Prev  

14. Surah Ibrahîm سورة إبراهيم

  Next  




Ayah  14:1  الأية
    +/- -/+  
بِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
الر ۚ كِتَابٌ أَنزَلْنَاهُ إِلَيْكَ لِتُخْرِجَ النَّاسَ مِنَ الظُّلُمَاتِ إِلَى النُّورِ بِإِذْنِ رَبِّهِمْ إِلَىٰ صِرَاطِ الْعَزِيزِ الْحَمِيدِ
Yoruba
 
'Alif lām rọ̄. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.) (Èyí ni) Tírà kan tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ nítorí kí o lè mú àwọn ènìyàn kúrò láti inú àwọn òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Olúwa wọn. (Wọn yó sì bọ́) sí ọ̀nà Alágbára, Ọlọ́pẹ́ (tí ọpẹ́ tọ́ sí),

Ayah  14:2  الأية
    +/- -/+  
اللهِ الَّذِي لَهُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۗ وَوَيْلٌ لِّلْكَافِرِينَ مِنْ عَذَابٍ شَدِيدٍ
Yoruba
 
Allāhu, Ẹni tí Ó ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Ègbé ni fún àwọn aláìgbàgbọ́ níbi ìyà líle.

Ayah  14:3  الأية
    +/- -/+  
الَّذِينَ يَسْتَحِبُّونَ الْحَيَاةَ الدُّنْيَا عَلَى الْآخِرَةِ وَيَصُدُّونَ عَن سَبِيلِ اللهِ وَيَبْغُونَهَا عِوَجًا ۚ أُولَٰئِكَ فِي ضَلَالٍ بَعِيدٍ
Yoruba
 
Àwọn tó ń fẹ́ràn ìṣẹ̀mí ayé ju tọ̀run, tí wọ́n ń ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, wọ́n sì ń fẹ́ kó wọ́; àwọn wọ̀nyẹn wà nínú ìṣìnà tó jìnnà.

Ayah  14:4  الأية
    +/- -/+  
وَمَا أَرْسَلْنَا مِن رَّسُولٍ إِلَّا بِلِسَانِ قَوْمِهِ لِيُبَيِّنَ لَهُمْ ۖ فَيُضِلُّ اللهُ مَن يَشَاءُ وَيَهْدِي مَن يَشَاءُ ۚ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ
Yoruba
 
A kò rán Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ àfi pẹ̀lú èdè àwọn ènìyàn rẹ̀ nítorí kí ó lè ṣàlàyé (ẹ̀sìn) fún wọn. Nígbà náà, Allāhu yóò ṣi ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́nà. Ó sì máa tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sọ́nà; Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

Ayah  14:5  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا مُوسَىٰ بِآيَاتِنَا أَنْ أَخْرِجْ قَوْمَكَ مِنَ الظُّلُمَاتِ إِلَى النُّورِ وَذَكِّرْهُم بِأَيَّامِ اللهِ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِّكُلِّ صَبَّارٍ شَكُورٍ
Yoruba
 
A kúkú fi àwọn āyah Wa rán (Ànábì) Mūsā níṣẹ́ pé: "Mú ìjọ rẹ kúrò láti inú àwọn òkùnkùn bọ́ sínú ìmólẹ̀. Kí o sì rán wọn létí àwọn ìdẹ̀ra Allāhu (lórí wọn)." Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún gbogbo onísùúrù, olùdúpẹ́.

Ayah  14:6  الأية
    +/- -/+  
وَإِذْ قَالَ مُوسَىٰ لِقَوْمِهِ اذْكُرُوا نِعْمَةَ اللهِ عَلَيْكُمْ إِذْ أَنجَاكُم مِّنْ آلِ فِرْعَوْنَ يَسُومُونَكُمْ سُوءَ الْعَذَابِ وَيُذَبِّحُونَ أَبْنَاءَكُمْ وَيَسْتَحْيُونَ نِسَاءَكُمْ ۚ وَفِي ذَٰلِكُم بَلَاءٌ مِّن رَّبِّكُمْ عَظِيمٌ
Yoruba
 
(Rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún ìjọ rẹ̀ pé, ẹ rántí ìkẹ́ Allāhu lórí yín nígbà tí Ó gbà yín là lọ́wọ́ àwọn ènìyàn Fir‘aon, tí wọ́n ń fi ìyà burúkú jẹ yín; wọ́n ń dúnńbú àwọn ọmọkùnrin yín, wọ́n sì ń dá àwọn ọmọbìnrin yín sí. Àdánwò ńlá wà nínú ìyẹn láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín.

Ayah  14:7  الأية
    +/- -/+  
وَإِذْ تَأَذَّنَ رَبُّكُمْ لَئِن شَكَرْتُمْ لَأَزِيدَنَّكُمْ ۖ وَلَئِن كَفَرْتُمْ إِنَّ عَذَابِي لَشَدِيدٌ
Yoruba
 
(Ẹ rántí) nígbà tí Olúwa Ẹlẹ́dàá yín sọ ọ́ di mímọ̀ (fún yín pé): "Dájúdájú tí ẹ bá dúpẹ́, Èmi yóò ṣàlékún fún yín. Dájúdájú tí ẹ bá sì ṣàì moore, dájúdájú ìyà Mi mà le."

Ayah  14:8  الأية
    +/- -/+  
وَقَالَ مُوسَىٰ إِن تَكْفُرُوا أَنتُمْ وَمَن فِي الْأَرْضِ جَمِيعًا فَإِنَّ اللهَ لَغَنِيٌّ حَمِيدٌ
Yoruba
 
(Ànábì) Mūsā sọ pé: "Tí ẹ bá ṣàì moore, ẹ̀yin àti àwọn tó ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé pátápátá, dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́rọ̀, Ọlọ́pẹ́."

Ayah  14:9  الأية
    +/- -/+  
أَلَمْ يَأْتِكُمْ نَبَأُ الَّذِينَ مِن قَبْلِكُمْ قَوْمِ نُوحٍ وَعَادٍ وَثَمُودَ ۛ وَالَّذِينَ مِن بَعْدِهِمْ ۛ لَا يَعْلَمُهُمْ إِلَّا اللهُ ۚ جَاءَتْهُمْ رُسُلُهُم بِالْبَيِّنَاتِ فَرَدُّوا أَيْدِيَهُمْ فِي أَفْوَاهِهِمْ وَقَالُوا إِنَّا كَفَرْنَا بِمَا أُرْسِلْتُم بِهِ وَإِنَّا لَفِي شَكٍّ مِّمَّا تَدْعُونَنَا إِلَيْهِ مُرِيبٍ
Yoruba
 
Ṣé ìró àwọn tó ṣíwájú yín kò tí ì dé ba yín ni? Ìjọ (Ànábì) Nūh, ìjọ ‘Ād, ìjọ Thamūd àti àwọn tó wá lẹ́yìn wọn; kò sí ẹni tí ó mọ̀ wọ́n àfi Allāhu. Àwọn Òjíṣẹ́ wọn mú àwọn ẹ̀rí tó yanjú wá bá wọn. Nígbà náà, wọ́n dá ọwọ́ wọn padà sí ẹnu wọn, wọ́n sì wí pé: "Dájúdájú àwa ṣàì gbàgbọ́ nínú n̄ǹkan tí wọ́n fi ran yín níṣẹ́. Àti pé dájúdájú àwa wà nínú iyèméjì tó gbópọn nípa ohun tí ẹ̀ ń pè wá sí."

Ayah  14:10  الأية
    +/- -/+  
قَالَتْ رُسُلُهُمْ أَفِي اللهِ شَكٌّ فَاطِرِ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ يَدْعُوكُمْ لِيَغْفِرَ لَكُم مِّن ذُنُوبِكُمْ وَيُؤَخِّرَكُمْ إِلَىٰ أَجَلٍ مُّسَمًّى ۚ قَالُوا إِنْ أَنتُمْ إِلَّا بَشَرٌ مِّثْلُنَا تُرِيدُونَ أَن تَصُدُّونَا عَمَّا كَانَ يَعْبُدُ آبَاؤُنَا فَأْتُونَا بِسُلْطَانٍ مُّبِينٍ
Yoruba
 
Àwọn Òjíṣẹ́ wọn sọ pé: "Ṣé iyèméjì kan ń bẹ níbi (bíbẹ) Allāhu, Olùpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀? Ó ń pè yín nítorí kí Ó lè forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jìn yín àti nítorí kí Ó lè lọ yín lára di gbèdéke àkókò kan." Wọ́n wí pé: "Ẹ̀yin kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe abara bí irú wa. Ẹ̀yin sì fẹ́ ṣẹ́ wa lórí kúrò níbi n̄ǹkan tí àwọn bàbá wa ń jọ́sìn fún. Nítorí náà, ẹ fún wa ní ẹ̀rí pọ́nńbélé."

