Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, àwọn dúkìá wọn àti àwọn ọmọ wọn kò níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kiní kan lọ́dọ̀ Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni n̄ǹkan ìkoná.
Ibẹ̀yẹn ni Zakariyyā ti pe Olúwa rẹ̀. Ó sọ pé: "Olúwa mi, ta mí ní ọrẹ àrọ́mọdọ́mọ dáadáa láti ọ̀dọ̀ Rẹ. Dájúdájú Ìwọ ni Olùgbọ́-àdúà."
(Zakariyyā) sọ pé: "Olúwa mi, báwo ni èmi yóò ṣe ní ọmọkùnrin; mo mà ti dàgbàlágbà, àgàn sì ni obìnrin mi?" (Mọlāika) sọ pé: "Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣe ohun tí Ó bá fẹ́."
Ìyẹn wà nínú ìró ìkọ̀kọ̀ tí À ń fi ìmísí rẹ̀ ránṣẹ́ sí ọ. Ìwọ kò kúkú sí lọ́dọ̀ wọn nígbà tí wọ́n ń ju gègé wọn (sínú odò láti mọ) ta ni nínú wọn ni ó máa gba Mọryam wò. Ìwọ kò sì sí lọ́dọ̀ wọn nígbà tí wọ́n ń ṣe ìfàn̄fà (lórí rẹ̀).
(Mọryam) sọ pé: "Olúwa mi báwo ni èmi yó ṣe ní ọmọkùnrin, (nígbà tí) abara kan kò fọwọ́ kàn mí." Ó sọ pé: Báyẹn ni Allāhu ṣe ń dá ohun tí Ó bá fẹ́. Nígbà tí Ó bá (gbèrò) láti dá ẹ̀dá kan ohun tí Ó máa sọ fún un ni pé: "Jẹ́ bẹ́ẹ̀." Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀.
Mo sì ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó ṣíwájú mi nínú at-Taorāh nítorí kí èmi lè ṣe apá kan èyí tí wọ́n ṣe ní èèwọ̀ fún yín ní ẹ̀tọ́ fún yín. Mo ti mú àmì kan wá fún yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
Nígbà tí (Ànábì) ‘Īsā fura sí àìgbàgbọ́ lọ́dọ̀ wọn (pé wọ́n fẹ́ pa òun), ó sọ pé: "Ta ni olùrànlọ́wọ́ mi sí ọ̀dọ̀ Allāhu?" Àwọn ọmọlẹ́yìn (rẹ̀) sọ pé: "Àwa ni olùrànlọ́wọ́ fún (ẹ̀sìn) Allāhu. A gba Allāhu gbọ́. Kí o sì jẹ́rìí pé dájúdájú mùsùlùmí ni wá.
Ó ń bẹ nínú àwọn onítírà, ẹni tí ó jẹ́ pé tí o bá fi ọkàn tán an pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ owó, ó máa dá a padà fún ọ. Ó sì ń bẹ nínú wọn, ẹni tí ó jẹ́ pé tí o bá fi ọkàn tán an pẹ̀lú owó dinar kan (owó kékeré), kò níí dá a padà fún ọ àyàfi tí o bá dógò tì í lọ́rùn. Ìyẹn nítorí pé wọ́n wí pé: "Wọn kò lè fí ọ̀nà kan kan bá wa wí nítorí àwọn aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà." Ńṣe ni wọ́n ń pa irọ́ mọ́ Allāhu, wọ́n sì mọ̀.
Ṣé ẹ̀sìn mìíràn yàtọ̀ sí ẹ̀sìn Allāhu ni wọ́n ń wá ni? Nígbà tí ó jẹ́ pé tiRẹ̀ ni gbogbo ẹni tí ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ fún, wọ́n fẹ́ wọ́n kọ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni Wọ́n máa dá wọn padà sí.
Sọ pé: "A gbàgbọ́ nínú Allāhu àti ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún wa àti ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún (Ànábì) 'Ibrọ̄hīm, 'Ismọ̄‘īl, 'Ishāƙ, Ya‘ƙūb, àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ (rẹ̀. A gbàgbọ́ nínú) ohun tí wọ́n fún (Ànábì) Mūsā àti ‘Īsā àti àwọn Ànábì láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn; A kò ya ẹnì kan kan sọ́tọ̀ nínú wọn. Àwa sì ni mùsùlùmí (olùjuwọ́-jusẹ̀-sílẹ̀) fún Un."
Olùṣegbére ni wọ́n nínú ègún. Nítorí náà, A ò níí ṣe ìyà náà ní fífúyẹ́ fún wọn, A ò sì níí fún wọn ní ìsinmi (nínú Iná).
Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì kú nígbà tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́, A ò níí gba ẹ̀kún ilẹ̀ wúrà lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni nínú wọn, ìbáà fi ṣèràpadà (fún ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Iná). Àwọn wọ̀nyẹn ni ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún. Kò sì níí sí àwọn olùrànlọ́wọ́ fún wọn.
Báwo ni ẹ̀yin ṣe lè ṣàì gbàgbọ́, ẹ̀yin mà ni wọ́n ń ké àwọn āyah Allāhu fún, Òjíṣẹ́ Rẹ̀ sì wà láààrin yín! Ẹnikẹ́ni tí ó bá dúró ṣinṣin ti Allāhu, A ti tọ́ ọ sí ọ̀nà tààrà.
Kí ó máa bẹ nínú yín, ìjọ kan tí yóò máa pèpè síbi ohun tó lóore, wọn yóò máa pàṣẹ ohun rere, wọn yó sì máa kọ ohun burúkú. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùjèrè.
Wọn kò níí kó ìnira ba yín àyàfi ìpalára díẹ̀. Tí wọ́n bá sì ba yín jà, wọ́n á sá fún yín. Lẹ́yìn náà, A ò níí ràn wọ́n lọ́wọ́.
Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, àwọn dúkìá wọn àti àwọn ọmọ wọn kò níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kiní kan (níbi ìyà) lọ́dọ̀ Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.
Àpèjúwe ohun tí wọ́n ń ná nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí dà bí àpèjúwe afẹ́fẹ́ tí atẹ́gùn òtútù líle wà nínú rẹ̀. Ó fẹ́ lu oko àwọn ènìyàn tó ṣe àbòsí s'órí ara wọn. Ó sì pa á run. Allāhu kò sì ṣe àbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí.