Prev  

35. Surah Fâtir or Al­Malâ'ikah سورة فاطر

  Next  




Ayah  35:1  الأية
    +/- -/+  
بِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
الْحَمْدُ لِلَّهِ فَاطِرِ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ جَاعِلِ الْمَلَائِكَةِ رُسُلًا أُولِي أَجْنِحَةٍ مَّثْنَىٰ وَثُلَاثَ وَرُبَاعَ ۚ يَزِيدُ فِي الْخَلْقِ مَا يَشَاءُ ۚ إِنَّ اللهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
Yoruba
 
Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Olùpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, (Ẹni tí) Ó ṣe àwọn mọlāika alápá méjì àti mẹ́ta àti mẹ́rin ní Òjíṣẹ́. Ó ń ṣe àlékún ohun tí Ó bá fẹ́ lára ẹ̀dá. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.

Ayah  35:2  الأية
    +/- -/+  
مَّا يَفْتَحِ اللهُ لِلنَّاسِ مِن رَّحْمَةٍ فَلَا مُمْسِكَ لَهَا ۖ وَمَا يُمْسِكْ فَلَا مُرْسِلَ لَهُ مِن بَعْدِهِ ۚ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ
Yoruba
 
Ohunkóhun tí Allāhu bá ṣí ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀ nínú ìkẹ́ fún àwọn ènìyàn, kò sí ẹni tí ó lè dì í mọ́wọ́ (láti dá a dúró). Ohunkóhun tí Ó bá sì mú dání, kò sí ẹni tí ó lè mú un wá lẹ́yìn Rẹ̀. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

Ayah  35:3  الأية
    +/- -/+  
يَا أَيُّهَا النَّاسُ اذْكُرُوا نِعْمَتَ اللهِ عَلَيْكُمْ ۚ هَلْ مِنْ خَالِقٍ غَيْرُ اللهِ يَرْزُقُكُم مِّنَ السَّمَاءِ وَالْأَرْضِ ۚ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ۖ فَأَنَّىٰ تُؤْفَكُونَ
Yoruba
 
Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ rántí ìdẹ̀ra Allāhu lórí yín. Ǹjẹ́ ẹ̀lẹ́dàá kan yàtọ̀ sí Allāhu tún wà tí ó ń pèsè fún yín láti inú sánmọ̀ àti ilẹ̀? Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ yín lórí kúrò níbi òdodo?

Ayah  35:4  الأية
    +/- -/+  
وَإِن يُكَذِّبُوكَ فَقَدْ كُذِّبَتْ رُسُلٌ مِّن قَبْلِكَ ۚ وَإِلَى اللهِ تُرْجَعُ الْأُمُورُ
Yoruba
 
Tí wọ́n bá pè ọ́ ní òpùrọ́, wọ́n kúkú ti pe àwọn Òjíṣẹ́ kan ní òpùrọ́ ṣíwájú rẹ. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí.

Ayah  35:5  الأية
    +/- -/+  
يَا أَيُّهَا النَّاسُ إِنَّ وَعْدَ اللهِ حَقٌّ ۖ فَلَا تَغُرَّنَّكُمُ الْحَيَاةُ الدُّنْيَا ۖ وَلَا يَغُرَّنَّكُم بِاللهِ الْغَرُورُ
Yoruba
 
Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìṣẹ̀mí ayé tàn yín jẹ. Kí ẹ sì má ṣe jẹ́ kí (Èṣù) ẹlẹ́tàn tàn yín jẹ.

Ayah  35:6  الأية
    +/- -/+  
إِنَّ الشَّيْطَانَ لَكُمْ عَدُوٌّ فَاتَّخِذُوهُ عَدُوًّا ۚ إِنَّمَا يَدْعُو حِزْبَهُ لِيَكُونُوا مِنْ أَصْحَابِ السَّعِيرِ
Yoruba
 
Dájúdájú Èṣù ni ọ̀tá fún yín. Nítorí náà, ẹ mú un ní ọ̀tá. Ó kàn ń pe àwọn ìjọ rẹ̀ nítorí kí wọ́n lè jẹ́ èrò inú Iná tó ń jó.

Ayah  35:7  الأية
    +/- -/+  
الَّذِينَ كَفَرُوا لَهُمْ عَذَابٌ شَدِيدٌ ۖ وَالَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ لَهُم مَّغْفِرَةٌ وَأَجْرٌ كَبِيرٌ
Yoruba
 
Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, ìyà líle ń bẹ fún wọn. Àwọn tó sì gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe iṣẹ́ rere, àforíjìn àti ẹ̀san tó tóbi ń bẹ fún wọn.

Ayah  35:8  الأية
    +/- -/+  
أَفَمَن زُيِّنَ لَهُ سُوءُ عَمَلِهِ فَرَآهُ حَسَنًا ۖ فَإِنَّ اللهَ يُضِلُّ مَن يَشَاءُ وَيَهْدِي مَن يَشَاءُ ۖ فَلَا تَذْهَبْ نَفْسُكَ عَلَيْهِمْ حَسَرَاتٍ ۚ إِنَّ اللهَ عَلِيمٌ بِمَا يَصْنَعُونَ
Yoruba
 
Ṣé ẹni tí wọ́n ṣe iṣẹ́ aburú ọwọ́ rẹ̀ ní ọ̀ṣọ́ fún, tí ó sì ń rí i ní (iṣẹ́) dáadáa, (l'o fẹ́ máa banújẹ́ nítorí rẹ̀?) Dájúdájú Allāhu ń ṣi ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́nà. Ó sì ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí Ó bá fẹ́. Nítorí náà, má ṣe fi ìbanújẹ́ pa ara rẹ̀ nítorí tiwọn. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

Ayah  35:9  الأية
    +/- -/+  
وَاللهُ الَّذِي أَرْسَلَ الرِّيَاحَ فَتُثِيرُ سَحَابًا فَسُقْنَاهُ إِلَىٰ بَلَدٍ مَّيِّتٍ فَأَحْيَيْنَا بِهِ الْأَرْضَ بَعْدَ مَوْتِهَا ۚ كَذَٰلِكَ النُّشُورُ
Yoruba
 
Allāhu ni Ẹni tí Ó fi àwọn atẹ́gùn ránṣẹ́. (Atẹ́gùn náà) sì máa tú ẹ̀ṣújò sókè. A sì fi fún ìlú (tí ilẹ̀ rẹ̀) ti kú lómi mu. A sì fi ta ilẹ̀ náà jí lẹ́yìn tí ó ti kú. Báyẹn ni àjíǹde (ẹ̀dá yó ṣe rí).

Ayah  35:10  الأية
    +/- -/+  
مَن كَانَ يُرِيدُ الْعِزَّةَ فَلِلَّهِ الْعِزَّةُ جَمِيعًا ۚ إِلَيْهِ يَصْعَدُ الْكَلِمُ الطَّيِّبُ وَالْعَمَلُ الصَّالِحُ يَرْفَعُهُ ۚ وَالَّذِينَ يَمْكُرُونَ السَّيِّئَاتِ لَهُمْ عَذَابٌ شَدِيدٌ ۖ وَمَكْرُ أُولَٰئِكَ هُوَ يَبُورُ
Yoruba
 
Ẹní tí ó bá ń fẹ́ iyì dájúdájú ti Allāhu ni gbogbo iyì pátápátá. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni ọ̀rọ̀ dáadáa ń gòkè lọ. Ó sì ń gbé iṣẹ́ rere gòkè (sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀). Àwọn tí wọ́n ń pète àwọn aburú, ìyà líle ń bẹ fún wọn. Ète àwọn wọ̀nyẹn sì máa parun.

Ayah  35:11  الأية
    +/- -/+  
وَاللهُ خَلَقَكُم مِّن تُرَابٍ ثُمَّ مِن نُّطْفَةٍ ثُمَّ جَعَلَكُمْ أَزْوَاجًا ۚ وَمَا تَحْمِلُ مِنْ أُنثَىٰ وَلَا تَضَعُ إِلَّا بِعِلْمِهِ ۚ وَمَا يُعَمَّرُ مِن مُّعَمَّرٍ وَلَا يُنقَصُ مِنْ عُمُرِهِ إِلَّا فِي كِتَابٍ ۚ إِنَّ ذَٰلِكَ عَلَى اللهِ يَسِيرٌ
Yoruba
 
Allāhu da yín láti ara erùpẹ̀. Lẹ́yìn náà, (Ó tún da yín) láti ara àtọ̀. Lẹ́yìn náà, Ó ṣe yín ní akọ-abo. Obìnrin kan kò níí lóyún, kò sì níí bímọ àfi pẹ̀lú ìmọ̀ Rẹ̀. Àti pé A kò níí fa ẹ̀mí ẹlẹ́mìí-gígùn gùn, A kò sì ní ṣe àdínkù nínú ọjọ́ orí (ẹlòmíìràn), àfi kí ó ti wà nínú tírà kan. Dájúdájú ìyẹn rọrùn fún Allāhu.

Ayah  35:12  الأية
    +/- -/+  
وَمَا يَسْتَوِي الْبَحْرَانِ هَٰذَا عَذْبٌ فُرَاتٌ سَائِغٌ شَرَابُهُ وَهَٰذَا مِلْحٌ أُجَاجٌ ۖ وَمِن كُلٍّ تَأْكُلُونَ لَحْمًا طَرِيًّا وَتَسْتَخْرِجُونَ حِلْيَةً تَلْبَسُونَهَا ۖ وَتَرَى الْفُلْكَ فِيهِ مَوَاخِرَ لِتَبْتَغُوا مِن فَضْلِهِ وَلَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ
Yoruba
 
Àwọn odò méjì náà kò dọ́gba; èyí ni (omi) dídùn gan-an, tí mímu rẹ̀ ń lọ tìnrín ní ọ̀fun. Èyí sì ni (omi) iyọ̀ tó móró. Àti pé nínú gbogbo (omi odò wọ̀nyí) l'ẹ ti ń jẹ ẹran (odò àti ẹja) tútù. Ẹ sì ń wa kùsà àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tí ẹ̀ ń wọ̀ (sára). O sì ń rí àwọn ọkọ̀ ojú-omi tó ń la ààrin omi kọjá nítorí kí ẹ lè wá nínú oore Allāhu àti nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Un).

Ayah  35:13  الأية
    +/- -/+  
يُولِجُ اللَّيْلَ فِي النَّهَارِ وَيُولِجُ النَّهَارَ فِي اللَّيْلِ وَسَخَّرَ الشَّمْسَ وَالْقَمَرَ كُلٌّ يَجْرِي لِأَجَلٍ مُّسَمًّى ۚ ذَٰلِكُمُ اللهُ رَبُّكُمْ لَهُ الْمُلْكُ ۚ وَالَّذِينَ تَدْعُونَ مِن دُونِهِ مَا يَمْلِكُونَ مِن قِطْمِيرٍ
Yoruba
 
(Allāhu) ń ti òru bọ inú ọ̀sán. Ó sì ń ti ọ̀sán bọ inú òru. Ó rọ òòrùn àti òṣùpá; ìkọ̀ọ̀kan wọn máa rìn fún gbèdéke àkókò kan. Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín. TiRẹ̀ ni ìjọba. Àwọn tí ẹ sì ń pè lẹ́yìn Rẹ̀, wọn kò ní ìkápá kan lórí èpo kóró inú dàbínù.

Ayah  35:14  الأية
    +/- -/+  
إِن تَدْعُوهُمْ لَا يَسْمَعُوا دُعَاءَكُمْ وَلَوْ سَمِعُوا مَا اسْتَجَابُوا لَكُمْ ۖ وَيَوْمَ الْقِيَامَةِ يَكْفُرُونَ بِشِرْكِكُمْ ۚ وَلَا يُنَبِّئُكَ مِثْلُ خَبِيرٍ
Yoruba
 
Tí ẹ bá pè wọ́n, wọn kò lè gbọ́ ìpè yín. Tí ó bá sì jẹ́ pé wọ́n gbọ́, wọn kò lè da yín lóhùn. Àti pé ní Ọjọ́ Àjíǹde, wọn yóò tako bí ẹ ṣe fi wọ́n ṣe akẹgbẹ́ fún Allāhu. Kò sì sí ẹni tí ó lè fún ọ ní ìró kan (nípa ẹ̀dá ju) irú (ìró tí) Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ (fún ọ nípa wọn).

Ayah  35:15  الأية
    +/- -/+  
يَا أَيُّهَا النَّاسُ أَنتُمُ الْفُقَرَاءُ إِلَى اللهِ ۖ وَاللهُ هُوَ الْغَنِيُّ الْحَمِيدُ
Yoruba
 
Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ̀yin ni aláìní (tí ẹ ní bùkátà) sí Allāhu. Allāhu, Òun ni Ọlọ́rọ̀, Ẹlẹ́yìn.

Ayah  35:16  الأية
    +/- -/+  
إِن يَشَأْ يُذْهِبْكُمْ وَيَأْتِ بِخَلْقٍ جَدِيدٍ
Yoruba
 
Tí Ó bá fẹ́, Ó máa mu yín kúrò lórí ilẹ̀. Ó sì máa mú ẹ̀dá titun wá.

Ayah  35:17  الأية
    +/- -/+  
وَمَا ذَٰلِكَ عَلَى اللهِ بِعَزِيزٍ
Yoruba
 
Ìyẹn kò sì lágbara kan lára Allāhu.

Ayah  35:18  الأية
    +/- -/+  
وَلَا تَزِرُ وَازِرَةٌ وِزْرَ أُخْرَىٰ ۚ وَإِن تَدْعُ مُثْقَلَةٌ إِلَىٰ حِمْلِهَا لَا يُحْمَلْ مِنْهُ شَيْءٌ وَلَوْ كَانَ ذَا قُرْبَىٰ ۗ إِنَّمَا تُنذِرُ الَّذِينَ يَخْشَوْنَ رَبَّهُم بِالْغَيْبِ وَأَقَامُوا الصَّلَاةَ ۚ وَمَن تَزَكَّىٰ فَإِنَّمَا يَتَزَكَّىٰ لِنَفْسِهِ ۚ وَإِلَى اللهِ الْمَصِيرُ
Yoruba
 
Ẹlẹ́rù ẹ̀ṣẹ̀ kan kò níí ru ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíìràn. Kódà kí ẹnì kan tí ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ wọ̀ lọ́rùn ké sí (ẹlòmíìràn) fún àbárù ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, wọn kò níí bá a ru kiní kan nínú rẹ̀, ìbáà jẹ́ ìbátan. Àwọn tí ò ń ṣèkìlọ̀ fún ni àwọn tó ń páyà Olúwa wọn ní ìkọ̀kọ̀, tí wọ́n sì ń kírun. Ẹni tí ó bá ṣàfọ̀mọ́ (ara rẹ̀ kúrò nínú ìwà ẹ̀ṣẹ̀), ó ṣàfọ̀mọ́ fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ni. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.

Ayah  35:19  الأية
    +/- -/+  
وَمَا يَسْتَوِي الْأَعْمَىٰ وَالْبَصِيرُ
Yoruba
 
Afọ́jú àti olùríran kò dọ́gba.

Ayah  35:20  الأية
    +/- -/+  
وَلَا الظُّلُمَاتُ وَلَا النُّورُ
Yoruba
 
Àwọn òkùnkùn àti ìmọ́lẹ̀ (kò dọ́gba).

Ayah  35:21  الأية
    +/- -/+  
وَلَا الظِّلُّ وَلَا الْحَرُورُ
Yoruba
 
Àwọn ibòji àti ìgbóná òòrùn (kò dọ́gba).

Ayah  35:22  الأية
    +/- -/+  
وَمَا يَسْتَوِي الْأَحْيَاءُ وَلَا الْأَمْوَاتُ ۚ إِنَّ اللهَ يُسْمِعُ مَن يَشَاءُ ۖ وَمَا أَنتَ بِمُسْمِعٍ مَّن فِي الْقُبُورِ
Yoruba
 
Àwọn alààyè àti òkú kò dọ́gba. Dájúdájú Allāhu l'Ó ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́ ní ọ̀rọ̀ gbọ́. Ìwọ kò sì lè fún ẹni tí ó wà nínú sàréè ní ọ̀rọ̀ gbọ́.

Ayah  35:23  الأية
    +/- -/+  
إِنْ أَنتَ إِلَّا نَذِيرٌ
Yoruba
 
Ìwọ kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe olùkìlọ̀.

Ayah  35:24  الأية
    +/- -/+  
إِنَّا أَرْسَلْنَاكَ بِالْحَقِّ بَشِيرًا وَنَذِيرًا ۚ وَإِن مِّنْ أُمَّةٍ إِلَّا خَلَا فِيهَا نَذِيرٌ
Yoruba
 
Dájúdájú Àwa fi òdodo rán ọ níṣẹ́. (O sì jẹ́) oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀. Kò sí ìjọ kan (ṣíwájú rẹ) àfi kí olùkìlọ̀ ti rè kọjá láààrin wọn.

Ayah  35:25  الأية
    +/- -/+  
وَإِن يُكَذِّبُوكَ فَقَدْ كَذَّبَ الَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ جَاءَتْهُمْ رُسُلُهُم بِالْبَيِّنَاتِ وَبِالزُّبُرِ وَبِالْكِتَابِ الْمُنِيرِ
Yoruba
 
Tí wọ́n bá sì ń pè ọ́ ní òpùrọ́, àwọn tó ṣíwájú wọn náà kúkú pe (ọ̀rọ̀ Allāhu) ní irọ́ (nígbà tí) àwọn Òjíṣẹ́ wọn wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tó yanjú, àwọn ìpín-ìpín Tírà àti Tírà tó ń tànmọ́lẹ̀ sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn.

Ayah  35:26  الأية
    +/- -/+  
ثُمَّ أَخَذْتُ الَّذِينَ كَفَرُوا ۖ فَكَيْفَ كَانَ نَكِيرِ
Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, Mo gbá àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ mú. Báwo sì ni bí Mo ṣe (fi ìyà) kọ (aburú fún wọn) ti rí!

Ayah  35:27  الأية
    +/- -/+  
أَلَمْ تَرَ أَنَّ اللهَ أَنزَلَ مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَأَخْرَجْنَا بِهِ ثَمَرَاتٍ مُّخْتَلِفًا أَلْوَانُهَا ۚ وَمِنَ الْجِبَالِ جُدَدٌ بِيضٌ وَحُمْرٌ مُّخْتَلِفٌ أَلْوَانُهَا وَغَرَابِيبُ سُودٌ
Yoruba
 
Ṣé o kò rí i pé dájúdájú Allāhu l'Ó sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀? A sì fi mú àwọn èso tí àwọ̀ rẹ̀ yàtọ̀ síra wọn jáde. Àti pé àwọn ojú ọ̀nà funfun àti pupa tí àwọ̀ rẹ̀ yàtọ̀ síra wọn àti aláwọ̀ dúdú kirikiri wà nínú àwọn àpáta.

Ayah  35:28  الأية
    +/- -/+  
وَمِنَ النَّاسِ وَالدَّوَابِّ وَالْأَنْعَامِ مُخْتَلِفٌ أَلْوَانُهُ كَذَٰلِكَ ۗ إِنَّمَا يَخْشَى اللهَ مِنْ عِبَادِهِ الْعُلَمَاءُ ۗ إِنَّ اللهَ عَزِيزٌ غَفُورٌ
Yoruba
 
Àti pé ó wà nínú àwọn ènìyàn, àwọn n̄ǹkan ẹlẹ́mìí àti àwọn ẹran-ọ̀sìn tí àwọ̀ wọn yàtọ̀ síra wọn, gẹ́gẹ́ bí (àwọ̀ èso àti àpáta) wọ̀nyẹn (ṣe yàtọ̀ síra wọn). Àwọn tó ń páyà Allāhu nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ ni àwọn onímọ̀ (tí wọ́n mọ̀ pé), dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Aláforíjìn.

Ayah  35:29  الأية
    +/- -/+  
إِنَّ الَّذِينَ يَتْلُونَ كِتَابَ اللهِ وَأَقَامُوا الصَّلَاةَ وَأَنفَقُوا مِمَّا رَزَقْنَاهُمْ سِرًّا وَعَلَانِيَةً يَرْجُونَ تِجَارَةً لَّن تَبُورَ
Yoruba
 
Dájúdájú àwọn tó ń ké tírà Allāhu, tí wọ́n ń kírun, tí wọ́n sì ń ná nínú n̄ǹkan tí A ṣe ní arísìkí fún wọn ní ìkọ̀kọ̀ àti ní gban̄gba, wọ́n ń nírètí sí òwò kan tí kò níí parun.

Ayah  35:30  الأية
    +/- -/+  
لِيُوَفِّيَهُمْ أُجُورَهُمْ وَيَزِيدَهُم مِّن فَضْلِهِ ۚ إِنَّهُ غَفُورٌ شَكُورٌ
Yoruba
 
(Wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀) nítorí kí Allāhu lè san wọ́n ní ẹ̀san rere wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àti nítorí kí Ó lè ṣe àlékún fún wọn nínú oore àjùlọ Rẹ̀. Dájúdájú Òun ni Aláforíjìn, Ọlọ́pẹ́.

Ayah  35:31  الأية
    +/- -/+  
وَالَّذِي أَوْحَيْنَا إِلَيْكَ مِنَ الْكِتَابِ هُوَ الْحَقُّ مُصَدِّقًا لِّمَا بَيْنَ يَدَيْهِ ۗ إِنَّ اللهَ بِعِبَادِهِ لَخَبِيرٌ بَصِيرٌ
Yoruba
 
Ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ nínú Tírà, òhun ni òdodo tí ó ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó ṣíwájú rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀, Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn Rẹ̀.

Ayah  35:32  الأية
    +/- -/+  
ثُمَّ أَوْرَثْنَا الْكِتَابَ الَّذِينَ اصْطَفَيْنَا مِنْ عِبَادِنَا ۖ فَمِنْهُمْ ظَالِمٌ لِّنَفْسِهِ وَمِنْهُم مُّقْتَصِدٌ وَمِنْهُمْ سَابِقٌ بِالْخَيْرَاتِ بِإِذْنِ اللهِ ۚ ذَٰلِكَ هُوَ الْفَضْلُ الْكَبِيرُ
Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, A jogún tírà (al-Ƙur'ān) fún àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà nínú àwọn ẹrúsìn Wa. Nítorí náà, alábòsí tó ń bo ẹ̀mí ara rẹ̀ sí wà nínú wọn. Olùṣe-déédé wà nínú wọn. Olùgbawájú níbi àwọn iṣẹ́ rere tún wà nínú wọn pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Ìyẹn sì ni oore àjùlọ tó tóbi.

Ayah  35:33  الأية
    +/- -/+  
جَنَّاتُ عَدْنٍ يَدْخُلُونَهَا يُحَلَّوْنَ فِيهَا مِنْ أَسَاوِرَ مِن ذَهَبٍ وَلُؤْلُؤًا ۖ وَلِبَاسُهُمْ فِيهَا حَرِيرٌ
Yoruba
 
Àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére ni wọn yóò wọ inú rẹ̀. Àwọn kerewú wúrà àti òkúta olówó iyebíye ni A óò máa fi ṣe ọ̀ṣọ́ fún wọn nínú rẹ̀. Àti pé aṣọ àláárì ni aṣọ wọn nínú rẹ̀.

Ayah  35:34  الأية
    +/- -/+  
وَقَالُوا الْحَمْدُ لِلَّهِ الَّذِي أَذْهَبَ عَنَّا الْحَزَنَ ۖ إِنَّ رَبَّنَا لَغَفُورٌ شَكُورٌ
Yoruba
 
Wọ́n yóò sọ pé: "Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó mú ìbànújẹ́ kúrò fún wa. Dájúdájú Olúwa wa ni Aláforíjìn, Ọlọ́pẹ́,

Ayah  35:35  الأية
    +/- -/+  
الَّذِي أَحَلَّنَا دَارَ الْمُقَامَةِ مِن فَضْلِهِ لَا يَمَسُّنَا فِيهَا نَصَبٌ وَلَا يَمَسُّنَا فِيهَا لُغُوبٌ
Yoruba
 
Ẹni tí Ó sọ̀ wá kalẹ̀ sínú ibùgbé gbére nínú oore àjùlọ Rẹ̀. Wàhálà kan kò níí kàn wá nínú rẹ̀. Ìkáàárẹ̀ kan kò sì níí bá wa nínú rẹ̀.

Ayah  35:36  الأية
    +/- -/+  
وَالَّذِينَ كَفَرُوا لَهُمْ نَارُ جَهَنَّمَ لَا يُقْضَىٰ عَلَيْهِمْ فَيَمُوتُوا وَلَا يُخَفَّفُ عَنْهُم مِّنْ عَذَابِهَا ۚ كَذَٰلِكَ نَجْزِي كُلَّ كَفُورٍ
Yoruba
 
Àti pé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, iná Jahanamọ ń bẹ fún wọn. A ò níí pa wọ́n (sínú rẹ̀), áḿbọ̀sìbọ́sí pé wọ́n yóò kú. A ò níí ṣe ìyà inú rẹ̀ ní fífúyẹ́ fún wọn. Báyẹn ni A ṣe ń san gbogbo àwọn aláìgbàgbọ́ ní ẹ̀san.

Ayah  35:37  الأية
    +/- -/+  
وَهُمْ يَصْطَرِخُونَ فِيهَا رَبَّنَا أَخْرِجْنَا نَعْمَلْ صَالِحًا غَيْرَ الَّذِي كُنَّا نَعْمَلُ ۚ أَوَلَمْ نُعَمِّرْكُم مَّا يَتَذَكَّرُ فِيهِ مَن تَذَكَّرَ وَجَاءَكُمُ النَّذِيرُ ۖ فَذُوقُوا فَمَا لِلظَّالِمِينَ مِن نَّصِيرٍ
Yoruba
 
Wọn yóò máa lọgun ìrànlọ́wọ́ nínú rẹ̀ pé: "Olúwa wa, mú wa jáde nítorí kí á lè lọ́ ṣe iṣẹ́ rere, yàtọ̀ sí èyí tí a máa ń ṣe." Ṣé A ò fún yín ní ẹ̀mí gígùn lò tó fún ẹni tí ọ́ bá fẹ́ lo ìṣítí láti rí i lò nínú àsìkò náà ni? Olùkìlọ̀ sì wá ba yín. Nítorí náà, ẹ tọ́ ìyà wò. Kò sì níí sí alárànṣe kan fún àwọn alábòsí.

Ayah  35:38  الأية
    +/- -/+  
إِنَّ اللهَ عَالِمُ غَيْبِ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ إِنَّهُ عَلِيمٌ بِذَاتِ الصُّدُورِ
Yoruba
 
Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa ohun tó wà nínú igbá-àyà ẹ̀dá.

Ayah  35:39  الأية
    +/- -/+  
هُوَ الَّذِي جَعَلَكُمْ خَلَائِفَ فِي الْأَرْضِ ۚ فَمَن كَفَرَ فَعَلَيْهِ كُفْرُهُ ۖ وَلَا يَزِيدُ الْكَافِرِينَ كُفْرُهُمْ عِندَ رَبِّهِمْ إِلَّا مَقْتًا ۖ وَلَا يَزِيدُ الْكَافِرِينَ كُفْرُهُمْ إِلَّا خَسَارًا
Yoruba
 
Òun ní Ẹni tó ń fi yín ṣe àrólé lórí ilẹ̀. Nítorí náà, ẹni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́, (ìyà) àìgbàgbọ́ rẹ̀ wà lórí rẹ̀. Àìgbàgbọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ kò sì níí fún wọn ní àlékún kan lọ́dọ̀ Olúwa wọn bí kò ṣe ìbínú. Àìgbàgbọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ kò sì níí fún wọn ní àlékún kan bí kò ṣe òfò.

Ayah  35:40  الأية
    +/- -/+  
قُلْ أَرَأَيْتُمْ شُرَكَاءَكُمُ الَّذِينَ تَدْعُونَ مِن دُونِ اللهِ أَرُونِي مَاذَا خَلَقُوا مِنَ الْأَرْضِ أَمْ لَهُمْ شِرْكٌ فِي السَّمَاوَاتِ أَمْ آتَيْنَاهُمْ كِتَابًا فَهُمْ عَلَىٰ بَيِّنَتٍ مِّنْهُ ۚ بَلْ إِن يَعِدُ الظَّالِمُونَ بَعْضُهُم بَعْضًا إِلَّا غُرُورًا
Yoruba
 
Sọ pé: "Ẹ sọ fún mi nípa àwọn òrìṣà yín tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu, ẹ fi ohun tí wọ́n dá hàn mí lórí ilẹ̀? Tàbí wọ́n ní ìpín kan (pẹ̀lú Allāhu) níbi (ìṣẹ̀dá) àwọn sánmọ̀? Tàbí A fún wọn ní tírà kan, tí wọ́n ní ẹ̀rí tó yanjú lọ́wọ́ nínú rẹ̀? Rárá o! Kò sí àdéhùn kan tí àwọn alábòsí, apá kan wọn ń ṣe fún apá kan bí kò ṣe ẹ̀tàn."

Ayah  35:41  الأية
    +/- -/+  
إِنَّ اللهَ يُمْسِكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ أَن تَزُولَا ۚ وَلَئِن زَالَتَا إِنْ أَمْسَكَهُمَا مِنْ أَحَدٍ مِّن بَعْدِهِ ۚ إِنَّهُ كَانَ حَلِيمًا غَفُورًا
Yoruba
 
Dájúdájú Allāhu l'Ó ń mú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ dúró ṣinṣin tí wọn kò fi yẹ̀ lulẹ̀. Dájúdájú tí wọ́n bá sì yẹ̀ lulẹ̀, kò sí ẹnì kan kan tí ó máa mú un dúró lẹ́yìn Rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Aláfaradà, Aláforíjìn.

Ayah  35:42  الأية
    +/- -/+  
وَأَقْسَمُوا بِاللهِ جَهْدَ أَيْمَانِهِمْ لَئِن جَاءَهُمْ نَذِيرٌ لَّيَكُونُنَّ أَهْدَىٰ مِنْ إِحْدَى الْأُمَمِ ۖ فَلَمَّا جَاءَهُمْ نَذِيرٌ مَّا زَادَهُمْ إِلَّا نُفُورًا
Yoruba
 
Wọ́n sì fi Allāhu búra tí ìbúra wọn sì lágbára gan-an pé: "Dájúdájú tí olùkìlọ̀ kan bá fi lè wá bá àwọn, dájúdájú àwọn yóò mọ̀nà tààrà ju èyíkéyìí nínú ìjọ (tó ti ṣíwájú)." Nígbà tí olùkìlọ̀ kan sì wá bá wọn, (èyí) kò ṣe àlékún kan fún wọn bí kò ṣe sísá (fún òdodo)

Ayah  35:43  الأية
    +/- -/+  
اسْتِكْبَارًا فِي الْأَرْضِ وَمَكْرَ السَّيِّئِ ۚ وَلَا يَحِيقُ الْمَكْرُ السَّيِّئُ إِلَّا بِأَهْلِهِ ۚ فَهَلْ يَنظُرُونَ إِلَّا سُنَّتَ الْأَوَّلِينَ ۚ فَلَن تَجِدَ لِسُنَّتِ اللهِ تَبْدِيلًا ۖ وَلَن تَجِدَ لِسُنَّتِ اللهِ تَحْوِيلًا
Yoruba
 
Ní ti ṣíṣe ìgbéraga lórí ilẹ̀ àti ní ti ète aburú. Ète aburú kò sì níí yí ẹnì kan po àfi oníṣẹ́ aburú. Ṣé wọ́n ń retí kiní kan bí kò ṣe ìṣe(Allāhu lórí) àwọn ẹni àkọ́kọ́? Nítorí náà, o ò níí rí ìpààrọ̀ fún ìṣe Allāhu. Àní sẹ́, o ò níí rí ìyípadà fún ìṣe Allāhu.

Ayah  35:44  الأية
    +/- -/+  
أَوَلَمْ يَسِيرُوا فِي الْأَرْضِ فَيَنظُرُوا كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ وَكَانُوا أَشَدَّ مِنْهُمْ قُوَّةً ۚ وَمَا كَانَ اللهُ لِيُعْجِزَهُ مِن شَيْءٍ فِي السَّمَاوَاتِ وَلَا فِي الْأَرْضِ ۚ إِنَّهُ كَانَ عَلِيمًا قَدِيرًا
Yoruba
 
Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe rí? Wọ́n sì ní agbára ju àwọn (wọ̀nyí) lọ! Àti pé kò sí kiní kan nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ tí ó lè mórí bọ́ lọ́wọ́ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Alágbára.

Ayah  35:45  الأية
    +/- -/+  
وَلَوْ يُؤَاخِذُ اللهُ النَّاسَ بِمَا كَسَبُوا مَا تَرَكَ عَلَىٰ ظَهْرِهَا مِن دَابَّةٍ وَلَٰكِن يُؤَخِّرُهُمْ إِلَىٰ أَجَلٍ مُّسَمًّى ۖ فَإِذَا جَاءَ أَجَلُهُمْ فَإِنَّ اللهَ كَانَ بِعِبَادِهِ بَصِيرًا
Yoruba
 
Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu yó (tètè) máa mú ènìyàn pẹ̀lú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ ni, ìbá tí ṣẹ́ ku n̄ǹkan ẹlẹ́mìí kan kan mọ́ lórí ilẹ̀. Ṣùgbọ́n Ó ń lọ́ wọn lára di gbèdéke àkókò kan. Nígbà tí àkókò náà bá dé, dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn Rẹ̀.
 


© EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us