(Èyí ni) Sūrah kan tí A sọ̀kalẹ̀. A ṣe ìdájọ́ inú rẹ̀ ní òfin (dandan). A sì sọ àwọn āyah tó yanjú kalẹ̀ sínú rẹ̀ nítorí kí ẹ lè lo ìrántí.
Àwọn tó ń fi ẹ̀sùn sìná kan àwọn ọmọlúàbí lóbìnrin, lẹ́yìn náà tí wọn kò mú àwọn ẹlẹ́rìí mẹ́rin wá, ẹ nà wọ́n ní ọgọ́rin kòbókò. Ẹ má ṣe gba ẹ̀rí wọn mọ́ láéláé; àwọn wọ̀nyẹn sì ni òbìlẹ̀jẹ́.
Kí ni kò jẹ́ kí wọ́n mú ẹlẹ́rìí mẹ́rin wá lórí rẹ̀? Nítorí náà, nígbà tí wọn kò ti mú àwọn ẹlẹ́rìí wá, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni òpùrọ́ lọ́dọ̀ Allāhu.
Nígbà tí ẹ gbọ́ ọ, kí ni kò jẹ́ kí ẹ sọ pé: "Kì í ṣe ẹ̀tọ́ fún wa pé kí á sọ èyí. Mímọ́ ni fún Ọ (Allāhu)! Èyí ni ìparọ́-mọ́ni tó tóbi."
Sọ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin pé kí wọ́n rẹ ojú wọn nílẹ̀, kí wọ́n sì ṣọ́ abẹ́ wọn. Ìyẹn fọ̀ wọ́n mọ́ jùlọ. Dájúdájú Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu ni gbogbo ẹni tó ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti lórí ilẹ̀ ń ṣe àfọ̀mọ́ fún? Àwọn ẹyẹ náà (ń ṣe bẹ́ẹ̀) nígbà tí wọ́n bá ń na ìyẹ́ apá wọn? Ìkọ̀ọ̀kan wọn kúkú ti mọ bí ó ṣe máa kírun rẹ̀ àti bí ó ṣe máa ṣe àfọ̀mọ́ rẹ̀ (fún Un). Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Àti pé nígbà tí wọ́n bá pè wọ́n sí ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ nítorí kí ó lè ṣèdájọ́ láààrin wọn, nígbà náà ni igun kan nínú wọn yóò máa gbúnrí.
Ṣé àrùn wà nínú ọkàn wọn ni tàbí wọ́n ṣeyèméjì? Tàbí wọ́n ń páyà pé Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ yóò fi ẹjọ́ wọn ṣègbè ni? Rárá o. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni alábòsí.
Ohun tí ó máa jẹ́ ọ̀rọ̀ àwọn onígbàgbọ́ òdodo nígbà tí wọ́n bá pè wọ́n sí ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ nítorí kí ó lè ṣèdájọ́ láààrin wọn ni pé, wọ́n á sọ pé: "A gbọ́ (àṣẹ), a sì tẹ̀lé (àṣẹ)." Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni olùjèrè.
Wọ́n sì fi Allāhu búra tí ìbura wọn sì ní agbára pé: "Dájúdájú tí o bá pàṣẹ fún àwọn, dájúdájú àwọn yóò jáde." Sọ pé: "Ẹ má ṣe búra mọ́. Títẹ̀lé àṣẹ (pẹ̀lú ìbúra irọ́ ẹnu yín) ti di ohun mímọ̀ (fún wa)." Dájúdájú Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Allāhu ṣàdéhùn fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo nínú yín, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere pé dájúdájú Ó máa fi wọ́n ṣe àrólé lórí ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe fi àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe àrólé. Dájúdájú Ó máa fi àyè gba ẹ̀sìn wọn fún wọn, èyí tí Ó yọ́nú sí fún wọn. Lẹ́yìn ìbẹ̀rù wọn, dájúdájú Ó máa fi ìfàyàbalẹ̀ dípò rẹ̀ fún wọn. Wọ́n ń jọ́sìn fún Mi, wọn kò sì fi n̄ǹkan kan ṣẹbọ sí Mi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàì moore lẹ́yìn ìyẹn, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni òbìlẹ̀jẹ́.
Nígbà tí àwọn ọmọdé yín bá sì bàlágà, kí àwọn náà máa gba ìyọ̀ǹda gẹ́gẹ́ bí àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe gba ìyọ̀ǹda. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah Rẹ̀ fún yín. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Gbọ́! Dájúdájú ti Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó sì ti mọ ohun tí ẹ wà lórí rẹ̀. (Rántí) ọjọ́ tí wọn yó dá wọn padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀, Ó sì máa fún wọn ní ìró ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.