1st Ayah 1 الأية ١الأوليبِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا أَوْفُوا بِالْعُقُودِ ۚ أُحِلَّتْ لَكُم بَهِيمَةُ
الْأَنْعَامِ إِلَّا مَا يُتْلَىٰ عَلَيْكُمْ غَيْرَ مُحِلِّي الصَّيْدِ وَأَنتُمْ
حُرُمٌ ۗ إِنَّ اللهَ يَحْكُمُ مَا يُرِيدُ
Ya ayyuha allatheena amanooawfoo bilAAuqoodi ohillat lakum baheematu
al-anAAamiilla ma yutla AAalaykum ghayra muhilleeassaydi waantum hurumun inna
Allahayahkumu ma yureed
Yoruba
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ mú àwọn àdéhùn ṣẹ. Wọ́n ṣe àwọn ẹran-ọ̀sìn ní ẹ̀tọ́ fún yín àfi èyí tí wọ́n bá ń kà fún yín (ní èèwọ̀), ẹ má ṣe sọ ìdọdẹ ẹranko di ẹ̀tọ́ nígbà tí ẹ bá wà nínú aṣọ húrùmí. Dájúdájú Allāhu ń ṣe ìdájọ́ ohun tí Ó bá fẹ́.
|
Ayah 5:2 الأية
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تُحِلُّوا شَعَائِرَ اللهِ وَلَا الشَّهْرَ
الْحَرَامَ وَلَا الْهَدْيَ وَلَا الْقَلَائِدَ وَلَا آمِّينَ الْبَيْتَ الْحَرَامَ
يَبْتَغُونَ فَضْلًا مِّن رَّبِّهِمْ وَرِضْوَانًا ۚ وَإِذَا حَلَلْتُمْ
فَاصْطَادُوا ۚ وَلَا يَجْرِمَنَّكُمْ شَنَآنُ قَوْمٍ أَن صَدُّوكُمْ عَنِ
الْمَسْجِدِ الْحَرَامِ أَن تَعْتَدُوا ۘ وَتَعَاوَنُوا عَلَى الْبِرِّ
وَالتَّقْوَىٰ ۖ وَلَا تَعَاوَنُوا عَلَى الْإِثْمِ وَالْعُدْوَانِ ۚ وَاتَّقُوا
اللهَ ۖ إِنَّ اللهَ شَدِيدُ الْعِقَابِ
Ya ayyuha allatheena amanoola tuhilloo shaAAa-ira Allahi walaashshahra alharama
wala alhadya walaalqala-ida wala ammeena albayta alharamayabtaghoona fadlan min
rabbihim waridwananwa-itha halaltum fastadoo walayajrimannakum shanaanu qawmin
an saddookum AAanialmasjidi alharami an taAAtadoo wataAAawanooAAala albirri
wattaqwa wala taAAawanooAAala al-ithmi walAAudwani wattaqooAllaha inna Allaha
shadeedu alAAiqab
Yoruba
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe rú òfin àwọn n̄ǹkan àríṣàmì tí Allāhu gbékalẹ̀ fún ẹ̀sìn Rẹ̀ (nínú iṣẹ́ hajj). Ẹ má ṣe rú òfin oṣù ọ̀wọ̀, àti ẹran ọrẹ (tí wọn kò ṣàmì sí lọ́rùn) àti (àwọn ẹran ọrẹ) tí wọ́n ṣàmì sí lọ́rùn. Ẹ má ṣe ìdíwọ́ fún àwọn tó ń gbèrò láti lọ sí Ilé Haram, tí wọ́n ń wá oore àjùlọ àti ìyọ́nú láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Tí ẹ bá sì ti túra sílẹ̀ nínú aṣọ hurumi, nígbà náà ẹ (lè) dọdẹ (ẹranko). Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìkórira àwọn ènìyàn kan tì yín láti tayọ ẹnu-ààlà nítorí pé, wọ́n ṣe yín lórí kúrò ní Mọ́sálásí Haram. Ẹ ran ara yín lọ́wọ́ lórí iṣẹ́ rere àti ìbẹ̀rù Allāhu. Ẹ má ṣe ran ara yín lọ́wọ́ lórí (ìwà) ẹ̀ṣẹ̀ àti ìtayọ ẹnu-ààlà. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu le (níbi) ìyà.
|
Ayah 5:3 الأية
حُرِّمَتْ عَلَيْكُمُ الْمَيْتَةُ وَالدَّمُ وَلَحْمُ الْخِنزِيرِ وَمَا أُهِلَّ
لِغَيْرِ اللهِ بِهِ وَالْمُنْخَنِقَةُ وَالْمَوْقُوذَةُ وَالْمُتَرَدِّيَةُ
وَالنَّطِيحَةُ وَمَا أَكَلَ السَّبُعُ إِلَّا مَا ذَكَّيْتُمْ وَمَا ذُبِحَ عَلَى
النُّصُبِ وَأَن تَسْتَقْسِمُوا بِالْأَزْلَامِ ۚ ذَٰلِكُمْ فِسْقٌ ۗ الْيَوْمَ
يَئِسَ الَّذِينَ كَفَرُوا مِن دِينِكُمْ فَلَا تَخْشَوْهُمْ وَاخْشَوْنِ ۚ
الْيَوْمَ أَكْمَلْتُ لَكُمْ دِينَكُمْ وَأَتْمَمْتُ عَلَيْكُمْ نِعْمَتِي
وَرَضِيتُ لَكُمُ الْإِسْلَامَ دِينًا ۚ فَمَنِ اضْطُرَّ فِي مَخْمَصَةٍ غَيْرَ
مُتَجَانِفٍ لِّإِثْمٍ ۙ فَإِنَّ اللهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ
Hurrimat AAalaykumu almaytatu waddamuwalahmu alkhinzeeri wama ohilla lighayri
Allahibihi walmunkhaniqatu walmawqoothatu walmutaraddiyatuwannateehatu wama
akala assabuAAuilla ma thakkaytum wama thubihaAAala annusubi waan tastaqsimoo
bil-azlamithalikum fisqun alyawma ya-isa allatheena kafaroomin deenikum fala
takhshawhum wakhshawni alyawmaakmaltu lakum deenakum waatmamtu AAalaykum
niAAmatee waradeetulakumu al-islama deenan famani idturra fee makhmasatinghayra
mutajanifin li-ithmin fa-inna Allahaghafoorun raheem
Yoruba
A ṣe é ní èèwọ̀ fún yín ẹran òkúǹbete àti ẹ̀jẹ̀ àti ẹran ẹlẹ́dẹ̀ àti èyí tí wọ́n pa pẹ̀lú orúkọ tí kì í ṣe "Allāhu" àti ẹran tí wọ́n fún lọ́rùn pa àti ẹran tí wọ́n lù pa àti ẹran tí ó ré lulẹ̀ tí ó kú àti ẹran tí wọ́n kàn pa àti èyí tí ẹranko abìjàwàrà jẹ kù àfi èyí tí ẹ bá rí dú (ṣíwájú kí ó tó kú) àti èyí tí wọ́n pa sídìí òrìṣà. Èèwọ̀ sì ni fún yín láti yẹṣẹ́ wò. Ìwọ̀nyẹn ni ìbàjẹ́. Lónìí ni àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ sọ̀rètí nù nípa ẹ̀sìn yín. Nítorí náà, ẹ má ṣe páyà wọn. Ẹ páyà Mi. Mo parí ẹ̀sìn yín fún yín lónìí. Mo sì ṣe àṣepé ìdẹ̀ra Mi fún yín. Mo sì yọ́nú sí 'Islām ní ẹ̀sìn fún yín. Nítorí náà, ẹni tí ìnira ebi bá mú (jẹ ẹran èèwọ̀) nínú ebi tó lágbára gan-an, tí kì í ṣe ẹni tí ẹ̀ṣẹ̀ ń wùú dá, dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
|
Ayah 5:4 الأية
يَسْأَلُونَكَ مَاذَا أُحِلَّ لَهُمْ ۖ قُلْ أُحِلَّ لَكُمُ الطَّيِّبَاتُ ۙ وَمَا
عَلَّمْتُم مِّنَ الْجَوَارِحِ مُكَلِّبِينَ تُعَلِّمُونَهُنَّ مِمَّا عَلَّمَكُمُ
اللهُ ۖ فَكُلُوا مِمَّا أَمْسَكْنَ عَلَيْكُمْ وَاذْكُرُوا اسْمَ اللهِ
عَلَيْهِ ۖ وَاتَّقُوا اللهَ ۚ إِنَّ اللهَ سَرِيعُ الْحِسَابِ
Yas-aloonaka matha ohilla lahumqul ohilla lakumu attayyibatu wamaAAallamtum mina
aljawarihi mukallibeenatuAAallimoonahunna mimma AAallamakumu Allahufakuloo mimma
amsakna AAalaykum wathkurooisma Allahi AAalayhi wattaqoo Allaha innaAllaha
sareeAAu alhisab
Yoruba
Wọ́n ń bi ọ́ léèrè pé: "Kí ni wọ́n ṣe ní ẹ̀tọ́ fún wọn?" Sọ pé: "Wọ́n ṣe àwọn n̄ǹkan dáadáa ní ẹ̀tọ́ fún yín àti (ẹran tí ẹ pa nípasẹ̀) èyí tí ẹ kọ́ ní ẹ̀kọ́ (ìdọdẹ) nínú àwọn ẹranko àti ẹyẹ tí ń dọdẹ. Ẹ kọ́ àwọn ajá lẹ́kọ̀ọ́ ìdọdẹ, kí ẹ kọ́ wọn nínú ohun tí Allāhu fi mọ̀ yín. Nítorí náà, ẹ jẹ nínú ohun tí wọ́n bá pa fún yín, kí ẹ sì ṣe bismillāh sí i. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́.
|
Ayah 5:5 الأية
الْيَوْمَ أُحِلَّ لَكُمُ الطَّيِّبَاتُ ۖ وَطَعَامُ الَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ
حِلٌّ لَّكُمْ وَطَعَامُكُمْ حِلٌّ لَّهُمْ ۖ وَالْمُحْصَنَاتُ مِنَ الْمُؤْمِنَاتِ
وَالْمُحْصَنَاتُ مِنَ الَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ مِن قَبْلِكُمْ إِذَا
آتَيْتُمُوهُنَّ أُجُورَهُنَّ مُحْصِنِينَ غَيْرَ مُسَافِحِينَ وَلَا مُتَّخِذِي
أَخْدَانٍ ۗ وَمَن يَكْفُرْ بِالْإِيمَانِ فَقَدْ حَبِطَ عَمَلُهُ وَهُوَ فِي
الْآخِرَةِ مِنَ الْخَاسِرِينَ
Alyawma ohilla lakumu attayyibatuwataAAamu allatheena ootoo alkitaba hillunlakum
wataAAamukum hillun lahum walmuhsanatumina almu/minati walmuhsanatu
minaallatheena ootoo alkitaba min qablikum itha ataytumoohunnaojoorahunna
muhsineena ghayra musafiheenawala muttakhithee akhdanin waman yakfur
bil-eemanifaqad habita AAamaluhu wahuwa fee al-akhiratimina alkhasireen
Yoruba
Wọ́n ṣe àwọn n̄ǹkan dáadáa ní ẹ̀tọ́ fún yín lónìí. Àti oúnjẹ àwọn tí A fún ní tírà, ẹ̀tọ́ ni fún yín. Oúnjẹ tiyín náà, ẹ̀tọ́ ni fún wọn. (Ẹ̀tọ́ ni fún yín láti fẹ́) àwọn olómìnira nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin àti àwọn olómìnira lóbìnrin nínú àwọn tí A fún ní tírà ṣíwájú yín, nígbà tí ẹ bá ti fún wọn ní ṣọ̀daàkí wọn; ẹ fẹ́ wọn ní fífẹ́ (bí 'Islām ṣe ní kí ẹ fẹ́ ìyàwó), láì níí máa bá wọn ṣe sìná (ṣíwájú yìgì) láì sì níí máa yàn wọ́n lálè. Ẹnikẹ́ni tí ó bá lòdì sí ìgbàgbọ́ òdodo, iṣẹ́ rẹ̀ ti bàjẹ́. Ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, ó sì máa wà nínú àwọn ẹni òfò.
|
Ayah 5:6 الأية
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِذَا قُمْتُمْ إِلَى الصَّلَاةِ فَاغْسِلُوا
وُجُوهَكُمْ وَأَيْدِيَكُمْ إِلَى الْمَرَافِقِ وَامْسَحُوا بِرُءُوسِكُمْ
وَأَرْجُلَكُمْ إِلَى الْكَعْبَيْنِ ۚ وَإِن كُنتُمْ جُنُبًا فَاطَّهَّرُوا ۚ وَإِن
كُنتُم مَّرْضَىٰ أَوْ عَلَىٰ سَفَرٍ أَوْ جَاءَ أَحَدٌ مِّنكُم مِّنَ الْغَائِطِ
أَوْ لَامَسْتُمُ النِّسَاءَ فَلَمْ تَجِدُوا مَاءً فَتَيَمَّمُوا صَعِيدًا
طَيِّبًا فَامْسَحُوا بِوُجُوهِكُمْ وَأَيْدِيكُم مِّنْهُ ۚ مَا يُرِيدُ اللهُ
لِيَجْعَلَ عَلَيْكُم مِّنْ حَرَجٍ وَلَٰكِن يُرِيدُ لِيُطَهِّرَكُمْ وَلِيُتِمَّ
نِعْمَتَهُ عَلَيْكُمْ لَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ
Ya ayyuha allatheena amanooitha qumtum ila assalati faghsiloowujoohakum
waaydiyakum ila almarafiqi wamsahoobiruoosikum waarjulakum ila alkaAAbayni wa-in
kuntumjunuban fattahharoo wa-in kuntum marda awAAala safarin aw jaa ahadun
minkum mina algha-itiaw lamastumu annisaa falam tajidoo maanfatayammamoo
saAAeedan tayyiban famsahoobiwujoohikum waaydeekum minhu ma yureedu
AllahuliyajAAala AAalaykum min harajin walakin yureeduliyutahhirakum waliyutimma
niAAmatahu AAalaykumlaAAallakum tashkuroon
Yoruba
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá fẹ́ kírun, ẹ wẹ ojú yín àti ọwọ́ yín títí dé ìgúnpá. Ẹ fi omi pá orí yín. Ẹ wẹ ẹsẹ̀ yín títí dé kókósẹ̀ méjèèjì. Tí ẹ bá ní jánnábà lára, ẹ wẹ ìwẹ̀ ìmọ́ra. Tí ẹ bá jẹ́ aláìsàn, tàbí ẹ wà lórí ìrìn-àjò tàbí ẹnì kan nínú yín dé láti ilé ìgbọ̀nsẹ̀, tàbí ẹ súnmọ́ obìnrin, tí ẹ ò bá rí omi, nígbà náà kí ẹ fi erùpẹ̀ mímọ́ ṣe tayamọmu. Ẹ fi pá ojú yín àti ọwọ́ yín lára rẹ̀. Allāhu kò fẹ́ láti kó wàhálà ba yín, ṣùgbọ́n Ó fẹ́ láti fọ̀ yín mọ́. Ó sì fẹ́ ṣe àṣepé ìdẹ̀ra Rẹ̀ fún yín nítorí kí ẹ lè dúpẹ́.
|
Ayah 5:7 الأية
وَاذْكُرُوا نِعْمَةَ اللهِ عَلَيْكُمْ وَمِيثَاقَهُ الَّذِي وَاثَقَكُم بِهِ
إِذْ قُلْتُمْ سَمِعْنَا وَأَطَعْنَا ۖ وَاتَّقُوا اللهَ ۚ إِنَّ اللهَ عَلِيمٌ
بِذَاتِ الصُّدُورِ
Wathkuroo niAAmata AllahiAAalaykum wameethaqahu allathee wathaqakumbihi ith
qultum samiAAna waataAAna wattaqooAllaha inna Allaha AAaleemun bithati assudoor
Yoruba
Ẹ rántí ìdẹ̀ra tí Allāhu ṣe fún yín àti àdéhùn Rẹ̀, èyí tí Ó ba yín ṣe, nígbà tí ẹ̀yin sọ pé: "A gbọ́, a sì tẹ̀lé e." Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà ẹ̀dá.
|
Ayah 5:8 الأية
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا كُونُوا قَوَّامِينَ لِلَّهِ شُهَدَاءَ بِالْقِسْطِ
ۖ وَلَا يَجْرِمَنَّكُمْ شَنَآنُ قَوْمٍ عَلَىٰ أَلَّا تَعْدِلُوا ۚ اعْدِلُوا هُوَ
أَقْرَبُ لِلتَّقْوَىٰ ۖ وَاتَّقُوا اللهَ ۚ إِنَّ اللهَ خَبِيرٌ بِمَا
تَعْمَلُونَ
Ya ayyuha allatheena amanookoonoo qawwameena lillahi shuhadaa bilqistiwala
yajrimannakum shanaanu qawmin AAala allataAAdiloo iAAdiloo huwa aqrabu littaqwa
wattaqooAllaha inna Allaha khabeerun bima taAAmaloon
Yoruba
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ jẹ́ olùdúró ṣinṣin lórí déédé nítorí ti Allāhu nígbà tí ẹ bá ń jẹ́rìí. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìkórira àwọn ènìyàn kan tì yín láti má ṣe déédé. Ẹ ṣe déédé, òhun l'ó súnmọ́ ìbẹ̀rù Allāhu jùlọ. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
|
Ayah 5:9 الأية
وَعَدَ اللهُ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ ۙ لَهُم مَّغْفِرَةٌ
وَأَجْرٌ عَظِيمٌ
WaAAada Allahu allatheena amanoowaAAamiloo assalihati lahum maghfiratunwaajrun
AAatheem
Yoruba
Allāhu ṣe àdéhùn fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣiṣẹ́ rere (pé) àforíjìn àti ẹ̀san ńlá ń bẹ fún wọn.
