Prev  

74. Surah Al-Muddaththir سورة المدّثر

  Next  




Ayah  74:1  الأية
    +/- -/+  
بِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ


Ayah  74:3  الأية
    +/- -/+  



Ayah  74:6  الأية
    +/- -/+  
وَلَا تَمْنُن تَسْتَكْثِرُ
Yoruba
 
Má ṣe tọrẹ nítorí kí o lè rí púpọ̀ gbà.

Ayah  74:7  الأية
    +/- -/+  

Ayah  74:8  الأية
    +/- -/+  
فَإِذَا نُقِرَ فِي النَّاقُورِ
Yoruba
 
Nígbà tí wọ́n bá fọn fèrè oníwo fún àjíǹde,

Ayah  74:9  الأية
    +/- -/+  
فَذَٰلِكَ يَوْمَئِذٍ يَوْمٌ عَسِيرٌ
Yoruba
 
Ìyẹn, ní ọjọ́ yẹn, ni ọjọ́ ìnira,

Ayah  74:10  الأية
    +/- -/+  
عَلَى الْكَافِرِينَ غَيْرُ يَسِيرٍ
Yoruba
 
Tí kò níí rọrùn fún àwọn aláìgbàgbọ́.

Ayah  74:11  الأية
    +/- -/+  
ذَرْنِي وَمَنْ خَلَقْتُ وَحِيدًا
Yoruba
 
Fi Mí dá ẹni tí Mo dá ní òun nìkan (ìyẹn nínú ikùn ìyá rẹ̀).

Ayah  74:12  الأية
    +/- -/+  
وَجَعَلْتُ لَهُ مَالًا مَّمْدُودًا
Yoruba
 
Mo sì fún un ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ dúkìá

Ayah  74:13  الأية
    +/- -/+  

Ayah  74:14  الأية
    +/- -/+  

Ayah  74:15  الأية
    +/- -/+  
ثُمَّ يَطْمَعُ أَنْ أَزِيدَ
Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, ó tún ń jẹ̀rankàn pé kí N̄g ṣe àlékún.

Ayah  74:16  الأية
    +/- -/+  
كَلَّا ۖ إِنَّهُ كَانَ لِآيَاتِنَا عَنِيدًا
Yoruba
 
Rárá o! Dájúdájú ó jẹ́ alátakò sí àwọn āyah Wa.

Ayah  74:17  الأية
    +/- -/+  
سَأُرْهِقُهُ صَعُودًا
Yoruba
 
Èmi yóò la ìyà pọ́nkèpọ́nkè bọ̀ ọ́ lọ́rùn (nínú Iná).

Ayah  74:18  الأية
    +/- -/+  
إِنَّهُ فَكَّرَ وَقَدَّرَ
Yoruba
 
Dájúdájú ó ronú (lódì nípa al-Ƙur'ān). Ó sì pinnu (ọ̀rọ̀ kan nínú ẹ̀mí rẹ̀).

Ayah  74:19  الأية
    +/- -/+  

Ayah  74:20  الأية
    +/- -/+  
ثُمَّ قُتِلَ كَيْفَ قَدَّرَ
Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, Wọ́n tún ṣẹ́bi lé e nípa bí ó ṣe pinnu.


Ayah  74:22  الأية
    +/- -/+  
ثُمَّ عَبَسَ وَبَسَرَ
Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, ó fajú ro, ó sì dijú mágbárí.

Ayah  74:23  الأية
    +/- -/+  
ثُمَّ أَدْبَرَ وَاسْتَكْبَرَ
Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, ó pẹ̀yìndà, ó sì ṣègbéraga.

Ayah  74:24  الأية
    +/- -/+  
فَقَالَ إِنْ هَٰذَا إِلَّا سِحْرٌ يُؤْثَرُ
Yoruba
 
Ó sì wí pé: "Kí ni èyí bí kò ṣe idán àtọwọ́dọ́wọ́.

