Prev  

56. Surah Al-Wâqi'ah سورة الواقعة

  Next  




Ayah  56:1  الأية
    +/- -/+  
بِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
إِذَا وَقَعَتِ الْوَاقِعَةُ
Yoruba
 
Nígbà tí Ìṣẹ̀lẹ̀ (Àjíǹde) bá ṣẹlẹ̀,

Ayah  56:2  الأية
    +/- -/+  
لَيْسَ لِوَقْعَتِهَا كَاذِبَةٌ
Yoruba
 
- kò sí irọ́ kan nípa ìṣẹ̀lẹ̀ rẹ̀-

Ayah  56:3  الأية
    +/- -/+  
خَافِضَةٌ رَّافِعَةٌ
Yoruba
 
Ó máa mú (àwọn kan) wálẹ̀ (sínú Iná), ó sì máa gbé (àwọn kan) sókè (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra).

Ayah  56:4  الأية
    +/- -/+  
إِذَا رُجَّتِ الْأَرْضُ رَجًّا
Yoruba
 
Nígbà tí wọ́n bá mi ilẹ̀ tìtì ní mímìtìtì,

Ayah  56:5  الأية
    +/- -/+  
وَبُسَّتِ الْجِبَالُ بَسًّا
Yoruba
 
Àti nígbà tí Wọ́n bá fọ́ àwọn àpáta ní fífọ́ wómúwómú,

Ayah  56:6  الأية
    +/- -/+  

Ayah  56:7  الأية
    +/- -/+  

Ayah  56:8  الأية
    +/- -/+  
فَأَصْحَابُ الْمَيْمَنَةِ مَا أَصْحَابُ الْمَيْمَنَةِ
Yoruba
 
Àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún, kí ni (ó máa ti dára tó fún) àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún?

Ayah  56:9  الأية
    +/- -/+  
وَأَصْحَابُ الْمَشْأَمَةِ مَا أَصْحَابُ الْمَشْأَمَةِ
Yoruba
 
Àwọn èrò ọwọ́ òsì, kí ni (ó máa ti burú tó fún) àwọn èrò ọwọ́ òsì?

Ayah  56:10  الأية
    +/- -/+  
وَالسَّابِقُونَ السَّابِقُونَ
Yoruba
 
Àwọn aṣíwájú sì ni àwọn aṣíwájú.

Ayah  56:11  الأية
    +/- -/+  
أُولَٰئِكَ الْمُقَرَّبُونَ
Yoruba
 
Àwọn wọ̀nyẹn ni alásùn-únmọ́ (Allāhu)


Ayah  56:13  الأية
    +/- -/+  
ثُلَّةٌ مِّنَ الْأَوَّلِينَ
Yoruba
 
Wọ́n pọ̀ nínú àwọn ẹni àkọ́kọ́.

Ayah  56:14  الأية
    +/- -/+  
وَقَلِيلٌ مِّنَ الْآخِرِينَ
Yoruba
 
Wọ́n sì kéré nínú àwọn ẹni Ìkẹ́yìn.

Ayah  56:15  الأية
    +/- -/+  
عَلَىٰ سُرُرٍ مَّوْضُونَةٍ
Yoruba
 
(Wọn yóò wà) lórí ìtẹ́ tí wọ́n fi góòlù hun.

Ayah  56:16  الأية
    +/- -/+  
مُّتَّكِئِينَ عَلَيْهَا مُتَقَابِلِينَ
Yoruba
 
Wọn yóò rọ̀gbọ̀kú sórí rẹ̀, wọn sì máa dojú kọra wọn.

Ayah  56:17  الأية
    +/- -/+  
يَطُوفُ عَلَيْهِمْ وِلْدَانٌ مُّخَلَّدُونَ
Yoruba
 
Àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí kò níí darúgbó yó sì máa lọ bọ̀ láààrin wọn

Ayah  56:18  الأية
    +/- -/+  
بِأَكْوَابٍ وَأَبَارِيقَ وَكَأْسٍ مِّن مَّعِينٍ
Yoruba
 
Pẹ̀lú àwọn ife omi, ohun ìrọmi fẹ̀ǹfẹ̀ àti ife ọtí aládùn láti inú odò kan tó ń ṣàn (káà kiri ọ̀dọ̀ wọn).

