Prev  

37. Surah As-Sâffât سورة الصافات

  Next  



Ayah  37:1  الأية
    +/- -/+  
بِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
وَالصَّافَّاتِ صَفًّا
Yoruba
 
Allāhu fi àwọn mọlāika tí ó ń tò ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ búra.

Ayah  37:2  الأية
    +/- -/+  
فَالزَّاجِرَاتِ زَجْرًا
Yoruba
 
Allāhu tún fi àwọn mọlāika tó ń wọ́ ẹ̀ṣújò kiri tààrà bura.

Ayah  37:3  الأية
    +/- -/+  
فَالتَّالِيَاتِ ذِكْرًا
Yoruba
 
Allāhu tún fi àwọn mọlāika tó ń ka ìrántí bura.

Ayah  37:4  الأية
    +/- -/+  
إِنَّ إِلَٰهَكُمْ لَوَاحِدٌ
Yoruba
 
Dájúdájú ọ̀kan ṣoṣo ni Ọlọ́hun yín tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo.

Ayah  37:5  الأية
    +/- -/+  
رَّبُّ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا وَرَبُّ الْمَشَارِقِ
Yoruba
 
Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. Òun sì ni Olúwa àwọn ibùyọ òòrùn.

Ayah  37:6  الأية
    +/- -/+  
إِنَّا زَيَّنَّا السَّمَاءَ الدُّنْيَا بِزِينَةٍ الْكَوَاكِبِ
Yoruba
 
Dájúdájú Àwa fi àwọn ìràwọ̀ ṣe sánmọ̀ ilé ayé ní ọ̀ṣọ́

Ayah  37:7  الأية
    +/- -/+  
وَحِفْظًا مِّن كُلِّ شَيْطَانٍ مَّارِدٍ
Yoruba
 
Àti ìṣọ́ kúrò níbi (aburú) gbogbo èṣù olóríkunkun.

Ayah  37:8  الأية
    +/- -/+  
لَّا يَسَّمَّعُونَ إِلَى الْمَلَإِ الْأَعْلَىٰ وَيُقْذَفُونَ مِن كُلِّ جَانِبٍ
Yoruba
 
(Àwọn èṣù) kò sì níí lè tẹ́tí sí ìjọ (mọlāika tó wà ní) àyè gíga jùlọ (nínú sánmọ̀. Bí wọ́n bá sì gbìyànjú láti yọ́ ọ̀rọ̀ gbọ́ láti sánmọ̀, àwọn mọlāika) yó sì máa kù wọ́n lókò (ẹ̀ta ìràwọ̀) ní gbogbo agbègbè (sánmọ̀).

Ayah  37:9  الأية
    +/- -/+  
دُحُورًا ۖ وَلَهُمْ عَذَابٌ وَاصِبٌ
Yoruba
 
Wọ́n máa lé wọn dànù. Ìyà àìlópin sì wà fún wọn.

Ayah  37:10  الأية
    +/- -/+  
إِلَّا مَنْ خَطِفَ الْخَطْفَةَ فَأَتْبَعَهُ شِهَابٌ ثَاقِبٌ
Yoruba
 
(Wọn kò níí gbọ́ ọ̀rọ̀ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́) àyàfi ẹni tí ó bá rí ọ̀rọ̀ àjígbọ́ gbé, nígbà náà (ni mọlāika) yó sì fi ẹ̀ta ìràwọ̀ iná tó máa jó o tẹ̀lé e.

Ayah  37:11  الأية
    +/- -/+  
فَاسْتَفْتِهِمْ أَهُمْ أَشَدُّ خَلْقًا أَم مَّنْ خَلَقْنَا ۚ إِنَّا خَلَقْنَاهُم مِّن طِينٍ لَّازِبٍ
Yoruba
 
Bi wọ́n léèrè wò pé, ṣé àwọn (ènìyàn) ni ìṣẹ̀dá wọn lágbára jùlọ ni tàbí àwọn (n̄ǹkan mìíràn) tí A dá? Dájúdájú Àwa dá àwọn (ènìyàn) láti ara ẹrẹ̀ tó lẹ̀ mọ́ra wọn.

Ayah  37:12  الأية
    +/- -/+  
بَلْ عَجِبْتَ وَيَسْخَرُونَ
Yoruba
 
Rárá (kò jọra wọn); ìwọ ṣèèmọ̀ (nípa al-Ƙur'ān), àwọn sì ń ṣe yẹ̀yẹ́.

Ayah  37:13  الأية
    +/- -/+  
وَإِذَا ذُكِّرُوا لَا يَذْكُرُونَ
Yoruba
 
Àti pé nígbà tí wọ́n bá ṣe ìrántí fún wọn, wọn kò níí lo ìrántí.

Ayah  37:14  الأية
    +/- -/+  
وَإِذَا رَأَوْا آيَةً يَسْتَسْخِرُونَ
Yoruba
 
Nígbà tí wọ́n bá tún rí àmì kan, wọn yóò máa ṣe yẹ̀yẹ́.

Ayah  37:15  الأية
    +/- -/+  
وَقَالُوا إِنْ هَٰذَا إِلَّا سِحْرٌ مُّبِينٌ
Yoruba
 
Wọ́n sì wí pé: "Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe idán pọ́nńbélé.

Ayah  37:16  الأية
    +/- -/+  
أَإِذَا مِتْنَا وَكُنَّا تُرَابًا وَعِظَامًا أَإِنَّا لَمَبْعُوثُونَ
Yoruba
 
Ṣé nígbà tí a bá kú tán, tí a ti di erùpẹ̀ àti egungun, ṣé dájúdájú Wọn yóò tún gbé wa dìde ni?

Ayah  37:17  الأية
    +/- -/+  
أَوَآبَاؤُنَا الْأَوَّلُونَ
Yoruba
 
Ṣé àti àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́?"

Ayah  37:18  الأية
    +/- -/+  
قُلْ نَعَمْ وَأَنتُمْ دَاخِرُونَ
Yoruba
 
Sọ pé: "Bẹ́ẹ̀ ni. Ẹ̀yin yó sì di ẹni yẹpẹrẹ."

Ayah  37:19  الأية
    +/- -/+  
فَإِنَّمَا هِيَ زَجْرَةٌ وَاحِدَةٌ فَإِذَا هُمْ يَنظُرُونَ
Yoruba
 
Nítorí náà, igbe ẹyọ kan mà ni. Nígbà náà ni wọn yóò máa wò sùn.

Ayah  37:20  الأية
    +/- -/+  
وَقَالُوا يَا وَيْلَنَا هَٰذَا يَوْمُ الدِّينِ
Yoruba
 
Wọ́n á wí pé: "Ègbé wa ò! Èyí ni Ọjọ́ ẹ̀san."

Ayah  37:21  الأية
    +/- -/+  
هَٰذَا يَوْمُ الْفَصْلِ الَّذِي كُنتُم بِهِ تُكَذِّبُونَ
Yoruba
 
Èyí ni ọjọ́ Ìdájọ́ èyí tí ẹ̀ ń pè ní irọ́.

Ayah  37:22  الأية
    +/- -/+  
احْشُرُوا الَّذِينَ ظَلَمُوا وَأَزْوَاجَهُمْ وَمَا كَانُوا يَعْبُدُونَ
Yoruba
 
Ẹ kó àwọn tó ṣàbòsí jọ, àwọn ìyàwó wọn àti ohun tí wọ́n ń jọ́sìn fún

Ayah  37:23  الأية
    +/- -/+  
مِن دُونِ اللهِ فَاهْدُوهُمْ إِلَىٰ صِرَاطِ الْجَحِيمِ
Yoruba
 
Lẹ́yìn Allāhu. Kí ẹ sì júwe wọn sí ojú ọ̀nà iná Jẹhīm.

Ayah  37:24  الأية
    +/- -/+  
وَقِفُوهُمْ ۖ إِنَّهُم مَّسْئُولُونَ
Yoruba
 
Ẹ dá wọn dúró ná, dájúdájú wọ́n máa bi wọ́n léèrè ìbéèrè.

Ayah  37:25  الأية
    +/- -/+  
مَا لَكُمْ لَا تَنَاصَرُونَ
Yoruba
 
Kí ni kò jẹ́ kí ẹ ran ara yín lọ́wọ́?

Ayah  37:26  الأية
    +/- -/+  
بَلْ هُمُ الْيَوْمَ مُسْتَسْلِمُونَ
Yoruba
 
Rárá, wọ́n ti juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ ní òní ni.

Ayah  37:27  الأية
    +/- -/+  
وَأَقْبَلَ بَعْضُهُمْ عَلَىٰ بَعْضٍ يَتَسَاءَلُونَ
Yoruba
 
Apá kan wọn yóò dojú kọ apá kan, tí wọn yóò máa bi ara wọn léèrè ìbéèrè.

Ayah  37:28  الأية
    +/- -/+  
قَالُوا إِنَّكُمْ كُنتُمْ تَأْتُونَنَا عَنِ الْيَمِينِ
Yoruba
 
(Àwọn ènìyàn) wí pé: "Dájúdájú ẹ̀yin l'ẹ̀ ń gba ọ̀tún wọlé sí wa lára (láti ṣì wá lọ́nà)."

Ayah  37:29  الأية
    +/- -/+  
قَالُوا بَل لَّمْ تَكُونُوا مُؤْمِنِينَ
Yoruba
 
(Àwọn àlùjànnú) wí pé: "Rárá o (àwa kọ́), ẹ̀yin ni ẹ kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.

Ayah  37:30  الأية
    +/- -/+  
وَمَا كَانَ لَنَا عَلَيْكُم مِّن سُلْطَانٍ ۖ بَلْ كُنتُمْ قَوْمًا طَاغِينَ
Yoruba
 
Àti pé àwa kò ní agbára kan lórí yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin jẹ́ ìjọ olùtayọ-ẹnu ààlà.

Ayah  37:31  الأية
    +/- -/+  
فَحَقَّ عَلَيْنَا قَوْلُ رَبِّنَا ۖ إِنَّا لَذَائِقُونَ
Yoruba
 
Ọ̀rọ̀ Olúwa wa sì kò lé wa lórí pé dájúdájú àwa yóò tọ́ Iná wò.

Ayah  37:32  الأية
    +/- -/+  
فَأَغْوَيْنَاكُمْ إِنَّا كُنَّا غَاوِينَ
Yoruba
 
Nítorí náà, a ṣì yín lọ́nà. Dájúdájú àwa náà sì jẹ́ olùṣìnà."

Ayah  37:33  الأية
    +/- -/+  
فَإِنَّهُمْ يَوْمَئِذٍ فِي الْعَذَابِ مُشْتَرِكُونَ
Yoruba
 
Dájúdájú ní ọjọ́ yẹn, akẹgbẹ́ ni wọ́n nínú Ìyà. (Wọ́n dìjọ máa wà nínú Iná.)

Ayah  37:34  الأية
    +/- -/+  
إِنَّا كَذَٰلِكَ نَفْعَلُ بِالْمُجْرِمِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú báyẹn ni Àwa yóò ti ṣe pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.

Ayah  37:35  الأية
    +/- -/+  
إِنَّهُمْ كَانُوا إِذَا قِيلَ لَهُمْ لَا إِلَٰهَ إِلَّا اللهُ يَسْتَكْبِرُونَ
Yoruba
 
Dájúdájú nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé "Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Allāhu.", wọn yóò máa ṣègbéraga.

Ayah  37:36  الأية
    +/- -/+  
وَيَقُولُونَ أَئِنَّا لَتَارِكُو آلِهَتِنَا لِشَاعِرٍ مَّجْنُونٍ
Yoruba
 
Wọ́n sì ń wí pé: "Ṣé a máa fi àwọn òrìṣà wa sílẹ̀ nítorí eléwì wèrè kan?"

Ayah  37:37  الأية
    +/- -/+  
بَلْ جَاءَ بِالْحَقِّ وَصَدَّقَ الْمُرْسَلِينَ
Yoruba
 
Kò rí bẹ́ẹ̀. Ó mú òdodo wá ni. Ó sì ń jẹ́rìí sí òdodo àwọn Òjíṣẹ́ náà.

Ayah  37:38  الأية
    +/- -/+  
إِنَّكُمْ لَذَائِقُو الْعَذَابِ الْأَلِيمِ
Yoruba
 
Dájúdájú ẹ máa tọ́ ìyà ẹlẹ́ta-eléro wò.

