Prev  

15. Surah Al-Hijr سورة الحجر

  Next  




Ayah  15:1  الأية
    +/- -/+  
بِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
الر ۚ تِلْكَ آيَاتُ الْكِتَابِ وَقُرْآنٍ مُّبِينٍ
Yoruba
 
'Alif lām rọ̄. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.) Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà náà àti (àwọn āyah) al-Ƙur'ān tó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá.

Ayah  15:2  الأية
    +/- -/+  
رُّبَمَا يَوَدُّ الَّذِينَ كَفَرُوا لَوْ كَانُوا مُسْلِمِينَ
Yoruba
 
Ó ṣeé ṣe kí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nífẹ̀ẹ́ sí pé àwọn ìbá sì ti jẹ́ mùsùlùmí (nílé ayé).

Ayah  15:3  الأية
    +/- -/+  
ذَرْهُمْ يَأْكُلُوا وَيَتَمَتَّعُوا وَيُلْهِهِمُ الْأَمَلُ ۖ فَسَوْفَ يَعْلَمُونَ
Yoruba
 
Fi wọ́n sílẹ̀, kí wọ́n jẹ, kí wọ́n gbádùn, kí ìrètí (ẹ̀mí gígùn) kó àìrójú ráàyè bá wọn (láti ṣẹ̀sìn); láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀.

Ayah  15:4  الأية
    +/- -/+  
وَمَا أَهْلَكْنَا مِن قَرْيَةٍ إِلَّا وَلَهَا كِتَابٌ مَّعْلُومٌ
Yoruba
 
A kò pa ìlú kan run rí àfi kí ó ní àkọsílẹ̀ tí A ti mọ̀.

Ayah  15:5  الأية
    +/- -/+  
مَّا تَسْبِقُ مِنْ أُمَّةٍ أَجَلَهَا وَمَا يَسْتَأْخِرُونَ
Yoruba
 
Kò sí ìjọ kan (tí ó parun) ṣíwájú àkókò rẹ̀ (nínú Laohul-Mahfuuṭḥ); wọn kò sì níí sún un ṣíwájú fún wọn.

Ayah  15:6  الأية
    +/- -/+  
وَقَالُوا يَا أَيُّهَا الَّذِي نُزِّلَ عَلَيْهِ الذِّكْرُ إِنَّكَ لَمَجْنُونٌ
Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "Ìwọ tí wọ́n sọ al-Ƙur'ān kalẹ̀ fún, dájúdájú wèrè ni ọ́.

Ayah  15:7  الأية
    +/- -/+  
لَّوْ مَا تَأْتِينَا بِالْمَلَائِكَةِ إِن كُنتَ مِنَ الصَّادِقِينَ
Yoruba
 
Kí ni kò jẹ́ kí ìwọ mú àwọn mọlāika wá bá wa, tí ìwọ bá wà nínú àwọn olódodo?"

Ayah  15:8  الأية
    +/- -/+  
مَا نُنَزِّلُ الْمَلَائِكَةَ إِلَّا بِالْحَقِّ وَمَا كَانُوا إِذًا مُّنظَرِينَ
Yoruba
 
A kò níí sọ mọlāika kalẹ̀ bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo. Wọn kò sì níí lọ́ wọn lára mọ́ nígbà náà (tí àwọn mọlāika bá sọ̀kalẹ̀).

Ayah  15:9  الأية
    +/- -/+  
إِنَّا نَحْنُ نَزَّلْنَا الذِّكْرَ وَإِنَّا لَهُ لَحَافِظُونَ
Yoruba
 
Dájúdájú Àwa l'A sọ Tírà Ìrántí kalẹ̀ (ìyẹn al-Ƙur'ān). Dájúdájú Àwa sì ni Olùṣọ́ rẹ̀.

Ayah  15:10  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا مِن قَبْلِكَ فِي شِيَعِ الْأَوَّلِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú ṣíwájú rẹ A ti rán (àwọn Òjíṣẹ́) níṣẹ́ sí àwọn ìjọ, àwọn ẹni àkọ́kọ́.

Ayah  15:11  الأية
    +/- -/+  
وَمَا يَأْتِيهِم مِّن رَّسُولٍ إِلَّا كَانُوا بِهِ يَسْتَهْزِئُونَ
Yoruba
 
Òjíṣẹ́ kan kò sì níí dé bá wọn àfi kí wọ́n máa fi ṣe yẹ̀yẹ́.

