1st Ayah 1 الأية ١الأوليبِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
الَّذِينَ كَفَرُوا وَصَدُّوا عَن سَبِيلِ اللهِ أَضَلَّ أَعْمَالَهُمْ
Allatheena kafaroo wasaddooAAan sabeeli Allahi adalla aAAmalahum
Yoruba
Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n tún ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà Allāhu, (Allāhu) máa sọ iṣẹ́ wọn di òfò.
|
Ayah 47:2 الأية
وَالَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ وَآمَنُوا بِمَا نُزِّلَ عَلَىٰ
مُحَمَّدٍ وَهُوَ الْحَقُّ مِن رَّبِّهِمْ ۙ كَفَّرَ عَنْهُمْ سَيِّئَاتِهِمْ
وَأَصْلَحَ بَالَهُمْ
Wallatheena amanoowaAAamiloo assalihati waamanoo bimanuzzila AAala muhammadin
wahuwa alhaqqu minrabbihim kaffara AAanhum sayyi-atihim waaslahabalahum
Yoruba
Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe àwọn iṣẹ́ rere, tí wọ́n tún gbàgbọ́ nínú ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún (Ànábì) Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, òhun sì ni òdodo láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn, (Allāhu) máa pa àwọn (iṣẹ́) aburú wọn rẹ́, Ó sì máa ṣe àtúnṣe ọ̀rọ̀ wọn sí dáadáa.
|
Ayah 47:3 الأية
ذَٰلِكَ بِأَنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا اتَّبَعُوا الْبَاطِلَ وَأَنَّ الَّذِينَ
آمَنُوا اتَّبَعُوا الْحَقَّ مِن رَّبِّهِمْ ۚ كَذَٰلِكَ يَضْرِبُ اللهُ
لِلنَّاسِ أَمْثَالَهُمْ
Thalika bi-anna allatheenakafaroo ittabaAAoo albatila waanna allatheena
amanooittabaAAoo alhaqqa min rabbihim kathalika yadribuAllahu linnasi amthalahum
Yoruba
Ìyẹn (rí bẹ́ẹ̀) nítorí pé, dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ tẹ̀lé irọ́. Àti pé dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ tẹ̀lé òdodo láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń fi àpèjúwe wọn lélẹ̀ fún àwọn ènìyàn.
|
Ayah 47:4 الأية
فَإِذَا لَقِيتُمُ الَّذِينَ كَفَرُوا فَضَرْبَ الرِّقَابِ حَتَّىٰ إِذَا
أَثْخَنتُمُوهُمْ فَشُدُّوا الْوَثَاقَ فَإِمَّا مَنًّا بَعْدُ وَإِمَّا فِدَاءً
حَتَّىٰ تَضَعَ الْحَرْبُ أَوْزَارَهَا ۚ ذَٰلِكَ وَلَوْ يَشَاءُ اللهُ
لَانتَصَرَ مِنْهُمْ وَلَٰكِن لِّيَبْلُوَ بَعْضَكُم بِبَعْضٍ ۗ وَالَّذِينَ
قُتِلُوا فِي سَبِيلِ اللهِ فَلَن يُضِلَّ أَعْمَالَهُمْ
Fa-itha laqeetumu allatheenakafaroo fadarba arriqabi hattaitha athkhantumoohum
fashuddoo alwathaqa fa-immamannan baAAdu wa-imma fidaan hatta tadaAAaalharbu
awzaraha thalika walaw yashaoAllahu lantasara minhum walakinliyabluwa baAAdakum
bibaAAdin wallatheenaqutiloo fee sabeeli Allahi falan yudillaaAAmalahum
Yoruba
Nítorí náà, nígbà tí ẹ bá pàdé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ (lójú ogun ẹ̀sìn), ẹ máa bẹ́ wọn lọ́rùn ǹsó títí di ìgbà tí ẹ máa fi rí wọn pa dáadáa. (Nígbà tí ọwọ́ yín bá ti bà wọ́n tán), ẹ dè wọ́n mọ́lẹ̀ sórí ìgbèkùn. Lẹ́yìn náà, ẹ lè tú wọn sílẹ̀ ní ọ̀fẹ́ tàbí kí ẹ tú wọn sílẹ̀ pẹ̀lú owó ìtúsílẹ̀ títí kò fi níí sí ogun ẹ̀sìn mọ́.1 Ìyẹn (wà bẹ́ẹ̀). Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá gbẹ̀san fúnra Rẹ̀ (láì níí la ogun lọ), ṣùgbọ́n nítorí kí Ó lè dán apá kan yín wò lára apá kan ni. Àwọn mùsùlùmí tí wọ́n sì pa sí ojú-ọ̀nà Allāhu, Allāhu kò níí sọ iṣẹ́ wọn dòfo.