Ayah  37:39  الأية
    +/- -/+  
وَمَا تُجْزَوْنَ إِلَّا مَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ
Yoruba
 
A kò níí san yín ní ẹ̀san kan àfi ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

Ayah  37:40  الأية
    +/- -/+  
إِلَّا عِبَادَ اللهِ الْمُخْلَصِينَ
Yoruba
 
Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo).

Ayah  37:41  الأية
    +/- -/+  
أُولَٰئِكَ لَهُمْ رِزْقٌ مَّعْلُومٌ
Yoruba
 
Ti àwọn wọ̀nyẹn sì ni arísìkí tí wọ́n ti mọ̀;

Ayah  37:42  الأية
    +/- -/+  
فَوَاكِهُ ۖ وَهُم مُّكْرَمُونَ
Yoruba
 
Àwọn èso. Àwọn sì ni alápọ̀n-ọ́nlé

Ayah  37:43  الأية
    +/- -/+  

Ayah  37:44  الأية
    +/- -/+  
عَلَىٰ سُرُرٍ مُّتَقَابِلِينَ
Yoruba
 
Lórí àwọn ìtẹ́ ni wọn yóò ti kọjú síra wọn.

Ayah  37:45  الأية
    +/- -/+  
يُطَافُ عَلَيْهِم بِكَأْسٍ مِّن مَّعِينٍ
Yoruba
 
Wọn yóò máa gbé ife ọtí mímọ́ láti inú odò kan tó ń ṣàn káà kiri ọ̀dọ̀ wọn.

Ayah  37:46  الأية
    +/- -/+  
بَيْضَاءَ لَذَّةٍ لِّلشَّارِبِينَ
Yoruba
 
Funfun ni (ọtí náà). Ó ń dùn lẹ́nu àwọn tó máa mu ún.

Ayah  37:47  الأية
    +/- -/+  
لَا فِيهَا غَوْلٌ وَلَا هُمْ عَنْهَا يُنزَفُونَ
Yoruba
 
Kò sí ìpalára kan fún wọn nínú rẹ̀, wọn kò sì níí hunrírà lórí rẹ̀.

Ayah  37:48  الأية
    +/- -/+  
وَعِندَهُمْ قَاصِرَاتُ الطَّرْفِ عِينٌ
Yoruba
 
Àwọn obìnrin tí kì í wo ẹlòmíìràn, àwọn ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́ yó sì wà lọ́dọ̀ wọn.

Ayah  37:49  الأية
    +/- -/+  
كَأَنَّهُنَّ بَيْضٌ مَّكْنُونٌ
Yoruba
 
Wọ́n dà bí ẹyin tí wọn kò ì bó èèpo rẹ̀ kúrò lára rẹ̀.

Ayah  37:50  الأية
    +/- -/+  
فَأَقْبَلَ بَعْضُهُمْ عَلَىٰ بَعْضٍ يَتَسَاءَلُونَ
Yoruba
 
Apá kan wọn yóò dojú kọ apá kan, tí wọn yóò máa bira wọn léèrè ìbéèrè.

Ayah  37:51  الأية
    +/- -/+  
قَالَ قَائِلٌ مِّنْهُمْ إِنِّي كَانَ لِي قَرِينٌ
Yoruba
 
Òǹsọ̀rọ̀ kan nínú wọn yóò sọ pé: "Dájúdájú èmi ní ọ̀rẹ́ kan tí ó ń wí pé, "Ṣé dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn onígbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Àjíǹde? Ṣé nígbà tí a bá kú tán, tí a ti di erùpẹ̀ àti egungun, ṣé dájúdájú Wọn yóò san wá ní ẹ̀san ni?" Ó sọ pé: "Ṣé ẹ̀yin yóò yọjú wo (ẹni náà tí kò gbàgbọ́ nínú Ọjọ́ àjíǹde)?"

Ayah  37:52  الأية
    +/- -/+  
يَقُولُ أَإِنَّكَ لَمِنَ الْمُصَدِّقِينَ
Yoruba
 
Tí ó ń wí pé, "Ṣé dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn onígbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Àjíǹde?

Ayah  37:53  الأية
    +/- -/+  
أَإِذَا مِتْنَا وَكُنَّا تُرَابًا وَعِظَامًا أَإِنَّا لَمَدِينُونَ
Yoruba
 
Ṣé nígbà tí a bá kú tán, tí a ti di erùpẹ̀ àti egungun, ṣé dájúdájú Wọn yóò san wá ní ẹ̀san ni?"

Ayah  37:54  الأية
    +/- -/+  
قَالَ هَلْ أَنتُم مُّطَّلِعُونَ
Yoruba
 
Ó sọ pé: "Ṣé ẹ̀yin yóò yọjú wo (ẹni náà tí kò gbàgbọ́ nínú Ọjọ́ àjíǹde)?"

Ayah  37:55  الأية
    +/- -/+  
فَاطَّلَعَ فَرَآهُ فِي سَوَاءِ الْجَحِيمِ
Yoruba
 
Ó yọjú wò ó. Ó sì rí́i láààrin gbùngbùn nínú iná Jẹhīm.

Ayah  37:56  الأية
    +/- -/+  
قَالَ تَاللهِ إِن كِدتَّ لَتُرْدِينِ
Yoruba
 
Ó (sì) sọ pé: "Mó fi Allāhu búra, ìwọ fẹ́ẹ̀ kó ìparun bá mi tán.

Ayah  37:57  الأية
    +/- -/+  
وَلَوْلَا نِعْمَةُ رَبِّي لَكُنتُ مِنَ الْمُحْضَرِينَ
Yoruba
 
Àti pé tí kì í bá ṣe ìdẹ̀ra Olúwa mi ni, èmi náà ìbá wà nínú ẹni tí wọ́n máa mú wá sínú Iná.

Ayah  37:58  الأية
    +/- -/+  

Ayah  37:59  الأية
    +/- -/+  
إِلَّا مَوْتَتَنَا الْأُولَىٰ وَمَا نَحْنُ بِمُعَذَّبِينَ
Yoruba
 
Àfi ikú wa àkọ́kọ́. Wọn kò sì níí jẹ àwa níyà.

Ayah  37:60  الأية
    +/- -/+  
إِنَّ هَٰذَا لَهُوَ الْفَوْزُ الْعَظِيمُ
Yoruba
 
Dájúdájú èyí, òhun ni èrèǹjẹ ńlá."