Ayah  74:25  الأية
    +/- -/+  
إِنْ هَٰذَا إِلَّا قَوْلُ الْبَشَرِ
Yoruba
 
Kí ni èyí bí kò ṣe ọ̀rọ̀ abara"


Ayah  74:27  الأية
    +/- -/+  
وَمَا أَدْرَاكَ مَا سَقَرُ
Yoruba
 
Kí l'ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ iná Saƙọr?

Ayah  74:28  الأية
    +/- -/+  
لَا تُبْقِي وَلَا تَذَرُ
Yoruba
 
(Saƙọr) kò níí ṣẹ́ ẹ kù, kò sì níí pa á tì.


Ayah  74:30  الأية
    +/- -/+  
عَلَيْهَا تِسْعَةَ عَشَرَ
Yoruba
 
(Àwọn mọlāika) mọ́kàndínlógún ni ẹ̀ṣọ́ rẹ̀.

Ayah  74:31  الأية
    +/- -/+  
وَمَا جَعَلْنَا أَصْحَابَ النَّارِ إِلَّا مَلَائِكَةً ۙ وَمَا جَعَلْنَا عِدَّتَهُمْ إِلَّا فِتْنَةً لِّلَّذِينَ كَفَرُوا لِيَسْتَيْقِنَ الَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ وَيَزْدَادَ الَّذِينَ آمَنُوا إِيمَانًا ۙ وَلَا يَرْتَابَ الَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ وَالْمُؤْمِنُونَ ۙ وَلِيَقُولَ الَّذِينَ فِي قُلُوبِهِم مَّرَضٌ وَالْكَافِرُونَ مَاذَا أَرَادَ اللهُ بِهَٰذَا مَثَلًا ۚ كَذَٰلِكَ يُضِلُّ اللهُ مَن يَشَاءُ وَيَهْدِي مَن يَشَاءُ ۚ وَمَا يَعْلَمُ جُنُودَ رَبِّكَ إِلَّا هُوَ ۚ وَمَا هِيَ إِلَّا ذِكْرَىٰ لِلْبَشَرِ
Yoruba
 
Àwa kò ṣe ẹnì kan ní ẹ̀ṣọ́ Iná àfi àwọn mọlāika. Àwa kò sì ṣe òǹkà wọn (bẹ́ẹ̀) bí kò ṣe (nítorí kí ó lè jẹ́) àdánwò fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, àti nítorí kí àwọn tí A fún ní Tírà lè ní àmọ̀dájú àti nítorí kí àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ ní òdodo lè lékún ní ìgbàgbọ́ òdodo. (Ó rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí àwọn tí A fún ní Tírà àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo má baà ṣeyèméjì àti nítorí kí àwọn tí àrùn wà nínú ọkàn wọn àti àwọn aláìgbàgbọ́ lè wí pé: "Kí ni Allāhu gbà lérò pẹ̀lú àpèjúwe yìí?" Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣi ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́nà, Ó sì ń tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sọ́nà. Kò sì sí ẹni tí ó mọ àwọn ọmọ ogun Olúwa rẹ àfi Òun náà. (Iná Saƙọr) kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ìrántí fún abara.


Ayah  74:33  الأية
    +/- -/+  

Ayah  74:34  الأية
    +/- -/+  
وَالصُّبْحِ إِذَا أَسْفَرَ
Yoruba
 
Ó tún fi òwúrọ̀ nígbà tí ojúmọ́ bá mọ́ búra.

Ayah  74:35  الأية
    +/- -/+  
إِنَّهَا لَإِحْدَى الْكُبَرِ
Yoruba
 
Dájúdájú (iná Saƙọr) ni ọ̀kan nínú (àwọn àdánwò) tó tóbi.


Ayah  74:37  الأية
    +/- -/+  
لِمَن شَاءَ مِنكُمْ أَن يَتَقَدَّمَ أَوْ يَتَأَخَّرَ
Yoruba
 
Fún ẹni tí ó bá fẹ́ nínú yín láti tẹ̀ síwájú tàbí láti fà sẹ́yìn (nínú ẹ̀ṣẹ̀).

