1st Ayah 1 الأية ١الأوليبِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
ن ۚ وَالْقَلَمِ وَمَا يَسْطُرُونَ
Noon walqalami wama yasturoon
Yoruba
Nūn. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú háràfí náà.) Allāhu fi gègé ìkọ̀wé àti ohun tí àwọn mọlāika ń kọ sílẹ̀ búra.
|
Ayah 68:2 الأية
مَا أَنتَ بِنِعْمَةِ رَبِّكَ بِمَجْنُونٍ
Ma anta biniAAmati rabbika bimajnoon
Yoruba
Ìwọ kì í ṣe wèrè nípa ìdẹ̀ra Olúwa rẹ.
|
Ayah 68:3 الأية
وَإِنَّ لَكَ لَأَجْرًا غَيْرَ مَمْنُونٍ
Wa-inna laka laajran ghayra mamnoon
Yoruba
Àti pé dájúdájú ẹ̀san tí kò níí dáwọ́ dúró ti wà fún ọ.
|
Ayah 68:4 الأية
وَإِنَّكَ لَعَلَىٰ خُلُقٍ عَظِيمٍ
Wa-innaka laAAala khuluqin AAatheem
Yoruba
Dájúdájú ìwọ sì wà̀lórí ìwà ńlá (ìwà alápọ̀n-ọ́nlé).
|
Ayah 68:5 الأية
فَسَتُبْصِرُ وَيُبْصِرُونَ
Fasatubsiru wayubsiroon
Yoruba
Láìpẹ́ ìwọ yóò rí i, àwọn náà yó sì rí i;
|
Ayah 68:6 الأية
بِأَييِّكُمُ الْمَفْتُونُ
Bi-ayyikumu almaftoon
Yoruba
Èwo nínú yín ni aládàn-ánwò (wèrè)?
|
Ayah 68:7 الأية
إِنَّ رَبَّكَ هُوَ أَعْلَمُ بِمَن ضَلَّ عَن سَبِيلِهِ وَهُوَ أَعْلَمُ
بِالْمُهْتَدِينَ
Inna rabbaka huwa aAAlamu biman dallaAAan sabeelihi wahuwa aAAlamu bilmuhtadeen
Yoruba
Dájúdájú Olúwa rẹ, Ó nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tó ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà Rẹ̀. Ó sì nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùmọ̀nà.
|
Ayah 68:8 الأية
فَلَا تُطِعِ الْمُكَذِّبِينَ
Fala tutiAAi almukaththibeen
Yoruba
Nítorí náà, má ṣe tẹ̀lé àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
|
Ayah 68:9 الأية
وَدُّوا لَوْ تُدْهِنُ فَيُدْهِنُونَ
Waddoo law tudhinu fayudhinoon
Yoruba
Àti pé wọ́n fẹ́ kí o dẹwọ́, kí àwọn náà sì dẹwọ́.
|
Ayah 68:10 الأية
وَلَا تُطِعْ كُلَّ حَلَّافٍ مَّهِينٍ
Wala tutiAA kulla hallafinmaheen
Yoruba
Má ṣe tẹ̀lé gbogbo ẹni tí ìbúra rẹ̀ pọ̀, ẹni yẹpẹrẹ,
|
Ayah 68:11 الأية
هَمَّازٍ مَّشَّاءٍ بِنَمِيمٍ
Hammazin mashsha-in binameem
Yoruba
Abúni, alárìnká tó ń sòfófó kiri,
|
Ayah 68:12 الأية
مَّنَّاعٍ لِّلْخَيْرِ مُعْتَدٍ أَثِيمٍ
MannaAAin lilkhayri muAAtadin atheem
Yoruba
Olùdènà iṣẹ́ rere, alákọyọ, ẹlẹ́ṣẹ̀,
|
Ayah 68:13 الأية
عُتُلٍّ بَعْدَ ذَٰلِكَ زَنِيمٍ
AAutullin baAAda thalika zaneem
Yoruba
ọ̀dájú. Lẹ́yìn ìyẹn, ògbólógbòó ẹni ibi (àsáwọ̀, ọmọ zina) ni.
|
Ayah 68:14 الأية
أَن كَانَ ذَا مَالٍ وَبَنِينَ
An kana tha malinwabaneen
Yoruba
Nítorí pé ó ní dúkìá àti àwọn ọmọkùnrin,
|
Ayah 68:15 الأية
إِذَا تُتْلَىٰ عَلَيْهِ آيَاتُنَا قَالَ أَسَاطِيرُ الْأَوَّلِينَ
Itha tutla AAalayhi ayatunaqala asateeru al-awwaleen
Yoruba
Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa fún un, ó máa wí pé: "Àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́ (nìwọ̀nyí)".
|
Ayah 68:16 الأية
سَنَسِمُهُ عَلَى الْخُرْطُومِ
Sanasimuhu AAala alkhurtoom
Yoruba
A máa fi àmì sí i ní góńgórí imú.
|
Ayah 68:17 الأية
إِنَّا بَلَوْنَاهُمْ كَمَا بَلَوْنَا أَصْحَابَ الْجَنَّةِ إِذْ أَقْسَمُوا
لَيَصْرِمُنَّهَا مُصْبِحِينَ
Inna balawnahum kamabalawna as-haba aljannati ith aqsamoolayasrimunnaha
musbiheen
Yoruba
Dájúdájú Àwa dán wọn wò gẹ́gẹ́ bí A ṣe dán àwọn ọlọ́gbà wò nígbà tí wọ́n búra pé, dájúdájú àwọn yóò ká gbogbo èso ọgbà náà ní òwúrọ̀ kùtùkùtù.
|
Ayah 68:18 الأية
وَلَا يَسْتَثْنُونَ
Wala yastathnoon
Yoruba
Wọn kò sì ṣe àyàfi pé, "tí Allāhu bá fẹ́".
|
Ayah 68:19 الأية
فَطَافَ عَلَيْهَا طَائِفٌ مِّن رَّبِّكَ وَهُمْ نَائِمُونَ
Fatafa AAalayha ta-ifunmin rabbika wahum na-imoon
Yoruba
Àdánwò tó ń yí n̄ǹkan po láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ sì yí ọgbà náà po, nígbà tí wọ́n sùn lọ.
|
Ayah 68:20 الأية
فَأَصْبَحَتْ كَالصَّرِيمِ
Faasbahat kassareem
Yoruba
Ó sì dà bí oko àgédànù (tí wọ́n ti résun).
|
Ayah 68:21 الأية
فَتَنَادَوْا مُصْبِحِينَ
Fatanadaw musbiheen
Yoruba
Wọ́n ń pera wọn ní òwúrọ̀ kùtùkùtù
|
Ayah 68:22 الأية
أَنِ اغْدُوا عَلَىٰ حَرْثِكُمْ إِن كُنتُمْ صَارِمِينَ
Ani ighdoo AAala harthikum inkuntum sarimeen
Yoruba
Pé ẹ jí lọ sí oko yín tí ẹ bá fẹ́ ká èso.
|
Ayah 68:23 الأية
فَانطَلَقُوا وَهُمْ يَتَخَافَتُونَ
Fantalaqoo wahum yatakhafatoon
Yoruba
Wọ́n lọ, wọ́n sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ bára wọn sọ̀rọ̀
|
Ayah 68:24 الأية
أَن لَّا يَدْخُلَنَّهَا الْيَوْمَ عَلَيْكُم مِّسْكِينٌ
An la yadkhulannaha alyawmaAAalaykum miskeen
Yoruba
Pé ní òní mẹ̀kúnnù kan kò gbọdọ̀ wọnú rẹ̀ wá ba yín.
|
Ayah 68:25 الأية
وَغَدَوْا عَلَىٰ حَرْدٍ قَادِرِينَ
Waghadaw AAala hardin qadireen
Yoruba
Wọ́n jí lọ (sí oko wọn) lórí èrò-ọkàn kan (pé) àwọn lágbára.