Ayah  14:11  الأية
    +/- -/+  
قَالَتْ لَهُمْ رُسُلُهُمْ إِن نَّحْنُ إِلَّا بَشَرٌ مِّثْلُكُمْ وَلَٰكِنَّ اللهَ يَمُنُّ عَلَىٰ مَن يَشَاءُ مِنْ عِبَادِهِ ۖ وَمَا كَانَ لَنَا أَن نَّأْتِيَكُم بِسُلْطَانٍ إِلَّا بِإِذْنِ اللهِ ۚ وَعَلَى اللهِ فَلْيَتَوَكَّلِ الْمُؤْمِنُونَ
Yoruba
 
Àwọn Òjíṣẹ́ wọn sọ fún wọn pé: "Àwa kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe abara bí irú yín. Ṣùgbọ́n Allāhu ń ṣoore fún ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Kò sì lẹ́tọ̀ọ́ fún wa láti fún yín ní ẹ̀rí kan àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Àti pé, Allāhu ni kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbáralé.

Ayah  14:12  الأية
    +/- -/+  
وَمَا لَنَا أَلَّا نَتَوَكَّلَ عَلَى اللهِ وَقَدْ هَدَانَا سُبُلَنَا ۚ وَلَنَصْبِرَنَّ عَلَىٰ مَا آذَيْتُمُونَا ۚ وَعَلَى اللهِ فَلْيَتَوَكَّلِ الْمُتَوَكِّلُونَ
Yoruba
 
Kí ni ó máa ṣe wá tí a ò níí gbáralé Allāhu, Ó kúkú ti fi àwọn ọ̀nà wa mọ̀ wá. Dájúdájú a máa ṣe sùúrù lórí ohun tí ẹ bá fi kó ìnira bá wa. Allāhu sì ni kí àwọn olùgbáralé gbáralé."

Ayah  14:13  الأية
    +/- -/+  
وَقَالَ الَّذِينَ كَفَرُوا لِرُسُلِهِمْ لَنُخْرِجَنَّكُم مِّنْ أَرْضِنَا أَوْ لَتَعُودُنَّ فِي مِلَّتِنَا ۖ فَأَوْحَىٰ إِلَيْهِمْ رَبُّهُمْ لَنُهْلِكَنَّ الظَّالِمِينَ
Yoruba
 
Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ wí fún àwọn Òjíṣẹ́ wọn pé: "Dájúdájú àwa yóò le yín jáde kúrò lórí ilẹ̀ wa tàbí kí ẹ kúkú padà sínú ẹ̀sìn wa." Nígbà náà, Olúwa wọn fi ìmísí ránṣẹ́ sí wọn pé: "Dájúdájú A máa pa àwọn alábòsí run.

Ayah  14:14  الأية
    +/- -/+  
وَلَنُسْكِنَنَّكُمُ الْأَرْضَ مِن بَعْدِهِمْ ۚ ذَٰلِكَ لِمَنْ خَافَ مَقَامِي وَخَافَ وَعِيدِ
Yoruba
 
Dájúdájú A sì máa fún yín ní ibùgbé lórí ilẹ̀ lẹ́yìn wọn. " Ìyẹn wà fún ẹni tí ó bá páyà ìdúró (níwájú) Mi, tí ó tún páyà ìlérí Mi.

Ayah  14:15  الأية
    +/- -/+  
وَاسْتَفْتَحُوا وَخَابَ كُلُّ جَبَّارٍ عَنِيدٍ
Yoruba
 
Wọ́n sì tọrọ àrànṣe (Allāhu lórí ìjọ wọn). Gbogbo aláfojúdi, olóríkunkun sì parun.

Ayah  14:16  الأية
    +/- -/+  
مِّن وَرَائِهِ جَهَنَّمُ وَيُسْقَىٰ مِن مَّاءٍ صَدِيدٍ
Yoruba
 
Iná Jahanamọ ń bẹ lẹ́yìn (ìparun) rẹ̀; A ó sì máa fún un ní omi àwọyúnwẹ̀jẹ̀ mu.

Ayah  14:17  الأية
    +/- -/+  
يَتَجَرَّعُهُ وَلَا يَكَادُ يُسِيغُهُ وَيَأْتِيهِ الْمَوْتُ مِن كُلِّ مَكَانٍ وَمَا هُوَ بِمَيِّتٍ ۖ وَمِن وَرَائِهِ عَذَابٌ غَلِيظٌ
Yoruba
 
Ó ma máa mu ún díẹ̀díẹ̀, kò sì níí fẹ́ẹ̀ lè gbé e mì. (Ìnira) ikú yó sì yọ sí i ní gbogbo àyè, síbẹ̀ kò níí kú. Ìyà tó nípọn tún wà fún un lẹ́yìn rẹ̀.