|
Ayah 47:5 الأية
سَيَهْدِيهِمْ وَيُصْلِحُ بَالَهُمْ
sayahdeehim wayuslihu balahum
Yoruba
Ó máa fi ọ̀nà (Ọgbà Ìdẹ̀ra) mọ̀ wọ́n. Ó sì máa tún ọ̀rọ̀ wọn ṣe sí dáadáa.
|
Ayah 47:6 الأية
وَيُدْخِلُهُمُ الْجَنَّةَ عَرَّفَهَا لَهُمْ
Wayudkhiluhumu aljannata AAarrafahalahum
Yoruba
Ó máa fi wọ́n wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, èyí tí Ó ti fi mọ̀ wọ́n.
|
Ayah 47:7 الأية
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِن تَنصُرُوا اللهَ يَنصُرْكُمْ وَيُثَبِّتْ
أَقْدَامَكُمْ
Ya ayyuha allatheena amanooin tansuroo Allaha yansurkum wayuthabbit aqdamakum
Yoruba
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, tí ẹ bá ran (ẹ̀sìn) Allāhu lọ́wọ́, (Allāhu) máa ràn ẹ̀yin náà lọ́wọ́. Ó sì máa mú ẹsẹ̀ yín dúró ṣinṣin (nínú ẹ̀sìn).
|
Ayah 47:8 الأية
وَالَّذِينَ كَفَرُوا فَتَعْسًا لَّهُمْ وَأَضَلَّ أَعْمَالَهُمْ
Wallatheena kafaroo fataAAsanlahum waadalla aAAmalahum
Yoruba
Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, ìparun ni fún wọn. (Allāhu) sì máa sọ iṣẹ́ wọn di òfò.
|
Ayah 47:9 الأية
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ كَرِهُوا مَا أَنزَلَ اللهُ فَأَحْبَطَ أَعْمَالَهُمْ
Thalika bi-annahum karihoo maanzala Allahu faahbata aAAmalahum
Yoruba
Ìyẹn nítorí pé, dájúdájú wọ́n kórira ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀. Nítorí náà, (Allāhu) sì ba iṣẹ́ wọn jẹ́.
|
Ayah 47:10 الأية
أَفَلَمْ يَسِيرُوا فِي الْأَرْضِ فَيَنظُرُوا كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الَّذِينَ
مِن قَبْلِهِمْ ۚ دَمَّرَ اللهُ عَلَيْهِمْ ۖ وَلِلْكَافِرِينَ أَمْثَالُهَا
Afalam yaseeroo fee al-ardi fayanthurookayfa kana AAaqibatu allatheena min
qablihimdammara Allahu AAalayhim walilkafireena amthaluha
Yoruba
Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe rí? Allāhu pa wọ́n rẹ́. Irú rẹ̀ tún wà fún àwọn aláìgbàgbọ́.
|
Ayah 47:11 الأية
ذَٰلِكَ بِأَنَّ اللهَ مَوْلَى الَّذِينَ آمَنُوا وَأَنَّ الْكَافِرِينَ لَا
مَوْلَىٰ لَهُمْ
Thalika bi-anna Allaha mawlaallatheena amanoo waanna alkafireena lamawla lahum
Yoruba
Ìyẹn nítorí pé dájúdájú Allāhu ni Olùrànlọ́wọ́ àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo. Dájúdájú àwọn aláìgbàgbọ́, kò sí olùrànlọ́wọ́ kan fún wọn.
|
Ayah 47:12 الأية
إِنَّ اللهَ يُدْخِلُ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ جَنَّاتٍ
تَجْرِي مِن تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ ۖ وَالَّذِينَ كَفَرُوا يَتَمَتَّعُونَ
وَيَأْكُلُونَ كَمَا تَأْكُلُ الْأَنْعَامُ وَالنَّارُ مَثْوًى لَّهُمْ
Inna Allaha yudkhilu allatheenaamanoo waAAamiloo assalihati jannatintajree min
tahtiha al-anharu wallatheenakafaroo yatamattaAAoona waya/kuloona kama ta/kulu
al-anAAamuwannaru mathwan lahum
Yoruba
Dájúdájú Allāhu yóò fi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Àwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́, àwọn ń gbádùn, wọ́n sì ń jẹ (kiri) gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹran-ọ̀sìn ṣe ń jẹ (kiri). Iná sì ni ibùgbé fún wọn.
|
Ayah 47:13 الأية
وَكَأَيِّن مِّن قَرْيَةٍ هِيَ أَشَدُّ قُوَّةً مِّن قَرْيَتِكَ الَّتِي
أَخْرَجَتْكَ أَهْلَكْنَاهُمْ فَلَا نَاصِرَ لَهُمْ
Wakaayyin min qaryatin hiya ashaddu quwwatanmin qaryatika allatee akhrajatka
ahlaknahum fala nasiralahum
Yoruba
Mélòó mélòó nínú àwọn (ará) ìlú tí ó lágbára ju (ará) ìlú rẹ, tí ó lé ọ jáde, tí A sì ti pa wọ́n rẹ́. Kò sì sí alárànṣe kan fún wọn.
|
Ayah 47:14 الأية
أَفَمَن كَانَ عَلَىٰ بَيِّنَةٍ مِّن رَّبِّهِ كَمَن زُيِّنَ لَهُ سُوءُ عَمَلِهِ
وَاتَّبَعُوا أَهْوَاءَهُم
Afaman kana AAala bayyinatinmin rabbihi kaman zuyyina lahu soo-o AAamalihi
wattabaAAooahwaahum
Yoruba
Ǹjẹ́ ẹni tí ó wà̀lórí ẹ̀rí tó yanjú láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀, ṣé ó dà bí ẹni tí wọ́n ṣe iṣẹ́ aburú rẹ̀ ní ọ̀ṣọ́ fún, tí wọ́n sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn?
|
Ayah 47:15 الأية
مَّثَلُ الْجَنَّةِ الَّتِي وُعِدَ الْمُتَّقُونَ ۖ فِيهَا أَنْهَارٌ مِّن مَّاءٍ
غَيْرِ آسِنٍ وَأَنْهَارٌ مِّن لَّبَنٍ لَّمْ يَتَغَيَّرْ طَعْمُهُ وَأَنْهَارٌ
مِّنْ خَمْرٍ لَّذَّةٍ لِّلشَّارِبِينَ وَأَنْهَارٌ مِّنْ عَسَلٍ مُّصَفًّى ۖ
وَلَهُمْ فِيهَا مِن كُلِّ الثَّمَرَاتِ وَمَغْفِرَةٌ مِّن رَّبِّهِمْ ۖ كَمَنْ
هُوَ خَالِدٌ فِي النَّارِ وَسُقُوا مَاءً حَمِيمًا فَقَطَّعَ أَمْعَاءَهُمْ
Mathalu aljannati allatee wuAAidaalmuttaqoona feeha anharun min ma-in ghayri
asininwaanharun min labanin lam yataghayyar taAAmuhuwaanharun min khamrin
laththatin lishsharibeenawaanharun min AAasalin musaffan walahum feehamin kulli
aththamarati wamaghfiratun min rabbihimkaman huwa khalidun fee annari wasuqoo
maanhameeman faqattaAAa amAAaahum
Yoruba
Àpèjúwe Ọgbà Ìdẹ̀ra èyí tí wọ́n ṣe ní àdéhùn fún àwọn olùbẹ̀rù Allāhu (nìyí): àwọn omi odò wà nínú rẹ̀ tí kò níí yí padà àti àwọn odò wàrà tí adùn rẹ̀ kò níí yí padà àti àwọn odò ọtí dídùn fún àwọn tó máa mu ún àti àwọn odò oyin mímọ́. Gbogbo èso wà fún wọn nínú rẹ̀ àti àforíjìn láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. (Ṣé ẹni tí ó wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra yìí) dà bí olùṣegbére nínú Iná bí, tí wọ́n ń fún wọn ní omi tó gbóná parí mu, tí ó sì máa já àwọn ìfun wọn pútupùtu?