Ayah  37:61  الأية
    +/- -/+  
لِمِثْلِ هَٰذَا فَلْيَعْمَلِ الْعَامِلُونَ
Yoruba
 
Nítorí irú èyí, kí àwọn olùṣẹ̀sìn máa ṣẹ̀sìn lọ.

Ayah  37:62  الأية
    +/- -/+  
أَذَٰلِكَ خَيْرٌ نُّزُلًا أَمْ شَجَرَةُ الزَّقُّومِ
Yoruba
 
Ǹjẹ́ ìyẹn l'ó lóore jùlọ ní ibùdésí ni tàbí igi zaƙūm (igi ẹlẹ́gùn-ún)?

Ayah  37:63  الأية
    +/- -/+  
إِنَّا جَعَلْنَاهَا فِتْنَةً لِّلظَّالِمِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú Àwa ṣe é ní àdánwò fún àwọn alábòsí.

Ayah  37:64  الأية
    +/- -/+  
إِنَّهَا شَجَرَةٌ تَخْرُجُ فِي أَصْلِ الْجَحِيمِ
Yoruba
 
Dájúdájú òhun ni igi kan tí ó máa hù jáde láti ìdí iná Jẹhīm.

Ayah  37:65  الأية
    +/- -/+  
طَلْعُهَا كَأَنَّهُ رُءُوسُ الشَّيَاطِينِ
Yoruba
 
Èso rẹ̀ dà bí orí àwọn èṣù.

Ayah  37:66  الأية
    +/- -/+  
فَإِنَّهُمْ لَآكِلُونَ مِنْهَا فَمَالِئُونَ مِنْهَا الْبُطُونَ
Yoruba
 
Dájúdájú wọn yóò máa jẹ nínú rẹ̀. Wọ́n sì máa jẹ ẹ́ ní àjẹyo bámúbámú.

Ayah  37:67  الأية
    +/- -/+  
ثُمَّ إِنَّ لَهُمْ عَلَيْهَا لَشَوْبًا مِّنْ حَمِيمٍ
Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, dájúdájú wọn yóò mu àwọnúwẹ̀jẹ̀ olómi gbígbóná tó gbóná parí lé e lórí.

Ayah  37:68  الأية
    +/- -/+  
ثُمَّ إِنَّ مَرْجِعَهُمْ لَإِلَى الْجَحِيمِ
Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, dájúdájú ibùpadàsí wọn ni iná Jẹhīm.

Ayah  37:69  الأية
    +/- -/+  
إِنَّهُمْ أَلْفَوْا آبَاءَهُمْ ضَالِّينَ
Yoruba
 
Dájúdájú wọ́n bá àwọn bàbá wọn ní olùṣìnà.

Ayah  37:70  الأية
    +/- -/+  
فَهُمْ عَلَىٰ آثَارِهِمْ يُهْرَعُونَ
Yoruba
 
Àwọn náà sì ń yára tẹ̀lé orípa wọn.

Ayah  37:71  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدْ ضَلَّ قَبْلَهُمْ أَكْثَرُ الْأَوَّلِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ẹni àkọ́kọ́ ti ṣìnà ṣíwájú wọn.

Ayah  37:72  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا فِيهِم مُّنذِرِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú A ti rán àwọn olùkìlọ̀ sí wọn.

Ayah  37:73  الأية
    +/- -/+  
فَانظُرْ كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الْمُنذَرِينَ
Yoruba
 
Nítorí náà, wo bí àtubọ̀tán àwọn ẹni-akìlọ̀-fún ti rí.

Ayah  37:74  الأية
    +/- -/+  
إِلَّا عِبَادَ اللهِ الْمُخْلَصِينَ
Yoruba
 
Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo).

Ayah  37:75  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدْ نَادَانَا نُوحٌ فَلَنِعْمَ الْمُجِيبُونَ
Yoruba
 
Dájúdájú (Ànábì) Nūh pè Wá. A sì dára ní olùjẹ́pè.

Ayah  37:76  الأية
    +/- -/+  
وَنَجَّيْنَاهُ وَأَهْلَهُ مِنَ الْكَرْبِ الْعَظِيمِ
Yoruba
 
A gba òun àti àwọn ará ilé rẹ̀ là kúrò nínú ìbànújẹ́ ńlá náà.

Ayah  37:77  الأية
    +/- -/+  
وَجَعَلْنَا ذُرِّيَّتَهُ هُمُ الْبَاقِينَ
Yoruba
 
A dá àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ sí lẹ́yìn rẹ̀.

Ayah  37:78  الأية
    +/- -/+  
وَتَرَكْنَا عَلَيْهِ فِي الْآخِرِينَ
Yoruba
 
A sì fún un ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn.

Ayah  37:79  الأية
    +/- -/+  
سَلَامٌ عَلَىٰ نُوحٍ فِي الْعَالَمِينَ
Yoruba
 
Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) Nūh láààrin gbogbo ẹ̀dá.

Ayah  37:80  الأية
    +/- -/+  
إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجْزِي الْمُحْسِنِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).

Ayah  37:81  الأية
    +/- -/+  
إِنَّهُ مِنْ عِبَادِنَا الْمُؤْمِنِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

Ayah  37:82  الأية
    +/- -/+  
ثُمَّ أَغْرَقْنَا الْآخَرِينَ
Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, A tẹ àwọn yòókù rì sínú agbami.

Ayah  37:83  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّ مِن شِيعَتِهِ لَإِبْرَاهِيمَ
Yoruba
 
Dájúdájú (Ànábì) 'Ibrọ̄hīm wà nínú ìjọ (tí ó tẹ̀lé ìlànà) rẹ̀.

Ayah  37:84  الأية
    +/- -/+  
إِذْ جَاءَ رَبَّهُ بِقَلْبٍ سَلِيمٍ
Yoruba
 
(Ẹ rántí) nígbà tí ó dojú kọ Olúwa rẹ̀ pẹ̀lú ọkàn mímọ́.

Ayah  37:85  الأية
    +/- -/+  
إِذْ قَالَ لِأَبِيهِ وَقَوْمِهِ مَاذَا تَعْبُدُونَ
Yoruba
 
(Rántí) nígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: "Kí ni ẹ̀ ń jọ́sìn fún?