Ayah  14:18  الأية
    +/- -/+  
مَّثَلُ الَّذِينَ كَفَرُوا بِرَبِّهِمْ ۖ أَعْمَالُهُمْ كَرَمَادٍ اشْتَدَّتْ بِهِ الرِّيحُ فِي يَوْمٍ عَاصِفٍ ۖ لَّا يَقْدِرُونَ مِمَّا كَسَبُوا عَلَىٰ شَيْءٍ ۚ ذَٰلِكَ هُوَ الضَّلَالُ الْبَعِيدُ
Yoruba
 
Àfiwé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú Olúwa wọn: àwọn iṣẹ́ wọn dà bí eérú tí atẹ́gùn fẹ́ dànù pátápátá ní ọjọ́ ìjì atẹ́gùn. Wọn kò ní agbára kan lórí ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Ìyẹn ni ìṣìnà tó jìnnà.

Ayah  14:19  الأية
    +/- -/+  
أَلَمْ تَرَ أَنَّ اللهَ خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ بِالْحَقِّ ۚ إِن يَشَأْ يُذْهِبْكُمْ وَيَأْتِ بِخَلْقٍ جَدِيدٍ
Yoruba
 
Ṣé o kò wòye pé dájúdájú Allāhu l'Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo? Tí Ó bá fẹ́, Ó máa ko yín kúrò. Ó sì máa mú ẹ̀dá titun wá.

Ayah  14:20  الأية
    +/- -/+  
وَمَا ذَٰلِكَ عَلَى اللهِ بِعَزِيزٍ
Yoruba
 
Ìyẹn kò sì lè dá Allāhu lágara.

Ayah  14:21  الأية
    +/- -/+  
وَبَرَزُوا لِلَّهِ جَمِيعًا فَقَالَ الضُّعَفَاءُ لِلَّذِينَ اسْتَكْبَرُوا إِنَّا كُنَّا لَكُمْ تَبَعًا فَهَلْ أَنتُم مُّغْنُونَ عَنَّا مِنْ عَذَابِ اللهِ مِن شَيْءٍ ۚ قَالُوا لَوْ هَدَانَا اللهُ لَهَدَيْنَاكُمْ ۖ سَوَاءٌ عَلَيْنَا أَجَزِعْنَا أَمْ صَبَرْنَا مَا لَنَا مِن مَّحِيصٍ
Yoruba
 
Gbogbo ẹ̀dá sì máa jáde sọ́dọ̀ Allāhu (lọ́jọ́ Àjíǹde). Nígbà náà, àwọn aláìlágbára yóò wí fún àwọn tó ṣègbéraga pé: "Dájúdájú àwa jẹ́ ọmọlẹ́yìn fún yín, ǹjẹ́ ẹ̀yin lè gbé n̄ǹkan kan kúrò fún wa nínú ìyà Allāhu?" Wọn yóò wí pé: "Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu tọ́ wa sọ́nà ni, àwa ìbá tọ yín sọ́nà. Bákan náà sì ni fún wa, yálà a káyà sókè tàbí a ṣàtẹ̀mọ́ra (ìyà); kò sí ibùsásí kan fún wa."

Ayah  14:22  الأية
    +/- -/+  
وَقَالَ الشَّيْطَانُ لَمَّا قُضِيَ الْأَمْرُ إِنَّ اللهَ وَعَدَكُمْ وَعْدَ الْحَقِّ وَوَعَدتُّكُمْ فَأَخْلَفْتُكُمْ ۖ وَمَا كَانَ لِيَ عَلَيْكُم مِّن سُلْطَانٍ إِلَّا أَن دَعَوْتُكُمْ فَاسْتَجَبْتُمْ لِي ۖ فَلَا تَلُومُونِي وَلُومُوا أَنفُسَكُم ۖ مَّا أَنَا بِمُصْرِخِكُمْ وَمَا أَنتُم بِمُصْرِخِيَّ ۖ إِنِّي كَفَرْتُ بِمَا أَشْرَكْتُمُونِ مِن قَبْلُ ۗ إِنَّ الظَّالِمِينَ لَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ
Yoruba
 
Èṣù yó sì wí nígbà tí A bá ṣèdájọ́ (ẹ̀dá) tán, pé: "Dájúdájú Allāhu ṣe àdéhùn fún yín ní àdéhùn òdodo. Èmi náà ṣe àdéhùn fún yín. Mo sì yapa àdéhùn tí mo ṣe fún yín. Èmi kò sì ní agbára kan lórí yín bí kò ṣe pé mo pè yín ẹ sì jẹ́pè mi. Nítorí náà, ẹ má ṣe bú mi; ara yín ni kí ẹ bú. Èmi kò lè gbà yín là (nínú ìyà), Ẹ̀yin náà kò sì lè gbà mí là (nínú ìyà). Dájúdájú èmi ti lòdì sí ohun tí ẹ fi sọ mí di akẹgbẹ́ Allāhu ṣíwájú." Dájúdájú àwọn alábòsí, ìyà ẹlẹ́ta-eléro wà fún wọn.

