Ìjọ (Ànábì) Nūh pe òdodo ní irọ́ ṣíwájú wọn. Àwọn ìjọ (mìíràn) lẹ́yìn wọn (náà ṣe bẹ́ẹ̀). Ìjọ kọ̀ọ̀kan ló gbèrò láti ki Òjíṣẹ́ wọn mọ́lẹ̀. Wọ́n fi irọ́ ja òdodo níyàn nítorí kí wọ́n lè fi wó òdodo lulẹ̀. Mo sì gbá wọn mú. Nítorí náà, báwo ni ìyà (tí Mo fi jẹ wọ́n) ti rí (lára wọn ná)!
Ní òní ni A óò san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́. Kò sì sí àbòsí kan ní́òní. Dájúdájú Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́.
Àti pé Allāhu l'Ó máa fi òdodo dájọ́. Àwọn tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀, wọn kò lè ṣe ìdájọ́ kan kan. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Olùríran.
Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe rí? Wọ́n ní agbára jù wọ́n lọ. Wọ́n sì lo ilẹ̀ (fún oko dídá jù wọ́n lọ). Síbẹ̀síbẹ̀ Allāhu mú wọn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Kò sì sí olùṣọ́ kan fún wọn (níbi ìyà) Allāhu.
"(Ohun tí ẹ jọ́sìn fún) lẹ́yìn Allāhu (dà)?" Wọ́n á wí pé: "Wọ́n ti di òfò mọ́ wa lọ́wọ́. Bẹ́ẹ̀ tiẹ̀ kọ́, àwa kì í pe n̄ǹkan kan tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀." Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣi àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́nà.
Nítorí náà, ṣe sùúrù. Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Ó ṣeé ṣe kí A fi apá kan èyí tí A ṣe ní ìlérí fún wọn hàn ọ́ tàbí kí A ti gba ẹ̀mí rẹ (ṣíwájú àsìkò náà). Ọ̀dọ̀ Wa kúkú ni wọ́n máa dá wọn padà sí.