|
Ayah 5:10 الأية
وَالَّذِينَ كَفَرُوا وَكَذَّبُوا بِآيَاتِنَا أُولَٰئِكَ أَصْحَابُ الْجَحِيمِ
Wallatheena kafaroo wakaththaboobi-ayatina ola-ika as-habualjaheem
Yoruba
Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì pe àwọn āyah Wa ní irọ́, àwọn wọ̀nyẹn ní èrò inú iná Jẹhīm.
|
Ayah 5:11 الأية
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا اذْكُرُوا نِعْمَتَ اللهِ عَلَيْكُمْ إِذْ هَمَّ
قَوْمٌ أَن يَبْسُطُوا إِلَيْكُمْ أَيْدِيَهُمْ فَكَفَّ أَيْدِيَهُمْ عَنكُمْ ۖ
وَاتَّقُوا اللهَ ۚ وَعَلَى اللهِ فَلْيَتَوَكَّلِ الْمُؤْمِنُونَ
Ya ayyuha allatheena amanooothkuroo niAAmata Allahi AAalaykum ith hammaqawmun an
yabsutoo ilaykum aydiyahum fakaffa aydiyahumAAankum wattaqoo Allaha waAAala
Allahifalyatawakkali almu/minoon
Yoruba
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ rántí ìdẹ̀ra tí Allāhu ṣe fún yín; nígbà tí ìjọ kan gbèrò látinawọ́ ìjà si yín, (Allāhu) sì kó wọn lọ́wọ́ rọ̀ fún yín. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Àti pé Allāhu ni kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbáralé.
|
Ayah 5:12 الأية
وَلَقَدْ أَخَذَ اللهُ مِيثَاقَ بَنِي إِسْرَائِيلَ وَبَعَثْنَا مِنْهُمُ اثْنَيْ
عَشَرَ نَقِيبًا ۖ وَقَالَ اللهُ إِنِّي مَعَكُمْ ۖ لَئِنْ أَقَمْتُمُ الصَّلَاةَ
وَآتَيْتُمُ الزَّكَاةَ وَآمَنتُم بِرُسُلِي وَعَزَّرْتُمُوهُمْ وَأَقْرَضْتُمُ
اللهَ قَرْضًا حَسَنًا لَّأُكَفِّرَنَّ عَنكُمْ سَيِّئَاتِكُمْ
وَلَأُدْخِلَنَّكُمْ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِن تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ ۚ فَمَن كَفَرَ
بَعْدَ ذَٰلِكَ مِنكُمْ فَقَدْ ضَلَّ سَوَاءَ السَّبِيلِ
Walaqad akhatha Allahu meethaqabanee isra-eela wabaAAathna minhumu ithnay
AAasharanaqeeban waqala Allahu innee maAAakum la-inaqamtumu assalata waataytumu
azzakatawaamantum birusulee waAAazzartumoohum waaqradtumuAllaha qardan hasanan
laokaffiranna AAankumsayyi-atikum walaodkhilannakum jannatin tajree mintahtiha
al-anharu faman kafara baAAda thalikaminkum faqad dalla sawaa assabeel
Yoruba
Dájúdájú Allāhu gba àdéhùn lọ́wọ́ àwọn ọmọ 'Isrọ̄'īl. A sì gbé ìjòyè méjìlá dìde nínú wọn. Allāhu sì sọ (fún wọn) pé: "Dájúdájú Mò ń bẹ pẹ̀lú yín, tí ẹ bá ń kírun, tí ẹ̀ bá ń yọ Zakāh, tí ẹ bá gba àwọn Òjíṣẹ́ Mi gbọ́, tí ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́, tí ẹ sì yá Allāhu ní dúkìá tó dára. Dájúdájú Mo máa pa àwọn àṣìṣe yín rẹ́. Dájúdájú Mo máa mu yín wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Àmọ́ ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn ìyẹn nínú yín, ó kúkú ti ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà tààrà."
|
Ayah 5:13 الأية
فَبِمَا نَقْضِهِم مِّيثَاقَهُمْ لَعَنَّاهُمْ وَجَعَلْنَا قُلُوبَهُمْ قَاسِيَةً ۖ
يُحَرِّفُونَ الْكَلِمَ عَن مَّوَاضِعِهِ ۙ وَنَسُوا حَظًّا مِّمَّا ذُكِّرُوا بِهِ
ۚ وَلَا تَزَالُ تَطَّلِعُ عَلَىٰ خَائِنَةٍ مِّنْهُمْ إِلَّا قَلِيلًا مِّنْهُمْ ۖ
فَاعْفُ عَنْهُمْ وَاصْفَحْ ۚ إِنَّ اللهَ يُحِبُّ الْمُحْسِنِينَ
Fabima naqdihim meethaqahumlaAAannahum wajaAAalna quloobahum
qasiyatanyuharrifoona alkalima AAan mawadiAAihi wanasoo haththanmimma thukkiroo
bihi wala tazalu tattaliAAuAAala kha-inatin minhum illa qaleelan minhumfaAAfu
AAanhum wasfah inna Allahayuhibbu almuhsineen
Yoruba
Nítorí yíyẹ̀ tí wọ́n fúnra wọn yẹ àdéhùn wọn ni A fi ṣẹ́bi lé wọn. A sì mú ọkàn wọn le koko (nítorí pé), wọ́n ń gbé àwọn ọ̀rọ̀ kúrò ní àwọn àyè rẹ̀, wọ́n sì gbàgbé ìpín kan nínúoore tí́A rán wọn létí rẹ̀. O ò níí yé rí oníjàǹbá láààrin wọn àfi díẹ̀ nínú wọn. Nítorí náà, ṣe àmójúkúrò fún wọn, kí o sì foríjìn wọ́n. Dájúdájú Allāhu fẹ́ràn àwọn olùṣe-rere.
|
Ayah 5:14 الأية
وَمِنَ الَّذِينَ قَالُوا إِنَّا نَصَارَىٰ أَخَذْنَا مِيثَاقَهُمْ فَنَسُوا حَظًّا
مِّمَّا ذُكِّرُوا بِهِ فَأَغْرَيْنَا بَيْنَهُمُ الْعَدَاوَةَ وَالْبَغْضَاءَ
إِلَىٰ يَوْمِ الْقِيَامَةِ ۚ وَسَوْفَ يُنَبِّئُهُمُ اللهُ بِمَا كَانُوا
يَصْنَعُونَ
Wamina allatheena qaloo innanasara akhathna meethaqahumfanasoo haththan mimma
thukkiroobihi faaghrayna baynahumu alAAadawata walbaghdaaila yawmi alqiyamati
wasawfa yunabbi-ohumu Allahubima kanoo yasnaAAoon
Yoruba
Àti pé lọ́dọ̀ àwọn tó wí pé: "Dájúdájú nasọ̄rọ̄ ni àwa.", A gba àdéhùn lọ́wọ́ wọn, wọ́n sì gbàgbé ìpín kan nínú oore tí A rán wọn létí rẹ̀. Nítorí náà, A dá ọ̀tá àti ọ̀tẹ̀ sáààrin wọn títí di Ọjọ́ Àjíǹde. Láìpẹ́ Allāhu máa fún wọn ní ìró ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
|
Ayah 5:15 الأية
يَا أَهْلَ الْكِتَابِ قَدْ جَاءَكُمْ رَسُولُنَا يُبَيِّنُ لَكُمْ كَثِيرًا
مِّمَّا كُنتُمْ تُخْفُونَ مِنَ الْكِتَابِ وَيَعْفُو عَن كَثِيرٍ ۚ قَدْ جَاءَكُم
مِّنَ اللهِ نُورٌ وَكِتَابٌ مُّبِينٌ
Ya ahla alkitabi qad jaakumrasooluna yubayyinu lakum katheeran mimma
kuntumtukhfoona mina alkitabi wayaAAfoo AAan katheerin qad jaakummina Allahi
noorun wakitabun mubeen
Yoruba
Ẹ̀yin onítírà, dájúdájú Òjíṣẹ́ Wa ti wá ba yín. Ó ń ṣàlàyé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ohun tí ẹ fi pamọ́ nínú tírà fún yín. Ó sì ń ṣàmójúkúrò níbi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀. Ìmọ́lẹ̀ àti Tírà tó yanjú kúkú ti dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Allāhu.
|
Ayah 5:16 الأية
يَهْدِي بِهِ اللهُ مَنِ اتَّبَعَ رِضْوَانَهُ سُبُلَ السَّلَامِ وَيُخْرِجُهُم
مِّنَ الظُّلُمَاتِ إِلَى النُّورِ بِإِذْنِهِ وَيَهْدِيهِمْ إِلَىٰ صِرَاطٍ
مُّسْتَقِيمٍ
Yahdee bihi Allahu mani ittabaAAa ridwanahusubula assalami wayukhrijuhum mina
aththulumatiila annoori bi-ithnihi wayahdeehim ilasiratin mustaqeem
Yoruba
(Tírà tó yanjú náà, al-Ƙur'ān), Allāhu ń fi ṣe ìmọ̀nà fún ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé (àwọn n̄ǹkan) tí Allāhu yọ́nú sí, àwọn ọ̀nà àlàáfíà (àwọn ọ̀nà ọlà). Ó sì ń mú wọn jáde láti inú àwọn òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Ó sì ń tọ́ wọn sí ọ̀nà tààrà ('Islām).
|
Ayah 5:17 الأية
لَّقَدْ كَفَرَ الَّذِينَ قَالُوا إِنَّ اللهَ هُوَ الْمَسِيحُ ابْنُ مَرْيَمَ ۚ
قُلْ فَمَن يَمْلِكُ مِنَ اللهِ شَيْئًا إِنْ أَرَادَ أَن يُهْلِكَ الْمَسِيحَ
ابْنَ مَرْيَمَ وَأُمَّهُ وَمَن فِي الْأَرْضِ جَمِيعًا ۗ وَلِلَّهِ مُلْكُ
السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا ۚ يَخْلُقُ مَا يَشَاءُ ۚ وَاللهُ
عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
Laqad kafara allatheena qalooinna Allaha huwa almaseehu ibnu maryama qul
famanyamliku mina Allahi shay-an in arada an yuhlikaalmaseeha ibna maryama
waommahu waman fee al-ardijameeAAan walillahi mulku assamawatiwal-ardi wama
baynahuma yakhluqu mayashao wallahu AAala kulli shay-inqadeer
Yoruba
Wọ́n kúkú ti di kèfèrí, àwọn tó wí pé: "Dájúdájú Allāhu ni Mọsīh ọmọ Mọryam." Sọ pé: "Ta ló ní ìkápá kiní kan lọ́dọ̀ Allāhu tí (Allāhu) bá fẹ́ pa Mọsīh ọmọ Mọryam àti ìyá rẹ̀ àti àwọn tó ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé run pátápátá?" Ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. (Allāhu) ń ṣẹ́dàá ohunkóhun tí Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
|
Ayah 5:18 الأية
وَقَالَتِ الْيَهُودُ وَالنَّصَارَىٰ نَحْنُ أَبْنَاءُ اللهِ وَأَحِبَّاؤُهُ ۚ
قُلْ فَلِمَ يُعَذِّبُكُم بِذُنُوبِكُم ۖ بَلْ أَنتُم بَشَرٌ مِّمَّنْ خَلَقَ ۚ
يَغْفِرُ لِمَن يَشَاءُ وَيُعَذِّبُ مَن يَشَاءُ ۚ وَلِلَّهِ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ
وَالْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا ۖ وَإِلَيْهِ الْمَصِيرُ
Waqalati alyahoodu wannasaranahnu abnao Allahi waahibbaohuqul falima
yuAAaththibukum bithunoobikum bal antumbasharun mimman khalaqa yaghfiru liman
yashao wayuAAaththibuman yashao walillahi mulku assamawatiwal-ardi wama
baynahuma wa-ilayhialmaseer
Yoruba
Àwọn yẹhudi àti nasọ̄rọ̄ wí pé: "Àwa ni ọmọ Allāhu àti olólùfẹ́ Rẹ̀." Sọ pé: "Kí ni ìdí tí Ó ṣe ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ yín jẹ yín nígbà náà?" Rárá (kò rí bí ẹ ṣe wí, àmọ́) abara ni yín nínú àwọn tí Ó ṣẹ̀dá. Ó ń ṣàforíjìn fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń jẹ ẹni tí Ó bá fẹ́ níyà. Ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.
|
Ayah 5:19 الأية
يَا أَهْلَ الْكِتَابِ قَدْ جَاءَكُمْ رَسُولُنَا يُبَيِّنُ لَكُمْ عَلَىٰ فَتْرَةٍ
مِّنَ الرُّسُلِ أَن تَقُولُوا مَا جَاءَنَا مِن بَشِيرٍ وَلَا نَذِيرٍ ۖ فَقَدْ
جَاءَكُم بَشِيرٌ وَنَذِيرٌ ۗ وَاللهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
Ya ahla alkitabi qad jaakumrasooluna yubayyinu lakum AAala fatratin mina
arrusulian taqooloo ma jaana min basheerin walanatheerin faqad jaakum basheerun
wanatheerunwallahu AAala kulli shay-in qadeer
Yoruba
Ẹ̀yin onítírà, dájúdájú Òjíṣẹ́ Wa ti dé ba yín, tí ó ń ṣe àlàyé (ọ̀rọ̀) fún yín lẹ́yìn àsìkò tí A ti dá àwọn Òjísẹ́ dúró, nítorí kí ẹ má ṣe wí pé: "Kò sí oníròó ìdùnnú tàbí olùkìlọ̀ kan tí ó wá bá wa." Nítorí náà, dájúdájú oníròó ìdùnnú àti olùkìlọ̀ kan ti wá ba yín. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
|
Ayah 5:20 الأية
وَإِذْ قَالَ مُوسَىٰ لِقَوْمِهِ يَا قَوْمِ اذْكُرُوا نِعْمَةَ اللهِ عَلَيْكُمْ
إِذْ جَعَلَ فِيكُمْ أَنبِيَاءَ وَجَعَلَكُم مُّلُوكًا وَآتَاكُم مَّا لَمْ يُؤْتِ
أَحَدًا مِّنَ الْعَالَمِينَ
Wa-ith qala moosaliqawmihi ya qawmi othkuroo niAAmata AllahiAAalaykum ith
jaAAala feekum anbiyaa wajaAAalakummulookan waatakum ma lam yu/ti ahadanmina
alAAalameen
Yoruba
Nígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ rántí ìdẹ̀ra tí Allāhu ṣe fún yín, nígbà tí Ó fi àwọn Ànábì sáààrin yín, tí Ó ṣe yín ní ọba, tí Ó tún fún yín ní n̄ǹkan tí kò fún ẹnì kan rí ní àgbáyé (lásìkò tiyín).
|
Ayah 5:21 الأية
يَا قَوْمِ ادْخُلُوا الْأَرْضَ الْمُقَدَّسَةَ الَّتِي كَتَبَ اللهُ لَكُمْ
وَلَا تَرْتَدُّوا عَلَىٰ أَدْبَارِكُمْ فَتَنقَلِبُوا خَاسِرِينَ
Ya qawmi odkhuloo al-ardaalmuqaddasata allatee kataba Allahu lakum walatartaddoo
AAala adbarikum fatanqaliboo khasireen
Yoruba
Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ wọ orí ilẹ̀ mímọ́ tí Allāhu pa láṣẹ fún yín. Ẹ má se padà sẹ́yìn, nítorí kí ẹ má baà padà di ẹni òfò.
|
Ayah 5:22 الأية
قَالُوا يَا مُوسَىٰ إِنَّ فِيهَا قَوْمًا جَبَّارِينَ وَإِنَّا لَن نَّدْخُلَهَا
حَتَّىٰ يَخْرُجُوا مِنْهَا فَإِن يَخْرُجُوا مِنْهَا فَإِنَّا دَاخِلُونَ
Qaloo ya moosa innafeeha qawman jabbareena wa-inna lannadkhulaha hatta yakhrujoo
minhafa-in yakhrujoo minha fa-inna dakhiloon
Yoruba
Wọ́n wí pé: "Mūsā, dájúdájú ìjọ ajẹni-nípá wà nínú ìlú náà. Dájúdájú àwa kò sì níí wọ inú rẹ̀ títí wọn yóò fi jáde kúrò nínú rẹ̀. Tí wọ́n bá jáde kúrò nínú rẹ̀, àwa máa wọ inú rẹ̀ nígbà náà."
|
Ayah 5:23 الأية
قَالَ رَجُلَانِ مِنَ الَّذِينَ يَخَافُونَ أَنْعَمَ اللهُ عَلَيْهِمَا ادْخُلُوا
عَلَيْهِمُ الْبَابَ فَإِذَا دَخَلْتُمُوهُ فَإِنَّكُمْ غَالِبُونَ ۚ وَعَلَى
اللهِ فَتَوَكَّلُوا إِن كُنتُم مُّؤْمِنِينَ
Qala rajulani mina allatheenayakhafoona anAAama Allahu AAalayhimaodkhuloo
AAalayhimu albaba fa-itha dakhaltumoohufa-innakum ghaliboona waAAala
Allahifatawakkaloo in kuntum mu/mineen
Yoruba
Àwọn ọkùnrin méjì kan nínú àwọn tí ń páyà (Allāhu) - Allāhu sì kẹ́ àwọn méjèèjì - wọ́n sọ pé: "Ẹ gba ẹnu bodè wọ inú ìlú tọ̀ wọ́n. Tí ẹ bá wọ inú ìlú tọ̀ wọ́n, dájúdájú ẹ máa borí wọn. Allāhu sì ni kí ẹ gbáralé, tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo."
|
Ayah 5:24 الأية
قَالُوا يَا مُوسَىٰ إِنَّا لَن نَّدْخُلَهَا أَبَدًا مَّا دَامُوا فِيهَا ۖ
فَاذْهَبْ أَنتَ وَرَبُّكَ فَقَاتِلَا إِنَّا هَاهُنَا قَاعِدُونَ
Qaloo ya moosa innalan nadkhulaha abadan ma damoo feehafa-ithhab anta warabbuka
faqatila innahahuna qaAAidoon
Yoruba
Wọ́n wí pé: "Ìwọ Mūsā, dájúdájú àwa kò níí wọ inú ìlú náà láéláé níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá sì wà nínú rẹ̀. Nítorí náà, kí ìwọ àti Olúwa rẹ lọ (síbẹ̀). Kí ẹ̀yin méjèèjì jà wọ́n lógun. Dájúdájú ibí yìí ni àwa yóò jókòó sí ná."
|
Ayah 5:25 الأية
قَالَ رَبِّ إِنِّي لَا أَمْلِكُ إِلَّا نَفْسِي وَأَخِي ۖ فَافْرُقْ بَيْنَنَا
وَبَيْنَ الْقَوْمِ الْفَاسِقِينَ
Qala rabbi innee la amliku illanafsee waakhee fafruq baynana wabayna alqawmi
alfasiqeen
Yoruba
Ó sọ pé: "Olúwa mi, dájúdájú èmi kò ní ìkápá lórí ẹnì kan bí kò ṣe (lórí) ara mi àti arákùnrin mi. Nítorí náà, ya àwa àti ìjọ òbìlẹ̀jẹ́ sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀."
|
Ayah 5:26 الأية
قَالَ فَإِنَّهَا مُحَرَّمَةٌ عَلَيْهِمْ ۛ أَرْبَعِينَ سَنَةً ۛ يَتِيهُونَ فِي
الْأَرْضِ ۚ فَلَا تَأْسَ عَلَى الْقَوْمِ الْفَاسِقِينَ
Qala fa-innaha muharramatunAAalayhim arbaAAeena sanatan yateehoona fee al-ardi
falata/sa AAala alqawmi alfasiqeen
Yoruba
(Allāhu) sọ pé: "Dájúdájú ó ti di èèwọ̀ fún wọn (láti wọnú ìlú náà) fún ogójì ọdún tí wọn yóò fi rin àrìnnù lórí́ilẹ̀. Nítorí náà, má ṣe banújẹ́ nítorí ìjọ òbìlẹ̀jẹ́."
|
Ayah 5:27 الأية
وَاتْلُ عَلَيْهِمْ نَبَأَ ابْنَيْ آدَمَ بِالْحَقِّ إِذْ قَرَّبَا قُرْبَانًا
فَتُقُبِّلَ مِنْ أَحَدِهِمَا وَلَمْ يُتَقَبَّلْ مِنَ الْآخَرِ قَالَ
لَأَقْتُلَنَّكَ ۖ قَالَ إِنَّمَا يَتَقَبَّلُ اللهُ مِنَ الْمُتَّقِينَ
Watlu AAalayhim nabaa ibnay adamabilhaqqi ith qarraba qurbananfatuqubbila min
ahadihima walam yutaqabbal mina al-akhariqala laaqtulannaka qala innama
yataqabbaluAllahu mina almuttaqeen
Yoruba
Ka ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ (Ànábì) Ādam méjèèjì fún wọn pẹ̀lú òdodo. (Rántí) nígbà tí àwọn méjèèjì ṣe ọrẹ àsè (láti fi súnmọ́ Allāhu). A gba ti ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì, A kò sì gba ti ìkejì. (Ẹni tí A kò gba tirẹ̀) wí pé: "Dájúdájú èmi yóò pa ọ́." (Ìkejì) sì sọ pé: "(Ọrẹ àsè) tàwọn olùbẹ̀rù nìkan ni Allāhu máa gbà.
|
Ayah 5:28 الأية
لَئِن بَسَطتَ إِلَيَّ يَدَكَ لِتَقْتُلَنِي مَا أَنَا بِبَاسِطٍ يَدِيَ إِلَيْكَ
لِأَقْتُلَكَ ۖ إِنِّي أَخَافُ اللهَ رَبَّ الْعَالَمِينَ
La-in basatta ilayya yadakalitaqtulanee ma ana bibasitin yadiyailayka
li-aqtulaka innee akhafu Allaha rabba alAAalameen
Yoruba
Dájúdájú tí o bá na ọwọ́ rẹ sí mi láti pa mí, èmi kò sì níí na ọwọ́ mi sí ọ láti pa ọ́, nítorí pé dájúdáju èmi ń bẹ̀rù Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
|
Ayah 5:29 الأية
إِنِّي أُرِيدُ أَن تَبُوءَ بِإِثْمِي وَإِثْمِكَ فَتَكُونَ مِنْ أَصْحَابِ
النَّارِ ۚ وَذَٰلِكَ جَزَاءُ الظَّالِمِينَ
Innee oreedu an taboo-a bi-ithmee wa-ithmikafatakoona min as-habi annari
wathalikajazao aththalimeen
Yoruba
Dájúdájú èmi fẹ́ kí o padà (sí ọ̀dọ̀ Allāhu ní Ọjọ́ Àjíǹde) pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ (bí ó ṣe pa) mí àti ẹ̀ṣẹ̀ tìrẹ nítorí kí o lè jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn èrò inú Iná. Ìyẹn sì ni ẹ̀san àwọn alábòsí."
|
Ayah 5:30 الأية
فَطَوَّعَتْ لَهُ نَفْسُهُ قَتْلَ أَخِيهِ فَقَتَلَهُ فَأَصْبَحَ مِنَ
الْخَاسِرِينَ
FatawwaAAat lahu nafsuhu qatlaakheehi faqatalahu faasbaha mina alkhasireen
Yoruba
Ó mú ọkàn ara rẹ̀ gírí láti pa arákùnrin rẹ̀. Ó pa á. Ó sì di ọ̀kan nínú àwọn ẹni òfò.
|
Ayah 5:31 الأية
فَبَعَثَ اللهُ غُرَابًا يَبْحَثُ فِي الْأَرْضِ لِيُرِيَهُ كَيْفَ يُوَارِي
سَوْءَةَ أَخِيهِ ۚ قَالَ يَا وَيْلَتَا أَعَجَزْتُ أَنْ أَكُونَ مِثْلَ هَٰذَا
الْغُرَابِ فَأُوَارِيَ سَوْءَةَ أَخِي ۖ فَأَصْبَحَ مِنَ النَّادِمِينَ
FabaAAatha Allahu ghuraban yabhathufee al-ardi liyuriyahu kayfa yuwaree
saw-ataakheehi qala ya waylata aAAajaztu an akoonamithla hatha alghurabi
faowariya saw-ataakhee faasbaha mina annadimeen
Yoruba
Allāhu sì gbé ẹyẹ kannakánná kan dìde, tí ó ń fi ẹsẹ̀ walẹ̀ nítorí kí ó lè fi bí ó ṣe máa bo òkú arákùnrin rẹ̀ mọ́ inú ilẹ̀ hàn án. Ó wí pé: "Tèmí bá mi o! Ṣé mo kágara ni láti dà bí irú ẹyẹ kannakánná yìí, kí èmi náà sì lè bo òkú arákùnrin mi mọ́lẹ̀?" Ó sì di ara àwọn alábàámọ̀.
|
Ayah 5:32 الأية
مِنْ أَجْلِ ذَٰلِكَ كَتَبْنَا عَلَىٰ بَنِي إِسْرَائِيلَ أَنَّهُ مَن قَتَلَ
نَفْسًا بِغَيْرِ نَفْسٍ أَوْ فَسَادٍ فِي الْأَرْضِ فَكَأَنَّمَا قَتَلَ النَّاسَ
جَمِيعًا وَمَنْ أَحْيَاهَا فَكَأَنَّمَا أَحْيَا النَّاسَ جَمِيعًا ۚ وَلَقَدْ
جَاءَتْهُمْ رُسُلُنَا بِالْبَيِّنَاتِ ثُمَّ إِنَّ كَثِيرًا مِّنْهُم بَعْدَ
ذَٰلِكَ فِي الْأَرْضِ لَمُسْرِفُونَ
Min ajli thalika katabna AAalabanee isra-eela annahu man qatala nafsan bighayri
nafsinaw fasadin fee al-ardi fakaannama qatala annasajameeAAan waman ahyaha
fakaannama ahyaannasa jameeAAan walaqad jaat-hum rusulunabilbayyinati thumma
inna katheeran minhum baAAda thalikafee al-ardi lamusrifoon
Yoruba
Nítorí ìyẹn, A sì ṣe é ní òfin fún àwọn ọmọ 'Isrọ̄'īl pé, dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ẹ̀mí (ènìyàn) kan láìjẹ́ nítorí pípa ẹ̀mí (ènìyàn) kan tàbí ṣíṣe ìbàjẹ́ kan lórí ilẹ̀, ó dà bí ẹni tí ó pa gbogbo ènìyàn pátápátá. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì mú ẹ̀mí (ènìyàn) ṣẹ̀mí, ó dà bí ẹni tí ó mú gbogbo ènìyàn ṣẹ̀mí pátápátá. Àwọn Òjíṣẹ́ Wa sì ti wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tó yanjú. Lẹ́yìn náà, dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn lẹ́yìn ìyẹn ni alákọyọ lórí ilẹ̀.
|
Ayah 5:33 الأية
إِنَّمَا جَزَاءُ الَّذِينَ يُحَارِبُونَ اللهَ وَرَسُولَهُ وَيَسْعَوْنَ فِي
الْأَرْضِ فَسَادًا أَن يُقَتَّلُوا أَوْ يُصَلَّبُوا أَوْ تُقَطَّعَ أَيْدِيهِمْ
وَأَرْجُلُهُم مِّنْ خِلَافٍ أَوْ يُنفَوْا مِنَ الْأَرْضِ ۚ ذَٰلِكَ لَهُمْ خِزْيٌ
فِي الدُّنْيَا ۖ وَلَهُمْ فِي الْآخِرَةِ عَذَابٌ عَظِيمٌ
Innama jazao allatheenayuhariboona Allaha warasoolahu wayasAAawna feeal-ardi
fasadan an yuqattaloo aw yusallabooaw tuqattaAAa aydeehim waarjuluhum min
khilafin awyunfaw mina al-ardi thalika lahum khizyun fee addunyawalahum fee
al-akhirati AAathabun AAatheem
Yoruba
Ẹ̀san àwọn tó ń gbógun ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣe ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀ ni pé, kí ẹ pa wọ́n tàbí kí ẹ kàn wọ́n mọ́ igi àgbélébùú tàbí kí ẹ gé ọwọ́ wọn àti ẹsẹ̀ wọn ní ìpasípayọ tàbí kí ẹ lé wọn kúrò nínú ìlú. Ìyẹn ni ìyẹpẹrẹ fún wọn nílé ayé. Ìyà ńlá sì ń bẹ fún wọn ní ọ̀run.
|
Ayah 5:34 الأية
إِلَّا الَّذِينَ تَابُوا مِن قَبْلِ أَن تَقْدِرُوا عَلَيْهِمْ ۖ فَاعْلَمُوا
أَنَّ اللهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ
Illa allatheena taboomin qabli an taqdiroo AAalayhim faAAlamoo anna
Allahaghafoorun raheem
Yoruba
Àyàfi àwọn tó ronú pìwàdà ṣíwájú kí ẹ tó lágbára lórí wọn. Nítorí náà, ẹ mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
|
Ayah 5:35 الأية
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا اتَّقُوا اللهَ وَابْتَغُوا إِلَيْهِ
الْوَسِيلَةَ وَجَاهِدُوا فِي سَبِيلِهِ لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ
Ya ayyuha allatheena amanooittaqoo Allaha wabtaghoo ilayhi alwaseelata
wajahidoofee sabeelihi laAAallakum tuflihoon
Yoruba
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì wá àtẹ̀gùn sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ẹ jagun sí ojú-ọ̀nà Rẹ̀ nítorí kí ẹ lè jèrè.
|
Ayah 5:36 الأية
إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا لَوْ أَنَّ لَهُم مَّا فِي الْأَرْضِ جَمِيعًا وَمِثْلَهُ
مَعَهُ لِيَفْتَدُوا بِهِ مِنْ عَذَابِ يَوْمِ الْقِيَامَةِ مَا تُقُبِّلَ مِنْهُمْ
ۖ وَلَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ
Inna allatheena kafaroo law annalahum ma fee al-ardi jameeAAan wamithlahu
maAAahuliyaftadoo bihi min AAathabi yawmi alqiyamati matuqubbila minhum walahum
AAathabun aleem
Yoruba
Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí ó bá jẹ́ pé gbogbo ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé pátápátá jẹ́ tiwọn àti irú rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ láti fi gba ara wọn sílẹ̀ níbi ìyà Ọjọ́ Àjíǹde, A ò níí gbà á ní ọwọ́ wọn. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sìwà fún wọn.
|
Ayah 5:37 الأية
يُرِيدُونَ أَن يَخْرُجُوا مِنَ النَّارِ وَمَا هُم بِخَارِجِينَ مِنْهَا ۖ
وَلَهُمْ عَذَابٌ مُّقِيمٌ
Yureedoona an yakhrujoo mina annariwama hum bikharijeena minha walahum
AAathabunmuqeem
Yoruba
Wọn yóò fẹ́ jáde kúrò nínú Iná, wọn kò sì níí lè jáde kúrò nínú rẹ̀. Ìyà gbére sì wà fún wọn.
|
Ayah 5:38 الأية
وَالسَّارِقُ وَالسَّارِقَةُ فَاقْطَعُوا أَيْدِيَهُمَا جَزَاءً بِمَا كَسَبَا
نَكَالًا مِّنَ اللهِ ۗ وَاللهُ عَزِيزٌ حَكِيمٌ
Wassariqu wassariqatufaqtaAAoo aydiyahuma jazaan bimakasaba nakalan mina Allahi
wallahuAAazeezun hakeem
Yoruba
Olè lọ́kùnrin àti olè lóbìnrin, ẹ gé ọwọ́ àwọn méjèèjì. (Ó jẹ́) ẹ̀san fún iṣẹ́ ọwọ́ àwọn méjèèjì. (Ó sì jẹ́) ìjìyà láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
|
Ayah 5:39 الأية
فَمَن تَابَ مِن بَعْدِ ظُلْمِهِ وَأَصْلَحَ فَإِنَّ اللهَ يَتُوبُ عَلَيْهِ ۗ
إِنَّ اللهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ
Faman taba min baAAdi thulmihiwaaslaha fa-inna Allaha yatoobu AAalayhiinna
Allaha ghafoorun raheem
Yoruba
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ronú pìwàdà lẹ́yìn àbòsí (ọwọ́) rẹ̀, tí ó sì ṣe àtúnṣe, dájúdájú Allāhu yóò gba ìronúpìwàdà rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Aláàánú.
|
Ayah 5:40 الأية
أَلَمْ تَعْلَمْ أَنَّ اللهَ لَهُ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ يُعَذِّبُ
مَن يَشَاءُ وَيَغْفِرُ لِمَن يَشَاءُ ۗ وَاللهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
Alam taAAlam anna Allaha lahu mulku assamawatiwal-ardi yuAAaththibu man
yashaowayaghfiru liman yashao wallahu AAalakulli shay-in qadeer
Yoruba
Ṣé o ò mọ̀ pé dájúdájú ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀? Ó máa jẹ ẹni tí Ó bá fẹ́ níyà. Ó sì máa forí jin ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
|
Ayah 5:41 الأية
يَا أَيُّهَا الرَّسُولُ لَا يَحْزُنكَ الَّذِينَ يُسَارِعُونَ فِي الْكُفْرِ مِنَ
الَّذِينَ قَالُوا آمَنَّا بِأَفْوَاهِهِمْ وَلَمْ تُؤْمِن قُلُوبُهُمْ ۛ وَمِنَ
الَّذِينَ هَادُوا ۛ سَمَّاعُونَ لِلْكَذِبِ سَمَّاعُونَ لِقَوْمٍ آخَرِينَ لَمْ
يَأْتُوكَ ۖ يُحَرِّفُونَ الْكَلِمَ مِن بَعْدِ مَوَاضِعِهِ ۖ يَقُولُونَ إِنْ
أُوتِيتُمْ هَٰذَا فَخُذُوهُ وَإِن لَّمْ تُؤْتَوْهُ فَاحْذَرُوا ۚ وَمَن يُرِدِ
اللهُ فِتْنَتَهُ فَلَن تَمْلِكَ لَهُ مِنَ اللهِ شَيْئًا ۚ أُولَٰئِكَ
الَّذِينَ لَمْ يُرِدِ اللهُ أَن يُطَهِّرَ قُلُوبَهُمْ ۚ لَهُمْ فِي الدُّنْيَا
خِزْيٌ ۖ وَلَهُمْ فِي الْآخِرَةِ عَذَابٌ عَظِيمٌ
Ya ayyuha arrasoolu layahzunka allatheena yusariAAoona fee alkufrimina
allatheena qaloo amanna bi-afwahihimwalam tu/min quloobuhum wamina allatheena
hadoosammaAAoona lilkathibi sammaAAoona liqawmin akhareenalam ya/tooka
yuharrifoona alkalima min baAAdi mawadiAAihiyaqooloona in ooteetum hatha
fakhuthoohu wa-in lamtu/tawhu fahtharoo waman yuridi Allahufitnatahu falan
tamlika lahu mina Allahi shay-an ola-ikaallatheena lam yuridi Allahu an
yutahhiraquloobahum lahum fee addunya khizyun walahum feeal-akhirati AAathabun
AAatheem
Yoruba
Ìwọ Òjíṣẹ́, má ṣe jẹ́ kí ó bà ọ́ nínú jẹ́ àwọn tó ń yára lọ sínú àìgbàgbọ́ nínú àwọn tó fi ẹnu ara wọn wí pé: "A gbàgbọ́." - tí ọkàn wọn kò sì gbàgbọ́ ní òdodo - àti àwọn tó di yẹhudi, tí wọ́n ń tẹ́tí sí irọ́, tí wọ́n sì ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ fún àwọn ènìyàn mìíràn tí kò wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, tí wọ́n ń yí ọ̀rọ̀ padà kúrò ní àwọn àyè rẹ̀, wọ́n sì ń wí pé: "Tí wọ́n bá fún yín ní èyí ẹ gbà á. Tí wọn kò bá sì fún yín ẹ ṣọ́ra." Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fẹ́ fòòró rẹ̀, o ò ní ìkápá kiní kan lọ́dọ̀ Allāhu fún un. Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu kò fẹ́ fọ ọkàn wọn mọ́. Ìdójútì ń bẹ fún wọn ní ayé. Ìyà ńlá sì ń bẹ fún wọn ní ọ̀run.
|
Ayah 5:42 الأية
سَمَّاعُونَ لِلْكَذِبِ أَكَّالُونَ لِلسُّحْتِ ۚ فَإِن جَاءُوكَ فَاحْكُم
بَيْنَهُمْ أَوْ أَعْرِضْ عَنْهُمْ ۖ وَإِن تُعْرِضْ عَنْهُمْ فَلَن يَضُرُّوكَ
شَيْئًا ۖ وَإِنْ حَكَمْتَ فَاحْكُم بَيْنَهُم بِالْقِسْطِ ۚ إِنَّ اللهَ يُحِبُّ
الْمُقْسِطِينَ
SammaAAoona lilkathibi akkaloonalissuhti fa-in jaooka fahkumbaynahum aw aAArid
AAanhum wa-in tuAArid AAanhumfalan yadurrooka shay-an wa-in hakamta
fahkumbaynahum bilqisti inna Allaha yuhibbualmuqsiteen
Yoruba
Wọ́n ń tẹ́tí gbọ́ irọ́, wọ́n sì ń jẹ n̄ǹkan èèwọ̀. Nítorí náà, tí wọ́n bá wá bá ọ, ṣèdájọ́ láààrin wọn tàbí kí o ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn. Tí o bá ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn, wọn kò lè kó ìnira kan kan bá ọ. Tí o bá sì fẹ́ dájọ́, ṣe ìdájọ́ láààrin wọn pẹ̀lú déédé. Dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn onídéédé.
|
Ayah 5:43 الأية
وَكَيْفَ يُحَكِّمُونَكَ وَعِندَهُمُ التَّوْرَاةُ فِيهَا حُكْمُ اللهِ ثُمَّ
يَتَوَلَّوْنَ مِن بَعْدِ ذَٰلِكَ ۚ وَمَا أُولَٰئِكَ بِالْمُؤْمِنِينَ
Wakayfa yuhakkimoonaka waAAindahumu attawratufeeha hukmu Allahi thumma
yatawallawna minbaAAdi thalika wama ola-ika bilmu/mineen
Yoruba
Báwo ni wọ́n á ṣe fi ọ́ ṣe adájọ́, nígbà tí ó jẹ́ pé at-Taorāh wà lọ́dọ̀ wọn. Ìdájọ́ Allāhu sì wà nínú rẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọ́n ń pẹ̀yìndà lẹ́yìn ìyẹn. Àwọn wọ̀nyẹn kì í ṣe onígbàgbọ́ òdodo.
|
Ayah 5:44 الأية
إِنَّا أَنزَلْنَا التَّوْرَاةَ فِيهَا هُدًى وَنُورٌ ۚ يَحْكُمُ بِهَا
النَّبِيُّونَ الَّذِينَ أَسْلَمُوا لِلَّذِينَ هَادُوا وَالرَّبَّانِيُّونَ
وَالْأَحْبَارُ بِمَا اسْتُحْفِظُوا مِن كِتَابِ اللهِ وَكَانُوا عَلَيْهِ
شُهَدَاءَ ۚ فَلَا تَخْشَوُا النَّاسَ وَاخْشَوْنِ وَلَا تَشْتَرُوا بِآيَاتِي
ثَمَنًا قَلِيلًا ۚ وَمَن لَّمْ يَحْكُم بِمَا أَنزَلَ اللهُ فَأُولَٰئِكَ هُمُ
الْكَافِرُونَ
Inna anzalna attawratafeeha hudan wanoorun yahkumu biha annabiyyoonaallatheena
aslamoo lillatheena hadoo warrabbaniyyoonawal-ahbaru bima istuhfithoomin kitabi
Allahi wakanoo AAalayhi shuhadaafala takhshawoo annasa wakhshawniwala tashtaroo
bi-ayatee thamanan qaleelanwaman lam yahkum bima anzala Allahu faola-ikahumu
alkafiroon
Yoruba
Dájúdájú Àwa sọ at-Taorāh kalẹ̀. Ìmọ̀nà àti ìmọ́lẹ̀ ń bẹ nínú rẹ̀. Àwọn Ànábì tí wọ́n jẹ́ mùsùlùmí ń fi ṣe ìdájọ́ fún àwọn tó di yẹhudi. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn àlùfáà àti àwọn amòfin ẹ̀sìn (ń fi ṣe ìdájọ́) nítorí ohun tí A fún wọn ṣọ́ nínú tírà Allāhu. Wọ́n sì jẹ́ ẹlẹ́rìí lórí rẹ̀. Nítorí náà, má ṣe páyà ènìyàn. Ẹ páyà Mi. Ẹ má ṣe ta àwọn āyah Mi ní owó kékeré. Ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣèdájọ́ pẹ̀lú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni aláìgbàgbọ́.
|
Ayah 5:45 الأية
وَكَتَبْنَا عَلَيْهِمْ فِيهَا أَنَّ النَّفْسَ بِالنَّفْسِ وَالْعَيْنَ
بِالْعَيْنِ وَالْأَنفَ بِالْأَنفِ وَالْأُذُنَ بِالْأُذُنِ وَالسِّنَّ بِالسِّنِّ
وَالْجُرُوحَ قِصَاصٌ ۚ فَمَن تَصَدَّقَ بِهِ فَهُوَ كَفَّارَةٌ لَّهُ ۚ وَمَن
لَّمْ يَحْكُم بِمَا أَنزَلَ اللهُ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الظَّالِمُونَ
Wakatabna AAalayhim feeha annaannafsa binnafsi walAAayna bilAAayniwal-anfa
bil-anfi walothuna bilothuniwassinna bissinni waljurooha qisasunfaman tasaddaqa
bihi fahuwa kaffaratun lahu wamanlam yahkum bima anzala Allahu faola-ikahumu
aththalimoon
Yoruba
A sì ṣe é ní òfin sínú rẹ̀ fún wọn pé dájúdájú ẹ̀mí fún ẹ̀mí, ojú fún ojú, imú fún imú, etí fún etí àti eyín fún eyín. Òfin ẹ̀san gbígbà sì wà fún ojú-ọgbẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sí yọ̀ǹda ìgbẹ̀san, ó sì máa jẹ́ pípa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ́ fún un. Ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣèdájọ́ pẹ̀lú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni alábòsí.
|
Ayah 5:46 الأية
وَقَفَّيْنَا عَلَىٰ آثَارِهِم بِعِيسَى ابْنِ مَرْيَمَ مُصَدِّقًا لِّمَا بَيْنَ
يَدَيْهِ مِنَ التَّوْرَاةِ ۖ وَآتَيْنَاهُ الْإِنجِيلَ فِيهِ هُدًى وَنُورٌ
وَمُصَدِّقًا لِّمَا بَيْنَ يَدَيْهِ مِنَ التَّوْرَاةِ وَهُدًى وَمَوْعِظَةً
لِّلْمُتَّقِينَ
Waqaffayna AAala atharihimbiAAeesa ibni maryama musaddiqan lima baynayadayhi
mina attawrati waataynahual-injeela feehi hudan wanoorun wamusaddiqan limabayna
yadayhi mina attawrati wahudan wamawAAithatanlilmuttaqeen
Yoruba
A fi ‘Īsā ọmọ Mọryam tẹ̀lé orípa wọn (ìyẹn, àwọn Ànábì tí wọ́n jẹ́ mùsùlùmí); tí ó ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó ṣíwájú rẹ̀ nínú at-Taorāh. A sì fún un ní al-'Injīl. Ìmọ̀nà àti ìmọ́lẹ̀ wà nínú rẹ̀, tí ó ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó ṣíwájú rẹ̀ nínú at-Taorāh. (Ó jẹ́) ìmọ̀nà àti wáàsí fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu ní àsìkò tirẹ̀).
|
Ayah 5:47 الأية
وَلْيَحْكُمْ أَهْلُ الْإِنجِيلِ بِمَا أَنزَلَ اللهُ فِيهِ ۚ وَمَن لَّمْ
يَحْكُم بِمَا أَنزَلَ اللهُ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الْفَاسِقُونَ
Walyahkum ahlu al-injeeli bimaanzala Allahu feehi waman lam yahkum bimaanzala
Allahu faola-ika humu alfasiqoon
Yoruba
Kí àwọn tí A fún ní al-'Injīl ṣèdájọ́ pẹ̀lú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ nínú rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣèdájọ́ pẹ̀lú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni òbìlẹ̀jẹ́.
|
Ayah 5:48 الأية
وَأَنزَلْنَا إِلَيْكَ الْكِتَابَ بِالْحَقِّ مُصَدِّقًا لِّمَا بَيْنَ يَدَيْهِ
مِنَ الْكِتَابِ وَمُهَيْمِنًا عَلَيْهِ ۖ فَاحْكُم بَيْنَهُم بِمَا أَنزَلَ
اللهُ ۖ وَلَا تَتَّبِعْ أَهْوَاءَهُمْ عَمَّا جَاءَكَ مِنَ الْحَقِّ ۚ لِكُلٍّ
جَعَلْنَا مِنكُمْ شِرْعَةً وَمِنْهَاجًا ۚ وَلَوْ شَاءَ اللهُ لَجَعَلَكُمْ
أُمَّةً وَاحِدَةً وَلَٰكِن لِّيَبْلُوَكُمْ فِي مَا آتَاكُمْ ۖ فَاسْتَبِقُوا
الْخَيْرَاتِ ۚ إِلَى اللهِ مَرْجِعُكُمْ جَمِيعًا فَيُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمْ
فِيهِ تَخْتَلِفُونَ
Waanzalna ilayka alkitaba bilhaqqimusaddiqan lima bayna yadayhi mina
alkitabiwamuhayminan AAalayhi fahkum baynahum bimaanzala Allahu wala tattabiAA
ahwaahum AAammajaaka mina alhaqqi likullin jaAAalna minkumshirAAatan waminhajan
walaw shaa AllahulajaAAalakum ommatan wahidatan walakin liyabluwakumfeema atakum
fastabiqoo alkhayratiila Allahi marjiAAukum jameeAAan fayunabbi-okum bimakuntum
feehi takhtalifoon
Yoruba
A sọ Tírà (al-Ƙur'ān) kalẹ̀ fún ọ pẹ̀lú òdodo. Ó ń jẹ́rìí sí èyí tó jẹ́ òdodo nínú èyí tó ṣíwájú rẹ̀ nínú Tírà. Ó ń wá ààbò fún àwọn òfin inú rẹ̀. Nítorí náà, fi ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ dájọ́ láààrin wọn. Má ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn tó yapa sí ohun tí ó dé bá ọ nínú òdodo. Olúkùlùkù nínú yín ni A ti ṣe òfin àti ìlànà fún. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá ṣe yín ní ìjọ kan ṣoṣo (sínú 'Islām), ṣùgbọ́n nítorí kí Ó lè dan yín wò nínú ohun tí Ó fún yín ni. Nítorí náà, ẹ gbawájú níbi iṣẹ́ rere. Ọ̀dọ̀ Allāhu ni ibùpadàsí gbogbo yín pátápátá. Ó sì máa fún yín ní ìró nípa ohun tí ẹ̀ ń yapa-ẹnu lórí rẹ̀.
|
Ayah 5:49 الأية
وَأَنِ احْكُم بَيْنَهُم بِمَا أَنزَلَ اللهُ وَلَا تَتَّبِعْ أَهْوَاءَهُمْ
وَاحْذَرْهُمْ أَن يَفْتِنُوكَ عَن بَعْضِ مَا أَنزَلَ اللهُ إِلَيْكَ ۖ فَإِن
تَوَلَّوْا فَاعْلَمْ أَنَّمَا يُرِيدُ اللهُ أَن يُصِيبَهُم بِبَعْضِ
ذُنُوبِهِمْ ۗ وَإِنَّ كَثِيرًا مِّنَ النَّاسِ لَفَاسِقُونَ
Waani ohkum baynahum bimaanzala Allahu wala tattabiAA ahwaahum wahtharhuman
yaftinooka AAan baAAdi ma anzala Allahuilayka fa-in tawallaw faAAlam annama
yureedu Allahuan yuseebahum bibaAAdi thunoobihim wa-innakatheeran mina annasi
lafasiqoon
Yoruba
Àti pé kí o fi ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ ṣe ìdájọ́ láààrin wọn. Má ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn. Ṣọ́ra fún wọn kí wọ́n má baà fòòró rẹ kúrò níbi apá kan ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ fún ọ. Tí wọ́n bá sì gbúnrí, mọ̀ pé Allāhu kàn fẹ́ fi àdánwò kàn wọ́n ni nítorí apá kan ẹ̀ṣẹ̀ wọn.Àti pé dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú ènìyàn ni òbìlẹ̀jẹ́.
|
Ayah 5:50 الأية
أَفَحُكْمَ الْجَاهِلِيَّةِ يَبْغُونَ ۚ وَمَنْ أَحْسَنُ مِنَ اللهِ حُكْمًا
لِّقَوْمٍ يُوقِنُونَ
Afahukma aljahiliyyatiyabghoona waman ahsanu mina Allahu hukmanliqawmin
yooqinoon
Yoruba
Ṣé ìdájọ́ ìgbà àìmọ̀kan ni wọ́n ń wá ni? Ta ni ẹni tí ó dára ju Allāhu lọ níbi ìdájọ́ fún ìjọ tó ní àmọ̀dájú (nípa Rẹ̀)?
|
Ayah 5:51 الأية
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَتَّخِذُوا الْيَهُودَ وَالنَّصَارَىٰ
أَوْلِيَاءَ ۘ بَعْضُهُمْ أَوْلِيَاءُ بَعْضٍ ۚ وَمَن يَتَوَلَّهُم مِّنكُمْ
فَإِنَّهُ مِنْهُمْ ۗ إِنَّ اللهَ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الظَّالِمِينَ
Ya ayyuha allatheena amanoola tattakhithoo alyahooda wannasaraawliyaa baAAduhum
awliyao baAAdinwaman yatawallahum minkum fa-innahu minhum inna Allaha layahdee
alqawma aththalimeen
Yoruba
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe mú àwọn yẹhudi àti nasọ̄rọ̄ ní ọ̀rẹ́ àyò. Apá kan wọn lọ̀rẹ́ apá kan. Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú wọn ní ọ̀rẹ́ àyò nínú yín, dájúdájú ó ti di ara wọn. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí.
|
Ayah 5:52 الأية
فَتَرَى الَّذِينَ فِي قُلُوبِهِم مَّرَضٌ يُسَارِعُونَ فِيهِمْ يَقُولُونَ
نَخْشَىٰ أَن تُصِيبَنَا دَائِرَةٌ ۚ فَعَسَى اللهُ أَن يَأْتِيَ بِالْفَتْحِ
أَوْ أَمْرٍ مِّنْ عِندِهِ فَيُصْبِحُوا عَلَىٰ مَا أَسَرُّوا فِي أَنفُسِهِمْ
نَادِمِينَ
Fatara allatheena feequloobihim maradun yusariAAoona feehim yaqooloonanakhsha an
tuseebana da-iratun faAAasaAllahu an ya/tiya bilfathi aw amrin minAAindihi
fayusbihoo AAala ma asarroofee anfusihim nadimeen
Yoruba
Nítorí náà, o máa rí àwọn tí àárẹ̀ wà nínú ọkàn wọn, tí wọn yóò máa yára lọ sáààrin wọn. Wọn yóò máa wí pé: "À ń bẹ̀rù pé kí àpadàsí ìgbà má baà kàn wá ni." Ó súnmọ́ kí Allāhu mú ìṣẹ́gun tàbí àṣẹ kan wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Wọn yó sì di alábàámọ̀ lórí ohun tí wọ́n fi pamọ́ sínú ọkàn wọn.
|
Ayah 5:53 الأية
وَيَقُولُ الَّذِينَ آمَنُوا أَهَٰؤُلَاءِ الَّذِينَ أَقْسَمُوا بِاللهِ جَهْدَ
أَيْمَانِهِمْ ۙ إِنَّهُمْ لَمَعَكُمْ ۚ حَبِطَتْ أَعْمَالُهُمْ فَأَصْبَحُوا
خَاسِرِينَ
Wayaqoolu allatheena amanoo ahaola-iallatheena aqsamoo billahi jahda
aymanihiminnahum lamaAAakum habitat aAAmaluhum faasbahookhasireen
Yoruba
Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo sì máa sọ pé: "Ṣé àwọn (yẹhudi) wọ̀nyí kọ́ ni àwọn tó fi Allāhu búra tí ìbúra wọn sì lágbára gan-an pé, dájúdájú àwọn ń bẹ pẹ̀lú ẹ̀yin (munāfiki)?" Iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́. Nítorí náà, wọ́n sì di ẹni òfò.