Ayah  56:19  الأية
    +/- -/+  
لَّا يُصَدَّعُونَ عَنْهَا وَلَا يُنزِفُونَ
Yoruba
 
Kò níí fọ́ wọn lórí; kò sì níí mú wọn húnrìrà.

Ayah  56:20  الأية
    +/- -/+  
وَفَاكِهَةٍ مِّمَّا يَتَخَيَّرُونَ
Yoruba
 
Èso tí wọn yóò máa ṣẹ̀ṣà nínú rẹ̀ (tún wà fún wọn).

Ayah  56:21  الأية
    +/- -/+  
وَلَحْمِ طَيْرٍ مِّمَّا يَشْتَهُونَ
Yoruba
 
Àti ẹran ẹyẹ, èyí tí wọ́n ń fẹ́ (yó wà fún wọn).

Ayah  56:22  الأية
    +/- -/+  

Ayah  56:23  الأية
    +/- -/+  
كَأَمْثَالِ اللُّؤْلُؤِ الْمَكْنُونِ
Yoruba
 
Wọ́n dà bí àlúùúlù (òkúta olówó-iye-bíye) tí wọ́n fi pamọ́ sínú apó rẹ̀.

Ayah  56:24  الأية
    +/- -/+  
جَزَاءً بِمَا كَانُوا يَعْمَلُونَ
Yoruba
 
(Ìwọ̀nyí ni) ẹ̀san fún ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

Ayah  56:25  الأية
    +/- -/+  
لَا يَسْمَعُونَ فِيهَا لَغْوًا وَلَا تَأْثِيمًا
Yoruba
 
Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ àti ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra.

Ayah  56:26  الأية
    +/- -/+  
إِلَّا قِيلًا سَلَامًا سَلَامًا
Yoruba
 
Àyàfi ọ̀rọ̀ àlàáfíà, àlàáfíà.

Ayah  56:27  الأية
    +/- -/+  
وَأَصْحَابُ الْيَمِينِ مَا أَصْحَابُ الْيَمِينِ
Yoruba
 
Àwọn èrò ọwọ́ ọtún, kí ni (ó máa ti dára tó fún) àwọn èrò ọwọ́ ọtún?

Ayah  56:28  الأية
    +/- -/+  



Ayah  56:31  الأية
    +/- -/+  


Ayah  56:33  الأية
    +/- -/+  
لَّا مَقْطُوعَةٍ وَلَا مَمْنُوعَةٍ
Yoruba
 
Tí kò níí já (ní ọ̀dọ̀ wọn), kò sì níí dèèwọ̀ (fún wọn).

Ayah  56:34  الأية
    +/- -/+  
وَفُرُشٍ مَّرْفُوعَةٍ
Yoruba
 
(Wọ́n máa wà lórí) ìtẹ́ tí wọ́n gbé sókè.

Ayah  56:35  الأية
    +/- -/+  
إِنَّا أَنشَأْنَاهُنَّ إِنشَاءً
Yoruba
 
Dájúdájú Àwa dá (àwọn obìnrin Ọgbà Ìdẹ̀ra) ní ẹ̀dá kan (tó yàtọ̀ sí tayé).

Ayah  56:36  الأية
    +/- -/+  

Ayah  56:37  الأية
    +/- -/+  

Ayah  56:38  الأية
    +/- -/+  

Ayah  56:39  الأية
    +/- -/+  
ثُلَّةٌ مِّنَ الْأَوَّلِينَ
Yoruba
 
Wọ́n pọ̀ nínú àwọn ẹni àkọ́kọ́.

Ayah  56:40  الأية
    +/- -/+  
وَثُلَّةٌ مِّنَ الْآخِرِينَ
Yoruba
 
Wọ́n tún pọ̀ nínú àwọn ẹni Ìkẹ́yìn.

Ayah  56:41  الأية
    +/- -/+  
وَأَصْحَابُ الشِّمَالِ مَا أَصْحَابُ الشِّمَالِ
Yoruba
 
Àwọn èrò ọwọ́ òsì, kí ni (ó máa ti burú tó fún) àwọn èrò ọwọ́ òsì?