Ayah  15:12  الأية
    +/- -/+  
كَذَٰلِكَ نَسْلُكُهُ فِي قُلُوبِ الْمُجْرِمِينَ
Yoruba
 
Báyẹn náà ni A ṣe máa fi (àìsàn pípe al-Ƙur'ān nírọ́) sínú ọkàn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ (nínú ìjọ tìrẹ náà).

Ayah  15:13  الأية
    +/- -/+  
لَا يُؤْمِنُونَ بِهِ ۖ وَقَدْ خَلَتْ سُنَّةُ الْأَوَّلِينَ
Yoruba
 
Wọn kò níí gbà á gbọ́; ìṣe (Allāhu lórí) àwọn ẹni àkọ́kọ́ kúkú ti ré kọjá.

Ayah  15:14  الأية
    +/- -/+  
وَلَوْ فَتَحْنَا عَلَيْهِم بَابًا مِّنَ السَّمَاءِ فَظَلُّوا فِيهِ يَعْرُجُونَ
Yoruba
 
Tí ó bá jẹ́ pé A ṣí ìlẹ̀kùn kan sílẹ̀ fún wọn láti inú sánmọ̀, tí wọn kò sì yé gbabẹ̀ gùnkè lọ (sínú sánmọ̀),

Ayah  15:15  الأية
    +/- -/+  
لَقَالُوا إِنَّمَا سُكِّرَتْ أَبْصَارُنَا بَلْ نَحْنُ قَوْمٌ مَّسْحُورُونَ
Yoruba
 
Dájúdájú wọ́n á wí pé: "Wọ́n kan fi n̄ǹkan bo ojú wa ni. Rárá, ènìyàn tí wọ́n ń dan ni àwa sẹ́."

Ayah  15:16  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدْ جَعَلْنَا فِي السَّمَاءِ بُرُوجًا وَزَيَّنَّاهَا لِلنَّاظِرِينَ
Yoruba
 
A kúkú fi àwọn ibùsọ̀ ìràwọ̀ sínú sánmọ̀ (ayé). A ṣe é ní ọ̀ṣọ́ fún àwọn olùwòran.

Ayah  15:17  الأية
    +/- -/+  
وَحَفِظْنَاهَا مِن كُلِّ شَيْطَانٍ رَّجِيمٍ
Yoruba
 
A sì ṣọ́ ọ kúrò lọ́dọ̀ gbogbo èṣù, ẹni ẹ̀kọ̀.

Ayah  15:18  الأية
    +/- -/+  
إِلَّا مَنِ اسْتَرَقَ السَّمْعَ فَأَتْبَعَهُ شِهَابٌ مُّبِينٌ
Yoruba
 
Àfi (èṣù) tí ó bá jí ọ̀rọ̀ gbọ́. Nígbà náà sì ni ògúnná pọ́nńbélé yó tẹ̀lé e láti ẹ̀yìn.

Ayah  15:19  الأية
    +/- -/+  
وَالْأَرْضَ مَدَدْنَاهَا وَأَلْقَيْنَا فِيهَا رَوَاسِيَ وَأَنبَتْنَا فِيهَا مِن كُلِّ شَيْءٍ مَّوْزُونٍ
Yoruba
 
Ilẹ̀, A tẹ́ ẹ pẹrẹsẹ. A sì ju àwọn àpáta tó dúró gbagidi sínú rẹ̀. A sì mú gbogbo n̄ǹkan tí ó ní òdíwọ̀n hù jáde láti inú rẹ̀.

Ayah  15:20  الأية
    +/- -/+  
وَجَعَلْنَا لَكُمْ فِيهَا مَعَايِشَ وَمَن لَّسْتُمْ لَهُ بِرَازِقِينَ
Yoruba
 
A ṣe ọ̀nà ìjẹ-ìmu sínú (ilé ayé) fun ẹ̀yin àti àwọn tí ẹ̀yin kò lè pèsè fún.

Ayah  15:21  الأية
    +/- -/+  
وَإِن مِّن شَيْءٍ إِلَّا عِندَنَا خَزَائِنُهُ وَمَا نُنَزِّلُهُ إِلَّا بِقَدَرٍ مَّعْلُومٍ
Yoruba
 
Kò sì sí kiní kan àfi kí ilé-ọrọ̀ rẹ̀ wà lọ́dọ̀ Wa. Àwa kò sì níí sọ̀ ọ́ kalẹ̀ àfi pẹ̀lú òdíwọ̀n tí A ti mọ̀.

