1st Ayah 1 الأية ١الأوليبِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
حم
Ha-meem
Yoruba
Hā mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)
|
Ayah 43:2 الأية
وَالْكِتَابِ الْمُبِينِ
Walkitabi almubeen
Yoruba
(Allāhu) fi Tírà tó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá búra.
|
Ayah 43:3 الأية
إِنَّا جَعَلْنَاهُ قُرْآنًا عَرَبِيًّا لَّعَلَّكُمْ تَعْقِلُونَ
Inna jaAAalnahu qur-ananAAarabiyyan laAAallakum taAAqiloona
Yoruba
Dájúdájú Àwa se é ní al-Ƙur'ān (n̄ǹkan kíké) ní èdè Lárúbáwá nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè.
|
Ayah 43:4 الأية
وَإِنَّهُ فِي أُمِّ الْكِتَابِ لَدَيْنَا لَعَلِيٌّ حَكِيمٌ
Wa-innahu fee ommi alkitabi ladaynalaAAaliyyun hakeem
Yoruba
Àti pé dájúdájú nínú Tírà Ìpìlẹ̀ tó wà lọ́dọ̀ Wa, al-Ƙur'ān mà ga, ó sì kún fún ọgbọ́n.
|
Ayah 43:5 الأية
أَفَنَضْرِبُ عَنكُمُ الذِّكْرَ صَفْحًا أَن كُنتُمْ قَوْمًا مُّسْرِفِينَ
Afanadribu AAankumu aththikrasafhan an kuntum qawman musrifeen
Yoruba
Ṣé kí Á ká Tírà Ìrántí (al-Ƙur'ān) kúrò nílẹ̀ fún yín pátápátá (kí Á máa wò yín ní ìran) nítorí pé, ẹ jẹ́ ìjọ alákọyọ?
|
Ayah 43:6 الأية
وَكَمْ أَرْسَلْنَا مِن نَّبِيٍّ فِي الْأَوَّلِينَ
Wakam arsalna min nabiyyin feeal-awwaleen
Yoruba
Mélòó mélòó nínú àwọn Ànábì tí A ti rán sí àwọn ẹni àkọ́kọ́.
|
Ayah 43:7 الأية
وَمَا يَأْتِيهِم مِّن نَّبِيٍّ إِلَّا كَانُوا بِهِ يَسْتَهْزِئُونَ
Wama ya/teehim min nabiyyin illakanoo bihi yastahzi-oon
Yoruba
Kò sí Ànábì kan tí ó wá bá wọn àyàfi kí wọ́n máa fi ṣe yẹ̀yẹ́.
|
Ayah 43:8 الأية
فَأَهْلَكْنَا أَشَدَّ مِنْهُم بَطْشًا وَمَضَىٰ مَثَلُ الْأَوَّلِينَ
Faahlakna ashadda minhum batshanwamada mathalu al-awwaleen
Yoruba
Nítorí náà, A ti pa àwọn tó ní agbára ju àwọn (wọ̀nyí) rẹ́. Àpèjúwe (ìparun) àwọn ẹni àkọ́kọ́ sì ti ṣíwájú.
|
Ayah 43:9 الأية
وَلَئِن سَأَلْتَهُم مَّنْ خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ لَيَقُولُنَّ
خَلَقَهُنَّ الْعَزِيزُ الْعَلِيمُ
Wala-in saaltahum man khalaqa assamawatiwal-arda layaqoolunna khalaqahunna
alAAazeezualAAaleem
Yoruba
Tí o bá kúkú bi wọ́n léèrè pé: "Ta ni Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀?", dájúdájú wọ́n á wí pé: "Ẹni tó dá wọn ni Alágbára, Onímọ̀;
|
Ayah 43:10 الأية
الَّذِي جَعَلَ لَكُمُ الْأَرْضَ مَهْدًا وَجَعَلَ لَكُمْ فِيهَا سُبُلًا
لَّعَلَّكُمْ تَهْتَدُونَ
Allathee jaAAala lakumu al-ardamahdan wajaAAala lakum feeha subulan laAAallakum
tahtadoon
Yoruba
Ẹni tí Ó ṣe ilẹ̀ ní ìtẹ́ fún yín. Ó sì fi àwọn ojú ọ̀nà sínú rẹ̀ fún yín nítorí kí ẹ lè mọ̀nà;
|
Ayah 43:11 الأية
وَالَّذِي نَزَّلَ مِنَ السَّمَاءِ مَاءً بِقَدَرٍ فَأَنشَرْنَا بِهِ بَلْدَةً
مَّيْتًا ۚ كَذَٰلِكَ تُخْرَجُونَ
Wallathee nazzala mina assama-imaan biqadarin faansharna bihi baldatan maytan
kathalikatukhrajoon
Yoruba
Ẹni tí Ó ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀ níwọ̀n-níwọ̀n. Ó sì ń fi sọ òkú ilẹ̀ di àyè ilẹ̀. Báyẹn náà ni wọn yóò ṣe mu yín jáde.
|
Ayah 43:12 الأية
وَالَّذِي خَلَقَ الْأَزْوَاجَ كُلَّهَا وَجَعَلَ لَكُم مِّنَ الْفُلْكِ
وَالْأَنْعَامِ مَا تَرْكَبُونَ
Wallathee khalaqa al-azwajakullaha wajaAAala lakum mina alfulki wal-anAAamima
tarkaboon
Yoruba
Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá gbogbo n̄ǹkan ní oríṣiríṣi. Ó sì ṣe n̄ǹkan tí ẹ̀ ń gùn fún yín láti ara àwọn ọkọ̀ ojú-omi àti àwọn ẹran-ọ̀sìn.
|
Ayah 43:13 الأية
لِتَسْتَوُوا عَلَىٰ ظُهُورِهِ ثُمَّ تَذْكُرُوا نِعْمَةَ رَبِّكُمْ إِذَا
اسْتَوَيْتُمْ عَلَيْهِ وَتَقُولُوا سُبْحَانَ الَّذِي سَخَّرَ لَنَا هَٰذَا وَمَا
كُنَّا لَهُ مُقْرِنِينَ
Litastawoo AAala thuhoorihithumma tathkuroo niAAmata rabbikum itha
istawaytumAAalayhi wataqooloo subhana allathee sakhkhara lanahatha wama kunna
lahu muqrineen
Yoruba
Nítorí kí ẹ lè jókòó dáadáa sẹ́yìn rẹ̀, lẹ́yìn náà kí ẹ lè ṣe ìrántí ìdẹ̀ra Olúwa yín nígbà tí ẹ bá jókòó dáadáa tán sórí rẹ̀, kí ẹ sì sọ pé: "Mímọ́ ni fún Ẹni tí Ó rọ èyí fún wa, kì í ṣe pé a jẹ́ alágbára lórí rẹ̀.