Ayah  37:86  الأية
    +/- -/+  
أَئِفْكًا آلِهَةً دُونَ اللهِ تُرِيدُونَ
Yoruba
 
Ṣé ẹ̀ ń gbèrò láti sọ irọ́ di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu?

Ayah  37:87  الأية
    +/- -/+  
فَمَا ظَنُّكُم بِرَبِّ الْعَالَمِينَ
Yoruba
 
Kí sì ni èrò ọkàn yín sí Olúwa gbogbo ẹ̀dá?"

Ayah  37:88  الأية
    +/- -/+  
فَنَظَرَ نَظْرَةً فِي النُّجُومِ
Yoruba
 
Ó ṣíjú wo àwọn ìràwọ̀ ní wíwò kan.

Ayah  37:89  الأية
    +/- -/+  

Ayah  37:90  الأية
    +/- -/+  
فَتَوَلَّوْا عَنْهُ مُدْبِرِينَ
Yoruba
 
Nítorí náà, wọ́n pa á tì, wọ́n sì lọ.

Ayah  37:91  الأية
    +/- -/+  
فَرَاغَ إِلَىٰ آلِهَتِهِمْ فَقَالَ أَلَا تَأْكُلُونَ
Yoruba
 
Nígbà náà, ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn òrìṣà wọn. Ó sì sọ pé: "Ṣé ẹ kò níí jẹun ni?

Ayah  37:92  الأية
    +/- -/+  

Ayah  37:93  الأية
    +/- -/+  
فَرَاغَ عَلَيْهِمْ ضَرْبًا بِالْيَمِينِ
Yoruba
 
Nígbà náà, ó dojú lílù kọ wọ́n pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún (ó sì rún wọn wómúwómú).

Ayah  37:94  الأية
    +/- -/+  
فَأَقْبَلُوا إِلَيْهِ يَزِفُّونَ
Yoruba
 
(Àwọn abọ̀rìṣà) sáré wá dojú kọ ọ́.

Ayah  37:95  الأية
    +/- -/+  
قَالَ أَتَعْبُدُونَ مَا تَنْحِتُونَ
Yoruba
 
Ó sọ pé: "Ṣé ẹ óò máa jọ́sìn fún n̄ǹkan tí ẹ gbẹ́ kalẹ̀ lére ni?

Ayah  37:96  الأية
    +/- -/+  
وَاللهُ خَلَقَكُمْ وَمَا تَعْمَلُونَ
Yoruba
 
Allāhu l'Ó sì dá ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́."

Ayah  37:97  الأية
    +/- -/+  
قَالُوا ابْنُوا لَهُ بُنْيَانًا فَأَلْقُوهُ فِي الْجَحِيمِ
Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "Ẹ mọ ilé kan fún un, kí ẹ sì jù ú sínú iná."

Ayah  37:98  الأية
    +/- -/+  
فَأَرَادُوا بِهِ كَيْدًا فَجَعَلْنَاهُمُ الْأَسْفَلِينَ
Yoruba
 
Wọ́n gbèrò ète sí i. A sì sọ wọ́n di ẹni yẹpẹrẹ.

Ayah  37:99  الأية
    +/- -/+  
وَقَالَ إِنِّي ذَاهِبٌ إِلَىٰ رَبِّي سَيَهْدِينِ
Yoruba
 
Ó sọ pé: "Dájúdájú mo máa lọ sí (ìlú tí) Olúwa mi (pa mí láṣẹ láti lọ). Ó sì máa tọ́ mi sọ́nà (láti dé ibẹ̀).

Ayah  37:100  الأية
    +/- -/+  
رَبِّ هَبْ لِي مِنَ الصَّالِحِينَ
Yoruba
 
Olúwa mi, ta mí lọ́rẹ ọmọ nínú àwọn ẹni rere."

Ayah  37:101  الأية
    +/- -/+  
فَبَشَّرْنَاهُ بِغُلَامٍ حَلِيمٍ
Yoruba
 
A sì fún un ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ọmọkùnrin kan tí ó máa ní ìfaradà.

Ayah  37:102  الأية
    +/- -/+  
فَلَمَّا بَلَغَ مَعَهُ السَّعْيَ قَالَ يَا بُنَيَّ إِنِّي أَرَىٰ فِي الْمَنَامِ أَنِّي أَذْبَحُكَ فَانظُرْ مَاذَا تَرَىٰ ۚ قَالَ يَا أَبَتِ افْعَلْ مَا تُؤْمَرُ ۖ سَتَجِدُنِي إِن شَاءَ اللهُ مِنَ الصَّابِرِينَ
Yoruba
 
Nígbà tí (ọmọ náà) dàgbà, tí ó tó bá (bàbá rẹ̀) ṣe iṣẹ́, (bàbá rẹ̀) sọ pé: "Ọmọ mi, dájúdájú èmi lá àlá pé dájúdájú mò ń dúńbú rẹ. Nítorí náà, wòye sí i, kí ni o rí sí i." Ó sọ pé: "Bàbá mi, ṣe ohun tí Wọ́n pa láṣẹ fún ọ. O máa bá mi nínú àwọn onísùúrù, tí Allāhu bá fẹ́."

Ayah  37:103  الأية
    +/- -/+  
فَلَمَّا أَسْلَمَا وَتَلَّهُ لِلْجَبِينِ
Yoruba
 
Nígbà tí àwọn méjèèjì juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀, tí (Ànábì 'Ibrọ̄hīm) sì dojú (ọmọ) rẹ̀ bolẹ̀,

Ayah  37:104  الأية
    +/- -/+  
وَنَادَيْنَاهُ أَن يَا إِبْرَاهِيمُ
Yoruba
 
A pè é (báyìí) pé, 'Ibrọ̄hīm,

Ayah  37:105  الأية
    +/- -/+  
قَدْ صَدَّقْتَ الرُّؤْيَا ۚ إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجْزِي الْمُحْسِنِينَ
Yoruba
 
O kúkú ti mú àlá náà ṣẹ. Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).

Ayah  37:106  الأية
    +/- -/+  
إِنَّ هَٰذَا لَهُوَ الْبَلَاءُ الْمُبِينُ
Yoruba
 
Dájúdájú èyí, òhun ni àdánwò pọ́nńbélé.

Ayah  37:107  الأية
    +/- -/+  
وَفَدَيْنَاهُ بِذِبْحٍ عَظِيمٍ
Yoruba
 
A sì fi àgbò ńlá ṣèràpadà rẹ̀.

Ayah  37:108  الأية
    +/- -/+  
وَتَرَكْنَا عَلَيْهِ فِي الْآخِرِينَ
Yoruba
 
A tún fún un ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn.

Ayah  37:109  الأية
    +/- -/+  
سَلَامٌ عَلَىٰ إِبْرَاهِيمَ
Yoruba
 
Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) 'Ibrọ̄hīm.

Ayah  37:110  الأية
    +/- -/+  
كَذَٰلِكَ نَجْزِي الْمُحْسِنِينَ
Yoruba
 
Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).

Ayah  37:111  الأية
    +/- -/+  
إِنَّهُ مِنْ عِبَادِنَا الْمُؤْمِنِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

Ayah  37:112  الأية
    +/- -/+  
وَبَشَّرْنَاهُ بِإِسْحَاقَ نَبِيًّا مِّنَ الصَّالِحِينَ
Yoruba
 
A tún fún un ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) 'Ishāƙ, (ó máa jẹ́) Ànábì. (Ó sì máa wà) nínú àwọn ẹni rere.

Ayah  37:113  الأية
    +/- -/+  
وَبَارَكْنَا عَلَيْهِ وَعَلَىٰ إِسْحَاقَ ۚ وَمِن ذُرِّيَّتِهِمَا مُحْسِنٌ وَظَالِمٌ لِّنَفْسِهِ مُبِينٌ
Yoruba
 
Àti pé A fún òun àti 'Ishāƙ ní ìbùkún. Ẹni rere àti alábòsí pọ́nńbélé (tó ń ṣàbòsí sí) ẹ̀mí ara rẹ̀ wà nínú àrọ́mọdọ́mọ àwọn méjèèjì.

Ayah  37:114  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدْ مَنَنَّا عَلَىٰ مُوسَىٰ وَهَارُونَ
Yoruba
 
Dájúdájú A ṣoore fún (Ànábì) Mūsā àti Hārūn.

Ayah  37:115  الأية
    +/- -/+  
وَنَجَّيْنَاهُمَا وَقَوْمَهُمَا مِنَ الْكَرْبِ الْعَظِيمِ
Yoruba
 
A gba àwọn méjèèjì àti ìjọ àwọn méjèèjì là kúrò nínú ìbànújẹ́ ńlá náà.

Ayah  37:116  الأية
    +/- -/+  
وَنَصَرْنَاهُمْ فَكَانُوا هُمُ الْغَالِبِينَ
Yoruba
 
A tún ṣàrànṣe fún wọn. Àwọn ni wọ́n jẹ́ olùborí (ọ̀tá wọn).

Ayah  37:117  الأية
    +/- -/+  
وَآتَيْنَاهُمَا الْكِتَابَ الْمُسْتَبِينَ
Yoruba
 
A sì fún àwọn méjèèjì ní Tírà tó yanjú.

Ayah  37:118  الأية
    +/- -/+  
وَهَدَيْنَاهُمَا الصِّرَاطَ الْمُسْتَقِيمَ
Yoruba
 
A tún fi àwọn méjèèjì mọ̀nà tààrà.

Ayah  37:119  الأية
    +/- -/+  
وَتَرَكْنَا عَلَيْهِمَا فِي الْآخِرِينَ
Yoruba
 
A fún àwọn méjèèjì ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn.

Ayah  37:120  الأية
    +/- -/+  
سَلَامٌ عَلَىٰ مُوسَىٰ وَهَارُونَ
Yoruba
 
Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) Mūsā àti Hārūn.

Ayah  37:121  الأية
    +/- -/+  
إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجْزِي الْمُحْسِنِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).

Ayah  37:122  الأية
    +/- -/+  
إِنَّهُمَا مِنْ عِبَادِنَا الْمُؤْمِنِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú àwọn méjèèjì wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

Ayah  37:123  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّ إِلْيَاسَ لَمِنَ الْمُرْسَلِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú (Ànábì) 'Ilyās wà nínú àwọn Òjíṣẹ́.

Ayah  37:124  الأية
    +/- -/+  
إِذْ قَالَ لِقَوْمِهِ أَلَا تَتَّقُونَ
Yoruba
 
(Ẹ rántí) nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: "Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù Allāhu ni?

Ayah  37:125  الأية
    +/- -/+  
أَتَدْعُونَ بَعْلًا وَتَذَرُونَ أَحْسَنَ الْخَالِقِينَ
Yoruba
 
Ṣé ẹ óò máa pe òrìṣà kan, ẹ sì máa fi Ẹni tó dára jùlọ nínú àwọn ẹlẹ́dàá sílẹ̀?

Ayah  37:126  الأية
    +/- -/+  
اللهَ رَبَّكُمْ وَرَبَّ آبَائِكُمُ الْأَوَّلِينَ
Yoruba
 
(ẹ̀ ń fi) Allāhu (sílẹ̀), Olúwa yín àti Olúwa àwọn bàbá yín, àwọn ẹni àkọ́kọ́?"

Ayah  37:127  الأية
    +/- -/+  
فَكَذَّبُوهُ فَإِنَّهُمْ لَمُحْضَرُونَ
Yoruba
 
Wọ́n sì pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, wọ́n máa mú wọn wá sínú Iná.

Ayah  37:128  الأية
    +/- -/+  
إِلَّا عِبَادَ اللهِ الْمُخْلَصِينَ
Yoruba
 
Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo).

Ayah  37:129  الأية
    +/- -/+  
وَتَرَكْنَا عَلَيْهِ فِي الْآخِرِينَ
Yoruba
 
A fún un ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn.

Ayah  37:130  الأية
    +/- -/+  
سَلَامٌ عَلَىٰ إِلْ يَاسِينَ
Yoruba
 
Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) 'Ilyās.

Ayah  37:131  الأية
    +/- -/+  
إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجْزِي الْمُحْسِنِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).

Ayah  37:132  الأية
    +/- -/+  
إِنَّهُ مِنْ عِبَادِنَا الْمُؤْمِنِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

Ayah  37:133  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّ لُوطًا لَّمِنَ الْمُرْسَلِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú (Ànábì) Lūt wà nínú àwọn Òjíṣẹ́.