|
Ayah 68:26 الأية
فَلَمَّا رَأَوْهَا قَالُوا إِنَّا لَضَالُّونَ
Falamma raawha qalooinna ladalloon
Yoruba
Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n wí pé: "Dájúdájú àwa ti ṣìnà.
|
Ayah 68:27 الأية
بَلْ نَحْنُ مَحْرُومُونَ
Bal nahnu mahroomoon
Yoruba
Rárá o, wọ́n ṣe ìkórè oko léèwọ̀ fún wa ni."
|
Ayah 68:28 الأية
قَالَ أَوْسَطُهُمْ أَلَمْ أَقُل لَّكُمْ لَوْلَا تُسَبِّحُونَ
Qala awsatuhum alam aqul lakumlawla tusabbihoon
Yoruba
Ẹni tó dúró déédé jùlọ nínú wọn sọ pé: "Ṣé èmi kò sọ fún yín pé ẹ̀yin kò ṣe ṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu (pé "a máa kórè oko wa, 'in ṣā 'Allāhu.)"?
|
Ayah 68:29 الأية
قَالُوا سُبْحَانَ رَبِّنَا إِنَّا كُنَّا ظَالِمِينَ
Qaloo subhana rabbinainna kunna thalimeen
Yoruba
Wọ́n wí pé: "Mímọ́ ni fún Olúwa wa, dájúdájú àwa jẹ́ alábòsí."
|
Ayah 68:30 الأية
فَأَقْبَلَ بَعْضُهُمْ عَلَىٰ بَعْضٍ يَتَلَاوَمُونَ
Faaqbala baAAduhum AAala baAAdinyatalawamoon
Yoruba
Apá kan wọn kọjú sí apá kan; wọ́n sì ń dára wọn lẹ́bi.
|
Ayah 68:31 الأية
قَالُوا يَا وَيْلَنَا إِنَّا كُنَّا طَاغِينَ
Qaloo ya waylana innakunna tagheen
Yoruba
Wọ́n wí pé: "Ègbé wa ò! Dájúdájú àwa jẹ́ olùtayọ-ẹnu ààlà.
|
Ayah 68:32 الأية
عَسَىٰ رَبُّنَا أَن يُبْدِلَنَا خَيْرًا مِّنْهَا إِنَّا إِلَىٰ رَبِّنَا
رَاغِبُونَ
AAasa rabbuna an yubdilanakhayran minha inna ila rabbina raghiboon
Yoruba
Ó ṣeé ṣe kí Olúwa wa fi èyí tó dára ju èyí lọ pààrọ̀ rẹ̀ fún wa. Dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa wa ni àwa ń rokàn oore sí."
|
Ayah 68:33 الأية
كَذَٰلِكَ الْعَذَابُ ۖ وَلَعَذَابُ الْآخِرَةِ أَكْبَرُ ۚ لَوْ كَانُوا
يَعْلَمُونَ
Kathalika alAAathabu walaAAathabual-akhirati akbaru law kanoo yaAAlamoon
Yoruba
Báyẹn ni ìyà náà ṣe rí (fún wọn). Ìyà ọ̀run sì tóbi jùlọ, tí ó bá jẹ́ pé wọ́n mọ̀.
|
Ayah 68:34 الأية
إِنَّ لِلْمُتَّقِينَ عِندَ رَبِّهِمْ جَنَّاتِ النَّعِيمِ
Inna lilmuttaqeena AAinda rabbihim jannatiannaAAeem
Yoruba
Dájúdájú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra wà fún àwọn olùbẹ̀rù Allāhu lọ́dọ̀ Olúwa wọn.
|
Ayah 68:35 الأية
أَفَنَجْعَلُ الْمُسْلِمِينَ كَالْمُجْرِمِينَ
AfanajAAalu almuslimeena kalmujrimeen
Yoruba
Ṣé A máa ṣe àwọn mùsùlùmí bí (A ṣe máa ṣe) àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bí?
|
Ayah 68:36 الأية
مَا لَكُمْ كَيْفَ تَحْكُمُونَ
Ma lakum kayfa tahkumoon
Yoruba
Kí l'ó ń ṣe yín tí ẹ fi ń dájọ́ báyìí ná?
