Prev  

67. Surah Al-Mulk سورة الملك

  Next  




1st Ayah  1  الأية ١الأولي
بِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
تَبَارَكَ الَّذِي بِيَدِهِ الْمُلْكُ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
Tabaraka allathee biyadihialmulku wahuwa AAala kulli shay-in qadeer

Yoruba
 
Ìbùkún ni fún Ẹni tí gbogbo ìjọba wà ní Ọwọ́ Rẹ̀. Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.

Ayah  67:2  الأية
الَّذِي خَلَقَ الْمَوْتَ وَالْحَيَاةَ لِيَبْلُوَكُمْ أَيُّكُمْ أَحْسَنُ عَمَلًا ۚ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْغَفُورُ
Allathee khalaqa almawta walhayataliyabluwakum ayyukum ahsanu AAamalan wahuwa alAAazeezualghafoor

Yoruba
 
Ẹni tí Ó dá ikú àti ìṣẹ̀mí nítorí kí ó lè dan yín wò; èwo nínú yín l'ó máa ṣe iṣẹ́ rere jùlọ. Òun sì ni Alágbára, Aláforíjìn.

Ayah  67:3  الأية
الَّذِي خَلَقَ سَبْعَ سَمَاوَاتٍ طِبَاقًا ۖ مَّا تَرَىٰ فِي خَلْقِ الرَّحْمَٰنِ مِن تَفَاوُتٍ ۖ فَارْجِعِ الْبَصَرَ هَلْ تَرَىٰ مِن فُطُورٍ
Allathee khalaqa sabAAa samawatintibaqan ma tara fee khalqi arrahmanimin tafawutin farjiAAi albasara hal taramin futoor

Yoruba
 
Ẹni tí Ó dá àwọn sánmọ̀ méje ní ìpele ìpele. O ò lè rí àìgúnrégé kan lára ẹ̀dá Àjọkẹ́-ayé. Nítorí náà, wò ó padà, ǹjẹ́ o rí ojú sísán kan (lára sánmọ̀)?

Ayah  67:4  الأية
ثُمَّ ارْجِعِ الْبَصَرَ كَرَّتَيْنِ يَنقَلِبْ إِلَيْكَ الْبَصَرُ خَاسِئًا وَهُوَ حَسِيرٌ
Thumma irjiAAi albasara karratayniyanqalib ilayka albasaru khasi-an wahuwa haseer

Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, wò ó padà ní ẹ̀ẹ̀ mejì, kí ojú rẹ padà sí ọ̀dọ̀ rẹ pẹ̀lú ìyẹpẹrẹ. Ó sì máa káàárẹ̀.

Ayah  67:5  الأية
وَلَقَدْ زَيَّنَّا السَّمَاءَ الدُّنْيَا بِمَصَابِيحَ وَجَعَلْنَاهَا رُجُومًا لِّلشَّيَاطِينِ ۖ وَأَعْتَدْنَا لَهُمْ عَذَابَ السَّعِيرِ
Walaqad zayyanna assamaaaddunya bimasabeeha wajaAAalnaharujooman lishshayateeni waaAAtadna lahumAAathaba assaAAeer

Yoruba
 
Dájúdájú A ti fi (àwọn ìràwọ̀ tó ń tànmọ́lẹ̀ bí) àtùpà ṣe sánmọ̀ ilé ayé ní ọ̀ṣọ́. A tún ṣe wọ́n ni ẹ̀ta-ìràwọ̀ tí wọ́n ń jù mọ́ àwọn èṣù. A sì pèsè ìyà Iná tó ń jó sílẹ̀ dè wọ́n.

Ayah  67:6  الأية
وَلِلَّذِينَ كَفَرُوا بِرَبِّهِمْ عَذَابُ جَهَنَّمَ ۖ وَبِئْسَ الْمَصِيرُ
Walillatheena kafaroo birabbihim AAathabujahannama wabi/sa almaseer

Yoruba
 
Ìyà iná Jahanamọ sì wà fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́. Ìkángun náà sì burú.

Ayah  67:7  الأية
إِذَا أُلْقُوا فِيهَا سَمِعُوا لَهَا شَهِيقًا وَهِيَ تَفُورُ
Itha olqoo feeha samiAAoo lahashaheeqan wahiya tafoor

Yoruba
 
Nígbà tí wọ́n bá jù wọ́n sínú rẹ̀, wọn yóò máa gbọ́ kíkùn rẹ̀, tí yó sì máa ru sókè.

