَ لَهُمْ أَيْنَ مَا كُنتُمْ تُشْرِكُونَ
Thumma qeela lahum ayna ma kuntumtushrikoon
Yoruba
Lẹ́yìn náà, wọ́n máa sọ fún wọn pé: "Ibo ni ohun tí ẹ sọ di òrìṣà wà?"
|
Ayah 40:74 الأية
مِن دُونِ اللهِ ۖ قَالُوا ضَلُّوا عَنَّا بَل لَّمْ نَكُن نَّدْعُو مِن قَبْلُ
شَيْئًا ۚ كَذَٰلِكَ يُضِلُّ اللهُ الْكَافِرِينَ
Min dooni Allahi qaloo dallooAAanna bal lam nakun nadAAoo min qablu shay-an
kathalikayudillu Allahu alkafireen
Yoruba
"(Ohun tí ẹ jọ́sìn fún) lẹ́yìn Allāhu (dà)?" Wọ́n á wí pé: "Wọ́n ti di òfò mọ́ wa lọ́wọ́. Bẹ́ẹ̀ tiẹ̀ kọ́, àwa kì í pe n̄ǹkan kan tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀." Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣi àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́nà.
|
Ayah 40:75 الأية
ذَٰلِكُم بِمَا كُنتُمْ تَفْرَحُونَ فِي الْأَرْضِ بِغَيْرِ الْحَقِّ وَبِمَا
كُنتُمْ تَمْرَحُونَ
Thalikum bima kuntum tafrahoonafee al-ardi bighayri alhaqqi wabima
kuntumtamrahoon
Yoruba
Ìyẹn nítorí pé ẹ̀ ń yọ lórí ilẹ̀ ní ọ̀nà àìtọ́ àti nítorí pé, ẹ̀ ń ṣe fáàrí (lórí àìgbàgbọ́).
|
Ayah 40:76 الأية
ادْخُلُوا أَبْوَابَ جَهَنَّمَ خَالِدِينَ فِيهَا ۖ فَبِئْسَ مَثْوَى
الْمُتَكَبِّرِينَ
Odkhuloo abwaba jahannama khalideenafeeha fabi/sa mathwa almutakabbireen
Yoruba
Ẹ wọ àwọn ẹnu ọ̀na iná Jahanamọ; olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ó sì burú ní ibùgbé fún àwọn onígbèéraga.
|
Ayah 40:77 الأية
فَاصْبِرْ إِنَّ وَعْدَ اللهِ حَقٌّ ۚ فَإِمَّا نُرِيَنَّكَ بَعْضَ الَّذِي
نَعِدُهُمْ أَوْ نَتَوَفَّيَنَّكَ فَإِلَيْنَا يُرْجَعُونَ
Fasbir inna waAAda Allahihaqqun fa-imma nuriyannaka baAAda allatheenaAAiduhum aw
natawaffayannaka fa-ilayna yurjaAAoon
Yoruba
Nítorí náà, ṣe sùúrù. Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Ó ṣeé ṣe kí A fi apá kan èyí tí A ṣe ní ìlérí fún wọn hàn ọ́ tàbí kí A ti gba ẹ̀mí rẹ (ṣíwájú àsìkò náà). Ọ̀dọ̀ Wa kúkú ni wọ́n máa dá wọn padà sí.
|
Ayah 40:78 الأية
وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا رُسُلًا مِّن قَبْلِكَ مِنْهُم مَّن قَصَصْنَا عَلَيْكَ
وَمِنْهُم مَّن لَّمْ نَقْصُصْ عَلَيْكَ ۗ وَمَا كَانَ لِرَسُولٍ أَن يَأْتِيَ
بِآيَةٍ إِلَّا بِإِذْنِ اللهِ ۚ فَإِذَا جَاءَ أَمْرُ اللهِ قُضِيَ بِالْحَقِّ
وَخَسِرَ هُنَالِكَ الْمُبْطِلُونَ
Walaqad arsalna rusulan min qablikaminhum man qasasna AAalayka waminhum man
lamnaqsus AAalayka wama kana lirasoolinan ya/tiya bi-ayatin illa bi-ithni
Allahifa-itha jaa amru Allahi qudiya bilhaqqiwakhasira hunalika almubtiloon
Yoruba
Àti pé A kúkú ti rán àwọn Òjísẹ́ níṣẹ́ ṣíwájú rẹ. Àwọn tí A sọ ìtàn wọn fún ọ wà nínú wọn. Àwọn tí A kò sọ ìtàn wọn fún ọ wà nínú wọn. Àti pé kò tọ́ fún Òjísẹ́ kan láti mú àmì kan wá àyàfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Nígbà tí àṣẹ Allāhu bá sì dé, A máa fi òdodo dájọ́. Àwọn òpùrọ́ sì máa ṣòfò dànù níbẹ̀ yẹn.
|
Ayah 40:79 الأية
اللهُ الَّذِي جَعَلَ لَكُمُ الْأَنْعَامَ لِتَرْكَبُوا مِنْهَا وَمِنْهَا
تَأْكُلُونَ
Allahu allathee jaAAala lakumual-anAAama litarkaboo minha waminhata/kuloon
Yoruba
Allāhu ni Ẹni tí Ó dá àwọn ẹran-ọ̀sìn fún yín nítorí kí ẹ lè máa gùn nínú wọn. Ẹ ó sì máa jẹ nínú wọn.