|
Ayah 43:14 الأية
وَإِنَّا إِلَىٰ رَبِّنَا لَمُنقَلِبُونَ
Wa-inna ila rabbinalamunqaliboon
Yoruba
Àti pé dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa wa ni àwa yóò padà sí."
|
Ayah 43:15 الأية
وَجَعَلُوا لَهُ مِنْ عِبَادِهِ جُزْءًا ۚ إِنَّ الْإِنسَانَ لَكَفُورٌ مُّبِينٌ
WajaAAaloo lahu min AAibadihi juz-aninna al-insana lakafoorun mubeen
Yoruba
Wọ́n fi ìpín kan nínú àwọn ẹrúsìn (Allāhu) tì sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ (ní ti ọmọ bíbí). Dájúdájú ènìyàn ni aláìmoore pọ́nńbélé.
|
Ayah 43:16 الأية
أَمِ اتَّخَذَ مِمَّا يَخْلُقُ بَنَاتٍ وَأَصْفَاكُم بِالْبَنِينَ
Ami ittakhatha mimma yakhluqubanatin waasfakum bilbaneen
Yoruba
Tàbí (ẹ̀yin ń wí pé): "Ó mú nínú n̄ǹkan tí Ó dá ní ọmọbìnrin (fúnra Rẹ̀). Ó sì fi àwọn ọmọkùnrin ṣa ẹ̀yin lẹ́ṣà."
|
Ayah 43:17 الأية
وَإِذَا بُشِّرَ أَحَدُهُم بِمَا ضَرَبَ لِلرَّحْمَٰنِ مَثَلًا ظَلَّ وَجْهُهُ
مُسْوَدًّا وَهُوَ كَظِيمٌ
Wa-itha bushshira ahaduhum bimadaraba lirrahmani mathalan thallawajhuhu
muswaddan wahuwa katheem
Yoruba
Nígbà tí wọ́n bá fún ẹnì kan nínú wọn ní ìró ìdùnnú ohun tí ó fi ṣe àpẹ̀ẹrẹ fún Àjọkẹ́-ayé, ojú rẹ̀ máa dúdú wá (pé òun bí ọmọbìnrin). Ó sì máa kún fún ìbànújẹ́.
|
Ayah 43:18 الأية
أَوَمَن يُنَشَّأُ فِي الْحِلْيَةِ وَهُوَ فِي الْخِصَامِ غَيْرُ مُبِينٍ
Awaman yunashshao fee alhilyatiwahuwa fee alkhisami ghayru mubeen
Yoruba
Ṣé ẹni tí wọ́n ń tọ́ nínú ọ̀ṣọ́ (tí ó ń to ọ̀ṣọ́ mọ́ra), tí kò sì lè bọ́ sí gban̄gba níbi ìjà (ni ẹ̀ ń pè ní ọmọ Àjọkẹ́-ayé)!?
|
Ayah 43:19 الأية
وَجَعَلُوا الْمَلَائِكَةَ الَّذِينَ هُمْ عِبَادُ الرَّحْمَٰنِ إِنَاثًا ۚ
أَشَهِدُوا خَلْقَهُمْ ۚ سَتُكْتَبُ شَهَادَتُهُمْ وَيُسْأَلُونَ
WajaAAaloo almala-ikata allatheenahum AAibadu arrahmani inathanashahidoo
khalqahum satuktabu shahadatuhum wayus-aloon
Yoruba
Àwọn mọlāika, àwọn tó jẹ́ ẹrúsìn Àjọkẹ́-ayé, wọ́n tún sọ wọ́n di ọmọbìnrin! Ṣé wọ́n fojú rí ìṣẹ̀dá wọn ni? Wọ́n máa ṣàkọsílẹ̀ ohun tí wọ́n fojú rí. Wọ́n sì máa bi wọ́n léèrè (nípa rẹ̀).
|
Ayah 43:20 الأية
وَقَالُوا لَوْ شَاءَ الرَّحْمَٰنُ مَا عَبَدْنَاهُم ۗ مَّا لَهُم بِذَٰلِكَ مِنْ
عِلْمٍ ۖ إِنْ هُمْ إِلَّا يَخْرُصُونَ
Waqaloo law shaa arrahmanuma AAabadnahum ma lahum bithalika minAAilmin in hum
illa yakhrusoon
Yoruba
Wọ́n tún wí pé: "Tí Àjọkẹ́-ayé bá fẹ́, àwa ìbá tí jọ́sìn fún wọn." Kò sí ìmọ̀ kan fún wọn nípa ìyẹn. Wọn kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe pé wọ́n ń parọ́.
|
Ayah 43:21 الأية
أَمْ آتَيْنَاهُمْ كِتَابًا مِّن قَبْلِهِ فَهُم بِهِ مُسْتَمْسِكُونَ
Am ataynahum kitabanmin qablihi fahum bihi mustamsikoon
Yoruba
Tàbí A ti fún wọn ní Tírà kan ṣíwájú al-Ƙur'ān, tí wọ́n ń lò ní ẹ̀rí?
|
Ayah 43:22 الأية
بَلْ قَالُوا إِنَّا وَجَدْنَا آبَاءَنَا عَلَىٰ أُمَّةٍ وَإِنَّا عَلَىٰ آثَارِهِم
مُّهْتَدُونَ
Bal qaloo inna wajadna abaanaAAala ommatin wa-inna AAala atharihimmuhtadoon
Yoruba
Rárá. Wọ́n wí pé: "Dájúdájú àwa bá àwọn bàbá wa lórí ẹ̀sìn kan. Dájúdájú àwa sì ni olùmọ̀nà lórí orípa wọn."
|
Ayah 43:23 الأية
وَكَذَٰلِكَ مَا أَرْسَلْنَا مِن قَبْلِكَ فِي قَرْيَةٍ مِّن نَّذِيرٍ إِلَّا قَالَ
مُتْرَفُوهَا إِنَّا وَجَدْنَا آبَاءَنَا عَلَىٰ أُمَّةٍ وَإِنَّا عَلَىٰ آثَارِهِم
مُّقْتَدُونَ
Wakathalika ma arsalnamin qablika fee qaryatin min natheerin illa qalamutrafooha
inna wajadna abaanaAAala ommatin wa-inna AAala atharihimmuqtadoon
Yoruba
Bákan náà, Àwa kò rán olùkìlọ̀ kan sí ìlú kan ṣíwájú rẹ, àyàfi kí àwọn onígbẹdẹmukẹ ìlú náà wí pé: "Dájúdájú àwa bá àwọn bàbá wa lórí ẹ̀sìn kan. Dájúdájú àwa sì ni olùtẹ̀lé wọn lórí orípa wọn."