Ayah  67:8  الأية
تَكَادُ تَمَيَّزُ مِنَ الْغَيْظِ ۖ كُلَّمَا أُلْقِيَ فِيهَا فَوْجٌ سَأَلَهُمْ خَزَنَتُهَا أَلَمْ يَأْتِكُمْ نَذِيرٌ
Takadu tamayyazu mina alghaythikullama olqiya feeha fawjun saalahum khazanatuhaalam ya/tikum natheer

Yoruba
 
Iná máa fẹ́ẹ̀ pínra rẹ̀ láti ara ìbínu¹́. Ìgbàkígbà tí wọ́n bá ju ìjọ kan sínú rẹ̀, àwọn ẹ̀ṣọ́ Iná yóò máa bi wọ́n léèrè pé: "Ǹjẹ́ olùkìlọ̀ kan kò wá ba yín bí?"

Ayah  67:9  الأية
قَالُوا بَلَىٰ قَدْ جَاءَنَا نَذِيرٌ فَكَذَّبْنَا وَقُلْنَا مَا نَزَّلَ اللهُ مِن شَيْءٍ إِنْ أَنتُمْ إِلَّا فِي ضَلَالٍ كَبِيرٍ
Qaloo bala qad jaananatheerun fakaththabna waqulna manazzala Allahu min shay-in in antum illa fee dalalinkabeer

Yoruba
 
Wọn yóò wí pé: "Bẹ́ẹ̀ ni, dájúdájú olùkìlọ̀ kan ti wá bá wa, ṣùgbọ́n a pè é ní òpùrọ́. A sì wí pé Allāhu kò sọ n̄ǹkan kan kalẹ̀. Kí ni ẹ̀yin bí kò ṣe pé ẹ wà nínú ìṣìnà tó tóbi."

Ayah  67:10  الأية
وَقَالُوا لَوْ كُنَّا نَسْمَعُ أَوْ نَعْقِلُ مَا كُنَّا فِي أَصْحَابِ السَّعِيرِ
Waqaloo law kunna nasmaAAu awnaAAqilu ma kunna fee as-habi assaAAeer

Yoruba
 
Wọ́n tún wí pé: "Tí ó bá jẹ́ pé a gbọ́ràn ni tàbí pé a ṣe làákàyè ni, àwa kò níí wà nínú èrò inú Iná tó ń jó."

Ayah  67:11  الأية
فَاعْتَرَفُوا بِذَنبِهِمْ فَسُحْقًا لِّأَصْحَابِ السَّعِيرِ
FaAAtarafoo bithanbihim fasuhqanli-as-habi assaAAeer

Yoruba
 
Wọ́n sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Nítorí náà, ìjìnnà sí ìkẹ́ Allāhu yó wà fún àwọn èrò inú Iná tó ń jó.

Ayah  67:12  الأية
إِنَّ الَّذِينَ يَخْشَوْنَ رَبَّهُم بِالْغَيْبِ لَهُم مَّغْفِرَةٌ وَأَجْرٌ كَبِيرٌ
Inna allatheena yakhshawna rabbahumbilghaybi lahum maghfiratun waajrun kabeer

Yoruba
 
Dájúdájú àwọn tó ń páyà Olúwa wọn ní ìkọ̀kọ̀, àforíjìn àti ẹ̀san tó tóbi ń bẹ fún wọn.

Ayah  67:13  الأية
وَأَسِرُّوا قَوْلَكُمْ أَوِ اجْهَرُوا بِهِ ۖ إِنَّهُ عَلِيمٌ بِذَاتِ الصُّدُورِ
Waasirroo qawlakum awi ijharoo bihi innahuAAaleemun bithati assudoor

Yoruba
 
Ẹ wí ọ̀rọ̀ yín ní jẹ́ẹ́jẹ́ tàbí ẹ wí i sókè, dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa ohun tó wà nínú àwọn igbá-àyà ẹ̀dá.

Ayah  67:14  الأية
أَلَا يَعْلَمُ مَنْ خَلَقَ وَهُوَ اللَّطِيفُ الْخَبِيرُ
Ala yaAAlamu man khalaqa wahuwa allateefualkhabeer

Yoruba
 
Ṣé kò mọ Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá ni? Òun sì ni Aláàánú, Alámọ̀tán.

Ayah  67:15  الأية
هُوَ الَّذِي جَعَلَ لَكُمُ الْأَرْضَ ذَلُولًا فَامْشُوا فِي مَنَاكِبِهَا وَكُلُوا مِن رِّزْقِهِ ۖ وَإِلَيْهِ النُّشُورُ
Huwa allathee jaAAala lakumu al-ardathaloolan famshoo fee manakibihawakuloo min rizqihi wa-ilayhi annushoor

Yoruba
 
Òun ni Ẹni tí Ó rọ ilẹ̀ fún yín. Nítorí náà, ẹ rìn ní àwọn agbègbè rẹ̀ káàkiri, kí ẹ sì jẹ nínú arísìkí Rẹ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àjíǹde ẹ̀dá wà.