|
Ayah 5:54 الأية
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا مَن يَرْتَدَّ مِنكُمْ عَن دِينِهِ فَسَوْفَ
يَأْتِي اللهُ بِقَوْمٍ يُحِبُّهُمْ وَيُحِبُّونَهُ أَذِلَّةٍ عَلَى
الْمُؤْمِنِينَ أَعِزَّةٍ عَلَى الْكَافِرِينَ يُجَاهِدُونَ فِي سَبِيلِ اللهِ
وَلَا يَخَافُونَ لَوْمَةَ لَائِمٍ ۚ ذَٰلِكَ فَضْلُ اللهِ يُؤْتِيهِ مَن يَشَاءُ
ۚ وَاللهُ وَاسِعٌ عَلِيمٌ
Ya ayyuha allatheena amanooman yartadda minkum AAan deenihi fasawfa ya/tee
Allahubiqawmin yuhibbuhum wayuhibboonahu athillatinAAala almu/mineena aAAizzatin
AAala alkafireenayujahidoona fee sabeeli Allahi wala yakhafoonalawmata la-imin
thalika fadlu Allahiyu/teehi man yashao wallahu wasiAAunAAaleem
Yoruba
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹnikẹ́ni tí ó bá pẹ̀yìndà níbi ẹ̀sìn rẹ̀ nínú yín, láìpẹ́ Allāhu máa mú àwọn ènìyàn kan wá; Ó máa nífẹ̀ẹ́ wọn, àwọn náà máa nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀. Wọn yóò rọ̀ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Wọn yó sì le mọ́ àwọn aláìgbàgbọ́. Wọn yóò máa jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu. Wọn kò sì níí bẹ̀rù èébú eléèébú. Ìyẹn ni oore àjùlọ Allāhu. Ó ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Olùgbòòrò, Onímọ̀
|
Ayah 5:55 الأية
إِنَّمَا وَلِيُّكُمُ اللهُ وَرَسُولُهُ وَالَّذِينَ آمَنُوا الَّذِينَ
يُقِيمُونَ الصَّلَاةَ وَيُؤْتُونَ الزَّكَاةَ وَهُمْ رَاكِعُونَ
Innama waliyyukumu Allahuwarasooluhu wallatheena amanoo allatheenayuqeemoona
assalata wayu/toona azzakatawahum rakiAAoon
Yoruba
Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo nìkan ni ọ̀rẹ́ yín, àwọn tó ń kírun, tí wọ́n sì ń yọ Zakāh, àwọn sì ni olùdáwọ́tẹ-orúnkún (lórí ìrun).
|
Ayah 5:56 الأية
وَمَن يَتَوَلَّ اللهَ وَرَسُولَهُ وَالَّذِينَ آمَنُوا فَإِنَّ حِزْبَ اللهِ
هُمُ الْغَالِبُونَ
Waman yatawalla Allaha warasoolahu wallatheenaamanoo fa-inna hizba Allahi humu
alghaliboon
Yoruba
Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ọ̀rẹ́; dájúdájú ìjọ Allāhu, àwọn ni olùborí.
|
Ayah 5:57 الأية
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَتَّخِذُوا الَّذِينَ اتَّخَذُوا دِينَكُمْ
هُزُوًا وَلَعِبًا مِّنَ الَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ مِن قَبْلِكُمْ
وَالْكُفَّارَ أَوْلِيَاءَ ۚ وَاتَّقُوا اللهَ إِن كُنتُم مُّؤْمِنِينَ
Ya ayyuha allatheena amanoola tattakhithoo allatheena ittakhathoodeenakum
huzuwan walaAAiban mina allatheena ootoo alkitabamin qablikum walkuffara awliyaa
wattaqooAllaha in kuntum mu/mineen
Yoruba
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe mú àwọn tó sọ ẹ̀sìn yín di n̄ǹkan yẹ̀yẹ́ àti eré ṣíṣe ní ọ̀rẹ́ nínú àwọn tí A fún ní tírà ṣíwájú yín àti àwọn aláìgbàgbọ́. Ẹ bẹ̀rù Allāhu tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
|
Ayah 5:58 الأية
وَإِذَا نَادَيْتُمْ إِلَى الصَّلَاةِ اتَّخَذُوهَا هُزُوًا وَلَعِبًا ۚ ذَٰلِكَ
بِأَنَّهُمْ قَوْمٌ لَّا يَعْقِلُونَ
Wa-itha nadaytum ila assalatiittakhathooha huzuwan walaAAiban thalikabi-annahum
qawmun la yaAAqiloon
Yoruba
Nígbà tí ẹ bá pèpè síbi ìrun kíkí, wọn yóò sọ ọ́ di n̄ǹkan yẹ̀yẹ́ àti eré ṣíṣe. Ìyẹn nítorí pé dájúdájú àwọn ni ìjọ tí kò ṣe làákàyè.
|
Ayah 5:59 الأية
قُلْ يَا أَهْلَ الْكِتَابِ هَلْ تَنقِمُونَ مِنَّا إِلَّا أَنْ آمَنَّا بِاللهِ
وَمَا أُنزِلَ إِلَيْنَا وَمَا أُنزِلَ مِن قَبْلُ وَأَنَّ أَكْثَرَكُمْ فَاسِقُونَ
Qul ya ahla alkitabi haltanqimoona minna illa an amanna billahiwama onzila
ilayna wama onzila min qabluwaanna aktharakum fasiqoon
Yoruba
Sọ pé: "Ẹ̀yin onítírà, ǹjẹ́ ẹ rí àlèébù kan (ǹjẹ́ ẹ sì kórira kiní kan) lára wa bí kò ṣe pé a gbàgbọ́ nínú Allāhu àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún wa àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú?" Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ yín ni òbìlẹ̀jẹ́.
|
Ayah 5:60 الأية
قُلْ هَلْ أُنَبِّئُكُم بِشَرٍّ مِّن ذَٰلِكَ مَثُوبَةً عِندَ اللهِ ۚ مَن
لَّعَنَهُ اللهُ وَغَضِبَ عَلَيْهِ وَجَعَلَ مِنْهُمُ الْقِرَدَةَ
وَالْخَنَازِيرَ وَعَبَدَ الطَّاغُوتَ ۚ أُولَٰئِكَ شَرٌّ مَّكَانًا وَأَضَلُّ عَن
سَوَاءِ السَّبِيلِ
Qul hal onabbi-okum bisharrin min thalikamathoobatan AAinda Allahi man laAAanahu
Allahuwaghadiba AAalayhi wajaAAala minhumu alqiradata walkhanazeerawaAAabada
attaghooti ola-ika sharrun makananwaadallu AAan sawa-i assabeel
Yoruba
Sọ pé: "Ṣé kí n̄g fún yín ní ìró nípa èyí tí ó burú ju ìyẹn lọ ní ẹ̀san ní ọ̀dọ̀ Allāhu?"(Òhun ni ẹ̀san) ẹni tí Allāhu ṣẹ́bilé, tí Ó sì bínú sí, tí Ó sì sọ àwọn kan nínú wọn di ọ̀bọ àti ẹlẹ́dẹ̀ àti (ẹ̀san) ẹni tí ó ń bọ àwọn Ànábì kan, tí wọn kò pe ara wọn ní ọlọ́hun, tí wọn kò sì yọ̀nù sí bí ẹ ṣe sọ wọ́n di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ. Àwọn wọ̀nyẹn ni ipò wọn burú jùlọ, àwọn sì ni wọ́n ṣìnà jùlọ kúrò lójú-ọ̀nà tààrà.
|
Ayah 5:61 الأية
وَإِذَا جَاءُوكُمْ قَالُوا آمَنَّا وَقَد دَّخَلُوا بِالْكُفْرِ وَهُمْ قَدْ
خَرَجُوا بِهِ ۚ وَاللهُ أَعْلَمُ بِمَا كَانُوا يَكْتُمُونَ
Wa-itha jaookum qaloo amannawaqad dakhaloo bilkufri wahum qad kharajoo bihi
wallahuaAAlamu bima kanoo yaktumoon
Yoruba
Nígbà tí wọ́n bá wá sí ọ̀dọ̀ yín, wọ́n á wí pé: "A gbàgbọ́." Dájúdájú wọ́n wọlé (tì yín) pẹ̀lú àìgbàgbọ́, wọ́n sì ti jáde pẹ̀lú rẹ̀. Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń fi pamọ́.
|
Ayah 5:62 الأية
وَتَرَىٰ كَثِيرًا مِّنْهُمْ يُسَارِعُونَ فِي الْإِثْمِ وَالْعُدْوَانِ
وَأَكْلِهِمُ السُّحْتَ ۚ لَبِئْسَ مَا كَانُوا يَعْمَلُونَ
Watara katheeran minhum yusariAAoonafee al-ithmi walAAudwani waaklihimu
assuhtalabi/sa ma kanoo yaAAmaloon
Yoruba
O máa rí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn, tí wọ́n ń yára kó sínú ẹ̀ṣẹ̀, ìtayọ ẹnu-ààlà àti jíjẹ tí wọ́n ń jẹ owó èrú. Dájúdájú ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ burú.
|
Ayah 5:63 الأية
لَوْلَا يَنْهَاهُمُ الرَّبَّانِيُّونَ وَالْأَحْبَارُ عَن قَوْلِهِمُ الْإِثْمَ
وَأَكْلِهِمُ السُّحْتَ ۚ لَبِئْسَ مَا كَانُوا يَصْنَعُونَ
Lawla yanhahumu arrabbaniyyoonawal-ahbaru AAan qawlihimu al-ithmawaaklihimu
assuhta labi/sa ma kanooyasnaAAoon
Yoruba
Kí ni kò jẹ́ kí àwọn àlùfáà àti àwọn amòfin ẹ̀sìn máa kọ̀ fún wọn nípa ọ̀rọ̀ ẹnu wọn (tí ó jẹ́) ẹ̀ṣẹ̀ àti jíjẹ tí wọ́n ń jẹ owó èrú! Dájúdájú ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ burú.
|
Ayah 5:64 الأية
وَقَالَتِ الْيَهُودُ يَدُ اللهِ مَغْلُولَةٌ ۚ غُلَّتْ أَيْدِيهِمْ وَلُعِنُوا
بِمَا قَالُوا ۘ بَلْ يَدَاهُ مَبْسُوطَتَانِ يُنفِقُ كَيْفَ يَشَاءُ ۚ
وَلَيَزِيدَنَّ كَثِيرًا مِّنْهُم مَّا أُنزِلَ إِلَيْكَ مِن رَّبِّكَ طُغْيَانًا
وَكُفْرًا ۚ وَأَلْقَيْنَا بَيْنَهُمُ الْعَدَاوَةَ وَالْبَغْضَاءَ إِلَىٰ يَوْمِ
الْقِيَامَةِ ۚ كُلَّمَا أَوْقَدُوا نَارًا لِّلْحَرْبِ أَطْفَأَهَا اللهُ ۚ
وَيَسْعَوْنَ فِي الْأَرْضِ فَسَادًا ۚ وَاللهُ لَا يُحِبُّ الْمُفْسِدِينَ
Waqalati alyahoodu yadu Allahimaghloolatun ghullat aydeehim waluAAinoo bima
qaloobal yadahu mabsootatani yunfiqu kayfa yashaowalayazeedanna katheeran minhum
ma onzila ilayka minrabbika tughyanan wakufran waalqaynabaynahumu alAAadawata
walbaghdaa ilayawmi alqiyamati kullama awqadoo naran lilharbiatfaaha Allahu
wayasAAawna fee al-ardifasadan wallahu la yuhibbualmufsideen
Yoruba
Àwọn yẹhudi wí pé: "Ọwọ́ Allāhu wà ní dídì pa." A di ọwọ́ wọn pa. A sì ṣẹ́bi lé wọn nítorí ohun tí wọ́n wí. Ọ̀rọ̀ kò rí bí wọ́n ṣe sọ ọ́ bí kò ṣe pé, ọwọ́ Rẹ̀ méjèèjì wà ní títẹ́ sílẹ̀. Ó sì ń tọrẹ bí Ó ṣe fẹ́. Ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa Rẹ̀ yóò kúkú jẹ́ kí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn lékún ní ìgbéraga àti àìgbàgbọ́ ni. A sì ju ọ̀tá àti ìkórira sáààrin wọn títí di Ọjọ́ Àjíǹde. Ìgbàkígbà tí wọ́n bá dáná ogun, Allāhu sì máa paná rẹ̀. Wọ́n sì ń ṣe ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀. Allāhu kò sì nífẹ̀ẹ́ àwọn òbìlẹ̀jẹ́.
|
Ayah 5:65 الأية
وَلَوْ أَنَّ أَهْلَ الْكِتَابِ آمَنُوا وَاتَّقَوْا لَكَفَّرْنَا عَنْهُمْ
سَيِّئَاتِهِمْ وَلَأَدْخَلْنَاهُمْ جَنَّاتِ النَّعِيمِ
Walaw anna ahla alkitabi amanoowattaqaw lakaffarna AAanhum
sayyi-atihimwalaadkhalnahum jannati annaAAeem
Yoruba
Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú àwọn onítírà gbàgbọ́ ní òdodo, kí wọ́n sì bẹ̀rù (Allāhu), Àwa ìbá pa àwọn àìda wọn rẹ́ fún wọn, Àwa ìbá sì mú wọn wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra.
|
Ayah 5:66 الأية
وَلَوْ أَنَّهُمْ أَقَامُوا التَّوْرَاةَ وَالْإِنجِيلَ وَمَا أُنزِلَ إِلَيْهِم
مِّن رَّبِّهِمْ لَأَكَلُوا مِن فَوْقِهِمْ وَمِن تَحْتِ أَرْجُلِهِم ۚ مِّنْهُمْ
أُمَّةٌ مُّقْتَصِدَةٌ ۖ وَكَثِيرٌ مِّنْهُمْ سَاءَ مَا يَعْمَلُونَ
Walaw annahum aqamoo attawratawal-injeela wama onzila ilayhim min
rabbihimlaakaloo min fawqihim wamin tahti arjulihim minhum ommatunmuqtasidatun
wakatheerun minhum saa mayaAAmaloon
Yoruba
Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú wọ́n lo at-Taorāh àti al-'Injīl àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún wọn láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn (ìyẹn, al-Ƙur'ān), wọn ìbá máa jẹ láti òkè wọn àti láti ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ wọn. Ìjọ kan ń bẹ nínú wọn tó dúró déédé, (àmọ́) ohun tí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn ń ṣe níṣẹ́ burú.
|
Ayah 5:67 الأية
يَا أَيُّهَا الرَّسُولُ بَلِّغْ مَا أُنزِلَ إِلَيْكَ مِن رَّبِّكَ ۖ وَإِن لَّمْ
تَفْعَلْ فَمَا بَلَّغْتَ رِسَالَتَهُ ۚ وَاللهُ يَعْصِمُكَ مِنَ النَّاسِ ۗ
إِنَّ اللهَ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الْكَافِرِينَ
Ya ayyuha arrasooluballigh ma onzila ilayka min rabbika wa-in lam tafAAal
famaballaghta risalatahu wallahu yaAAsimukamina annasi inna Allaha la
yahdeealqawma alkafireen
Yoruba
Ìwọ Òjíṣẹ́, kéde gbogbo ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Tí o kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, o ò jẹ́ iṣẹ́ Rẹ̀ pé. Allāhu yó sì dáàbò bò ọ́ lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ aláìgbàgbọ́ (láti ṣe ọ́ ní aburú).
|
Ayah 5:68 الأية
قُلْ يَا أَهْلَ الْكِتَابِ لَسْتُمْ عَلَىٰ شَيْءٍ حَتَّىٰ تُقِيمُوا التَّوْرَاةَ
وَالْإِنجِيلَ وَمَا أُنزِلَ إِلَيْكُم مِّن رَّبِّكُمْ ۗ وَلَيَزِيدَنَّ كَثِيرًا
مِّنْهُم مَّا أُنزِلَ إِلَيْكَ مِن رَّبِّكَ طُغْيَانًا وَكُفْرًا ۖ فَلَا تَأْسَ
عَلَى الْقَوْمِ الْكَافِرِينَ
Qul ya ahla alkitabi lastumAAala shay-in hatta tuqeemoo attawratawal-injeela
wama onzila ilaykum min rabbikumwalayazeedanna katheeran minhum ma onzila ilayka
minrabbika tughyanan wakufran fala ta/sa AAalaalqawmi alkafireen
Yoruba
Sọ pé: "Ẹ̀yin onítírà, ẹ ò rí kiní kan ṣe (nínú ẹ̀sìn) títí ẹ máa fi lo at-Taorāh àti al-'Injīl àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín (ìyẹn, al-Ƙur'ān)." Ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa Rẹ yóò kúkú jẹ́ kí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn lékún ní ìgbéraga àti àìgbàgbọ́ ni. Nítorí náà, má ṣe banújẹ́ nítorí ìjọ aláìgbàgbọ́.
|
Ayah 5:69 الأية
إِنَّ الَّذِينَ آمَنُوا وَالَّذِينَ هَادُوا وَالصَّابِئُونَ وَالنَّصَارَىٰ مَنْ
آمَنَ بِاللهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ وَعَمِلَ صَالِحًا فَلَا خَوْفٌ عَلَيْهِمْ
وَلَا هُمْ يَحْزَنُونَ
Inna allatheena amanoo wallatheenahadoo wassabi-oona wannasaraman amana billahi
walyawmi al-akhiriwaAAamila salihan fala khawfun AAalayhim walahum yahzanoon
Yoruba
Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo àti àwọn tó di yẹhudi, - àwọn sọ̄bi'ūn àti àwọn nasọ̄rọ̄, - ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, tí ó sì ṣiṣẹ́ rere, kò níí sí ìbẹ̀rù fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́.
|
Ayah 5:70 الأية
لَقَدْ أَخَذْنَا مِيثَاقَ بَنِي إِسْرَائِيلَ وَأَرْسَلْنَا إِلَيْهِمْ رُسُلًا ۖ
كُلَّمَا جَاءَهُمْ رَسُولٌ بِمَا لَا تَهْوَىٰ أَنفُسُهُمْ فَرِيقًا كَذَّبُوا
وَفَرِيقًا يَقْتُلُونَ
Laqad akhathna meethaqabanee isra-eela waarsalna ilayhim rusulan kullamajaahum
rasoolun bima la tahwaanfusuhum fareeqan kaththaboo wafareeqan yaqtuloon
Yoruba
A kúkú gba àdéhùn lọ́wọ́ àwọn ọmọ 'Isrọ̄'īl. A sì rán àwọn Òjíṣẹ́ kan sí wọn. Ìgbàkígbà tí Òjíṣẹ́ kan bá dé bá wọn pẹ̀lú ohun tí ẹ̀mí wọn kò fẹ́, wọ́n pe igun kan ní òpùrọ́, wọ́n sì ń pa igun kan.
