Prev  

63. Surah Al-Munâfiqûn سورة المنافقون

  Next  




Ayah  63:1  الأية
    +/- -/+  
بِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
إِذَا جَاءَكَ الْمُنَافِقُونَ قَالُوا نَشْهَدُ إِنَّكَ لَرَسُولُ اللهِ ۗ وَاللهُ يَعْلَمُ إِنَّكَ لَرَسُولُهُ وَاللهُ يَشْهَدُ إِنَّ الْمُنَافِقِينَ لَكَاذِبُونَ
Yoruba
 
Nígbà tí àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí bá wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, wọ́n á wí pé: "À ń jẹ́rìí pé dájúdájú ìwọ, Òjíṣẹ́ Allāhu ni ọ́." Allāhu sì mọ̀ pé dájúdájú ìwọ, Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ni ọ́. Allāhu sì ń jẹ́rìí pé dájúdájú àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí, òpùrọ́ ni wọ́n.

Ayah  63:2  الأية
    +/- -/+  
اتَّخَذُوا أَيْمَانَهُمْ جُنَّةً فَصَدُّوا عَن سَبِيلِ اللهِ ۚ إِنَّهُمْ سَاءَ مَا كَانُوا يَعْمَلُونَ
Yoruba
 
Wọ́n fi àwọn ìbúra wọn ṣe ààbò (fún ẹ̀mí ara wọn), wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu; dájúdájú ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ burú.

Ayah  63:3  الأية
    +/- -/+  
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ آمَنُوا ثُمَّ كَفَرُوا فَطُبِعَ عَلَىٰ قُلُوبِهِمْ فَهُمْ لَا يَفْقَهُونَ
Yoruba
 
(Wọ́n ṣe) ìyẹn nítorí pé, wọ́n gbàgbọ́, lẹ́yìn náà wọ́n ṣàì gbàgbọ́. Nítorí náà, A ti fi èdídí dí ọkàn wọn; wọn kò sì níí gbọ́ àgbọ́yé.

Ayah  63:4  الأية
    +/- -/+  
وَإِذَا رَأَيْتَهُمْ تُعْجِبُكَ أَجْسَامُهُمْ ۖ وَإِن يَقُولُوا تَسْمَعْ لِقَوْلِهِمْ ۖ كَأَنَّهُمْ خُشُبٌ مُّسَنَّدَةٌ ۖ يَحْسَبُونَ كُلَّ صَيْحَةٍ عَلَيْهِمْ ۚ هُمُ الْعَدُوُّ فَاحْذَرْهُمْ ۚ قَاتَلَهُمُ اللهُ ۖ أَنَّىٰ يُؤْفَكُونَ
Yoruba
 
Nígbà tí o bá rí wọn, ìrísí wọn yóò jọ ọ́ lójú. Tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀, ìwọ yóò tẹ́tí́gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn. Wọ́n sì dà bí igi tí wọ́n gbé ti ògiri. Wọ́n sì ń lérò pé gbogbo igbe (ìbòsí) ń bẹ lórí wọn (nípa ìṣọ̀bẹ-ṣèlu wọn). Ọ̀tá ni wọ́n. Nítorí náà, ṣọ́ra fún wọn. Allāhu ti ṣẹ́bi lé wọn. Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo!

Ayah  63:5  الأية
    +/- -/+  
وَإِذَا قِيلَ لَهُمْ تَعَالَوْا يَسْتَغْفِرْ لَكُمْ رَسُولُ اللهِ لَوَّوْا رُءُوسَهُمْ وَرَأَيْتَهُمْ يَصُدُّونَ وَهُم مُّسْتَكْبِرُونَ
Yoruba
 
Àti pé nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: "Ẹ wá kí Òjíṣẹ́ ba yín tọrọ àforíjìn." Wọ́n á gbúnrí. O sì máa rí wọn tí wọn yóò máa gbúnrí lọ, tí wọn yóò máa ṣègbéraga.