|
Ayah 43:24 الأية
قَالَ أَوَلَوْ جِئْتُكُم بِأَهْدَىٰ مِمَّا وَجَدتُّمْ عَلَيْهِ آبَاءَكُمْ ۖ
قَالُوا إِنَّا بِمَا أُرْسِلْتُم بِهِ كَافِرُونَ
Qala awa law ji/tukum bi-ahdamimma wajadtum AAalayhi abaakum qalooinna bima
orsiltum bihi kafiroon
Yoruba
(Olùkìlọ̀) sì sọ pé: "Ǹjẹ́ èmi kò ti mú wá fún yín ohun tí ó jẹ́ ìmọ̀nà jùlọ sí ohun tí ẹ bá àwọn bàbá yín lórí rẹ̀?" Wọ́n wí pé: "Dájúdájú àwa jẹ́ aláìgbàgbọ́ nínú ohun tí wọ́n fi ran yín níṣẹ́."
|
Ayah 43:25 الأية
فَانتَقَمْنَا مِنْهُمْ ۖ فَانظُرْ كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الْمُكَذِّبِينَ
Fantaqamna minhum fanthurkayfa kana AAaqibatu almukaththibeen
Yoruba
Nítorí náà, A gbẹ̀san lára wọn. Wo bí ìkángun àwọn tó pe òdodo ní irọ́ ti rí!
|
Ayah 43:26 الأية
وَإِذْ قَالَ إِبْرَاهِيمُ لِأَبِيهِ وَقَوْمِهِ إِنَّنِي بَرَاءٌ مِّمَّا
تَعْبُدُونَ
Wa-ith qala ibraheemuli-abeehi waqawmihi innanee baraon mimma taAAbudoon
Yoruba
(Rántí) nígbà tí (Ànábì) 'Ibrọ̄hīm sọ fún bàbá rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: "Dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ kúrò nínú ohun tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún.
|
Ayah 43:27 الأية
إِلَّا الَّذِي فَطَرَنِي فَإِنَّهُ سَيَهْدِينِ
Illa allathee fataraneefa-innahu sayahdeen
Yoruba
Àfi Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá mi. Dájúdájú Òun l'Ó máa fi ọ̀nà tààrà mọ̀ mí."
|
Ayah 43:28 الأية
وَجَعَلَهَا كَلِمَةً بَاقِيَةً فِي عَقِبِهِ لَعَلَّهُمْ يَرْجِعُونَ
WajaAAalaha kalimatan baqiyatanfee AAaqibihi laAAallahum yarjiAAoon
Yoruba
Allāhu sì ṣe é ní ọ̀rọ̀ kan tó máa wà títí láéláé láààrin àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (síbi òdodo).
|
Ayah 43:29 الأية
بَلْ مَتَّعْتُ هَٰؤُلَاءِ وَآبَاءَهُمْ حَتَّىٰ جَاءَهُمُ الْحَقُّ وَرَسُولٌ
مُّبِينٌ
Bal mattaAAtu haola-i waabaahumhatta jaahumu alhaqqu warasoolunmubeen
Yoruba
Ṣùgbọ́n Mo fún àwọn wọ̀nyí àti àwọn bàbá wọn ní ìgbádùn ayé títí òdodo àti Òjíṣẹ́ pọ́nńbélé fi dé bá wọn.
|
Ayah 43:30 الأية
وَلَمَّا جَاءَهُمُ الْحَقُّ قَالُوا هَٰذَا سِحْرٌ وَإِنَّا بِهِ كَافِرُونَ
Walamma jaahumu alhaqquqaloo hatha sihrun wa-inna bihi kafiroon
Yoruba
Nígbà tí òdodo dé bá wọn, wọ́n wí pé: "Idán ni èyí; dájúdájú àwa kò sì níí gbà á gbọ́."
|
Ayah 43:31 الأية
وَقَالُوا لَوْلَا نُزِّلَ هَٰذَا الْقُرْآنُ عَلَىٰ رَجُلٍ مِّنَ الْقَرْيَتَيْنِ
عَظِيمٍ
Waqaloo lawla nuzzila hathaalqur-anu AAala rajulin mina alqaryatayni AAatheem
Yoruba
Wọ́n tún wí pé: "Kí ni kò jẹ́ kí Wọ́n sọ al-Ƙur'ān yìí kalẹ̀ fún ọkùnrin ńlá kan nínú àwọn ìlú méjèèjì?"
|
Ayah 43:32 الأية
أَهُمْ يَقْسِمُونَ رَحْمَتَ رَبِّكَ ۚ نَحْنُ قَسَمْنَا بَيْنَهُم مَّعِيشَتَهُمْ
فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا ۚ وَرَفَعْنَا بَعْضَهُمْ فَوْقَ بَعْضٍ دَرَجَاتٍ
لِّيَتَّخِذَ بَعْضُهُم بَعْضًا سُخْرِيًّا ۗ وَرَحْمَتُ رَبِّكَ خَيْرٌ مِّمَّا
يَجْمَعُونَ
Ahum yaqsimoona rahmata rabbika nahnuqasamna baynahum maAAeeshatahum fee
alhayatiaddunya warafaAAna baAAdahum fawqabaAAdin darajatin liyattakhitha
baAAduhumbaAAdan sukhriyyan warahmatu rabbika khayrun mimmayajmaAAoon
Yoruba
Ṣé àwọn ni wọn máa pín ìkẹ́ Olúwa rẹ ni? Àwa l'A pín n̄ǹkan ìṣẹ̀mí wọn fún wọn nínú ìgbésí ayé. A sì fi àwọn ipò gíga gbé apá kan wọn ga ju apá kan lọ nítorí kí apá kan wọn lè máa ṣiṣẹ́ fún apá kan. Ìkẹ́ Olúwa rẹ sì lóore jùlọ sí ohun tí wọ́n ń kó jọ.