Ayah  15:22  الأية
    +/- -/+  
وَأَرْسَلْنَا الرِّيَاحَ لَوَاقِحَ فَأَنزَلْنَا مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَأَسْقَيْنَاكُمُوهُ وَمَا أَنتُمْ لَهُ بِخَازِنِينَ
Yoruba
 
Àti pé A rán àwọn atẹ́gùn láti kó àwọn ẹ̀ṣújò jọ. A sì sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. Nítorí náà, A fún yín mu. Ẹ̀yin sì kọ́ ni ẹ kó omi òjò jọ (sójú sánmọ̀).

Ayah  15:23  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّا لَنَحْنُ نُحْيِي وَنُمِيتُ وَنَحْنُ الْوَارِثُونَ
Yoruba
 
Dájúdájú Àwa, Àwa ń sọ (ẹ̀dá) di alààyè. A sì ń sọ ọ́ di òkú. Àwa sì ni A óò jogún (ẹ̀dá).

Ayah  15:24  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدْ عَلِمْنَا الْمُسْتَقْدِمِينَ مِنكُمْ وَلَقَدْ عَلِمْنَا الْمُسْتَأْخِرِينَ
Yoruba
 
Àti pé dájúdájú A mọ àwọn olùgbawájú nínú yín. Dájúdájú A sì mọ àwọn olùgbẹ̀yìn.

Ayah  15:25  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّ رَبَّكَ هُوَ يَحْشُرُهُمْ ۚ إِنَّهُ حَكِيمٌ عَلِيمٌ
Yoruba
 
Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun l'Ó máa kó wọn jọ. Dájúdájú Òun ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀.

Ayah  15:26  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدْ خَلَقْنَا الْإِنسَانَ مِن صَلْصَالٍ مِّنْ حَمَإٍ مَّسْنُونٍ
Yoruba
 
Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara amọ̀ tó ń dún koko, tó ti pàwọ̀dà.

Ayah  15:27  الأية
    +/- -/+  
وَالْجَانَّ خَلَقْنَاهُ مِن قَبْلُ مِن نَّارِ السَّمُومِ
Yoruba
 
Àti pé àlùjànnú, A ṣẹ̀dá rẹ̀ ṣíwájú (ènìyàn) láti ara iná alátẹ́gùn gbígbóná tí kò ní èéfín.

Ayah  15:28  الأية
    +/- -/+  
وَإِذْ قَالَ رَبُّكَ لِلْمَلَائِكَةِ إِنِّي خَالِقٌ بَشَرًا مِّن صَلْصَالٍ مِّنْ حَمَإٍ مَّسْنُونٍ
Yoruba
 
(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ sọ fún àwọn mọlāika pé: "Dájúdájú Èmi yóò ṣe ẹ̀dá abara kan láti ara amọ̀ tó ń dún koko, tó ti pàwọ̀dà.

Ayah  15:29  الأية
    +/- -/+  
فَإِذَا سَوَّيْتُهُ وَنَفَخْتُ فِيهِ مِن رُّوحِي فَقَعُوا لَهُ سَاجِدِينَ
Yoruba
 
Nígbà tí Mo bá ṣe é tó gún régétán, tí Mo fẹ́ ẹ̀mí sí i (lára) nínú ẹ̀mí Mi (tí Mo dá), nígbà náà ẹ dojú bolẹ̀ fún un ní olùforíkanlẹ̀-kíni."

Ayah  15:30  الأية
    +/- -/+  
فَسَجَدَ الْمَلَائِكَةُ كُلُّهُمْ أَجْمَعُونَ
Yoruba
 
Nítorí náà, àwọn mọlāika, gbogbo wọn pátápátá sì forí kanlẹ̀ kí i.

Ayah  15:31  الأية
    +/- -/+  
إِلَّا إِبْلِيسَ أَبَىٰ أَن يَكُونَ مَعَ السَّاجِدِينَ
Yoruba
 
Àyàfi 'Iblīs. Ó kọ̀ láti wà nínú àwọn olùforíkanlẹ̀-kíni náà.

Ayah  15:32  الأية
    +/- -/+  
قَالَ يَا إِبْلِيسُ مَا لَكَ أَلَّا تَكُونَ مَعَ السَّاجِدِينَ
Yoruba
 
(Allāhu) sọ pé: "'Iblīs, kí ló dí ọ lọ́wọ́ láti wà nínú àwọn olùforíkanlẹ̀-kíni?"

Ayah  15:33  الأية
    +/- -/+  
قَالَ لَمْ أَكُن لِّأَسْجُدَ لِبَشَرٍ خَلَقْتَهُ مِن صَلْصَالٍ مِّنْ حَمَإٍ مَّسْنُونٍ
Yoruba
 
Ó wí pé: "Èmi kò níí forí kanlẹ̀ kí abara kan tí O ṣẹ̀dá rẹ̀ láti ara amọ̀ tó ń dún koko, tó ti pàwọ̀dà."