Ayah  56:42  الأية
    +/- -/+  
فِي سَمُومٍ وَحَمِيمٍ
Yoruba
 
(Wọn yóò wà) nínú atẹ́gùn gbígbóná (iná) àti omi tó gbóná parí,

Ayah  56:43  الأية
    +/- -/+  


Ayah  56:45  الأية
    +/- -/+  
إِنَّهُمْ كَانُوا قَبْلَ ذَٰلِكَ مُتْرَفِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú wọ́n ti jẹ́ onígbẹdẹmukẹ ṣíwájú ìyẹn.

Ayah  56:46  الأية
    +/- -/+  
وَكَانُوا يُصِرُّونَ عَلَى الْحِنثِ الْعَظِيمِ
Yoruba
 
Wọ́n sì máa ń ṣoríkunkun lórí ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.

Ayah  56:47  الأية
    +/- -/+  
وَكَانُوا يَقُولُونَ أَئِذَا مِتْنَا وَكُنَّا تُرَابًا وَعِظَامًا أَإِنَّا لَمَبْعُوثُونَ
Yoruba
 
Wọ́n sì máa ń wí pé: "Ṣé nígbà tí a bá di òkú, tí a sì di erùpẹ̀ àti egungun, ǹjẹ́ Wọn yóò tún gbé wa dìde ni?

Ayah  56:48  الأية
    +/- -/+  
أَوَآبَاؤُنَا الْأَوَّلُونَ
Yoruba
 
Ṣé àti àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́?"

Ayah  56:49  الأية
    +/- -/+  
قُلْ إِنَّ الْأَوَّلِينَ وَالْآخِرِينَ
Yoruba
 
Sọ pé: "Dájúdájú àwọn ẹni àkọ́kọ́ àti àwọn ẹni Ìkẹ́yìn,

Ayah  56:50  الأية
    +/- -/+  
لَمَجْمُوعُونَ إِلَىٰ مِيقَاتِ يَوْمٍ مَّعْلُومٍ
Yoruba
 
Dájúdájú A óò kó wọn jọ papọ̀ ní àkókò ọjọ́ kan tí A ti mọ̀."

Ayah  56:51  الأية
    +/- -/+  
ثُمَّ إِنَّكُمْ أَيُّهَا الضَّالُّونَ الْمُكَذِّبُونَ
Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, dájúdájú ẹ̀yin olùṣìnà, olùpe-òdodo-nírọ́,

Ayah  56:52  الأية
    +/- -/+  
لَآكِلُونَ مِن شَجَرٍ مِّن زَقُّومٍ
Yoruba
 
Dájúdájú ẹ̀yin máa jẹ nínú igi zaƙƙūm (igi iwọ).

Ayah  56:53  الأية
    +/- -/+  
فَمَالِئُونَ مِنْهَا الْبُطُونَ
Yoruba
 
Ikùn yín sì máa kún bámúbámú fún (jíjẹ) igi náà.

Ayah  56:54  الأية
    +/- -/+  
فَشَارِبُونَ عَلَيْهِ مِنَ الْحَمِيمِ
Yoruba
 
Ẹ̀yin yó sì máa mu omi tó gbóná parí lé e lórí.

Ayah  56:55  الأية
    +/- -/+  
فَشَارِبُونَ شُرْبَ الْهِيمِ
Yoruba
 
Ẹ̀yin yóò máa mu ún ní ìmumi ràkúnmí tí òǹgbẹ ń gbẹ.

Ayah  56:56  الأية
    +/- -/+  
هَٰذَا نُزُلُهُمْ يَوْمَ الدِّينِ
Yoruba
 
Èyí ni n̄ǹkan àlejò wọn ní Ọjọ́ ẹ̀san.

Ayah  56:57  الأية
    +/- -/+  
نَحْنُ خَلَقْنَاكُمْ فَلَوْلَا تُصَدِّقُونَ
Yoruba
 
Àwa l'A ṣẹ̀dá yín. Kí ni kò jẹ́ kí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo!

Ayah  56:58  الأية
    +/- -/+  
أَفَرَأَيْتُم مَّا تُمْنُونَ
Yoruba
 
Ẹ sọ fún Mi nípa àtọ̀ tí ẹ̀ ń dà jáde (sínú àpòlùkẹ́),

Ayah  56:59  الأية
    +/- -/+  
أَأَنتُمْ تَخْلُقُونَهُ أَمْ نَحْنُ الْخَالِقُونَ
Yoruba
 
ṣé ẹ̀yin lẹ ṣẹ̀dá rẹ̀ ni tàbí Àwa l'A ṣẹ̀dá rẹ̀?

Ayah  56:60  الأية
    +/- -/+  
نَحْنُ قَدَّرْنَا بَيْنَكُمُ الْمَوْتَ وَمَا نَحْنُ بِمَسْبُوقِينَ
Yoruba
 
Àwa l'A yan kádàrá (ọjọ́) ikú fún gbogbo yín. Kò sì sí ẹni tó lè dá Wa lágara

Ayah  56:61  الأية
    +/- -/+  
عَلَىٰ أَن نُّبَدِّلَ أَمْثَالَكُمْ وَنُنشِئَكُمْ فِي مَا لَا تَعْلَمُونَ
Yoruba
 
Láti yí irú yín padà (láti inú erùpẹ̀ sí alààyè), kí á sì ṣẹ̀dá yín (ní ọ̀tun) sínú ohun tí ẹ kò mọ̀ (nínú àwọn ìrísí).

Ayah  56:62  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدْ عَلِمْتُمُ النَّشْأَةَ الْأُولَىٰ فَلَوْلَا تَذَكَّرُونَ
Yoruba
 
Ẹ kúkú mọ ìṣẹ̀dá àkọ́kọ́ (pé láti ibi àìsí ni ẹ ti di alààyè), ẹ kò ṣe lo ìrántí?

Ayah  56:63  الأية
    +/- -/+  
أَفَرَأَيْتُم مَّا تَحْرُثُونَ
Yoruba
 
Ẹ sọ fún Mi nípa n̄ǹkan tí ẹ̀ ń gbìn sínú ilẹ̀,

Ayah  56:64  الأية
    +/- -/+  
أَأَنتُمْ تَزْرَعُونَهُ أَمْ نَحْنُ الزَّارِعُونَ
Yoruba
 
ṣé ẹ̀yin l'ẹ̀ ń jẹ́ kí ó hù jáde tàbí Àwa l'À ń jẹ́ kí ó hù jáde?

Ayah  56:65  الأية
    +/- -/+  
لَوْ نَشَاءُ لَجَعَلْنَاهُ حُطَامًا فَظَلْتُمْ تَفَكَّهُونَ
Yoruba
 
Tí A bá fẹ́ ni, Àwa ìbá sọ ọ́ di gbígbẹ, ẹ̀yin yó sì máa ṣèèmọ̀ (tí ẹ óò máa ká àbámọ̀).

Ayah  56:66  الأية
    +/- -/+  
إِنَّا لَمُغْرَمُونَ
Yoruba
 
(Ẹ̀yin yó sì wí pé:) "Dájúdájú àwa ti di onígbèsè."

Ayah  56:67  الأية
    +/- -/+  
بَلْ نَحْنُ مَحْرُومُونَ
Yoruba
 
(Àwọn mìíràn yó sì wí pé:) "Rárá o! Wọ́n ṣe ìkórè oko ní èèwọ̀ fún wa ni."

Ayah  56:68  الأية
    +/- -/+  
أَفَرَأَيْتُمُ الْمَاءَ الَّذِي تَشْرَبُونَ
Yoruba
 
Ẹ sọ fún mi nípa omi tí ẹ̀ ń mu,

Ayah  56:69  الأية
    +/- -/+  
أَأَنتُمْ أَنزَلْتُمُوهُ مِنَ الْمُزْنِ أَمْ نَحْنُ الْمُنزِلُونَ
Yoruba
 
ṣé ẹ̀yin l'ẹ̀ ń sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti inú ẹ̀ṣújò ni tàbí Àwa l'À ń sọ̀ ọ́ kalẹ̀?