Ayah  14:23  الأية
    +/- -/+  
وَأُدْخِلَ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِن تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا بِإِذْنِ رَبِّهِمْ ۖ تَحِيَّتُهُمْ فِيهَا سَلَامٌ
Yoruba
 
Wọ́n sì máa mú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe àwọn iṣẹ́ rere wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ pẹ̀lú ìyọ̀nda Olúwa wọn. Ìkíni wọn nínú rẹ̀ ni ‘àlàáfíà'.

Ayah  14:24  الأية
    +/- -/+  
أَلَمْ تَرَ كَيْفَ ضَرَبَ اللهُ مَثَلًا كَلِمَةً طَيِّبَةً كَشَجَرَةٍ طَيِّبَةٍ أَصْلُهَا ثَابِتٌ وَفَرْعُهَا فِي السَّمَاءِ
Yoruba
 
Ṣé o kò wòye sí bí Allāhu ṣe ṣàkàwé ọ̀rọ̀ dáadáa pẹ̀lú igi dáadáa, tí gbòǹgbò rẹ̀ fi ìdí múlẹ̀ ṣinṣin, tí ẹ̀ka rẹ̀ sì wà nínú sánmọ̀,

Ayah  14:25  الأية
    +/- -/+  
تُؤْتِي أُكُلَهَا كُلَّ حِينٍ بِإِذْنِ رَبِّهَا ۗ وَيَضْرِبُ اللهُ الْأَمْثَالَ لِلنَّاسِ لَعَلَّهُمْ يَتَذَكَّرُونَ
Yoruba
 
Tó sì ń so èso rẹ̀ ní gbogbo ìgbà pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Olúwa rẹ̀? Allāhu ń fún àwọn ènìyàn ní àwọn àkàwé nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí.

Ayah  14:26  الأية
    +/- -/+  
وَمَثَلُ كَلِمَةٍ خَبِيثَةٍ كَشَجَرَةٍ خَبِيثَةٍ اجْتُثَّتْ مِن فَوْقِ الْأَرْضِ مَا لَهَا مِن قَرَارٍ
Yoruba
 
Àkàwé ọ̀rọ̀ tí kò dára sì dà bí igi tí kò dára, tí wọ́n fà tu lókè ilẹ̀, tí kò rí ìdí fi jókòó lórí ilẹ̀.

Ayah  14:27  الأية
    +/- -/+  
يُثَبِّتُ اللهُ الَّذِينَ آمَنُوا بِالْقَوْلِ الثَّابِتِ فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَفِي الْآخِرَةِ ۖ وَيُضِلُّ اللهُ الظَّالِمِينَ ۚ وَيَفْعَلُ اللهُ مَا يَشَاءُ
Yoruba
 
Allāhu yóò máa fi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo rinlẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tó rinlẹ̀ nínú ìṣẹ̀mí ayé àti ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Ó sì máa ṣi àwọn alábòsí lọ́nà. Àti pé Allāhu ń ṣe ohun tí Ó bá fẹ́.

Ayah  14:28  الأية
    +/- -/+  
أَلَمْ تَرَ إِلَى الَّذِينَ بَدَّلُوا نِعْمَتَ اللهِ كُفْرًا وَأَحَلُّوا قَوْمَهُمْ دَارَ الْبَوَارِ
Yoruba
 
Ṣé o kò wòye sí àwọn tó yí ìdẹ̀ra Allāhu padà sí àìgbàgbọ́, wọ́n sì mú ìjọ wọn gúnlẹ̀ sí ilé ìparun?

Ayah  14:29  الأية
    +/- -/+  
جَهَنَّمَ يَصْلَوْنَهَا ۖ وَبِئْسَ الْقَرَارُ
Yoruba
 
Iná Jahanamọ ni wọn yóò gúnlẹ̀ sí; ibùgbé náà sì burú.

Ayah  14:30  الأية
    +/- -/+  
وَجَعَلُوا لِلَّهِ أَندَادًا لِّيُضِلُّوا عَن سَبِيلِهِ ۗ قُلْ تَمَتَّعُوا فَإِنَّ مَصِيرَكُمْ إِلَى النَّارِ
Yoruba
 
Wọ́n sọ (àwọn kan di) akẹgbẹ́ fún Allāhu nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò nínú ojú-ọ̀nà (ẹ̀sìn) Rẹ̀. Sọ pé: "Ẹ máa gbádùn ǹsó, nítorí pé dájúdájú inú Iná ni ẹ máa gúnlẹ̀ sí."