|
Ayah 43:33 الأية
وَلَوْلَا أَن يَكُونَ النَّاسُ أُمَّةً وَاحِدَةً لَّجَعَلْنَا لِمَن يَكْفُرُ
بِالرَّحْمَٰنِ لِبُيُوتِهِمْ سُقُفًا مِّن فِضَّةٍ وَمَعَارِجَ عَلَيْهَا
يَظْهَرُونَ
Walawla an yakoona annasuommatan wahidatan lajaAAalna liman yakfuru
birrahmanilibuyootihim suqufan min fiddatin wamaAAarijaAAalayha yathharoon
Yoruba
Tí kò bá jẹ́ pé àwọn ènìyàn máa di ìjọ kan ṣoṣo (tí gbogbo wọn máa di kèfèrí nítorí ọrọ̀ ayé), A ìbá ṣe àwọn òrùlé àti àwọn àkàbà tí wọn yóò fi máa gùnkè nínú ilé ní fàdákà fún ẹni tó ń ṣàì gbàgbọ́ nínú Àjọkẹ́-ayé.
|
Ayah 43:34 الأية
وَلِبُيُوتِهِمْ أَبْوَابًا وَسُرُرًا عَلَيْهَا يَتَّكِئُونَ
Walibuyootihim abwaban wasururanAAalayha yattaki-oon
Yoruba
(A ìbá tún ṣe) àwọn ẹnu ọ̀nà ilé wọn àti àwọn ibùsùn tí wọn yóò máa rọ̀gbọ̀kú lé lórí (ní fàdákà)
|
Ayah 43:35 الأية
وَزُخْرُفًا ۚ وَإِن كُلُّ ذَٰلِكَ لَمَّا مَتَاعُ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا ۚ
وَالْآخِرَةُ عِندَ رَبِّكَ لِلْمُتَّقِينَ
Wazukhrufan wa-in kullu thalika lammamataAAu alhayati addunya wal-akhiratuAAinda
rabbika lilmuttaqeen
Yoruba
Àti góòlù. Gbogbo n̄ǹkan wọ̀nyí kò jẹ́ n̄ǹkan kan bí kò ṣe ìgbádùn ìṣẹ̀mí ayé lásán. (Ọgbà Ìdẹ̀ra) Ọ̀run sì wà ní ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).
|
Ayah 43:36 الأية
وَمَن يَعْشُ عَن ذِكْرِ الرَّحْمَٰنِ نُقَيِّضْ لَهُ شَيْطَانًا فَهُوَ لَهُ
قَرِينٌ
Waman yaAAshu AAan thikri arrahmaninuqayyid lahu shaytanan fahuwa lahu qareen
Yoruba
Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbúnrí kúrò níbi ìrántí Àjọké-ayé, A máa yan èṣù kan fún un. Òun sì ni alábàárìn rẹ̀.
|
Ayah 43:37 الأية
وَإِنَّهُمْ لَيَصُدُّونَهُمْ عَنِ السَّبِيلِ وَيَحْسَبُونَ أَنَّهُم مُّهْتَدُونَ
Wa-innahum layasuddoonahum AAani assabeeliwayahsaboona annahum muhtadoon
Yoruba
Dájúdájú àwọn èṣù náà yóò máa ṣẹ́rí wọn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn Allāhu). Wọn yó sì máa lérò pé dájúdájú àwọn ni olùmọ̀nà.
|
Ayah 43:38 الأية
حَتَّىٰ إِذَا جَاءَنَا قَالَ يَا لَيْتَ بَيْنِي وَبَيْنَكَ بُعْدَ
الْمَشْرِقَيْنِ فَبِئْسَ الْقَرِينُ
Hatta itha jaanaqala ya layta baynee wabaynaka buAAda almashriqaynifabi/sa
alqareen
Yoruba
Títí di ìgbà tí ó fi máa wá bá Wa, ó sì máa wí pé: "Háà! Kí ó sì jẹ́ pé (ìtakété bí) ìtakété ibùyọ-òòrùn àti ibùwọ̀ rẹ̀ sì wà láààrin èmi àti ìwọ (èṣù alábàárìn yìí, ìbá dára); alábàárìn burúkú sì ni.
|
Ayah 43:39 الأية
وَلَن يَنفَعَكُمُ الْيَوْمَ إِذ ظَّلَمْتُمْ أَنَّكُمْ فِي الْعَذَابِ
مُشْتَرِكُونَ
Walan yanfaAAakumu alyawma ith thalamtumannakum fee alAAathabi mushtarikoon
Yoruba
(Àbámọ̀ yín) kò níí ṣe yín ní àǹfààní ní Òní nígbà tí ẹ ti ṣàbòsí. (Àti pé) dájúdájú ẹ̀yin (àti òrìṣà yín) ni ẹ dìjọ máa kẹ́gbẹ́ nínú ìyà.
|
Ayah 43:40 الأية
أَفَأَنتَ تُسْمِعُ الصُّمَّ أَوْ تَهْدِي الْعُمْيَ وَمَن كَانَ فِي ضَلَالٍ
مُّبِينٍ
Afaanta tusmiAAu assumma awtahdee alAAumya waman kana fee dalalinmubeen
Yoruba
Ṣé ìwọ l'o máa fún àwọn adití ní ọ̀rọ̀ gbọ́ tàbí o máa fún àwọn afọ́jú ní ìmọ̀nà àti ẹni tí ó wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé?
|
Ayah 43:41 الأية
فَإِمَّا نَذْهَبَنَّ بِكَ فَإِنَّا مِنْهُم مُّنتَقِمُونَ
Fa-imma nathhabanna bikafa-inna minhum muntaqimoon
Yoruba
Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kí Á ti mú ọ kúrò (lórí ilẹ̀ ayé ṣíwájú àsìkò ìyà wọn), dájúdájú Àwa yóò gbẹ̀san (ìyà) lára wọn.
|
Ayah 43:42 الأية
أَوْ نُرِيَنَّكَ الَّذِي وَعَدْنَاهُمْ فَإِنَّا عَلَيْهِم مُّقْتَدِرُونَ
Aw nuriyannaka allathee waAAadnahumfa-inna AAalayhim muqtadiroon
Yoruba
Tàbí kí Á fi ohun tí A ṣe ní ìlérí fún wọn hàn ọ́, dájúdájú Àwa jẹ́ Alágbára lórí wọn.
|
Ayah 43:43 الأية
فَاسْتَمْسِكْ بِالَّذِي أُوحِيَ إِلَيْكَ ۖ إِنَّكَ عَلَىٰ صِرَاطٍ مُّسْتَقِيمٍ
Fastamsik billatheeoohiya ilayka innaka AAala siratinmustaqeem
Yoruba
Nítorí náà, di ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ mú ṣinṣin. Dájúdájú ìwọ wà lójú ọ̀nà tààrà ('Islām).
