1st Ayah 1 الأية ١الأوليبِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
قُلْ أُوحِيَ إِلَيَّ أَنَّهُ اسْتَمَعَ نَفَرٌ مِّنَ الْجِنِّ فَقَالُوا إِنَّا
سَمِعْنَا قُرْآنًا عَجَبًا
Qul oohiya ilayya annahu istamaAAanafarun mina aljinni faqaloo inna
samiAAnaqur-anan AAajaba
Yoruba
Sọ pé: "Wọ́n fi ìmísí ránṣẹ́ sí mi pé, dájúdájú ìjọ kan nínú àwọn àlùjànnú tẹ́tí (sí al-Ƙur'ān)." Wọ́n sì sọ pé: "Dájúdájú àwa gbọ́ al-Ƙur'ān ìyanu.
|
Ayah 72:2 الأية
يَهْدِي إِلَى الرُّشْدِ فَآمَنَّا بِهِ ۖ وَلَن نُّشْرِكَ بِرَبِّنَا أَحَدًا
Yahdee ila arrushdi faamannabihi walan nushrika birabbina ahada
Yoruba
Ó ń ṣètọ́sọ́nà síbi ìmọ̀nà. Nítorí náà, a gbà á gbọ́. Àwa kò sì níí fi ẹnì kan kan ṣe akẹgbẹ́ fún Olúwa wa (àwa kò níí ṣẹbọ).
|
Ayah 72:3 الأية
وَأَنَّهُ تَعَالَىٰ جَدُّ رَبِّنَا مَا اتَّخَذَ صَاحِبَةً وَلَا وَلَدًا
Waannahu taAAala jaddu rabbinama ittakhatha sahibatan wala walada
Yoruba
Àti pé dájúdájú títóbi Olúwa wa ga. Kò fi ẹnì kan kan ṣe aya àti ọmọ.
|
Ayah 72:4 الأية
وَأَنَّهُ كَانَ يَقُولُ سَفِيهُنَا عَلَى اللهِ شَطَطًا
Waannahu kana yaqoolu safeehunaAAala Allahi shatata
Yoruba
Dájúdájú òmùgọ̀ nínú wa máa ń sọ ìsọkúsọ nípa Allāhu.
|
Ayah 72:5 الأية
وَأَنَّا ظَنَنَّا أَن لَّن تَقُولَ الْإِنسُ وَالْجِنُّ عَلَى اللهِ كَذِبًا
Waanna thanannaan lan taqoola al-insu waljinnu AAala Allahikathiba
Yoruba
Dájúdájú àwa sì ń rò pé ènìyàn àti àlùjànnú kò níí pa irọ́ mọ́ Allāhu ni.
|
Ayah 72:6 الأية
وَأَنَّهُ كَانَ رِجَالٌ مِّنَ الْإِنسِ يَعُوذُونَ بِرِجَالٍ مِّنَ الْجِنِّ
فَزَادُوهُمْ رَهَقًا
Waannahu kana rijalun minaal-insi yaAAoothoona birijalin mina aljinni
fazadoohumrahaqa
Yoruba
Àti pé dájúdájú àwọn ọkùnrin kan nínú ènìyàn máa ń fi àwọn ọkùnrin kan nínú àwọn àlùjànnú wá ààbò. Àwọn àlùjànnú sì ṣe àlékún aburú fún wọn.
|
Ayah 72:7 الأية
وَأَنَّهُمْ ظَنُّوا كَمَا ظَنَنتُمْ أَن لَّن يَبْعَثَ اللهُ أَحَدًا
Waannahum thannoo kama thanantuman lan yabAAatha Allahu ahada
Yoruba
Dájúdájú àwọn àlùjànnú lérò gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ènìyàn náà ṣe lérò pé, Allāhu kò níí gbé ẹnì kan kan dìde (lẹ́yìn ikú).