|
Ayah 47:16 الأية
وَمِنْهُم مَّن يَسْتَمِعُ إِلَيْكَ حَتَّىٰ إِذَا خَرَجُوا مِنْ عِندِكَ قَالُوا
لِلَّذِينَ أُوتُوا الْعِلْمَ مَاذَا قَالَ آنِفًا ۚ أُولَٰئِكَ الَّذِينَ طَبَعَ
اللهُ عَلَىٰ قُلُوبِهِمْ وَاتَّبَعُوا أَهْوَاءَهُمْ
Waminhum man yastamiAAu ilayka hattaitha kharajoo min AAindika qaloo
lillatheenaootoo alAAilma matha qala anifan ola-ikaallatheena tabaAAa Allahu
AAalaquloobihim wattabaAAoo ahwaahum
Yoruba
Ó wà nínú wọn, ẹni tí ó ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ rẹ títí di ìgbà tí wọ́n bá jáde kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ tán, wọn yó sì wí fún àwọn onímọ̀-ẹ̀sìn pé: "Kí l'ó sọ lẹ́ẹ̀ẹ̀ kan ná?" Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ti dí ọkàn wọn pa. Wọ́n sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn.
|
Ayah 47:17 الأية
وَالَّذِينَ اهْتَدَوْا زَادَهُمْ هُدًى وَآتَاهُمْ تَقْوَاهُمْ
Wallatheena ihtadaw zadahumhudan waatahum taqwahum
Yoruba
Àwọn tó sì tẹ̀lé ìmọ̀nà, (Allāhu) ṣàlékún ìmọ̀nà fún wọn. Ó sì máa fún wọn ní ìbẹ̀rù wọn (nínú Allāhu).
|
Ayah 47:18 الأية
فَهَلْ يَنظُرُونَ إِلَّا السَّاعَةَ أَن تَأْتِيَهُم بَغْتَةً ۖ فَقَدْ جَاءَ
أَشْرَاطُهَا ۚ فَأَنَّىٰ لَهُمْ إِذَا جَاءَتْهُمْ ذِكْرَاهُمْ
Fahal yanthuroona illaassaAAata an ta/tiyahum baghtatan faqad jaaashratuha
faanna lahum itha jaat-humthikrahum
Yoruba
Ṣé wọ́n ń retí kiní kan bí kò ṣe Àkókò náà, tí ó máa dé bá wọn ní òjijì? Àwọn àmì rẹ̀ kúkú ti dé. Nítorí náà, báwo ni ìrántí (yó ṣe wúlò fún) wọ́n nígbà tí ó bá dé bá wọn?