|
Ayah 40:80 الأية
وَلَكُمْ فِيهَا مَنَافِعُ وَلِتَبْلُغُوا عَلَيْهَا حَاجَةً فِي صُدُورِكُمْ
وَعَلَيْهَا وَعَلَى الْفُلْكِ تُحْمَلُونَ
Walakum feeha manafiAAuwalitablughoo AAalayha hajatan fee sudoorikumwaAAalayha
waAAala alfulki tuhmaloon
Yoruba
Àwọn àǹfààní (mìíràn) wà fún yín lára ẹran-ọ̀sìn. Àti nítorí kí ẹ lè dé ọ̀nà jíjìn tó wà lọ́kàn yín lórí (gígùn) wọ́n (kiri). Ẹ sì ń fi àwọn (ẹran-ọ̀sìn) àti ọkọ̀ ojú-omi gbé àwọn ẹrù.
|
Ayah 40:81 الأية
وَيُرِيكُمْ آيَاتِهِ فَأَيَّ آيَاتِ اللهِ تُنكِرُونَ
Wayureekum ayatihi faayya ayatiAllahi tunkiroon
Yoruba
(Allāhu) ń fi àwọn àmì Rẹ̀ hàn yín. Nítorí náà, èwo nínú àwọn àmì Allāhu l'ẹ máa takò?
|
Ayah 40:82 الأية
أَفَلَمْ يَسِيرُوا فِي الْأَرْضِ فَيَنظُرُوا كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الَّذِينَ
مِن قَبْلِهِمْ ۚ كَانُوا أَكْثَرَ مِنْهُمْ وَأَشَدَّ قُوَّةً وَآثَارًا فِي
الْأَرْضِ فَمَا أَغْنَىٰ عَنْهُم مَّا كَانُوا يَكْسِبُونَ
Afalam yaseeroo fee al-ardi fayanthurookayfa kana AAaqibatu allatheena min
qablihimkanoo akthara minhum waashadda quwwatan waatharanfee al-ardi fama aghna
AAanhum ma kanooyaksiboon
Yoruba
Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe rí? Wọ́n pọ̀ (ní òǹkà) jù wọ́n lọ. Wọ́n ní agbára jù wọ́n lọ. Wọ́n sì lo ilẹ̀(fún oko dídá jù wọ́n lọ). Síbẹ̀síbẹ̀ ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ (níbi ìyà).
|
Ayah 40:83 الأية
فَلَمَّا جَاءَتْهُمْ رُسُلُهُم بِالْبَيِّنَاتِ فَرِحُوا بِمَا عِندَهُم مِّنَ
الْعِلْمِ وَحَاقَ بِهِم مَّا كَانُوا بِهِ يَسْتَهْزِئُونَ
Falamma jaat-hum rusuluhum bilbayyinatifarihoo bima AAindahum mina alAAilmi
wahaqabihim ma kanoo bihi yastahzi-oon
Yoruba
Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ wọn mú àwọn ẹ̀rí tó yanjú wá bá wọn, wọ́n yọ àyọ̀pọ̀rọ́ nítorí ohun tó wà lọ́dọ̀ wọn nínú ìmọ̀ (ayé). Ohun tí wọ́n sì ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì dìyà tó yí wọn po.
|
Ayah 40:84 الأية
فَلَمَّا رَأَوْا بَأْسَنَا قَالُوا آمَنَّا بِاللهِ وَحْدَهُ وَكَفَرْنَا بِمَا
كُنَّا بِهِ مُشْرِكِينَ
Falamma raaw ba/sana qalooamanna billahi wahdahuwakafarna bima kunna bihi
mushrikeen
Yoruba
Nígbà tí wọ́n rí ìyà Wa, wọ́n wí pé: "A gbàgbọ́ nínú Allāhu nìkan ṣoṣo. A sì lòdì sí n̄ǹkan tí a sọ di akẹgbẹ́ fún Un."
|
Ayah 40:85 الأية
فَلَمْ يَكُ يَنفَعُهُمْ إِيمَانُهُمْ لَمَّا رَأَوْا بَأْسَنَا ۖ سُنَّتَ اللهِ
الَّتِي قَدْ خَلَتْ فِي عِبَادِهِ ۖ وَخَسِرَ هُنَالِكَ الْكَافِرُونَ
Falam yaku yanfaAAuhum eemanuhum lammaraaw ba/sana sunnata Allahi allatee qad
khalat feeAAibadihi wakhasira hunalika alkafiroon
Yoruba
Ìgbàgbọ́ wọn kò sì ṣe wọ́n ní àǹfààní nígbà tí wọ́n rí ìyà Wa. Ìṣe Allāhu, èyí tí ó ti ṣẹlẹ̀ ṣíwájú sí àwọn ẹrú Rẹ̀ (ni èyí). Àwọn aláìgbàgbọ́ sì ṣòfò dànù níbẹ̀ yẹn.
|
©
EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us
|