Ayah  63:6  الأية
    +/- -/+  
سَوَاءٌ عَلَيْهِمْ أَسْتَغْفَرْتَ لَهُمْ أَمْ لَمْ تَسْتَغْفِرْ لَهُمْ لَن يَغْفِرَ اللهُ لَهُمْ ۚ إِنَّ اللهَ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الْفَاسِقِينَ
Yoruba
 
Bákan náà ni fún wọn; yálà o bá wọn tọrọ àforíjìn tàbí o ò bá wọn tọrọ àforíjìn. Allāhu kò níí foríjìn wọ́n. Dájúdájú Allāhu kò nií fi ọ̀nà mọ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.

Ayah  63:7  الأية
    +/- -/+  
هُمُ الَّذِينَ يَقُولُونَ لَا تُنفِقُوا عَلَىٰ مَنْ عِندَ رَسُولِ اللهِ حَتَّىٰ يَنفَضُّوا ۗ وَلِلَّهِ خَزَائِنُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَلَٰكِنَّ الْمُنَافِقِينَ لَا يَفْقَهُونَ
Yoruba
 
Àwọn ni àwọn tó ń wí pé: "Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ ná owó fún àwọn tó wà lọ́dọ̀ Ójíṣẹ́ Allāhu títí wọn yóò fi fọ́nká. Ti Allāhu sì ni àwọn ilé ọrọ̀ sánmọ̀ àti ilẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí kò gbọ́ àgbọ́yé.

Ayah  63:8  الأية
    +/- -/+  
يَقُولُونَ لَئِن رَّجَعْنَا إِلَى الْمَدِينَةِ لَيُخْرِجَنَّ الْأَعَزُّ مِنْهَا الْأَذَلَّ ۚ وَلِلَّهِ الْعِزَّةُ وَلِرَسُولِهِ وَلِلْمُؤْمِنِينَ وَلَٰكِنَّ الْمُنَافِقِينَ لَا يَعْلَمُونَ
Yoruba
 
Wọ́n ń wí pé: "Dájúdájú tí a bá padà dé sínú ìlú Mọdīnah, ńṣe ni àwọn alágbára (ìlú) yóò yọ àwọn ẹni yẹpẹrẹ jáde kúrò nínú ìlú." Agbára sì ń jẹ́ ti Allāhu, àti ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo, ṣùgbọ́n àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí kò mọ̀.

Ayah  63:9  الأية
    +/- -/+  
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تُلْهِكُمْ أَمْوَالُكُمْ وَلَا أَوْلَادُكُمْ عَن ذِكْرِ اللهِ ۚ وَمَن يَفْعَلْ ذَٰلِكَ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الْخَاسِرُونَ
Yoruba
 
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe jẹ́ kí àwọn dúkìá yín àti àwọn ọmọ yín kó àìrójú ba yín níbi ìrántí Allāhu. Ẹnikẹ́ni tí ó bá kó sínú (àìrójú) yẹn, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni ẹni òfò.

Ayah  63:10  الأية
    +/- -/+  
وَأَنفِقُوا مِن مَّا رَزَقْنَاكُم مِّن قَبْلِ أَن يَأْتِيَ أَحَدَكُمُ الْمَوْتُ فَيَقُولَ رَبِّ لَوْلَا أَخَّرْتَنِي إِلَىٰ أَجَلٍ قَرِيبٍ فَأَصَّدَّقَ وَأَكُن مِّنَ الصَّالِحِينَ
Yoruba
 
Ẹ ná nínú ohun tí A pèsè fún yín ṣíwájú kí ikú tó dé bá ẹnì kan yín, kí ó wá wí pé: "Olúwa mi, kí ó sì jẹ́ pé O lọ́ mi lára sí i títí di ìgbà kan tó súnmọ́, èmi ìbá sì lè máa tọrẹ, èmi ìbá sì wà lára àwọn ẹni rere."

Ayah  63:11  الأية
    +/- -/+  
وَلَن يُؤَخِّرَ اللهُ نَفْسًا إِذَا جَاءَ أَجَلُهَا ۚ وَاللهُ خَبِيرٌ بِمَا تَعْمَلُونَ
Yoruba
 
Allāhu kò sì níí lọ́ ẹ̀mí kan lára nígbà tí ọjọ́ ikú rẹ̀ bá dé. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
 


© EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us