|
Ayah 5:71 الأية
وَحَسِبُوا أَلَّا تَكُونَ فِتْنَةٌ فَعَمُوا وَصَمُّوا ثُمَّ تَابَ اللهُ
عَلَيْهِمْ ثُمَّ عَمُوا وَصَمُّوا كَثِيرٌ مِّنْهُمْ ۚ وَاللهُ بَصِيرٌ بِمَا
يَعْمَلُونَ
Wahasiboo alla takoonafitnatun faAAamoo wasammoo thumma taba AllahuAAalayhim
thumma AAamoo wasammoo katheerun minhum wallahubaseerun bima yaAAmaloon
Yoruba
Wọ́n sì lérò pé kò níí sí ìfòòró; wọ́n fọ́jú, wọ́n sì dití (sí òdodo). Lẹ́yìn náà, Allāhu gba ìronúpìwàdà wọn. Lẹ́yìn náà, wọ́n fọ́jú, wọ́n tún dití (sí òdodo); ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn (ló ṣe bẹ́ẹ̀). Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
|
Ayah 5:72 الأية
لَقَدْ كَفَرَ الَّذِينَ قَالُوا إِنَّ اللهَ هُوَ الْمَسِيحُ ابْنُ مَرْيَمَ ۖ
وَقَالَ الْمَسِيحُ يَا بَنِي إِسْرَائِيلَ اعْبُدُوا اللهَ رَبِّي وَرَبَّكُمْ ۖ
إِنَّهُ مَن يُشْرِكْ بِاللهِ فَقَدْ حَرَّمَ اللهُ عَلَيْهِ الْجَنَّةَ
وَمَأْوَاهُ النَّارُ ۖ وَمَا لِلظَّالِمِينَ مِنْ أَنصَارٍ
Laqad kafara allatheena qalooinna Allaha huwa almaseehu ibnu maryama
waqalaalmaseehu ya banee isra-eela oAAbudoo Allaharabbee warabbakum innahu man
yushrik billahi faqadharrama Allahu AAalayhi aljannata wama/wahuannaru wama
liththalimeenamin ansar
Yoruba
Wọ́n kúkú ti di kèfèrí, àwọn tó wí pé: "Dájúdájú Allāhu, Òun ni Mọsīh ọmọ Mọryam." Mọsīh sì sọ pé: "Ẹ̀yin ọmọ 'Isrọ̄'īl, ẹ jọ́sìn fún Allāhu, Olúwa mi àti Olúwa yín. Dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá bá Allāhu wá akẹgbẹ́, Allāhu ti ṣe Ọgbà Ìdẹ̀ra ní èèwọ̀ fún un. Iná sì ni ibùgbé rẹ̀. Kò sì níí sí alárànṣe kan fún àwọn alábòsí."
|
Ayah 5:73 الأية
لَّقَدْ كَفَرَ الَّذِينَ قَالُوا إِنَّ اللهَ ثَالِثُ ثَلَاثَةٍ ۘ وَمَا مِنْ
إِلَٰهٍ إِلَّا إِلَٰهٌ وَاحِدٌ ۚ وَإِن لَّمْ يَنتَهُوا عَمَّا يَقُولُونَ
لَيَمَسَّنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا مِنْهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ
Laqad kafara allatheena qalooinna Allaha thalithu thalathatin wamamin ilahin
illa ilahun wahidun wa-inlam yantahoo AAamma yaqooloona layamassanna
allatheenakafaroo minhum AAathabun aleem
Yoruba
Wọ́n kúkú ti di kèfèrí, àwọn tó wí pé: "Dájúdájú Allāhu ni Ìkẹta (àwọn) mẹ́ta." Kò sì sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Ọlọ́hun, Ọ̀kan ṣoṣo. Tí wọn kò bá jáwọ́ níbi ohun tí wọ́n ń wí, dájúdájú ìyà ẹlẹ́ta eléro l'ó máa jẹ àwọn tó di kèfèrí nínú wọn.
|
Ayah 5:74 الأية
أَفَلَا يَتُوبُونَ إِلَى اللهِ وَيَسْتَغْفِرُونَهُ ۚ وَاللهُ غَفُورٌ
رَّحِيمٌ
Afala yatooboona ila Allahiwayastaghfiroonahu wallahu ghafoorun raheem
Yoruba
Nítorí náà, ṣé wọn kò níí ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Allāhu, kí wọ́n sì tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Rẹ̀? Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
|
Ayah 5:75 الأية
مَّا الْمَسِيحُ ابْنُ مَرْيَمَ إِلَّا رَسُولٌ قَدْ خَلَتْ مِن قَبْلِهِ الرُّسُلُ
وَأُمُّهُ صِدِّيقَةٌ ۖ كَانَا يَأْكُلَانِ الطَّعَامَ ۗ انظُرْ كَيْفَ نُبَيِّنُ
لَهُمُ الْآيَاتِ ثُمَّ انظُرْ أَنَّىٰ يُؤْفَكُونَ
Ma almaseehu ibnu maryama illarasoolun qad khalat min qablihi arrusulu waommuhu
siddeeqatunkana ya/kulani attaAAamaonthur kayfa nubayyinu lahumu al-ayatithumma
onthur anna yu/fakoon
Yoruba
Kí ni Mọsīh bí kò ṣe Òjíṣẹ́ kan. Àwọn Òjíṣẹ́ sì ti lọ ṣíwájú rẹ̀. Olódodo sì ni ìyá rẹ̀. Àwọn méjèèjì máa ń jẹ oúnjẹ. Wo bí A ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah náà fún wọn. Lẹ́yìn náà, wo bí wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo!
|
Ayah 5:76 الأية
قُلْ أَتَعْبُدُونَ مِن دُونِ اللهِ مَا لَا يَمْلِكُ لَكُمْ ضَرًّا وَلَا
نَفْعًا ۚ وَاللهُ هُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ
Qul ataAAbudoona min dooni Allahi mala yamliku lakum darran wala nafAAan
wallahuhuwa assameeAAu alAAaleem
Yoruba
Sọ pé: "Ṣé ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu ohun tí kò ní ìkápá ìnira àti àǹfààní kan fún yín? Allāhu, Òun sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀."
|
Ayah 5:77 الأية
قُلْ يَا أَهْلَ الْكِتَابِ لَا تَغْلُوا فِي دِينِكُمْ غَيْرَ الْحَقِّ وَلَا
تَتَّبِعُوا أَهْوَاءَ قَوْمٍ قَدْ ضَلُّوا مِن قَبْلُ وَأَضَلُّوا كَثِيرًا
وَضَلُّوا عَن سَوَاءِ السَّبِيلِ
Qul ya ahla alkitabi lataghloo fee deenikum ghayra alhaqqi wala tattabiAAooahwaa
qawmin qad dalloo min qablu waadallookatheeran wadalloo AAan sawa-i assabeel
Yoruba
Sọ pé: "Ẹ̀yin onítírà, ẹ má ṣe tayọ ẹnu-ààlà nínú ẹ̀sìn yín, (ẹ má sọ ohun tí) kì í ṣe òdodo. Ẹ má sì ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú ìjọ kan tó ti ṣìnà ṣíwájú (ìyẹn, àwọn yẹhudi). Wọ́n ṣi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ lọ́nà. Wọ́n sì ṣìnà kúrò ní ojú ọ̀nà tààrà."
|
Ayah 5:78 الأية
لُعِنَ الَّذِينَ كَفَرُوا مِن بَنِي إِسْرَائِيلَ عَلَىٰ لِسَانِ دَاوُودَ
وَعِيسَى ابْنِ مَرْيَمَ ۚ ذَٰلِكَ بِمَا عَصَوا وَّكَانُوا يَعْتَدُونَ
LuAAina allatheena kafaroo min baneeisra-eela AAala lisani dawoodawaAAeesa ibni
maryama thalika bima AAasawwakanoo yaAAtadoon
Yoruba
Wọ́n ṣẹ́bi lé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn ọmọ 'Isrọ̄'īl lórí ahọ́n (Ànábì) Dāwūd àti ‘Īsā ọmọ Mọryam. Ìyẹn nítorí pé, wọ́n yapa (àṣẹ Allāhu), wọ́n sì ń tayọ ẹnu-ààlà.
|
Ayah 5:79 الأية
كَانُوا لَا يَتَنَاهَوْنَ عَن مُّنكَرٍ فَعَلُوهُ ۚ لَبِئْسَ مَا كَانُوا
يَفْعَلُونَ
Kanoo la yatanahawnaAAan munkarin faAAaloohu labi/sa ma kanooyafAAaloon
Yoruba
Wọn kì í kọ ìwà ìbàjẹ́ tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ láààrin ara wọn. Ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ sì burú.
|
Ayah 5:80 الأية
تَرَىٰ كَثِيرًا مِّنْهُمْ يَتَوَلَّوْنَ الَّذِينَ كَفَرُوا ۚ لَبِئْسَ مَا
قَدَّمَتْ لَهُمْ أَنفُسُهُمْ أَن سَخِطَ اللهُ عَلَيْهِمْ وَفِي الْعَذَابِ هُمْ
خَالِدُونَ
Tara katheeran minhum yatawallawnaallatheena kafaroo labi/sa ma qaddamat
lahumanfusuhum an sakhita Allahu AAalayhim wafee alAAathabihum khalidoon
Yoruba
O máa rí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn tó ń bá àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ṣọ̀rẹ́. Ohun tí ẹ̀mí wọn tì síwájú fún wọn sì burú tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí Allāhu fi bínú sí wọn. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú Ìyà.
|
Ayah 5:81 الأية
وَلَوْ كَانُوا يُؤْمِنُونَ بِاللهِ وَالنَّبِيِّ وَمَا أُنزِلَ إِلَيْهِ مَا
اتَّخَذُوهُمْ أَوْلِيَاءَ وَلَٰكِنَّ كَثِيرًا مِّنْهُمْ فَاسِقُونَ
Walaw kanoo yu/minoona billahiwannabiyyi wama onzila ilayhi ma
ittakhathoohumawliyaa walakinna katheeran minhum fasiqoon
Yoruba
Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún un, wọn kò níí mú wọn ní ọ̀rẹ́ àyò, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn ni òbìlẹ̀jẹ́.
|
Ayah 5:82 الأية
لَتَجِدَنَّ أَشَدَّ النَّاسِ عَدَاوَةً لِّلَّذِينَ آمَنُوا الْيَهُودَ
وَالَّذِينَ أَشْرَكُوا ۖ وَلَتَجِدَنَّ أَقْرَبَهُم مَّوَدَّةً لِّلَّذِينَ
آمَنُوا الَّذِينَ قَالُوا إِنَّا نَصَارَىٰ ۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّ مِنْهُمْ
قِسِّيسِينَ وَرُهْبَانًا وَأَنَّهُمْ لَا يَسْتَكْبِرُونَ
Latajidanna ashadda annasiAAadawatan lillatheena amanoo alyahooda
wallatheenaashrakoo walatajidanna aqrabahum mawaddatan lillatheena
amanooallatheena qaloo inna nasara thalikabi-anna minhum qisseeseena waruhbanan
waannahum layastakbiroon
Yoruba
Dájúdájú o máa rí i pé àwọn ènìyàn tí ọ̀tá wọn le jùlọ sí àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo ni àwọn yẹhudi àti àwọn ọ̀ṣẹbọ. Dájúdájú o sì máa rí i pé àwọn ènìyàn tó súnmọ́ àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo jùlọ ní ìfẹ́ ni àwọn tó wí pé: "Dájúdájú nasọ̄rọ̄ ni àwa." Ìyẹn nítorí pé àwọn àlùfáà àti olùfọkànsìn ń bẹ láààrin wọn. Àti pé dájúdáju wọn kò níí ṣègbéraga (sí òdodo).
|
Ayah 5:83 الأية
وَإِذَا سَمِعُوا مَا أُنزِلَ إِلَى الرَّسُولِ تَرَىٰ أَعْيُنَهُمْ تَفِيضُ مِنَ
الدَّمْعِ مِمَّا عَرَفُوا مِنَ الْحَقِّ ۖ يَقُولُونَ رَبَّنَا آمَنَّا
فَاكْتُبْنَا مَعَ الشَّاهِدِينَ
Wa-itha samiAAoo ma onzila ilaarrasooli tara aAAyunahum tafeedu mina
addamAAimimma AAarafoo mina alhaqqi yaqooloona rabbanaamanna faktubna maAAa
ashshahideen
Yoruba
Nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún Òjíṣẹ́ náà, o máa rí ẹyinjú wọn tí ó máa damije nítorí ohun tí wọ́n ti mọ̀ nínú òdodo. Wọ́n á sì sọ pé: "Olúwa wa, a gbàgbọ́ ní òdodo, kọ wá mọ́ ara àwọn olùjẹ́rìí (òdodo).
|
Ayah 5:84 الأية
وَمَا لَنَا لَا نُؤْمِنُ بِاللهِ وَمَا جَاءَنَا مِنَ الْحَقِّ وَنَطْمَعُ أَن
يُدْخِلَنَا رَبُّنَا مَعَ الْقَوْمِ الصَّالِحِينَ
Wama lana la nu/minu billahiwama jaana mina alhaqqi wanatmaAAuan yudkhilana
rabbuna maAAa alqawmi assaliheen
Yoruba
Kí ni ó máa dí wa lọ́wọ́ tí a ò fi níí gbàgbọ́ nínú Allāhu àti ohun tí ó dé bá wa nínú òdodo (ìyẹn, al-Ƙur'ān), tí a sì ń jẹ̀rankàn pé kí Olúwa wa fi wá sínú àwọn ẹni-ire."
|
Ayah 5:85 الأية
فَأَثَابَهُمُ اللهُ بِمَا قَالُوا جَنَّاتٍ تَجْرِي مِن تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ
خَالِدِينَ فِيهَا ۚ وَذَٰلِكَ جَزَاءُ الْمُحْسِنِينَ
Faathabahumu Allahu bimaqaloo jannatin tajree min tahtihaal-anharu khalideena
feeha wathalikajazao almuhsineen
Yoruba
Nítorí náà, nítorí ohun tí wọ́n sọ, Allāhu san wọ́n ní ẹ̀san pẹ̀lú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ìyẹn sì ni ẹ̀san fún àwọn olùṣe-rere.
|
Ayah 5:86 الأية
وَالَّذِينَ كَفَرُوا وَكَذَّبُوا بِآيَاتِنَا أُولَٰئِكَ أَصْحَابُ الْجَحِيمِ
Wallatheena kafaroo wakaththaboobi-ayatina ola-ika as-habualjaheem
Yoruba
Àwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n pe àwọn āyah Wa nírọ́, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú iná Jẹhīm.
|
Ayah 5:87 الأية
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تُحَرِّمُوا طَيِّبَاتِ مَا أَحَلَّ اللهُ
لَكُمْ وَلَا تَعْتَدُوا ۚ إِنَّ اللهَ لَا يُحِبُّ الْمُعْتَدِينَ
Ya ayyuha allatheena amanoola tuharrimoo tayyibati ma ahallaAllahu lakum wala
taAAtadoo inna Allaha layuhibbu almuAAtadeen
Yoruba
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe sọ àwọn n̄ǹkan dáadáa tí Allāhu ṣe ní ẹ̀tọ́ fún yín di èèwọ̀. Ẹ sì má ṣe tayọ ẹnu-ààlà. Dájúdájú Allāhu kò fẹ́ràn àwọn olùtayọ ẹnu-ààlà.
|
Ayah 5:88 الأية
وَكُلُوا مِمَّا رَزَقَكُمُ اللهُ حَلَالًا طَيِّبًا ۚ وَاتَّقُوا اللهَ
الَّذِي أَنتُم بِهِ مُؤْمِنُونَ
Wakuloo mimma razaqakumu Allahuhalalan tayyiban wattaqoo Allahaallathee antum
bihi mu/minoon
Yoruba
Ẹ jẹ n̄ǹkan ẹ̀tọ́ tó dára nínú ohun tí Allāhu ṣe ní arísìkí fún yín. Àti pé ẹ bẹ̀rù Allāhu, Ẹni tí ẹ̀yin gbàgbọ́ nínú Rẹ̀.
|
Ayah 5:89 الأية
لَا يُؤَاخِذُكُمُ اللهُ بِاللَّغْوِ فِي أَيْمَانِكُمْ وَلَٰكِن يُؤَاخِذُكُم
بِمَا عَقَّدتُّمُ الْأَيْمَانَ ۖ فَكَفَّارَتُهُ إِطْعَامُ عَشَرَةِ مَسَاكِينَ
مِنْ أَوْسَطِ مَا تُطْعِمُونَ أَهْلِيكُمْ أَوْ كِسْوَتُهُمْ أَوْ تَحْرِيرُ
رَقَبَةٍ ۖ فَمَن لَّمْ يَجِدْ فَصِيَامُ ثَلَاثَةِ أَيَّامٍ ۚ ذَٰلِكَ كَفَّارَةُ
أَيْمَانِكُمْ إِذَا حَلَفْتُمْ ۚ وَاحْفَظُوا أَيْمَانَكُمْ ۚ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ
اللهُ لَكُمْ آيَاتِهِ لَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ
La yu-akhithukumu Allahubillaghwi fee aymanikum walakin yu-akhithukumbima
AAaqqadtumu al-aymana fakaffaratuhu itAAamuAAasharati masakeena min awsati ma
tutAAimoonaahleekum aw kiswatuhum aw tahreeru raqabatin faman lamyajid fasiyamu
thalathati ayyamin thalikakaffaratu aymanikum itha halaftum wahfathooaymanakum
kathalika yubayyinu Allahu lakum ayatihilaAAallakum tashkuroon
Yoruba
Allāhu kò níí fí ìbúra tí ó bọ́ lẹ́nu yín bi yín, ṣùgbọ́n Ó máa fi àwọn ìbúra tí ẹ fínnúfíndọ̀ mú wá bi yín. Nítorí náà, ìtánràn rẹ̀ ni bíbọ́ tálíkà mẹ́wàá pẹ̀lú oúnjẹ tí ó wà ní ìwọ̀ntún-wọ̀nsì tí ẹ̀ ń fi bọ́ ará ilé yín, tàbí kí ẹ raṣọ fún wọn, tàbí kí ẹ tú ẹrú kan sílẹ̀ lóko ẹrú. Ẹni tí kò bá rí (èyí ṣe), ó máa gba ààwẹ̀ ọjọ́ mẹ́ta. Ìyẹn ni ìtánràn ìbúra yín nígbà tí ẹ bá búra. Ẹ ṣọ́ ìbúra yín. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah Rẹ̀ fún yín, nítorí kí ẹ lè dúpẹ́.
|
Ayah 5:90 الأية
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِنَّمَا الْخَمْرُ وَالْمَيْسِرُ وَالْأَنصَابُ
وَالْأَزْلَامُ رِجْسٌ مِّنْ عَمَلِ الشَّيْطَانِ فَاجْتَنِبُوهُ لَعَلَّكُمْ
تُفْلِحُونَ
Ya ayyuha allatheena amanooinnama alkhamru walmaysiru wal-ansabuwal-azlamu
rijsun min AAamali ashshaytanifajtaniboohu laAAallakum tuflihoon
Yoruba
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, dájúdájú ọtí, tẹ́tẹ́, àwọn òrìṣà àti iṣẹ́ yíyẹ̀wò, ẹ̀gbin nínú iṣẹ́ Èṣù ni. Nítorí náà, ẹ jìnnà sí i nítorí kí ẹ lè jèrè.
|
Ayah 5:91 الأية
إِنَّمَا يُرِيدُ الشَّيْطَانُ أَن يُوقِعَ بَيْنَكُمُ الْعَدَاوَةَ وَالْبَغْضَاءَ
فِي الْخَمْرِ وَالْمَيْسِرِ وَيَصُدَّكُمْ عَن ذِكْرِ اللهِ وَعَنِ الصَّلَاةِ ۖ
فَهَلْ أَنتُم مُّنتَهُونَ
Innama yureedu ashshaytanuan yooqiAAa baynakumu alAAadawata walbaghdaafee
alkhamri walmaysiri wayasuddakum AAan thikriAllahi waAAani assalati fahal
antummuntahoon
Yoruba
Ohun tí Èṣù ń fẹ́ ni pé ó máa dá ọ̀tá àti ìkórira sílẹ̀ láààrin yín níbi ọtí àti tẹ́tẹ́. Ó sì fẹ́ ṣẹ yín lórí kúrò níbi ìrántí Allāhu àti níbi ìrun kíkí. Ṣé ẹ̀yin kò níí jáwọ́ (níbi iṣẹ́ Èṣù) ni?
|
Ayah 5:92 الأية
وَأَطِيعُوا اللهَ وَأَطِيعُوا الرَّسُولَ وَاحْذَرُوا ۚ فَإِن تَوَلَّيْتُمْ
فَاعْلَمُوا أَنَّمَا عَلَىٰ رَسُولِنَا الْبَلَاغُ الْمُبِينُ
WaateeAAoo Allaha waateeAAooarrasoola wahtharoo fa-in tawallaytum
faAAlamooannama AAala rasoolina albalaghualmubeen
Yoruba
Ẹ tẹ̀lé ti Allāhu, ẹ tẹ̀lé ti Òjíṣẹ́. Kí ẹ sì ṣọ́ra. Nítorí náà, tí ẹ bá gbúnrí, kí ẹ mọ̀ pé ìkéde (ẹ̀sìn) tó yanjú ni ojúṣe Òjíṣẹ́ Wa.
|
Ayah 5:93 الأية
لَيْسَ عَلَى الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ جُنَاحٌ فِيمَا طَعِمُوا
إِذَا مَا اتَّقَوا وَّآمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ ثُمَّ اتَّقَوا وَّآمَنُوا
ثُمَّ اتَّقَوا وَّأَحْسَنُوا ۗ وَاللهُ يُحِبُّ الْمُحْسِنِينَ
Laysa AAala allatheena amanoowaAAamiloo assalihati junahun feemataAAimoo itha ma
ittaqaw waamanoowaAAamiloo assalihati thumma ittaqaw waamanoothumma ittaqaw
waahsanoo wallahu yuhibbualmuhsineen
Yoruba
Kò sí ìbáwí fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣiṣẹ́ rere nípa ohun tí wọ́n jẹ (nínú ouńjẹ ṣíwájú òfin) nígbà tí wọ́n bá ti bẹ̀rù Allāhu, tí wọ́n sì gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n tún ṣiṣẹ́ rere, lẹ́yìn náà, tí wọ́n bẹ̀rù Allāhu, tí wọ́n sì gbàgbọ́ ní òdodo, lẹ́yìn náà, tí wọ́n bẹ́rù Allāhu, tí wọ́n tún ṣiṣẹ́ rere. Allāhu sì fẹ́ràn àwọn olùṣe-rere.
|
Ayah 5:94 الأية
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَيَبْلُوَنَّكُمُ اللهُ بِشَيْءٍ مِّنَ
الصَّيْدِ تَنَالُهُ أَيْدِيكُمْ وَرِمَاحُكُمْ لِيَعْلَمَ اللهُ مَن يَخَافُهُ
بِالْغَيْبِ ۚ فَمَنِ اعْتَدَىٰ بَعْدَ ذَٰلِكَ فَلَهُ عَذَابٌ أَلِيمٌ
Ya ayyuha allatheena amanoolayabluwannakumu Allahu bishay-in mina
assayditanaluhu aydeekum warimahukum liyaAAlama Allahuman yakhafuhu bilghaybi
famani iAAtadabaAAda thalika falahu AAathabun aleem
Yoruba
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, dájúdájú Allāhu yóò fi kiní kan dan yín wò níbi ẹran-ìgbẹ́ tí ọwọ́ yín àti ọ̀kọ̀ yín bà (nínú aṣọ hurumi) nítorí kí Allāhu lè ṣàfi hàn ẹni tó ń páyà Rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tayọ ẹnu-ààlà lẹ́yìn ìyẹn, ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún un.
|
Ayah 5:95 الأية
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَقْتُلُوا الصَّيْدَ وَأَنتُمْ حُرُمٌ ۚ وَمَن
قَتَلَهُ مِنكُم مُّتَعَمِّدًا فَجَزَاءٌ مِّثْلُ مَا قَتَلَ مِنَ النَّعَمِ
يَحْكُمُ بِهِ ذَوَا عَدْلٍ مِّنكُمْ هَدْيًا بَالِغَ الْكَعْبَةِ أَوْ كَفَّارَةٌ
طَعَامُ مَسَاكِينَ أَوْ عَدْلُ ذَٰلِكَ صِيَامًا لِّيَذُوقَ وَبَالَ أَمْرِهِ ۗ
عَفَا اللهُ عَمَّا سَلَفَ ۚ وَمَنْ عَادَ فَيَنتَقِمُ اللهُ مِنْهُ ۗ
وَاللهُ عَزِيزٌ ذُو انتِقَامٍ
Ya ayyuha allatheena amanoola taqtuloo assayda waantum hurumunwaman qatalahu
minkum mutaAAammidan fajazaon mithlu maqatala mina annaAAami yahkumu bihi
thawaAAadlin minkum hadyan baligha alkaAAbati aw kaffaratuntaAAamu masakeena aw
AAadlu thalika siyamanliyathooqa wabala amrihi AAafa AllahuAAamma salafa waman
AAada fayantaqimu Allahuminhu wallahu AAazeezun thoo intiqam
Yoruba
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe pa ẹran-ìgbẹ́ nígbà tí ẹ bá wà nínú aṣọ hurumi (hajj tàbí ‘umrah). Ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ̀ọ́mọ̀ pa á nínú yín, ẹ̀san rẹ̀ ni (pé ó máa pa) irú ohun tí ó pa nínú ẹran ọ̀sìn. Àwọn onídéédé méjì nínú yín l'ó sì máa ṣe ìdájọ́ (òṣùwọ̀n) rẹ̀ (fún un. Ó máa jẹ́) ẹran ọrẹ tí ó máa mú dé Kaaba. Tàbí kí ó fi bíbọ́ àwọn tálíkà ṣe ìtánràn. Tàbí kí ó fi ààwẹ̀ dípò ìyẹn, nítorí kí ó lè tọ́ bí ọ̀ràn rẹ̀ ṣe lágbára tó wò. Allāhu ti mójú kúrò níbi ohun tó ré kọjá. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tún padà (mọ̀ọ́mọ̀ dọdẹ nínú aṣọ húrùmí tàbí nínú húrùmí), Allāhu yóò gbẹ̀san lára rẹ̀ rẹ̀. Allāhu sì ni Alágbára, Olùgbẹ̀san.
|
Ayah 5:96 الأية
أُحِلَّ لَكُمْ صَيْدُ الْبَحْرِ وَطَعَامُهُ مَتَاعًا لَّكُمْ وَلِلسَّيَّارَةِ ۖ
وَحُرِّمَ عَلَيْكُمْ صَيْدُ الْبَرِّ مَا دُمْتُمْ حُرُمًا ۗ وَاتَّقُوا اللهَ
الَّذِي إِلَيْهِ تُحْشَرُونَ
Ohilla lakum saydu albahriwataAAamuhu mataAAan lakum walissayyaratiwahurrima
AAalaykum saydu albarri ma dumtum hurumanwattaqoo Allaha allathee ilayhi
tuhsharoon
Yoruba
Wọ́n ṣe odò dídẹ àti jíjẹ oúnjẹ (òkúǹbete) inú rẹ̀ ní ẹ̀tọ́ fún yín. Ó jẹ́ n̄ǹkan ìgbádùn fún ẹ̀yin àti àwọn onírìn-àjò. Wọ́n sì ṣe ìgbẹ́ dídẹ ní èèwọ̀ fún yín nígbà tí ẹ bá wà ní nínú aṣọ hurumi (hajj tàbí ‘umrah). Ẹ bẹ̀rù Allāhu, Ẹni tí wọ́n máa ko yín jọ sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
|
Ayah 5:97 الأية
جَعَلَ اللهُ الْكَعْبَةَ الْبَيْتَ الْحَرَامَ قِيَامًا لِّلنَّاسِ وَالشَّهْرَ
الْحَرَامَ وَالْهَدْيَ وَالْقَلَائِدَ ۚ ذَٰلِكَ لِتَعْلَمُوا أَنَّ اللهَ
يَعْلَمُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ وَأَنَّ اللهَ بِكُلِّ
شَيْءٍ عَلِيمٌ
JaAAala Allahu alkaAAbata albayta alharamaqiyaman linnasi washshahra
alharamawalhadya walqala-ida thalikalitaAAlamoo anna Allaha yaAAlamu ma fee
assamawatiwama fee al-ardi waanna Allaha bikullishay-in AAaleem
Yoruba
Allāhu ṣe Kaabah Ilé Ọ̀wọ̀ ní àyè ààbò fún àwọn ènìyàn. (N̄ǹkan ààbò náà ni) àwọn oṣù ọ̀wọ̀, àwọn ẹran ọrẹ (tí wọn kò ṣàmì sí lọ́rùn) àti (àwọn ẹran ọrẹ) tí wọ́n ṣàmì sí lọ́rùn. Ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ nítorí kí ẹ lè mọ̀ pé dájúdájú Allāhu mọ ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Àti pé dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
|
Ayah 5:98 الأية
اعْلَمُوا أَنَّ اللهَ شَدِيدُ الْعِقَابِ وَأَنَّ اللهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ
IAAlamoo anna Allaha shadeedu alAAiqabiwaanna Allaha ghafoorun raheem
Yoruba
Ẹ mọ̀ pé dájúdájú Allāhu le níbi ìyà. Àti pé dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
|
Ayah 5:99 الأية
مَّا عَلَى الرَّسُولِ إِلَّا الْبَلَاغُ ۗ وَاللهُ يَعْلَمُ مَا تُبْدُونَ وَمَا
تَكْتُمُونَ
Ma AAala arrasooli illaalbalaghu wallahu yaAAlamu matubdoona wama taktumoon
Yoruba
Kò sí ojúṣe kan fún Òjíṣẹ́ náà bí kò ṣe ìkéde (ẹ̀sìn). Allāhu sì mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣàfi hàn rẹ̀ àti ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́.
|
Ayah 5:100 الأية
قُل لَّا يَسْتَوِي الْخَبِيثُ وَالطَّيِّبُ وَلَوْ أَعْجَبَكَ كَثْرَةُ الْخَبِيثِ
ۚ فَاتَّقُوا اللهَ يَا أُولِي الْأَلْبَابِ لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ
Qul la yastawee alkhabeethu wattayyibuwalaw aAAjabaka kathratu alkhabeethi
fattaqoo Allahaya olee al-albabi laAAallakum tuflihoon
Yoruba
Sọ pé: "Ohun burúkú àti ohun dáadáa kò dọ́gba, púpọ̀ ohun burúkú ìbáà jọ ọ́ lójú". Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, ẹ̀yin onílàákàyè, nítorí kí ẹ lè jèrè."
|
Ayah 5:101 الأية
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَسْأَلُوا عَنْ أَشْيَاءَ إِن تُبْدَ لَكُمْ
تَسُؤْكُمْ وَإِن تَسْأَلُوا عَنْهَا حِينَ يُنَزَّلُ الْقُرْآنُ تُبْدَ لَكُمْ
عَفَا اللهُ عَنْهَا ۗ وَاللهُ غَفُورٌ حَلِيمٌ
Ya ayyuha allatheena amanoola tas-aloo AAan ashyaa in tubda lakum tasu/kumwa-in
tas-aloo AAanha heena yunazzalu alqur-anutubda lakum AAafa Allahu AAanha
wallahughafoorun haleem
Yoruba
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe máa bèèrè nípa àwọn n̄ǹkan sá. Tí A bá fi hàn yín, ó máa kó ìpalára ba yín. Tí ẹ bá sì bèèrè nípa (àwọn n̄ǹkan tó yẹ láti bèèrè nípa ẹ̀sìn) nígbà tí À ń sọ al-Ƙur'ān kalẹ̀ lọ́wọ́, A máa fi hàn yín. Allāhu ti ṣe àmójúkúrò nípa rẹ̀. Allāhu ni Aláforíjìn, Aláfaradà.
|
Ayah 5:102 الأية
قَدْ سَأَلَهَا قَوْمٌ مِّن قَبْلِكُمْ ثُمَّ أَصْبَحُوا بِهَا كَافِرِينَ
Qad saalaha qawmun min qablikumthumma asbahoo biha kafireen
Yoruba
Ìjọ kan kúkú ti bèèrè rẹ̀ ṣíwájú yín. Lẹ́yìn náà, wọ́n sì di aláìgbàgbọ́ nípasẹ̀ rẹ̀.
|
Ayah 5:103 الأية
مَا جَعَلَ اللهُ مِن بَحِيرَةٍ وَلَا سَائِبَةٍ وَلَا وَصِيلَةٍ وَلَا حَامٍ ۙ
وَلَٰكِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا يَفْتَرُونَ عَلَى اللهِ الْكَذِبَ ۖ
وَأَكْثَرُهُمْ لَا يَعْقِلُونَ
Ma jaAAala Allahu min baheeratinwala sa-ibatin wala waseelatin walahamin
walakinna allatheena kafarooyaftaroona AAala Allahi alkathibawaaktharuhum la
yaAAqiloon
Yoruba
Allāhu kò fi ẹran bahīrah, ẹran sā'ibah, ẹran wasīlah àti ẹran hām lọ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ń dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu ni. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò ṣe làákàyè.
|
Ayah 5:104 الأية
وَإِذَا قِيلَ لَهُمْ تَعَالَوْا إِلَىٰ مَا أَنزَلَ اللهُ وَإِلَى الرَّسُولِ
قَالُوا حَسْبُنَا مَا وَجَدْنَا عَلَيْهِ آبَاءَنَا ۚ أَوَلَوْ كَانَ آبَاؤُهُمْ
لَا يَعْلَمُونَ شَيْئًا وَلَا يَهْتَدُونَ
Wa-itha qeela lahum taAAalawila ma anzala Allahu wa-ila arrasooliqaloo hasbuna
ma wajadnaAAalayhi abaana awa law kana abaohumla yaAAlamoona shay-an wala
yahtadoon
Yoruba
Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: "Ẹ máa bọ̀ wá síbi ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀. (Ẹ máa bọ̀ wá) sí ọ̀dọ̀ Òjíṣẹ́ náà." Wọ́n á wí pé: "Ohun tí a bá àwọn bàbá wa lórí rẹ̀ ti tó wa." Ṣé pẹ̀lú bí ó ṣe jẹ́ pé àwọn bàbá wọn kò nímọ̀ kan kan, tí wọn kò sì mọ̀nà?