|
Ayah 43:44 الأية
وَإِنَّهُ لَذِكْرٌ لَّكَ وَلِقَوْمِكَ ۖ وَسَوْفَ تُسْأَلُونَ
Wa-innahu lathikrun laka waliqawmikawasawfa tus-aloon
Yoruba
Dájúdájú al-Ƙur'ān ni tírà ìrántí fún ìwọ àti ìjọ rẹ. Láìpẹ́ wọ́n máa bi yín léèrè (nípa rẹ̀).
|
Ayah 43:45 الأية
وَاسْأَلْ مَنْ أَرْسَلْنَا مِن قَبْلِكَ مِن رُّسُلِنَا أَجَعَلْنَا مِن دُونِ
الرَّحْمَٰنِ آلِهَةً يُعْبَدُونَ
Was-al man arsalna minqablika min rusulina ajaAAalna min dooni arrahmanialihatan
yuAAbadoon
Yoruba
Bèèrè wò lọ́wọ́ àwọn tí A rán níṣẹ́ ṣíwájú rẹ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Wa (pé): "Ǹjẹ́ A sọ àwọn kan di ọlọ́hun tí wọn yóò máa jọ́sìn fún lẹ́yìn Àjọkẹ́-ayé bí?"
|
Ayah 43:46 الأية
وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا مُوسَىٰ بِآيَاتِنَا إِلَىٰ فِرْعَوْنَ وَمَلَئِهِ فَقَالَ
إِنِّي رَسُولُ رَبِّ الْعَالَمِينَ
Walaqad arsalna moosa bi-ayatinaila firAAawna wamala-ihi faqala innee rasoolu
rabbialAAalameen
Yoruba
A kúkú fi àwọn àmì Wa rán (Ànábì) Mūsā níṣẹ́ sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀. Ó sì sọ pé: "Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ Olúwa gbogbo ẹ̀dá."
|
Ayah 43:47 الأية
فَلَمَّا جَاءَهُم بِآيَاتِنَا إِذَا هُم مِّنْهَا يَضْحَكُونَ
Falamma jaahum bi-ayatinaitha hum minha yadhakoon
Yoruba
Ṣùgbọ́n nígbà tí ó mú àwọn àmì Wa wá bá wọn, ńṣe ni wọ́n ń fi àwọn àmì náà rẹ́rìn-ín nígbà náà.
|
Ayah 43:48 الأية
وَمَا نُرِيهِم مِّنْ آيَةٍ إِلَّا هِيَ أَكْبَرُ مِنْ أُخْتِهَا ۖ وَأَخَذْنَاهُم
بِالْعَذَابِ لَعَلَّهُمْ يَرْجِعُونَ
Wama nureehim min ayatin illahiya akbaru min okhtiha waakhathnahum
bilAAathabilaAAallahum yarjiAAoon
Yoruba
A kò níí fi àmì kan hàn wọ́n àyàfi kí ó tóbi ju irú rẹ̀ (tó ṣíwájú). A sì fi ìyà jẹ wọ́n nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (síbi òdodo).
|
Ayah 43:49 الأية
وَقَالُوا يَا أَيُّهَ السَّاحِرُ ادْعُ لَنَا رَبَّكَ بِمَا عَهِدَ عِندَكَ
إِنَّنَا لَمُهْتَدُونَ
Waqaloo ya ayyuha asahiruodAAu lana rabbaka bima AAahida AAindaka
innanalamuhtadoon
Yoruba
Wọ́n sì wí pé: "Ìwọ òpìdán, pe Olúwa rẹ fún wa nítorí àdéhùn tí Ó ṣe pẹ̀lú rẹ. Dájúdájú àwa máa tẹ̀lé ìmọ̀nà Rẹ̀."
|
Ayah 43:50 الأية
فَلَمَّا كَشَفْنَا عَنْهُمُ الْعَذَابَ إِذَا هُمْ يَنكُثُونَ
Falamma kashafna AAanhumualAAathaba itha hum yankuthoon
Yoruba
Ṣùgbọ́n nígbà tí A bá mú ìyà kúrò fún wọn, nígbà náà ni wọ́n tún ń yẹ àdéhùn.
|
Ayah 43:51 الأية
وَنَادَىٰ فِرْعَوْنُ فِي قَوْمِهِ قَالَ يَا قَوْمِ أَلَيْسَ لِي مُلْكُ مِصْرَ
وَهَٰذِهِ الْأَنْهَارُ تَجْرِي مِن تَحْتِي ۖ أَفَلَا تُبْصِرُونَ
Wanada firAAawnu fee qawmihi qalaya qawmi alaysa lee mulku misra
wahathihial-anharu tajree min tahtee afala tubsiroon
Yoruba
Fir‘aon sì pèpè láààrin àwọn ènìyàn rẹ̀, ó wí pé: "Ẹ̀yin ènìyàn mi, ṣé tèmi kọ́ ni ìjọba Misrọ àti àwọn odò wọ̀nyí tó ń ṣàn nísàlẹ̀ (ọ̀dọ̀) mi? Ṣé ẹ kò ríran ni?
|
Ayah 43:52 الأية
أَمْ أَنَا خَيْرٌ مِّنْ هَٰذَا الَّذِي هُوَ مَهِينٌ وَلَا يَكَادُ يُبِينُ
Am ana khayrun min hatha allatheehuwa maheenun wala yakadu yubeen
Yoruba
Tàbí ṣé èmi kò lóore ju èyí tí ó jẹ́ ọ̀lẹ ẹni yẹpẹrẹ, tí ó fẹ́ẹ̀ má lè dá ọ̀rọ̀ sọ yanjú?
|
Ayah 43:53 الأية
فَلَوْلَا أُلْقِيَ عَلَيْهِ أَسْوِرَةٌ مِّن ذَهَبٍ أَوْ جَاءَ مَعَهُ
الْمَلَائِكَةُ مُقْتَرِنِينَ
Falawla olqiya AAalayhi aswiratun minthahabin aw jaa maAAahu
almala-ikatumuqtarineen
Yoruba
Kí ni kò jẹ́ kí wọ́n fún un ní àwọn ẹ̀gbà-ọwọ́ góòlù tàbí (kí ni kò jẹ́ kí) àwọn mọlāika wá pẹ̀lú rẹ̀, kí wọ́n jẹ́ alábàárìn (tí wọn yóò máa jẹ́rìí rẹ̀)?"
