Prev  

26. Surah Ash-Shu'arâ' سورة الشعراء

  Next  



Ayah  26:1  الأية
    +/- -/+  
بِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
طسم
Yoruba
 
Tọ̄ sīn mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)

Ayah  26:2  الأية
    +/- -/+  
تِلْكَ آيَاتُ الْكِتَابِ الْمُبِينِ
Yoruba
 
Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà tó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá.

Ayah  26:3  الأية
    +/- -/+  
لَعَلَّكَ بَاخِعٌ نَّفْسَكَ أَلَّا يَكُونُوا مُؤْمِنِينَ
Yoruba
 
Nítorí kí ni o ṣe máa para rẹ pé wọn kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.

Ayah  26:4  الأية
    +/- -/+  
إِن نَّشَأْ نُنَزِّلْ عَلَيْهِم مِّنَ السَّمَاءِ آيَةً فَظَلَّتْ أَعْنَاقُهُمْ لَهَا خَاضِعِينَ
Yoruba
 
Tí A bá fẹ́, A máa sọ àmì kan kalẹ̀ fún wọn láti sánmọ̀. Àwọn ọrùn wọn kò sì níí yé tẹríba fún un.

Ayah  26:5  الأية
    +/- -/+  
وَمَا يَأْتِيهِم مِّن ذِكْرٍ مِّنَ الرَّحْمَٰنِ مُحْدَثٍ إِلَّا كَانُوا عَنْهُ مُعْرِضِينَ
Yoruba
 
Kò sí ìrántí kan tí ó máa dé bá wọn ní titun láti ọ̀dọ̀ Àjọkẹ́-ayé àfi kí wọ́n jẹ́ olùgbúnrí kúrò níbẹ̀.

Ayah  26:6  الأية
    +/- -/+  
فَقَدْ كَذَّبُوا فَسَيَأْتِيهِمْ أَنبَاءُ مَا كَانُوا بِهِ يَسْتَهْزِئُونَ
Yoruba
 
Dájúdájú wọ́n ti pe (āyah Wa) nírọ́. Nítorí náà, àwọn ìró ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ ń bọ̀ wá bá wọn.

Ayah  26:7  الأية
    +/- -/+  
أَوَلَمْ يَرَوْا إِلَى الْأَرْضِ كَمْ أَنبَتْنَا فِيهَا مِن كُلِّ زَوْجٍ كَرِيمٍ
Yoruba
 
Ṣé wọn kò rí ilẹ̀ pé mélòó mélòó nínú gbogbo oríṣiríṣi n̄ǹkan alápọ̀n-ọ́nlé tí A mú hù jáde láti inú rẹ̀?

Ayah  26:8  الأية
    +/- -/+  
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُم مُّؤْمِنِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.

Ayah  26:9  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ
Yoruba
 
Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

Ayah  26:10  الأية
    +/- -/+  
وَإِذْ نَادَىٰ رَبُّكَ مُوسَىٰ أَنِ ائْتِ الْقَوْمَ الظَّالِمِينَ
Yoruba
 
(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ pe (Ànábì) Mūsā pé: "Lọ bá ìjọ alábòsí,

Ayah  26:11  الأية
    +/- -/+  
قَوْمَ فِرْعَوْنَ ۚ أَلَا يَتَّقُونَ
Yoruba
 
Ìjọ Fir‘aon (kí o sì sọ̱ fún wọn) pé, ‘Ṣé wọn kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni.' "

Ayah  26:12  الأية
    +/- -/+  
قَالَ رَبِّ إِنِّي أَخَافُ أَن يُكَذِّبُونِ
Yoruba
 
Ó sọ pé: "Olúwa mi, dájúdájú èmi ń bẹ̀rù pé wọ́n máa pè mí ní òpùrọ́.

Ayah  26:13  الأية
    +/- -/+  
وَيَضِيقُ صَدْرِي وَلَا يَنطَلِقُ لِسَانِي فَأَرْسِلْ إِلَىٰ هَارُونَ
Yoruba
 
Ó sì máa jẹ́ ìnira fún mi (tí wọ́n bá pè mí ní òpùrọ́). Ahọ́n mi kò sì já gaaraga. Nítorí náà, ránṣẹ́ sí Hārūn.

Ayah  26:14  الأية
    +/- -/+  
وَلَهُمْ عَلَيَّ ذَنبٌ فَأَخَافُ أَن يَقْتُلُونِ
Yoruba
 
Àti pé mo ní ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́rùn lọ́dọ̀ wọn. Nítorí náà, mò ń bẹ̀rù pé wọ́n máa pa mí."

Ayah  26:15  الأية
    +/- -/+  
قَالَ كَلَّا ۖ فَاذْهَبَا بِآيَاتِنَا ۖ إِنَّا مَعَكُم مُّسْتَمِعُونَ
Yoruba
 
(Allāhu) sọ pé: "Rárá (wọn kò lè pa ọ́). Nítorí náà, kí ẹ̀yin méjèèjì mú àwọn àmì (iṣẹ́ ìyanu) Wa lọ (bá wọn). Dájúdájú Àwa ń bẹ pẹ̀lú yín; À ń gbọ́ (ọ̀rọ̀ yín).

Ayah  26:16  الأية
    +/- -/+  
فَأْتِيَا فِرْعَوْنَ فَقُولَا إِنَّا رَسُولُ رَبِّ الْعَالَمِينَ
Yoruba
 
Ẹ̀yin méjèèjì, ẹ lọ bá Fir‘aon. Kí ẹ sọ fún un pé: "Dájúdájú àwa ni Òjíṣẹ́ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

Ayah  26:17  الأية
    +/- -/+  
أَنْ أَرْسِلْ مَعَنَا بَنِي إِسْرَائِيلَ
Yoruba
 
(À ń sọ fún ọ) pé kí o jẹ́ kí àwọn ọmọ 'Isrọ̄'īl máa bá wa lọ."

Ayah  26:18  الأية
    +/- -/+  
قَالَ أَلَمْ نُرَبِّكَ فِينَا وَلِيدًا وَلَبِثْتَ فِينَا مِنْ عُمُرِكَ سِنِينَ
Yoruba
 
(Fir‘aon) wí pé: "Ṣé kì í ṣe ní ààrin wa ni a ti tọ́ ọ ní kékeré ni, tí o sì gbé ní ọ̀dọ̀ wa fún ọdún púpọ̀ nínú ìṣẹ̀mí ayé rẹ?

Ayah  26:19  الأية
    +/- -/+  
وَفَعَلْتَ فَعْلَتَكَ الَّتِي فَعَلْتَ وَأَنتَ مِنَ الْكَافِرِينَ
Yoruba
 
O sì ṣe iṣẹ́ ọwọ́ rẹ tí o ṣe (sí wa). Ìwọ sì wà nínú àwọn aláìmoore."

Ayah  26:20  الأية
    +/- -/+  
قَالَ فَعَلْتُهَا إِذًا وَأَنَا مِنَ الضَّالِّينَ
Yoruba
 
(Ànábì Mūsā) sọ pé: "Mo ṣe é nígbà náà nígbà tí mo wà nínú àwọn aláṣìṣe (èmi kò mọ̀ọ́mọ̀ ṣe é).

Ayah  26:21  الأية
    +/- -/+  
فَفَرَرْتُ مِنكُمْ لَمَّا خِفْتُكُمْ فَوَهَبَ لِي رَبِّي حُكْمًا وَجَعَلَنِي مِنَ الْمُرْسَلِينَ
Yoruba
 
Mo sì sá fún yín nígbà tí mo bẹ̀rù yín. Lẹ́yìn náà, Allāhu ta mí lọ́rẹ ipò Ànábì. Ó sì ṣe mí ní (ọ̀kan) nínú àwọn Òjíṣẹ́.

Ayah  26:22  الأية
    +/- -/+  
وَتِلْكَ نِعْمَةٌ تَمُنُّهَا عَلَيَّ أَنْ عَبَّدتَّ بَنِي إِسْرَائِيلَ
Yoruba
 
Àti pé ìyẹn ni ìdẹ̀ra tí ò ń ṣe ìrègún rẹ̀ lé mi lórí. Pé ó sọ àwọn ọmọ 'Isrọ̄'īl di ẹrú (ńkọ́?).