|
Ayah 47:19 الأية
فَاعْلَمْ أَنَّهُ لَا إِلَٰهَ إِلَّا اللهُ وَاسْتَغْفِرْ لِذَنبِكَ
وَلِلْمُؤْمِنِينَ وَالْمُؤْمِنَاتِ ۗ وَاللهُ يَعْلَمُ مُتَقَلَّبَكُمْ
وَمَثْوَاكُمْ
FaAAlam annahu la ilahailla Allahu wastaghfir lithanbikawalilmu/mineena
walmu/minati wallahuyaAAlamu mutaqallabakum wamathwakum
Yoruba
Nítorí náà, mọ̀ pé dájúdájú kò sí ọlọ́hun tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Allāhu. Kí o sì tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin. Allāhu mọ lílọ-bíbọ̀ yín àti ibùgbé yín.
|
Ayah 47:20 الأية
وَيَقُولُ الَّذِينَ آمَنُوا لَوْلَا نُزِّلَتْ سُورَةٌ ۖ فَإِذَا أُنزِلَتْ
سُورَةٌ مُّحْكَمَةٌ وَذُكِرَ فِيهَا الْقِتَالُ ۙ رَأَيْتَ الَّذِينَ فِي
قُلُوبِهِم مَّرَضٌ يَنظُرُونَ إِلَيْكَ نَظَرَ الْمَغْشِيِّ عَلَيْهِ مِنَ
الْمَوْتِ ۖ فَأَوْلَىٰ لَهُمْ
Wayaqoolu allatheena amanoolawla nuzzilat sooratun fa-itha onzilat sooratun
muhkamatunwathukira feeha alqitalu raayta allatheenafee quloobihim maradun
yanthuroona ilayka natharaalmaghshiyyi AAalayhi mina almawti faawla lahum
Yoruba
Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo ń sọ pé: "Kí ni kò jẹ́ kí wọ́n sọ sūrah kan kalẹ̀?" Nígbà tí wọ́n bá sọ sūrah aláìnípọ́n-na kalẹ̀, tí wọ́n sì sọ ọ̀rọ̀ ogun ẹ̀sìn nínú rẹ̀, ìwọ yóò rí àwọn tí àrùn wà nínú ọkàn wọn, tí wọn yóò máa wò ọ́ ní wíwò bí ẹni pé wọ́n ti dákú lọ pọnrangandan. Ohun tí ó sì dára jùlọ fún wọn
|
Ayah 47:21 الأية
طَاعَةٌ وَقَوْلٌ مَّعْرُوفٌ ۚ فَإِذَا عَزَمَ الْأَمْرُ فَلَوْ صَدَقُوا اللهَ
لَكَانَ خَيْرًا لَّهُمْ
TaAAatun waqawlun maAAroofun fa-ithaAAazama al-amru falaw sadaqoo Allaha
lakanakhayran lahum
Yoruba
Ni ìtẹ̀lé àṣẹ (Allāhu) àti (sísọ) ọ̀rọ̀ rere. Nígbà tí ọ̀rọ̀ náà (ìyẹn ogun ẹ̀sìn) sì ti di dandan, wọn ìbá gbà pé Allāhu sọ òdodo, ìbá dára jùlọ fún wọn.
|
Ayah 47:22 الأية
فَهَلْ عَسَيْتُمْ إِن تَوَلَّيْتُمْ أَن تُفْسِدُوا فِي الْأَرْضِ وَتُقَطِّعُوا
أَرْحَامَكُمْ
Fahal AAasaytum in tawallaytum an tufsidoofee al-ardi watuqattiAAoo arhamakum
Yoruba
Ó súnmọ́ pé tí ẹ̀yin bá kọ̀yìn sí ogun ẹ̀sìn, (ẹ̀ ń lọ sí oko ìparun nìyẹn, ẹ sì máa padà síbi ìwà ìgbà àìmọ̀kan) tí ẹ̀yin yóò máa ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀, tí ẹ óò sì máa já okùn-ìbí yín?
|
Ayah 47:23 الأية
أُولَٰئِكَ الَّذِينَ لَعَنَهُمُ اللهُ فَأَصَمَّهُمْ وَأَعْمَىٰ أَبْصَارَهُمْ
Ola-ika allatheena laAAanahumuAllahu faasammahum waaAAma absarahum
Yoruba
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ti ṣẹ́bi lé. Nítorí náà, Ó di wọ́n létí pa. Ó sì fọ́ ìríran wọn.