|
Ayah 43:54 الأية
فَاسْتَخَفَّ قَوْمَهُ فَأَطَاعُوهُ ۚ إِنَّهُمْ كَانُوا قَوْمًا فَاسِقِينَ
Fastakhaffa qawmahu faataAAoohuinnahum kanoo qawman fasiqeen
Yoruba
Nítorí náà, ó sọ àwọn ènìyàn rẹ̀ di òpè. Wọ́n sì tẹ̀lé e. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.
|
Ayah 43:55 الأية
فَلَمَّا آسَفُونَا انتَقَمْنَا مِنْهُمْ فَأَغْرَقْنَاهُمْ أَجْمَعِينَ
Falamma asafoonaintaqamna minhum faaghraqnahum ajmaAAeen
Yoruba
Nígbà tí wọ́n wá ìbínú Wa, A gba ẹ̀san (ìyà) lára wọn. Nítorí náà, A tẹ gbogbo wọn rì (sínú agbami odò).
|
Ayah 43:56 الأية
فَجَعَلْنَاهُمْ سَلَفًا وَمَثَلًا لِّلْآخِرِينَ
FajaAAalnahum salafan wamathalan lil-akhireen
Yoruba
A sì ṣe wọ́n ní ìjọ aṣíwájú (nínú ìparun) àti àpẹ̀ẹrẹ (fèyíkọ́gbọ́n) fún àwọn ẹni ìkẹ́yìn.
|
Ayah 43:57 الأية
وَلَمَّا ضُرِبَ ابْنُ مَرْيَمَ مَثَلًا إِذَا قَوْمُكَ مِنْهُ يَصِدُّونَ
Walamma duriba ibnu maryamamathalan itha qawmuka minhu yasiddoon
Yoruba
Nígbà tí àwọn ọ̀ṣẹbọ fi ọmọ Mọryam ṣe àpẹ̀ẹrẹ (fún òrìṣà wọn), nígbà náà ni àwọn ènìyàn rẹ bá ń fi (àpẹ̀ẹrẹ náà) rẹ́rìn-ín.
|
Ayah 43:58 الأية
وَقَالُوا أَآلِهَتُنَا خَيْرٌ أَمْ هُوَ ۚ مَا ضَرَبُوهُ لَكَ إِلَّا جَدَلًا ۚ
بَلْ هُمْ قَوْمٌ خَصِمُونَ
Waqaloo aalihatunakhayrun am huwa ma daraboohu laka illajadalan bal hum qawmun
khasimoon
Yoruba
Wọ́n sì wí pé: "Ṣé àwọn òrìṣà wa l'ó lóore jùlọ ni tàbí òun? Wọn kò wulẹ̀ fi ṣàpẹ̀ẹrẹ fún ọ bí kò ṣe (fún) àtakò. Àní sẹ́, ìjọ oníyànjíjà ni wọ́n.
|
Ayah 43:59 الأية
إِنْ هُوَ إِلَّا عَبْدٌ أَنْعَمْنَا عَلَيْهِ وَجَعَلْنَاهُ مَثَلًا لِّبَنِي
إِسْرَائِيلَ
In huwa illa AAabdun anAAamnaAAalayhi wajaAAalnahu mathalan libanee isra-eel
Yoruba
Kí ni òun bí kò ṣe ẹrúsìn kan tí A ṣe ìdẹ̀ra fún. A sì ṣe é ní àpẹ̀ẹrẹ rere fún àwọn ọmọ 'Isrọ̄'īl.
|
Ayah 43:60 الأية
وَلَوْ نَشَاءُ لَجَعَلْنَا مِنكُم مَّلَائِكَةً فِي الْأَرْضِ يَخْلُفُونَ
Walaw nashao lajaAAalna minkummala-ikatan fee al-ardi yakhlufoon
Yoruba
Tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́, A ìbá máa fi àwọn mọlāika rọ́pò yín lórí ilẹ̀.
|
Ayah 43:61 الأية
وَإِنَّهُ لَعِلْمٌ لِّلسَّاعَةِ فَلَا تَمْتَرُنَّ بِهَا وَاتَّبِعُونِ ۚ هَٰذَا
صِرَاطٌ مُّسْتَقِيمٌ
Wa-innahu laAAilmun lissaAAatifala tamtarunna biha wattabiAAooni hathasiratun
mustaqeem
Yoruba
Dájúdájú òun ni ìmọ̀ (tàbí àmì fún ìsúnmọ́) Àkókò náà. Nítorí náà, ẹ kò gbọdọ̀ ṣeyèméjì lórí rẹ̀. Kí ẹ sì tẹ̀lé mi. Èyí ni ọ̀nà tààrà.
|
Ayah 43:62 الأية
وَلَا يَصُدَّنَّكُمُ الشَّيْطَانُ ۖ إِنَّهُ لَكُمْ عَدُوٌّ مُّبِينٌ
Wala yasuddannakumu ashshaytanuinnahu lakum AAaduwwun mubeen
Yoruba
Ẹ má ṣe jẹ́ kí Èṣù ṣẹ yín lórí (kúrò lójú ọ̀nà tààrà náà); dájúdájú òun ni ọ̀tá pọ́nńbélé fún yín.
|
Ayah 43:63 الأية
وَلَمَّا جَاءَ عِيسَىٰ بِالْبَيِّنَاتِ قَالَ قَدْ جِئْتُكُم بِالْحِكْمَةِ
وَلِأُبَيِّنَ لَكُم بَعْضَ الَّذِي تَخْتَلِفُونَ فِيهِ ۖ فَاتَّقُوا اللهَ
وَأَطِيعُونِ
Walamma jaa AAeesa bilbayyinatiqala qad ji/tukum bilhikmati wali-obayyinalakum
baAAda allathee takhtalifoona feehi fattaqooAllaha waateeAAoon
Yoruba
Nígbà tí (Ànábì) ‘Īsā dé pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tó yanjú, ó sọ pé: "Dájúdájú mo dé wá ba yín pẹ̀lú ọgbọ́n ìjìnlẹ̀. (Mo sì dé) nítorí kí n̄g lè ṣe àlàyé apá kan èyí tí ẹ̀ ń yapa-ẹnu lórí rẹ̀ fún yín. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
|
Ayah 43:64 الأية
إِنَّ اللهَ هُوَ رَبِّي وَرَبُّكُمْ فَاعْبُدُوهُ ۚ هَٰذَا صِرَاطٌ مُّسْتَقِيمٌ
Inna Allaha huwa rabbee warabbukum faAAbudoohuhatha siratun mustaqeem
Yoruba
Dájúdájú Allāhu ni Olúwa mi àti Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Un. Èyí ni ọ̀nà tààrà."