Ayah  26:23  الأية
    +/- -/+  
قَالَ فِرْعَوْنُ وَمَا رَبُّ الْعَالَمِينَ
Yoruba
 
Fir‘aon wí pé: "Kí ni Olúwa gbogbo ẹ̀dá?"

Ayah  26:24  الأية
    +/- -/+  
قَالَ رَبُّ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا ۖ إِن كُنتُم مُّوقِنِينَ
Yoruba
 
(Ànábì Mūsā) sọ pé: "(Allāhu ni) Olúwa àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti ohunkóhun tó ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì, tí ẹ̀yin bá jẹ́ alámọ̀dájú."

Ayah  26:25  الأية
    +/- -/+  
قَالَ لِمَنْ حَوْلَهُ أَلَا تَسْتَمِعُونَ
Yoruba
 
(Fir‘aon) wí fún àwọn tó wà ní àyíká rẹ̀ pé: "Ṣé ẹ ẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ (tó ń sọ ni)?"

Ayah  26:26  الأية
    +/- -/+  
قَالَ رَبُّكُمْ وَرَبُّ آبَائِكُمُ الْأَوَّلِينَ
Yoruba
 
(Ànábì Mūsā) sọ pé: "(Allāhu ni) Olúwa yín àti Olúwa àwọn bàbá yín, àwọn ẹni àkọ́kọ́."

Ayah  26:27  الأية
    +/- -/+  
قَالَ إِنَّ رَسُولَكُمُ الَّذِي أُرْسِلَ إِلَيْكُمْ لَمَجْنُونٌ
Yoruba
 
(Fir‘aon) wí pé: "Dájúdájú Òjíṣẹ́ yín èyí tí wọ́n rán si yín, wèrè mà ni."

Ayah  26:28  الأية
    +/- -/+  
قَالَ رَبُّ الْمَشْرِقِ وَالْمَغْرِبِ وَمَا بَيْنَهُمَا ۖ إِن كُنتُمْ تَعْقِلُونَ
Yoruba
 
(Ànábì Mūsā) sọ pé: "(Allāhu ni) Olúwa ibùyọ òòrùn, ibùwọ̀ òòrùn àti ohunkóhun tó ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì, tí ẹ bá máa ń ṣe làákàyè."

Ayah  26:29  الأية
    +/- -/+  
قَالَ لَئِنِ اتَّخَذْتَ إِلَٰهًا غَيْرِي لَأَجْعَلَنَّكَ مِنَ الْمَسْجُونِينَ
Yoruba
 
(Fir‘aon) wí pé: "Dájúdájú tí o bá fi lè jọ́sìn fún ọlọ́hun kan yàtọ̀ sí mi, dájúdájú mo máa sọ ọ́ di ara àwọn ẹlẹ́wọ̀n."

Ayah  26:30  الأية
    +/- -/+  
قَالَ أَوَلَوْ جِئْتُكَ بِشَيْءٍ مُّبِينٍ
Yoruba
 
(Ànábì Mūsā) sọ pé: "Tí ó bá jẹ́ pé mo mú kiní kan tó yanjú wá fún ọ ńkọ́?"

Ayah  26:31  الأية
    +/- -/+  
قَالَ فَأْتِ بِهِ إِن كُنتَ مِنَ الصَّادِقِينَ
Yoruba
 
(Fir‘aon) wí pé: "Mú un wá nígbà náà tí ìwọ bá wà nínú àwọn olódodo."

Ayah  26:32  الأية
    +/- -/+  
فَأَلْقَىٰ عَصَاهُ فَإِذَا هِيَ ثُعْبَانٌ مُّبِينٌ
Yoruba
 
Nítorí náà, ó ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di ejò pọ́nńbélé.

Ayah  26:33  الأية
    +/- -/+  
وَنَزَعَ يَدَهُ فَإِذَا هِيَ بَيْضَاءُ لِلنَّاظِرِينَ
Yoruba
 
Ó tún fa ọwọ́ rẹ̀ yọ síta, ó sì di funfun fún àwọn olùwòran.

Ayah  26:34  الأية
    +/- -/+  
قَالَ لِلْمَلَإِ حَوْلَهُ إِنَّ هَٰذَا لَسَاحِرٌ عَلِيمٌ
Yoruba
 
(Fir‘aon) wí fún àwọn ìjòyè tí wọ́n wà ní àyíká rẹ̀ pé: "Dájúdájú èyí ni onímọ̀ nípa idán pípa.

Ayah  26:35  الأية
    +/- -/+  
يُرِيدُ أَن يُخْرِجَكُم مِّنْ أَرْضِكُم بِسِحْرِهِ فَمَاذَا تَأْمُرُونَ
Yoruba
 
Ó fẹ́ ko yín kúrò lórí ilẹ̀ yín ni. Kí ni ohun tí ẹ máa mú wá ní ìmọ̀ràn?"

Ayah  26:36  الأية
    +/- -/+  
قَالُوا أَرْجِهْ وَأَخَاهُ وَابْعَثْ فِي الْمَدَائِنِ حَاشِرِينَ
Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "Dá òun àti arákùnrin rẹ̀ dúró ná, kí o sì rán àwọn akónijọ sí àwọn ìlú

Ayah  26:37  الأية
    +/- -/+  
يَأْتُوكَ بِكُلِّ سَحَّارٍ عَلِيمٍ
Yoruba
 
(pé) kí gbogbo onímọ̀ nípa idán pípa wá bá ọ."

Ayah  26:38  الأية
    +/- -/+  
فَجُمِعَ السَّحَرَةُ لِمِيقَاتِ يَوْمٍ مَّعْلُومٍ
Yoruba
 
Wọ́n sì kó àwọn òpìdán jọ ní àsìkò tí wọ́n fi àdéhùn sí ní ọjọ́ tí (gbogbo ìlú) ti mọ̀.

Ayah  26:39  الأية
    +/- -/+  
وَقِيلَ لِلنَّاسِ هَلْ أَنتُم مُّجْتَمِعُونَ
Yoruba
 
Wọ́n sì wí fún àwọn ènìyàn pé: "Ṣé ẹ̀yin máa kó jọ (síbẹ̀) bí?

Ayah  26:40  الأية
    +/- -/+  
لَعَلَّنَا نَتَّبِعُ السَّحَرَةَ إِن كَانُوا هُمُ الْغَالِبِينَ
Yoruba
 
Nítorí kí á lè tẹ̀lé àwọn òpìdán tí ó bá jẹ́ pé àwọn ni olùborí."

Ayah  26:41  الأية
    +/- -/+  
فَلَمَّا جَاءَ السَّحَرَةُ قَالُوا لِفِرْعَوْنَ أَئِنَّ لَنَا لَأَجْرًا إِن كُنَّا نَحْنُ الْغَالِبِينَ
Yoruba
 
Nígbà tí àwọn òpìdán dé, wọ́n wí fún Fir‘aon pé: "Ǹjẹ́ owó-ọ̀yà kan wà fún wa, tí ó bá jẹ́ pé àwa gan-an la jẹ́ olùborí?"

Ayah  26:42  الأية
    +/- -/+  
قَالَ نَعَمْ وَإِنَّكُمْ إِذًا لَّمِنَ الْمُقَرَّبِينَ
Yoruba
 
(Fir‘aon) wí pé: "Bẹ́ẹ̀ ni, dájúdájú nígbà náà ẹ máa wà nínú àwọn alásùn-únmọ́ (mi)."

Ayah  26:43  الأية
    +/- -/+  
قَالَ لَهُم مُّوسَىٰ أَلْقُوا مَا أَنتُم مُّلْقُونَ
Yoruba
 
(Ànábì) Mūsā sọ fún wọn pé: "Ẹ ju ohun tí ẹ fẹ́ jù sílẹ̀."

Ayah  26:44  الأية
    +/- -/+  
فَأَلْقَوْا حِبَالَهُمْ وَعِصِيَّهُمْ وَقَالُوا بِعِزَّةِ فِرْعَوْنَ إِنَّا لَنَحْنُ الْغَالِبُونَ
Yoruba
 
Wọ́n sì ju àwọn okùn wọn àti ọ̀pá wọn sílẹ̀. Wọ́n wí pé: "Pẹ̀lú ògo Fir‘aon, dájúdájú àwa, àwa ni olùborí."

Ayah  26:45  الأية
    +/- -/+  
فَأَلْقَىٰ مُوسَىٰ عَصَاهُ فَإِذَا هِيَ تَلْقَفُ مَا يَأْفِكُونَ
Yoruba
 
Nígbà náà, (Ànábì) Mūsā ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀. Ó sì ń gbé ohun tí wọ́n pa nírọ́ kalẹ̀ mì kálókáló.

Ayah  26:46  الأية
    +/- -/+  
فَأُلْقِيَ السَّحَرَةُ سَاجِدِينَ
Yoruba
 
Nítorí náà, iṣẹ́ ìyanu (Ànábì Mūsā) mú àwọn òpìdán wó lulẹ̀, tí wọ́n forí kanlẹ̀ (fún Allāhu).

Ayah  26:47  الأية
    +/- -/+  
قَالُوا آمَنَّا بِرَبِّ الْعَالَمِينَ
Yoruba
 
Wọ́n sọ pé: "A gbàgbọ́ nínú Olúwa gbogbo ẹ̀dá,

Ayah  26:48  الأية
    +/- -/+  

Ayah  26:49  الأية
    +/- -/+  
قَالَ آمَنتُمْ لَهُ قَبْلَ أَنْ آذَنَ لَكُمْ ۖ إِنَّهُ لَكَبِيرُكُمُ الَّذِي عَلَّمَكُمُ السِّحْرَ فَلَسَوْفَ تَعْلَمُونَ ۚ لَأُقَطِّعَنَّ أَيْدِيَكُمْ وَأَرْجُلَكُم مِّنْ خِلَافٍ وَلَأُصَلِّبَنَّكُمْ أَجْمَعِينَ
Yoruba
 
Fir‘aon wí pé: "Ẹ gbà Á gbọ́ ṣíwájú kí n̄g tó yọ̀ǹda fún yín! Dájúdájú òun ni àgbà yín tí ó kọ yín ní idán pípa. Láìpẹ́ ẹ̀ ń bọ̀ wá mọ̀. Dájúdájú mo máa gé ọwọ́ yín àti ẹsẹ̀ yín ní ìpasípayọ. Lẹ́yìn náà, dájúdájú mo máa kan gbogbo yín mọ́gi."

Ayah  26:50  الأية
    +/- -/+  
قَالُوا لَا ضَيْرَ ۖ إِنَّا إِلَىٰ رَبِّنَا مُنقَلِبُونَ
Yoruba
 
(Àwọn òpìdán) sọ pé: "Kò sí ìnira fún wa! Dájúdájú àwa yó sì fàbọ̀ sí ọ̀dọ̀ Olúwa wa.

Ayah  26:51  الأية
    +/- -/+  
إِنَّا نَطْمَعُ أَن يَغْفِرَ لَنَا رَبُّنَا خَطَايَانَا أَن كُنَّا أَوَّلَ الْمُؤْمِنِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú àwa n retí pé Olúwa wa yóò ṣe àforíjìn àwọn àṣìṣe wa fún wa nítorí pé àwa jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ (tí ó jẹ́) onígbàgbọ́ òdodo."

Ayah  26:52  الأية
    +/- -/+  
وَأَوْحَيْنَا إِلَىٰ مُوسَىٰ أَنْ أَسْرِ بِعِبَادِي إِنَّكُم مُّتَّبَعُونَ
Yoruba
 
A fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā pé: "Mú àwọn ẹrúsìn Mi rìn ní òru (nítorí pé), dájúdájú wọn yóò lépa yín."

Ayah  26:53  الأية
    +/- -/+  
فَأَرْسَلَ فِرْعَوْنُ فِي الْمَدَائِنِ حَاشِرِينَ
Yoruba
 
Fir‘aon sì rán àwọn akónijọ sínú àwọn ìlú (láti sọ pé):

Ayah  26:54  الأية
    +/- -/+  
إِنَّ هَٰؤُلَاءِ لَشِرْذِمَةٌ قَلِيلُونَ
Yoruba
 
"Dájúdájú àwọn (ọmọ 'Isrọ̄'īl) wọ̀nyí, ìjọ péréte díẹ̀ ni wọ́n.

Ayah  26:55  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّهُمْ لَنَا لَغَائِظُونَ
Yoruba
 
Àti pé dájúdájú wọ́n ti ṣe ohun tó ń bí wa nínú.

Ayah  26:56  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّا لَجَمِيعٌ حَاذِرُونَ
Yoruba
 
Dájúdájú gbogbo wa ni kí á sì wà tìfura-tìfura."

Ayah  26:57  الأية
    +/- -/+  
فَأَخْرَجْنَاهُم مِّن جَنَّاتٍ وَعُيُونٍ
Yoruba
 
Nítorí náà, A mú (ìjọ Fir‘aon) jáde kúrò nínú àwọn ọgbà oko àti ìṣẹ́lẹ̀rú omi,

Ayah  26:58  الأية
    +/- -/+  
وَكُنُوزٍ وَمَقَامٍ كَرِيمٍ
Yoruba
 
Àti àwọn ilé ọrọ̀ àti ibùjókòó àpọ́nlé.

Ayah  26:59  الأية
    +/- -/+  
كَذَٰلِكَ وَأَوْرَثْنَاهَا بَنِي إِسْرَائِيلَ
Yoruba
 
Báyẹn (lọ̀rọ̀ rí). A sì jogún rẹ̀ fún àwọn ọmọ 'Isrọ̄'īl.

Ayah  26:60  الأية
    +/- -/+  
فَأَتْبَعُوهُم مُّشْرِقِينَ
Yoruba
 
Wọ́n sì lépa wọn ní àsìkò tí òòrùn yọ.

Ayah  26:61  الأية
    +/- -/+  
فَلَمَّا تَرَاءَى الْجَمْعَانِ قَالَ أَصْحَابُ مُوسَىٰ إِنَّا لَمُدْرَكُونَ
Yoruba
 
Nígbà tí ìjọ méjèèjì ríra wọn, àwọn ìjọ (Ànábì) Mūsā sọ pé: "Dájúdájú wọn yóò lé wa bá."

Ayah  26:62  الأية
    +/- -/+  
قَالَ كَلَّا ۖ إِنَّ مَعِيَ رَبِّي سَيَهْدِينِ
Yoruba
 
(Ànábì) Mūsā sọ pé: "Rárá, dájúdájú Olúwa mi ń bẹ pẹ̀lú mi. Ó sì máa fi ọ̀nà mọ̀ mí."

Ayah  26:63  الأية
    +/- -/+  
فَأَوْحَيْنَا إِلَىٰ مُوسَىٰ أَنِ اضْرِب بِّعَصَاكَ الْبَحْرَ ۖ فَانفَلَقَ فَكَانَ كُلُّ فِرْقٍ كَالطَّوْدِ الْعَظِيمِ
Yoruba
 
A sì fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā pé: "Fi ọ̀pá rẹ na agbami òkun." (Ó fi nà án). Ó sì pín (sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀). Ìpín kọ̀ọ̀kan sì dà bí àpáta ńlá.

Ayah  26:64  الأية
    +/- -/+  
وَأَزْلَفْنَا ثَمَّ الْآخَرِينَ
Yoruba
 
A sì mú ìjọ kejì (ìyẹn, ìjọ Fir‘aon) súnmọ́ ibẹ̀ yẹn.

Ayah  26:65  الأية
    +/- -/+  
وَأَنجَيْنَا مُوسَىٰ وَمَن مَّعَهُ أَجْمَعِينَ
Yoruba
 
A gba (Ànábì) Mūsā àti gbogbo àwọn tó ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ là pátápátá.

Ayah  26:66  الأية
    +/- -/+  
ثُمَّ أَغْرَقْنَا الْآخَرِينَ
Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, A tẹ ìjọ kejì rì (sínú agbami).

Ayah  26:67  الأية
    +/- -/+  
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُم مُّؤْمِنِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.

Ayah  26:68  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ
Yoruba
 
Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

Ayah  26:69  الأية
    +/- -/+  
وَاتْلُ عَلَيْهِمْ نَبَأَ إِبْرَاهِيمَ
Yoruba
 
Ka ìròyìn (Ànábì) 'Ibrọ̄hīm fún wọn.

Ayah  26:70  الأية
    +/- -/+  
إِذْ قَالَ لِأَبِيهِ وَقَوْمِهِ مَا تَعْبُدُونَ
Yoruba
 
Nígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: "Kí ni n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún ná?"

