Prev  

60. Surah Al-Mumtahinah سورة الممتحنة

  Next  




1st Ayah  1  الأية ١الأولي
بِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَتَّخِذُوا عَدُوِّي وَعَدُوَّكُمْ أَوْلِيَاءَ تُلْقُونَ إِلَيْهِم بِالْمَوَدَّةِ وَقَدْ كَفَرُوا بِمَا جَاءَكُم مِّنَ الْحَقِّ يُخْرِجُونَ الرَّسُولَ وَإِيَّاكُمْ ۙ أَن تُؤْمِنُوا بِاللهِ رَبِّكُمْ إِن كُنتُمْ خَرَجْتُمْ جِهَادًا فِي سَبِيلِي وَابْتِغَاءَ مَرْضَاتِي ۚ تُسِرُّونَ إِلَيْهِم بِالْمَوَدَّةِ وَأَنَا أَعْلَمُ بِمَا أَخْفَيْتُمْ وَمَا أَعْلَنتُمْ ۚ وَمَن يَفْعَلْهُ مِنكُمْ فَقَدْ ضَلَّ سَوَاءَ السَّبِيلِ
Ya ayyuha allatheena amanoola tattakhithoo AAaduwwee waAAaduwwakum awliyaatulqoona ilayhim bilmawaddati waqad kafaroo bima jaakummina alhaqqi yukhrijoona arrasoola wa-iyyakuman tu/minoo billahi rabbikum in kuntum kharajtumjihadan fee sabeelee wabtighaa mardateetusirroona ilayhim bilmawaddati waana aAAlamu bimaakhfaytum wama aAAlantum waman yafAAalhu minkum faqad dallasawaa assabeel

Yoruba
 
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe mú ọ̀tá Mi àti ọ̀tá yín ní ọ̀rẹ́ tí ẹ óò máa fi ìfẹ́ hàn sí. Wọ́n kúkú ti ṣàì gbàgbọ́ nínú ohun tí ó dé ba yín nínú òdodo. Wọ́n yọ Òjíṣẹ́ àti ẹ̀yin náà kúrò nínú ìlú nítorí pé, ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu, Olúwa yín. Tí ẹ̀yin bá jáde fún ogun ní ojú-ọ̀nà Mi àti nítorí wíwá ìyọ́nú Mi, (ṣé) ẹ̀yin yóò tún máa ní ìfẹ́ kọ̀rọ̀ sí wọn ni! Èmi sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ẹ fi pamọ́ àti ohun tí ẹ fi hàn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀ nínú yín, dájúdájú ó ti ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà tààrà.

Ayah  60:2  الأية
إِن يَثْقَفُوكُمْ يَكُونُوا لَكُمْ أَعْدَاءً وَيَبْسُطُوا إِلَيْكُمْ أَيْدِيَهُمْ وَأَلْسِنَتَهُم بِالسُّوءِ وَوَدُّوا لَوْ تَكْفُرُونَ
In yathqafookum yakoonoo lakam aAAdaanwayabsutoo ilaykum aydiyahum waalsinatahum bissoo-iwawaddoo law takfuroon

Yoruba
 
Tí ọwọ́ wọn bá bà yín, wọ́n máa di ọ̀tá fún yín. Wọn yó sì fi ọwọ́ wọn àti ahọ́n wọn nawọ́ aburú si yín. Wọ́n sì máa fẹ́ kí ó jẹ́ pé ẹ di aláìgbàgbọ́.

Ayah  60:3  الأية
لَن تَنفَعَكُمْ أَرْحَامُكُمْ وَلَا أَوْلَادُكُمْ ۚ يَوْمَ الْقِيَامَةِ يَفْصِلُ بَيْنَكُمْ ۚ وَاللهُ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرٌ
Lan tanfaAAakum arhamukum walaawladukum yawma alqiyamati yafsilu baynakumwallahu bima taAAmaloona baseer

Yoruba
 
Àwọn ẹbí yín àti àwọn ọmọ yín kò lè ṣe yín ní àǹfààní; ní Ọjọ́ Àjíǹde ni Allāhu máa ṣèpínyà láààrin yín. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

Ayah  60:4  الأية
قَدْ كَانَتْ لَكُمْ أُسْوَةٌ حَسَنَةٌ فِي إِبْرَاهِيمَ وَالَّذِينَ مَعَهُ إِذْ قَالُوا لِقَوْمِهِمْ إِنَّا بُرَآءُ مِنكُمْ وَمِمَّا تَعْبُدُونَ مِن دُونِ اللهِ كَفَرْنَا بِكُمْ وَبَدَا بَيْنَنَا وَبَيْنَكُمُ الْعَدَاوَةُ وَالْبَغْضَاءُ أَبَدًا حَتَّىٰ تُؤْمِنُوا بِاللهِ وَحْدَهُ إِلَّا قَوْلَ إِبْرَاهِيمَ لِأَبِيهِ لَأَسْتَغْفِرَنَّ لَكَ وَمَا أَمْلِكُ لَكَ مِنَ اللهِ مِن شَيْءٍ ۖ رَّبَّنَا عَلَيْكَ تَوَكَّلْنَا وَإِلَيْكَ أَنَبْنَا وَإِلَيْكَ الْمَصِيرُ
Qad kanat lakum oswatun hasanatunfee ibraheema wallatheena maAAahu ithqaloo liqawmihim inna buraao minkum wamimmataAAbudoona min dooni Allahi kafarna bikum wabadabaynana wabaynakumu alAAadawatu walbaghdaoabadan hatta tu/minoo billahi wahdahuilla qawla ibraheema li-abeehi laastaghfiranna lakawama amliku laka mina Allahi min shay-in rabbanaAAalayka tawakkalna wa-ilayka anabna wa-ilayka almaseer

Yoruba
 
Dájúdájú àwòkọ́ṣe rere ti wà fún yín ní ara (Ànábì) 'Ibrọ̄hīm àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀. Nígbà tí wọ́n sọ fún ìjọ wọn pé: "Dájúdájú àwa yọwọ́-yọsẹ̀ kúrò nínú ọ̀rọ̀ yín àti ohun tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu. A takò yín. Ọ̀tá àti ìkórira sì ti hàn láààrin wa títí láéláé àyàfi ìgbà tí ẹ bá tó gbàgbọ́ nínú Allāhu nìkan ṣoṣo. - Àfi ọ̀rọ̀ tí (Ànábì) 'Ibrọ̄hīm sọ fún bàbá rẹ̀ pé: "Dájúdájú mo máa tọrọ àforíjìn fún ọ, èmi kò sì ní ìkápá kiní kan fún ọ lọ́dọ̀ Allāhu. - Olúwa wa, Ìwọ l'a gbáralé. Ọ̀dọ̀ Rẹ l'a ṣẹ́rí padà sí (nípa ìronúpìwàdà). Ọ̀dọ̀ Rẹ sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.

Ayah  60:5  الأية
رَبَّنَا لَا تَجْعَلْنَا فِتْنَةً لِّلَّذِينَ كَفَرُوا وَاغْفِرْ لَنَا رَبَّنَا ۖ إِنَّكَ أَنتَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ
Rabbana la tajAAalnafitnatan lillatheena kafaroo waghfir lanarabbana innaka anta alAAazeezu alhakeem

Yoruba
 
Olúwa wa, má ṣe wá ní àdánwò fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́. Foríjìn wá, Olúwa wa. Dájúdájú Ìwọ ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n."