Ayah  15:34  الأية
    +/- -/+  
قَالَ فَاخْرُجْ مِنْهَا فَإِنَّكَ رَجِيمٌ
Yoruba
 
(Allāhu) sọ pé: "Nítorí náà, jáde kúrò nínú rẹ̀. Dájúdájú, ìwọ ni ẹni-ẹ̀kọ̀.

Ayah  15:35  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّ عَلَيْكَ اللَّعْنَةَ إِلَىٰ يَوْمِ الدِّينِ
Yoruba
 
Àti pé, dájúdájú ègún ń bẹ lórí rẹ títí di Ọjọ́ ẹ̀san."

Ayah  15:36  الأية
    +/- -/+  
قَالَ رَبِّ فَأَنظِرْنِي إِلَىٰ يَوْمِ يُبْعَثُونَ
Yoruba
 
Ó wí pé: "Olúwa mi, lọ́ mi lára títí di Ọjọ́ tí wọ́n máa gbé ẹ̀dá dìde."

Ayah  15:37  الأية
    +/- -/+  
قَالَ فَإِنَّكَ مِنَ الْمُنظَرِينَ
Yoruba
 
(Allāhu) sọ pé: "Dájúdájú ìwọ wà lára àwọn tí A óò lọ́ lára

Ayah  15:38  الأية
    +/- -/+  
إِلَىٰ يَوْمِ الْوَقْتِ الْمَعْلُومِ
Yoruba
 
Títí di ọjọ́ àkókò tí A ti mọ."

Ayah  15:39  الأية
    +/- -/+  
قَالَ رَبِّ بِمَا أَغْوَيْتَنِي لَأُزَيِّنَنَّ لَهُمْ فِي الْأَرْضِ وَلَأُغْوِيَنَّهُمْ أَجْمَعِينَ
Yoruba
 
Ó wí pé: "Olúwa mi, fún wí pé O ti ṣe mí ní ẹni anù, dájúdájú emí yóò ṣe (aburú) ní ọ̀ṣọ́ fún wọn lórí ilẹ̀. Dájúdájú èmi yó sì kó gbogbo wọn sínú anù

Ayah  15:40  الأية
    +/- -/+  
إِلَّا عِبَادَكَ مِنْهُمُ الْمُخْلَصِينَ
Yoruba
 
Àfi àwọn ẹrúsìn Rẹ, àwọn tí O ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo)."

Ayah  15:41  الأية
    +/- -/+  
قَالَ هَٰذَا صِرَاطٌ عَلَيَّ مُسْتَقِيمٌ
Yoruba
 
(Allāhu) sọ pé: "(Ìdúróṣinṣin lójú) ọ̀nà tààrà, Ọwọ́ Mi ni èyí wà."

Ayah  15:42  الأية
    +/- -/+  
إِنَّ عِبَادِي لَيْسَ لَكَ عَلَيْهِمْ سُلْطَانٌ إِلَّا مَنِ اتَّبَعَكَ مِنَ الْغَاوِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú àwọn ẹrúsìn Mi, kò sí agbára kan fún ọ lórí wọn, àyàfi ẹni tí ó bá tẹ̀lé ọ nínú àwọn ẹni anù.

Ayah  15:43  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّ جَهَنَّمَ لَمَوْعِدُهُمْ أَجْمَعِينَ
Yoruba
 
Àti pé dájúdájú iná Jahanamọ ni àdéhùn fún gbogbo wọn.

Ayah  15:44  الأية
    +/- -/+  
لَهَا سَبْعَةُ أَبْوَابٍ لِّكُلِّ بَابٍ مِّنْهُمْ جُزْءٌ مَّقْسُومٌ
Yoruba
 
Àwọn ojú ọ̀nà méje ń bẹ fún (iná). Àtúnpín tún wà fún ojú-ọ̀nà kọ̀ọ̀kan.

Ayah  15:45  الأية
    +/- -/+  
إِنَّ الْمُتَّقِينَ فِي جَنَّاتٍ وَعُيُونٍ
Yoruba
 
Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) máa wà nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra pẹ̀lú àwọn odò (tó ń ṣàn nísàlẹ̀ rẹ̀).

Ayah  15:46  الأية
    +/- -/+  
ادْخُلُوهَا بِسَلَامٍ آمِنِينَ
Yoruba
 
(A máa sọ pé): "Ẹ wọ inú rẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà ní olùfàyàbalẹ̀."

Ayah  15:47  الأية
    +/- -/+  
وَنَزَعْنَا مَا فِي صُدُورِهِم مِّنْ غِلٍّ إِخْوَانًا عَلَىٰ سُرُرٍ مُّتَقَابِلِينَ
Yoruba
 
A sì máa yọ ohun tí ń bẹ nínú ọkàn wọn tó jẹ́ inúnibíni kúrò; (wọn yóò di) ọmọ-ìyá (ara wọn. Wọn yóò wà) lórí ibùsùn, tí wọn yóò kọjú síra wọn.

Ayah  15:48  الأية
    +/- -/+  
لَا يَمَسُّهُمْ فِيهَا نَصَبٌ وَمَا هُم مِّنْهَا بِمُخْرَجِينَ
Yoruba
 
Wàhálà kan kò níí bá wọn nínú rẹ̀. Wọn kò sì níí mú wọn jáde kúrò nínú rẹ̀.

Ayah  15:49  الأية
    +/- -/+  
نَبِّئْ عِبَادِي أَنِّي أَنَا الْغَفُورُ الرَّحِيمُ
Yoruba
 
Fún àwọn ẹrúsìn Mi ní ìró pé dájúdájú Èmi ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

Ayah  15:50  الأية
    +/- -/+  
وَأَنَّ عَذَابِي هُوَ الْعَذَابُ الْأَلِيمُ
Yoruba
 
Àti pé dájúdájú ìyà Mi ni ìyà ẹlẹ́ta-eléro.

Ayah  15:51  الأية
    +/- -/+  
وَنَبِّئْهُمْ عَن ضَيْفِ إِبْرَاهِيمَ
Yoruba
 
Fún wọn ní ìró nípa àlejò (Ànábì) 'Ibrọ̄hīm.

Ayah  15:52  الأية
    +/- -/+  
إِذْ دَخَلُوا عَلَيْهِ فَقَالُوا سَلَامًا قَالَ إِنَّا مِنكُمْ وَجِلُونَ
Yoruba
 
(Rántí) nígbà tí wọ́n wọlé tọ̀ ọ́, wọ́n sì sọ pé: "Àlàáfíà". Ó sọ pé: "Dájúdájú ẹ̀rù yín ń ba àwa."

Ayah  15:53  الأية
    +/- -/+  
قَالُوا لَا تَوْجَلْ إِنَّا نُبَشِّرُكَ بِغُلَامٍ عَلِيمٍ
Yoruba
 
Wọ́n sọ pé: "Má ṣe bẹ̀rù. Dájúdájú àwa yóò fún ọ ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ọmọkùnrin kan tí ó máa ní ìmọ̀."

Ayah  15:54  الأية
    +/- -/+  
قَالَ أَبَشَّرْتُمُونِي عَلَىٰ أَن مَّسَّنِيَ الْكِبَرُ فَبِمَ تُبَشِّرُونَ
Yoruba
 
Ó sọ pé: "Ṣé ẹ̀ ń fún mi ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí ọmọ) nígbà tí ogbó ti dé sí mi? Ìró ìdùnnú wo ni ẹ̀ ń fún mi ná?"

Ayah  15:55  الأية
    +/- -/+  
قَالُوا بَشَّرْنَاكَ بِالْحَقِّ فَلَا تَكُن مِّنَ الْقَانِطِينَ
Yoruba
 
Wọ́n sọ pé: "À ń fún ọ ní ìró ìdùnnú pẹ̀lú òdodo. Nítorí náà, má ṣe wà lára àwọn olùjákànmùná."

Ayah  15:56  الأية
    +/- -/+  
قَالَ وَمَن يَقْنَطُ مِن رَّحْمَةِ رَبِّهِ إِلَّا الضَّالُّونَ
Yoruba
 
Ó sọ pé: "Kò mà sí ẹni tí ó máa jákànmùná nínú ìkẹ́ Olúwa Rẹ̀ bí kò ṣe àwọn olùṣìnà."

Ayah  15:57  الأية
    +/- -/+  
قَالَ فَمَا خَطْبُكُمْ أَيُّهَا الْمُرْسَلُونَ
Yoruba
 
Ó sọ pé: "Kí tún ni ọ̀rọ̀ tí ẹ bá wá, ẹ̀yin Òjíṣẹ́?"

Ayah  15:58  الأية
    +/- -/+  
قَالُوا إِنَّا أُرْسِلْنَا إِلَىٰ قَوْمٍ مُّجْرِمِينَ
Yoruba
 
Wọ́n sọ pé: "Dájúdájú Wọ́n rán wa níṣẹ́ sí ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.

Ayah  15:59  الأية
    +/- -/+  
إِلَّا آلَ لُوطٍ إِنَّا لَمُنَجُّوهُمْ أَجْمَعِينَ
Yoruba
 
Àfi ará ilé (Ànábì) Lūt. Dájúdájú àwa yóò gba wọn là pátápátá.

Ayah  15:60  الأية
    +/- -/+  
إِلَّا امْرَأَتَهُ قَدَّرْنَا ۙ إِنَّهَا لَمِنَ الْغَابِرِينَ
Yoruba
 
Àfi ìyàwó rẹ̀; A ti kọ kádàrá rẹ̀ (pé) dájúdájú ó máa wà nínú àwọn tó máa ṣẹ́kù lẹ́yìn sínú ìparun."

Ayah  15:61  الأية
    +/- -/+  
فَلَمَّا جَاءَ آلَ لُوطٍ الْمُرْسَلُونَ
Yoruba
 
Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ dé ọ̀dọ̀ ará ilé (Ànábì) Lūt,

Ayah  15:62  الأية
    +/- -/+  
قَالَ إِنَّكُمْ قَوْمٌ مُّنكَرُونَ
Yoruba
 
(Ànábì Lūt) sọ pé: "Dájúdájú ẹ̀yin jẹ́ àjòjì ènìyàn."

Ayah  15:63  الأية
    +/- -/+  
قَالُوا بَلْ جِئْنَاكَ بِمَا كَانُوا فِيهِ يَمْتَرُونَ
Yoruba
 
Wọ́n sọ pé: "Rárá, a wá sọ́dọ̀ rẹ nítorí ohun tí wọ́n ń ṣeyèméjì nípa rẹ̀.

Ayah  15:64  الأية
    +/- -/+  
وَأَتَيْنَاكَ بِالْحَقِّ وَإِنَّا لَصَادِقُونَ
Yoruba
 
A mú òdodo wá bá ọ ni. Àti pé dájúdájú olódodo ni àwa.

Ayah  15:65  الأية
    +/- -/+  
فَأَسْرِ بِأَهْلِكَ بِقِطْعٍ مِّنَ اللَّيْلِ وَاتَّبِعْ أَدْبَارَهُمْ وَلَا يَلْتَفِتْ مِنكُمْ أَحَدٌ وَامْضُوا حَيْثُ تُؤْمَرُونَ
Yoruba
 
Nítorí náà, mú ará ilé rẹ jáde ní apá kan òru. Kí o sì tẹ̀lé wọn lẹ́yìn. Ẹnì kan nínú yín kò sì gbọdọ̀ ṣíjú wo ẹ̀yìn wò. Kí ẹ sì lọ sí àyè tí wọ́n ń pa láṣẹ fún yín."

Ayah  15:66  الأية
    +/- -/+  
وَقَضَيْنَا إِلَيْهِ ذَٰلِكَ الْأَمْرَ أَنَّ دَابِرَ هَٰؤُلَاءِ مَقْطُوعٌ مُّصْبِحِينَ
Yoruba
 
A sì jẹ́ kí ìdájọ́ ọ̀rọ̀ yìí hàn sí i pé dájúdájú A máa pa àwọn (ẹlẹ́ṣẹ̀) wọ̀nyí run pátápátá nígbà tí wọ́n bá mọ́júmọ́.

Ayah  15:67  الأية
    +/- -/+  
وَجَاءَ أَهْلُ الْمَدِينَةِ يَسْتَبْشِرُونَ
Yoruba
 
Àwọn ará ìlú náà dé, wọ́n sì ń yọ̀ sẹ̀sẹ̀.

Ayah  15:68  الأية
    +/- -/+  
قَالَ إِنَّ هَٰؤُلَاءِ ضَيْفِي فَلَا تَفْضَحُونِ
Yoruba
 
(Ànábì Lūt) sọ pé: "Dájúdájú àwọn wọ̀nyí ni àlejò mi. Nítorí náà, ẹ má ṣe dójú tì mí.

Ayah  15:69  الأية
    +/- -/+  
وَاتَّقُوا اللهَ وَلَا تُخْزُونِ
Yoruba
 
Kí ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì má ṣe yẹpẹrẹ mi."

Ayah  15:70  الأية
    +/- -/+  
قَالُوا أَوَلَمْ نَنْهَكَ عَنِ الْعَالَمِينَ
Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "Ǹjẹ́ àwa kò ti kọ̀ fún ọ (nípa gbígba àlejò) àwọn ẹ̀dá?"

Ayah  15:71  الأية
    +/- -/+  
قَالَ هَٰؤُلَاءِ بَنَاتِي إِن كُنتُمْ فَاعِلِينَ
Yoruba
 
Ó sọ pé: "Àwọn ọmọbìnrin mi nìwọ̀nyí, tí ẹ bá ní n̄ǹkan tí ẹ fẹ́ (fi wọ́n) ṣe."

Ayah  15:72  الأية
    +/- -/+  
لَعَمْرُكَ إِنَّهُمْ لَفِي سَكْرَتِهِمْ يَعْمَهُونَ
Yoruba
 
(Allāhu sọ pé): "Mo fi ìṣẹ̀mí ìwọ (Ànábì Muhammad) búra; dájúdájú wọ́n kúkú wà nínú ìṣìnà àti àìmọ̀kan wọn, tí wọ́n ń pa rìdàrìdà."

Ayah  15:73  الأية
    +/- -/+  
فَأَخَذَتْهُمُ الصَّيْحَةُ مُشْرِقِينَ
Yoruba
 
Nítorí náà, ohùn igbe mú wọn nígbà tí òòrùn òwúrọ̀ yọ sí wọn.

Ayah  15:74  الأية
    +/- -/+  
فَجَعَلْنَا عَالِيَهَا سَافِلَهَا وَأَمْطَرْنَا عَلَيْهِمْ حِجَارَةً مِّن سِجِّيلٍ
Yoruba
 
A sì sọ òkè ìlú wọn di ìsàlẹ̀ rẹ̀ (ìlú wọ́n dojú bolẹ̀). A tún rọ òjò òkúta amọ̀ (sísun) lé wọn lórí.

Ayah  15:75  الأية
    +/- -/+  
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِّلْمُتَوَسِّمِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún àwọn alárìíwòye.

Ayah  15:76  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّهَا لَبِسَبِيلٍ مُّقِيمٍ
Yoruba
 
Dájúdájú (ìlú náà) kúkú wà lójú ọ̀nà (tí ẹ̀ ń tọ̀ lọ tọ̀ bọ̀).

Ayah  15:77  الأية
    +/- -/+  
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً لِّلْمُؤْمِنِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

Ayah  15:78  الأية
    +/- -/+  
وَإِن كَانَ أَصْحَابُ الْأَيْكَةِ لَظَالِمِينَ
Yoruba
 
Àwọn ará 'Aekah náà jẹ́ alábòsí.

Ayah  15:79  الأية
    +/- -/+  
فَانتَقَمْنَا مِنْهُمْ وَإِنَّهُمَا لَبِإِمَامٍ مُّبِينٍ
Yoruba
 
A sì gbẹ́san lára wọn. Dájújájú àwọn ìlú méjèèjì ló kúkú wà lójú ọ̀nà gban̄gba (tí ẹ̀ ń tọ̀ lọ tọ̀ bọ̀).

Ayah  15:80  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدْ كَذَّبَ أَصْحَابُ الْحِجْرِ الْمُرْسَلِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú àwọn ará Ihò àpáta pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.

Ayah  15:81  الأية
    +/- -/+  
وَآتَيْنَاهُمْ آيَاتِنَا فَكَانُوا عَنْهَا مُعْرِضِينَ
Yoruba
 
A sì fún wọn ní àwọn àmì Wa. Àmọ́ wọ́n gbúnrí kúrò níbẹ̀.

Ayah  15:82  الأية
    +/- -/+  
وَكَانُوا يَنْحِتُونَ مِنَ الْجِبَالِ بُيُوتًا آمِنِينَ
Yoruba
 
Wọ́n máa ń gbẹ́ àwọn ilé ìgbé ìfàyàbalẹ̀ sínú àwọn àpáta.

Ayah  15:83  الأية
    +/- -/+  
فَأَخَذَتْهُمُ الصَّيْحَةُ مُصْبِحِينَ
Yoruba
 
Ohùn igbe sì mú wọn nígbà tí wọ́n mọ́júmọ́.

Ayah  15:84  الأية
    +/- -/+  
فَمَا أَغْنَىٰ عَنْهُم مَّا كَانُوا يَكْسِبُونَ
Yoruba
 
Ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ kò sì rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ (níbi ìyà).

Ayah  15:85  الأية
    +/- -/+  
وَمَا خَلَقْنَا السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَمَا بَيْنَهُمَا إِلَّا بِالْحَقِّ ۗ وَإِنَّ السَّاعَةَ لَآتِيَةٌ ۖ فَاصْفَحِ الصَّفْحَ الْجَمِيلَ
Yoruba
 
A kò ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti n̄ǹkan tó wà láààrin àwọn méjèèjì bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo. Dájúdájú Àkókò náà máa dé. Nítorí náà, ṣàmójúkúrò ní àmójúkúrò tó rẹwà.