Ayah  26:71  الأية
    +/- -/+  
قَالُوا نَعْبُدُ أَصْنَامًا فَنَظَلُّ لَهَا عَاكِفِينَ
Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "À ń jọ́sìn fún àwọn ère òrìṣà kan ni. A ò sì níí yé takú tì wọ́n lọ́rùn."

Ayah  26:72  الأية
    +/- -/+  
قَالَ هَلْ يَسْمَعُونَكُمْ إِذْ تَدْعُونَ
Yoruba
 
(Ànábì 'Ibrọ̄hīm) sọ pé: "Ǹjẹ́ wọ́n ń gbọ́ ọ̀rọ̀ yín nígbà tí ẹ bá ń pè wọ́n?

Ayah  26:73  الأية
    +/- -/+  
أَوْ يَنفَعُونَكُمْ أَوْ يَضُرُّونَ
Yoruba
 
Tàbí (ṣé) wọ́n lè ṣe yín ní àǹfààní tàbí wọ́n lè fi ìnira kàn yín?"

Ayah  26:74  الأية
    +/- -/+  
قَالُوا بَلْ وَجَدْنَا آبَاءَنَا كَذَٰلِكَ يَفْعَلُونَ
Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "Rárá o! A bá àwọn bàbá wa tí wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni"

Ayah  26:75  الأية
    +/- -/+  
قَالَ أَفَرَأَيْتُم مَّا كُنتُمْ تَعْبُدُونَ
Yoruba
 
(Ànábì 'Ibrọ̄hīm) sọ pé: " Ẹ sọ fún mi, kí ni n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún,

Ayah  26:76  الأية
    +/- -/+  
أَنتُمْ وَآبَاؤُكُمُ الْأَقْدَمُونَ
Yoruba
 
ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín àwọn ẹni ìṣáájú?

Ayah  26:77  الأية
    +/- -/+  
فَإِنَّهُمْ عَدُوٌّ لِّي إِلَّا رَبَّ الْعَالَمِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú àwọn ni ọ̀tá fún mi àyàfi Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

Ayah  26:78  الأية
    +/- -/+  
الَّذِي خَلَقَنِي فَهُوَ يَهْدِينِ
Yoruba
 
(Òun ni) Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá mi. Nítorí náà, Ó máa fi ọ̀nà mọ̀ mí;

Ayah  26:79  الأية
    +/- -/+  
وَالَّذِي هُوَ يُطْعِمُنِي وَيَسْقِينِ
Yoruba
 
Ẹni tó ń fún mi ní jíjẹ, tó ń fún mi ní mímu;

Ayah  26:80  الأية
    +/- -/+  
وَإِذَا مَرِضْتُ فَهُوَ يَشْفِينِ
Yoruba
 
Àti pé nígbà tí ara mi kò bá yá, Òun l'Ó ń wò mí sàn;

Ayah  26:81  الأية
    +/- -/+  
وَالَّذِي يُمِيتُنِي ثُمَّ يُحْيِينِ
Yoruba
 
Ẹni tí Ó máa pa mí, lẹ́yìn náà, Ó máa sọ mí di alààyè;

Ayah  26:82  الأية
    +/- -/+  
وَالَّذِي أَطْمَعُ أَن يَغْفِرَ لِي خَطِيئَتِي يَوْمَ الدِّينِ
Yoruba
 
Ẹni tí mo ní ìrètí sí pé Ó máa forí àwọn àṣìṣe mi jìn mí ní Ọjọ́ Ẹ̀san.

Ayah  26:83  الأية
    +/- -/+  
رَبِّ هَبْ لِي حُكْمًا وَأَلْحِقْنِي بِالصَّالِحِينَ
Yoruba
 
Olúwa mi, ta mí ní ọrẹ ipò Ànábì. Dà mí pọ̀ mọ́ àwọn ẹni rere.

Ayah  26:84  الأية
    +/- -/+  
وَاجْعَل لِّي لِسَانَ صِدْقٍ فِي الْآخِرِينَ
Yoruba
 
Fi òdodo sórí ahọ́n àwọn tó ń bọ̀ lẹ́yìn mi nìpa mi (ìyẹn ni pé, jẹ́ kí àwọn tó ń bọ̀ lẹ́yìn mi máa sọ̀rọ̀ mi ní dáadáa).

Ayah  26:85  الأية
    +/- -/+  
وَاجْعَلْنِي مِن وَرَثَةِ جَنَّةِ النَّعِيمِ
Yoruba
 
Ṣe mí ní ọ̀kan nínú àwọn olùjogún Ọgbà Ìdẹ̀ra.

Ayah  26:86  الأية
    +/- -/+  
وَاغْفِرْ لِأَبِي إِنَّهُ كَانَ مِنَ الضَّالِّينَ
Yoruba
 
Kí O sì foríjin bàbá mi. Dájúdájú ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn olùṣìnà.

Ayah  26:87  الأية
    +/- -/+  
وَلَا تُخْزِنِي يَوْمَ يُبْعَثُونَ
Yoruba
 
Má ṣe dójú tì mí ní ọjọ́ tí wọn yóò gbé ẹ̀dá dìde.

Ayah  26:88  الأية
    +/- -/+  
يَوْمَ لَا يَنفَعُ مَالٌ وَلَا بَنُونَ
Yoruba
 
Ọjọ́ tí dúkìá kan tàbí àwọn ọmọ kò níí ṣàǹfààní.

Ayah  26:89  الأية
    +/- -/+  
إِلَّا مَنْ أَتَى اللهَ بِقَلْبٍ سَلِيمٍ
Yoruba
 
Àyàfi ẹni tí ó bá dé ọ̀dọ̀ Allāhu pẹ̀lú ọkàn mímọ́."

Ayah  26:90  الأية
    +/- -/+  
وَأُزْلِفَتِ الْجَنَّةُ لِلْمُتَّقِينَ
Yoruba
 
A máa mú Ọgbà Ìdẹ̀ra súnmọ́ àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).

Ayah  26:91  الأية
    +/- -/+  
وَبُرِّزَتِ الْجَحِيمُ لِلْغَاوِينَ
Yoruba
 
Wọ́n sì máa fi iná Jẹhīm han àwọn olùṣìnà,

Ayah  26:92  الأية
    +/- -/+  
وَقِيلَ لَهُمْ أَيْنَ مَا كُنتُمْ تَعْبُدُونَ
Yoruba
 
Wọn yó sì sọ fún wọn pé: "Níbo ni n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún wà?"

Ayah  26:93  الأية
    +/- -/+  
مِن دُونِ اللهِ هَلْ يَنصُرُونَكُمْ أَوْ يَنتَصِرُونَ
Yoruba
 
(N̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún) lẹ́yìn Allāhu, ṣé wọ́n lè ràn yín lọ́wọ́ tàbí ṣé wọ́n lè ran ara wọn lọ́wọ́?

Ayah  26:94  الأية
    +/- -/+  
فَكُبْكِبُوا فِيهَا هُمْ وَالْغَاوُونَ
Yoruba
 
Wọ́n sì máa taari gbogbo wọn ṣubú sínú Iná; àwọn (olùṣìnà) àti àwọn ọ̀gá wọn (nínú ìṣìnà),

Ayah  26:95  الأية
    +/- -/+  
وَجُنُودُ إِبْلِيسَ أَجْمَعُونَ
Yoruba
 
Àti àwọn ọmọ ogun 'Iblīs pátápátá.

Ayah  26:96  الأية
    +/- -/+  
قَالُوا وَهُمْ فِيهَا يَخْتَصِمُونَ
Yoruba
 
(Àwọn aláìgbàgbọ́), nígbà tí wọ́n bá ń bá ara wọn jiyàn nínú Iná, wọ́n á wí pé:

Ayah  26:97  الأية
    +/- -/+  
تَاللهِ إِن كُنَّا لَفِي ضَلَالٍ مُّبِينٍ
Yoruba
 
"A fi Allāhu búra, dájúdájú àwa kúkú ti wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé

Ayah  26:98  الأية
    +/- -/+  
إِذْ نُسَوِّيكُم بِرَبِّ الْعَالَمِينَ
Yoruba
 
Nígbà tí a fi yín ṣe akẹgbẹ́ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

Ayah  26:99  الأية
    +/- -/+  
وَمَا أَضَلَّنَا إِلَّا الْمُجْرِمُونَ
Yoruba
 
Kò sí ohun tí ó ṣì wá lọ́nà bí kò ṣe àwọn (èṣù) ẹlẹ́ṣẹ̀.