Ayah  67:16  الأية
أَأَمِنتُم مَّن فِي السَّمَاءِ أَن يَخْسِفَ بِكُمُ الْأَرْضَ فَإِذَا هِيَ تَمُورُ
Aamintum man fee assama-i anyakhsifa bikumu al-arda fa-itha hiya tamoor

Yoruba
 
Ṣé ẹ fọkànbalẹ̀ sí Ẹni tí Ó wà ní (òkè) sánmọ̀ pé kò lè jẹ́ kí ilẹ̀ gbe yín mì? Nígbà náà, ilẹ̀ yó sì máa mì tìtì.

Ayah  67:17  الأية
أَمْ أَمِنتُم مَّن فِي السَّمَاءِ أَن يُرْسِلَ عَلَيْكُمْ حَاصِبًا ۖ فَسَتَعْلَمُونَ كَيْفَ نَذِيرِ
Am amintum man fee assama-ian yursila AAalaykum hasiban fasataAAlamoona kayfa natheer

Yoruba
 
Tàbí ẹ̀ fọkànbalẹ̀ sí Ẹni tí Ó wà ní (òkè) sánmọ̀ pé kò lè fi òkúta iná ránṣẹ́ si yín ni? Nígbà náà, ẹ sì máa mọ bí ìkìlọ̀ Mi ti rí.

Ayah  67:18  الأية
وَلَقَدْ كَذَّبَ الَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ فَكَيْفَ كَانَ نَكِيرِ
Walaqad kaththaba allatheenamin qablihim fakayfa kana nakeer

Yoruba
 
Àwọn tó ṣíwájú wọn kúkú pe òdodo ní irọ́. Báwo sì ni bí Mo ṣe (fi ìyà) kọ (aburú fún wọn) ti rí!

Ayah  67:19  الأية
أَوَلَمْ يَرَوْا إِلَى الطَّيْرِ فَوْقَهُمْ صَافَّاتٍ وَيَقْبِضْنَ ۚ مَا يُمْسِكُهُنَّ إِلَّا الرَّحْمَٰنُ ۚ إِنَّهُ بِكُلِّ شَيْءٍ بَصِيرٌ
Awa lam yaraw ila attayrifawqahum saffatin wayaqbidna mayumsikuhunna illa arrahmanu innahubikulli shay-in baseer

Yoruba
 
Ṣé wọn kò rí àwọn ẹyẹ tí ó wà ní òkè wọn, tí (wọ́n) ń na ìyẹ́ apá (wọn), tí wọ́n sì ń pa á mọ́ra? Kiní kan kò mú wọn dúró (sínú òfurufú) àfi Àjọkẹ́-ayé. Dájúdájú Òun sì ni Olùríran nípa gbogbo n̄ǹkan.

Ayah  67:20  الأية
أَمَّنْ هَٰذَا الَّذِي هُوَ جُندٌ لَّكُمْ يَنصُرُكُم مِّن دُونِ الرَّحْمَٰنِ ۚ إِنِ الْكَافِرُونَ إِلَّا فِي غُرُورٍ
Amman hatha allathee huwajundun lakum yansurukum min dooni arrahmaniini alkafiroona illa fee ghuroor

Yoruba
 
Ta ni ẹni tí ó máa jẹ́ ọmọ ogun fún yín, tí ó máa ràn yín lọ́wọ́ lẹ́yìn Àjọkẹ́-ayé? (Nínú) kí ni àwọn aláìgbàgbọ́ wà bí kò ṣe nínú ẹ̀tàn.

Ayah  67:21  الأية
أَمَّنْ هَٰذَا الَّذِي يَرْزُقُكُمْ إِنْ أَمْسَكَ رِزْقَهُ ۚ بَل لَّجُّوا فِي عُتُوٍّ وَنُفُورٍ
Amman hatha allatheeyarzuqukum in amsaka rizqahu bal lajjoo fee AAutuwwin wanufoor

Yoruba
 
Ta ni ẹni tí ó máa pèsè fún yín tí Ó bá dá arísìkí Rẹ̀ dúró? Ńṣe ni wọ́n ń ṣorí kunkun sí i nínú ìgbéraga àti sísá fún òdodo.

Ayah  67:22  الأية
أَفَمَن يَمْشِي مُكِبًّا عَلَىٰ وَجْهِهِ أَهْدَىٰ أَمَّن يَمْشِي سَوِيًّا عَلَىٰ صِرَاطٍ مُّسْتَقِيمٍ
Afaman yamshee mukibban AAala wajhihiahda amman yamshee sawiyyan AAala siratinmustaqeem

Yoruba
 
Ǹjẹ́ ẹni tó ń rìn ní ìdojúbolẹ̀ l'ó mọ̀nà jùlọ ni tàbí ẹni tó ń rìn sàn án lójú ọ̀nà tààrà?