Ayah  60:6  الأية
لَقَدْ كَانَ لَكُمْ فِيهِمْ أُسْوَةٌ حَسَنَةٌ لِّمَن كَانَ يَرْجُو اللهَ وَالْيَوْمَ الْآخِرَ ۚ وَمَن يَتَوَلَّ فَإِنَّ اللهَ هُوَ الْغَنِيُّ الْحَمِيدُ
Laqad kana lakum feehim oswatun hasanatunliman kana yarjoo Allaha walyawma al-akhirawaman yatawalla fa-inna Allaha huwa alghanniyyu alhameed

Yoruba
 
Dájúdájú àwòkọ́ṣe rere ti wà fún yín ní ara wọn fún ẹni tó ń retí (ẹ̀sán) Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbúnrí, dájúdájú Allāhu, Òun ni Ọlọ́rọ̀, Ẹlẹ́yìn.

Ayah  60:7  الأية
عَسَى اللهُ أَن يَجْعَلَ بَيْنَكُمْ وَبَيْنَ الَّذِينَ عَادَيْتُم مِّنْهُم مَّوَدَّةً ۚ وَاللهُ قَدِيرٌ ۚ وَاللهُ غَفُورٌ رَّحِيمٌ
AAasa Allahu an yajAAalabaynakum wabayna allatheena AAadaytum minhummawaddatan wallahu qadeerun wallahughafoorun raheem

Yoruba
 
Ó lè jẹ́ pé Allāhu yóò fi ìfẹ́ sí ààrin ẹ̀yin àti àwọn tí ẹ mú ní ọ̀tá nínú wọn (ìyẹn, nígbà tí wọ́n bá di mùsùlùmí). Allāhu ni Alágbára. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

Ayah  60:8  الأية
لَّا يَنْهَاكُمُ اللهُ عَنِ الَّذِينَ لَمْ يُقَاتِلُوكُمْ فِي الدِّينِ وَلَمْ يُخْرِجُوكُم مِّن دِيَارِكُمْ أَن تَبَرُّوهُمْ وَتُقْسِطُوا إِلَيْهِمْ ۚ إِنَّ اللهَ يُحِبُّ الْمُقْسِطِينَ
La yanhakumu AllahuAAani allatheena lam yuqatilookum fee addeeniwalam yukhrijookum min diyarikum an tabarroohum watuqsitooilayhim inna Allaha yuhibbu almuqsiteen

Yoruba
 
Allāhu kò kọ̀ fún yín nípa àwọn tí kò gbé ogun tì yín nípa ẹ̀sìn, tí wọn kò sì lè yín jáde kúrò nínú ìlú yín, pé kí ẹ ṣe dáadáa sí wọn, kí ẹ sì ṣe déédé sí wọn. Dájúdájú Allāhu fẹ́ràn àwọn olùṣe-déédé.

Ayah  60:9  الأية
إِنَّمَا يَنْهَاكُمُ اللهُ عَنِ الَّذِينَ قَاتَلُوكُمْ فِي الدِّينِ وَأَخْرَجُوكُم مِّن دِيَارِكُمْ وَظَاهَرُوا عَلَىٰ إِخْرَاجِكُمْ أَن تَوَلَّوْهُمْ ۚ وَمَن يَتَوَلَّهُمْ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الظَّالِمُونَ
Innama yanhakumu AllahuAAani allatheena qatalookum fee addeeniwaakhrajookum min diyarikum wathaharooAAala ikhrajikum an tawallawhum waman yatawallahumfaola-ika humu aththalimoon

Yoruba
 
Ohun tí Allāhu kọ̀ fún yín nípa àwọn tó gbógun tì yín nínú ẹ̀sìn, tí wọ́n sì lè yín jáde kúrò nínú ìlú yín, tí wọ́n tún ṣe ìrànlọ́wọ́ (fún àwọn ọ̀tá yín) láti le yín jáde, ni pé (Ó kọ̀ fún yín) láti mú wọn ní ọ̀rẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú wọn ní ọ̀rẹ́, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni alábòsí.