|
Ayah 43:65 الأية
فَاخْتَلَفَ الْأَحْزَابُ مِن بَيْنِهِمْ ۖ فَوَيْلٌ لِّلَّذِينَ ظَلَمُوا مِنْ
عَذَابِ يَوْمٍ أَلِيمٍ
Fakhtalafa al-ahzabumin baynihim fawaylun lillatheena thalamoomin AAathabi
yawmin aleem
Yoruba
Àwọn ìjọ (rẹ̀) sì yapa (ẹ̀sìn 'Islām) láààrin ara wọn. Nítorí náà, ègbé ni fún àwọn tó ṣàbòsí ní ọjọ́ ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
|
Ayah 43:66 الأية
هَلْ يَنظُرُونَ إِلَّا السَّاعَةَ أَن تَأْتِيَهُم بَغْتَةً وَهُمْ لَا
يَشْعُرُونَ
Hal yanthuroona illa assaAAataan ta/tiyahum baghtatan wahum la yashAAuroon
Yoruba
Ṣé wọ́n ń retí kiní kan bí kò ṣe Àkókò náà; tí ó máa dé bá wọn ní òjijì; wọn kò sì níí fura?
|
Ayah 43:67 الأية
الْأَخِلَّاءُ يَوْمَئِذٍ بَعْضُهُمْ لِبَعْضٍ عَدُوٌّ إِلَّا الْمُتَّقِينَ
Al-akhillao yawma-ithin baAAduhumlibaAAdin AAaduwwun illa almuttaqeen
Yoruba
Àwọn ọ̀rẹ́ àyò ní ọjọ́ yẹn, apá kan wọn yóò jẹ́ ọ̀tá fún apá kan àyàfi àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).
|
Ayah 43:68 الأية
يَا عِبَادِ لَا خَوْفٌ عَلَيْكُمُ الْيَوْمَ وَلَا أَنتُمْ تَحْزَنُونَ
Ya AAibadi la khawfunAAalaykumu alyawma wala antum tahzanoon
Yoruba
Ẹ̀yin ẹrúsìn Mi, kò sí ìbẹ̀rù fún yín ní òní. Ẹ̀yin kò sì níí banújẹ́.
|
Ayah 43:69 الأية
الَّذِينَ آمَنُوا بِآيَاتِنَا وَكَانُوا مُسْلِمِينَ
Allatheena amanoo bi-ayatinawakanoo muslimeen
Yoruba
(Àwọn ni) àwọn tó gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa, tí wọ́n sì jẹ́ mùsùlùmí (olùjuwọ́-jusẹ̀ sílẹ̀ fún Allāhu).
|
Ayah 43:70 الأية
ادْخُلُوا الْجَنَّةَ أَنتُمْ وَأَزْوَاجُكُمْ تُحْبَرُونَ
Odkhuloo aljannata antum waazwajukumtuhbaroon
Yoruba
Ẹ wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, ẹ̀yin àti àwọn ìyàwó yín; kí wọ́n máa dun yín nínú.
|
Ayah 43:71 الأية
يُطَافُ عَلَيْهِم بِصِحَافٍ مِّن ذَهَبٍ وَأَكْوَابٍ ۖ وَفِيهَا مَا تَشْتَهِيهِ
الْأَنفُسُ وَتَلَذُّ الْأَعْيُنُ ۖ وَأَنتُمْ فِيهَا خَالِدُونَ
Yutafu AAalayhim bisihafinmin thahabin waakwabin wafeeha matashtaheehi al-anfusu
watalaththu al-aAAyunu waantum feehakhalidoon
Yoruba
Wọn yóò máa gbé àwọn àwo góòlù àti àwọn ife ìmumi káà kiri ọ̀dọ̀ wọn. Ohun tí ẹ̀mí ń fẹ́ àti (ohun tí) ojú yóò máa dúnnú sí wà nínú rẹ̀. Olùṣegbére sì ni yín nínú rẹ̀.
|
Ayah 43:72 الأية
وَتِلْكَ الْجَنَّةُ الَّتِي أُورِثْتُمُوهَا بِمَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ
Watilka aljannatu allatee oorithtumoohabima kuntum taAAmaloon
Yoruba
Ìyẹn ni Ọgbà Ìdẹ̀ra tí A jogún rẹ̀ fún yín nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
|
Ayah 43:73 الأية
لَكُمْ فِيهَا فَاكِهَةٌ كَثِيرَةٌ مِّنْهَا تَأْكُلُونَ
Lakum feeha fakihatunkatheeratun minha ta/kuloon
Yoruba
Èso púpọ̀ wà fún yín nínú rẹ̀. Ẹ̀yin yó sì máa jẹ nínú rẹ̀.
|
Ayah 43:74 الأية
إِنَّ الْمُجْرِمِينَ فِي عَذَابِ جَهَنَّمَ خَالِدُونَ
Inna almujrimeena fee AAathabijahannama khalidoon
Yoruba
Dájúdájú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni olùṣegbére nínú ìyà iná Jahanamọ.
|
Ayah 43:75 الأية
لَا يُفَتَّرُ عَنْهُمْ وَهُمْ فِيهِ مُبْلِسُونَ
La yufattaru AAanhum wahum feehimublisoon
Yoruba
A kò níí gbé e fúyẹ́ fún wọn. Wọn yó sì sọ̀rètí nù nínú Iná.
|
Ayah 43:76 الأية
وَمَا ظَلَمْنَاهُمْ وَلَٰكِن كَانُوا هُمُ الظَّالِمِينَ
Wama thalamnahumwalakin kanoo humu aththalimeen
Yoruba
A kò ṣàbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n àwọn ni wọ́n jẹ́ alábòsí.
|
Ayah 43:77 الأية
وَنَادَوْا يَا مَالِكُ لِيَقْضِ عَلَيْنَا رَبُّكَ ۖ قَالَ إِنَّكُم مَّاكِثُونَ
Wanadaw ya maliku liyaqdiAAalayna rabbuka qala innakum makithoon
Yoruba
Wọn yóò pe (mọlāika kan) pé: "Mọ̄lik (ẹ̀ṣọ́ Iná), jẹ́ kí Olúwa rẹ pa wá ráúráú." (Mọ̄lik) yóò sọ pé: "Dájúdájú ẹ̀yin yóò máa gbé inú rẹ̀ ni."