|
Ayah 47:24 الأية
أَفَلَا يَتَدَبَّرُونَ الْقُرْآنَ أَمْ عَلَىٰ قُلُوبٍ أَقْفَالُهَا
Afala yatadabbaroona alqur-anaam AAala quloobin aqfaluha
Yoruba
Ṣé wọn kò níí ronú nípa al-Ƙur'ān ni tàbí àwọn àgádágodo ti wà lórí ọkàn wọn ni?
|
Ayah 47:25 الأية
إِنَّ الَّذِينَ ارْتَدُّوا عَلَىٰ أَدْبَارِهِم مِّن بَعْدِ مَا تَبَيَّنَ لَهُمُ
الْهُدَى ۙ الشَّيْطَانُ سَوَّلَ لَهُمْ وَأَمْلَىٰ لَهُمْ
Inna allatheena irtaddoo AAalaadbarihim min baAAdi ma tabayyana lahumu
alhudaashshaytanu sawwala lahum waamla lahum
Yoruba
Dájúdájú àwọn tó pẹ̀yìn dà (sí 'Islām) lẹ́yìn tí ìmọ̀nà ti fojú hàn sí wọn, Èṣù ló ṣe ìṣìnà ní ọ̀ṣọ́ fún wọn. Ó sì fún wọn ní ìrètí asán nípa ẹ̀mí gígùn.
|
Ayah 47:26 الأية
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ قَالُوا لِلَّذِينَ كَرِهُوا مَا نَزَّلَ اللهُ
سَنُطِيعُكُمْ فِي بَعْضِ الْأَمْرِ ۖ وَاللهُ يَعْلَمُ إِسْرَارَهُمْ
Thalika bi-annahum qaloo lillatheenakarihoo ma nazzala Allahu sanuteeAAukum
feebaAAdi al-amri wallahu yaAAlamu israrahum
Yoruba
Ìyẹn nítorí pé (àwọn aláìsàn ọkàn) ń sọ fún àwọn tó kórira ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ (ìyẹn àwọn yẹhudi) pé: "Àwa yóò tẹ̀lé yin nínú apá kan ọ̀rọ̀ náà." Allāhu sì mọ àṣírí wọn.
|
Ayah 47:27 الأية
فَكَيْفَ إِذَا تَوَفَّتْهُمُ الْمَلَائِكَةُ يَضْرِبُونَ وُجُوهَهُمْ
وَأَدْبَارَهُمْ
Fakayfa itha tawaffat-humu almala-ikatuyadriboona wujoohahum waadbarahum
Yoruba
Báwo ni (ó ṣe máa rí fún wọn) nígbà tí àwọn mọlāika bá gba ẹ̀mí wọn, tí wọn yó sì máa lù wọ́n lójú, lù wọ́n lẹ́yìn?
|
Ayah 47:28 الأية
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمُ اتَّبَعُوا مَا أَسْخَطَ اللهَ وَكَرِهُوا رِضْوَانَهُ
فَأَحْبَطَ أَعْمَالَهُمْ
Thalika bi-annahumu ittabaAAoo maaskhata Allaha wakarihoo ridwanahufaahbata
aAAmalahum
Yoruba
Ìyẹn nítorí pé, dájúdájú wọ́n tẹ̀lé ohun tí ó bí Allāhu nínú. Wọ́n sì kórira ìyọ́nú Rẹ̀. Nítorí náà, Allāhu ba àwọn iṣẹ́ wọn jẹ́.
|
Ayah 47:29 الأية
أَمْ حَسِبَ الَّذِينَ فِي قُلُوبِهِم مَّرَضٌ أَن لَّن يُخْرِجَ اللهُ
أَضْغَانَهُمْ
Am hasiba allatheena feequloobihim maradun an lan yukhrija Allahu adghanahum
Yoruba
Tàbí àwọn tí àrùn wà nínú ọkàn wọn ń lérò pé Allāhu kò níí ṣe àfihàn àdìsọ́kàn burúkú wọn ni?