Ayah  60:10  الأية
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِذَا جَاءَكُمُ الْمُؤْمِنَاتُ مُهَاجِرَاتٍ فَامْتَحِنُوهُنَّ ۖ اللهُ أَعْلَمُ بِإِيمَانِهِنَّ ۖ فَإِنْ عَلِمْتُمُوهُنَّ مُؤْمِنَاتٍ فَلَا تَرْجِعُوهُنَّ إِلَى الْكُفَّارِ ۖ لَا هُنَّ حِلٌّ لَّهُمْ وَلَا هُمْ يَحِلُّونَ لَهُنَّ ۖ وَآتُوهُم مَّا أَنفَقُوا ۚ وَلَا جُنَاحَ عَلَيْكُمْ أَن تَنكِحُوهُنَّ إِذَا آتَيْتُمُوهُنَّ أُجُورَهُنَّ ۚ وَلَا تُمْسِكُوا بِعِصَمِ الْكَوَافِرِ وَاسْأَلُوا مَا أَنفَقْتُمْ وَلْيَسْأَلُوا مَا أَنفَقُوا ۚ ذَٰلِكُمْ حُكْمُ اللهِ ۖ يَحْكُمُ بَيْنَكُمْ ۚ وَاللهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ
Ya ayyuha allatheena amanooitha jaakumu almu/minatu muhajiratinfamtahinoohunna Allahu aAAlamu bi-eemanihinnafa-in AAalimtumoohunna mu/minatin falatarjiAAoohunna ila alkuffari la hunna hillunlahum wala hum yahilloona lahunna waatoohumma anfaqoo wala junaha AAalaykum an tankihoohunnaitha ataytumoohunna ojoorahunna walatumsikoo biAAisami alkawafiri was-aloo maanfaqtum walyas-aloo ma anfaqoo thalikum hukmuAllahi yahkumu baynakum wallahuAAaleemun hakeem

Yoruba
 
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin bá wá ba yín, tí wọ́n gbé ìlú àwọn aláìgbàgbọ́ jù sílẹ̀, ẹ ṣe ìdánwò fún wọn. Allāhu nímọ̀ jùlọ nípa ìgbàgbọ́ wọn. Nítorí náà, tí ẹ bá mọ̀ wọ́n sí onígbàgbọ́ òdodo, ẹ má ṣe dá wọn padà sí ọ̀dọ̀ àwọn aláìgbàgbọ́. Àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin kò lẹ́tọ̀ọ́ sí wọn. Àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́kùnrin kò sì lẹ́tọ̀ọ́ sí wọn. Ẹ fún (àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́kùnrin) ní owó tí wọ́n ná (ìyẹn, owó-orí obìnrin náà). Kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹ̀yin náà pé kí ẹ fẹ́ wọn nígbà tí ẹ bá ti fún (àwọn obìnrin wọ̀nyí) ní owó-orí wọn. Ẹ má ṣe fi owó-orí àwọn obìnrin yín tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́ mú wọn mọ́lẹ̀ (gẹ́gẹ́ bí ìyàwó yín láì jẹ́ pé wọ́n gba 'Islām pẹ̀lú yín). Ẹ bèèrè ohun tí ẹ ná (ìyẹn, owó-orí wọn lọ́wọ́ aláìgbàgbọ́ lọ́kùnrin tí wọ́n sá lọ bá). Kí àwọn (aláìgbàgbọ́ lọ́kùnrin náà) bèèrè ohun tí àwọn náà ná (ìyẹn, owó-orí wọn lọ́wọ́ ẹ̀yin tí onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin sá wá bá). Ìyẹn ni ìdájọ́ Allāhu. Ó sì ń dájọ́ láààrin yín. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n