|
Ayah 68:37 الأية
أَمْ لَكُمْ كِتَابٌ فِيهِ تَدْرُسُونَ
Am lakum kitabun feehi tadrusoon
Yoruba
Tàbí tírà kan wà fún yín tí ẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀
|
Ayah 68:38 الأية
إِنَّ لَكُمْ فِيهِ لَمَا تَخَيَّرُونَ
Inna lakum feehi lama takhayyaroon
Yoruba
Pé dájúdájú ẹ̀yin lẹ ni ohun tí ẹ bá ń ṣà lẹ́ṣà nínú ìdájọ́?
|
Ayah 68:39 الأية
أَمْ لَكُمْ أَيْمَانٌ عَلَيْنَا بَالِغَةٌ إِلَىٰ يَوْمِ الْقِيَامَةِ ۙ إِنَّ
لَكُمْ لَمَا تَحْكُمُونَ
Am lakum aymanun AAalayna balighatunila yawmi alqiyamati inna lakum lama
tahkumoon
Yoruba
Ǹjẹ́ ẹ ni àwọn àdéhùn kan lọ́dọ̀ wa tí ó máa wà títí di Ọjọ́ Àjíǹde pé: "Dájúdájú tiyín ni ìdájọ́ tí ẹ bá ti mú wá."?
|
Ayah 68:40 الأية
سَلْهُمْ أَيُّهُم بِذَٰلِكَ زَعِيمٌ
Salhum ayyuhum bithalika zaAAeem
Yoruba
Bi wọ́n léèrè wò pé èwo nínú wọn l'ó lè fọwọ́ ìyẹn sọ̀yà!
|
Ayah 68:41 الأية
أَمْ لَهُمْ شُرَكَاءُ فَلْيَأْتُوا بِشُرَكَائِهِمْ إِن كَانُوا صَادِقِينَ
Am lahum shurakao falya/too bishuraka-ihimin kanoo sadiqeen
Yoruba
Tàbí wọ́n ní (àwọn òrìṣà kan) tí wọ́n jẹ́ akẹgbẹ́ Wa? Kí wọ́n mú àwọn òrìṣà wọn wá nígbà náà tí wọ́n bá jẹ́ olódodo.
|
Ayah 68:42 الأية
يَوْمَ يُكْشَفُ عَن سَاقٍ وَيُدْعَوْنَ إِلَى السُّجُودِ فَلَا يَسْتَطِيعُونَ
Yawma yukshafu AAan saqin wayudAAawnaila assujoodi fala yastateeAAoon
Yoruba
Ní ọjọ́ tí A máa ṣí ojúgun sílẹ̀, A sì máa pè wọ́n síbi ìforíkanlẹ̀, wọn kò sì níí lè ṣe é.
|
Ayah 68:43 الأية
خَاشِعَةً أَبْصَارُهُمْ تَرْهَقُهُمْ ذِلَّةٌ ۖ وَقَدْ كَانُوا يُدْعَوْنَ إِلَى
السُّجُودِ وَهُمْ سَالِمُونَ
KhashiAAatan absaruhumtarhaquhum thillatun waqad kanoo yudAAawna ilaassujoodi
wahum salimoon
Yoruba
Ojú wọn yóò wálẹ̀. Ìyẹpẹrẹ máa bò wọ́n mọ́lẹ̀. Wọ́n kúkú ti pè wọ́n síbi ìforíkanlẹ̀ nígbà tí wọ́n ní àlàáfíà (wọn kò sì kírun).
|
Ayah 68:44 الأية
فَذَرْنِي وَمَن يُكَذِّبُ بِهَٰذَا الْحَدِيثِ ۖ سَنَسْتَدْرِجُهُم مِّنْ حَيْثُ
لَا يَعْلَمُونَ
Fatharnee waman yukaththibubihatha alhadeethi sanastadrijuhum min haythula
yaAAlamoon
Yoruba
Nítorí náà, fi Èmi àti ẹni tó ń pe ọ̀rọ̀ yìí ní irọ́ sílẹ̀. A óò máa dẹ wọ́n lẹ́kẹ láti jẹ wọ́n níyà ní àyè tí wọn kò mọ̀.