|
Ayah 72:8 الأية
وَأَنَّا لَمَسْنَا السَّمَاءَ فَوَجَدْنَاهَا مُلِئَتْ حَرَسًا شَدِيدًا وَشُهُبًا
Waanna lamasna assamaafawajadnaha muli-at harasan shadeedanwashuhuba
Yoruba
Dájúdájú àwa wá (ọ̀rọ̀ àyọ́gbọ́) wá sí sánmọ̀, a sì bá a tí ó ti kún fún àwọn ẹ̀ṣọ́ tó lágbára àti àwọn ògúnná.
|
Ayah 72:9 الأية
وَأَنَّا كُنَّا نَقْعُدُ مِنْهَا مَقَاعِدَ لِلسَّمْعِ ۖ فَمَن يَسْتَمِعِ الْآنَ
يَجِدْ لَهُ شِهَابًا رَّصَدًا
Waanna kunna naqAAudu minhamaqaAAida lissamAAi faman yastamiAAi al-anayajid lahu
shihaban rasada
Yoruba
Dájúdájú àwa máa ń jókòó síbẹ̀ ní àwọn ibùdó kan fún gbígbọ́ ọ̀rọ̀. Ṣùgbọ́n ẹni tó bá jọ́rọ̀ gbọ́ lásìkò yìí, ó máa rí ògúnná tó ti lúgọ dè é.
|
Ayah 72:10 الأية
وَأَنَّا لَا نَدْرِي أَشَرٌّ أُرِيدَ بِمَن فِي الْأَرْضِ أَمْ أَرَادَ بِهِمْ
رَبُّهُمْ رَشَدًا
Waanna la nadree asharrunoreeda biman fee al-ardi am arada bihim rabbuhumrashada
Yoruba
Dájúdájú àwa kò sì mọ̀ bóyá aburú ni wọ́n gbàlérò pẹ̀lú àwọn tó wà lórí ilẹ̀ tàbí Olúwa wọn gbèrò ìmọ̀nà fún wọn.
|
Ayah 72:11 الأية
وَأَنَّا مِنَّا الصَّالِحُونَ وَمِنَّا دُونَ ذَٰلِكَ ۖ كُنَّا طَرَائِقَ قِدَدًا
Waanna minna assalihoonawaminna doona thalika kunna tara-iqaqidada
Yoruba
Dájúdájú àwọn ẹni rere wà nínú wa. Àwọn mìíràn yàtọ̀ sí ìyẹn tún wà nínú wa. A wà lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
|
Ayah 72:12 الأية
وَأَنَّا ظَنَنَّا أَن لَّن نُّعْجِزَ اللهَ فِي الْأَرْضِ وَلَن نُّعْجِزَهُ
هَرَبًا
Wanna thanannaan lan nuAAjiza Allaha fee al-ardi walan nuAAjizahuharaba
Yoruba
Dájúdájú àwa mọ àmọ̀dájú pé àwa kò lè mórí bọ́ mọ́ Allāhu lọ́wọ́ lórí ilẹ̀. Àwa kò sì lè sá mọ́ Ọn lọ́wọ́.
|
Ayah 72:13 الأية
وَأَنَّا لَمَّا سَمِعْنَا الْهُدَىٰ آمَنَّا بِهِ ۖ فَمَن يُؤْمِن بِرَبِّهِ فَلَا
يَخَافُ بَخْسًا وَلَا رَهَقًا
Waanna lamma samiAAnaalhuda amanna bihi faman yu/min birabbihifala yakhafu
bakhsan wala rahaqa
Yoruba
Dájúdájú nígbà tí a gbọ́ nípa ìmọ̀nà (láti inú al-Ƙur'ān), a gbà á gbọ́. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàgbọ́ ní òdodo nínú Olúwa rẹ̀, kí ó má bẹ̀rù àdínkù(nínú ẹ̀san rere) àti (àlékún) aburú.
|
Ayah 72:14 الأية
وَأَنَّا مِنَّا الْمُسْلِمُونَ وَمِنَّا الْقَاسِطُونَ ۖ فَمَنْ أَسْلَمَ
فَأُولَٰئِكَ تَحَرَّوْا رَشَدًا
Waanna minna almuslimoonawaminna alqasitoona faman aslama faola-ikataharraw
rashada
Yoruba
Dájúdájú àwọn mùsùlùmí wà nínú wa. Àwọn arúfin náà wà nínú wa. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe 'Islām, àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n ṣe àwárí ìmọ̀nà."
