Àwọn tó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, dájúdájú A máa ha àwọn iṣẹ́ aburú wọn dànù fún wọn. Dájúdájú A ó sì san wọ́n lẹ́san pẹ̀lú èyí tó dára ju ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
A pa á ní àṣẹ fún ènìyàn láti ṣe dáadáa sí àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì. Tí àwọn méjèèjì bá sì jà ọ́ lógun pé kí ó fi ohun tí ìwọ kò ní ìmọ̀ nípa rẹ̀ ṣẹbọ sí Mi, má ṣe tẹ̀lé àwọn méjèèjì. Ọ̀dọ̀ Mi ni ibùpadàsí yín. Nítorí náà, Mo máa fún yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Wọ́n pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, ohùn igbe líle tó mi ilẹ̀ tìtì gbá wọn mú. Wọ́n sì di ẹni tó dà lulẹ̀, tí wọ́n ti dòkú sínú ìlú wọn.
A sì mú ìkọ̀ọ̀kan wọn nípa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ó wà nínú wọn, ẹni tí A fi òkúta iná ránṣẹ́ sí. Ó wà nínú wọn ẹni tí igbe líle gbá mú. Ó wà nínú wọn ẹni tí A jẹ́ kí ilẹ̀ ríri gbé e mì. Ó sì wà nínú wọn ẹni tí A tẹ̀rì sínú omi. Allāhu kò sì níí ṣàbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí.
Wọ́n sì wí pé: "Nítorí kí ni Wọn kò ṣe sọ àwọn àmì (ìyanu) kan kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀?" Sọ pé: "Allāhu nìkan ni àwọn àmì (ìyanu) wà lọ́dọ̀ Rẹ̀. Àti pé olùkìlọ̀ pọ́nńbélé ni èmi."
Tí o bá bi wọ́n léèrè pé: "Ta ni Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, tí Ó sì rọ òòrùn àti òṣùpá?", dájúdájú wọ́n á wí pé: "Allāhu ni." Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo?
Tí o bá bi wọ́n léèrè pé: "Ta ni Ó sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀, tí Ó fi ta ilẹ̀ jí lẹ́yìn tí ó ti kú?", dájúdájú wọ́n á wí pé: "Allāhu ni." Sọ pé: "Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò ṣe làákàyè."
Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú Àwa ṣe Haram (Mọkkah) ni àyè ìfàyàbalẹ̀, tí wọ́n sì ń jí àwọn ènìyàn gbé lọ ní àyíká wọn? Ṣé irọ́ (òrìṣà) ni wọn yóò gbàgbọ́, tí wọn yó sì ṣàì moore sí ìdẹ̀ra Allāhu?