Àwọn ọkùnrin ní ìpín nínú ohun tí òbí méjèèjì àti ẹbí fi sílẹ̀. Àti pé àwọn obìnrin náà ní ìpín nínú ohun tí òbí méjéèjì àti ẹbí fi sílẹ̀. Nínú ohun tó kéré nínú rẹ̀ tàbí tó pọ̀; (ó jẹ́) ìpín tí wọ́n ti pín (tí wọ́n ti ṣàdáyanrí rẹ̀ fún wọn).
Tiyín ni ìlàjì ohun tí àwọn ìyàwó yín fi sílẹ̀, tí wọn kò bá ní ọmọ. Tí wọ́n bá sì ní ọmọ, tiyín ni ìdá kan nínú ìdá mẹ́rin ohun tí wọ́n fi sílẹ̀, lẹ́yìn àsọọ́lẹ̀ tí wọ́n sọ tàbí gbèsè. Tiwọn sì ni ìdá kan nínú ìdá mẹ́rin ohun tí ẹ fi sílẹ̀, tí ẹ̀yin kò bá ní ọmọ láyé. Tí ẹ bá ní ọmọ láyé, ìdá kan nínú ìdá mẹ́jọ ni tiwọn nínú ohun tí ẹ fi sílẹ̀ lẹ́yìn àsọọ́lẹ̀ tí ẹ sọ tàbí gbèsè. Tí ọkùnrin kan tàbí obìnrin kan tí wọ́n fẹ́ jogún rẹ̀ kò bá ní òbí àti ọmọ, tí ó sì ní arákùnrin kan tàbí arábìnrin kan, ìdá kan nínú ìdá mẹ́fà ni ti ìkọ̀ọ̀kan àwọn méjèèjì. Tí wọ́n bá sì pọ̀ ju bẹ́ẹ̀ lọ, wọn yóò dìjọ pín ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta, lẹ́yìn àsọọ́lẹ̀ tí wọ́n sọ tàbí gbèsè, tí kò níí jẹ́ ìpalára. Àsọọ́lẹ̀ (òfin) kan ni láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ni Onímọ̀, Aláfaradà.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe fi èrú jẹ dúkìá yín láààrin ara yín àyàfi kí ó jẹ́ òwò ṣíṣe pẹ̀lú ìyọ́nú láààrin ara yín. Ẹ má ṣe para yín. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Aláàánú si yín.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣe ìyẹn láti fi tayọ ẹnu-ààlà àti láti fi ṣe àbòsí, láìpẹ́ A máa mú un wọ inú Iná. Ìrọ̀rùn sì ni ìyẹn jẹ́ fún Allāhu.
Ìkọ̀ọ̀kan (àwọn dúkìá) ni A ti ṣe àdáyanrí rẹ̀ fún àwọn tí ó máa jogún rẹ̀ nínú ohun tí àwọn òbí àti ẹbí fi sílẹ̀. Àwọn tí ẹ sì búra fún (pé ẹ máa fún ní n̄ǹkan), ẹ fún wọn ní ìpín wọn. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Ẹlẹ́rìí lórí gbogbo n̄ǹkan.
Àwọn tó ń ṣahun, (àwọn) tó ń pa ènìyàn láṣẹ ahun ṣíṣe àti (àwọn) tó ń fi ohun tí Allāhu fún wọn nínú oore àjùlọ Rẹ̀ pamọ́; A ti pèsè ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́.
Kí ni ìpalára tí ó máa ṣe fún wọn tí wọ́n bá gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, tí wọ́n sì ná nínú ohun tí Allāhu ṣe ní arísìkí fún wọn? Allāhu sì jẹ́ Onímọ̀ nípa wọ́n.
Ní ọjọ́ yẹn, àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì yapa Òjíṣẹ́ náà, wọ́n á fẹ́ kí àwọn bá ilẹ̀ dọ́gba (kí wọ́n di erùpẹ̀). Wọn kò sì lè fi ọ̀rọ̀ kan pamọ́ fún Allāhu.
Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, A óò mú wọn wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé. Àwọn ìyàwó mímọ́ ń bẹ fún wọn nínú rẹ̀. A sì máa fi wọ́n sí abẹ́ ibòji tó máa ṣíji bò wọ́n dáradára.
Ṣé ìwọ kò wòye sí àwọn tó ń sọ̀rọ̀ (tí kò sì rí bẹ́ẹ̀) pé dájúdájú àwọn gbàgbọ́ nínú ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú rẹ, tí wọ́n sì ń gbèrò láti gbé ẹjọ́ lọ bá òrìṣà, A sì ti pa wọ́n láṣẹ pé kí wọ́n lòdì sí i. Èṣù sì fẹ́ ṣì wọ́n lọ́nà ní ìṣìnà tó jìnnà.
Báwo ni ó ṣe jẹ́ pé nígbà tí àdánwò kan bá kàn wọ́n nípasẹ̀ ohun tí ọwọ́ wọ́n tì síwájú, lẹ́yìn náà wọ́n máa wá bá ọ, wọ́n yó sì máa fi Allāhu búra pé kò sí ohun tí a gbàlérò bí kò ṣe dáadáa àti ìrẹ́pọ̀.
A kò rán Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ àfi nítorí kí wọ́n lè tẹ̀lé e pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Tí ó bá jẹ́ pé nígbà tí wọ́n ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn, wọ́n wá bá ọ, wọ́n sì tọrọ àforíjìn Allāhu, tí Òjíṣẹ́ sì tún bá wọn tọrọ àforíjìn, wọn ìbá kúkú rí Allāhu ní Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Tí ó bá jẹ́ pé A ṣe é ní ọ̀ran- anyàn fún wọn pé: "Ẹ pa ara yín tàbí ẹ jáde kúrò nínú ìlú yín," wọn kò níí ṣe é àfi díẹ̀ nínú wọn. Tí ó bá tún jẹ́ pé wọ́n ṣe ohun tí A fi ń ṣe wáàsí fún wọn ni, ìbá jẹ́ oore àti ìdúróṣinṣin tó lágbára jùlọ fún wọn.
Nígbà tí wọ́n bá ki yín ní kíkí kan, ẹ kí wọn (padà) pẹ̀lú èyí tó dára jù ú lọ tàbí kí ẹ dá a padà (pẹ̀lú bí wọ́n ṣe ki yín). Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Olùṣírò lórí gbogbo n̄ǹkan.
Wọ́n ń fi ara pamọ́ fún àwọn ènìyàn, wọn kò sì lè fara pamọ́ fún Allāhu (nítorí pé) Ó wà pẹ̀lú wọn (pẹ̀lú ìmọ̀ Rẹ̀) nígbà tí wọ́n ń pètepèrò lórí ohun tí (Allāhu) kò yọ́nú sí nínú ọ̀rọ̀ sísọ. Allāhu sì ń jẹ́ Alámọ̀tán nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Kíyè sí i, ẹ̀yin wọ̀nyí ni ẹ̀ ń bá wọn mú àwíjàre wá nílé ayé. Ta ni ó máa bá wọn mú àwíjàre wá ní ọ̀dọ̀ Allāhu ní Ọjọ́ Àjíǹde? Tàbí ta ni ó máa jẹ́ aláàbò fún wọn?
Dájúdájú mo máa ṣì wọ́n lọ́nà. Dájúdájú mo máa tàn wọ́n jẹ. Dájúdájú mo máa pa wọ́n láṣẹ, wọn yó sì máa gé etí ẹran-ọ̀sìn (láti yà á sọ́tọ̀ fún òrìṣà). Dájúdájú mo máa pa wọ́n láṣẹ, wọn yó sì máa yí ẹ̀sìn Allāhu padà." Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú Èṣù ní ọ̀rẹ́ lẹ́yìn Allāhu, dájúdájú ó ti ṣòfò ní òfò pọ́nńbélé.