|
Ayah 72:15 الأية
وَأَمَّا الْقَاسِطُونَ فَكَانُوا لِجَهَنَّمَ حَطَبًا
Waama alqasitoona fakanoolijahannama hataba
Yoruba
Ní ti àwọn arúfin, àwọn ni wọ́n máa jẹ́ igi ìkoná fún iná Jahanamọ."
|
Ayah 72:16 الأية
وَأَن لَّوِ اسْتَقَامُوا عَلَى الطَّرِيقَةِ لَأَسْقَيْنَاهُم مَّاءً غَدَقًا
Waallawi istaqamoo AAala attareeqatilaasqaynahum maan ghadaqa
Yoruba
Àti pé tí ó bá jẹ́ pé wọ́n dúró ṣinṣin lójú ọ̀nà ('Islām) ni, dájúdájú Àwa ìbá fún wọn ní omi púpọ̀ mu.
|
Ayah 72:17 الأية
لِّنَفْتِنَهُمْ فِيهِ ۚ وَمَن يُعْرِضْ عَن ذِكْرِ رَبِّهِ يَسْلُكْهُ عَذَابًا
صَعَدًا
Linaftinahum feehi waman yuAArid AAanthikri rabbihi yasluk-hu AAathaban saAAada
Yoruba
Nítorí kí Á lè fi dán wọn wò ni. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbúnrí kúrò níbi ìrántí Olúwa rẹ̀, Allāhu máa mú un wọ inú ìyà ìnira.
|
Ayah 72:18 الأية
وَأَنَّ الْمَسَاجِدَ لِلَّهِ فَلَا تَدْعُوا مَعَ اللهِ أَحَدًا
Waanna almasajida lillahi falatadAAoo maAAa Allahi ahada
Yoruba
Dájúdájú àwọn mọ́sálásí ń jẹ́ ti Allāhu. Nítorí náà, ẹ kò gbọ́dọ̀ pe ẹnì kan pẹ̀lú Allāhu.
|
Ayah 72:19 الأية
وَأَنَّهُ لَمَّا قَامَ عَبْدُ اللهِ يَدْعُوهُ كَادُوا يَكُونُونَ عَلَيْهِ
لِبَدًا
Waannahu lamma qama AAabdu AllahiyadAAoohu kadoo yakoonoona AAalayhi libada
Yoruba
Dájúdájú nígbà tí ẹrúsìn Allāhu dìde dúró tó ń pe Allāhu, àwọn àlùjànnú fẹ́ẹ̀ máa dìfún-ùn-ùnfún lọ́dọ̀ rẹ̀ (láti tẹ́tí sí al-Ƙur'ān).
|
Ayah 72:20 الأية
قُلْ إِنَّمَا أَدْعُو رَبِّي وَلَا أُشْرِكُ بِهِ أَحَدًا
Qul innama adAAoo rabbee walaoshriku bihi ahada
Yoruba
Sọ pé: "Olúwa mi ni mò ń pè. Àti pé èmi kò níí sọ ẹnì kan kan di akẹgbẹ́ fún Un."
|
Ayah 72:21 الأية
قُلْ إِنِّي لَا أَمْلِكُ لَكُمْ ضَرًّا وَلَا رَشَدًا
Qul innee la amliku lakum darranwala rashada
Yoruba
Sọ pé: "Dájúdájú èmi kò ní ìkápá lórí ìnira àti ìmọ̀nà fún yín."
|
Ayah 72:22 الأية
قُلْ إِنِّي لَن يُجِيرَنِي مِنَ اللهِ أَحَدٌ وَلَنْ أَجِدَ مِن دُونِهِ
مُلْتَحَدًا
Qul innee lan yujeeranee mina Allahiahadun walan ajida min doonihi multahada
Yoruba
Sọ pé: "Dájúdájú èmi, kò sí ẹnì kan tó lè gbà mí là lọ́dọ̀ Allāhu. Èmi kò sì rí ibùsásí kan lẹ́yìn Rẹ̀.