Ayah  14:31  الأية
    +/- -/+  
قُل لِّعِبَادِيَ الَّذِينَ آمَنُوا يُقِيمُوا الصَّلَاةَ وَيُنفِقُوا مِمَّا رَزَقْنَاهُمْ سِرًّا وَعَلَانِيَةً مِّن قَبْلِ أَن يَأْتِيَ يَوْمٌ لَّا بَيْعٌ فِيهِ وَلَا خِلَالٌ
Yoruba
 
Sọ fún àwọn ẹrúsìn Mi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo pé, kí wọ́n kírun, kí wọ́n sì ná nínú ohun tí A pèsè fún wọn ní ìkọ̀kọ̀ àti ní gban̄gba ṣíwájú kí ọjọ́ kan tó dé, tí kò níí sí títà-rírà kan àti yíyan ọ̀rẹ́ kan nínú rẹ̀.

Ayah  14:32  الأية
    +/- -/+  
اللهُ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَأَنزَلَ مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَأَخْرَجَ بِهِ مِنَ الثَّمَرَاتِ رِزْقًا لَّكُمْ ۖ وَسَخَّرَ لَكُمُ الْفُلْكَ لِتَجْرِيَ فِي الْبَحْرِ بِأَمْرِهِ ۖ وَسَخَّرَ لَكُمُ الْأَنْهَارَ
Yoruba
 
Allāhu ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. Ó sì fi ń mú àwọn èso jáde; (ó jẹ́) arísìkí fún yín. Ó sì rọ ọkọ̀ ojú-omi fún yín kí ó lè rìn lójú omi pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀. Ó tún rọ àwọn odò fún yín.

Ayah  14:33  الأية
    +/- -/+  
وَسَخَّرَ لَكُمُ الشَّمْسَ وَالْقَمَرَ دَائِبَيْنِ ۖ وَسَخَّرَ لَكُمُ اللَّيْلَ وَالنَّهَارَ
Yoruba
 
Ó rọ òòrùn àti òṣùpá fún yín, tí méjèèjì ń rìn láì sinmi. Ó tún rọ òru àti ọ̀sán fún yín.

Ayah  14:34  الأية
    +/- -/+  
وَآتَاكُم مِّن كُلِّ مَا سَأَلْتُمُوهُ ۚ وَإِن تَعُدُّوا نِعْمَتَ اللهِ لَا تُحْصُوهَا ۗ إِنَّ الْإِنسَانَ لَظَلُومٌ كَفَّارٌ
Yoruba
 
Àti pé Ó ń fún yín nínú gbogbo n̄ǹkan tí ẹ tọrọ lọ́dọ̀ Rẹ̀. Tí ẹ bá ṣe òǹkà ìdẹ̀ra Allāhu, ẹ kò lè kà á tán. Dájúdájú ènìyàn ni alábòsí aláìmoore.

Ayah  14:35  الأية
    +/- -/+  
وَإِذْ قَالَ إِبْرَاهِيمُ رَبِّ اجْعَلْ هَٰذَا الْبَلَدَ آمِنًا وَاجْنُبْنِي وَبَنِيَّ أَن نَّعْبُدَ الْأَصْنَامَ
Yoruba
 
(Rántí) nígbà tí (Ànábì) 'Ibrọ̄hīm sọ pé: "Olúwa mi, ṣe ìlú yìí ní ìlú ìfàyàbalẹ̀. Kí O sì mú èmi àti àwọn ọmọ mi jìnnà sí jíjọ́sìn fún àwọn òrìṣà.

Ayah  14:36  الأية
    +/- -/+  
رَبِّ إِنَّهُنَّ أَضْلَلْنَ كَثِيرًا مِّنَ النَّاسِ ۖ فَمَن تَبِعَنِي فَإِنَّهُ مِنِّي ۖ وَمَنْ عَصَانِي فَإِنَّكَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ
Yoruba
 
Olúwa mi, dájúdájú àwọn òrìṣà ti kó ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn ènìyàn ṣìnà. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé mi, dájúdájú òun ni ẹni mi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì yapa mi, dájúdájú Ìwọ ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́.

Ayah  14:37  الأية
    +/- -/+  
رَّبَّنَا إِنِّي أَسْكَنتُ مِن ذُرِّيَّتِي بِوَادٍ غَيْرِ ذِي زَرْعٍ عِندَ بَيْتِكَ الْمُحَرَّمِ رَبَّنَا لِيُقِيمُوا الصَّلَاةَ فَاجْعَلْ أَفْئِدَةً مِّنَ النَّاسِ تَهْوِي إِلَيْهِمْ وَارْزُقْهُم مِّنَ الثَّمَرَاتِ لَعَلَّهُمْ يَشْكُرُونَ
Yoruba
 
Olúwa wa, dájúdájú èmi wá ibùgbé fún àrọ́mọdọ́mọ mi sí ilẹ̀ àfonífojì, ilẹ̀ tí kò ní èso, nítòsí Ilé Abọ̀wọ̀ Rẹ. Olúwa wa, nítorí kí wọ́n lè kírun ni. Nítorí náà, jẹ́ kí ọkàn àwọn ènìyàn fà sọ́dọ̀ wọn. Kí O sì pèsè àwọn èso fún wọn nítorí kí wọ́n lè dúpẹ́ (fún Ọ).