|
Ayah 43:78 الأية
لَقَدْ جِئْنَاكُم بِالْحَقِّ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَكُمْ لِلْحَقِّ كَارِهُونَ
Laqad ji/nakum bilhaqqiwalakinna aktharakum lilhaqqi karihoon
Yoruba
Dájúdájú A ti mú òdodo wá ba yín, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ yin kórira òdodo.
|
Ayah 43:79 الأية
أَمْ أَبْرَمُوا أَمْرًا فَإِنَّا مُبْرِمُونَ
Am abramoo amran fa-inna mubrimoon
Yoruba
Tàbí àwọn (aláìgbàgbọ́) ti pinnu ọ̀rọ̀ kan ni? Dájúdájú Àwa náà ń pinnu ọ̀rọ̀.
|
Ayah 43:80 الأية
أَمْ يَحْسَبُونَ أَنَّا لَا نَسْمَعُ سِرَّهُمْ وَنَجْوَاهُم ۚ بَلَىٰ وَرُسُلُنَا
لَدَيْهِمْ يَكْتُبُونَ
Am yahsaboona anna lanasmaAAu sirrahum wanajwahum bala warusulunaladayhim
yaktuboon
Yoruba
Tàbí wọ́n ń lérò pé Àwa kò gbọ́ ọ̀rọ̀ àṣírí wọn àti ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ wọn? Bẹ́ẹ̀ ni (À ń gbọ́ ọ); àwọn Òjíṣẹ́ Wa wà ní ọ̀dọ̀ wọn, tí wọ́n ń ṣe àkọsílẹ̀ (ọ̀rọ̀ wọn).
|
Ayah 43:81 الأية
قُلْ إِن كَانَ لِلرَّحْمَٰنِ وَلَدٌ فَأَنَا أَوَّلُ الْعَابِدِينَ
Qul in kana lirrahmaniwaladun faana awwalu alAAabideen
Yoruba
Sọ pé: "Kò sí ọmọ kan fún Àjọké ayé. Nítorí náà, èmi ni ẹni àkọ́kọ́ nínú àwọn olùjọ́sìn (fún Allāhu ní àsìkò tèmi).
|
Ayah 43:82 الأية
سُبْحَانَ رَبِّ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ رَبِّ الْعَرْشِ عَمَّا يَصِفُونَ
Subhana rabbi assamawatiwal-ardi rabbi alAAarshi AAamma yasifoon
Yoruba
Mímọ́ ni fún Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, Olúwa Ìtẹ́-ọlá tayọ irọ́ tí wọ́n ń pa (mọ́ Ọn).
|
Ayah 43:83 الأية
فَذَرْهُمْ يَخُوضُوا وَيَلْعَبُوا حَتَّىٰ يُلَاقُوا يَوْمَهُمُ الَّذِي
يُوعَدُونَ
Fatharhum yakhoodoowayalAAaboo hatta yulaqoo yawmahumu allatheeyooAAadoon
Yoruba
Nítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n máa sọ ìsọkúsọ (wọn), kí wọ́n sì máa ṣeré wọn lọ títí wọn yóò fi pàdé ọjọ́ wọn, tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn.
|
Ayah 43:84 الأية
وَهُوَ الَّذِي فِي السَّمَاءِ إِلَٰهٌ وَفِي الْأَرْضِ إِلَٰهٌ ۚ وَهُوَ
الْحَكِيمُ الْعَلِيمُ
Wahuwa allathee fee assama-iilahun wafee al-ardi ilahun wahuwa
alhakeemualAAaleem
Yoruba
(Allāhu) Òun ni Ọlọ́hun tí wọ́n ń jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo nínú sánmọ̀. Òun náà sì ni Ọlọ́hun tí wọ́n gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo lórí ilẹ̀. Òun ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀.
|
Ayah 43:85 الأية
وَتَبَارَكَ الَّذِي لَهُ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا
وَعِندَهُ عِلْمُ السَّاعَةِ وَإِلَيْهِ تُرْجَعُونَ
Watabaraka allathee lahu mulkuassamawati wal-ardi wamabaynahuma waAAindahu
AAilmu assaAAatiwa-ilayhi turjaAAoon
Yoruba
Ìbùkún ni fún Ẹni tí Ó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tó wà láààrin méjèèjì. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni ìmọ̀ Àkókò náà wà. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọ́n máa da yín padà sí.
|
Ayah 43:86 الأية
وَلَا يَمْلِكُ الَّذِينَ يَدْعُونَ مِن دُونِهِ الشَّفَاعَةَ إِلَّا مَن شَهِدَ
بِالْحَقِّ وَهُمْ يَعْلَمُونَ
Wala yamliku allatheenayadAAoona min doonihi ashshafaAAata illaman shahida
bilhaqqi wahum yaAAlamoon
Yoruba
Àwọn tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀, wọn kò ní ìkápá ìṣìpẹ̀ àyàfi ẹni tí ó bá jẹ́rìí sí òdodo (kalmọtuṣ-ṣahaadah), tí wọ́n sì nímọ̀ (rẹ̀).
|
Ayah 43:87 الأية
وَلَئِن سَأَلْتَهُم مَّنْ خَلَقَهُمْ لَيَقُولُنَّ اللهُ ۖ فَأَنَّىٰ
يُؤْفَكُونَ
Wala-in saaltahum man khalaqahumlayaqoolunna Allahu faanna yu/fakoon
Yoruba
Àti pé tí o bá bi wọ́n léèrè pé: "Ta ni Ó dá wọn?", dájúdájú wọn á wí pé: "Allāhu ni." Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo?
|
Ayah 43:88 الأية
وَقِيلِهِ يَا رَبِّ إِنَّ هَٰؤُلَاءِ قَوْمٌ لَّا يُؤْمِنُونَ
Waqeelihi ya rabbi inna haola-iqawmun la yu/minoon
Yoruba
Ọ̀rọ̀ (tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ń sọ fún Allāhu ni pé): "Olúwa Mi, dájúdájú àwọn wọ̀nyí ni ìjọ tí kò gbàgbọ́."
|
Ayah 43:89 الأية
فَاصْفَحْ عَنْهُمْ وَقُلْ سَلَامٌ ۚ فَسَوْفَ يَعْلَمُونَ
Fasfah AAanhum waqulsalamun fasawfa yaAAlamoon
Yoruba
Nítorí náà, ṣàmójú kúrò fún wọn, kí ó sì sọ pé: "Àlàáfíà!" Láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀.
|
©
EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us
|