Ayah  26:100  الأية
    +/- -/+  
فَمَا لَنَا مِن شَافِعِينَ
Yoruba
 
Kò sì sí àwọn olùṣìpẹ̀ kan fún wa mọ́.

Ayah  26:101  الأية
    +/- -/+  

Ayah  26:102  الأية
    +/- -/+  
فَلَوْ أَنَّ لَنَا كَرَّةً فَنَكُونَ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ
Yoruba
 
Tí ó bá jẹ́ pé ìpadà sí ilé ayé wà fún wa ni, nígbà náà àwa ìbá wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo."

Ayah  26:103  الأية
    +/- -/+  
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُم مُّؤْمِنِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.

Ayah  26:104  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ
Yoruba
 
Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

Ayah  26:105  الأية
    +/- -/+  
كَذَّبَتْ قَوْمُ نُوحٍ الْمُرْسَلِينَ
Yoruba
 
Ìjọ (Ànábì) Nūh pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.

Ayah  26:106  الأية
    +/- -/+  
إِذْ قَالَ لَهُمْ أَخُوهُمْ نُوحٌ أَلَا تَتَّقُونَ
Yoruba
 
Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Nūh, sọ pé: "Ṣé ẹ kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni?

Ayah  26:107  الأية
    +/- -/+  
إِنِّي لَكُمْ رَسُولٌ أَمِينٌ
Yoruba
 
Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fún yín.

Ayah  26:108  الأية
    +/- -/+  
فَاتَّقُوا اللهَ وَأَطِيعُونِ
Yoruba
 
Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.

Ayah  26:109  الأية
    +/- -/+  
وَمَا أَسْأَلُكُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ ۖ إِنْ أَجْرِيَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ الْعَالَمِينَ
Yoruba
 
Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

Ayah  26:110  الأية
    +/- -/+  
فَاتَّقُوا اللهَ وَأَطِيعُونِ
Yoruba
 
Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi."

Ayah  26:111  الأية
    +/- -/+  
قَالُوا أَنُؤْمِنُ لَكَ وَاتَّبَعَكَ الْأَرْذَلُونَ
Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "Ṣé kí á gbà ọ́ gbọ́ nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn ènìyàn yẹpẹrẹ l'ó ń tẹ̀lé ọ!?"

Ayah  26:112  الأية
    +/- -/+  
قَالَ وَمَا عِلْمِي بِمَا كَانُوا يَعْمَلُونَ
Yoruba
 
Ó sọ pé: "Èmi kò nímọ̀ sí ohun tí wọ́n ń ṣe (lẹ́yìn mi).

Ayah  26:113  الأية
    +/- -/+  
إِنْ حِسَابُهُمْ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّي ۖ لَوْ تَشْعُرُونَ
Yoruba
 
Kò sí ìṣírò-iṣẹ́ wọn lọ́dọ̀ ẹnì kan bí kò ṣe lọ́dọ̀ Olúwa mi, tí ó bá jẹ́ pé ẹ bá fura.

Ayah  26:114  الأية
    +/- -/+  
وَمَا أَنَا بِطَارِدِ الْمُؤْمِنِينَ
Yoruba
 
Èmi kò sì níí lé àwọn onígbàgbọ́ òdodo dànù.

Ayah  26:115  الأية
    +/- -/+  
إِنْ أَنَا إِلَّا نَذِيرٌ مُّبِينٌ
Yoruba
 
Èmi kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe olùkìlọ̀ pọ́nńbélé."

Ayah  26:116  الأية
    +/- -/+  
قَالُوا لَئِن لَّمْ تَنتَهِ يَا نُوحُ لَتَكُونَنَّ مِنَ الْمَرْجُومِينَ
Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "Dájúdájú tí ìwọ Nūh kò bá jáwọ́ (nibí ìpèpè rẹ) dájúdájú o máa wà nínú àwọn tí a máa jù lókò."

Ayah  26:117  الأية
    +/- -/+  
قَالَ رَبِّ إِنَّ قَوْمِي كَذَّبُونِ
Yoruba
 
Ó sọ pé: "Olúwa mi, dájúdájú àwọn ènìyàn mi ti pè mí ní òpùrọ́.

Ayah  26:118  الأية
    +/- -/+  
فَافْتَحْ بَيْنِي وَبَيْنَهُمْ فَتْحًا وَنَجِّنِي وَمَن مَّعِيَ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ
Yoruba
 
Nítorí náà, ṣèdájọ́ tààrà láààrin èmi àti àwọn. Kí o sì la èmi àti àwọn tó wà pẹ̀lú mi nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo."

Ayah  26:119  الأية
    +/- -/+  
فَأَنجَيْنَاهُ وَمَن مَّعَهُ فِي الْفُلْكِ الْمَشْحُونِ
Yoruba
 
A la òun àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ọkọ̀ ojú-omi tó kún kẹ́kẹ́.

Ayah  26:120  الأية
    +/- -/+  
ثُمَّ أَغْرَقْنَا بَعْدُ الْبَاقِينَ
Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, A tẹ àwọn tó ṣẹ́kù rì sínú omi.

Ayah  26:121  الأية
    +/- -/+  
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُم مُّؤْمِنِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.

Ayah  26:122  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ
Yoruba
 
Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

Ayah  26:123  الأية
    +/- -/+  
كَذَّبَتْ عَادٌ الْمُرْسَلِينَ
Yoruba
 
Àwọn ìran ‘Ād pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.

Ayah  26:124  الأية
    +/- -/+  
إِذْ قَالَ لَهُمْ أَخُوهُمْ هُودٌ أَلَا تَتَّقُونَ
Yoruba
 
Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Hūd, sọ pé: "Ṣé ẹ kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni?

Ayah  26:125  الأية
    +/- -/+  
إِنِّي لَكُمْ رَسُولٌ أَمِينٌ
Yoruba
 
Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fún yín.

Ayah  26:126  الأية
    +/- -/+  
فَاتَّقُوا اللهَ وَأَطِيعُونِ
Yoruba
 
Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.

Ayah  26:127  الأية
    +/- -/+  
وَمَا أَسْأَلُكُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ ۖ إِنْ أَجْرِيَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ الْعَالَمِينَ
Yoruba
 
Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

Ayah  26:128  الأية
    +/- -/+  
أَتَبْنُونَ بِكُلِّ رِيعٍ آيَةً تَعْبَثُونَ
Yoruba
 
Ṣé ẹ óò máa kọ́ ilé ńlá ńlá sí àwọn àyè gíga (kí ẹ lè) máa fi àwọn olùrékọjá ṣẹ̀fẹ̀?

Ayah  26:129  الأية
    +/- -/+  
وَتَتَّخِذُونَ مَصَانِعَ لَعَلَّكُمْ تَخْلُدُونَ
Yoruba
 
Ẹ sì ń kọ́ àwọn ilé ńlá ńlá bí ẹni pé ẹ máa ṣe gbére (nílé ayé yìí).

Ayah  26:130  الأية
    +/- -/+  
وَإِذَا بَطَشْتُم بَطَشْتُمْ جَبَّارِينَ
Yoruba
 
Nígbà tí ẹ bá sì gbá (ènìyàn mú láti fìyà jẹ wọ́n), ẹ̀ ń gbá wọn mú ní ìgbámú aláìlójú-àánú.

Ayah  26:131  الأية
    +/- -/+  
فَاتَّقُوا اللهَ وَأَطِيعُونِ
Yoruba
 
Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.

Ayah  26:132  الأية
    +/- -/+  
وَاتَّقُوا الَّذِي أَمَدَّكُم بِمَا تَعْلَمُونَ
Yoruba
 
Ẹ bẹ̀rù Ẹni tí Ó ràn yín lọ́wọ́ pẹ̀lú ohun tí ẹ mọ̀;

Ayah  26:133  الأية
    +/- -/+  
أَمَدَّكُم بِأَنْعَامٍ وَبَنِينَ
Yoruba
 
Ó ràn yín lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn ẹran-ọ̀sìn àti àwọn ọmọ,

Ayah  26:134  الأية
    +/- -/+  
وَجَنَّاتٍ وَعُيُونٍ
Yoruba
 
Àti àwọn ọgbà oko pẹ̀lú àwọn ìṣẹ́lẹ̀rú omi.