Ayah  14:38  الأية
    +/- -/+  
رَبَّنَا إِنَّكَ تَعْلَمُ مَا نُخْفِي وَمَا نُعْلِنُ ۗ وَمَا يَخْفَىٰ عَلَى اللهِ مِن شَيْءٍ فِي الْأَرْضِ وَلَا فِي السَّمَاءِ
Yoruba
 
Olúwa wa, dájúdájú Ìwọ l'O mọ ohun tí à ń fi pamọ́ àti ohun tí à ń ṣe àfihàn rẹ̀. Kò sì sí kiní kan nínú ilẹ̀ àti nínú sánmọ̀ tó pamọ́ fún Allāhu.

Ayah  14:39  الأية
    +/- -/+  
الْحَمْدُ لِلَّهِ الَّذِي وَهَبَ لِي عَلَى الْكِبَرِ إِسْمَاعِيلَ وَإِسْحَاقَ ۚ إِنَّ رَبِّي لَسَمِيعُ الدُّعَاءِ
Yoruba
 
Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó fún mi ní 'Ismọ̄‘īl àti 'Ishāƙ nígbà tí mo ti darúgbó. Dájúdájú, Olúwa mi ni Olùgbọ́ àdúà.

Ayah  14:40  الأية
    +/- -/+  
رَبِّ اجْعَلْنِي مُقِيمَ الصَّلَاةِ وَمِن ذُرِّيَّتِي ۚ رَبَّنَا وَتَقَبَّلْ دُعَاءِ
Yoruba
 
Olúwa mi, ṣe èmi àti nínú àrọ́mọdọ́mọ mi ní olùkírun. Olúwa wa, kí O sì gba àdúà mi.

Ayah  14:41  الأية
    +/- -/+  
رَبَّنَا اغْفِرْ لِي وَلِوَالِدَيَّ وَلِلْمُؤْمِنِينَ يَوْمَ يَقُومُ الْحِسَابُ
Yoruba
 
Olúwa mi, ṣàforíjìn fún èmi àti àwọn òbí mi méjèèjì àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ọjọ́ tí ìṣírò-iṣẹ́ yóò ṣẹlẹ̀."

Ayah  14:42  الأية
    +/- -/+  
وَلَا تَحْسَبَنَّ اللهَ غَافِلًا عَمَّا يَعْمَلُ الظَّالِمُونَ ۚ إِنَّمَا يُؤَخِّرُهُمْ لِيَوْمٍ تَشْخَصُ فِيهِ الْأَبْصَارُ
Yoruba
 
Má ṣe lérò pé Allāhu gbàgbé n̄ǹkan tí àwọn alábòsí ń ṣe níṣẹ́. Ó kàn ń lọ́ wọn lára dí ọjọ́ kan tí àwọn ojú yóò yọ síta ràngàndàn.

Ayah  14:43  الأية
    +/- -/+  
مُهْطِعِينَ مُقْنِعِي رُءُوسِهِمْ لَا يَرْتَدُّ إِلَيْهِمْ طَرْفُهُمْ ۖ وَأَفْئِدَتُهُمْ هَوَاءٌ
Yoruba
 
Wọn yóò má sáré (lọ síbi àkójọ fún ìṣírò-iṣẹ́), wọn yóò gbé orí wọn sókè, ìpéǹpéjú wọn kò sì níí padà sọ́dọ̀ wọn, àwọn ọkàn wọn yó sì pa sófo pátápátá (fún ìbẹ̀rù).

Ayah  14:44  الأية
    +/- -/+  
وَأَنذِرِ النَّاسَ يَوْمَ يَأْتِيهِمُ الْعَذَابُ فَيَقُولُ الَّذِينَ ظَلَمُوا رَبَّنَا أَخِّرْنَا إِلَىٰ أَجَلٍ قَرِيبٍ نُّجِبْ دَعْوَتَكَ وَنَتَّبِعِ الرُّسُلَ ۗ أَوَلَمْ تَكُونُوا أَقْسَمْتُم مِّن قَبْلُ مَا لَكُم مِّن زَوَالٍ
Yoruba
 
Kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn nípa ọjọ́ tí ìyà yóò dé bá wọn, àwọn tó ṣàbòsí yó sì wí pé: "Olúwa wa, lọ́ wa lára fún àsìkò díẹ̀ sí i, a máa jẹ́pè Rẹ, a sì máa tẹ̀lé àwọn Òjíṣẹ́." Ṣé ẹ̀yin kò ti búra ṣíwájú pé ẹ̀yin kò níí kúrò nílé ayé?