|
Ayah 5:105 الأية
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا عَلَيْكُمْ أَنفُسَكُمْ ۖ لَا يَضُرُّكُم مَّن
ضَلَّ إِذَا اهْتَدَيْتُمْ ۚ إِلَى اللهِ مَرْجِعُكُمْ جَمِيعًا فَيُنَبِّئُكُم
بِمَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ
Ya ayyuha allatheena amanooAAalaykum anfusakum la yadurrukum man dallaitha
ihtadaytum ila Allahi marjiAAukumjameeAAan fayunabbi-okum bima kuntum taAAmaloon
Yoruba
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ̀mí ara yín dọwọ́ yín. Ẹni tí ó ti ṣìnà kò lè kó ìnira ba yín nígbà tí ẹ bá ti mọ̀nà. Ọ̀dọ̀ Allāhu ni ibùpadàsí gbogbo yín pátápátá. Nígbà náà, Ó máa fún yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
|
Ayah 5:106 الأية
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا شَهَادَةُ بَيْنِكُمْ إِذَا حَضَرَ أَحَدَكُمُ
الْمَوْتُ حِينَ الْوَصِيَّةِ اثْنَانِ ذَوَا عَدْلٍ مِّنكُمْ أَوْ آخَرَانِ مِنْ
غَيْرِكُمْ إِنْ أَنتُمْ ضَرَبْتُمْ فِي الْأَرْضِ فَأَصَابَتْكُم مُّصِيبَةُ
الْمَوْتِ ۚ تَحْبِسُونَهُمَا مِن بَعْدِ الصَّلَاةِ فَيُقْسِمَانِ بِاللهِ إِنِ
ارْتَبْتُمْ لَا نَشْتَرِي بِهِ ثَمَنًا وَلَوْ كَانَ ذَا قُرْبَىٰ ۙ وَلَا
نَكْتُمُ شَهَادَةَ اللهِ إِنَّا إِذًا لَّمِنَ الْآثِمِينَ
Ya ayyuha allatheena amanooshahadatu baynikum itha hadara ahadakumualmawtu heena
alwasiyyati ithnani thawaAAadlin minkum aw akharani min ghayrikum in antum
darabtumfee al-ardi faasabatkum museebatu almawti tahbisoonahumamin baAAdi
assalati fayuqsimani billahiini irtabtum la nashtaree bihi thamanan walaw kana
thaqurba wala naktumu shahadata Allahiinna ithan lamina al-athimeen
Yoruba
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, (ẹ wá) ẹ̀rí jíjẹ́ láààrin yín nígbà tí (ìpọ́kàkà) ikú bá dé bá ẹnì kan nínú yín tí ó fẹ́ sọ àsọọ́lẹ̀. (Ẹ wá) onídéédé méjì nínú yín. Tàbí àwọn méjì mìíràn yàtọ̀ si yín tí ẹ̀yin bá wà lórí ìrìn-àjò tí àjálù ikú bá fẹ́ ṣẹlẹ̀ si yín. Ẹ dá àwọn méjèèjì dúró lẹ́yìn ìrun, kí wọ́n fi Allāhu búra, tí ẹ bá ṣeyèméjì (sí òdodo wọn, kí wọ́n sì sọ pé:) "A ò níí ta ìbúra wa ní iye kan kan, kódà kó jẹ́ ẹbí. A ò sì níí fi ẹ̀rí jíjẹ́ tí Allāhu (pa láṣẹ) pamọ́. (Bí bẹ́ẹ̀ kọ́) nígbà náà, dájúdájú àwa wà nínú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀."
|
Ayah 5:107 الأية
فَإِنْ عُثِرَ عَلَىٰ أَنَّهُمَا اسْتَحَقَّا إِثْمًا فَآخَرَانِ يَقُومَانِ
مَقَامَهُمَا مِنَ الَّذِينَ اسْتَحَقَّ عَلَيْهِمُ الْأَوْلَيَانِ فَيُقْسِمَانِ
بِاللهِ لَشَهَادَتُنَا أَحَقُّ مِن شَهَادَتِهِمَا وَمَا اعْتَدَيْنَا إِنَّا
إِذًا لَّمِنَ الظَّالِمِينَ
Fa-in AAuthira AAala annahumaistahaqqa ithman faakharani yaqoomanimaqamahuma
mina allatheena istahaqqaAAalayhimu al-awlayani fayuqsimani billahilashahadatuna
ahaqqu min shahadatihimawama iAAtadayna inna ithan lamina aththalimeen
Yoruba
Tí wọ́n bá sì mọ̀ pé àwọn méjèèjì dá ẹ̀ṣẹ̀ (nípa yíyí àsọọ́lẹ̀ padà tàbí jíjí dúkìá aláìsí), kí àwọn méjì mìíràn nínú ẹbí òkú tí àsọọ́lẹ̀ lẹ́tọ̀ọ́ sì jùlọ, (ìyẹn) ènìyàn méjì tí ó súnmọ́ òkú jùlọ rọ́pò àwọn méjèèjì àkọ́kọ́ (níbi mímú àsọọ́lẹ̀ mìíràn wá fún òkú). Kí àwọn náà sì fi Allāhu búra pé: "Dájúdájú ẹ̀rí jíjẹ́ tiwa jẹ́ òdodo ju ẹ̀rí jíjẹ́ ti àwọn méjèèjì (àkọ́kọ́). A ò sì níí tayọ ẹnu-ààlà. (Bí bẹ́ẹ̀ kọ́) nígbà náà, dájúdájú a ti wà nínú àwọn alábòsí."
|
Ayah 5:108 الأية
ذَٰلِكَ أَدْنَىٰ أَن يَأْتُوا بِالشَّهَادَةِ عَلَىٰ وَجْهِهَا أَوْ يَخَافُوا أَن
تُرَدَّ أَيْمَانٌ بَعْدَ أَيْمَانِهِمْ ۗ وَاتَّقُوا اللهَ وَاسْمَعُوا ۗ
وَاللهُ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الْفَاسِقِينَ
Thalika adna an ya/too bishshahadatiAAala wajhiha aw yakhafoo an turadda
aymanunbaAAda aymanihim wattaqoo Allaha wasmaAAoowallahu la yahdee alqawma
alfasiqeen
Yoruba
Ìyẹn súnmọ́ jùlọ láti mú ẹ̀rí jíjẹ́ wá ní ojú-pọ̀nnà rẹ̀ tàbí láti (lè là nínú) ìpáyà pé wọ́n yóò da ìbúra kan nù (ìbúra ẹni méjì àkọ́kọ́) lẹ́yìn ìbúra tiwọn (ìbúrà ẹni méjì kejì). Ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì gbọ́ràn. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.
|
Ayah 5:109 الأية
يَوْمَ يَجْمَعُ اللهُ الرُّسُلَ فَيَقُولُ مَاذَا أُجِبْتُمْ ۖ قَالُوا لَا
عِلْمَ لَنَا ۖ إِنَّكَ أَنتَ عَلَّامُ الْغُيُوبِ
Yawma yajmaAAu Allahu arrusulafayaqoolu matha ojibtum qaloo la AAilma lanainnaka
anta AAallamu alghuyoob
Yoruba
Ní ọjọ́ tí Allāhu yóò kó àwọn Òjíṣẹ́ jọ, Ó sì máa sọ pé: "Kí ni èsì tí wọ́n fún yín?" Wọ́n á sọ pé: "Kò sí ìmọ̀ kan fún wa (nípa rẹ̀). Dájúdájú Ìwọ, Ìwọ ni Onímọ̀ nípa àwọn ìkọ̀kọ̀."
|
Ayah 5:110 الأية
إِذْ قَالَ اللهُ يَا عِيسَى ابْنَ مَرْيَمَ اذْكُرْ نِعْمَتِي عَلَيْكَ وَعَلَىٰ
وَالِدَتِكَ إِذْ أَيَّدتُّكَ بِرُوحِ الْقُدُسِ تُكَلِّمُ النَّاسَ فِي الْمَهْدِ
وَكَهْلًا ۖ وَإِذْ عَلَّمْتُكَ الْكِتَابَ وَالْحِكْمَةَ وَالتَّوْرَاةَ
وَالْإِنجِيلَ ۖ وَإِذْ تَخْلُقُ مِنَ الطِّينِ كَهَيْئَةِ الطَّيْرِ بِإِذْنِي
فَتَنفُخُ فِيهَا فَتَكُونُ طَيْرًا بِإِذْنِي ۖ وَتُبْرِئُ الْأَكْمَهَ
وَالْأَبْرَصَ بِإِذْنِي ۖ وَإِذْ تُخْرِجُ الْمَوْتَىٰ بِإِذْنِي ۖ وَإِذْ
كَفَفْتُ بَنِي إِسْرَائِيلَ عَنكَ إِذْ جِئْتَهُم بِالْبَيِّنَاتِ فَقَالَ
الَّذِينَ كَفَرُوا مِنْهُمْ إِنْ هَٰذَا إِلَّا سِحْرٌ مُّبِينٌ
Ith qala Allahu yaAAeesa ibna maryama othkur niAAmatee AAalaykawaAAala
walidatika ith ayyadtuka biroohialqudusi tukallimu annasa fee almahdi
wakahlanwa-ith AAallamtuka alkitaba walhikmatawattawrata wal-injeela
wa-ithtakhluqu mina atteeni kahay-ati attayribi-ithnee fatanfukhu feeha
fatakoonu tayranbi-ithnee watubri-o al-akmaha wal-abrasabi-ithnee wa-ith
tukhriju almawta bi-ithneewa-ith kafaftu banee isra-eela AAanka ithji/tahum
bilbayyinati faqala allatheenakafaroo minhum in hatha illa sihrun mubeen
Yoruba
(Rántí) nígbà tí Allāhu sọ pé: "‘Īsā ọmọ Mọryam, rántí ìdẹ̀ra Mi lórí rẹ àti lórí ìyá rẹ, nígbà tí Mo fi ẹ̀mí Mímọ́ (mọlāika Jibrīl) ràn ọ́ lọ́wọ́, tí o sì ń bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ lórí ìtẹ́ ní òpóǹló àti nígbà tí o dàgbà. (Rántí) nígbà tí Mo fún ọ ní ìmọ̀ Tírà, òye ìjìnlẹ̀, at-Taorāh àti al-'Injīl. (Rántí) nígbà tí ò ń mọ n̄ǹkan láti inú amọ̀ bí ìrísí ẹyẹ, tí ò ń fẹ́ atẹ́gùn sínú rẹ̀, tí ó ń di ẹyẹ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Mi. Ò ń wo afọ́jú àti adẹ́tẹ̀ sàn pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Mi. (Rántí) nígbà tí ò ń mú àwọn òkú jáde (ní alààyè láti inú sàréè) pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Mi. (Rántí) nígbà tí Mo dí àwọn ọmọ 'Isrọ̄'īl lọ́wọ́ fún ọ, nígbà tí o mú àwọn ẹ̀rí tó yanjú wá bá wọn. Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú wọn sì wí pé: "Kí ni èyí bí kò ṣe idán pọ́nńbélé."
|
Ayah 5:111 الأية
وَإِذْ أَوْحَيْتُ إِلَى الْحَوَارِيِّينَ أَنْ آمِنُوا بِي وَبِرَسُولِي قَالُوا
آمَنَّا وَاشْهَدْ بِأَنَّنَا مُسْلِمُونَ
Wa-ith awhaytu ila alhawariyyeenaan aminoo bee wabirasoolee qaloo amannawashhad
bi-annana muslimoon
Yoruba
(Rántí) nígbà tí Mo fi mọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ nínú ọkàn wọn pé kí wọ́n gbàgbọ́ nínú Èmi àti Òjíṣẹ́ Mi. Wọ́n sọ pé: "A gbàgbọ́. Kí o sì jẹ́rìí pé dájúdájú mùsùlùmí ni wá."
|
Ayah 5:112 الأية
إِذْ قَالَ الْحَوَارِيُّونَ يَا عِيسَى ابْنَ مَرْيَمَ هَلْ يَسْتَطِيعُ رَبُّكَ
أَن يُنَزِّلَ عَلَيْنَا مَائِدَةً مِّنَ السَّمَاءِ ۖ قَالَ اتَّقُوا اللهَ إِن
كُنتُم مُّؤْمِنِينَ
Ith qala alhawariyyoonaya AAeesa ibna maryama hal yastateeAAurabbuka an
yunazzila AAalayna ma-idatan mina assama-iqala ittaqoo Allaha in kuntum
mu/mineen
Yoruba
(Rántí) nígbà tí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ sọ pé: "‘Īsā ọmọ Mọryam, ǹjẹ́ Olúwa rẹ lè sọ ọpọ́n oúnjẹ kan kalẹ̀ fún wa láti sánmọ̀?" Ó sọ pé: "Ẹ bẹ̀rù Allāhu tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo."
|
Ayah 5:113 الأية
قَالُوا نُرِيدُ أَن نَّأْكُلَ مِنْهَا وَتَطْمَئِنَّ قُلُوبُنَا وَنَعْلَمَ أَن
قَدْ صَدَقْتَنَا وَنَكُونَ عَلَيْهَا مِنَ الشَّاهِدِينَ
Qaloo nureedu an na/kula minhawatatma-inna quloobuna wanaAAlama an qad
sadaqtanawanakoona AAalayha mina ashshahideen
Yoruba
Wọ́n sọ pé: "A fẹ́ jẹ nínú rẹ̀, a sì fẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀, kí á sì lè mọ̀ pé o ti sọ òdodo fún wa. A sì máa wà nínú àwọn olùjẹ́rìí."
|
Ayah 5:114 الأية
قَالَ عِيسَى ابْنُ مَرْيَمَ اللهُمَّ رَبَّنَا أَنزِلْ عَلَيْنَا مَائِدَةً
مِّنَ السَّمَاءِ تَكُونُ لَنَا عِيدًا لِّأَوَّلِنَا وَآخِرِنَا وَآيَةً مِّنكَ ۖ
وَارْزُقْنَا وَأَنتَ خَيْرُ الرَّازِقِينَ
Qala AAeesa ibnu maryama allahummarabbana anzil AAalayna ma-idatan mina
assama-itakoonu lana AAeedan li-awwalina waakhirinawaayatan minka warzuqna
waanta khayru arraziqeen
Yoruba
‘Īsā ọmọ Mọryam sọ pé: "Allāhu, Olúwa wa, sọ ọpọ́n oúnjẹ kan kalẹ̀ fún wa láti inú sánmọ̀, kí ó jẹ́ ọdún fún ẹni àkọ́kọ́ wa àti ẹni ìkẹ́yìn wa. Kí ó sì jẹ́ àmì kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ. Pèsè fún wa, Ìwọ sì lóore jùlọ nínú àwọn olùpèsè."
|
Ayah 5:115 الأية
قَالَ اللهُ إِنِّي مُنَزِّلُهَا عَلَيْكُمْ ۖ فَمَن يَكْفُرْ بَعْدُ مِنكُمْ
فَإِنِّي أُعَذِّبُهُ عَذَابًا لَّا أُعَذِّبُهُ أَحَدًا مِّنَ الْعَالَمِينَ
Qala Allahu innee munazziluhaAAalaykum faman yakfur baAAdu minkum fa-innee
oAAaththibuhuAAathaban la oAAaththibuhu ahadanmina alAAalameen
Yoruba
Allāhu sọ pé: "Dájúdájú Èmi yóò sọ̀ ọ́ kalẹ̀ fún yín. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn náà nínú yín, dájúdájú Mo máa jẹ ẹ́ níyà kan tí Mi ò fi jẹ ẹnì kan rí nínú gbogbo ẹ̀dá."
|
Ayah 5:116 الأية
وَإِذْ قَالَ اللهُ يَا عِيسَى ابْنَ مَرْيَمَ أَأَنتَ قُلْتَ لِلنَّاسِ
اتَّخِذُونِي وَأُمِّيَ إِلَٰهَيْنِ مِن دُونِ اللهِ ۖ قَالَ سُبْحَانَكَ مَا
يَكُونُ لِي أَنْ أَقُولَ مَا لَيْسَ لِي بِحَقٍّ ۚ إِن كُنتُ قُلْتُهُ فَقَدْ
عَلِمْتَهُ ۚ تَعْلَمُ مَا فِي نَفْسِي وَلَا أَعْلَمُ مَا فِي نَفْسِكَ ۚ إِنَّكَ
أَنتَ عَلَّامُ الْغُيُوبِ
Wa-ith qala Allahu yaAAeesa ibna maryama aanta qulta linnasiittakhithoonee
waommiya ilahayni min dooni Allahiqala subhanaka ma yakoonu lee an aqoola
malaysa lee bihaqqin in kuntu qultuhu faqad AAalimtahutaAAlamu ma fee nafsee
wala aAAlamu ma feenafsika innaka anta AAallamu alghuyoob
Yoruba
(Rántí) nígbà tí Allāhu sọ pé: "‘Īsā ọmọ Mọryam, ṣé ìwọ l'o sọ fún àwọn ènìyàn pé: "Ẹ mú èmi àti ìyá mi ní ọlọ́hun méjì tí ẹ óò máa jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu?" Ó sọ pé: "Mímọ́ ni fún Ọ, kò tọ́ fún mi láti sọ ohun tí èmi kò lẹ́tọ̀ọ́ (sí láti sọ). Tí mo bá sọ bẹ́ẹ̀, O kúkú ti mọ̀. O mọ ohun tí ń bẹ nínú ẹ̀mí mi. Èmi ò sì mọ ohun tí ń bẹ nínú ẹ̀mí Rẹ. Dájúdájú Ìwọ ni Onímọ̀ nípa àwọn ìkọ̀kọ̀.
|
Ayah 5:117 الأية
مَا قُلْتُ لَهُمْ إِلَّا مَا أَمَرْتَنِي بِهِ أَنِ اعْبُدُوا اللهَ رَبِّي
وَرَبَّكُمْ ۚ وَكُنتُ عَلَيْهِمْ شَهِيدًا مَّا دُمْتُ فِيهِمْ ۖ فَلَمَّا
تَوَفَّيْتَنِي كُنتَ أَنتَ الرَّقِيبَ عَلَيْهِمْ ۚ وَأَنتَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ
شَهِيدٌ
Ma qultu lahum illa maamartanee bihi ani oAAbudoo Allaha rabbee
warabbakumwakuntu AAalayhim shaheedan ma dumtu feehim falammatawaffaytanee kunta
anta arraqeeba AAalayhim waanta AAalakulli shay-in shaheed
Yoruba
Èmi kò sọ ohun kan fún wọn bí kò ṣe ohun tí O pa mí láṣẹ rẹ̀ pé: "Ẹ jọ́sìn fún Allāhu, Olúwa mi àti Olúwa yín." Mo sì jẹ́ ẹlẹ́rìí lórí wọn níwọ̀n ìgbà tí mò ń bẹ láààrin wọn. Ṣùgbọ́n nígbà tí O gbà mí kúrò lọ́wọ́ wọn, Ìwọ ni Olùṣọ́ lórí wọn. Ìwọ sì ni Arínú-róde gbogbo n̄ǹkan.
|
|