Ayah  56:70  الأية
    +/- -/+  
لَوْ نَشَاءُ جَعَلْنَاهُ أُجَاجًا فَلَوْلَا تَشْكُرُونَ
Yoruba
 
Tí A bá fẹ́ ni, Àwa ìbá ṣe é ní omi tó móró. Ẹ ò ṣe máa dúpẹ́?

Ayah  56:71  الأية
    +/- -/+  
أَفَرَأَيْتُمُ النَّارَ الَّتِي تُورُونَ
Yoruba
 
Ẹ sọ fún Mi nípa iná tí ẹ̀ ń dá,

Ayah  56:72  الأية
    +/- -/+  
أَأَنتُمْ أَنشَأْتُمْ شَجَرَتَهَا أَمْ نَحْنُ الْمُنشِئُونَ
Yoruba
 
ṣé ẹ̀yin l'ẹ ṣẹ̀dá igi rẹ̀ ni tàbí Àwa ni Aṣẹ̀dá?

Ayah  56:73  الأية
    +/- -/+  
نَحْنُ جَعَلْنَاهَا تَذْكِرَةً وَمَتَاعًا لِّلْمُقْوِينَ
Yoruba
 
Àwa ṣe iná ayé ní ìrántí (fún Iná ọ̀run) àti n̄ǹkan èlò fún àwọn onírìn-àjò.

Ayah  56:74  الأية
    +/- -/+  
فَسَبِّحْ بِاسْمِ رَبِّكَ الْعَظِيمِ
Yoruba
 
Nítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Atóbi.

Ayah  56:75  الأية
    +/- -/+  
فَلَا أُقْسِمُ بِمَوَاقِعِ النُّجُومِ
Yoruba
 
Nítorí náà, Mò ń fi àwọn àyè tí ìkọ̀ọ̀kan gbólóhùn al-Ƙur'ān wà nínú sánmọ̀ búra.

Ayah  56:76  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّهُ لَقَسَمٌ لَّوْ تَعْلَمُونَ عَظِيمٌ
Yoruba
 
Dájúdájú ìbúra ńlá ni, tí ẹ bá mọ̀.

Ayah  56:77  الأية
    +/- -/+  
إِنَّهُ لَقُرْآنٌ كَرِيمٌ
Yoruba
 
Dájúdájú (al-Ƙur'ān) ni n̄ǹkan kíké alápọ̀n-ọ́nlé.

Ayah  56:78  الأية
    +/- -/+  
فِي كِتَابٍ مَّكْنُونٍ
Yoruba
 
Ó wà nínú Tírà kan tí wọ́n ń fi ààbò bò (ìyẹn Laohul-Mahfūṭḥ).

Ayah  56:79  الأية
    +/- -/+  
لَّا يَمَسُّهُ إِلَّا الْمُطَهَّرُونَ
Yoruba
 
Kò sí ẹni tó lè fọwọ́ kàn án (ní ọ̀dọ̀ Allāhu) àfi àwọn ẹni mímọ́ (ìyẹn, àwọn mọlāika).

Ayah  56:80  الأية
    +/- -/+  
تَنزِيلٌ مِّن رَّبِّ الْعَالَمِينَ
Yoruba
 
Wọ́n sọ al-Ƙur'ān kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

Ayah  56:81  الأية
    +/- -/+  
أَفَبِهَٰذَا الْحَدِيثِ أَنتُم مُّدْهِنُونَ
Yoruba
 
Nítorí náà, ṣé ọ̀rọ̀ (al-Ƙur'ān) yìí l'ẹ̀ ń pè ní irọ́?

Ayah  56:82  الأية
    +/- -/+  
وَتَجْعَلُونَ رِزْقَكُمْ أَنَّكُمْ تُكَذِّبُونَ
Yoruba
 
Ẹ sì ń sọ ìdúpẹ́ arísìkí yín di pé dájúdájú ẹ̀ ń pe òdodo ní irọ́.

Ayah  56:83  الأية
    +/- -/+  
فَلَوْلَا إِذَا بَلَغَتِ الْحُلْقُومَ
Yoruba
 
Kí ni ó máa ti rí (fún yín) nígbà tí ẹ̀mí (yín) bá dé ọ̀nà ọ̀fun,