Ayah  60:11  الأية
وَإِن فَاتَكُمْ شَيْءٌ مِّنْ أَزْوَاجِكُمْ إِلَى الْكُفَّارِ فَعَاقَبْتُمْ فَآتُوا الَّذِينَ ذَهَبَتْ أَزْوَاجُهُم مِّثْلَ مَا أَنفَقُوا ۚ وَاتَّقُوا اللهَ الَّذِي أَنتُم بِهِ مُؤْمِنُونَ
Wa-in fatakum shay-on min azwajikumila alkuffari faAAaqabtum faatoo allatheenathahabat azwajuhum mithla ma anfaqoo wattaqooAllaha allathee antum bihi mu/minoon

Yoruba
 
Tí kiní kan láti ọ̀dọ̀ àwọn ìyàwó yín bá bọ́ mọ yín lọ́wọ́ sí ọ̀dọ̀ àwọn aláìgbàgbọ́, tí ẹ sì kórè ogun, ẹ fún àwọn tí ìyàwó wọn sá lọ ní irú òdiwọ̀n ohun tí wọ́n ná (ní owó-orí). Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu, Ẹni tí ẹ̀yin ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Rẹ̀.

Ayah  60:12  الأية
يَا أَيُّهَا النَّبِيُّ إِذَا جَاءَكَ الْمُؤْمِنَاتُ يُبَايِعْنَكَ عَلَىٰ أَن لَّا يُشْرِكْنَ بِاللهِ شَيْئًا وَلَا يَسْرِقْنَ وَلَا يَزْنِينَ وَلَا يَقْتُلْنَ أَوْلَادَهُنَّ وَلَا يَأْتِينَ بِبُهْتَانٍ يَفْتَرِينَهُ بَيْنَ أَيْدِيهِنَّ وَأَرْجُلِهِنَّ وَلَا يَعْصِينَكَ فِي مَعْرُوفٍ ۙ فَبَايِعْهُنَّ وَاسْتَغْفِرْ لَهُنَّ اللهَ ۖ إِنَّ اللهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ
Ya ayyuha annabiyyu ithajaaka almu/minatu yubayiAAnaka AAalaan la yushrikna billahi shay-an walayasriqna wala yazneena wala yaqtulna awladahunnawala ya/teena bibuhtanin yaftareenahu baynaaydeehinna waarjulihinna wala yaAAseenaka feemaAAroofin fabayiAAhunna wastaghfir lahunna Allahainna Allaha ghafoorun raheem

Yoruba
 
Ìwọ Ànábì, nígbà tí àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin bá wá bá ọ, tí wọ́n ń ṣe àdéhùn fún ọ pé àwọn kò níí fi kiní kan ṣẹbọ sí Allāhu, àwọn kò níí jalè, àwọn kò níí ṣe sìná, àwọn kò níí pa ọmọ wọn, àwọn kò níí mú àdápa irọ́ wá, àdápa irọ́ tí wọ́n ń mú wá láààrin ọwọ́ wọn àti ẹsẹ̀ wọn (ìyẹn ni gbígbé oyún olóyún fún ọkọ wọn), àwọn kò sì níí yapa rẹ níbi n̄ǹkan dáadáa, nígbà náà bá wọn ṣe àdéhùn, kí ó sì bá wọn tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

Ayah  60:13  الأية
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَتَوَلَّوْا قَوْمًا غَضِبَ اللهُ عَلَيْهِمْ قَدْ يَئِسُوا مِنَ الْآخِرَةِ كَمَا يَئِسَ الْكُفَّارُ مِنْ أَصْحَابِ الْقُبُورِ
Ya ayyuha allatheena amanoola tatawallaw qawman ghadiba AllahuAAalayhim qad ya-isoo mina al-akhirati kama ya-isaalkuffaru min as-habi alquboor

Yoruba
 
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe mú ìjọ kan tí Allāhu ti bínú sí ní ọ̀rẹ́. Dájúdájú wọ́n ti sọ̀rètí nù nípa ọ̀run, gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìgbàgbọ́ tó wà nínú sàréè (ṣe sọ̀rètí nù nípa ìkẹ́).





© EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us