Ayah  15:86  الأية
    +/- -/+  
إِنَّ رَبَّكَ هُوَ الْخَلَّاقُ الْعَلِيمُ
Yoruba
 
Dájúdájú Olúwa rẹ ni Ẹlẹ́dàá, Onímọ̀.

Ayah  15:87  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدْ آتَيْنَاكَ سَبْعًا مِّنَ الْمَثَانِي وَالْقُرْآنَ الْعَظِيمَ
Yoruba
 
Dájúdájú A fún ọ ní Sab‘u Mọthānī (ìyẹn, sūrah al-Fātihah) àti al-Ƙur'ān Ńlá.

Ayah  15:88  الأية
    +/- -/+  
لَا تَمُدَّنَّ عَيْنَيْكَ إِلَىٰ مَا مَتَّعْنَا بِهِ أَزْوَاجًا مِّنْهُمْ وَلَا تَحْزَنْ عَلَيْهِمْ وَاخْفِضْ جَنَاحَكَ لِلْمُؤْمِنِينَ
Yoruba
 
Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣíjú rẹ méjèèjì wo ohun tí A fi ṣe ìgbádún ayé fún oríṣiríṣi àwọn kan nínú àwọn aláìgbàgbọ́. Má ṣe banújẹ́ nítorí wọn. Kí o sì rẹ apá rẹ nílẹ̀ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

Ayah  15:89  الأية
    +/- -/+  
وَقُلْ إِنِّي أَنَا النَّذِيرُ الْمُبِينُ
Yoruba
 
Kí o sì sọ pé: "Dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé."

Ayah  15:90  الأية
    +/- -/+  
كَمَا أَنزَلْنَا عَلَى الْمُقْتَسِمِينَ
Yoruba
 
Gẹ́gẹ́ bí A ṣe sọ (ìyà) kalẹ̀ fún àwọn tó ń pín òdodo mọ́ irọ́;

Ayah  15:91  الأية
    +/- -/+  
الَّذِينَ جَعَلُوا الْقُرْآنَ عِضِينَ
Yoruba
 
Àwọn tí wọ́n sọ al-Ƙur'ān di ìpínkúpìn-ín,

Ayah  15:92  الأية
    +/- -/+  
فَوَرَبِّكَ لَنَسْأَلَنَّهُمْ أَجْمَعِينَ
Yoruba
 
Olúwa rẹ fi Ara Rẹ̀ búra fún ọ pé, A máa bi gbogbo wọn ní ìbéèrè

Ayah  15:93  الأية
    +/- -/+  

Ayah  15:94  الأية
    +/- -/+  
فَاصْدَعْ بِمَا تُؤْمَرُ وَأَعْرِضْ عَنِ الْمُشْرِكِينَ
Yoruba
 
Nítorí náà, kéde n̄ǹkan tí A pa láṣẹ fún ọ. Kí o sì ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọ̀ṣẹbọ.

Ayah  15:95  الأية
    +/- -/+  
إِنَّا كَفَيْنَاكَ الْمُسْتَهْزِئِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú Àwa yóò tó ọ (níbi aburú) àwọn oníyẹ̀yẹ́,

Ayah  15:96  الأية
    +/- -/+  
الَّذِينَ يَجْعَلُونَ مَعَ اللهِ إِلَٰهًا آخَرَ ۚ فَسَوْفَ يَعْلَمُونَ
Yoruba
 
Àwọn tó ń mú ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu. Láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀.

Ayah  15:97  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدْ نَعْلَمُ أَنَّكَ يَضِيقُ صَدْرُكَ بِمَا يَقُولُونَ
Yoruba
 
Àwa kúkú ti mọ̀ pé dájúdájú ohun tí wọ́n ń wí ń kó ìnira bá ọ.

Ayah  15:98  الأية
    +/- -/+  
فَسَبِّحْ بِحَمْدِ رَبِّكَ وَكُن مِّنَ السَّاجِدِينَ
Yoruba
 
Nítorí náà, ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ẹyìn fún Olúwa rẹ. Kí o sì wà nínú àwọn olùforíkanlẹ̀ (fún Un).

Ayah  15:99  الأية
    +/- -/+  
وَاعْبُدْ رَبَّكَ حَتَّىٰ يَأْتِيَكَ الْيَقِينُ
Yoruba
 
Jọ́sìn fún Olúwa rẹ títí àmọ̀dájú (ìyẹn, ikú) yóò fi dé bá ọ.
 


© EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us