Ayah  37:134  الأية
    +/- -/+  
إِذْ نَجَّيْنَاهُ وَأَهْلَهُ أَجْمَعِينَ
Yoruba
 
(Ẹ rántí) nígbà tí A gba òun àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀ là.

Ayah  37:135  الأية
    +/- -/+  
إِلَّا عَجُوزًا فِي الْغَابِرِينَ
Yoruba
 
Àyàfi arúgbóbìnrin kan tí ó wà nínú àwọn tó ṣẹ́ kù lẹ́yìn (láààrin àwọn tí A parẹ́).

Ayah  37:136  الأية
    +/- -/+  

Ayah  37:137  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّكُمْ لَتَمُرُّونَ عَلَيْهِم مُّصْبِحِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú ẹ̀yin náà kúkú ń gba ọ̀dọ̀ wọn kọjá láàárọ̀-láàárọ̀

Ayah  37:138  الأية
    +/- -/+  
وَبِاللَّيْلِ ۗ أَفَلَا تَعْقِلُونَ
Yoruba
 
Àti ní alaalẹ́. Ṣé ẹ kò níí ṣe làákàyè ni?

Ayah  37:139  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّ يُونُسَ لَمِنَ الْمُرْسَلِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú (Ànábì) Yūnus kúkú wà nínú àwọn Òjíṣẹ́.

Ayah  37:140  الأية
    +/- -/+  
إِذْ أَبَقَ إِلَى الْفُلْكِ الْمَشْحُونِ
Yoruba
 
(Ẹ rántí) nígbà tí ó sá lọ sínú ọkọ̀ ojú-omi tó kún (fún èrò).

Ayah  37:141  الأية
    +/- -/+  
فَسَاهَمَ فَكَانَ مِنَ الْمُدْحَضِينَ
Yoruba
 
Ó sì bá wọn ṣe kúríà papọ̀. Ó sì wà nínú àwọn tí kúrìá já.

Ayah  37:142  الأية
    +/- -/+  
فَالْتَقَمَهُ الْحُوتُ وَهُوَ مُلِيمٌ
Yoruba
 
Nítorí náà, ẹja gbé e mì; ó sì ń dá ara rẹ̀ lẹ́bi.

Ayah  37:143  الأية
    +/- -/+  
فَلَوْلَا أَنَّهُ كَانَ مِنَ الْمُسَبِّحِينَ
Yoruba
 
Nítorí náà, tí kò bá jẹ́ pé ó wà nínú àwọn olùṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu,

Ayah  37:144  الأية
    +/- -/+  
لَلَبِثَ فِي بَطْنِهِ إِلَىٰ يَوْمِ يُبْعَثُونَ
Yoruba
 
Dájúdájú ìbá wà nínú ẹja títí di ọjọ́ tí wọn yóò gbé ẹ̀dá dìde.

Ayah  37:145  الأية
    +/- -/+  
فَنَبَذْنَاهُ بِالْعَرَاءِ وَهُوَ سَقِيمٌ
Yoruba
 
Nítorí náà, A jù ú sí orí ilẹ́ gban̄sasa létí omi. Ó sì jẹ́ aláìlera.

Ayah  37:146  الأية
    +/- -/+  
وَأَنبَتْنَا عَلَيْهِ شَجَرَةً مِّن يَقْطِينٍ
Yoruba
 
A sì mú igi Yẹƙtīn hù jáde láti ṣíji bò ó.

Ayah  37:147  الأية
    +/- -/+  
وَأَرْسَلْنَاهُ إِلَىٰ مِائَةِ أَلْفٍ أَوْ يَزِيدُونَ
Yoruba
 
A tún rán an níṣẹ́ sí ọ̀kẹ́ márùn-ún (ènìyàn) tàbí kí wọ́n lékún sí i.

Ayah  37:148  الأية
    +/- -/+  
فَآمَنُوا فَمَتَّعْنَاهُمْ إِلَىٰ حِينٍ
Yoruba
 
Wọ́n gbàgbọ́ ní òdodo. A sì fún wọn ní ìgbádùn títí di ìgbà díẹ̀.

Ayah  37:149  الأية
    +/- -/+  
فَاسْتَفْتِهِمْ أَلِرَبِّكَ الْبَنَاتُ وَلَهُمُ الْبَنُونَ
Yoruba
 
Bi wọ́n léèrè wò pé: "Ṣé Olúwa rẹ l'ó ni àwọn ọmọbìnrin, tiwọn sì ni ọmọkùnrin?

Ayah  37:150  الأية
    +/- -/+  
أَمْ خَلَقْنَا الْمَلَائِكَةَ إِنَاثًا وَهُمْ شَاهِدُونَ
Yoruba
 
Tàbí A dá àwọn mọlāika ní obìnrin, tí àwọn sì jẹ́ ẹlẹ́rìí?"

Ayah  37:151  الأية
    +/- -/+  
أَلَا إِنَّهُم مِّنْ إِفْكِهِمْ لَيَقُولُونَ
Yoruba
 
Gbọ́, nínú irọ́ wọn ni pé dájúdájú wọ́n ń wí pé:

Ayah  37:152  الأية
    +/- -/+  
وَلَدَ اللهُ وَإِنَّهُمْ لَكَاذِبُونَ
Yoruba
 
"Allāhu bímọ." Dájúdájú òpùrọ́ sì ni wọ́n.

Ayah  37:153  الأية
    +/- -/+  
أَصْطَفَى الْبَنَاتِ عَلَى الْبَنِينَ
Yoruba
 
Ṣé (Allāhu) ṣẹ̀ṣà àwọn ọmọbìnrin lórí àwọn ọmọkùnrin ni?

Ayah  37:154  الأية
    +/- -/+  
مَا لَكُمْ كَيْفَ تَحْكُمُونَ
Yoruba
 
Kí l'ó ń ṣe yín tí ẹ fi ń dájọ́ báyìí?

Ayah  37:155  الأية
    +/- -/+  

Ayah  37:156  الأية
    +/- -/+  
أَمْ لَكُمْ سُلْطَانٌ مُّبِينٌ
Yoruba
 
Tàbí ẹ ní ẹ̀rí tó yanjú lọ́wọ́ ni?

Ayah  37:157  الأية
    +/- -/+  
فَأْتُوا بِكِتَابِكُمْ إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ
Yoruba
 
Ẹ mú tírà yín wà nígbà náà tí ẹ bá jẹ́ olódodo.