Ayah  26:135  الأية
    +/- -/+  
إِنِّي أَخَافُ عَلَيْكُمْ عَذَابَ يَوْمٍ عَظِيمٍ
Yoruba
 
Dájúdájú èmi ń páyà ìyà ọjọ́ ńlá fún yín."

Ayah  26:136  الأية
    +/- -/+  
قَالُوا سَوَاءٌ عَلَيْنَا أَوَعَظْتَ أَمْ لَمْ تَكُن مِّنَ الْوَاعِظِينَ
Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "Bákan náà ni fún wa; yálà o ṣe wáàsí fún wa tàbí o ò sí nínú àwọn oníwáàsí."

Ayah  26:137  الأية
    +/- -/+  
إِنْ هَٰذَا إِلَّا خُلُقُ الْأَوَّلِينَ
Yoruba
 
- Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ìwà àwọn ẹni àkọ́kọ́. –

Ayah  26:138  الأية
    +/- -/+  

Ayah  26:139  الأية
    +/- -/+  
فَكَذَّبُوهُ فَأَهْلَكْنَاهُمْ ۗ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُم مُّؤْمِنِينَ
Yoruba
 
Nítorí náà, wọ́n pè é ní òpùrọ́. A sì pa wọ́n run. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.

Ayah  26:140  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ
Yoruba
 
Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

Ayah  26:141  الأية
    +/- -/+  
كَذَّبَتْ ثَمُودُ الْمُرْسَلِينَ
Yoruba
 
Àwọn ìran Thamūd pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.

Ayah  26:142  الأية
    +/- -/+  
إِذْ قَالَ لَهُمْ أَخُوهُمْ صَالِحٌ أَلَا تَتَّقُونَ
Yoruba
 
Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Sọ̄lih, sọ pé: "Ṣé ẹ kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni?

Ayah  26:143  الأية
    +/- -/+  
إِنِّي لَكُمْ رَسُولٌ أَمِينٌ
Yoruba
 
Dájúdájú emi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fún yín.

Ayah  26:144  الأية
    +/- -/+  
فَاتَّقُوا اللهَ وَأَطِيعُونِ
Yoruba
 
Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.

Ayah  26:145  الأية
    +/- -/+  
وَمَا أَسْأَلُكُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ ۖ إِنْ أَجْرِيَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ الْعَالَمِينَ
Yoruba
 
Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

Ayah  26:146  الأية
    +/- -/+  
أَتُتْرَكُونَ فِي مَا هَاهُنَا آمِنِينَ
Yoruba
 
Ṣé kí wọ́n fi yín sílẹ̀ síbi n̄ǹkan tí ó wà (nílé ayé) níbí yìí (nínú ìgbádùn ayé, kí ẹ jẹ́) olùfọkànbalẹ̀

Ayah  26:147  الأية
    +/- -/+  

Ayah  26:148  الأية
    +/- -/+  
وَزُرُوعٍ وَنَخْلٍ طَلْعُهَا هَضِيمٌ
Yoruba
 
Àti oko irúgbìn pẹ̀lú igi dàbínù tí àwọn èso wọn ti gbó?

Ayah  26:149  الأية
    +/- -/+  
وَتَنْحِتُونَ مِنَ الْجِبَالِ بُيُوتًا فَارِهِينَ
Yoruba
 
Ẹ sì ń gbẹ́ àwọn ilé sínú àwọn àpáta (gẹ́gẹ́ bí) akọ́ṣẹ́-mọṣẹ́ olùgbéraga!

Ayah  26:150  الأية
    +/- -/+  
فَاتَّقُوا اللهَ وَأَطِيعُونِ
Yoruba
 
Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.

Ayah  26:151  الأية
    +/- -/+  
وَلَا تُطِيعُوا أَمْرَ الْمُسْرِفِينَ
Yoruba
 
Kí ẹ sì má ṣe tẹ̀lé àṣẹ àwọn alákọyọ (aláṣejù),

Ayah  26:152  الأية
    +/- -/+  
الَّذِينَ يُفْسِدُونَ فِي الْأَرْضِ وَلَا يُصْلِحُونَ
Yoruba
 
Àwọn tó ń ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀, tí wọn kò sì ṣe rere."

Ayah  26:153  الأية
    +/- -/+  
قَالُوا إِنَّمَا أَنتَ مِنَ الْمُسَحَّرِينَ
Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "Ìwọ kúkú wà nínú àwọn eléèdì.

Ayah  26:154  الأية
    +/- -/+  
مَا أَنتَ إِلَّا بَشَرٌ مِّثْلُنَا فَأْتِ بِآيَةٍ إِن كُنتَ مِنَ الصَّادِقِينَ
Yoruba
 
Ìwọ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe abara bí irú wa. Nítorí náà, mú àmì kan wá tí o bá wà nínú àwọn olódodo."

Ayah  26:155  الأية
    +/- -/+  
قَالَ هَٰذِهِ نَاقَةٌ لَّهَا شِرْبٌ وَلَكُمْ شِرْبُ يَوْمٍ مَّعْلُومٍ
Yoruba
 
Ó sọ pé: "Èyí ni abo ràkúnmí kan. Omi wà fún òhun, omi sì wà fún ẹ̀yin náà ní ọjọ́ tí a ti mọ̀ (ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀).

Ayah  26:156  الأية
    +/- -/+  
وَلَا تَمَسُّوهَا بِسُوءٍ فَيَأْخُذَكُمْ عَذَابُ يَوْمٍ عَظِيمٍ
Yoruba
 
Ẹ má ṣe fi aburú kan kàn án nítorí kí ìyà ọjọ́ ńlá má baà jẹ yín."

Ayah  26:157  الأية
    +/- -/+  
فَعَقَرُوهَا فَأَصْبَحُوا نَادِمِينَ
Yoruba
 
Wọ́n sì gún un pa. Nítorí náà, wọ́n sì di alábàámọ̀.

Ayah  26:158  الأية
    +/- -/+  
فَأَخَذَهُمُ الْعَذَابُ ۗ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُم مُّؤْمِنِينَ
Yoruba
 
Ìyà náà jẹ wọ́n. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.

Ayah  26:159  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ
Yoruba
 
Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

Ayah  26:160  الأية
    +/- -/+  
كَذَّبَتْ قَوْمُ لُوطٍ الْمُرْسَلِينَ
Yoruba
 
Ìjọ Lūt pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.

Ayah  26:161  الأية
    +/- -/+  
إِذْ قَالَ لَهُمْ أَخُوهُمْ لُوطٌ أَلَا تَتَّقُونَ
Yoruba
 
Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Lūt, sọ pé: "Ṣé ẹ kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni?

Ayah  26:162  الأية
    +/- -/+  
إِنِّي لَكُمْ رَسُولٌ أَمِينٌ
Yoruba
 
Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fún yín.

Ayah  26:163  الأية
    +/- -/+  
فَاتَّقُوا اللهَ وَأَطِيعُونِ
Yoruba
 
Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.

Ayah  26:164  الأية
    +/- -/+  
وَمَا أَسْأَلُكُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ ۖ إِنْ أَجْرِيَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ الْعَالَمِينَ
Yoruba
 
Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

Ayah  26:165  الأية
    +/- -/+  
أَتَأْتُونَ الذُّكْرَانَ مِنَ الْعَالَمِينَ
Yoruba
 
Ṣé àwọn ọkùnrin nínú ẹ̀dá ni ẹ̀yin ọkùnrin yóò lọ máa bá (fún adùn ìbálòpọ̀)?

Ayah  26:166  الأية
    +/- -/+  
وَتَذَرُونَ مَا خَلَقَ لَكُمْ رَبُّكُم مِّنْ أَزْوَاجِكُم ۚ بَلْ أَنتُمْ قَوْمٌ عَادُونَ
Yoruba
 
Ẹ sì ń pa ohun tí Olúwa yín dá fún yín tì nínú àwọn ìyàwó yín! Àní sẹ́, ìjọ alákọyọ ni ẹ̀yin."

Ayah  26:167  الأية
    +/- -/+  
قَالُوا لَئِن لَّمْ تَنتَهِ يَا لُوطُ لَتَكُونَنَّ مِنَ الْمُخْرَجِينَ
Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "Tí ìwọ Lūt kò bá jáwọ́ (nibí ìpèpè rẹ) dájúdájú o máa wà nínú àwọn tí a máa lé jáde kúrò nínú ìlú."