Ayah  14:45  الأية
    +/- -/+  
وَسَكَنتُمْ فِي مَسَاكِنِ الَّذِينَ ظَلَمُوا أَنفُسَهُمْ وَتَبَيَّنَ لَكُمْ كَيْفَ فَعَلْنَا بِهِمْ وَضَرَبْنَا لَكُمُ الْأَمْثَالَ
Yoruba
 
Ẹ sì gbé nínú ibùgbé àwọn tó ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn. Ó sì hàn si yín bí A ti ṣe pẹ̀lú wọn. A tún fún yín ni àwọn àpẹ̀ẹrẹ (gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí àti àlàyé ọ̀rọ̀).

Ayah  14:46  الأية
    +/- -/+  
وَقَدْ مَكَرُوا مَكْرَهُمْ وَعِندَ اللهِ مَكْرُهُمْ وَإِن كَانَ مَكْرُهُمْ لِتَزُولَ مِنْهُ الْجِبَالُ
Yoruba
 
Wọ́n kúkú ti dá ète wọn, ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni ète wọn wà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé (pẹ̀lú) ète wọn àpáta fẹ́ẹ̀ lè yẹ̀ lulẹ̀.

Ayah  14:47  الأية
    +/- -/+  
فَلَا تَحْسَبَنَّ اللهَ مُخْلِفَ وَعْدِهِ رُسُلَهُ ۗ إِنَّ اللهَ عَزِيزٌ ذُو انتِقَامٍ
Yoruba
 
Nítorí náà, má ṣe lérò pé Allāhu yóò yapa àdéhùn Rẹ̀ tí Ó ṣe fún àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Olùgbẹ̀san.

Ayah  14:48  الأية
    +/- -/+  
يَوْمَ تُبَدَّلُ الْأَرْضُ غَيْرَ الْأَرْضِ وَالسَّمَاوَاتُ ۖ وَبَرَزُوا لِلَّهِ الْوَاحِدِ الْقَهَّارِ
Yoruba
 
Ní ọjọ́ tí A máa yí ilẹ̀ ayé padà sì n̄ǹkan mìíràn. (A máa yí) àwọn sánmọ̀ náà (padà. Àwọn ẹ̀dá) sì máa jáde (síwájú) Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí.

Ayah  14:49  الأية
    +/- -/+  
وَتَرَى الْمُجْرِمِينَ يَوْمَئِذٍ مُّقَرَّنِينَ فِي الْأَصْفَادِ
Yoruba
 
O sì máa rí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ọjọ́ yẹn, tí wọn yóò so wọ́n papọ̀ mọ́ra wọn sínú sẹ́kẹ́sẹkẹ̀.

Ayah  14:50  الأية
    +/- -/+  
سَرَابِيلُهُم مِّن قَطِرَانٍ وَتَغْشَىٰ وُجُوهَهُمُ النَّارُ
Yoruba
 
Oje gbígbóná ni àwọn èwù wọn. Iná yó sì bo ojú wọn mọ́lẹ̀ bámúbámú

Ayah  14:51  الأية
    +/- -/+  
لِيَجْزِيَ اللهُ كُلَّ نَفْسٍ مَّا كَسَبَتْ ۚ إِنَّ اللهَ سَرِيعُ الْحِسَابِ
Yoruba
 
Nítorí kí Allāhu lè san ẹ̀san ohun tí ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ṣe níṣẹ́ fún un. Dájúdájú Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́.

Ayah  14:52  الأية
    +/- -/+  
هَٰذَا بَلَاغٌ لِّلنَّاسِ وَلِيُنذَرُوا بِهِ وَلِيَعْلَمُوا أَنَّمَا هُوَ إِلَٰهٌ وَاحِدٌ وَلِيَذَّكَّرَ أُولُو الْأَلْبَابِ
Yoruba
 
Èyí ni ìkéde (ẹ̀sìn) fún àwọn ènìyàn nítorí kí wọ́n lè fi ṣe ìkìlọ̀, kí wọ́n sì lè mọ̀ pé (Allāhu) Òun nìkan ni Ọlọ́hun Ọkan ṣoṣo tí wọ́n gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àti nítorí kí àwọn onílàákàyè lè lo ìrántí.
 


© EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us