|
Ayah 68:45 الأية
وَأُمْلِي لَهُمْ ۚ إِنَّ كَيْدِي مَتِينٌ
Waomlee lahum inna kaydee mateen
Yoruba
Mò ń lọ́ra fún wọn ni. Dájúdájú ète Mi lágbára.
|
Ayah 68:46 الأية
أَمْ تَسْأَلُهُمْ أَجْرًا فَهُم مِّن مَّغْرَمٍ مُّثْقَلُونَ
Am tas-aluhum ajran fahum min maghraminmuthqaloon
Yoruba
Tàbí ò ń bèèrè owó-ọ̀yà kan lọ́wọ́ wọn, ni gbèsè fi wọ̀ wọ́n lọ́rùn?
|
Ayah 68:47 الأية
أَمْ عِندَهُمُ الْغَيْبُ فَهُمْ يَكْتُبُونَ
Am AAindahumu alghaybu fahum yaktuboon
Yoruba
Tàbí lọ́dọ̀ wọn ni (wàláà) ìkọ̀kọ̀ wà ni wọ́n bá ń kọ ọ́ (síta)?
|
Ayah 68:48 الأية
فَاصْبِرْ لِحُكْمِ رَبِّكَ وَلَا تَكُن كَصَاحِبِ الْحُوتِ إِذْ نَادَىٰ وَهُوَ
مَكْظُومٌ
Fasbir lihukmi rabbikawala takun kasahibi alhooti ith nadawahuwa makthoom
Yoruba
Nítorí náà, ṣe sùúrù fún ìdájọ́ Olúwa rẹ. Kí ìwọ má sì ṣe dà bí ẹlẹ́ja (ìyẹn, Ànábì Yūnus) nígbà tí ó pe (Allāhu) pẹ̀lú ìbànújẹ́.
|
Ayah 68:49 الأية
لَّوْلَا أَن تَدَارَكَهُ نِعْمَةٌ مِّن رَّبِّهِ لَنُبِذَ بِالْعَرَاءِ وَهُوَ
مَذْمُومٌ
Lawla an tadarakahu niAAmatunmin rabbihi lanubitha bilAAara-i wahuwa mathmoom
Yoruba
Tí kò bá jẹ́ pé ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ lé e bá, wọn ìbá jù ú sórí ilẹ̀ gban̄sasa (láti inú ẹja) ní ẹni-èébú.
|
Ayah 68:50 الأية
فَاجْتَبَاهُ رَبُّهُ فَجَعَلَهُ مِنَ الصَّالِحِينَ
Fajtabahu rabbuhu fajaAAalahumina assaliheen
Yoruba
Nítorí náà, Olúwa rẹ̀ ṣà á lẹ́ṣà. Ó sì ṣe é ní ara àwọn ẹni rere.
|
Ayah 68:51 الأية
وَإِن يَكَادُ الَّذِينَ كَفَرُوا لَيُزْلِقُونَكَ بِأَبْصَارِهِمْ لَمَّا سَمِعُوا
الذِّكْرَ وَيَقُولُونَ إِنَّهُ لَمَجْنُونٌ
Wa-in yakadu allatheenakafaroo layuzliqoonaka bi-absarihim lamma
samiAAooaththikra wayaqooloona innahu lamajnoon
Yoruba
Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ fẹ́ẹ̀ fi ojú wọn gbé ọ ṣubú nígbà tí wọ́n gbọ́ ìrántí náà. Wọ́n sì ń wí pé: "Dájúdájú wèrè mà ni."
|
Ayah 68:52 الأية
وَمَا هُوَ إِلَّا ذِكْرٌ لِّلْعَالَمِينَ
Wama huwa illa thikrunlilAAalameen
Yoruba
Kí sì ni al-Ƙur'ān bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá.
|
©
EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us
|