Ayah  67:23  الأية
قُلْ هُوَ الَّذِي أَنشَأَكُمْ وَجَعَلَ لَكُمُ السَّمْعَ وَالْأَبْصَارَ وَالْأَفْئِدَةَ ۖ قَلِيلًا مَّا تَشْكُرُونَ
Qul huwa allathee anshaakum wajaAAalalakumu assamAAa wal-absara wal-af-idataqaleelan ma tashkuroon

Yoruba
 
Sọ pé: "Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín. Ó sì ṣe ìgbọ́rọ̀, ìríran àti àwọn ọkàn fún yín. Ọpẹ́ tí ẹ̀ ń dá sì kéré púpọ̀."

Ayah  67:24  الأية
قُلْ هُوَ الَّذِي ذَرَأَكُمْ فِي الْأَرْضِ وَإِلَيْهِ تُحْشَرُونَ
Qul huwa allathee tharaakumfee al-ardi wa-ilayhi tuhsharoon

Yoruba
 
Sọ pé: "Òun ni Ẹni tí Ó da yín sí orí ilẹ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò ko yín jọ sí."

Ayah  67:25  الأية
وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَٰذَا الْوَعْدُ إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ
Wayaqooloona mata hathaalwaAAdu in kuntum sadiqeen

Yoruba
 
Wọ́n ń wí pé: "Ìgbà wo ni àdéhùn yìí yóò ṣẹ tí ẹ bá jẹ́ olódodo?"

Ayah  67:26  الأية
قُلْ إِنَّمَا الْعِلْمُ عِندَ اللهِ وَإِنَّمَا أَنَا نَذِيرٌ مُّبِينٌ
Qul innama alAAilmu AAinda Allahiwa-innama ana natheerun mubeen

Yoruba
 
Sọ pé: "Ọ̀dọ̀ Allāhu nìkan ni ìmọ̀ (nípa) rẹ̀ wà. Èmi kàn jẹ́ olùkìlọ̀ pọ́nńbélé ni."

Ayah  67:27  الأية
فَلَمَّا رَأَوْهُ زُلْفَةً سِيئَتْ وُجُوهُ الَّذِينَ كَفَرُوا وَقِيلَ هَٰذَا الَّذِي كُنتُم بِهِ تَدَّعُونَ
Falamma raawhu zulfatan see-atwujoohu allatheena kafaroo waqeela hatha allatheekuntum bihi taddaAAoon

Yoruba
 
Nígbà tí wọ́n bá rí i tó súnmọ́, ojú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ yóò korò wá fún ìbànújẹ́. A ó sì sọ fún wọn pé: "Èyí ni ohun tí ẹ̀ ń pè."

Ayah  67:28  الأية
قُلْ أَرَأَيْتُمْ إِنْ أَهْلَكَنِيَ اللهُ وَمَن مَّعِيَ أَوْ رَحِمَنَا فَمَن يُجِيرُ الْكَافِرِينَ مِنْ عَذَابٍ أَلِيمٍ
Qul araaytum in ahlakaniya Allahuwaman maAAiya aw rahimana faman yujeeru alkafireenamin AAathabin aleem

Yoruba
 
Sọ pé: "Ẹ sọ fún mi, tí Allāhu bá pa èmi àti àwọn tó wà pẹ̀lú mi rẹ́, tàbí tí Ó bá kẹ́ wa (ṣé ẹ lè dí I lọ́wọ́ ni?) Nítorí náà, ta ni ó máa gba àwọn aláìgbàgbọ́ là nínú ìyà ẹlẹ́ta-eléro?

Ayah  67:29  الأية
قُلْ هُوَ الرَّحْمَٰنُ آمَنَّا بِهِ وَعَلَيْهِ تَوَكَّلْنَا ۖ فَسَتَعْلَمُونَ مَنْ هُوَ فِي ضَلَالٍ مُّبِينٍ
Qul huwa arrahmanu amannabihi waAAalayhi tawakkalna fasataAAlamoona man huwa fee dalalinmubeen

Yoruba
 
Sọ pé: "Òun ni Àjọkẹ́-ayé. Àwa gbà Á gbọ́. Òun sì la gbáralé. Láìpẹ́ ẹ máa mọ ta ni ó wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé."

Ayah  67:30  الأية
قُلْ أَرَأَيْتُمْ إِنْ أَصْبَحَ مَاؤُكُمْ غَوْرًا فَمَن يَأْتِيكُم بِمَاءٍ مَّعِينٍ
Qul araaytum in asbaha maokumghawran faman ya/teekum bima-in maAAeen

Yoruba
 
Sọ pé: "Ẹ sọ fún mi, tí omi yín bá gbẹ wá, ta ni ẹni tí ó máa mú omi tó ń ṣàn wá fún yín?"





© EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us