Ayah  26:168  الأية
    +/- -/+  
قَالَ إِنِّي لِعَمَلِكُم مِّنَ الْقَالِينَ
Yoruba
 
Ó sọ pé: "Dájúdájú èmi wà nínú àwọn olùbínú sí iṣẹ́ (aburú) ọwọ́ yín.

Ayah  26:169  الأية
    +/- -/+  
رَبِّ نَجِّنِي وَأَهْلِي مِمَّا يَعْمَلُونَ
Yoruba
 
Olúwa mi, la èmi àti àwọn ènìyàn mi níbí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ (aburú)."

Ayah  26:170  الأية
    +/- -/+  
فَنَجَّيْنَاهُ وَأَهْلَهُ أَجْمَعِينَ
Yoruba
 
Nítorí náà, A la òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pátápátá.

Ayah  26:171  الأية
    +/- -/+  
إِلَّا عَجُوزًا فِي الْغَابِرِينَ
Yoruba
 
Àfi arúgbóbìnrin kan tí ó wà nínú àwọn tó ṣẹ́ kù lẹ́yìn (láààrin àwọn tí A parẹ́).

Ayah  26:172  الأية
    +/- -/+  

Ayah  26:173  الأية
    +/- -/+  
وَأَمْطَرْنَا عَلَيْهِم مَّطَرًا ۖ فَسَاءَ مَطَرُ الْمُنذَرِينَ
Yoruba
 
A rọ òjò lé wọn lórí tààrà. Òjò àwọn tí A kìlọ̀ fún sì burú.

Ayah  26:174  الأية
    +/- -/+  
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُم مُّؤْمِنِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.

Ayah  26:175  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ
Yoruba
 
Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

Ayah  26:176  الأية
    +/- -/+  
كَذَّبَ أَصْحَابُ الْأَيْكَةِ الْمُرْسَلِينَ
Yoruba
 
Àwọn ará 'Aekah pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.

Ayah  26:177  الأية
    +/- -/+  
إِذْ قَالَ لَهُمْ شُعَيْبٌ أَلَا تَتَّقُونَ
Yoruba
 
Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Ṣu‘aeb, sọ pé: "Ṣé ẹ̀yin kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni?

Ayah  26:178  الأية
    +/- -/+  
إِنِّي لَكُمْ رَسُولٌ أَمِينٌ
Yoruba
 
Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fún yín.

Ayah  26:179  الأية
    +/- -/+  
فَاتَّقُوا اللهَ وَأَطِيعُونِ
Yoruba
 
Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.

Ayah  26:180  الأية
    +/- -/+  
وَمَا أَسْأَلُكُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ ۖ إِنْ أَجْرِيَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ الْعَالَمِينَ
Yoruba
 
Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

Ayah  26:181  الأية
    +/- -/+  
أَوْفُوا الْكَيْلَ وَلَا تَكُونُوا مِنَ الْمُخْسِرِينَ
Yoruba
 
Ẹ wọn òṣùwọ̀n kún. Kí ẹ sì má ṣe wà nínú àwọn tó ń dín òṣùwọ̀n kù.

Ayah  26:182  الأية
    +/- -/+  
وَزِنُوا بِالْقِسْطَاسِ الْمُسْتَقِيمِ
Yoruba
 
Ẹ fi ìwọ̀n tó tọ́ wọn n̄ǹkan.

Ayah  26:183  الأية
    +/- -/+  
وَلَا تَبْخَسُوا النَّاسَ أَشْيَاءَهُمْ وَلَا تَعْثَوْا فِي الْأَرْضِ مُفْسِدِينَ
Yoruba
 
Ẹ má ṣe dín n̄ǹkan àwọn ènìyàn kù. Kí ẹ sì má ṣèbàjẹ́ sórí ilẹ̀.

Ayah  26:184  الأية
    +/- -/+  
وَاتَّقُوا الَّذِي خَلَقَكُمْ وَالْجِبِلَّةَ الْأَوَّلِينَ
Yoruba
 
Kí ẹ sì bẹ̀rù Ẹni tí Ó dá yín àti àwọn ẹ̀dá àkọ́kọ́."

Ayah  26:185  الأية
    +/- -/+  
قَالُوا إِنَّمَا أَنتَ مِنَ الْمُسَحَّرِينَ
Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "Ìwọ kúkú wà nínú àwọn eléèdì.

Ayah  26:186  الأية
    +/- -/+  
وَمَا أَنتَ إِلَّا بَشَرٌ مِّثْلُنَا وَإِن نَّظُنُّكَ لَمِنَ الْكَاذِبِينَ
Yoruba
 
Ìwọ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe abara bí irú wa. Àti pé a kò rò ọ́ sí kiní kan bí kò ṣe pé o wà nínú àwọn òpùrọ́.

Ayah  26:187  الأية
    +/- -/+  
فَأَسْقِطْ عَلَيْنَا كِسَفًا مِّنَ السَّمَاءِ إِن كُنتَ مِنَ الصَّادِقِينَ
Yoruba
 
Nítorí náà, jẹ́ kí apá kan nínú sánmọ̀ ya lù wá mọ́lẹ̀, tí o bá wà nínú àwọn olódodo."

Ayah  26:188  الأية
    +/- -/+  
قَالَ رَبِّي أَعْلَمُ بِمَا تَعْمَلُونَ
Yoruba
 
Ó sọ pé: "Olúwa mi nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

Ayah  26:189  الأية
    +/- -/+  
فَكَذَّبُوهُ فَأَخَذَهُمْ عَذَابُ يَوْمِ الظُّلَّةِ ۚ إِنَّهُ كَانَ عَذَابَ يَوْمٍ عَظِيمٍ
Yoruba
 
Wọ́n sì pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, ìyà ọjọ́ ẹ̀ṣújò sì jẹ wọ́n. Dájúdájú ó jẹ́ ìyà ọjọ́ ńlá.

Ayah  26:190  الأية
    +/- -/+  
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُم مُّؤْمِنِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.

Ayah  26:191  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ
Yoruba
 
Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

Ayah  26:192  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّهُ لَتَنزِيلُ رَبِّ الْعَالَمِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú al-Ƙur'ān, wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

Ayah  26:193  الأية
    +/- -/+  
نَزَلَ بِهِ الرُّوحُ الْأَمِينُ
Yoruba
 
Mọlāika Jibrīl, olùfọkàntán l'ó sọ̀ ọ́ kalẹ̀

Ayah  26:194  الأية
    +/- -/+  
عَلَىٰ قَلْبِكَ لِتَكُونَ مِنَ الْمُنذِرِينَ
Yoruba
 
Sínú ọkàn rẹ nítorí kí o lè wà nínú àwọn olùkìlọ̀

Ayah  26:195  الأية
    +/- -/+  
بِلِسَانٍ عَرَبِيٍّ مُّبِينٍ
Yoruba
 
Pẹ̀lú èdè Lárúbáwá pọ́nńbélé.

Ayah  26:196  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّهُ لَفِي زُبُرِ الْأَوَّلِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú (ọ̀rọ̀ nípa rẹ̀) wà nínú ìpín-ìpín Tírà àwọn ẹni àkọ́kọ́.

Ayah  26:197  الأية
    +/- -/+  
أَوَلَمْ يَكُن لَّهُمْ آيَةً أَن يَعْلَمَهُ عُلَمَاءُ بَنِي إِسْرَائِيلَ
Yoruba
 
Ṣé kò jẹ́ àmì kan fún wọn pé àwọn onímọ̀ (nínú) àwọn ọmọ 'Isrọ̄'īl nímọ̀ (sí àsọọ́lẹ̀ nípa) rẹ̀ (nínú tírà ọwọ́ wọn)?

Ayah  26:198  الأية
    +/- -/+  
وَلَوْ نَزَّلْنَاهُ عَلَىٰ بَعْضِ الْأَعْجَمِينَ
Yoruba
 
Tí ó bá jẹ́ pé A sọ̀ ọ́ kalẹ̀ fún apá kan àwọn elédè mìíràn ni,

Ayah  26:199  الأية
    +/- -/+  
فَقَرَأَهُ عَلَيْهِم مَّا كَانُوا بِهِ مُؤْمِنِينَ
Yoruba
 
Tí ó sì ké e fún wọn, wọn kò níí gbà á gbọ́ ní òdodo.