|
Ayah 72:23 الأية
إِلَّا بَلَاغًا مِّنَ اللهِ وَرِسَالَاتِهِ ۚ وَمَن يَعْصِ اللهَ وَرَسُولَهُ
فَإِنَّ لَهُ نَارَ جَهَنَّمَ خَالِدِينَ فِيهَا أَبَدًا
Illa balaghan mina Allahiwarisalatihi waman yaAAsi Allahawarasoolahu fa-inna
lahu nara jahannama khalideenafeeha abada
Yoruba
Àfi (kí n̄g ṣe) ìkédé ẹ̀sìn (tó wá) láti ọ̀dọ̀ Allāhu àti pé (kí n̄g sì jẹ́) àwọn iṣẹ́ Rẹ̀ (t'Ó fi rán mi). Ẹnikẹ́ni tó bá yapa Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, dájúdájú iná Jahanamọ ń bẹ fún un. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé.
|
Ayah 72:24 الأية
حَتَّىٰ إِذَا رَأَوْا مَا يُوعَدُونَ فَسَيَعْلَمُونَ مَنْ أَضْعَفُ نَاصِرًا
وَأَقَلُّ عَدَدًا
Hatta itha raaw mayooAAadoona fasayaAAlamoona man adAAafu nasiranwaaqallu
AAadada
Yoruba
(Aláìgbàgbọ́ kò níí yé ṣàì gbàgbọ́) títí di ìgbà tí wọ́n yóò fi rí ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn. Nígbà náà, wọn yóò mọ ta ni ó lẹ jùlọ ní alárànṣe, tí ó sì kéré jùlọ ní òǹkà.
|
Ayah 72:25 الأية
قُلْ إِنْ أَدْرِي أَقَرِيبٌ مَّا تُوعَدُونَ أَمْ يَجْعَلُ لَهُ رَبِّي أَمَدًا
Qul in adree aqareebun ma tooAAadoonaam yajAAalu lahu rabbee amada
Yoruba
Sọ pé: "Èmi kò mọ̀ bóyá ohun tí Wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fún yín ti súnmọ́ tàbí Olúwa mi yóò fún un ní àkókò tó jìnnà.
|
Ayah 72:26 الأية
عَالِمُ الْغَيْبِ فَلَا يُظْهِرُ عَلَىٰ غَيْبِهِ أَحَدًا
AAalimu alghaybi fala yuthhiruAAala ghaybihi ahada
Yoruba
Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀, kò sì fi (ìmọ̀) ìkọ̀kọ̀ Rẹ̀ han ẹnì kan
|
Ayah 72:27 الأية
إِلَّا مَنِ ارْتَضَىٰ مِن رَّسُولٍ فَإِنَّهُ يَسْلُكُ مِن بَيْنِ يَدَيْهِ وَمِنْ
خَلْفِهِ رَصَدًا
Illa mani irtada min rasoolinfa-innahu yasluku min bayni yadayhi wamin khalfihi
rasada
Yoruba
Àyàfi ẹni tí Ó ṣàlẹ́ṣà tí ó jẹ́ Òjísẹ́. Dájúdájú Ó ń mú ẹ̀ṣọ́ kan rìn níwájú Òjíṣẹ́ náà àti lẹ́yìn rẹ̀
|
Ayah 72:28 الأية
لِّيَعْلَمَ أَن قَدْ أَبْلَغُوا رِسَالَاتِ رَبِّهِمْ وَأَحَاطَ بِمَا لَدَيْهِمْ
وَأَحْصَىٰ كُلَّ شَيْءٍ عَدَدًا
LiyaAAlama an qad ablaghoo risalatirabbihim waahata bima ladayhim waahsa
kullashay-in AAadada
Yoruba
Nítorí kí Ó lè ṣàfi hàn pé wọ́n ti jẹ́ àwọn iṣẹ́ Olúwa wọn dé ògòńgó. Àti pé Allāhu fi ìmọ̀ rọkiri ká ohun tí ń bẹ lọ́dọ̀ wọn. Ó sì ṣọ́ òǹkà gbogbo n̄ǹkan.
|
©
EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us
|