Ayah  37:158  الأية
    +/- -/+  
وَجَعَلُوا بَيْنَهُ وَبَيْنَ الْجِنَّةِ نَسَبًا ۚ وَلَقَدْ عَلِمَتِ الْجِنَّةُ إِنَّهُمْ لَمُحْضَرُونَ
Yoruba
 
Wọ́n tún fi ìbátan sáààrin (Allāhu) àti àlùjànnú! Àwọn àlùjànnú sì ti mọ̀ pé, dájúdájú wọ́n kúkú máa mú àwọn wá sínú Iná ni.

Ayah  37:159  الأية
    +/- -/+  
سُبْحَانَ اللهِ عَمَّا يَصِفُونَ
Yoruba
 
Mímọ́ ni fún Allāhu tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀).

Ayah  37:160  الأية
    +/- -/+  
إِلَّا عِبَادَ اللهِ الْمُخْلَصِينَ
Yoruba
 
Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo).

Ayah  37:161  الأية
    +/- -/+  
فَإِنَّكُمْ وَمَا تَعْبُدُونَ
Yoruba
 
Dájúdájú ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún (lẹ́yìn Allāhu),

Ayah  37:162  الأية
    +/- -/+  
مَا أَنتُمْ عَلَيْهِ بِفَاتِنِينَ
Yoruba
 
ẹ kò lè fi ṣi ẹnì kan kan lọ́nà

Ayah  37:163  الأية
    +/- -/+  
إِلَّا مَنْ هُوَ صَالِ الْجَحِيمِ
Yoruba
 
Àfi ẹni tí ó bá fẹ́ wọ inú iná Jẹhīm.

Ayah  37:164  الأية
    +/- -/+  
وَمَا مِنَّا إِلَّا لَهُ مَقَامٌ مَّعْلُومٌ
Yoruba
 
Kò sí ẹnì kan nínú àwa (mọlāika) àfi kí ó ní ibùdúró tí wọ́n ti mọ̀.

Ayah  37:165  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّا لَنَحْنُ الصَّافُّونَ
Yoruba
 
Dájúdájú àwa, a kúkú wà ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ni.

Ayah  37:166  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّا لَنَحْنُ الْمُسَبِّحُونَ
Yoruba
 
Àti pé dájúdájú àwa, àwa kúkú ni olùṣàfọ̀mọ́ (fún Allāhu).

Ayah  37:167  الأية
    +/- -/+  

Ayah  37:168  الأية
    +/- -/+  
لَوْ أَنَّ عِندَنَا ذِكْرًا مِّنَ الْأَوَّلِينَ
Yoruba
 
"Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú a bá ní (tírà) ìrántí kan nínú (àwọn tírà) àwọn ẹni àkọ́kọ́,

Ayah  37:169  الأية
    +/- -/+  
لَكُنَّا عِبَادَ اللهِ الْمُخْلَصِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú àwa ìbá jẹ́ ẹrúsìn Allāhu, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo)."

Ayah  37:170  الأية
    +/- -/+  
فَكَفَرُوا بِهِ ۖ فَسَوْفَ يَعْلَمُونَ
Yoruba
 
Ṣùgbọ́n wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú (Allāhu). Láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀.

Ayah  37:171  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدْ سَبَقَتْ كَلِمَتُنَا لِعِبَادِنَا الْمُرْسَلِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú ọ̀rọ̀ Wa ti ṣíwájú fún àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn Òjíṣẹ́.

Ayah  37:172  الأية
    +/- -/+  
إِنَّهُمْ لَهُمُ الْمَنصُورُونَ
Yoruba
 
Dájúdájú àwọn, àwọn l'a kúkú máa ṣàrànṣe fún.

Ayah  37:173  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّ جُندَنَا لَهُمُ الْغَالِبُونَ
Yoruba
 
Àti pé dájúdájú àwọn ọmọ ogun Wa, àwọn kúkú ni olùborí.

Ayah  37:174  الأية
    +/- -/+  
فَتَوَلَّ عَنْهُمْ حَتَّىٰ حِينٍ
Yoruba
 
Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn fún ìgbà díẹ̀.

Ayah  37:175  الأية
    +/- -/+  
وَأَبْصِرْهُمْ فَسَوْفَ يُبْصِرُونَ
Yoruba
 
Àti pé máa wò wọ́n níran ná, àwọn náà ń bọ̀ wá ríran wò.

Ayah  37:176  الأية
    +/- -/+  
أَفَبِعَذَابِنَا يَسْتَعْجِلُونَ
Yoruba
 
Ṣé ìyà Wa ni wọ́n ń wá pẹ̀lú ìkánjú?

Ayah  37:177  الأية
    +/- -/+  
فَإِذَا نَزَلَ بِسَاحَتِهِمْ فَسَاءَ صَبَاحُ الْمُنذَرِينَ
Yoruba
 
Nígbà tí ó bá sọ̀kalẹ̀ sí gbàgede wọn, òwúrọ̀ ọjọ́ náà yó sì burú fún àwọn ẹni-akìlọ̀-fún.

Ayah  37:178  الأية
    +/- -/+  
وَتَوَلَّ عَنْهُمْ حَتَّىٰ حِينٍ
Yoruba
 
Kúrò lọ́dọ̀ wọn títí di ìgbà kan ná.

Ayah  37:179  الأية
    +/- -/+  
وَأَبْصِرْ فَسَوْفَ يُبْصِرُونَ
Yoruba
 
Àti pé máa wò wọ́n níran ná, àwọn náà ń bọ̀ wá ríran wò.

Ayah  37:180  الأية
    +/- -/+  
سُبْحَانَ رَبِّكَ رَبِّ الْعِزَّةِ عَمَّا يَصِفُونَ
Yoruba
 
Mímọ́ ni fún Olúwa rẹ, Olúwa (tó ni) agbára, tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀).

Ayah  37:181  الأية
    +/- -/+  
وَسَلَامٌ عَلَى الْمُرْسَلِينَ
Yoruba
 
Kí àlàáfíà máa bá àwọn Òjíṣẹ́

Ayah  37:182  الأية
    +/- -/+  
وَالْحَمْدُ لِلَّهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ
Yoruba
 
Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
 


© EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us