|
Ayah 47:30 الأية
وَلَوْ نَشَاءُ لَأَرَيْنَاكَهُمْ فَلَعَرَفْتَهُم بِسِيمَاهُمْ ۚ
وَلَتَعْرِفَنَّهُمْ فِي لَحْنِ الْقَوْلِ ۚ وَاللهُ يَعْلَمُ أَعْمَالَكُمْ
Walaw nashao laaraynakahumfalaAAaraftahum biseemahum walataAArifannahum fee
lahnialqawli wallahu yaAAlamu aAAmalakum
Yoruba
Àti pé tí A bá fẹ́ Àwa ìbá fi wọ́n hàn ọ́, ìwọ ìbá sì mọ̀ wọ́n pẹ̀lú àmì wọn. Dájúdájú ìwọ yóò mọ̀ wọ́n níbi pé wọ́n máa ń pẹ́kọrọ ọ̀rọ̀. Allāhu sì mọ àwọn iṣẹ́ (ọwọ́) yín.
|
Ayah 47:31 الأية
وَلَنَبْلُوَنَّكُمْ حَتَّىٰ نَعْلَمَ الْمُجَاهِدِينَ مِنكُمْ وَالصَّابِرِينَ
وَنَبْلُوَ أَخْبَارَكُمْ
Walanabluwannakum hattanaAAlama almujahideena minkum wassabireenawanabluwa
akhbarakum
Yoruba
Dájúdájú A máa dan yín wò títí A fi máa ṣàfi hàn àwọn olùjagun-ẹ̀sìn àti àwọn onísùúrù nínú yín. A sì máa gbìdánwò àwọn ìró yín wò.
|
Ayah 47:32 الأية
إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا وَصَدُّوا عَن سَبِيلِ اللهِ وَشَاقُّوا الرَّسُولَ مِن
بَعْدِ مَا تَبَيَّنَ لَهُمُ الْهُدَىٰ لَن يَضُرُّوا اللهَ شَيْئًا وَسَيُحْبِطُ
أَعْمَالَهُمْ
Inna allatheena kafaroo wasaddooAAan sabeeli Allahi washaqqoo arrasoola
minbaAAdi ma tabayyana lahumu alhuda lan yadurooAllaha shay-an wasayuhbitu
aAAmalahum
Yoruba
Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, tí wọ́n tún yapa Òjíṣẹ́ Allāhu lẹ́yìn tí ìmọ̀nà ti fojú hàn sí wọn, wọn kò lè kó ìnira kiní kan bá Allāhu. (Allāhu) yó sì ba iṣẹ́ wọn jẹ́.
|
Ayah 47:33 الأية
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا أَطِيعُوا اللهَ وَأَطِيعُوا الرَّسُولَ وَلَا
تُبْطِلُوا أَعْمَالَكُمْ
Ya ayyuha allatheena amanooateeAAoo Allaha waateeAAoo arrasoolawala tubtiloo
aAAmalakum
Yoruba
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ tẹ̀lé (ọ̀rọ̀) Allāhu, ẹ tẹ̀lé (ọ̀rọ̀) Òjíṣẹ́ náà, kí ẹ sì má ṣe ba àwọn iṣẹ́ yín jẹ́.
|
Ayah 47:34 الأية
إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا وَصَدُّوا عَن سَبِيلِ اللهِ ثُمَّ مَاتُوا وَهُمْ
كُفَّارٌ فَلَن يَغْفِرَ اللهُ لَهُمْ
Inna allatheena kafaroo wasaddooAAan sabeeli Allahi thumma matoo wahum
kuffarunfalan yaghfira Allahu lahum
Yoruba
Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, lẹ́yìn náà tí wọ́n kú nígbà tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́, Allāhu kò níí foríjìn wọ́n.
|
Ayah 47:35 الأية
فَلَا تَهِنُوا وَتَدْعُوا إِلَى السَّلْمِ وَأَنتُمُ الْأَعْلَوْنَ وَاللهُ
مَعَكُمْ وَلَن يَتِرَكُمْ أَعْمَالَكُمْ
Fala tahinoo watadAAoo ila assalmiwaantumu al-aAAlawna wallahu maAAakum
walanyatirakum aAAmalakum
Yoruba
Ẹ má ṣe káàárẹ̀, kí ẹ sì má ṣe pèpè fún kòsógunmọ́, nígbà tí ẹ bá ń lékè lọ́wọ́. Allāhu wà pẹ̀lú yín; kò sì níí kó àdínkù bá ẹ̀san àwọn iṣẹ́ yín.
|
Ayah 47:36 الأية
إِنَّمَا الْحَيَاةُ الدُّنْيَا لَعِبٌ وَلَهْوٌ ۚ وَإِن تُؤْمِنُوا وَتَتَّقُوا
يُؤْتِكُمْ أُجُورَكُمْ وَلَا يَسْأَلْكُمْ أَمْوَالَكُمْ
Innama alhayatu addunyalaAAibun walahwun wa-in tu/minoo watattaqoo yu/tikum
ojoorakumwala yas-alkum amwalakum
Yoruba
Eré àti ìranù ni ìṣẹ̀mí ayé. (Àmọ́) tí ẹ bá gbàgbọ́ (nínú Allāhu), tí ẹ sì bẹ̀rù (Rẹ̀), Ó máa fún yín ní àwọn ẹ̀san yín. Kò sì níí bèèrè àwọn dúkìá yín (pé kí ẹ fi gbogbo rẹ̀ yọ Zakāh).
|
Ayah 47:37 الأية
إِن يَسْأَلْكُمُوهَا فَيُحْفِكُمْ تَبْخَلُوا وَيُخْرِجْ أَضْغَانَكُمْ
In yas-alkumooha fayuhfikumtabkhaloo wayukhrij adghanakum
Yoruba
Tí (Allāhu) bá bèèrè rẹ̀ ní ọwọ́ yín (pé, kí ẹ fi gbogbo rẹ̀ yọ Zakāh), tí Ó sì won̄koko mọ yín, ẹ máa ṣahun. Ó sì máa mú àrùn ọkàn yín jadé (àṣírí yín yó sì tú síta).
|
Ayah 47:38 الأية
هَا أَنتُمْ هَٰؤُلَاءِ تُدْعَوْنَ لِتُنفِقُوا فِي سَبِيلِ اللهِ فَمِنكُم مَّن
يَبْخَلُ ۖ وَمَن يَبْخَلْ فَإِنَّمَا يَبْخَلُ عَن نَّفْسِهِ ۚ وَاللهُ
الْغَنِيُّ وَأَنتُمُ الْفُقَرَاءُ ۚ وَإِن تَتَوَلَّوْا يَسْتَبْدِلْ قَوْمًا
غَيْرَكُمْ ثُمَّ لَا يَكُونُوا أَمْثَالَكُم
Ha antum haola-itudAAawna litunfiqoo fee sabeeli Allahi faminkum manyabkhalu
waman yabkhal fa-innama yabkhalu AAan nafsihi wallahualghaniyyu waantumu
alfuqarao wa-in tatawallaw yastabdilqawman ghayrakum thumma la yakoonoo
amthalakum
Yoruba
Ẹ̀yin náà mà nìwọ̀nyí tí wọ́n ń pè láti náwó sí ojú-ọ̀nà Allāhu. Ṣùgbọ́n ẹni tó ń ṣahun wà nínú yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣahun, ó ṣe é fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Allāhu ni Ọlọ́rọ̀. Ẹ̀yin sì ni aláìní. Tí ẹ bá gbúnrí, (Allāhu) máa fi ìjọ mìíràn pààrọ̀ yín. Lẹ́yìn náà, wọn kò sì níí dà bí irú yín.
|
©
EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us
|