Ayah  26:200  الأية
    +/- -/+  
كَذَٰلِكَ سَلَكْنَاهُ فِي قُلُوبِ الْمُجْرِمِينَ
Yoruba
 
Báyẹn ni A ṣe mú (àtakò) wọ inú ọkàn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.

Ayah  26:201  الأية
    +/- -/+  
لَا يُؤْمِنُونَ بِهِ حَتَّىٰ يَرَوُا الْعَذَابَ الْأَلِيمَ
Yoruba
 
Wọn kò níí gbà á gbọ́ ní òdodo títí wọn yóò fi rí ìyà ẹlẹ́ta-eléro.

Ayah  26:202  الأية
    +/- -/+  
فَيَأْتِيَهُم بَغْتَةً وَهُمْ لَا يَشْعُرُونَ
Yoruba
 
(Ìyà náà) yóò dé bá wọn ní òjijì; wọn kò sì níí fura.

Ayah  26:203  الأية
    +/- -/+  
فَيَقُولُوا هَلْ نَحْنُ مُنظَرُونَ
Yoruba
 
Nígbà náà ni wọn yóò wí pé: "Ǹjẹ́ wọ́n lè lọ́ wa lára bí?"

Ayah  26:204  الأية
    +/- -/+  
أَفَبِعَذَابِنَا يَسْتَعْجِلُونَ
Yoruba
 
Ṣé ìyà Wa ni wọ́n ń wá pẹ̀lú ìkánjú?

Ayah  26:205  الأية
    +/- -/+  
أَفَرَأَيْتَ إِن مَّتَّعْنَاهُمْ سِنِينَ
Yoruba
 
Sọ fún Mi tí A bá fún wọn ní ìgbádùn ayé fún ọdún gbọọrọ!

Ayah  26:206  الأية
    +/- -/+  
ثُمَّ جَاءَهُم مَّا كَانُوا يُوعَدُونَ
Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, kí ohun tí À ń ṣe ní ìlérí fún wọn dé bá wọn.

Ayah  26:207  الأية
    +/- -/+  
مَا أَغْنَىٰ عَنْهُم مَّا كَانُوا يُمَتَّعُونَ
Yoruba
 
Ohun tí A ṣe ní ìgbádùn fún wọn kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀.

Ayah  26:208  الأية
    +/- -/+  
وَمَا أَهْلَكْنَا مِن قَرْيَةٍ إِلَّا لَهَا مُنذِرُونَ
Yoruba
 
A ò sì pa ìlú kan run àfi kí wọ́n ti ní àwọn olùkìlọ̀.

Ayah  26:209  الأية
    +/- -/+  
ذِكْرَىٰ وَمَا كُنَّا ظَالِمِينَ
Yoruba
 
Ìrántí (dé fún wọn sẹ́). Àti pé Àwa kì í ṣe alábòsí.

Ayah  26:210  الأية
    +/- -/+  
وَمَا تَنَزَّلَتْ بِهِ الشَّيَاطِينُ
Yoruba
 
Kì í ṣe àwọn èṣù ni wọ́n sọ (al-Ƙur'ān) kalẹ̀.

Ayah  26:211  الأية
    +/- -/+  
وَمَا يَنبَغِي لَهُمْ وَمَا يَسْتَطِيعُونَ
Yoruba
 
Kò yẹ fún wọn. Wọn kò sì lágbára rẹ̀.

Ayah  26:212  الأية
    +/- -/+  
إِنَّهُمْ عَنِ السَّمْعِ لَمَعْزُولُونَ
Yoruba
 
Dájúdájú A ti mú wọn takété sí gbígbọ́ rẹ̀ (láti ojú sánmọ̀).

Ayah  26:213  الأية
    +/- -/+  
فَلَا تَدْعُ مَعَ اللهِ إِلَٰهًا آخَرَ فَتَكُونَ مِنَ الْمُعَذَّبِينَ
Yoruba
 
Nítorí náà, má ṣe pe ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu, nítorí kí ìwọ má baà wà nínú àwọn tí A máa jẹ níyà.

Ayah  26:214  الأية
    +/- -/+  
وَأَنذِرْ عَشِيرَتَكَ الْأَقْرَبِينَ
Yoruba
 
Kí o sì kìlọ̀ fún àwọn ẹbí rẹ tó súnmọ́ jùlọ.

Ayah  26:215  الأية
    +/- -/+  
وَاخْفِضْ جَنَاحَكَ لِمَنِ اتَّبَعَكَ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ
Yoruba
 
Kí o sì rẹ apá rẹ nílẹ̀ fún àwọn tó tẹ̀lé ọ nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

Ayah  26:216  الأية
    +/- -/+  
فَإِنْ عَصَوْكَ فَقُلْ إِنِّي بَرِيءٌ مِّمَّا تَعْمَلُونَ
Yoruba
 
Tí wọ́n bá sì yapa (àṣẹ) rẹ, sọ pé: "Dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń ṣe (níṣẹ́ aburú)."

Ayah  26:217  الأية
    +/- -/+  
وَتَوَكَّلْ عَلَى الْعَزِيزِ الرَّحِيمِ
Yoruba
 
Kí o sì gbáralé Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run;

Ayah  26:218  الأية
    +/- -/+  
الَّذِي يَرَاكَ حِينَ تَقُومُ
Yoruba
 
Ẹni tó ń rí ọ nígbà tí ò ń dìde nàró (fún ìrun kíkí)

Ayah  26:219  الأية
    +/- -/+  
وَتَقَلُّبَكَ فِي السَّاجِدِينَ
Yoruba
 
Àti ìyírapadà rẹ (fún rukuu àti ìforíkanlẹ̀) láààrin àwọn olùforíkanlẹ̀.

Ayah  26:220  الأية
    +/- -/+  
إِنَّهُ هُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ
Yoruba
 
Dájúdájú Òun mà ni Olùgbọ́, Onímọ̀.

Ayah  26:221  الأية
    +/- -/+  
هَلْ أُنَبِّئُكُمْ عَلَىٰ مَن تَنَزَّلُ الشَّيَاطِينُ
Yoruba
 
Ṣé kí n̄g sọ ẹni tí àwọn èṣù ń sọ̀kalẹ̀ wá bá fún yín?

Ayah  26:222  الأية
    +/- -/+  
تَنَزَّلُ عَلَىٰ كُلِّ أَفَّاكٍ أَثِيمٍ
Yoruba
 
Wọ́n ń sọ̀kalẹ̀ wá bá gbogbo àwọn òpùrọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀.

Ayah  26:223  الأية
    +/- -/+  
يُلْقُونَ السَّمْعَ وَأَكْثَرُهُمْ كَاذِبُونَ
Yoruba
 
(Àwọn èṣù) ń dẹtí (sí ìró sánmọ̀). Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì ni òpùrọ́.

Ayah  26:224  الأية
    +/- -/+  
وَالشُّعَرَاءُ يَتَّبِعُهُمُ الْغَاوُونَ
Yoruba
 
Àwọn eléwì, àwọn olùṣìnà l'ó ń tẹ̀lé wọn.

Ayah  26:225  الأية
    +/- -/+  
أَلَمْ تَرَ أَنَّهُمْ فِي كُلِّ وَادٍ يَهِيمُونَ
Yoruba
 
Ṣé o ò rí i pé gbogbo ọ̀gbun ọ̀rọ̀ ni wọ́n ń tẹnu bọ̀ ni?

Ayah  26:226  الأية
    +/- -/+  
وَأَنَّهُمْ يَقُولُونَ مَا لَا يَفْعَلُونَ
Yoruba
 
Àti pé dájúdájú wọ́n ń sọ ohun tí wọn kò níí ṣe.

Ayah  26:227  الأية
    +/- -/+  
إِلَّا الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ وَذَكَرُوا اللهَ كَثِيرًا وَانتَصَرُوا مِن بَعْدِ مَا ظُلِمُوا ۗ وَسَيَعْلَمُ الَّذِينَ ظَلَمُوا أَيَّ مُنقَلَبٍ يَنقَلِبُونَ
Yoruba
 
Àfi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe iṣẹ́ rere, tí wọ́n rántí Allāhu ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀, tí wọ́n sì jàjà gbara lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣàbòsí sí wọn. Àwọn tó ṣàbòsí sì máa mọ irú ìkángun tí wọ́n máa gúnlẹ̀ sí.
 


© EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us