Ayah  74:38  الأية
    +/- -/+  
كُلُّ نَفْسٍ بِمَا كَسَبَتْ رَهِينَةٌ
Yoruba
 
Ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ni onídùúró fún ohun tó ṣe níṣẹ́.

Ayah  74:39  الأية
    +/- -/+  

Ayah  74:40  الأية
    +/- -/+  
فِي جَنَّاتٍ يَتَسَاءَلُونَ
Yoruba
 
Wọn yóò máa bira wọn léèrè ọ̀rọ̀ nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra


Ayah  74:42  الأية
    +/- -/+  

Ayah  74:43  الأية
    +/- -/+  
قَالُوا لَمْ نَكُ مِنَ الْمُصَلِّينَ
Yoruba
 
Wọn yóò wí pé: "Àwa kò sí nínú àwọn olùkírun ni.

Ayah  74:44  الأية
    +/- -/+  
وَلَمْ نَكُ نُطْعِمُ الْمِسْكِينَ
Yoruba
 
Àwa kò sì sí nínú àwọn tó ń bọ́ àwọn mẹ̀kúnnù.

Ayah  74:45  الأية
    +/- -/+  
وَكُنَّا نَخُوضُ مَعَ الْخَائِضِينَ
Yoruba
 
Àwa sì máa ń sọ ìsọkúsọ pẹ̀lú àwọn onísọkúsọ.

Ayah  74:46  الأية
    +/- -/+  
وَكُنَّا نُكَذِّبُ بِيَوْمِ الدِّينِ
Yoruba
 
Àti pé àwa máa ń pe Ọjọ́ ẹ̀san ní irọ́

Ayah  74:47  الأية
    +/- -/+  

Ayah  74:48  الأية
    +/- -/+  
فَمَا تَنفَعُهُمْ شَفَاعَةُ الشَّافِعِينَ
Yoruba
 
Ìpẹ̀ àwọn olùṣìpẹ̀ kò sì níí ṣe wọ́n ní àǹfààní.

Ayah  74:49  الأية
    +/- -/+  
فَمَا لَهُمْ عَنِ التَّذْكِرَةِ مُعْرِضِينَ
Yoruba
 
Kí ló mú wọn ná tí wọ́n ń gbúnrí kúrò níbi ìrántí

Ayah  74:50  الأية
    +/- -/+  
كَأَنَّهُمْ حُمُرٌ مُّسْتَنفِرَةٌ
Yoruba
 
Bí ẹni pé àwọn ni kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tó ń sá lọ,


Ayah  74:52  الأية
    +/- -/+  
بَلْ يُرِيدُ كُلُّ امْرِئٍ مِّنْهُمْ أَن يُؤْتَىٰ صُحُفًا مُّنَشَّرَةً
Yoruba
 
Rárá, ńṣe ni ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú wọn ń fẹ́ kí Á fún òun náà ní Tírà tí ó máa ṣeé tẹ́ han àwọn ènìyàn (bíi ti al-Ƙur'ān).

Ayah  74:53  الأية
    +/- -/+  
كَلَّا ۖ بَل لَّا يَخَافُونَ الْآخِرَةَ
Yoruba
 
Rárá. Wọn kò páyà ọ̀run ni.

Ayah  74:54  الأية
    +/- -/+  
كَلَّا إِنَّهُ تَذْكِرَةٌ
Yoruba
 
Ẹ gbọ́! Dájúdájú al-Ƙur'ān ni ìrántí.

Ayah  74:55  الأية
    +/- -/+  
فَمَن شَاءَ ذَكَرَهُ
Yoruba
 
Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́, kí ó rántí rẹ̀.

Ayah  74:56  الأية
    +/- -/+  
وَمَا يَذْكُرُونَ إِلَّا أَن يَشَاءَ اللهُ ۚ هُوَ أَهْلُ التَّقْوَىٰ وَأَهْلُ الْمَغْفِرَةِ
Yoruba
 
Wọn kò sì níí rántí (al-Ƙur'ān) àfi tí Allāhu bá fẹ́. (Allāhu) Òun l'a gbọ́dọ̀ bẹ̀rù. Òun l'ó sì ni àforíjìn.
 


© EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us